\v 7 Nígbànà ni Hẹ́rọ́dù pe àwọn amòye náà sí ìkọ̀kọ̀ láti se ìwádìí àkókò tí ìràwọ̀ náà fi ara hàn? \v 8 Ó rán wọn lọ sí Bẹ́thlẹ́hẹ́mù, wípé "Ẹ lọ kí ẹ se ìwádìí dájúdájú fún mi nípa ọ̀dọ́modé náà. Nígbàtí ẹ bá sì ti ríi, ẹ padà wá sọ fún mi kí èmi pẹ̀lú le lọ láti fi orí balẹ̀ fún un.