adesinaabegunde_yo_php_text.../01/12.txt

1 line
454 B
Plaintext

\v 12 Ǹjẹ́, ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi ti mú kí ìhìnrere gbilẹ̀ síi. \v 13 Nítorí ìdí èyí, ó ti di mímọ̀ fún gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààfin àti àwọn yókù pé mo jẹ́ òǹdè fún Krístì. \v 14 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará ni wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run síi nítorí ìdè mi tí wọ́n sì ní ìgboyà láti sọ ọ̀rọ̀ náà.