\v 9 Jẹ́ kí òtòṣì arákùnrin ṣògo nínú ipò gíga rẹ̀, \v 10 sùgbọ́n ọlọ́rọ̀ nínú ipò ìrẹ̀sílẹ̀ rẹ̀, nítorí yóò kọjá lọ gẹ́gẹ́bí ìtànná koríko ìgbẹ́. \v 11 Nítorí òòrùn ń ráǹ pẹ̀lú ooru iná tí ó ń jó, ó sì ń mú kí àwọn koríko gbẹ. Òdòdó já lulẹ̀, ẹwà rẹ̀ sí ṣègbé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọlọ́rọ̀ yóò parẹ́ ní àárín gbùgbùn ìrìn àjò rẹ̀.