\v 9 Ẹ wà ní ìgbáradì. Nwọn ó jọ̀wọ́ yín fún àwọn ìjòyè, a ó sì nà yín nínú àwọn sínágógù. Ẹ̀yin yóò dúró ní iwájú àwọn gómìnà ati àwọn ọba nítorí mi, bi ẹ̀rí fún wọn. \v 10 Ṣùgbọ́n a kọ́kọ́ kéde ìhìnrere ní gbogbo orílẹ̀-èdè.