Biblica_yoOBYO17/43LUKyoOBYO17.SFM

1960 lines
219 KiB
Plaintext
Raw Permalink Blame History

This file contains invisible Unicode characters

This file contains invisible Unicode characters that are indistinguishable to humans but may be processed differently by a computer. If you think that this is intentional, you can safely ignore this warning. Use the Escape button to reveal them.

This file contains Unicode characters that might be confused with other characters. If you think that this is intentional, you can safely ignore this warning. Use the Escape button to reveal them.

\id LUK - Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible (Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
\rem Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
\h Luku
\toc1 Ìwé Ìyìnrere Luku
\toc2 Luku
\toc3 Lk
\mt1 Ìwé Ìyìnrere Luku
\c 1
\p
\v 1 Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó ti dáwọ́lé títo àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì jọ lẹ́sẹẹsẹ, èyí tí ó ti múlẹ̀ ṣinṣin láàrín wa,
\v 2 \x - \xo 1.2: \xt 1Jh 1.1; Ap 1.21; Hb 2.3.\x*àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó ṣe ojú wọn láti ìbẹ̀rẹ̀ ti fi lé wa lọ́wọ́.
\v 3 \x - \xo 1.3: \xt Ap 1.1.\x*Nítorí náà, ó sì yẹ fún èmi pẹ̀lú, láti kọ̀wé sí ọ lẹ́sẹẹsẹ bí mo ti wádìí ohun gbogbo fínní fínní sí láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, Teofilu ọlọ́lá jùlọ,
\v 4 \x - \xo 1.4: \xt Jh 20.31.\x*kí ìwọ kí ó le mọ òtítọ́ ohun wọ̀n-ọn-nì, tí a ti kọ́ ọ.
\s1 Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ibí Johanu onítẹ̀bọmi
\p
\v 5 \x - \xo 1.5: \xt Mt 2.1; 1Ki 24.10; 2Ki 31.2.\x*Nígbà ọjọ́ Herodu ọba Judea, àlùfáà kan wà, láti ìran Abijah, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Sekariah: aya rẹ̀ sì ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Aaroni, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Elisabeti.
\v 6 Àwọn méjèèjì sì ṣe olódodo níwájú Ọlọ́run, wọ́n ń rìn ní gbogbo òfin àti ìlànà Olúwa ní àìlẹ́gàn.
\v 7 Ṣùgbọ́n wọn kò ní ọmọ, nítorí tí Elisabeti yàgàn; àwọn méjèèjì sì di arúgbó.
\p
\v 8 Ó sì ṣe, nígbà tí ó ń ṣe iṣẹ́ àlùfáà níwájú Ọlọ́run ni àkókò tirẹ̀.
\v 9 \x - \xo 1.9: \xt Ek 30.7.\x*Bí ìṣe àwọn àlùfáà, ipa tirẹ̀ ni láti máa fi tùràrí jóná, nígbà tí ó bá wọ inú tẹmpili Olúwa lọ.
\v 10 Gbogbo ìjọ àwọn ènìyàn sì ń gbàdúrà lóde ní àkókò sísun tùràrí.
\p
\v 11 \x - \xo 1.11: \xt Lk 2.9; Ap 5.19.\x*Angẹli Olúwa kan sì fi ara hàn án, ó dúró ní apá ọ̀tún pẹpẹ tùràrí.
\v 12 Nígbà tí Sekariah sì rí i, orí rẹ̀ wú, ẹ̀rù sì bà á.
\v 13 \x - \xo 1.13: \xt Lk 1.30,60.\x*Ṣùgbọ́n angẹli náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Sekariah: nítorí tí àdúrà rẹ gbà; Elisabeti aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Johanu.
\v 14 Òun yóò sì jẹ́ ayọ̀ àti ìdùnnú fún ọ, ènìyàn púpọ̀ yóò sì yọ̀ sí ìbí rẹ.
\v 15 \x - \xo 1.15: \xt Nu 6.3; Lk 7.33.\x*Nítorí òun ó pọ̀ níwájú Olúwa, kì yóò sì mu ọtí wáìnì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sì mu ọtí líle; yóò sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àní láti inú ìyá rẹ̀ wá.
\v 16 Òun ó sì yí ènìyàn púpọ̀ padà nínú àwọn ọmọ Israẹli sí Olúwa Ọlọ́run wọn.
\v 17 \x - \xo 1.17: \xt Mt 11.14; 17.13; Ml 4.5.\x*Ẹ̀mí àti agbára Elijah ni Olúwa yóò sì fi ṣáájú rẹ̀ lọ, láti pa ọkàn àwọn baba dà sí ti àwọn ọmọ, àti ti àwọn aláìgbọ́ràn sí ọgbọ́n àwọn olóòtítọ́; kí ó le pèsè àwọn ènìyàn tí a múra sílẹ̀ de Olúwa.”
\p
\v 18 Sekariah sì wí fún angẹli náà pé, “Àmì wo ni èmi ó fi mọ èyí? Èmi sá ti di àgbà, àti Elisabeti aya mi sì di arúgbó.”
\p
\v 19 \x - \xo 1.19: \xt Da 8.16; 9.21; Mt 18.10.\x*Angẹli náà sì dáhùn ó wí fún un pé, “Èmi ni Gabrieli, tí máa ń dúró níwájú Ọlọ́run; èmi ni a rán wá láti sọ fún ọ, àti láti mú ìròyìn ayọ̀ wọ̀nyí fún ọ wá.
\v 20 Sì kíyèsi i, ìwọ ó yadi, ìwọ kì yóò sì le fọhùn, títí ọjọ́ náà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ, nítorí ìwọ kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́ tí yóò ṣẹ ní àkókò wọn.”
\p
\v 21 Àwọn ènìyàn sì ń dúró de Sekariah, ẹnu sì yà wọ́n nítorí tí ó pẹ́ nínú tẹmpili.
\v 22 Nígbà tí ó sì jáde wá, òun kò le bá wọn sọ̀rọ̀. Wọn sì kíyèsi wí pé ó ti rí ìran nínú tẹmpili, ó sì ń ṣe àpẹẹrẹ sí wọn, nítorí tí ó yadi.
\p
\v 23 Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ pé, ó lọ sí ilé rẹ̀.
\v 24 Lẹ́yìn èyí ni Elisabeti aya rẹ̀ lóyún, ó sì fi ara rẹ̀ pamọ́ ní oṣù márùn-ún,
\v 25 Ó sì wí pé, “Báyìí ni Olúwa ṣe fún mi ní ọjọ́ tí ó síjú wò mí, láti mú ẹ̀gàn mi kúrò láàrín àwọn ènìyàn.”
\s1 Ìsọtẹ́lẹ̀ ibi Jesu
\p
\v 26 Ní oṣù kẹfà Ọlọ́run sì rán angẹli Gabrieli sí ìlú kan ní Galili, tí à ń pè ní Nasareti,
\v 27 sí wúńdíá kan tí a ṣèlérí láti fẹ́ fún ọkùnrin kan, tí a ń pè ní Josẹfu, ti ìdílé Dafidi; orúkọ wúńdíá náà a sì máa jẹ́ Maria.
\v 28 Angẹli náà sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Àlàáfíà fun ọ, ìwọ ẹni tí a kọjú sí ṣe ní oore, Olúwa ń bẹ pẹ̀lú rẹ.”
\p
\v 29 Ṣùgbọ́n ọkàn Maria kò lélẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ náà, ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, irú kíkí kín ni èyí.
\v 30 \x - \xo 1.30: \xt Lk 1.13.\x*Ṣùgbọ́n angẹli náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Maria, nítorí ìwọ ti rí ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
\v 31 \x - \xo 1.31: \xt Lk 2.21; Mt 1.21.\x*Ìwọ yóò lóyún nínú rẹ, ìwọ ó sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní \nd Jesu\nd*.
\v 32 Òun ó pọ̀, ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó sì máa pè é, Olúwa Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fún.
\v 33 \x - \xo 1.33: \xt Mt 28.18; Da 2.44.\x*Yóò sì jẹ ọba lórí ilé Jakọbu títí láé; ìjọba rẹ̀ kì yóò sì ní ìpẹ̀kun.”
\p
\v 34 \x - \xo 1.34: \xt Lk 1.18.\x*Nígbà náà ni Maria béèrè lọ́wọ́ angẹli náà pé, “Èyí yóò ha ti ṣe rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí èmi kò tí ì mọ ọkùnrin.”
\p
\v 35 \x - \xo 1.35: \xt Mt 1.20.\x*Angẹli náà sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ yóò tọ̀ ọ́ wá, agbára Ọ̀gá-ògo jùlọ yóò síji bò ọ́. Nítorí náà ohun mímọ́ tí a ó ti inú rẹ bí, Ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè é.
\v 36 Sì kíyèsi i, Elisabeti ìbátan rẹ náà yóò sì ní ọmọkùnrin kan ní ògbólógbòó rẹ̀, èyí sì ni oṣù kẹfà fún ẹni tí à ń pè ní àgàn.
\v 37 \x - \xo 1.37: \xt Gẹ 18.14.\x*Nítorí kò sí ohun tí Ọlọ́run kò le ṣe.”
\p
\v 38 Maria sì dáhùn wí pé, “Wò ó ọmọ ọ̀dọ̀ Olúwa; kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.” Angẹli náà sì fi í sílẹ̀ lọ.
\s1 Maria bẹ Elisabeti wò
\p
\v 39 Ní àkókò náà ni Maria sì dìde, ó lọ kánkán sí ilẹ̀ òkè, sí ìlú kan ní Judea;
\v 40 Ó sì wọ ilé Sekariah lọ ó sì kí Elisabeti.
\v 41 Ó sì ṣe, nígbà tí Elisabeti gbọ́ kíkí Maria, ọlẹ̀ sọ nínú rẹ̀; Elisabeti sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́,
\v 42 \x - \xo 1.42: \xt Lk 11.27-28.\x*Ó sì ké ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Alábùkún fún ni ìwọ nínú àwọn obìnrin, alábùkún fún sì ni ọmọ tí ìwọ yóò bí.
\v 43 Èéṣe tí èmi fi rí irú ojúrere yìí, tí ìyá Olúwa mi ìbá fi tọ̀ mí wá?
\v 44 Sá wò ó, bí ohùn kíkí rẹ ti bọ́ sí mi ní etí, ọlẹ̀ sọ nínú mi fún ayọ̀.
\v 45 Alábùkún fún sì ni ẹni tí ó gbàgbọ́, nítorí nǹkan wọ̀nyí tí a ti sọ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò ṣẹ.”
\s1 Orin Maria
\p
\v 46 Maria sì dáhùn, ó ní:
\q1 “Ọkàn mi yin Olúwa lógo.
\q2
\v 47 Ẹ̀mí mi sì yọ̀ sí Ọlọ́run Olùgbàlà mi.
\q1
\v 48 Nítorí tí ó síjú wo ìwà ìrẹ̀lẹ̀
\q2 ọmọbìnrin ọ̀dọ̀ rẹ̀. Sá wò ó,
\q1 láti ìsinsin yìí lọ gbogbo ìran ènìyàn ni yóò máa pè mí ní alábùkún fún.
\q2
\v 49 Nítorí ẹni tí ó ní agbára ti ṣe ohun tí ó tóbi fún mi;
\q2 Mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀.
\q1
\v 50 Àánú rẹ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
\q2 láti ìrandíran.
\q1
\v 51 Ó ti fi agbára hàn ní apá rẹ̀;
\q2 o ti tú àwọn onígbèéraga ká ní ìrònú ọkàn wọn.
\q1
\v 52 Ó ti mú àwọn alágbára kúrò lórí ìtẹ́ wọn,
\q2 o sì gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ lékè.
\q1
\v 53 Ó ti fi ohun tí ó dára kún àwọn tí ebi ń pa
\q2 ó sì rán àwọn ọlọ́rọ̀ padà ní òfo.
\q1
\v 54 Ó ti ran Israẹli ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́,
\q2 ní ìrántí àánú rẹ̀;
\q1
\v 55 \x - \xo 1.55: \xt Mt 7.20; Gẹ 17.7; 18.18; 22.17.\x*sí Abrahamu àti àwọn ìran rẹ̀ láéláé, baba wa,
\q2 àti bí ó ti sọ fún àwọn baba wa.”
\p
\v 56 Maria sì jókòó tì Elisabeti níwọ̀n oṣù mẹ́ta, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀.
\s1 Ìbí Johanu onítẹ̀bọmi
\p
\v 57 Nígbà tí ọjọ́ Elisabeti pé tí yóò bí; ó sì bí ọmọkùnrin kan.
\v 58 Àwọn aládùúgbò, àti àwọn ìbátan rẹ̀ gbọ́ bí Olúwa ti fi àánú ńlá hàn fún un, wọ́n sì bá a yọ̀.
\p
\v 59 \x - \xo 1.59: \xt Le 12.3; Gẹ 17.12.\x*Ó sì ṣe, ní ọjọ́ kẹjọ wọ́n wá láti kọ ọmọ náà nílà; wọ́n sì fẹ́ sọ orúkọ rẹ̀ ní Sekariah, gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba rẹ̀.
\v 60 Ìyá rẹ̀ sì dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Johanu ni a ó pè é.”
\p
\v 61 Wọ́n sì wí fún un pé, “Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ará rẹ̀ tí à ń pè ní orúkọ yìí.”
\p
\v 62 Wọ́n sì ṣe àpẹẹrẹ sí baba rẹ̀, bí ó ti ń fẹ́ kí a pè é.
\v 63 Ó sì béèrè fún wàláà, ó sì kọ ọ wí pé, “Johanu ni orúkọ rẹ̀.” Ẹnu sì ya gbogbo wọn.
\v 64 Ẹnu rẹ̀ sì ṣí lọ́gán, okùn ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì sọ̀rọ̀, ó sì ń yin Ọlọ́run.
\v 65 Ẹ̀rù sì ba gbogbo àwọn tí ń bẹ ní agbègbè wọn, a sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí ká gbogbo ilẹ̀ òkè Judea.
\v 66 Ó sì jẹ́ ohun ìyanu fún gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì tò ó sínú ọkàn wọn, wọ́n ń wí pé, “Irú-ọmọ kín ni èyí yóò jẹ́?” Nítorí tí ọwọ́ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.
\s1 Orin Sakariah
\p
\v 67 Sekariah baba rẹ̀ sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì sọtẹ́lẹ̀, ó ní:
\q1
\v 68 “Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli;
\q2 nítorí tí ó ti bojú wò, tí ó sì ti dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè,
\q1
\v 69 Ó sì ti gbé ìwo ìgbàlà sókè fún wa
\q2 ní ilé Dafidi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀;
\q1
\v 70 (bí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tipẹ́tipẹ́),
\q1
\v 71 Pé, a ó gbà wá là lọ́wọ́
\q2 àwọn ọ̀tá wa àti lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wá.
\q1
\v 72 Láti ṣe àánú tí ó ṣèlérí fún àwọn baba wa,
\q2 àti láti rántí májẹ̀mú rẹ̀ mímọ́,
\q1
\v 73 ìbúra tí ó ti bú fún Abrahamu baba wa,
\q1
\v 74 láti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,
\q2 kí àwa kí ó lè máa sìn láìfòyà,
\q2
\v 75 ni ìwà mímọ́ àti ní òdodo níwájú rẹ̀, ní ọjọ́ ayé wa gbogbo.
\b
\b
\q1
\v 76 \x - \xo 1.76: \xt Lk 7.26; Ml 4.5.\x*“Àti ìwọ, ọmọ mi, wòlíì Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó máa pè ọ́:
\q2 nítorí ìwọ ni yóò ṣáájú Olúwa láti tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe;
\q1
\v 77 \x - \xo 1.77: \xt Mk 1.4.\x*láti fi ìmọ̀ ìgbàlà fún àwọn ènìyàn rẹ̀
\q2 fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
\q1
\v 78 \x - \xo 1.78: \xt Ml 4.2; Ef 5.14.\x*nítorí ìyọ́nú Ọlọ́run wà;
\q2 nípa èyí tí ìlà-oòrùn láti òkè wá bojú wò wá,
\q1
\v 79 \x - \xo 1.79: \xt Isa 9.2; Mt 4.16.\x*Láti fi ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó jókòó ní
\q2 òkùnkùn àti ní òjìji ikú,
\q1 àti láti fi ẹsẹ̀ wa lé ọ̀nà àlàáfíà.”
\p
\v 80 \x - \xo 1.80: \xt Lk 2.40; 2.52.\x*Ọmọ náà sì dàgbà, ó sì le ní ọkàn, ó sì ń gbé ní ijù títí ó fi di ọjọ́ ìfihàn rẹ̀ fún Israẹli.
\c 2
\s1 Ìbí Jesu
\p
\v 1 \x - \xo 2.1: \xt Lk 3.1.\x*Ó sì ṣe ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àṣẹ ti ọ̀dọ̀ Kesari Augustu jáde wá pé, kí a kọ orúkọ gbogbo ayé sínú ìwé.
\v 2 (Èyí ni ìkọ sínú ìwé èkínní tí a ṣe nígbà tí Kirene fi jẹ baálẹ̀ Siria.)
\v 3 Gbogbo àwọn ènìyàn sì lọ láti kọ orúkọ wọn sínú ìwé, olúkúlùkù sí ìlú ara rẹ̀.
\p
\v 4 \x - \xo 2.4: \xt Lk 1.27.\x*Josẹfu pẹ̀lú sì gòkè láti Nasareti ni Galili, sí ìlú Dafidi ní Judea, tí à ń pè ní Bẹtilẹhẹmu; nítorí ti ìran àti ìdílé Dafidi ní í ṣe,
\v 5 láti kọ orúkọ rẹ̀, pẹ̀lú Maria aya rẹ̀ àfẹ́sọ́nà, tí oyún rẹ̀ ti tó bí.
\v 6 Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, ọjọ́ rẹ̀ pé tí òun yóò bí.
\v 7 Ó sì bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkùnrin, ó sì fi ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran; nítorí tí ààyè kò sí fún wọn nínú ilé èrò.
\s1 Àwọn olùṣọ́-àgùntàn àti àwọn angẹli
\p
\v 8 Àwọn olùṣọ́-àgùntàn ń bẹ tí wọ́n ń gbé ní ìlú náà, wọ́n ń ṣọ́ agbo àgùntàn wọn ní òru ní pápá tí wọ́n ń gbé.
\v 9 \x - \xo 2.9: \xt Lk 1.11; Ap 5.19.\x*Angẹli Olúwa sì yọ sí wọn, ògo Olúwa sì ràn yí wọn ká, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.
\v 10 Angẹli náà sì wí fún wọn pé, “Má bẹ̀rù: sá wò ó, mo mú ìyìnrere ayọ̀ ńlá fún yín wá, tí yóò ṣe ti ènìyàn gbogbo.
\v 11 \x - \xo 2.11: \xt Jh 4.42; Ap 5.31; Mt 16.16; Ap 2.36.\x*Nítorí a ti bí Olùgbàlà fún yín lónìí ní ìlú Dafidi, tí í ṣe Kristi Olúwa.
