adesinaabegunde_yo_2th_text.../01/03.txt

1 line
651 B
Plaintext

\v 3 A gbọdọ̀ máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nígbàgbogbo fún yín, ará. Nítorí èyí ni ó tọ̀nà, nítorípé ìgbàgbọ́ yín ń dàgbà púpọ̀púpọ̀ àti ìfẹ́ olúkúlùkù sí ara wọn ń pọ̀si. \v 4 Nítorí náà ni àwa tìkarawa fi ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìgboyà nípa yín láàrin ìjọ Ọlọ́run. À ń sọ̀rọ̀ sùúrù àti ìgbàgbọ́ nínú gbogbo inúnibíni yín. À ń sọ̀rọ̀ nípa wàhálà tí ẹ faradà. \v 5 Èyí ni àpẹẹrẹ ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run. Ère rẹ̀ ni pé a ó kà yín yẹ ní ìjọba Ọlọ́run nínú èyí tí ẹ jìyà lé lórí.