Biblica_yoOBYO17/642JNyoOBYO17.SFM

36 lines
2.6 KiB
Plaintext

\id 2JN - Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible (Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
\rem Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
\h 2 Johanu
\toc1 Ìwé Johanu Kejì
\toc2 2 Johanu
\toc3 2Jh
\mt1 Ìwé Johanu Kejì
\c 1
\p
\v 1 \x - \xo 1: \xt 3Jh 1.\x*Alàgbà,
\b
\p Sì àyànfẹ́ obìnrin ọlọ́lá àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn tí mo fẹ́ ní òtítọ́, kì í sì í ṣe èmi nìkan, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó mọ òtítọ́ pẹ̀lú;
\v 2 nítorí òtítọ́ tí ń gbé inú wa, yóò sì bá wa gbé títí:
\b
\p
\v 3 Oore-ọ̀fẹ́, àánú, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba, àti láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, Ọmọ Baba, yóò wà pẹ̀lú wa nínú òtítọ́ àti nínú ìfẹ́.
\b
\b
\p
\v 4 Mo yọ̀ gidigidi pé mo rí nínú àwọn ọmọ rẹ tí ń rìn nínú òtítọ́, gẹ́gẹ́ bí Baba ti pa àṣẹ fún wa.
\v 5 \x - \xo 5: \xt Jh 13.34.\x*Ǹjẹ́ nísinsin yìí, mo bẹ̀ ọ́, obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe bí ẹni pé èmi ń kọ̀wé òfin tuntun kan sí ọ, bí kò ṣe èyí ti àwa tí ní ní àtètèkọ́ṣe, pé kí àwa fẹ́ràn ara wa.
\v 6 \x - \xo 6: \xt 1Jh 5.3.\x*Èyí sì ni ìfẹ́, pé, kí àwa máa rin nípa òfin rẹ̀, èyí ni òfin náà, àní bí ẹ ti gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé, kí ẹ̀yin rìn nínú rẹ̀.
\p
\v 7 \x - \xo 7: \xt 1Jh 2.22.\x*Nítorí ẹlẹ́tàn púpọ̀ ti jáde wa sínú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá nínú ara. Èyí ni ẹlẹ́tàn àti aṣòdì sí Kristi.
\v 8 Ẹ kíyèsára yín, kí ẹ má ba à sọ iṣẹ́ tí ẹ tí ṣe nù, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè rí èrè kíkún gbà.
\v 9 Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń rú òfin tí kò si dúró nínú ẹ̀kọ́ Kristi, kò mọ Ọlọ́run. Ẹni tí ó bá dúró nínú ẹ̀kọ́, òun ni ó mọ Baba àti Ọmọ.
\v 10 Bí ẹnikẹ́ni bá tọ̀ yín wá, tí kò sì mu ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má ṣe gbà á sí ilé, kí ẹ má sì ṣe kí i kú ààbọ̀.
\v 11 Nítorí ẹni tí ó bá kí kú ààbọ̀, ó ní ọwọ́ nínú iṣẹ́ búburú rẹ̀.
\b
\b
\p
\v 12 \x - \xo 12: \xt 1Jh 1.4; 3Jh 13.\x*Bí mo tilẹ̀ ní ohun púpọ̀ láti ṣe alábápín pẹ̀lú yín, síbẹ̀ èmi kò fẹ́ lo ìwé ìkọ̀wé àti jẹ́lú ìkọ̀wé. Ṣùgbọ́n èmi ní ìrètí láti tọ̀ yín wá àti láti bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú, kí ayọ̀ yín bá à le è kún.
\b
\p
\v 13 Àwọn ọmọ arábìnrin rẹ àyànfẹ́ kí ọ.