\v 12 \x - \xo 2.12: \xt 1Sa 2.34; 2Ọb 19.29; Isa 7.14.\x*Èyí ni yóò sì ṣe àmì fún yín; ẹ̀yin yóò rí ọmọ ọwọ́ tí a fi ọ̀já wé, ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran.”
\p
\v 13 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ọ̀run sì darapọ̀ mọ́ angẹli náà ní òjijì, wọ́n ń yin Ọlọ́run, wí pé,
\q1
\v 14 \x - \xo 2.14: \xt Lk 19.38; 3.22.\x*“Ògo ni fún Ọlọ́run lókè ọ̀run,
\q2 àti ní ayé àlàáfíà, ìfẹ́ inú rere sí ènìyàn.”
\p
\v 15 Ó sì ṣe, nígbà tí àwọn angẹli náà padà kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn olùṣọ́-àgùntàn náà bá ara wọn sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ tààrà sí Bẹtilẹhẹmu, kí á lè rí ohun tí ó ṣẹ̀, tí Olúwa fihàn fún wa.”
\p
\v 16 Wọ́n sì wá lọ́gán, wọ́n sì rí Maria àti Josẹfu, àti ọmọ ọwọ́ náà, ó dùbúlẹ̀ nínú ibùjẹ ẹran.
\v 17 Nígbà tí wọ́n sì ti rí i, wọ́n sọ ohun tí a ti wí fún wọn nípa ti ọmọ yìí.
\v 18 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ sí nǹkan wọ̀nyí tí a ti wí fún wọn láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́-àgùntàn wá.
\v 19 \x - \xo 2.19: \xt Lk 2.51.\x*Ṣùgbọ́n Maria pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́, ó ń rò wọ́n nínú ọkàn rẹ̀.
\v 20 Àwọn olùṣọ́-àgùntàn sì padà lọ, wọ́n ń fi ògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì yìn ín, nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti gbọ́ àti tí wọ́n ti rí, bí a ti wí i fún wọn.
\s1 A gbé Jesu kalẹ̀ nínú Tẹmpili
\p
\v 21 \x - \xo 2.21: \xt Lk 1.31,59; Mt 1.25.\x*Nígbà tí ọjọ́ mẹ́jọ sì pé láti kọ ọmọ náà nílà, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu, bí a ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ angẹli náà wá kí á tó lóyún rẹ̀.
\p
\v 22 \x - \xo 2.22-24: \xt Le 12.2-8.\x*Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nù Maria sì pé gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, Josẹfu àti Maria gbé Jesu wá sí Jerusalẹmu láti fi í fún Olúwa
\v 23 \x - \xo 2.23: \xt Ek 13.2,12.\x*(bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Olúwa pé, “Gbogbo ọmọ ọkùnrin tí ó ṣe àkọ́bí, òun ni a ó pè ní mímọ́ fún Olúwa”),
\v 24 àti láti rú ẹbọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí nínú òfin Olúwa: “Àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì.”
\p
\v 25 \x - \xo 2.25: \xt Lk 2.38; 23.51.\x*Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan wà ní Jerusalẹmu, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Simeoni; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́ àti olùfọkànsìn, ó ń retí ìtùnú Israẹli, Ẹ̀mí mímọ́ sì bà lé e.
\v 26 A sì ti fihàn án láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ náà wá pé, òun kì yóò rí ikú, kí ó tó rí Kristi Olúwa.
\v 27 Ó sì ti ipa Ẹ̀mí wá sínú tẹmpili. Nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ sì gbé Jesu wá, láti ṣe fún un bí ìṣe òfin.
\v 28 Nígbà náà ni Simeoni gbé e ní apá rẹ̀, ó fi ìbùkún fún Ọlọ́run, ó ní:
\q1
\v 29 “Olúwa Olódùmarè, nígbà yìí ni ó tó jọ̀wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ lọ́wọ́ lọ,
\q2 ní àlàáfíà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
\q1
\v 30 \x - \xo 2.30: \xt Isa 52.10; Lk 3.6.\x*Nítorí tí ojú mi ti rí ìgbàlà rẹ ná,
\q2
\v 31 tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀ níwájú ènìyàn gbogbo;
\q1
\v 32 \x - \xo 2.32: \xt Isa 42.6; 49.6; Ap 13.47; 26.23.\x*ìmọ́lẹ̀ láti mọ́ sí àwọn aláìkọlà,
\q2 àti ògo Israẹli ènìyàn rẹ̀.”
\p
\v 33 Ẹnu sì ya Josẹfu àti ìyá rẹ̀ sí nǹkan tí a ń sọ sí i wọ̀nyí.
\v 34 Simeoni sì súre fún wọn, ó sì wí fún Maria ìyá rẹ̀ pé, “Kíyèsi i, a gbé ọmọ yìí kalẹ̀ fún ìṣubú àti ìdìde ọ̀pọ̀ ènìyàn ní Israẹli; àti fún àmì tí a ń sọ̀rọ̀-òdì sí;
\v 35 (idà yóò sì gún ìwọ náà ní ọkàn pẹ̀lú) kí á lè fi ìrònú ọ̀pọ̀ ọkàn hàn.”
\p
\v 36 \x - \xo 2.36: \xt Ap 21.9; Jo 19.24; 1Tm 5.9.\x*Ẹnìkan sì ń bẹ, Anna wòlíì, ọmọbìnrin Penueli, nínú ẹ̀yà Aṣeri: ọjọ́ ogbó rẹ̀ pọ̀, ó ti bá ọkọ gbé ní ọdún méje láti ìgbà wúńdíá rẹ̀ wá;
\v 37 Ó sì ṣe opó títí ó fi di ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, ẹni tí kò kúrò ní tẹmpili, ṣùgbọ́n ó ń fi àwẹ̀ àti àdúrà sin Ọlọ́run lọ́sàn án àti lóru.
\v 38 Ó sì wólẹ̀ ní àkókò náà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pẹ̀lú, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún gbogbo àwọn tí ó ń retí ìdáǹdè Jerusalẹmu.
\p
\v 39 Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe nǹkan gbogbo tán gẹ́gẹ́ bí òfin Olúwa, wọ́n padà lọ sí Galili, sí Nasareti ìlú wọn.
\v 40 \x - \xo 2.40: \xt On 13.24; 1Sa 2.26.\x*Ọmọ náà sì ń dàgbà, ó sì ń lágbára, ó sì kún fún ọgbọ́n: oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sì ń bẹ lára rẹ̀.
\s1 Ọ̀dọ́mọkùnrin Jesu ni tẹmpili
\p
\v 41 \x - \xo 2.41: \xt De 16.1-8; Ek 23.15.\x*Àwọn òbí rẹ̀ a sì máa lọ sí Jerusalẹmu ní ọdọọdún sí àjọ ìrékọjá.
\v 42 Nígbà tí ó sì di ọmọ ọdún méjìlá, wọ́n gòkè lọ sí Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ìṣe àjọ náà.
\v 43 Nígbà tí ọjọ́ wọn sì pé bí wọ́n ti ń padà bọ̀, ọmọ náà, Jesu dúró lẹ́yìn ní Jerusalẹmu; Josẹfu àti ìyá rẹ̀ kò mọ̀.
\v 44 Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe bí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ èrò, wọ́n rin ìrìn ọjọ́ kan; wọ́n wá a kiri nínú àwọn ará àti àwọn ojúlùmọ̀ wọn.
\v 45 Nígbà tí wọn kò sì rí i, wọ́n padà sí Jerusalẹmu, wọ́n ń wá a kiri.
\v 46 Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta wọ́n rí i nínú tẹmpili ó jókòó ní àárín àwọn olùkọ́ni, ó ń gbọ́ tiwọn, ó sì ń bi wọ́n léèrè.
\v 47 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún òye àti ìdáhùn rẹ̀.
\v 48 \x - \xo 2.48: \xt Mk 3.31-35.\x*Nígbà tí wọ́n sì rí i, háà ṣe wọ́n, ìyá rẹ̀ sì bi í pé, “Ọmọ, èéṣe tí ìwọ fi ṣe wá bẹ́ẹ̀? Sá wò ó, baba rẹ̀ àti èmi ti ń fi ìbànújẹ́ wá ọ kiri.”
\p
\v 49 Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, \wj “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá mi kiri? Ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi kò lè ṣàìmá wà níbi iṣẹ́ Baba mi?”\wj*
\v 50 Ọ̀rọ̀ tí o sọ kò sì yé wọn.
\p
\v 51 \x - \xo 2.51: \xt Lk 2.19.\x*Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí Nasareti, sì fi ara balẹ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn rẹ̀.
\v 52 \x - \xo 2.52: \xt Lk 1.80; 2.40.\x*Jesu sì ń pọ̀ ní ọgbọ́n, sì ń dàgbà, ó sì wà ní ojúrere ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.
\c 3
\s1 Johanu onítẹ̀bọmi tún ọnà náà ṣe
\p
\v 1 \x - \xo 3.1: \xt Lk 23.1; 9.7; 13.31; 23.7.\x*Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún ìjọba Tiberiu Kesari, nígbà tí Pọntiu Pilatu jẹ́ baálẹ̀ Judea, tí Herodu sì jẹ́ tetrarki Galili, Filipi arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ tetrarki Iturea àti ti Trakoniti, Lisania sì jẹ́ tetrarki Abilene,
\v 2 \x - \xo 3.2: \xt Jh 18.13; Ap 4.6; Mt 26.3; Jh 11.49.\x*tí Annasi òun Kaiafa ń ṣe olórí àwọn àlùfáà, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Johanu ọmọ Sekariah wá ní ijù.
\v 3 \x - \xo 3.3-9: \xt Mt 3.1-10; Mk 1.1-5; Jh 1.6,23.\x*Ó sì wá sí gbogbo ilẹ̀ aginjù Jordani, ó ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀,
\v 4 \x - \xo 3.4-6: \xt Isa 40.3-5.\x*bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah pé,
\q1 “Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù,
\q1 ‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,
\q2 ẹ mú ipa ọ̀nà rẹ̀ tọ́.
\q1
\v 5 Gbogbo ọ̀gbun ni a yóò kún,
\q2 gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni a ó tẹ́ pẹẹrẹ.
\q1 Wíwọ́ ni a ó ṣe ní títọ́,
\q2 àti ọ̀nà gbọ́ngungbọ̀ngun ni a o sọ di dídán.
\q1
\v 6 \x - \xo 3.6: \xt Lk 2.30.\x*Gbogbo ènìyàn ni yóò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run.’ ”
\p
\v 7 \x - \xo 3.7: \xt Mt 12.34; 23.33.\x*Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀?
\v 8 \x - \xo 3.8: \xt Jh 8.33,39.\x*Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe sí í wí nínú ara yín pé, Àwa ní Abrahamu ní baba. Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu nínú òkúta wọ̀nyí.
\v 9 \x - \xo 3.9: \xt Mt 7.19; Hb 6.7-8.\x*Àti nísinsin yìí pẹ̀lú, a fi àáké lé gbòǹgbò igi náà, gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a óò ge lulẹ̀, a sì wọ jù sínú iná.”
\p
\v 10 Àwọn ènìyàn sì ń bi í pé, “Kí ni kí àwa kí ó ṣe?”
\p
\v 11 Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹni tí ó bá ní ẹ̀wù méjì, kí ó fi ọ̀kan fún ẹni tí kò ní; ẹni tí ó bá sì ní oúnjẹ, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”
\p
\v 12 Àwọn agbowó òde sì tọ̀ ọ́ wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bi í pé, “Olùkọ́, kí ni àwa ó ha ṣe?”
\p
\v 13 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe fi agbára gbà jù bí a ti rán yín lọ mọ́.”
\p
\v 14 Àwọn ọmọ-ogun sì béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Àti àwa, kí ni àwa ó ṣe?”
\p Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe hùwà ipá sí ẹnikẹ́ni, kí ẹ má sì ṣe ka ẹ̀sùn èké sí ẹnikẹ́ni; kí òwò ọ̀yà yín tó yín.”
\p
\v 15 \x - \xo 3.15: \xt Ap 13.25; Jh 1.19-22.\x*Bí àwọn ènìyàn sì ti ń retí, tí gbogbo wọn sì ń rò nínú ara wọn nítorí Johanu, bí òun ni Kristi tàbí òun kọ́;
\v 16 \x - \xo 3.16-18: \xt Mt 3.11-12; Mk 1.7-8; Jh 1.26-27,33; Ap 1.5; 11.16; 19.4.\x*Johanu dáhùn ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Lóòótọ́ ni èmi ń fi omi bamitiisi yín, ṣùgbọ́n ẹni tí ó lágbára jù mí lọ ń bọ̀, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó tú, Òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitiisi yín.
\v 17 Ẹni tí àtẹ rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, láti gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tó tó, kí ó sì kó alikama rẹ̀ sínú àká; ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.”
\v 18 Johanu lo oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ púpọ̀ láti gba àwọn ènìyàn níyànjú àti láti wàásù ìyìnrere fún wọn.
\p
\v 19 \x - \xo 3.19-20: \xt Mt 14.3-4; Mk 6.17-18.\x*Ṣùgbọ́n nígbà ti Johanu bú Herodu tetrarki, tí ó bá wí nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀, àti nítorí ohun búburú gbogbo tí Herodu tí ṣe,
\v 20 Ó fi èyí parí gbogbo rẹ̀ nígbà tí ó fi Johanu sínú túbú.
\s1 Ìtẹ̀bọmi àti ìtàn ìdílé Jesu
\p
\v 21 \x - \xo 3.21-22: \xt Mt 3.13-17; Mk 1.9-11; Jh 1.29-34.\x*\x - \xo 3.21: \xt Lk 5.16; 6.12; 9.18,28; 11.1; Mk 1.35.\x*Nígbà tí a ṣe ìtẹ̀bọmi àwọn ènìyàn gbogbo tán, ó sì ṣe, a bamitiisi Jesu pẹ̀lú, bí ó ti ń gbàdúrà, ọ̀run ṣí sílẹ̀,
\v 22 \x - \xo 3.22: \xt Sm 2.7; Isa 42.1; Lk 9.35; Ap 10.38; 2Pt 1.17.\x*Ẹ̀mí Mímọ́ sì sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ ní àwọ̀ àdàbà, ohùn kan sì ti ọ̀run wá, tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi; ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”
\p
\v 23 \x - \xo 3.23-38: \xt Mt 1.1-17; Gẹ 5.3-32; 11.10-26; Ru 4.18-22; 1Ki 1.1-4,24-28; 2.1-15.\x*\x - \xo 3.23: \xt Jh 8.57; Lk 1.27.\x*Jesu tìkára rẹ̀ ń tó bí ẹni ọgbọ̀n ọdún, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ (bí a ti fi pè) ọmọ Josẹfu,
\b
\li1 tí í ṣe ọmọ Eli,
\v 24 tí í ṣe ọmọ Mattati,
\li1 tí í ṣe ọmọ Lefi, tí í ṣe ọmọ Meliki,
\li1 tí í ṣe ọmọ Janai, tí í ṣe ọmọ Josẹfu,
\li1
\v 25 tí í ṣe ọmọ Mattatia, tí í ṣe ọmọ Amosi,
\li1 tí í ṣe ọmọ Naumu, tí í ṣe ọmọ Esili,
\li1 tí í ṣe ọmọ Nagai,
\v 26 tí í ṣe ọmọ Maati,
\li1 tí í ṣe ọmọ Mattatia, tí í ṣe ọmọ Ṣimei,
\li1 tí í ṣe ọmọ Josẹfu, tí í ṣe ọmọ Joda,
\li1
\v 27 tí í ṣe ọmọ Joana, tí í ṣe ọmọ Resa,
\li1 tí í ṣe ọmọ Serubbabeli, tí í ṣe ọmọ Ṣealitieli,
\li1 tí í ṣe ọmọ Neri,
\v 28 tí í ṣe ọmọ Meliki,
\li1 tí í ṣe ọmọ Adi, tí í ṣe ọmọ Kosamu,
\li1 tí í ṣe ọmọ Elmadamu, tí í ṣe ọmọ Eri,
\li1
\v 29 tí í ṣe ọmọ Joṣua, tí í ṣe ọmọ Elieseri,
\li1 tí í ṣe ọmọ Jorimu, tí í ṣe Mattati,
\li1 tí í ṣe ọmọ Lefi,
\v 30 tí í ṣe ọmọ Simeoni,
\li1 tí í ṣe ọmọ Juda, tí í ṣe ọmọ Josẹfu,
\li1 tí í ṣe ọmọ Jonamu, tí í ṣe ọmọ Eliakimu,
\li1
\v 31 tí í ṣe ọmọ Melea, tí í ṣe ọmọ Menna,
\li1 tí í ṣe ọmọ Mattata, tí í ṣe ọmọ Natani,
\li1 tí í ṣe ọmọ Dafidi,
\v 32 tí í ṣe ọmọ Jese,
\li1 tí í ṣe ọmọ Obedi, tí í ṣe ọmọ Boasi,
\li1 tí í ṣe ọmọ Salmoni, tí í ṣe ọmọ Nahiṣoni,
\li1
\v 33 tí í ṣe ọmọ Amminadabu, tí í ṣe ọmọ Ramu,
\li1 tí í ṣe ọmọ Hesroni, tí í ṣe ọmọ Peresi,
\li1 tí í ṣe ọmọ Juda.
\v 34 Tí í ṣe ọmọ Jakọbu,
\li1 tí í ṣe ọmọ Isaaki, tí í ṣe ọmọ Abrahamu,
\li1 tí í ṣe ọmọ Tẹra, tí í ṣe ọmọ Nahori,
\li1
\v 35 tí í ṣe ọmọ Serugu, tí í ṣe ọmọ Reu,
\li1 tí í ṣe ọmọ Pelegi, tí í ṣe ọmọ Eberi,
\li1 tí í ṣe ọmọ Ṣela.
\v 36 Tí í ṣe ọmọ Kainani,
\li1 tí í ṣe ọmọ Arfaksadi, tí í ṣe ọmọ Ṣemu,
\li1 tí í ṣe ọmọ Noa, tí í ṣe ọmọ Lameki,
\li1
\v 37 tí í ṣe ọmọ Metusela, tí í ṣe ọmọ Enoku,
\li1 tí í ṣe ọmọ Jaredi, tí í ṣe ọmọ Mahalaleli,
\li1 tí í ṣe ọmọ Kainani.
\v 38 Tí í ṣe ọmọ Enosi,
\li1 tí í ṣe ọmọ Seti, tí í ṣe ọmọ Adamu,
\li1 tí í ṣe ọmọ Ọlọ́run.
\c 4
\s1 Ìdánwò Jesu
\p
\v 1 \x - \xo 4.1-13: \xt Mt 4.1-11; Mk 1.12-13.\x*Jesu sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó padà ti Jordani wá, a sì ti ọwọ́ Ẹ̀mí darí rẹ̀ sí ijù,
\v 2 \x - \xo 4.2: \xt De 9.9; 1Ọb 19.8.\x*Ogójì ọjọ́ ni a fi dán an wò lọ́wọ́ èṣù. Kò sì jẹ ohunkóhun ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì: nígbà tí wọ́n sì parí, lẹ́yìn náà ni ebi wá ń pa á.
