adesinaabegunde_yo_tit_text.../02/06.txt

1 line
432 B
Plaintext

\v 6 Ní ọ̀nà kannǎ, gba àwọn okùnrin kékeré níyànjú láti jẹ́ ọlọ́pọlọ-pípé. \v 7 Ní ọ̀nà gbogbo fi ara rẹ hàn ní àpẹẹrẹ isẹ́ rere; àti nígbà tí ìwọ bá ń kọ́ni, fi ìwà òtítọ́ àti àgbà hàn. \v 8 Sọ ọ̀rọ̀ tí ó yè koro àti aláìlẹ́bi, kí ojú le è ti ẹnikẹ́ni tí ó bá lòdì si, nítorí kò ní ohun búburú kan láti sọ nípa wa.