adesinaabegunde_yo_php_text.../04/10.txt

1 line
808 B
Plaintext

\v 10 Mo yọ̀ gidigidi nínú Olúwa nítorí nísinsìnyí, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ẹ ti sọ àníyán yín fún mi dọ̀tun. Lóòótọ́ ni ọrọ mí ti ká yín làra tẹ́lẹ, ṣùgbọ́n ẹ kò ní àǹfàní láti ṣe ìrànlọ́wọ́. \v 11 Èmi kò sọ èyí nítorí pé mo ṣe aláìní. Nítorí mo ti kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínu ipòkípò tí mo bá wà. \v 12 Mo mọ ohun tí ó pè fún láti ṣe àìní, bẹ́ẹ̀ sì ni mo mọ ohun tí ó pè fún láti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. Ní gbogbo ọ̀nà àti nínú ohun gbogbo mo ti kọ́ bí a ṣe ń jẹ àjẹyó tàbí bí a ṣe ń wà lébi, bí a ṣe ń wà nínú ọ̀pọ̀ tàbí bí a ṣe ń ṣe aláìní. \v 13 Mo lè ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ Ẹnití ó fi okun fún mi.