\p
\v 3 Èṣù sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ fún òkúta yìí kí ó di àkàrà.”
\p
\v 4 \x - \xo 4.4: \xt De 8.3.\x*Jesu sì dáhùn, ó wí fún un pé, \wj “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, Ènìyàn kì yóò wà láààyè nípa àkàrà nìkan.’ ”\wj*
\p
\v 5 Lójúkan náà, èṣù sì mú un lọ sí orí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé hàn án.
\v 6 \x - \xo 4.6: \xt 1Jh 5.19.\x*Èṣù sì wí fún un pé, “Ìwọ ni èmi ó fi gbogbo agbára yìí àti ògo wọn fún: nítorí á sá ti fi fún mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù mí, èmi a fi í fún.
\v 7 Ǹjẹ́ bí ìwọ bá foríbalẹ̀ fún mi, gbogbo rẹ̀ ni yóò jẹ́ tìrẹ.”
\p
\v 8 \x - \xo 4.8: \xt De 6.13.\x*Jesu sì dáhùn ó sì wí fún un pé, \wj “Kúrò lẹ́yìn mi, Satani, nítorí tí a kọ̀wé rẹ̀ pé, Ìwọ foríbalẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ kí ó sì máa sìn.’ ”\wj*
\p
\v 9 Èṣù sì mú un lọ sí Jerusalẹmu, ó sì gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹmpili, ó sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ láti ibí yìí.
\v 10 \x - \xo 4.10-11: \xt Sm 91.11-12.\x*A sá ti kọ̀wé rẹ̀ pé,
\q1 “Yóò pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí rẹ,
\q2 láti máa ṣe ìtọ́jú rẹ;
\q1
\v 11 àti pé ní ọwọ́ wọn ni wọn ó gbé ọ sókè,
\q2 kí ìwọ kí ó má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ”
\p
\v 12 \x - \xo 4.12: \xt De 6.16.\x*Jesu sì dáhùn ó wí fún un pé, \wj “A ti kọ́ pé, Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”\wj*
\p
\v 13 \x - \xo 4.13: \xt Lk 22.28.\x*Nígbà tí èṣù sì parí ìdánwò náà gbogbo, ó fi í sílẹ̀ lọ fun sá à kan.
\s1 A kọ Jesu ni Nasareti
\p
\v 14 \x - \xo 4.14: \xt Mt 4.12; Mk 1.14; Mt 9.26; Lk 4.37.\x*Jesu sì fi agbára Ẹ̀mí padà wá sí Galili, òkìkí rẹ̀ sì kàn kálẹ̀ ní gbogbo agbègbè tí ó yí i ká.
\v 15 \x - \xo 4.15: \xt Mt 4.23; 9.35; 11.1.\x*Ó sì ń kọ́ni nínú Sinagọgu wọn; a ń yìn ín lógo láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn wá.
\p
\v 16 \x - \xo 4.16-30: \xt Mt 13.53-58; Mk 6.1-6; Isa 13.14-16.\x*Ó sì wá sí Nasareti, níbi tí a gbé ti tọ́ ọ dàgbà: bí ìṣe rẹ̀ ti rí, ó sì wọ inú Sinagọgu lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì dìde láti kàwé.
\v 17 A sì fi ìwé wòlíì Isaiah fún un. Nígbà tí ó sì ṣí ìwé náà, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé:
\q1
\v 18 \wj “Ẹ̀mí Olúwa ń bẹ lára mi,\wj*
\q2 \wj nítorí tí ó fi àmì òróró yàn mí\wj*
\q2 \wj láti wàásù ìyìnrere fún àwọn òtòṣì.\wj*
\q1 \wj Ó ti rán mi wá láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn, àti\wj*
\q2 \wj ìmúnríran fún àwọn afọ́jú,\wj*
\q1 \wj àti láti jọ̀wọ́ àwọn tí a pa lára lọ́wọ́,\wj*
\q2
\v 19 \wj láti kéde ọdún ojúrere Olúwa.”\wj*
\p
\v 20 Ó sì pa ìwé náà dé, ó fi í fún ìránṣẹ́, ó sì jókòó. Gbogbo àwọn tí ó ń bẹ nínú Sinagọgu sì tẹjúmọ́ ọn.
\v 21 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wí fún wọn pé, \wj “Lónìí ìwé mímọ́ yìí ṣẹ ní etí yín.”\wj*
\p
\v 22 \x - \xo 4.22: \xt Jh 6.42; 7.15.\x*Gbogbo wọn sì jẹ́rìí rẹ̀, háà sì ṣe wọ́n sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ń jáde ní ẹnu rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ọmọ Josẹfu kọ́ yìí?”
\p
\v 23 \x - \xo 4.23: \xt Mk 1.21; 2.1; Jh 4.46.\x*Jesu sì wí fún wọn pé, \wj “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó pa òwe yìí sí mi pé, Oníṣègùn, wo ara rẹ̀ sàn! Àwọn ohun tí àwa gbọ́ pé o ti ọwọ́ rẹ ṣe ní Kapernaumu, ṣe é níhìn-ín yìí pẹ̀lú ní ilẹ̀ ara rẹ.’ ”\wj*
\p
\v 24 \x - \xo 4.24: \xt Jh 4.44.\x*Ó sì wí pé, \wj “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, kò sí wòlíì tí a tẹ́wọ́gbà ní ilẹ̀ baba rẹ̀.\wj*
\v 25 \x - \xo 4.25: \xt 1Ọb 17.1,8-16; 18.1; Jk 5.17-18.\x*\wj Ṣùgbọ́n mo wí fún un yín nítòótọ́, opó púpọ̀ ni ó wà ní Israẹli nígbà ọjọ́ wòlíì Elijah, nígbà tí ọ̀run fi sé ní ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà, nígbà tí ìyàn ńlá fi mú ká ilẹ̀ gbogbo.\wj*
\v 26 \wj Kò sì sí ẹnìkan nínú wọn tí a rán Elijah sí, bí kò ṣe sí obìnrin opó kan ní Sarefati, ìlú kan ní Sidoni.\wj*
\v 27 \x - \xo 4.27: \xt 2Ọb 5.1-14.\x*\wj Adẹ́tẹ̀ púpọ̀ ní sì ń bẹ ní Israẹli nígbà wòlíì Eliṣa; kò sì ṣí ọ̀kan nínú wọn tí a wẹ̀nùmọ́, bí kò ṣe Naamani ará Siria.”\wj*
\p
\v 28 Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó wà nínú Sinagọgu gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, inú bi wọ́n gidigidi,
\v 29 \x - \xo 4.29: \xt Ap 7.58; Nu 15.35.\x*wọ́n sì dìde, wọ́n tì í sóde sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n sì fà á lọ sí bèbè òkè níbi tí wọ́n gbé tẹ ìlú wọn dó, kí wọn bá à lè sọ sílẹ̀ ní ògèdèǹgbé.
\v 30 \x - \xo 4.30: \xt Jh 8.59; 10.39.\x*Ṣùgbọ́n ó kọjá láàrín wọn, ó bá tirẹ̀ lọ.
\s1 Jesu lé ẹ̀mí èṣù jáde
\p
\v 31 \x - \xo 4.31-37: \xt Mk 1.21-28.\x*Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Kapernaumu, ìlú kan ní Galili, ó sì ń kọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi.
\v 32 \x - \xo 4.32: \xt Mt 7.28; 13.54; 22.33; Mk 11.18; Jh 7.46.\x*Ẹnu sì yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀: nítorí tàṣẹtàṣẹ ni ọ̀rọ̀ rẹ̀.
\p
\v 33 Ọkùnrin kan sì wà nínú Sinagọgu, ẹni tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, ó kígbe ní ohùn rara,
\v 34 “Ó wí pé, kín ni ṣe tàwa tìrẹ, Jesu ará Nasareti? Ìwọ́ wá láti pa wá run bí? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe, Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.”
\p
\v 35 Jesu sì bá a wí gidigidi, ó wí fun pe, \wj “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí o sì jáde lára rẹ̀.”\wj* Nígbà tí ẹ̀mí èṣù náà sì gbé e ṣánlẹ̀ ní àwùjọ, ó jáde kúrò lára rẹ̀, kò sì pa á lára.
\p
\v 36 Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ wí pé, “Irú ẹ̀kọ́ kín ni èyí? Nítorí pẹ̀lú àṣẹ àti agbára ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí àìmọ́ wí, wọ́n sì jáde kúrò.”
\v 37 \x - \xo 4.37: \xt Lk 4.14; 5.15; Mt 9.26.\x*Òkìkí rẹ̀ sì kàn níbi gbogbo ní agbègbè ilẹ̀ náà yíká.
\s1 Jesu wo ọ̀pọ̀ ènìyàn sàn
\p
\v 38 \x - \xo 4.38-41: \xt Mt 8.14-17; Mk 1.29-34.\x*Nígbà tí ó sì dìde kúrò nínú Sinagọgu, ó sì wọ̀ ilé Simoni lọ; ibà sì ti dá ìyá ìyàwó Simoni dùbúlẹ̀, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ nítorí rẹ̀.
\v 39 Ó sì súnmọ́ ọ, ó bá ibà náà wí; ibà sì náà sì fi sílẹ̀. O sì dìde lọ́gán, ó ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
\p
\v 40 Nígbà tí oòrùn sì ń wọ̀, àwọn ènìyàn gbe àwọn aláìsàn, tó ní onírúurú àìsàn wá sọ́dọ̀ Jesu; ó sì fi ọwọ́ lé olúkúlùkù wọn, ó sì mú wọn láradá.
\v 41 Àwọn ẹ̀mí èṣù sì jáde lára ẹni púpọ̀ pẹ̀lú, wọ́n ń kígbe, wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run!” Ó sì ń bá wọn wí kò sì jẹ́ kí wọn kí ó fọhùn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé Òun ni Kristi náà.
\p
\v 42 \x - \xo 4.42-43: \xt Mk 1.35-38.\x*Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, Jesu sì jáde lọ, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀. Ìjọ ènìyàn sì ń wá a kiri, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì dá a dúró, nítorí kí ó má ba à lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn.
\v 43 Ṣùgbọ́n ó sì wí fún wọn pé, \wj “Èmi kò lè ṣàìmá wàásù ìyìnrere ti ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú mìíràn pẹ̀lú, nítorí náà ni a sá ṣe rán mi.”\wj*
\v 44 \x - \xo 4.44: \xt Mt 4.23; Mk 1.39; Mt 9.35.\x*Ó sì ń wàásù nínú Sinagọgu ti Judea.
\c 5
\s1 Ìpè àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àkọ́kọ́
\p
\v 1 \x - \xo 5.1-11: \xt Mt 4.18-22; Mk 1.16-20; Jh 1.40-42; 21.1-19.\x*Ó sì ṣe, nígbà tí ìjọ ènìyàn súnmọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì dúró létí adágún Genesareti.
\v 2 Ó rí ọkọ̀ méjì ti o wá létí adágún: èyí tí àwọn apẹja ti sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú wọn, nítorí tí wọ́n ń fọ àwọ̀n wọn.
\v 3 \x - \xo 5.3: \xt Mt 13.1-2; Mk 4.1.\x*Ó sì wọ ọ̀kan nínú àwọn ọkọ̀ náà, tí í ṣe ti Simoni, ó sì bẹ̀ ẹ́ kí ó tì í sí ẹ̀yìn díẹ̀ kúrò ní ilẹ̀. Ó sì jókòó, ó sì ń kọ́ ìjọ ènìyàn láti inú ọkọ̀ náà.
\p
\v 4 Bí ó sì ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, ó wí fún Simoni pé, \wj “Tì í sí ibú, kí o sì ju àwọ̀n yín sí ìsàlẹ̀ fún àkópọ̀.”\wj*
\p
\v 5 \x - \xo 5.5: \xt Lk 8.24,45; 9.33,49; 17.13.\x*Simoni sì dáhùn ó sì wí fún un pé, \wj “Olùkọ́ni, gbogbo òru ni àwa fi ṣiṣẹ́, àwa kò sì mú nǹkan kan: ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀ rẹ èmi ó ju àwọ̀n náà sí ìsàlẹ̀.”\wj*
\p
\v 6 Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe èyí, wọ́n kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja: àwọ̀n wọn sì ya.
\v 7 Wọ́n sì pe àwọn ẹgbẹ́ wọn, tí ó wà nínú ọkọ̀ kejì, kí wọn kí ó wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n sì wá, wọ́n kó ẹja ọkọ̀ méjèèjì sì kún, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rì.
\p
\v 8 Nígbà tí Simoni Peteru sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá eékún Jesu, ó wí pé, “Lọ kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa; nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.”
\v 9 Ẹnu sì yà wọ́n, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀, fún àkópọ̀ ẹja tí wọ́n kó,
\v 10 bẹ́ẹ̀ ni Jakọbu àti Johanu àwọn ọmọ Sebede, tí ń ṣe alábákẹ́gbẹ́ Simoni.
\p Jesu sì wí fún Simoni pé, \wj “Má bẹ̀rù; láti ìsinsin yìí lọ ìwọ ó máa mú ènìyàn.”\wj*
\v 11 Nígbà tí wọ́n sì ti mú ọkọ̀ wọn dé ilẹ̀, wọ́n fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lọ.
\s1 Ọkùnrin pẹ̀lú ẹ̀tẹ̀
\p
\v 12 \x - \xo 5.12-16: \xt Mt 8.1-4; Mk 1.40-45; Lk 17.11-19.\x*Ó sì ṣe, nígbà tí Jesu wọ ọ̀kan nínú àwọn ìlú náà, kíyèsi i, ọkùnrin kan tí ẹ̀tẹ̀ bò wa síbẹ̀: nígbà tí ó rí Jesu, ó wólẹ̀, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, wí pé, “Olúwa, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè sọ mí di mímọ́.”
\p
\v 13 Jesu sì na ọwọ́ rẹ̀, ó fi kàn án, ó ní, \wj “Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́!”\wj* Lójúkan náà ẹ̀tẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ.
\p
\v 14 \x - \xo 5.14: \xt Le 13.49; 14.2-32.\x*Ó sì kìlọ̀ fún u pé, \wj “Kí ó má ṣe sọ fún ẹnìkan: ṣùgbọ́n kí ó lọ, kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn fún àlùfáà, kí ó sì ta ọrẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ gẹ́gẹ́ bi ẹ̀rí fun wọn.”\wj*
\p
\v 15 \x - \xo 5.15: \xt Lk 4.14,37; Mt 9.26.\x*Ṣùgbọ́n òkìkí rẹ̀ ń kàn kálẹ̀: tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì jùmọ̀ pàdé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti gba ìwòsàn lọ́dọ̀ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àìlera wọn.
\v 16 \x - \xo 5.16: \xt Lk 3.21; 6.12; 9.18,28; 11.1.\x*Ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà ni Jesu a máa yẹra kúrò si ibi ìdákẹ́rọ́rọ́, òun á sì máa dá wà láti gbàdúrà.
\s1 Jesu wo arọ sàn
\p
\v 17 \x - \xo 5.17-26: \xt Mt 9.1-8; Mk 2.1-12; Jh 5.1-9.\x*\x - \xo 5.17: \xt Mt 15.1; Mk 5.30; Lk 6.19.\x*Ní ọjọ́ kan, bí ó sì ti ń kọ́ni, àwọn Farisi àti àwọn amòfin jókòó pẹ̀lú rẹ̀, àwọn tí ó ti àwọn ìletò Galili gbogbo, àti Judea, àti Jerusalẹmu wá: agbára Olúwa sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ láti mú wọn láradá.
\v 18 Sá à sì kíyèsi i, àwọn ọkùnrin kan gbé ẹnìkan tí ó ní ààrùn ẹ̀gbà wà lórí àkéte: wọ́n ń wá ọ̀nà àti gbé e wọlé, àti láti tẹ́ ẹ síwájú Jesu.
\v 19 Nígbà tí wọn kò sì rí ọ̀nà tí wọn ìbá fi gbé e wọlé nítorí ìjọ ènìyàn, wọ́n gbé e gun òkè àjà ilé lọ, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ sí àárín èrò ti òun ti àkéte rẹ̀ níwájú Jesu.
\p
\v 20 \x - \xo 5.20: \xt Lk 7.48,49.\x*Nígbà tí ó sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí pé, \wj “Ọkùnrin yìí, a darí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”\wj*
\p
\v 21 \x - \xo 5.21: \xt Isa 43.25.\x*Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ sí í gbèrò wí pé, “Ta ni eléyìí tí ń sọ ọ̀rọ̀-òdì? Ta ni ó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí kò ṣe Ọlọ́run nìkan ṣoṣo.”
\p
\v 22 Jesu sì mọ èrò inú wọn, ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, \wj “Èéṣe tí ẹ fi ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín?\wj*
\v 23 \wj Èwo ni ó yá jù: láti wí pé, A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, tàbí láti wí pé, Dìde kí ìwọ sì máa rìn?\wj*
\v 24 \wj Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé Ọmọ Ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni.”\wj* Ó wí fún ẹlẹ́gbà náà pé, \wj “Mo wí fún ọ, dìde, sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa lọ sí ilé!”\wj*
\v 25 Ó sì dìde lọ́gán níwájú wọn, ó gbé ohun tí ó dùbúlẹ̀ lé, ó sì lọ sí ilé rẹ̀, ó yin Ọlọ́run lógo.
\v 26 Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, ẹ̀rù sì bà wọ́n, wọ́n ń wí pé, “Àwa rí ohun ìyanu lónìí.”
\s1 Ìpè Lefi
\p
\v 27 \x - \xo 5.27-32: \xt Mt 9.9-13; Mk 2.13-17.\x*Lẹ́hìn èyí, Jesu jáde lọ, ó sì rí agbowó òde kan tí à ń pè ní Lefi, ó jókòó sí ibi tí ó ti ń gba owó òde, Jesu sì wí fún un pé, \wj “Tẹ̀lé mi,”\wj*
\v 28 Lefi sì fi ohun gbogbo sílẹ̀ ó sì ń tẹ̀lé e.
\p
\v 29 Lefi sì ṣe àsè ńlá kan fún Jesu ní ilé rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti àwọn mìíràn sì ń jẹun pẹ̀lú wọn.
\v 30 \x - \xo 5.30: \xt Lk 15.1-2.\x*Ṣùgbọ́n àwọn Farisi, àwọn olùkọ́ òfin tí ó jẹ́ ara wọn fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pe, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń jẹun tí ẹ sì ń mú pẹ̀lú àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
\p
\v 31 Jesu dáhùn ó wí fún wọn pé, \wj “Ẹni tí ara rẹ̀ le kò nílò oníṣègùn, bí kò ṣe ẹni tí ara rẹ̀ kò dá.\wj*
\v 32 \x - \xo 5.32: \xt 1Tm 1.15.\x*\wj Èmí kò wá láti pe àwọn olódodo bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ìrònúpìwàdà.”\wj*
\s1 A béèrè nípa àwẹ̀ lọ́wọ́ Jesu
\p
\v 33 \x - \xo 5.33-38: \xt Mt 9.14-17; Mk 2.18-22.\x*\x - \xo 5.33: \xt Lk 7.18; 11.1; Jh 3.25-26.\x*Wọ́n wí fún pé, “Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu a máa gbààwẹ̀, wọn a sì máa gbàdúrà, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú sì ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn Farisi ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ a máa jẹ, wọn a sì máa mu pẹ̀lú.”
