adesinaabegunde_yo_mat_text.../28/08.txt

1 line
495 B
Plaintext

\v 8 Àwọn obìnrin náà tètè kúrò níbi ibojì náà pẹ̀lú ẹ̀rù àti ayọ̀ ńlá, wọ́n sì sáré lọ sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. \v 9 Kíyèsi, Jésù pàdé wọn ó ṣì wípé, "Àlàáfíà fún yín!" Àwọn obìnrin náà wá, wọ́n dì í ní ẹṣẹ̀ mú wọ́n sì sìn ín. \v 10 Jésù sì wí fún wọn pé, "Ẹ má bẹ̀rù. Ẹ lọ sọ fún àwọn arákùnrin mi kí wọn lọ sí Gálílì. Ibẹ̀ ni wọn yóò ti rí mi."