adesinaabegunde_yo_mrk_text.../04/38.txt

1 line
365 B
Plaintext

\v 38 Jesu ti sùn lọ lẹ́yìn ọkọ̀, ó gbé orí lé ìrọ̀rí. Wọ́n sì jí i wọ́n wí pé, “Olùkọ́ni, ǹjẹ́ ìwọ kò tilẹ̀ bìkítà pé gbogbo wa fẹ́ kú?” \v 39 Ó dìde, ó bá ìjì líle náà wí, ó sì wí fún òkun pé, “Àlááfíà! Dákẹ́ Jẹ́ẹ́!” Ìjì náà sì dá, ìparọ́rọ́ ńlá sì wà.