\p
\v 34 Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, \wj “Ǹjẹ́ ó ṣe é ṣe kí àwọn àlejò ọkọ ìyàwó máa gbààwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó wà pẹ̀lú wọn bí?\wj*
\v 35 \wj Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn, ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ni wọn yóò gbààwẹ̀.”\wj*
\p
\v 36 Ó sì pa òwe yìí fún wọn wí pé, \wj “Kò sí ẹni tó lè ya aṣọ tuntun kí ó sì rán mọ́, èyí tó ti gbó. Tí ó ba ṣe èyí, yóò ba aṣọ tuntun jẹ́, èyí tí ó tuntun náà kì yóò sì dọ́gba pẹ̀lú èyí tí ó ti gbó.\wj*
\v 37 \wj Àti wí pé, kò sí ẹni tí ó lè dá ọtí wáìnì tuntun sínú ògbólógbòó ìgò-awọ, tí ó bá ṣe èyí, wáìnì tuntun yóò fa awọ náà ya, wáìnì náà yóò dànù, awọ náà a sì bàjẹ́.\wj*
\v 38 \wj Nítorí náà, ó tọ́ kí á da wáìnì tuntun sínú awọ tuntun.\wj*
\v 39 \wj Kò sì ẹni tí yóò fẹ́ láti mu wáìnì tuntun lẹ́yìn tí ó bá ti mu ògbólógbòó tán, nítorí yóò wí pé, Èyí tí ó jẹ́ ògbólógbòó dára jù.’ ”\wj*
\c 6
\s1 Olúwa Ọjọ́ Ìsinmi
\p
\v 1 \x - \xo 6.1-5: \xt Mt 12.1-8; Mk 2.23-28.\x*\x - \xo 6.1: \xt De 23.25.\x*Ní ọjọ́ ìsinmi kejì, Jesu ń kọjá láàrín oko ọkà; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń ya ìpẹ́ ọkà, wọ́n sì ń jẹ ẹ́.
\v 2 \x - \xo 6.2: \xt Ek 20.10; 23.12; De 5.14.\x*Àwọn kan nínú àwọn Farisi sì wí fún wọn pé, “Ki lo de tí ẹ̀yin fi ń ṣe èyí tí kò yẹ láti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi?”
\p
\v 3 \x - \xo 6.3: \xt 1Sa 21.1-6.\x*Jesu sì dá wọn lóhùn pé, \wj “Ẹ̀yin kò kà nípa ohun tí Dafidi ṣe, nígbà tí ebi ń pa òun tìkára rẹ̀ àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀;\wj*
\v 4 \x - \xo 6.4: \xt Le 24.9.\x*\wj bi ó ti wọ ilé Ọlọ́run lọ, tí ó sì mú àkàrà ìfihàn tí ó sì jẹ ẹ́, tí ó sì fi fún àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú; tí kò yẹ fún un láti jẹ, bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà nìkan ṣoṣo?”\wj*
\v 5 Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Ọmọ Ènìyàn ni Olúwa Ọjọ́ Ìsinmi.”\wj*
\p
\v 6 \x - \xo 6.6-11: \xt Mt 12.9-14; Mk 3.1-6.\x*Ní ọjọ́ ìsinmi mìíràn, ó wọ inú Sinagọgu lọ, ó sì ń kọ́ni, ọkùnrin kan sì ń bẹ níbẹ̀ tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ rọ.
\v 7 Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi ń ṣọ́ ọ, bóyá yóò mú un láradá ní ọjọ́ ìsinmi; kí wọn lè rí ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kàn án.
\v 8 Ṣùgbọ́n ó mọ èrò inú wọn, ó sì wí fún ọkùnrin náà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé, \wj “Dìde, kí o sì dúró láàrín.”\wj* Ó sì dìde dúró.
\p
\v 9 Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, \wj “Èmi bi yín léèrè, Ó ha tọ́ láti máa ṣe rere ni ọjọ́ ìsinmi, tàbí láti máa ṣe búburú? Láti gba ọkàn là, tàbí láti pa á run?”\wj*
\p
\v 10 Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká, ó wí fún ọkùnrin náà pé, \wj “Na ọwọ́ rẹ.”\wj* Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀: ọwọ́ rẹ̀ sì padà bọ̀ sípò gẹ́gẹ́ bí èkejì.
\v 11 Wọ́n sì kún fún ìbínú gbígbóná; wọ́n sì bá ara wọn rò ohun tí àwọn ìbá ṣe sí Jesu.
\s1 Àwọn aposteli méjìlá
\p
\v 12 \x - \xo 6.12-16: \xt Mk 3.13-19; Mt 10.2-4; Ap 1.13.\x*\x - \xo 6.12: \xt Lk 3.21; 5.16; 9.18,28; 11.1.\x*Ni ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Jesu lọ sí orí òkè láti gbàdúrà, ó sì fi gbogbo òru náà gbàdúrà sí Ọlọ́run.
\v 13 Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; nínú wọn ni ó sì yan méjìlá, tí ó sì sọ ní aposteli:
\b
\li1
\v 14 Simoni (ẹni tí a pè ní Peteru) àti Anderu arákùnrin rẹ̀,
\li1 Jakọbu,
\li1 Johanu,
\li1 Filipi,
\li1 Bartolomeu,
\li1
\v 15 Matiu,
\li1 Tomasi,
\li1 Jakọbu ọmọ Alfeu,
\li1 Simoni tí a ń pè ní Sealoti,
\li1
\v 16 Judea arákùnrin Jakọbu,
\li1 àti Judasi Iskariotu tí ó di ọ̀dàlẹ̀.
\s1 Ìbùkún àti ègún
\p
\v 17 \x - \xo 6.17-19: \xt Mt 5.1-2; 4.24-25; Mk 3.7-12.\x*Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀, ó sì dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn, láti gbogbo Judea, àti Jerusalẹmu, àti agbègbè Tire àti Sidoni, tí wọ́n wá láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti gba ìmúláradá kúrò nínú ààrùn wọn;
\v 18 àti àwọn tí ara wọn kún fún ẹ̀mí àìmọ́ ni ó sì mú láradá.
\v 19 \x - \xo 6.19: \xt Mk 3.10; Mt 9.21; 14.36; Lk 5.17.\x*Gbogbo ìjọ ènìyàn sì ń fẹ́ láti fọwọ́ kàn án, nítorí tí àṣẹ ń jáde lára rẹ̀, ó sì mú gbogbo wọn láradá.
\p
\v 20 \x - \xo 6.20-23: \xt Mt 5.3-12.\x*Nígbà tí ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní:
\q1 \wj “Alábùkún fún ni ẹ̀yin òtòṣì,\wj*
\q2 \wj nítorí tiyín ni ìjọba Ọlọ́run.\wj*
\q1
\v 21 \wj Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ebi ń pa\wj*
\q2 \wj nísinsin yìí; nítorí tí ẹ ó yóò.\wj*
\q1 \wj Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ń\wj*
\q2 \wj sọkún nísinsin yìí: nítorí tí ẹ̀yin ó rẹ́rìn-ín.\wj*
\q1
\v 22 \x - \xo 6.22: \xt 1Pt 4.14; Jh 9.22; 16.2.\x*\wj Alábùkún fún ni ẹ̀yin, nígbà tí àwọn ènìyàn bá kórìíra yín,\wj*
\q2 \wj tí wọ́n bá yà yín kúrò nínú ẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n bá gàn yín,\wj*
\q2 \wj tí wọ́n bá ta orúkọ yín nù bí ohun búburú,\wj*
\q3 \wj nítorí Ọmọ Ènìyàn.\wj*
\p
\v 23 \wj “Ẹ jẹ́ kí inú yín dùn, kí ẹ sì fò fún ayọ̀, nítorí púpọ̀ ní èrè yín ni ọ̀run. Báyìí ni àwọn baba yín ṣe ṣe sí àwọn wòlíì.\wj*
\q1
\v 24 \x - \xo 6.24-26: \xt Lk 10.13-15; 11.38-52; 17.1; 21.23; 22.22.\x*\x - \xo 6.24: \xt Lk 16.25; Jk 5.1-5; Mt 6.2.\x*\wj “Ègbé ni fún ẹ̀yin ọlọ́rọ̀\wj*
\q2 \wj nítorí ẹ ti gba ìtùnú yín.\wj*
\q1
\v 25 \wj Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ó yó,\wj*
\q2 \wj nítorí ebi yóò pa yín,\wj*
\q1 \wj Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń rẹ́rìn-ín nísinsin yìí,\wj*
\q2 \wj nítorí tí ẹ̀yin ó ṣọ̀fọ̀, ẹ̀yin ó sì sọkún.\wj*
\q1
\v 26 \wj Ègbé ni fún yín, nígbà tí gbogbo ènìyàn bá ń sọ̀rọ̀ yín ní rere,\wj*
\q2 \wj nítorí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn baba wọn ṣe sí àwọn wòlíì èké.\wj*
\s1 Ìfẹ́ fún àwọn ọ̀tá
\p
\v 27 \x - \xo 6.27-30: \xt Mt 5.39-44; Ro 12.17; 1Kọ 6.7.\x*\wj “Ṣùgbọ́n mo wí fún ẹ̀yin tí ń gbọ́ mi, ẹ fẹ́ àwọn ọ̀tá yín, ṣoore fún àwọn tí ó kórìíra yín.\wj*
\v 28 \wj Súre fún àwọn tí ń fi yín ré, sì gbàdúrà fún àwọn tí ń kẹ́gàn yín.\wj*
\v 29 \wj Ẹni tí ó bá sì lù ọ́ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ kan, yí kejì sí i pẹ̀lú; àti ẹni tí ó gba agbádá rẹ, má ṣe dá a dúró láti gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ pẹ̀lú.\wj*
\v 30 \wj Sì fi fún gbogbo ẹni tí ó tọrọ lọ́dọ̀ rẹ; lọ́dọ̀ ẹni tí ó sì kó ọ ní ẹrù, má sì ṣe padà béèrè.\wj*
\v 31 \x - \xo 6.31: \xt Mt 7.12.\x*\wj Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin sì ti fẹ́ kí ènìyàn ṣe sí yín, kí ẹ̀yin sì ṣe bẹ́ẹ̀ sí wọn pẹ̀lú.\wj*
\p
\v 32 \x - \xo 6.32-36: \xt Mt 5.44-48.\x*\wj “Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin bá fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ yín, ọpẹ́ kí ni ẹ̀yin ní? Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú ń fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ wọn.\wj*
\v 33 \wj Bí ẹ̀yin sì ṣoore fún àwọn tí ó ṣoore fún yín, ọpẹ́ kín ni ẹ̀yin ní? Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.\wj*
\v 34 \wj Bí ẹ̀yin bá fi fún ẹni tí ẹ̀yin ń retí láti rí gbà padà, ọpẹ́ kín ni ẹ̀yin ní? Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú ń yá ẹlẹ́ṣẹ̀, kí wọn lè gba ìwọ̀n bẹ́ẹ̀ padà.\wj*
\v 35 \x - \xo 6.35: \xt Mt 5.9.\x*\wj Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin fẹ́ àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì ṣoore, kí ẹ̀yin sì yá ẹlòmíràn, kí ẹ̀yin má ṣe retí láti rí nǹkan gbà padà; èrè yín yóò sì pọ̀, àwọn ọmọ Ọ̀gá-ògo ni a ó sì máa pè yín: nítorí tí ó ṣe rere fún aláìmoore àti fún ẹni búburú.\wj*
\v 36 \wj Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin ní àánú, gẹ́gẹ́ bí Baba yín sì ti ní àánú.\wj*
\s1 Dídá ni lẹ́jọ́
\p
\v 37 \x - \xo 6.37-38: \xt Mt 7.1-2; Ro 2.1.\x*\wj “Ẹ má ṣe dá ni lẹ́jọ́, a kì yóò sì dá yín lẹ́jọ́: ẹ má ṣe dá ni lẹ́bi, a kì yóò sì dá yín lẹ́bi: ẹ dáríjì, a ó sì dáríjì yín.\wj*
\v 38 \x - \xo 6.38: \xt Mk 4.24; Ap 20.35.\x*\wj Ẹ fi fún ni, a ó sì fi fún yín; òsùwọ̀n dáradára, àkìmọ́lẹ̀, àti àmìpọ̀, àkúnwọ́sílẹ̀, ni a ó wọ́n si àyà yín: nítorí òsùwọ̀n náà tí ẹ̀yin fi wọ́n, òun ni a ó padà fi wọ́n fún yín.”\wj*
\p
\v 39 \x - \xo 6.39: \xt Mt 15.14.\x*Ó sì pa òwe kan fún wọn wí pé, \wj “Afọ́jú ha lè ṣe amọ̀nà afọ́jú bí? Àwọn méjèèjì kọ́ ni yóò ṣubú sínú ihò bí?\wj*
\v 40 \x - \xo 6.40: \xt Mt 10.24-25; Jh 13.16; 15.20.\x*\wj Ẹni tí a ń kọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ: ṣùgbọ́n olúkúlùkù ẹni tí a bá kọ dáradára, yóò dàbí olùkọ́ rẹ̀.\wj*
\p
\v 41 \x - \xo 6.41-42: \xt Mt 7.3-5.\x*\wj “Èétiṣe tí ìwọ fi ń wo ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ ní ojú ara rẹ?\wj*
\v 42 \wj Tàbí ìwọ ó ti ṣe lè wí fún arákùnrin rẹ pé, Arákùnrin, jẹ́ kí èmi yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ lójú rẹ, nígbà tí ìwọ tìkára rẹ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ lójú rẹ? Ìwọ àgàbàgebè, kọ́kọ́ yọ ìtí igi jáde kúrò lójú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ ó sì tó ríran gbangba láti yọ èérún igi tí ń bẹ lójú arákùnrin rẹ kúrò.\wj*
\s1 Igi àti èso rẹ̀
\p
\v 43 \x - \xo 6.43-45: \xt Mt 7.18-19; 12.33-35; Jk 3.11-12.\x*\wj “Nítorí igi rere kì í so èso búburú; bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kì í so èso rere.\wj*
\v 44 \wj Olúkúlùkù igi ni a ń fi èso rẹ̀ mọ̀ ọn; nítorí lórí ẹ̀gún òṣùṣú, ènìyàn kì í ká èso ọ̀pọ̀tọ́ bẹ́ẹ̀ ni lórí ẹ̀gún ọ̀gàn a kì í ká èso àjàrà.\wj*
\v 45 \x - \xo 6.45: \xt Mk 7.20.\x*\wj Ènìyàn rere láti inú yàrá ìṣúra rere ọkàn rẹ̀ ní mú ohun rere jáde wá; àti ènìyàn búburú láti inú ìṣúra búburú ọkàn rẹ̀ ní í mú ohun búburú jáde wá: nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọkàn ní ẹnu ti máa sọ jáde.\wj*
\s1 Ọlọ́gbọ́n àti òmùgọ̀ ọ̀mọ̀lé
\p
\v 46 \x - \xo 6.46: \xt Mt 7.21.\x*\wj “Nítorí náà, èéṣe tí ẹ̀yin ń pè mí ní, Olúwa, Olúwa, tí ẹ̀yin kò sì ṣe ohun tí mo wí?\wj*
\v 47 \x - \xo 6.47-49: \xt Mt 7.24-27; Jk 1.22-25.\x*\wj Ẹnikẹ́ni tí ó tọ̀ mí wá, tí ó sì ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó sì ń ṣe é, èmi yóò fi ẹni tí ó jọ hàn yín.\wj*
\v 48 \wj Ó jọ ọkùnrin kan, tí ó kọ́ ilé, tí ó sì wa ilẹ̀ jìn, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta, nígbà tí kíkún omi sì dé, ìgbì omi kọlu ilé náà, kò sì lè mì ín nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta.\wj*
\v 49 \wj Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́, tí kò sì ṣe é, ó dàbí ọkùnrin tí ó kọ́ ilé sí orí ilẹ̀ láìní ìpìlẹ̀; nígbà tí ìgbì omi kọlù ú, lọ́gán, ó sì wó; wíwó ilé náà sì pọ̀ púpọ̀.”\wj*
\c 7
\s1 Ìgbàgbọ́ ọ̀gágun Romu kan
\p
\v 1 \x - \xo 7.1-10: \xt Mt 8.5-10,13; Jh 4.46-53.\x*Nígbà tí ó sì parí gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ fun àwọn ènìyàn, ó wọ Kapernaumu lọ.
\v 2 Ọmọ ọ̀dọ̀ balógun ọ̀rún kan, tí ó ṣọ̀wọ́n fún un, ṣàìsàn, ó sì ń kú lọ.
\v 3 Nígbà tí ó sì gbúròó Jesu, ó rán àwọn àgbàgbà Júù sí i, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá mú ọmọ ọ̀dọ̀ òun láradá.
\v 4 Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n fi ìtara bẹ̀ ẹ́, pé, “Ó yẹ ní ẹni tí òun ìbá ṣe èyí fún.
\v 5 \x - \xo 7.5: \xt Ap 10.2.\x*Nítorí tí ó fẹ́ràn orílẹ̀-èdè wa, ó sì ti kọ́ Sinagọgu kan fún wa.”
\v 6 Jesu sì ń bá wọn lọ.
\p Nígbà tí kò sì jìn sí etí ilé mọ́, balógun ọ̀rún náà rán àwọn ọ̀rẹ́ sí i, pé, “Olúwa, má ṣe yọ ara rẹ lẹ́nu, nítorí tí èmi kò yẹ tí ìwọ ìbá fi wọ abẹ́ òrùlé mi.
\v 7 Nítorí náà èmi kò sì rò pé èmi náà yẹ láti tọ̀ ọ́ wá, ṣùgbọ́n sọ ní gbólóhùn kan, a ó sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ mi láradá.
\v 8 Nítorí èmi náà pẹ̀lú jẹ́ ẹni tí a fi sí abẹ́ àṣẹ, tí ó ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi, mo sì wí fún ọ̀kan pé, Lọ, a sì lọ; àti fún òmíràn pé, Wá, a sì wá; àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, Ṣe èyí, a sì ṣe é.”
\p
\v 9 Nígbà tí Jesu gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu sì yà, ó sì yípadà sí ìjọ ènìyàn tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó wí pé, \wj “Mo wí fún yín pé èmi kò rí irú ìgbàgbọ́ ńlá bí èyí nínú àwọn ènìyàn Israẹli.”\wj*
\v 10 Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ sì padà sí ilé, wọ́n bá ọmọ ọ̀dọ̀ náà tí ń ṣàìsàn, ara rẹ̀ ti dá.
