adesinaabegunde_yo_mat_text.../28/05.txt

1 line
566 B
Plaintext

\v 5 Áńgẹ́lì náà bá àwọn obìnrin náà sọ̀rọ̀ wípé "Ẹ má bẹ̀rù, nítorí mo mọ̀ wípé ẹ̀yin ń wá Jésù, tí wọ́n ti kàn mọ́ àgbélèbú. \v 6 Kòsí níbíyìí, ṣùgbọ́n ó ti jí dìde gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ. Ẹ wá wò ibi tí wọ́n tẹ́ Olúwa sí. \v 7 Ẹ tètè lọ kí ẹ sì wí fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, 'Ó ti jí dìde kúrò láàrin àwọn òkú. Ẹ wò ó, ó ń ṣiwájú yín lọ sí Gálílì. Ibẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti rí i.' Ẹ wò ó, èmi ti so fún yín."