adesinaabegunde_yo_mrk_text.../08/07.txt

1 line
547 B
Plaintext

\v 7 Wọ́n tún ní àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀ pẹ̀lú, lẹ́yìn tí ó dúpẹ́, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti pín wọn fún àwọn ènìyàn náà. \v 8 Wọ́n jẹun wọ́n sì yó, wọ́n kó àjẹkù ti ó kù jọ, agbọ̀n méje sì kún. \v 9 Àwọn tí ó wà níbẹ̀ tó ìwọ̀n ẹgbàajì ènìyàn. Ó sì rán wọn lọ. \v 10 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó wọ inú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì lọ sí agbègbè Dálímánútà.