\s1 Jesu jí òkú ọmọ opó kan dìde
\p
\v 11 \x - \xo 7.11-17: \xt Mk 5.21-24,35-43; Jh 11.1-44; 1Ọb 17.17-24; 2Ọb 4.32-37.\x*Ní ọjọ́ kejì, ó lọ sí ìlú kan tí a ń pè ní Naini, àwọn púpọ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń bá a lọ àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn.
\v 12 Bí ó sì ti súnmọ́ ẹnu ibodè ìlú náà, sì kíyèsi i, wọ́n ń gbé òkú ọkùnrin kan jáde, ọmọ kan ṣoṣo náà tí ìyá rẹ̀ bí, ó sì jẹ́ opó: ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ìlú náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.
\v 13 \x - \xo 7.13: \xt Lk 7.19; 10.1; 11.39; 12.42; 13.15; 17.5-6; 18.6; 19.8; 22.61; 24.3.\x*Nígbà tí Olúwa sì rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé, \wj “Má sọkún mọ́.”\wj*
\p
\v 14 Ó sì wá, ó sì fi ọwọ́ tọ́ pósí náà: àwọn tí ń rù ú dúró jẹ́. Ó sì wí pé, \wj “Ọ̀dọ́mọkùnrin, mo wí fún ọ, dìde!”\wj*
\v 15 Ẹni tí ó kú náà sì dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí i fọhùn. Ó sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.
\p
\v 16 \x - \xo 7.16: \xt Lk 7.39; 24.19; Mt 21.11; Jh 6.14.\x*Ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn: wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, pé, “Wòlíì ńlá dìde nínú wa,” àti pé, “Ọlọ́run sì wá bẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò!”
\v 17 Òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo Judea, àti gbogbo agbègbè tí ó yí i ká.
\s1 Jesu àti Johanu onítẹ̀bọmi
\p
\v 18 \x - \xo 7.18-35: \xt Mt 11.2-19.\x*Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu sì sọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún un.
\v 19 Nígbà tí Johanu sì pe àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rán wọn sọ́dọ̀ Olúwa, wí pé, “Ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?”
\p
\v 20 Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé, “Johanu onítẹ̀bọmi rán wa sọ́dọ̀ rẹ, pé, Ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?’ ”
\p
\v 21 \x - \xo 7.21: \xt Mt 4.23; Mk 3.10.\x*Ní wákàtí náà, ó sì ṣe ìmúláradá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú àìsàn, àti ààrùn, àti ẹ̀mí búburú; ó sì fi ìríran fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn afọ́jú.
\v 22 \x - \xo 7.22: \xt Isa 29.18-19; 35.5-6; 61.1; Lk 4.18-19.\x*Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, \wj “Ẹ padà lọ, ẹ ròyìn nǹkan tí ẹ̀yin rí, tí ẹ̀yin sì gbọ́ fún Johanu: àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúnkùn ún rìn, a sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́rọ̀, a ń jí àwọn òkú dìde, àti fún àwọn òtòṣì ni à ń wàásù ìyìnrere.\wj*
\v 23 \wj Alábùkún fún sì ni ẹnikẹ́ni tí kò kọsẹ̀ lára mi.”\wj*
\p
\v 24 Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Johanu padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ìjọ ènìyàn ní ti Johanu pé, \wj “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ sí ijù lọ wò? Ewéko tí afẹ́fẹ́ ń mì?\wj*
\v 25 \wj Ṣùgbọ́n kín ni ẹ̀yin jáde lọ wò? Ọkùnrin tí a wọ̀ ní aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́? Wò ó, àwọn tí á wọ̀ ní aṣọ ògo, tí wọ́n sì ń jayé, ń bẹ ní ààfin ọba!\wj*
\v 26 \wj Ṣùgbọ́n kí ni ẹ̀yin jáde lọ wò? Wòlíì? Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ!\wj*
\v 27 \x - \xo 7.27: \xt Ml 3.1; Mk 1.2.\x*\wj Èyí yìí ni ẹni tí a ti kọ̀wé nítorí rẹ̀ pé:\wj*
\q1 \wj “Wò ó, èmi yóò rán oníṣẹ́ mi síwájú rẹ;\wj*
\q2 \wj ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe níwájú rẹ.\wj*
\m
\v 28 \wj Mo wí fún yín nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí wòlíì tí ó pọ̀ ju Johanu Onítẹ̀bọmi lọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kéré jùlọ ní ìjọba Ọlọ́run, ó pọ̀jù ú lọ.”\wj*
\p
\v 29 \x - \xo 7.29-30: \xt Mt 21.32; Lk 3.12.\x*(Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó gbọ́ àti àwọn agbowó òde, wọ́n dá Ọlọ́run láre, nítorí tí a fi ìtẹ̀bọmi Johanu tẹ̀ wọn bọ mi.
\v 30 Ṣùgbọ́n àwọn Farisi àti àwọn amòfin kọ ète Ọlọ́run fún ara wọn, a kò bamitiisi wọn lọ́dọ̀ rẹ̀.)
\p
\v 31 Jesu sì wí pé, \wj “Kí ni èmi ìbá fi àwọn ènìyàn ìran yìí wé? Kí ni wọ́n sì jọ?\wj*
\v 32 \wj Wọ́n dàbí àwọn ọmọ kékeré tí ó jókòó ní ibi ọjà, tí wọ́n sì ń kọ sí ara wọn, tí wọ́n sì ń wí pé,\wj*
\q1 \wj “Àwa fọn fèrè fún yín,\wj*
\q2 \wj ẹ̀yin kò jó, àwa sì ṣọ̀fọ̀ fún yín,\wj*
\q1 \wj ẹ̀yin kò sọkún!\wj*
\m
\v 33 \x - \xo 7.33: \xt Lk 1.15.\x*\wj Nítorí Johanu Onítẹ̀bọmi wá, kò jẹ àkàrà, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu ọtí wáìnì, ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù?\wj*
\v 34 \x - \xo 7.34: \xt Lk 5.29; 15.1-2; 7.36-50.\x*\wj Ọmọ ènìyàn dé, ó ń jẹ, ó sì ń mu, ẹ̀yin sì wí pé, Wò ó, ọ̀jẹun, àti ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀!\wj*
\v 35 \wj Ṣùgbọ́n ọgbọ́n ni a dá láre nípasẹ̀ ọmọ rẹ.”\wj*
\s1 A da òróró sí Jesu lára nípasẹ̀ obìnrin ẹlẹ́ṣẹ̀
\p
\v 36 \x - \xo 7.36-50: \xt Mt 26.6-13; Mk 14.3-9; Jh 12.1-8.\x*\x - \xo 7.36: \xt Lk 11.37; 14.1.\x*Farisi kan sì rọ̀ ọ́ kí ó wá bá òun jẹun, ó sì wọ ilé Farisi náà lọ ó sì jókòó láti jẹun.
\v 37 Sì kíyèsi i, obìnrin kan wà ní ìlú náà, ẹni tí i ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀, nígbà tí ó mọ̀ pé Jesu jókòó, ó ń jẹun ní ilé Farisi, ó mú ṣágo kékeré alabasita òróró ìkunra wá,
\v 38 Ó sì dúró tì í lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn, ó ń sọkún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i fi omijé wẹ̀ ẹ́ ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ nù ún nù, ó sì ń fi ẹnu kò ó ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi òróró kùn wọ́n.
\p
\v 39 \x - \xo 7.39: \xt Lk 7.16; 24.19; Mt 21.11; Jh 6.14.\x*Nígbà tí Farisi tí ó pè é sì rí i, ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Ọkùnrin yìí ìbá ṣe wòlíì, ìbá mọ ẹni àti irú ẹni tí obìnrin yìí jẹ́ tí ń fi ọwọ́ kàn an, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”
\p
\v 40 Jesu sì dáhùn, ó wí fún un pé, \wj “Simoni, Mo ní ohun kan sọ fún ọ.”\wj*
\p Ó sì dáhùn pé, “Olùkọ́ máa wí.”
\p
\v 41 \wj “Ayánilówó kan wà tí ó ní ajigbèsè méjì: ọ̀kan jẹ ẹ́ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) owó idẹ, èkejì sì jẹ ẹ́ ní àádọ́ta.\wj*
\v 42 \x - \xo 7.42: \xt Mt 18.25.\x*\wj Nígbà tí wọn kò sì ní ohun tí wọn ó san, ó dáríjì àwọn méjèèjì. Wí nínú àwọn méjèèjì, ta ni yóò fẹ́ ẹ jù?”\wj*
\p
\v 43 \x - \xo 7.43: \xt Lk 10.28.\x*Simoni dáhùn wí pé, “Mo ṣe bí ẹni tí ó dáríjì jù ni.”
\p Jesu wí fún un pé, \wj “Ìwọ ti dájọ́ náà dáradára.”\wj*
\p
\v 44 Ó sì yípadà sí obìnrin náà, ó wí fún Simoni pé, \wj “Wo obìnrin yìí? Èmi wọ ilé rẹ, ìwọ kò fi omi wẹ ẹsẹ̀ fún mi: ṣùgbọ́n, omijé rẹ̀ ni ó fi ń rọ̀jò sí mi lẹ́sẹ̀ irun orí ni ó fi ń nù wọ́n nù.\wj*
\v 45 \wj Ìwọ kò fi ìfẹnukonu fún mi: ṣùgbọ́n òun, nígbà tí mo ti wọ ilé, kò dẹ́kun ẹnu fífi kò mí lẹ́sẹ̀.\wj*
\v 46 \wj Ìwọ kò fi òróró pa mí lórí, ṣùgbọ́n òun ti fi òróró pa mí lẹ́sẹ̀.\wj*
\v 47 \wj Ǹjẹ́ mo wí fún ọ, A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀ jì í: nítorí tí ó ní ìfẹ́ púpọ̀: ẹni tí a sì dárí díẹ̀ jì, òun náà ni ó ní ìfẹ́ díẹ̀.”\wj*
\p
\v 48 \x - \xo 7.48: \xt Mt 9.2; Mk 2.5; Lk 5.20.\x*Ó sì wí fún un pé, \wj “A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́!”\wj*
\p
\v 49 Àwọn tí ó bá a jókòó jẹun sì bẹ̀rẹ̀ sí í rò nínú ara wọn pé, “Ta ni èyí tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni pẹ̀lú?”
\p
\v 50 \x - \xo 7.50: \xt Mt 9.22; Mk 5.34; Lk 8.48.\x*Ó sì dáhùn wí fún obìnrin náà pé, \wj “Ìgbàgbọ́ rẹ gbà ọ́ là, máa lọ ní àlàáfíà.”\wj*
\c 8
\s1 Òwe afúnrúgbìn kan
\p
\v 1 \x - \xo 8.1-3: \xt Lk 4.15; Mk 15.40-41; Mt 27.55-56; Lk 23.49.\x*Ó sì ṣe lẹ́yìn náà, tí ó ń lá gbogbo ìlú àti ìletò kọjá lọ, ó ń wàásù, ó ń ròyìn ayọ̀ ìjọba Ọlọ́run. Àwọn méjìlá sì ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀,
\v 2 àti àwọn obìnrin kan, tí a ti mú láradá kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí búburú àti nínú àìlera wọn, Maria tí a ń pè ní Magdalene, lára ẹni tí ẹ̀mí èṣù méje ti jáde kúrò.
\v 3 Àti Joanna aya Kusa tí í ṣe ìríjú Herodu, àti Susana, àti àwọn púpọ̀ mìíràn, tí wọ́n ń ṣe ìránṣẹ́ fún un nínú ohun ìní wọn.
\p
\v 4 \x - \xo 8.4-8: \xt Mt 13.1-9; Mk 4.1-9.\x*Nígbà tí ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn péjọpọ̀, àwọn ènìyàn láti ìlú gbogbo sì tọ̀ ọ́ wá, ó fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé,
\v 5 \wj “Afúnrúgbìn kan jáde lọ láti fún irúgbìn rẹ̀: bí ó sì ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, a sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ṣà á jẹ.\wj*
\v 6 \wj Òmíràn sì bọ́ sórí àpáta; bí ó sì ti hù jáde, ó gbẹ nítorí tí kò ní omi.\wj*
\v 7 \wj Òmíràn sì bọ́ sínú ẹ̀gún; ẹ̀gún sì dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ sókè, ó sì fún un pa.\wj*
\v 8 \x - \xo 8.8: \xt Mt 11.15.\x*\wj Òmíràn sì bọ́ sí ilẹ̀ rere, ó sì hù sókè, ó sì so èso ọ̀rọ̀ọ̀rún ju èyí ti a gbin lọ.”\wj*
\p Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí tán, ó pariwo sókè pé, \wj “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́!”\wj*
\p
\v 9 \x - \xo 8.9-10: \xt Mt 13.10-13; Mk 4.10-12; Isa 6.9-10; Jr 5.21; El 12.2.\x*Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi í léèrè, pé, “Kí ni a lè mọ òwe yìí sí?”
\v 10 Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọ́run; ṣùgbọ́n fún àwọn ẹlòmíràn wọn yóò jẹ́ òwe, pé ní rí rí,\wj*
\q1 \wj “kí wọn má ba à rí,\wj*
\q2 \wj àti ní gbígbọ́ kí ó má lè yé wọn.\wj*
\p
\v 11 \x - \xo 8.11-15: \xt Mt 13.18-23; Mk 4.13-20.\x*\x - \xo 8.11: \xt 1Tẹ 2.13; 1Pt 1.23.\x*\wj “Ǹjẹ́ òwe náà ni èyí: irúgbìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.\wj*
\v 12 \wj Àwọn ti ẹ̀bá ọ̀nà ni àwọn tí ó gbọ́ nígbà náà ni èṣù wá ó sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò ní ọkàn wọn, kí wọn má ba à gbàgbọ́, kí a sì gbà wọ́n là.\wj*
\v 13 \wj Àwọn ti orí àpáta ni àwọn, tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà, àwọn wọ̀nyí kò sì ní gbòǹgbò, wọ́n á gbàgbọ́ fún sá à díẹ̀; nígbà ìdánwò, wọn á padà sẹ́yìn.\wj*
\v 14 \wj Àwọn tí ó bọ́ sínú ẹ̀gún ni àwọn, tí wọ́n gbọ́ tán, wọ́n ti n lọ, wọn a sì fi ìtọ́jú àti ọrọ̀ àti ìrora ayé fún un pa, wọn kò sì lè so èso àsogbó.\wj*
\v 15 \wj Ṣùgbọ́n ti ilẹ̀ rere ni àwọn tí wọ́n fi ọkàn òtítọ́ àti rere gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n dìímú ṣinṣin, wọ́n sì fi sùúrù so èso.\wj*
\s1 Àtùpà lórí tábìlì
\p
\v 16 \x - \xo 8.16: \xt Mk 4.21; Mt 5.15; Lk 11.33.\x*\wj “Kò sí ẹnikẹ́ni, nígbà tí ó bá tán fìtílà tan, tí yóò fi ohun èlò bò ó mọ́lẹ̀, tàbí tí yóò gbé e sábẹ́ àkéte; bí kò ṣe kí ó gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà, kí àwọn tí ń wọ ilé lè rí ìmọ́lẹ̀.\wj*
\v 17 \x - \xo 8.17: \xt Mk 4.22-23; Mt 10.26-27; Lk 12.2-3; Ef 5.13.\x*\wj Nítorí kò sí ohun tí ó fi ara sin, tí a kì yóò fihàn, tàbí ohun tí a fi pamọ́, ti a kì yóò sì mọ̀ kí ó sì yọ sí gbangba.\wj*
\v 18 \x - \xo 8.18: \xt Mk 4.24-25; Mt 13.12; 25.29; Lk 19.26.\x*\wj Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin máa kíyèsára bí ẹ̀yin ti ń gbọ́: nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní, lọ́wọ́ rẹ̀ ni a ó sì gba èyí tí ó ṣe bí òun ní.”\wj*
\s1 Àwọn ìyá àti arákùnrin Jesu
\p
\v 19 \x - \xo 8.19-21: \xt Mt 12.46-50; Mk 3.31-35.\x*Nígbà náà ní ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn kò sì lè súnmọ́ ọn nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn.
\v 20 Wọ́n sì wí fún un pé, “Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ dúró lóde, wọn fẹ́ rí ọ.”
\p
\v 21 \x - \xo 8.21: \xt Lk 11.28; Jh 15.14.\x*Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, \wj “Ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni àwọn wọ̀nyí tí wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń ṣe é.”\wj*
\s1 Jesu bá rírú omi okun wí
\p
\v 22 \x - \xo 8.22-25: \xt Mt 8.23-27; Mk 4.35-41; 6.47-52; Jh 6.16-21.\x*Ní ọjọ́ kan, ó sì wọ ọkọ̀ ojú omi kan lọ òun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. O sì wí fún wọn pé, \wj “Ẹ jẹ́ kí a rékọjá lọ sí ìhà kejì adágún.”\wj* Wọ́n sì ṣíkọ̀ láti lọ.
\v 23 Bí wọ́n sì ti ń lọ, ó sùn; ìjì ńlá sì dé, ó ń fẹ́ lójú adágún; omi si wọ inú ọkọ, wọ́n sì wà nínú ewu.
\p
\v 24 \x - \xo 8.24: \xt Lk 5.5; 8.45; 9.33,49; 17.13.\x*Wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá wọ́n sì jí i, wí pé, “Olùkọ́, Olùkọ́, àwa yóò ṣègbé!”
\p Nígbà náà ni ó dìde, ó sì bá ìjì líle àti ríru omi wí; wọ́n sì dúró, ìdákẹ́rọ́rọ́ sì dé.
\v 25 Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Ìgbàgbọ́ yín dà?”\wj*
\p Bí ẹ̀rù ti ń ba gbogbo wọn, tí hà sì ń ṣe wọ́n, wọ́n ń bi ara wọn pé, “Irú ọkùnrin wo ni èyí, nítorí ó bá ìjì líle àti ríru omi wí, wọ́n sì gbọ́ tirẹ̀?”
\s1 Jesu wo ọkùnrin ẹlẹ́mìí èṣù sàn
\p
\v 26 \x - \xo 8.26-39: \xt Mt 8.28-34; Mk 5.1-20.\x*Wọ́n sì gúnlẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Gadara, tí ó kọjú sí Galili.
\v 27 Nígbà tí ó sì sọ̀kalẹ̀, ọkùnrin kan pàdé rẹ̀ lẹ́yìn ìlú náà, tí ó ti ní àwọn ẹ̀mí èṣù fún ìgbà pípẹ́, tí kì í wọ aṣọ, bẹ́ẹ̀ ni kì í jókòó ní ilé kan, bí kò ṣe ní ibojì.
\v 28 \x - \xo 8.28: \xt Mk 1.24; Jh 2.4.\x*Nígbà tí ó rí Jesu, ó ké, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wí lóhùn rara, pé, “Kí ni mo ní í ṣe pẹ̀lú rẹ, Jesu, ìwọ Ọmọ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo? Èmi bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró.”
