adesinaabegunde_yo_mat_text.../05/21.txt

1 line
517 B
Plaintext

\v 21 Ẹ ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará àtijọ́, 'Ìwọ máṣe pàniyàn', àti pé, 'Ẹni tí ó bá pàniyàn yóó wà ní ewu ìdájọ́'. \v 22 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé gbogbo ẹni tí ó bá bínú sí arákùnrin rẹ̀ yóó wà ní ewu ìdájọ́; àti ẹnikẹ́ni tí ó bá wí fún arákùnrin rẹ̀ pé 'ìwọ aláìníláárí!' yóó wà ní ewu ìgbìmọ̀, àti ẹnikẹ́ni tí ó bá wí pé 'Ìwọ aláìlọ́gbọ́n!' yóó wà ní ewu ọ̀run àpáàdì.