adesinaabegunde_yo_mrk_text.../08/01.txt

1 line
659 B
Plaintext

\c 8 \v 1 Ní ọjọ́ wọǹnì, bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti péjọ, wọn kò sí ní oúnjẹ láti jẹ. Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, \v 2 “Àánú ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí ṣe mí, nítorí pé ó tó ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n ti wà pẹ̀lú ù mi kò sì sí ohun tí wọn yóò jẹ. \v 3 Bí mo bá rán wọn lọ sí ilé wọn láì jẹun, wọn le dákú lójú ọ̀nà. Àwọn mìíràn nínú wọn ti ọ̀nà jíjìn wá.” \v 4 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Níbo ni a ó ti rí àkàrà tí ó tó láti fi bọ́ wọn nínú aṣálẹ̀ yìí?”