\v 29 (Nítorí tí ó ti wí fún ẹ̀mí àìmọ́ náà pé, kí ó jáde kúrò lára ọkùnrin náà. Nígbàkígbà ni ó ń mú un: wọn a sì fi ẹ̀wọ̀n àti ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é; a sì ja gbogbo ìdè náà, ẹ̀mí èṣù náà a sì darí rẹ̀ sí ijù).
\p
\v 30 Jesu sì bi í pé, \wj “Kí ni orúkọ rẹ?”\wj*
\p Ó sì dáhùn pé, “Ligioni,” nítorí ẹ̀mí èṣù púpọ̀ ni ó wa nínú rẹ.
\v 31 Wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe rán wọn lọ sínú ọ̀gbun.
\p
\v 32 Agbo ẹlẹ́dẹ̀ púpọ̀ sì ń bẹ níbẹ̀ tí ń jẹ lórí òkè: wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹ́ kí àwọn wọ inú wọn lọ. Ó sì gba fún wọn.
\v 33 Nígbà tí àwọn ẹ̀mí èṣù sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ lọ. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ sì tú ka, wọ́n sí súré rọ́ gììrì sọ̀kalẹ̀ sì bèbè odò bọ́ sínú adágún náà, wọ́n sì rì sínú rẹ̀.
\p
\v 34 Nígbà tí àwọn tí n bọ́ wọn rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sá, wọ́n sì lọ, wọ́n sì ròyìn ní ìlú àti ní ilẹ̀ náà.
\v 35 Nígbà náà ni wọ́n jáde lọ wo ohun náà tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sì tọ Jesu wá, wọ́n sì rí ọkùnrin náà, lára ẹni tí àwọn ẹ̀mí èṣù ti jáde lọ, ó jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó wọ aṣọ, iyè rẹ̀ sì bọ́ sí ipò: ẹ̀rù sì bà wọ́n.
\v 36 Àwọn tí ó rí i ròyìn fún wọn bí ó ti ṣe mú ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù náà láradá.
\v 37 Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn láti ilẹ̀ Gadara yíká bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn; nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Ó sì bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, ó si kúrò.
\p
\v 38 Ǹjẹ́ ọkùnrin náà tí ẹ̀mí èṣù jáde kúrò lára rẹ̀, bẹ̀ ẹ́ kí òun lè máa bá a gbé: ṣùgbọ́n Jesu rán an lọ, wí pé,
\v 39 \wj “Padà lọ sí ilé rẹ, kí o sì sọ ohun tí Ọlọ́run ṣe fún ọ bí ó ti pọ̀ tó.”\wj* Ó sì lọ, o sì ń ròyìn ka gbogbo ìlú náà bí Jesu ti ṣe ohun ńlá fún òun tó.
\s1 Òkú obìnrin kan àti obìnrin aláìsàn kan
\p
\v 40 \x - \xo 8.40-56: \xt Mt 9.18-26; Mk 5.21-43.\x*Ó sì ṣe, nígbà tí Jesu padà lọ, àwọn ènìyàn tẹ́wọ́gbà á; nítorí tí gbogbo wọn ti ń retí rẹ̀.
\v 41 Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jairu, ọ̀kan nínú àwọn olórí Sinagọgu wá; ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó wá sí ilé òun,
\v 42 nítorí ó ní ọmọbìnrin kan ṣoṣo, ọmọ ìwọ̀n ọdún méjìlá, ti ó ń kú lọ.
\p Bí ó sì ti ń lọ àwọn ènìyàn ko fun ni ààyè.
\v 43 Obìnrin kan tí ó sì ní ìsun ẹ̀jẹ̀ láti ìgbà ọdún méjìlá, tí ó ná ohun gbogbo tí ó ní fún àwọn oníṣègùn, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó lè mú un láradá,
\v 44 Ó wá sí ẹ̀yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ tọ́ ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀; lọ́gán ni ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ti gbẹ.
\p
\v 45 \x - \xo 8.45: \xt Lk 8.24.\x*Jesu sì wí pé, \wj “Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mí?”\wj*
\p Nígbà tí gbogbo wọn sẹ́ Peteru àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sọ pé, “Olùkọ́, àwọn ènìyàn ko ní ààyè, wọ́n sì ń kọlù ọ́, ìwọ sì wí pé, Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mi?”
\p
\v 46 \x - \xo 8.46: \xt Lk 5.17; 6.19.\x*Jesu sì wí pé, \wj “Ẹnìkan fi ọwọ́ kàn mí: nítorí tí èmí mọ̀ pé, àṣẹ jáde lára mi.”\wj*
\p
\v 47 Nígbà tí obìnrin náà sì mọ̀ pé òun kò fi ara sin, ó wárìrì, ó wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ fún un lójú àwọn ènìyàn gbogbo nítorí ohun tí ó ṣe, tí òun fi fi ọwọ́ kàn án, àti bí a ti mú òun láradá lójúkan náà.
\v 48 \x - \xo 8.48: \xt Mt 9.22; Lk 7.50; 17.19; 18.42.\x*Ó sì wí fún un pé, \wj “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá, máa lọ ní Àlàáfíà.”\wj*
\p
\v 49 Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lẹ́nu, ẹnìkan ti ilé olórí Sinagọgu wá, ó wí fún un pé, “Ọmọbìnrin rẹ kú; má yọ olùkọ́ni lẹ́nu mọ́.”
\p
\v 50 Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu gbọ́, ó dá a lóhùn, pé, \wj “Má bẹ̀rù: sá gbàgbọ́ nìkan, a ó sì mú un láradá.”\wj*
\p
\v 51 Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu sì wọ ilé, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọlé, bí kò ṣe Peteru, àti Jakọbu, àti Johanu, àti baba àti ìyá ọmọbìnrin náà.
\v 52 Gbogbo wọn sì sọkún, wọ́n pohùnréré ẹkún rẹ̀: ó sì wí fún wọn pé, \wj “Ẹ má sọkún mọ́; kò kú, sísùn ni ó sùn.”\wj*
\p
\v 53 Wọ́n sì fi í ṣẹ̀fẹ̀, wọ́n sá mọ̀ pé ó kú.
\v 54 Nígbà tí ó sì sé gbogbo wọn mọ́ òde, ó mú un lọ́wọ́, ó sì wí pé, \wj “Ọmọbìnrin, dìde!”\wj*
\v 55 Ẹ̀mí rẹ̀ sì padà bọ̀, ó sì dìde lọ́gán: ó ní kí wọn fún un ní oúnjẹ.
\v 56 \x - \xo 8.56: \xt Mt 8.4; Mk 3.12; 7.36; Lk 9.21.\x*Ẹnu sì ya àwọn òbí rẹ̀: ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn pé, kí wọn má ṣe wí fún ẹnìkan ohun tí a ṣe.
\c 9
\s1 Jesu rán ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá lọ wàásù
\p
\v 1 \x - \xo 9.1-6: \xt Mt 10.1,5,7-11,14; Mk 6.7-12; Lk 10.4-11.\x*Ó sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá jọ, ó sì fún wọn ní agbára àti àṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí èṣù gbogbo, àti láti wo ààrùn sàn.
\v 2 Ó sì rán wọn lọ wàásù ìjọba Ọlọ́run, àti láti mú àwọn ọlọkùnrùn láradá.
\v 3 Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Ẹ má ṣe mú nǹkan lọ́wọ́ fún àjò yín, ọ̀pá, tàbí àpò tàbí àkàrà, tàbí owó, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má sì ṣe ní ẹ̀wù méjì.\wj*
\v 4 \wj Ní ilékílé tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin gbé, láti ibẹ̀ ni kí ẹ̀yin sì ti jáde.\wj*
\v 5 \x - \xo 9.5: \xt Ap 13.51.\x*\wj Iye àwọn tí kò bá si gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá jáde kúrò ní ìlú náà, ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín fún ẹ̀rí sí wọn.”\wj*
\v 6 Wọ́n sì lọ, wọ́n ń la ìletò kọjá wọ́n sì ń wàásù ìyìnrere, wọ́n sì ń mú ènìyàn láradá níbi gbogbo.
\p
\v 7 \x - \xo 9.7-9: \xt Mt 14.1-2; Mk 6.14-16; Lk 9.19.\x*Herodu tetrarki gbọ́ nǹkan gbogbo èyí tí a ṣe láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá: ó sì dààmú, nítorí tí àwọn ẹlòmíràn ń wí pé, Johanu ni ó jíǹde kúrò nínú òkú,
\v 8 Àwọn ẹlòmíràn sì wí pé Elijah ni ó farahàn; àwọn ẹlòmíràn sì wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde.
\v 9 \x - \xo 9.9: \xt Lk 23.8.\x*Herodu sì wí pé, “Johanu ni mo ti bẹ́ lórí, ṣùgbọ́n ta ni èyí tí èmi ń gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí sí?” Ó sì ń fẹ́ láti rí i.
\s1 Jesu bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ènìyàn
\p
\v 10 \x - \xo 9.10: \xt Mk 6.30-31; Lk 10.17; Jh 1.44.\x*Nígbà tí àwọn aposteli sì padà dé, wọ́n ròyìn ohun gbogbo fún un tí wọ́n ti ṣe. Ó sì mú wọn, lọ sí apá kan níbi tí a ń pè ní Betisaida.
\v 11 \x - \xo 9.11-17: \xt Mt 14.13-21; Mk 6.32-44; Jh 6.1-14; Mk 8.4-10.\x*Nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sì mọ̀, wọ́n tẹ̀lé e: ó sì gbà wọ́n, ó sì sọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún wọn; àwọn tí ó fẹ́ ìmúláradá, ni ó sì mú láradá.
\p
\v 12 Nígbà tí ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ sí rọlẹ̀, àwọn méjìlá wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Tú ìjọ ènìyàn ká, kí wọn lè lọ sí ìletò àti sí ìlú yíká, kí wọn lè wò, àti kí wọn lè wá oúnjẹ: nítorí ijù ni àwa sá wà níhìn-ín.”
\p
\v 13 \x - \xo 9.13: \xt 2Ọb 4.42-44.\x*Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, \wj “Ẹ fi oúnjẹ fún wọn jẹ!”\wj*
\p Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-ún lọ, pẹ̀lú ẹja méjì: bí kò ṣe pé àwa lọ ra oúnjẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí.”
\v 14 Nítorí àwọn ọkùnrin náà tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ènìyàn.
\p Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, \wj “Kí wọ́n mú wọn jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, ní àràádọ́ta.”\wj*
\v 15 Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì mú gbogbo wọn jókòó.
\v 16 \x - \xo 9.16: \xt Lk 22.19; 24.30-31; Ap 2.42; 20.11; 27.35.\x*Nígbà náà ni ó mú ìṣù àkàrà márùn-ún, àti ẹja méjì náà, nígbà tí ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó súre sí i, ó sì bù ú, ó sì fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, kí wọn gbé e kalẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn.
\v 17 Wọ́n sì jẹ, gbogbo wọn sì yó: wọ́n ṣa agbọ̀n méjìlá jọ nínú àjẹkù tí ó kù.
\s1 Peteru pe Jesu ní Ọmọ Ọlọ́run
\p
\v 18 \x - \xo 9.18-21: \xt Mt 16.13-20; Mk 8.27-30; Jh 1.49; 11.27; 6.66-69.\x*\x - \xo 9.18: \xt Lk 3.21; 5.16; 6.12; 9.28; 11.1.\x*Ó sì ṣe, nígbà tí ó ku òun nìkan ó gbàdúrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀: ó sì bi wọ́n pé, \wj “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi mí pè?”\wj*
\p
\v 19 \x - \xo 9.19: \xt Lk 9.9; Mk 9.11-13.\x*Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi; ṣùgbọ́n ẹlòmíràn ní Elijah ni, àti àwọn ẹlòmíràn wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde.”
\p
\v 20 Ó sì bi wọ́n pé, \wj “Ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin ń fi èmi pè?”\wj*
\p Peteru sì dáhùn, wí pe, “Kristi ti Ọlọ́run.”
\p
\v 21 Ó sì kìlọ̀ fún wọn, pé, kí wọn má ṣe sọ èyí fún ẹnìkan.
\v 22 \x - \xo 9.22: \xt Mt 16.21; Mk 8.31; Lk 9.43-45; 18.31-34; 17.5.\x*Ó sì wí pé, \wj “Ọmọ ènìyàn yóò jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà, olórí àlùfáà àti láti ọ̀dọ̀ àwọn akọ̀wé, a ó sì pa á, ní ọjọ́ kẹta a ó sì jí i dìde.”\wj*
\p
\v 23 \x - \xo 9.23-27: \xt Mt 16.24-28; Mk 8.349.1.\x*Ó sì wí fún gbogbo wọn pé, \wj “Bí ẹnìkan bá ń fẹ́ láti máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀ ní ọjọ́ gbogbo, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.\wj*
\v 24 \x - \xo 9.24-25: \xt Mt 10.38-39; Lk 14.27; 17.33; Jh 12.25.\x*\wj Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọkàn rẹ̀ nù nítorí mi, òun náà ni yóò sì gbà á là.\wj*
\v 25 \wj Nítorí pé èrè kín ni fún ènìyàn, bí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sì sọ ara rẹ̀ nù tàbí kí ó fi ṣòfò.\wj*
\v 26 \x - \xo 9.26: \xt Mt 10.33; Lk 12.9; 1Jh 2.28.\x*\wj Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú mi, àti ọ̀rọ̀ mi, òun ni Ọmọ Ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé inú ògo tirẹ̀, àti ti baba rẹ̀, àti ti àwọn angẹli mímọ́.\wj*
\p
\v 27 \x - \xo 9.27: \xt Lk 22.18; Mt 10.23; 1Tẹ 4.15-18; Jh 21.22.\x*\wj “Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹlòmíràn dúró níhìn-ín yìí, tí kì yóò rí ikú, títí wọn ó fi rí ìjọba Ọlọ́run.”\wj*
\s1 Ìràpadà
\p
\v 28 \x - \xo 9.28-36: \xt Mt 17.1-8; Mk 9.2-8; 2Pt 1.17-18.\x*\x - \xo 9.28: \xt Lk 8.51; 3.21; 5.16; 6.12; 9.18; 11.1.\x*Ó sì ṣe bí ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Peteru àti Johanu àti Jakọbu, ó gun orí òkè lọ láti lọ gbàdúrà.
\v 29 Bí ó sì ti ń gbàdúrà, àwọ̀ ojú rẹ̀ yípadà, aṣọ rẹ̀ sì funfun gbòò,
\v 30 \x - \xo 9.30: \xt Ap 1.9-11.\x*Sì kíyèsi i, àwọn ọkùnrin méjì, Mose àti Elijah, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀,
\v 31 tí wọ́n fi ara hàn nínú ògo, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ikú rẹ̀, tí òun yóò ṣe parí ní Jerusalẹmu.
\v 32 \x - \xo 9.32: \xt Jh 1.14.\x*Ṣùgbọ́n ojú Peteru àti ti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wúwo fún oorun. Nígbà tí wọ́n sì tají, wọ́n rí ògo rẹ̀, àti ti àwọn ọkùnrin méjèèjì tí ó bá a dúró.
\v 33 \x - \xo 9.33: \xt Lk 5.5; 8.24,45; 9.49; 17.13.\x*Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, Peteru wí fún Jesu pé, “Olùkọ́, ó dára fún wa kí a máa gbé ìhín yìí, jẹ́ kí àwa pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ìwọ, àti ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.” (Kò mọ èyí tí òun ń wí.)
\p
\v 34 Bí ó ti ń sọ báyìí, ìkùùkuu kan wá, ó síji bò wọ́n: ẹ̀rù sì bà wọ́n nígbà tí wọ́n ń wọ inú ìkùùkuu lọ.
\v 35 \x - \xo 9.35: \xt Lk 3.22; Jh 12.28-30.\x*Ohùn kan sì ti inú ìkùùkuu wá wí pé, “Èyí yìí ni àyànfẹ́ ọmọ mi: ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.”
\v 36 \x - \xo 9.36: \xt Mt 17.9; Mk 9.9-10.\x*Nígbà tí ohùn náà sì dákẹ́, Jesu nìkan ṣoṣo ni a rí. Wọ́n sì pa á mọ́, wọn kò sì sọ ohunkóhun tí wọ́n rí fún ẹnikẹ́ni ní ọjọ́ wọ̀nyí.
\s1 Ìwòsàn ọmọkùnrin kan tí o ní ẹ̀mí èṣù
\p
\v 37 \x - \xo 9.37-43: \xt Mt 17.14-18; Mk 9.14-27.\x*Ó sì ṣe, ní ọjọ́ kejì, nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti orí òkè, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn wá pàdé rẹ̀.
\v 38 Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan nínú ìjọ ènìyàn kígbe sókè pé, “Olùkọ́ mo bẹ̀ ọ́, wo ọmọ mi: nítorí ọmọ mi kan ṣoṣo náà ni.
\v 39 Sì kíyèsi i, ẹ̀mí èṣù a máa mú un, a sì máa kígbe lójijì; a sì máa nà án tàntàn títí yóò fi yọ ìfófó lẹ́nu, a máa pa á lára, kì í tilẹ̀ ń fẹ́ fi í sílẹ̀ lọ.
\v 40 Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ láti lé e jáde: wọn kò sì lè ṣe é.”
\p
\v 41 Jesu sì dáhùn pé, \wj “Ìran aláìgbàgbọ́ àti àrékérekè, èmi ó ti bá yín gbé pẹ́ tó? Èmi yóò sì ti ṣe sùúrù fún yín pẹ́ tó? Fa ọmọ rẹ wá níhìn-ín yìí.”\wj*
\p
\v 42 Bí ó sì ti ń bọ̀, ẹ̀mí èṣù náà gbé e ṣánlẹ̀, ó sì nà án tàntàn. Jesu sì bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí, ó sì mú ọmọ náà láradá, ó sì fà á lé baba rẹ̀ lọ́wọ́.
\v 43 \x - \xo 9.43-45: \xt Mt 17.22-23; Mk 9.30-32; Lk 9.22; 18.31-34; 17.25.\x*Ẹnu sì ya gbogbo wọn sí iṣẹ́ títóbi Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nígbà tí hà sì ń ṣe gbogbo wọn sí ohun gbogbo tí Jesu ṣe, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé,
\v 44 \wj “Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wọ̀ yín létí, nítorí a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́.”\wj*
\v 45 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yé wọn, ó sì ṣú wọn lójú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì mọ̀ ọ́n: ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti béèrè ìdí ọ̀rọ̀ náà.
\s1 Ta ni yí o ga jùlọ
\p
\v 46 \x - \xo 9.46-48: \xt Mt 18.1-5; Mk 9.33-37.\x*Iyàn kan sì dìde láàrín wọn, ní ti ẹni tí yóò ṣe olórí nínú wọn.
\v 47 Nígbà tí Jesu sì mọ èrò ọkàn wọn, ó mú ọmọdé kan, ó gbé e jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀.
