adesinaabegunde_yo_col_text.../01/21.txt

1 line
693 B
Plaintext

\v 21 Ẹ̀yin pẹ̀lú ti jẹ́ àlejó sí Ọlọ́run àti ọ̀tá nígbàkan rí nínú ọkàn yín àti nínú àwọn ìṣe búburú yín. \v 22 Ṣùgbọ́n nísinsìnyí Òun ti ṣe ìbálàjà fún yín nípaṣẹ ikú Rẹ̀. Òun ṣe èyí láti mú yín wá síwájú Rẹ̀ ní mímọ́, àìlábàwọ́n àti àìlábùkù, \v 23 bí ẹ̀yin bá tẹ̀síwájú nínú ìgbàgbọ́, ní ìfẹsẹ̀múlẹ̀ àti ìdúróṣinṣin, láì yọ ẹsẹ̀ kúrò nínú ìrètí ìyìnrere tí ẹ ti gbọ́. Èyí ni ìyìnrere tí a ti kéde fún gbogbo ènìyàn lábẹ́ ọ̀run. Eléyìí ni ìyìnrere tí èmi, Pọ́ọ̀lù, jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ́.