adesinaabegunde_yo_mrk_text.../04/26.txt

1 line
548 B
Plaintext

\v 26 Ó sì tún sọ pé, “Ìjọba Ọlọ́run dàbí okùnrin kan tí ó ń fúnrúgbìn sí ilẹ̀. \v 27 Ó ń sùn ní óru àti ní ọ̀sán ó dìde, irúgbìn náà hu jáde, ó sì dàgbà, òun kò sì mọ̀ bí ó ti ṣẹlẹ̀. \v 28 Nítorí tí ilẹ̀ hù èso jáde fún ara rẹ̀: ó mú èéhù ewé jáde, lẹ́yìn náà ní orí ọkà, ní ìparí ní orí ọkà tí ó ti gbó. \v 29 Nígbà tí èso bá gbó tán, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun a tẹ dòjé bọ inú ọkà náà, nítorí ìkórè ti dé."