adesinaabegunde_yo_tit_text.../01/01.txt

1 line
528 B
Plaintext

\c 1 \v 1 Póólu, ìránsẹ́ Ọlọ́run àti àpóstélì Jésù Krístì, fún ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn Ọlọ́run tí a yàn àti ìmọ̀ òtítọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìwà-mímọ́, \v 2 pẹ̀lú ìgboyà iyè àìnípẹ̀kun tí Ọlọ́run, tí kìí parọ́, ti se ìlérí sáájú ki ayé tó bẹ̀rẹ̀ . \v 3 Ní àkókò tí ó tọ́, ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó fi rán mi hàn pẹ̀lú ìgbàgbọ́ láti jísẹ́. Ó yẹ kí n se èyí nípa àsẹ Ọlọ́run Olùgbàlà wa.