\v 17 Ṣùgbọ́n bí a bá tilẹ̀ pa mí bíi ọrẹ lórí ìrúbọ àti iṣẹ́ ìsìn ìgbàgbọ́ yín, èmí yọ̀, èmí yóò sì yọ̀ pẹ̀lú gbogbo yín. \v 18 Bákannáà kí ẹ̀yin kí ó yọ̀, kí ẹ sì yọ̀ pẹ̀lú mi.