\v 17 Ẹnìkan láàrín èrò sì dáhùn ó wípé, "Olùkó, mo mú ọmọ mi tọ̀ Ọ́ wá.Ẹ̀míkẹ́mìí kan ti jẹ́ kó ya odi \v 18 Ó má ń gbáa mú, á sì gbée sánlẹ̀, bẹ́ẹ̀ni ó má ń mú kí ó máa pòfóló, kí ó sì ma payín keke, òun á sì gan pa. Mo bẹ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ kí wọ́n leèle jáde kúrò nínú rẹ̀ sùgbọ́n wọn kò leè ṣeé." \v 19 Ó sì wí fun wọn pé, "Ìran aláìgbàgbọ́, èmi ó ti bá n yín gbé pẹ́ tó? Èmi ó ti mú sùúrù pẹ́ tó fún n yín? Mú u wá fún mi.?"