adesinaabegunde_yo_1ti_text.../02/08.txt

1 line
531 B
Plaintext

\v 8 Nítorínà, kí gbogbo ènìyàn níbi gbogbo máa gbàdúra àti kí wọ́n sì gbé ọwọ́ sókè ní àìsí ìbínú ati àríyànjiyàn. \v 9 Bákannáà, mo fẹ́ kí àwọn obìnrin máa wọ ara wọn ní asọ tí ó tọ́nà, ní ìwọ̀ntunwọ̀nsì àti ní ìkoraẹni-ní-ìjanu. kìí ṣe níti irun dídí, tàbí wúrà, tàbí ọ̀ṣọ́, tàbí asọ olówó-iyebíye. \v 10 Kí wọ́n máa wọ ohun tí ó tọ̀ọ̀nà fún obìnrin tó ń kéde ìwàbí-Ọlórun nípa iṣẹ́ rere.