yo_php_text_ulb/04/04.txt

1 line
532 B
Plaintext

\v 4 Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbàgbogbo. Lẹ́ẹ̀kansíì màá tún sọ pe, ẹ máa yọ̀. \v 5 Ẹ jẹ́ kí ìwàpẹ̀lẹ́ yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn. Olúwa wà nítòsí. \v 6 Ẹ má ṣe káyàsókè nítori ohunkóhun. Kàkà bẹ́ẹ̀, nínú àdúrá áti ẹ̀bẹ̀, pẹ̀lú ọpẹ́, ẹ sọ ẹ̀bẹ̀ yín di mímọ̀ fún Ọlọ̀run, \v 7 àlàáfíà Ọlọ́run tí ó tayọ gbogbo òye yíò sì pa àwọn ọkàn àti àwọn èrò yín mọ́ nínú Krístì Jésù.