\v 48 \x - \xo 9.48: \xt Lk 10.16; Mt 10.40.\x*Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọdé yìí nítorí orúkọ mi, ó gbà mí: àti ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi: nítorí ẹni tí ó bá kéré jù nínú gbogbo yín, òun náà ni yóò pọ̀jù.”\wj*
\p
\v 49 \x - \xo 9.49-50: \xt Mk 9.38-40; Lk 11.23.\x*\x - \xo 9.49: \xt Lk 5.5; 8.24,45; 9.33; 17.13.\x*Johanu sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́, àwa rí ẹnìkan ó ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde; àwa sì dá a lẹ́kun, nítorí tí kò bá wa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”
\p
\v 50 Jesu sì wí fún un, pé, \wj “Má ṣe dá a lẹ́kun mọ́: nítorí ẹni tí kò bá lòdì sí i yín, ó wà fún yín.”\wj*
\s1 Ìtakò àwọn ará Samaria
\p
\v 51 \x - \xo 9.51-56: \xt Mk 10.1; Lk 17.11; Jh 4.40-42.\x*Nígbà tí ọjọ́ àti gbà á sókè ń súnmọ́, ó pinnu láti lọ sí Jerusalẹmu.
\v 52 \x - \xo 9.52: \xt Mt 10.5; Jh 4.4.\x*Ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ lọ sí iwájú rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì lọ wọ́n wọ ìletò kan tí í ṣe ti ará Samaria láti pèsè sílẹ̀ dè é.
\v 53 Wọn kò sì gbà á, nítorí pé ó ń lọ sí Jerusalẹmu.
\v 54 \x - \xo 9.54: \xt Mk 3.17; 2Ọb 1.9-16.\x*Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Jakọbu àti Johanu sì rí i, wọ́n ní, “Olúwa wa, jẹ́ kí a pe iná láti ọ̀run wá, kí a sì pa wọ́n run, bí Elijah ti ṣe?”
\v 55 Ṣùgbọ́n Jesu yípadà, ó sì bá wọn wí.
\v 56 Lẹ́yìn náà Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì lọ sí ìletò mìíràn.
\s1 Ìpinnu láti tọ Jesu lẹ́yìn
\p
\v 57 \x - \xo 9.57-60: \xt Mt 8.19-22.\x*Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ọkùnrin kan wí fún un pé, “Olúwa, Èmi ń fẹ́ láti máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”
\p
\v 58 Jesu sì wí fún un pé, \wj “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́; ṣùgbọ́n Ọmọ Ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”\wj*
\p
\v 59 Ó sì wí fún ẹlòmíràn pé, \wj “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”\wj*
\p Ṣùgbọ́n èyí wí fún un pé, “Olúwa, jẹ́ kí èmi lọ sìnkú baba mi ná.”
\p
\v 60 Jesu sì wí fún un pé, \wj “Jẹ́ kí àwọn òkú máa sìnkú ara wọn, ṣùgbọ́n ìwọ lọ kí o sì máa wàásù ìjọba Ọlọ́run.”\wj*
\p
\v 61 \x - \xo 9.61: \xt 1Ọb 19.20; Fp 3.13.\x*Ẹlòmíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, èmi yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ṣùgbọ́n jẹ́ kí n kọ́kọ́ lọ dágbére fún àwọn ará ilé mi.”
\p
\v 62 Jesu sì wí fún un pé, \wj “Kò sí ẹni, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun èlò ìtulẹ̀, tí ó sì wo ẹ̀yìn, tí ó yẹ fún ìjọba Ọlọ́run.”\wj*
\c 10
\s1 Jesu rán méjìléláàádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn jáde
\p
\v 1 \x - \xo 10.1: \xt Lk 9.1-2,51-52; 7.13.\x*Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Olúwa sì yan méjìléláàádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn pẹ̀lú, ó sì rán wọn ní méjì méjì lọ ṣáájú rẹ̀, sí gbogbo ìlú àti ibi tí òun tìkára rẹ̀ yóò sì dé.
\v 2 \x - \xo 10.2: \xt Mt 9.37-38; Jh 4.35.\x*Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan, nítorí náà ẹ bẹ Olúwa ìkórè, kí ó lè rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀.\wj*
\v 3 \x - \xo 10.3-12: \xt Mt 10.7-16; Mk 6.8-11; Lk 9.2-5; 22.35-36.\x*\wj Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n: sá wò ó, èmi rán yín lọ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sáàrín ìkookò.\wj*
\v 4 \wj Ẹ má ṣe mú àpò, ẹ má ṣe mú àpamọ́wọ́, tàbí bàtà: ẹ má sì ṣe kí ẹnikẹ́ni lọ́nà.\wj*
\p
\v 5 \x - \xo 10.5: \xt 1Sa 25.6.\x*\wj “Ní ilékílé tí ẹ̀yin bá wọ̀, kí ẹ kọ́ wí pé, Àlàáfíà fún ilé yìí!\wj*
\v 6 \wj Bí ọmọ àlàáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín yóò bà lé e: ṣùgbọ́n bí kò bá sí, yóò tún padà sọ́dọ̀ yín.\wj*
\v 7 \x - \xo 10.7: \xt 1Kọ 10.27; 9.14; 1Tm 5.18; De 24.15.\x*\wj Ẹ dúró sínú ilé náà, kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ohunkóhun tí wọ́n bá fi fún yín, nítorí ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i. Ẹ má ṣe lọ láti ilé dé ilé.\wj*
\p
\v 8 \wj “Ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá wọ̀, tí wọ́n bá sì gbà yín, ẹ jẹ ohunkóhun tí a bá gbé ka iwájú yín.\wj*
\v 9 \wj Ẹ sì mú àwọn aláìsàn tí ń bẹ nínú rẹ̀ láradá, kí ẹ sì wí fún wọn pé, Ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀ sí yín!\wj*
\v 10 \wj Ṣùgbọ́n ní ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, tí wọn kò bá sì gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá sì jáde ní ìgboro ìlú náà, kí ẹ̀yin sì wí pé,\wj*
\v 11 \x - \xo 10.11: \xt Ap 13.51.\x*\wj Eruku ìlú yín tí ó kù sí wa lẹ́sẹ̀, a gbọ̀n ọ́n sílẹ̀ fún yín! Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀.\wj*
\v 12 \x - \xo 10.12: \xt Mt 11.24; Gẹ 19.24-28; Jd 7.\x*\wj Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Sodomu ní ọjọ́ náà, ju fún ìlú náà lọ.\wj*
\p
\v 13 \x - \xo 10.13-15: \xt Mt 11.21-23; Lk 6.24-26.\x*\wj “Ègbé ni fún ìwọ, Korasini! Ègbé ni fún ìwọ Betisaida! Nítorí ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ agbára tí a ṣe nínú yín, ní Tire àti Sidoni, wọn ìbá ti ronúpìwàdà lọ́jọ́ pípẹ́ sẹ́yìn, wọn ìbá sì jókòó nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti nínú eérú.\wj*
\v 14 \wj Ṣùgbọ́n yóò sàn fún Tire àti Sidoni nígbà ìdájọ́ jù fún yín lọ.\wj*
\v 15 \wj Àti ìwọ, Kapernaumu, a ó ha gbé ọ ga dé òkè ọ̀run? A ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ dé isà òkú.\wj*
\p
\v 16 \x - \xo 10.16: \xt Mt 10.40; 18.5; Mk 9.37; Lk 9.48; Jh 13.20; 12.48.\x*\wj “Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ yín, ó kọ̀ mi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ mi, ó kọ ẹni tí ó rán mi.”\wj*
\p
\v 17 Àwọn àádọ́rin náà sì fi ayọ̀ padà, wí pé, “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù tilẹ̀ foríbalẹ̀ fún wa ní orúkọ rẹ.”
\p
\v 18 \x - \xo 10.18: \xt If 12.9; Jh 12.31.\x*Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Èmí rí Satani ṣubú bí mọ̀nàmọ́ná láti ọ̀run wá.\wj*
\v 19 \wj Kíyèsi i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèe mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá, kò sì ṣí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára.\wj*
\v 20 \x - \xo 10.20: \xt Ek 32.32; Sm 69.28; Da 12.1; Fp 4.3; Hb 12.23; If 3.5; 13.8; 21.27.\x*\wj Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe yọ̀ nítorí èyí pé, àwọn ẹ̀mí ń foríbalẹ̀ fún yín; ṣùgbọ́n ẹ kúkú yọ̀, pé; a kọ̀wé orúkọ yín ní ọ̀run!”\wj*
\p
\v 21 \x - \xo 10.21-22: \xt Mt 11.25-27.\x*\x - \xo 10.21: \xt 1Kọ 1.26-29.\x*Ní wákàtí kan náà Jesu yọ̀ nínú Ẹ̀mí mímọ́ ó sì wí pé, \wj “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ pa nǹkan wọ̀nyí mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, ìwọ sì fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ ọwọ́. Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, bẹ́ẹ̀ ni ó sá à yẹ ní ojú rẹ.\wj*
\p
\v 22 \x - \xo 10.22: \xt Mt 28.18; Jh 3.35; 13.3; 10.15; 17.25.\x*\wj “Ohun gbogbo ni a ti fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Baba mi; kò sì ṣí ẹni tí ó mọ ẹni tí ọmọ jẹ́, bí kò ṣe Baba, àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wu ọmọ láti fi í hàn fún.”\wj*
\p
\v 23 \x - \xo 10.23-24: \xt Mt 13.16-17; Jh 8.56; Hb 11.13; 1Pt 1.10-12.\x*Ó sì yípadà sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní apá kan. Ó ní, \wj “Ìbùkún ni fún ojú tí ń rí ohun tí ẹ̀yin ń rí.\wj*
\v 24 \wj Nítorí mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn ọba ni ó ń fẹ́ láti rí ohun tí ẹ̀yin ń rí, wọn kò sì rí wọn, àti láti gbọ́ ohun tí ẹ̀yin ń gbọ́, wọn kò sì gbọ́ wọn.”\wj*
\s1 Òwe aláàánú ará Samaria
\p
\v 25 \x - \xo 10.25-28: \xt Mt 22.34-39; Mk 12.28-31.\x*\x - \xo 10.25: \xt Mk 10.17; Mt 19.16; Lk 18.18.\x*Sì kíyèsi i amòfin kan dìde, ó ń dán an wò, ó ní, “Olùkọ́, kín ni èmi ó ṣe kí èmi lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”
\p
\v 26 Ó sì bi í pé, \wj “Kí ni a kọ sínú ìwé òfin? Báwo ni ìwọ sì ti kà á?”\wj*
\p
\v 27 \x - \xo 10.27: \xt De 6.5; Le 19.18; Ro 13.9; Ga 5.14; Jk 2.8.\x*Ó sì dáhùn wí pé, “Kí ìwọ fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ; àti, Ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.’ ”
\p
\v 28 \x - \xo 10.28: \xt Lk 20.39; Le 18.25.\x*Ó sì wí fún un pé, \wj “Ìwọ́ dáhùn rere. Ṣe èyí, ìwọ ó sì yè.”\wj*
\p
\v 29 Ṣùgbọ́n ó ń fẹ́ láti da ara rẹ̀ láre, ó wí fún Jesu wí pé, “Ta ha sì ni ẹnìkejì mi?”
\p
\v 30 Jesu sì dáhùn ó wí pé, \wj “Ọkùnrin kan ń ti Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jeriko, ó sì bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà; wọ́n gbà á ní aṣọ, wọ́n sá a lọ́gbẹ́, wọ́n sì fi sílẹ̀ lọ ní àìpatán.\wj*
\v 31 \wj Ní kòńgẹ́ àkókò yìí ni àlùfáà kan sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ lọ́nà náà. Nígbà tí ó sì rí i ó kọjá lọ níhà kejì.\wj*
\v 32 \wj Bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọmọ Lefi kan pẹ̀lú, nígbà tí ó dé ibẹ̀, tí ó sì rí i, ó kọjá lọ níhà kejì.\wj*
\v 33 \x - \xo 10.33: \xt Lk 9.51-56; 17.11-19; Jh 4.4-42.\x*\wj Ṣùgbọ́n ará Samaria kan, bí ó ti ń re àjò, ó dé ibi tí ó gbé wà; nígbà tí ó sì rí i, àánú ṣe é.\wj*
\v 34 \wj Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì di ọgbẹ́ rẹ̀, ó da òróró àti ọtí wáìnì sí i, ó sì gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ti òun tìkára rẹ̀, ó sì mú un wá sí ilé èrò, a sì ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀.\wj*
\v 35 \wj Nígbà tí ó sì lọ ní ọjọ́ kejì, ó fi owó idẹ méjì fún olórí ilé èrò ó sì wí fún un pé, Máa tọ́jú rẹ̀; ohunkóhun tí ìwọ bá sì ná kún un, nígbà tí mo bá padà dé, èmi ó san án fún ọ.\wj*
\p
\v 36 “Nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí, ta ni ìwọ rò pé ó jẹ́ ẹnìkejì ẹni tí ó bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà?”
\p
\v 37 Ó sì dáhùn wí pé, “Ẹni tí ó ṣàánú fún un ni.”
\p Jesu sì wí fún un pé, \wj “Lọ, kí o ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́!”\wj*
\s1 Ní ilé Marta àti Maria
\p
\v 38 \x - \xo 10.38-42: \xt Jh 12.1-3; 11.1-45.\x*Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, o wọ ìletò kan, obìnrin kan tí a ń pè ní Marta sì gbà á sí ilé rẹ̀.
\v 39 Ó sì ní arábìnrin kan tí a ń pè ní Maria tí ó sì jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Olúwa, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.
\v 40 Ṣùgbọ́n Marta ń ṣe ìyọnu ohun púpọ̀, ó sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Olúwa, ìwọ kò sì bìkítà sí ti arábìnrin mi pé ó fi mí sílẹ̀ láti máa nìkan ṣe ìránṣẹ́? Wí fún un kí ó ràn mí lọ́wọ́.”
\p
\v 41 \x - \xo 10.41: \xt Lk 7.13.\x*Ṣùgbọ́n Olúwa sì dáhùn, ó sì wí fún un pé, \wj “Marta, Marta, ìwọ ń ṣe àníyàn àti làálàá nítorí ohun púpọ̀.\wj*
\v 42 \wj Ṣùgbọ́n ohun kan ni a kò lè ṣe aláìní, Maria sì ti yan ipa rere náà tí a kò lè gbà lọ́wọ́ rẹ̀.”\wj*
\c 11
\s1 Jesu ń kọ́ ẹ̀kọ́ nípa àdúrà
\p
\v 1 \x - \xo 11.1: \xt Mk 1.35; Lk 3.21; 5.16; 6.12; 9.18,28; 5.33; 7.18.\x*Bí ó ti ń gbàdúrà ní ibi kan, bí ó ti dákẹ́, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olúwa, kọ́ wa bí a ti ń gbàdúrà, bí Johanu ti kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.”
\p
\v 2 \x - \xo 11.2-4: \xt Mt 6.9-13.\x*Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ máa wí pé:\wj*
\q1 \wj “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run,\wj*
\q1 \wj kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ yín.\wj*
\q1 \wj Kí ìjọba yín dé, ìfẹ́ tiyín ni kí a ṣe,\wj*
\q1 \wj bí i ti ọrun, bẹ́ẹ̀ ni ní ayé.\wj*
\q1
\v 3 \wj Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lójoojúmọ́.\wj*
\q1
\v 4 \x - \xo 11.4: \xt Mk 11.25; Mt 18.35.\x*\wj Kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá;\wj*
\q2 \wj nítorí àwa tìkára wa pẹ̀lú a máa dáríjì olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbèsè,\wj*
\q1 \wj Má sì fà wá sínú ìdánwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ ẹni búburú ni.’ ”\wj*
\p
\v 5 \x - \xo 11.5-8: \xt Lk 18.1-8.\x*Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Ta ni nínú yín tí yóò ní ọ̀rẹ́ kan, tí yóò sì tọ̀ ọ́ lọ láàrín ọ̀gànjọ́, tí yóò sì wí fún un pé, Ọ̀rẹ́, yá mi ní ìṣù àkàrà mẹ́ta.\wj*
\v 6 \wj Nítorí ọ̀rẹ́ mi kan ti àjò dé sọ́dọ̀ mi, èmi kò sì ní nǹkan tí èmi ó gbé kalẹ̀ níwájú rẹ̀.\wj*
\v 7 \wj Tí òun ó sì gbé inú ilé dáhùn wí fún un pé, Má yọ mí lẹ́nu, a ti sé ìlẹ̀kùn, àwọn ọmọ mi si ń bẹ lórí ẹní pẹ̀lú mi: èmi kò lè dìde fi fún ọ!\wj*
\v 8 \wj Mo wí fún yín, bí òun kò tilẹ̀ ti fẹ́ dìde kí ó fi fún un nítorí tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n nítorí àwíìyánnu rẹ̀, yóò dìde, yóò sì fún un tó bí ó ti ń fẹ́.\wj*
\p
\v 9 \x - \xo 11.9-13: \xt Mt 7.7-11.\x*\x - \xo 11.9: \xt Mt 18.19; 21.22; Mk 11.24; Jk 1.5-8; 1Jh 5.14-15; Jh 15.7; 16.23-24.\x*\wj “Èmí sì wí fún yín, ẹ béèrè, a ó sì fi fún un yín; ẹ wá kiri, ẹ̀yin ó sì rí; ẹ kànkùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín.\wj*
\v 10 \wj Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá béèrè, ó rí gbà; ẹni tí ó sì ń wá kiri, ó rí; àti ẹni tí ó kànkùn ni a ó ṣí i sílẹ̀ fún.\wj*
\p
\v 11 \wj “Ta ni baba nínú yín tí ọmọ rẹ̀ yóò béèrè àkàrà lọ́dọ̀ rẹ̀, tí yóò fún un ní òkúta? Tàbí bí ó béèrè ẹja, tí yóò fún un ní ejò?\wj*
\v 12 \wj Tàbí bí ó sì béèrè ẹ̀yin, tí yóò fún un ní àkéekèe?\wj*
\v 13 \wj Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí ó jẹ́ ènìyàn búburú bá mọ bí a ti í fi ẹ̀bùn dáradára fún àwọn ọmọ yín, mélòó mélòó ha ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ fún àwọn tí ó béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀!”\wj*
\s1 Jesu àti Beelsebulu
\p
\v 14 \x - \xo 11.14-23: \xt Mt 12.22-30; 10.25; Mk 3.23-27.\x*\x - \xo 11.14-15: \xt Mt 9.32-34.\x*Ó sì ń lé ẹ̀mí èṣù kan jáde, tí ó sì yadi. Nígbà tí ẹ̀mí èṣù náà jáde, odi sọ̀rọ̀; ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn.
\v 15 Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn wí pé, “Nípa Beelsebulu olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”
\v 16 \x - \xo 11.16: \xt Mt 12.38; 16.1; Mk 8.11; Jh 2.18; 6.30.\x*Àwọn ẹlòmíràn sì ń dán an wò, wọ́n ń fẹ́ àmì lọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọ̀run wá.
