adesinaabegunde_yo_mrk_text.../10/13.txt

1 line
452 B
Plaintext

\v 13 Lẹ́yìn náà wọ́n kó àwọn ọmọ wọn wẹẹrẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ kí ó le fi ọwọ́ kàn wọ́n, sùgbọ́n àwọn ọmọ ẹyìn bá wọn wí. \v 14 Ṣùgbọ́n nígbàtí Jésù se àkíyèsi rẹ̀, inú rẹ̀ kò dùn rárá ó sì wí fún wọn pé "ẹ jẹ́kí àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ mi, ẹ máse dí wọn lọ́wọ́, nítorí ìjọba Ọlọ́run wà fún àwọn tó dàbí wọn.