\v 4 Jésù sì wí fún wọn pé, "Wôlí kìí sa láì lọ́lá, àyàfi lárin ìlú rẹ̀, àti lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, àti nínú ilé rẹ̀." \v 5 Kò sì le sisẹ́ ìyanu lárin wọn, Ó kàn gbé ọwọ́ lé àwọn aláìsàn díẹ̀, Ó sì wò wón sàn. \v 6 Ẹnú sì yàá nítorí àìgbàgbọ́ wọn, Ó sì jáde lọ sí àwọn abúlé láti kọ́ wọn.