yo_eph_text_reg/04/28.txt

1 line
661 B
Plaintext

\v 28 Ẹnití ó n jalè, kò gbọdọ̀ jalè mọ́. Ó gbọ́dọ̀ sisẹ́, isẹ́ tí ó wúlò pẹ̀lú ọwọ́ ara rẹ̀, kí òun pẹ̀lú kí ó lè ní ohun tí ó lè pín pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn tí ó se aláìní. \v 29 Ẹ máse jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìdíbàjẹ́ kan kí ó ti ẹnu yín jáde. Ẹ máa lo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé ni ró gẹ́gẹ́bí aìní olukúlùkù, kí ọ̀rọ̀ yín lè jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tí ó bá ń gbọ́ yín \v 30 Ẹ má sì se mú Ẹ̀mímímọ́ Ọlọ́run bínú, nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ ni a se èdìdí yín fún ọjọ́ ìràpadà.