\c 1 \v 1 Pọ́ọ̀lù àti Tìmótíù, àwọn ìráńṣẹ́ Krístì Jésù, sí gbogbo àwọn tí a yà sọ́tọ̀ nínú Krístì Jésù tí wọ́n wà ní Fílípì, pẹ̀lú àwọn alábójútó àti àwọn díákónì. \v 2 Oore-ọ̀fẹ́ fún yín àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Bàbá wa àti Olúwa wa Jésù Krístì.