\v 18 Má se jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ti ó nfẹ́ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ abí ìsin àwọn ángẹ́lì se ìdájọ́ yín kúrò nínú ère yín. Irúfẹ́ ènìyàn bíwọ̀nyí a máa wọnú àwọn ohun ti ó rí àti pe asì màa gbéraga ni èro rẹ̀. \v 19 Òn kò sí ni ara orí. Láti ara orí ni ẹ̀ya ara gbogbo jákèjádò àwọn oríkeríkèé atí iṣan ti ngba ìpèsè tí wọn si so papọ́; o ndàgbà pẹ̀lú ìdàgbà ti Ọlọrun fi fun.