adesinaabegunde_yo_mrk_text.../10/01.txt

1 line
590 B
Plaintext

\c 10 \v 1 Jésù fi ibẹ̀ sílẹ̀ ó lọ sí agbègbè Jùdéà àti sí ìkọjá odò Jọ́rdánì, ọ̀pọ̀ àwọn èrò sì tún tọ̀ọ́ wá. ó tún nkọ́ wọn lẹ́ẹ̀kan si gẹ́gẹ́bí ó ti má n se. \v 2 Nígbànáà ni àwọn Farisí wá sọ́dọ̀ọ rẹ̀ láti dán-an wò wọ́n bèrè wípé, " ǹjẹ́ ó bá òfin mu kí ọkọ kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀?" \v 3 ó dá wọn lóhùn, " kínni Mósè palásẹ fún yín?" \v 4 Wọ́n wípé, "Mósè fi àyè gba ọkùnrin láti kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ kí ó sì lée jáde."