adesinaabegunde_yo_2th_text.../03/06.txt

1 line
794 B
Plaintext

\v 6 Ǹjẹ́, ará, ní orúkọ Olúwa wa Jésù Krístì, apaá lásẹ fún yín pé, kí ẹ yàgò fún àwọn ará tí ó n se ìmẹ́lẹ́ àti tí wọn kò rìn ní ìbamu pẹ̀lú ìlànà tí ẹti gbà láti ọ̀dọ wa. \v 7 Nítorí ẹ̀yin tìkarayín mọ̀ pe ohun tí ó tọ̀nà ni fún yín láti máa wo àwòkóse wa. Nítorí àwa kò gbé làárín yín bíi ẹnití kò lẹ́kọ̀ọ́. \v 8 Àwa kò jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni láì san owó. Dípò èyí, àwá ṣisẹ́ ní ọ̀sán àti ní òru pẹ̀lú agbárakáká, làálàá ati aápọn, kí àwá má baà jẹ́ àjàgà fún yín. \v 9 Àwa ṣìṣe èyí láti jẹ́ àpẹre rere fún yín àti pé, ki ẹ̀yin le tẹ̀lé àwòkọ́ṣe wa, kìí ṣepé àwa kòní àṣẹ.