adesinaabegunde_yo_mrk_text.../15/01.txt

1 line
437 B
Plaintext

\c 15 \v 1 Ní àárọ̀ kùtùkùtù, àwọn olórí àlúfàà pàdé pẹ̀lú àwọn àgbààgbà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé àti gbogbo ìgbìmọ̀ àwọn Júù. Lẹ́yìn náà ni wọ́n so Jésù, wọ́n sì múu lọ. Wọ́n fi lé Pílátù lọ́wó. \v 2 Pílátù bií, "Sé ìwọ ni ọba àwọn Júù bí?" Ó dáalóhùn, "Ìwọ́ wí." \v 3 Àwọn olórí àlùfáà ń fi ẹ̀sùn púpọ̀ kan Jésù.