adesinaabegunde_yo_1ti_text.../06/03.txt

1 line
635 B
Plaintext

\v 3 Bí ẹnikẹ́ni bá n kọ́ ni nì ẹ̀kọ́ ọ̀tọ̀ tí kò si gba ẹ̀kọ́ òtítọ́ wa, èyí nì, ọ̀rọ̀ Ọlúwa wa Jésù Kristì. Bí wọ́n kò bá gba ẹ̀kọ́ tó n yọrísí ìwà-bí-Ọlórun. \v 4 Ẹni na jẹ́ onígbéraga àti aláimọ̀kan. Dípò, ó ní àìsàn pèlú àríyànjiyàn àti ìjìyàn nípa ọ̀rọ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ yi já sí ìlara, ìjà, ẹ̀gàn, ìfura ibi àti \v 5 rògbòdìyàn gbogbo ìgbà lárìín àwọn èyàn pèlú ọ̀kàn ibi. Wọ́n lòdì sí òtítọ́. Wọ́n rò wípé ìwà-bí-Ọlórun jé ọ̀na láti di ọlọ́rọ̀.