adesinaabegunde_yo_mat_text.../10/21.txt

1 line
520 B
Plaintext

\v 21 Arákùnrin yóò jọ̀wọ́ arákùnrin rẹ̀ fún ikú, àti bàbá ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ yóò dìde lòdì sí àwọn òbí wọn láti jẹ́ kí wọ́n pa wọ́n. \v 22 A ó kórira yín nítorí orúkọ mi. Ṣùgbọ́n, ẹnití ó bá forítǐ dé òpin, ni a ó gbàlà. \v 23 Nígbàtí wọ́n bá pọ́nyínlójú ní ìlú yǐ, ẹ sá lọ sí òmíràn, nítorí looto ni mo wí fún yín, ẹ kò tí ì le la gbogbo ìlú Israeli kọjá tán kí Ọmọ Ènìyan yóò fi dé.