adesinaabegunde_yo_3jn_text.../01/01.txt

1 line
537 B
Plaintext

\c 1 \v 1 Alàgbà náà sí Gáíù olùfẹ́, ẹnití mo fẹ́ràn ní òtítọ́. \v 2 Olùfẹ́, mo gbàdúrà pé kí o le ṣe rere nínú ohun gbogbo àti kí o sì wà ní ìlera, gẹ́gẹ́ bí ọkàn rẹ se ń ṣe rere. \v 3 Nítorí mo yọ ayọ̀ ńláńlá nígbàtí àwọn arákùnrin dé tí wọ́n sì j'ẹ̀rí sí òtítọ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí o ti fi òtítọ́ rìn. \v 4 Èmi kò ní ayọ̀ ńlá kan tí óju báyìí lọ, láti gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń rìn nínú òtítọ́.