\p
\v 17 Ṣùgbọ́n òun mọ èrò inú wọn, ó wí fún wọn pé, \wj “Gbogbo ìjọba tí ó ya ara rẹ̀ ní ipá, ni a ń sọ di ahoro; ilé tí ó sì ya ara rẹ̀ nípá yóò wó.\wj*
\v 18 \wj Bí Satani ba yapa sí ara rẹ̀, ìjọba rẹ̀ yóò ha ṣe dúró? Nítorí ẹ̀yin wí pé, nípa Beelsebulu ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.\wj*
\v 19 \wj Bí ó ba ṣe pé nípa Beelsebulu ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, nípa ta ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde, nítorí náà àwọn ni yóò ṣe onídàájọ́ yín.\wj*
\v 20 \wj Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe pé nípa ìka ọwọ́ Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ǹjẹ́ ìjọba Ọlọ́run dé bá yín tán.\wj*
\p
\v 21 \wj “Nígbà tí alágbára ọkùnrin tí ó ni ìhámọ́ra bá ń ṣọ́ ààfin rẹ̀, ẹrù rẹ̀ yóò wà ní àlàáfíà.\wj*
\v 22 \wj Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹni tí ó ní agbára jù ú bá kọlù ú, tí ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ a gba gbogbo ìhámọ́ra rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé lọ́wọ́ rẹ̀, a sì pín ìkógun rẹ̀.\wj*
\p
\v 23 \x - \xo 11.23: \xt Lk 9.50.\x*\wj “Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, ó lòdì sí mi, ẹni tí kò bá sì bá mi kójọpọ̀, ó fọ́nká.\wj*
\p
\v 24 \x - \xo 11.24-26: \xt Mt 12.43-45.\x*\wj “Nígbà tí ẹ̀mí àìmọ́ bá jáde kúrò lára ènìyàn, a máa rìn kiri ní ibi gbígbẹ, a máa wá ibi ìsinmi; nígbà tí kò bá sì rí, a wí pé, Èmi yóò padà lọ sí ilé mi ní ibi tí mo gbé ti jáde wá.\wj*
\v 25 \wj Nígbà tí ó bá sì dé, tí ó sì rí tí a gbá a, tí a sì ṣe é ní ọ̀ṣọ́.\wj*
\v 26 \wj Nígbà náà ni yóò lọ, yóò sì mú ẹ̀mí méje mìíràn tí ó burú ju òun tìkára rẹ̀ lọ wá, wọn yóò wọlé, wọn yóò sì máa gbé níbẹ̀, ìgbẹ̀yìn ọkùnrin náà yóò sì burú ju ìṣáájú rẹ̀ lọ.”\wj*
\p
\v 27 \x - \xo 11.27: \xt Lk 1.42; 23.29.\x*Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, obìnrin kan gbóhùn rẹ̀ sókè nínú ìjọ, ó sì wí fún un pé, “Ìbùkún ni fún inú tí ó bí ọ, àti ọmú tí ìwọ mu!”
\p
\v 28 Ṣùgbọ́n òun wí pé, nítòótọ́, kí ó kúkú wí pé, \wj “Ìbùkún ni fún àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì pa á mọ́!”\wj*
\s1 Àmì ti Jona
\p
\v 29 \x - \xo 11.29-32: \xt Mt 12.39-42.\x*\x - \xo 11.29: \xt Mt 16.4; Mk 8.12; Lk 11.16; Jn 3.4-5.\x*Nígbà tí ìjọ ènìyàn sì ṣùjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, \wj “Ìran búburú ni èyí, wọ́n ń wá àmì; a kì yóò sì fi àmì kan fún un bí kò ṣe àmì Jona wòlíì!\wj*
\v 30 \wj Nítorí bí Jona ti jẹ́ àmì fún àwọn ará Ninefe, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ Ènìyàn yóò ṣe jẹ́ àmì fún ìran yìí.\wj*
\v 31 \x - \xo 11.31: \xt 1Ọb 10.1-10; 2Ki 9.1-12.\x*\wj Ọbabìnrin gúúsù yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ìran yìí, yóò sì dá wọn lẹ́bi: nítorí tí ó ti ìhà ìpẹ̀kun ayé wá láti gbọ́ ọgbọ́n Solomoni: sì kíyèsi i, ẹni tí ó pọ̀jù Solomoni lọ ń bẹ níhìn-ín yìí.\wj*
\v 32 \x - \xo 11.32: \xt Mt 12.6.\x*\wj Àwọn ará Ninefe yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú ìran yìí, wọn ó sì dá a lẹ́bi: nítorí tí wọn ronúpìwàdà nípa ìwàásù Jona; sì kíyèsi i, ẹni tí ó pọ̀jù Jona lọ ń bẹ níhìn-ín yìí.\wj*
\s1 Òwe nípa fìtílà tí a tàn
\p
\v 33 \x - \xo 11.33: \xt Mt 5.15; Mk 4.21; Lk 8.16.\x*\wj “Kò sí ẹnìkan, nígbà tí ó bá tan fìtílà tan, tí gbé e sí ìkọ̀kọ̀, tàbí sábẹ́ òsùwọ̀n, bí kò ṣe sórí ọ̀pá fìtílà, kí àwọn tí ń wọlé ba à lè máa rí ìmọ́lẹ̀.\wj*
\v 34 \x - \xo 11.34-35: \xt Mt 6.22-23.\x*\wj Ojú ni fìtílà ara: bí ojú rẹ bá mọ́lẹ̀ kedere, gbogbo ara rẹ a mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n bí ojú rẹ bá ṣókùnkùn, ara rẹ pẹ̀lú a kún fún òkùnkùn.\wj*
\v 35 \wj Nítorí náà kíyèsi i, kí ìmọ́lẹ̀ tí ń bẹ nínú rẹ má ṣe di òkùnkùn.\wj*
\v 36 \wj Ǹjẹ́ bí gbogbo ara rẹ bá kún fún ìmọ́lẹ̀, tí kò ní apá kan tí ó ṣókùnkùn, gbogbo rẹ̀ ni yóò ní ìmọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí fìtílà bá fi ìtànṣán rẹ̀ fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.”\wj*
\s1 Ègún mẹ́fà
\p
\v 37 \x - \xo 11.37: \xt Lk 7.36; 14.1.\x*Bí ó sì ti ń wí, Farisi kan bẹ̀ ẹ́ kí ó bá òun jẹun: ó sì wọlé, ó jókòó láti jẹun.
\v 38 \x - \xo 11.38: \xt Mk 7.1-5.\x*Nígbà tí Farisi náà sì rí i, ẹnu yà á nítorí tí kò kọ́kọ́ wẹ ọwọ́ kí ó tó jẹun.
\p
\v 39 \x - \xo 11.39-41: \xt Mt 23.25-26.\x*\x - \xo 11.39: \xt Lk 7.13.\x*Olúwa sì wí fún un pé, \wj “Ẹ̀yin Farisi a máa ń fọ òde ago àti àwopọ̀kọ́: ṣùgbọ́n, inú yín kún fún ìwà búburú àti ìrẹ́jẹ.\wj*
\v 40 \wj Ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹni tí ó ṣe èyí tí ń bẹ lóde, òun kò ha ṣe èyí tí ń bẹ nínú pẹ̀lú?\wj*
\v 41 \x - \xo 11.41: \xt Tt 1.15; Mk 7.19.\x*\wj Nípa ohun ti inú yin, ki ẹ̀yin kúkú máa ṣe ìtọrẹ àánú nínú ohun tí ẹ̀yin ní, sì kíyèsi i, ohun gbogbo ni ó di mímọ́ fún yín.\wj*
\p
\v 42 \x - \xo 11.42: \xt Mt 23.23-24; Le 27.30; Mt 6.8.\x*\wj “Ṣùgbọ́n ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisi, nítorí tí ẹ̀yin a máa san ìdámẹ́wàá minti àti irúgbìn, àti gbogbo ewébẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ ìdájọ́ àti ìfẹ́ Ọlọ́run: wọ̀nyí jẹ́ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe, láìsí fi àwọn ìyókù sílẹ̀ láìṣe.\wj*
\p
\v 43 \x - \xo 11.43: \xt Mt 23.6-7; Mk 12.38-39; Lk 20.46.\x*\wj “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisi, àgàbàgebè! Nítorí tí ẹ̀yin fẹ́ ipò ọlá nínú Sinagọgu, àti ìkíni ní ọjà.\wj*
\p
\v 44 \x - \xo 11.44: \xt Mt 23.27.\x*\wj “Ègbé ni fún un yín,\wj* \f + \fr 11.44 \ft ẹ̀yin akọ̀wé àti ẹ̀yin Farisi àgàbàgebè \f*\wj nítorí ẹ̀yin dàbí ibojì tí kò farahàn, tí àwọn ènìyàn sì ń rìn lórí rẹ̀ láìmọ̀.”\wj*
\p
\v 45 Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn amòfin dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́, nínú èyí tí ìwọ ń wí yìí ìwọ ń gan àwa pẹ̀lú.”
\p
\v 46 \x - \xo 11.46: \xt Mt 23.4.\x*Ó sì wí pé, \wj “Ègbé ni fún ẹ̀yin amòfin pẹ̀lú, nítorí tí ẹ̀yin di ẹrù tí ó wúwo láti rù lé ènìyàn lórí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin tìkára yín kò jẹ́ fi ìka yín kan ẹrù náà.\wj*
\p
\v 47 \x - \xo 11.47-48: \xt Mt 23.29-32; Ap 7.51-53.\x*\wj “Ègbé ni fún yín, nítorí tí ẹ̀yin kọ́ ibojì àwọn wòlíì, tí àwọn baba yín pa.\wj*
\v 48 \wj Ǹjẹ́ ẹ̀yin jẹ́ ẹlẹ́rìí, ẹ sì ní inú dídùn sí iṣẹ́ àwọn baba yín, nítorí tí wọn pa wọ́n, ẹ̀yin sì kọ́ ibojì wọn.\wj*
\v 49 \x - \xo 11.49-51: \xt Mt 23.34-36.\x*\x - \xo 11.49: \xt 1Kọ 1.24; 1Kọ 2.3.\x*\wj Nítorí èyí ni ọgbọ́n Ọlọ́run sì ṣe wí pé, Èmi ni ó rán àwọn wòlíì àti àwọn aposteli sí wọn, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí wọn.\wj*
\v 50 \wj Kí a lè béèrè ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì gbogbo, tí a ti ta sílẹ̀ láti ìgbà ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, lọ́wọ́ ìran yìí;\wj*
\v 51 \x - \xo 11.51: \xt Gẹ 4.8; 2Ki 24.20-21; Sk 1.1.\x*\wj láti ẹ̀jẹ̀ Abeli wá, títí ó sì fi dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah, tí ó ṣègbé láàrín pẹpẹ àti tẹmpili. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín ìran yìí ni yóò ru gbogbo ẹ̀bi àwọn nǹkan wọ̀nyí.\wj*
\p
\v 52 \x - \xo 11.52: \xt Mt 23.13.\x*\wj “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin amòfin, nítorí tí ẹ̀yin ti mú kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ kúrò; ẹ̀yin tìkára yín kò wọlé, àwọn tí sì ń wọlé, ni ẹ̀yin ń dí lọ́wọ́.”\wj*
\p
\v 53 Bí ó ti ń lọ kúrò níbẹ̀, àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ sí bi í lọ́rọ̀ gidigidi, wọ́n sì ń yọ ọ́ lẹ́nu láti wí nǹkan púpọ̀.
\v 54 Wọ́n ń ṣọ́ ọ, wọ́n ń wá ọ̀nà láti rí nǹkan gbámú lẹ́nu kí wọn bá à lè fi ẹ̀sùn kàn án.
\c 12
\s1 Àwọn ìkìlọ̀ àti ọ̀rọ̀ ìyànjú
\p
\v 1 \x - \xo 12.1: \xt Mt 16.6; Mk 8.15.\x*Ó sì ṣe, nígbà tí àìníye ìjọ ènìyàn péjọpọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sísọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, \wj “Ẹ máa ṣọ́ra yín nítorí ìwúkàrà àwọn Farisi tí í ṣe àgàbàgebè.\wj*
\v 2 \x - \xo 12.2-3: \xt Mt 10.26-27; Mk 4.22; Lk 8.17; Ef 5.13.\x*\wj Kò sí ohun tí a bò, tí a kì yóò sì fihàn; tàbí tí ó pamọ́, tí a kì yóò mọ̀.\wj*
\v 3 \wj Nítorí náà ohunkóhun tí ẹ̀yin sọ ní òkùnkùn, ní gbangba ni a ó ti gbọ́ ọ; àti ohun tí ẹ̀yin bá sọ sí etí ní iyàrá, lórí òrùlé ni a ó ti kéde rẹ̀.\wj*
\p
\v 4 \x - \xo 12.4: \xt Jh 15.14-15.\x*\x - \xo 12.4-9: \xt Mt 10.28-33.\x*\wj “Èmi sì wí fún yín ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó ń pa ara ènìyàn kú, lẹ́yìn èyí, wọn kò sì ní èyí tí wọ́n lè ṣe mọ́.\wj*
\v 5 \x - \xo 12.5: \xt Hb 10.31.\x*\wj Ṣùgbọ́n èmi ó sì sọ ẹni tí ẹ̀yin ó bẹ̀rù fún yín: Ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó lágbára lẹ́yìn tí ó bá pànìyàn tan, láti wọ́ ni lọ sí ọ̀run àpáàdì. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín òun ni kí ẹ bẹ̀rù.\wj*
\v 6 \wj Ológoṣẹ́ márùn-ún sá à ni a ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì? A kò sì gbàgbé ọ̀kan nínú wọn níwájú Ọlọ́run?\wj*
\v 7 \x - \xo 12.7: \xt Lk 21.18; Ap 27.34; Mt 12.12.\x*\wj Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín ni a kà pé ṣánṣán. Nítorí náà kí ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ̀yin ní iye lórí ju ológoṣẹ́ púpọ̀ lọ.\wj*
\p
\v 8 \wj “Mo sì wí fún yín pẹ̀lú, Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú àwọn ènìyàn. Ọmọ Ènìyàn yóò sì jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú àwọn angẹli Ọlọ́run.\wj*
\v 9 \x - \xo 12.9: \xt Mk 8.38; Lk 9.26; 2Tm 2.12.\x*\wj Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sẹ́ mi níwájú ènìyàn, a ó sẹ́ ẹ níwájú àwọn angẹli Ọlọ́run.\wj*
\v 10 \x - \xo 12.10: \xt Mt 12.31-32; Mk 3.28-29.\x*\wj Àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí Ọmọ Ènìyàn, a ó dárí rẹ̀ jì í; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́, a kì yóò dárí rẹ̀ jì í.\wj*
\p
\v 11 \x - \xo 12.11-12: \xt Mt 10.19-20; Mk 13.11; Lk 21.14-15.\x*\wj “Nígbà tí wọ́n bá sì mú yin wá sí Sinagọgu, àti síwájú àwọn olórí, àti àwọn aláṣẹ, ẹ má ṣe ṣàníyàn pé, báwo tàbí ohun kín ni ẹ̀yin yóò fèsì rẹ̀ tàbí kín ni ẹ̀yin ó wí.\wj*
\v 12 \wj Nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ yóò kọ́ yín ní wákàtí kan náà ní ohun tí ó yẹ kí ẹ sọ.”\wj*
\s1 Ìtàn òmùgọ̀ ọlọ́rọ̀
\p
\v 13 Ọ̀kan nínú àwùjọ wí fún un pé, “Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi kí ó pín mi ní ogún.”
\p
\v 14 Ó sì wí fún un pé, \wj “Ọkùnrin yìí, ta ni ó fi mí jẹ onídàájọ́ tàbí olùpíngún fún yín?”\wj*
\v 15 \x - \xo 12.15: \xt 1Tm 6.6-10.\x*Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Kíyèsára kí o sì máa ṣọ́ra nítorí ojúkòkòrò: nítorí ìgbésí ayé ènìyàn kò dúró lé ọ̀pọ̀ ohun tí ó ní.”\wj*
\p
\v 16 Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, \wj “Ilẹ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso.\wj*
\v 17 \wj Ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, Èmi ó ti ṣe, nítorí tí èmi kò ní ibi tí èmi ó gbé kó èso mi jọ sí.\wj*
\p
\v 18 \wj “Ó sì wí pé, Èyí ni èmi ó ṣe: èmi ó wó àká mi palẹ̀, èmi ó sì kọ́ èyí tí ó tóbi; níbẹ̀ ni èmi ó gbé to gbogbo èso àti ọrọ̀ mi jọ sí.\wj*
\v 19 \wj Èmi ó sì wí fún ọkàn mi pé, ọkàn, ìwọ ní ọrọ̀ púpọ̀ tí a tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; sinmi, máa jẹ, máa mu, máa yọ̀.\wj*
\p
\v 20 \x - \xo 12.20: \xt Jr 17.11; Jb 27.8; Sm 39.6; Lk 12.33-34.\x*\wj “Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún un pé, Ìwọ aṣiwèrè, lóru yìí ni a ó béèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ; ǹjẹ́ ti ta ni nǹkan wọ̀nyí yóò ha ṣe, tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀?\wj*
\p
\v 21 \wj “Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó to ìṣúra jọ fún ara rẹ̀, tí kò sì ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”\wj*
\s1 Má ṣe ṣe àníyàn
\p
\v 22 \x - \xo 12.22-31: \xt Mt 6.25-33.\x* Jesu sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, \wj “Nítorí náà mo wí fún yín pé, ẹ má ṣe ṣe àníyàn nítorí ẹ̀mí yín pé, kín ni ẹ̀yin yóò jẹ tàbí nípa ara yin pe kín ni ẹyin o fi bora.\wj*
\v 23 \wj Ẹ̀mí sá à ju oúnjẹ lọ, ara sì ju aṣọ lọ.\wj*
\v 24 \x - \xo 12.24: \xt Lk 12.6-7.\x*\wj Ẹ kíyèsi àwọn ẹyẹ ìwò: wọn kì í fúnrúgbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè: wọn kò ní àká, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní abà, Ọlọ́run sá à ń bọ́ wọn: mélòó mélòó ni tí ẹ̀yin fi sàn ju ẹyẹ lọ!\wj*
\v 25 \wj Ta ni nínú yín nípa àníyàn ṣíṣe tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ọjọ́ ayé rẹ̀?\wj*
\v 26 \wj Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò ti lè ṣe èyí tí ó kéré bí eléyìí, èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣàníyàn nítorí ìyókù?\wj*
\p
\v 27 \x - \xo 12.27: \xt 1Ọb 10.1-10.\x*\wj “Ẹ kíyèsi àwọn lílì bí wọ́n ti ń dàgbà; wọn kì í ṣiṣẹ́, wọn kì í rànwú; ṣùgbọ́n kí èmi wí fún yín, a kò ṣe Solomoni pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ ní gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí.\wj*
\v 28 \wj Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko igbó ní aṣọ tó bẹ́ẹ̀ èyí tí ó wà lónìí, tí a sì gbá a sínú iná lọ́la: mélòó mélòó ni yóò wọ̀ yín láṣọ, ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré.\wj*
\v 29 \wj Kí ẹ má sì ṣe lé ohun tí ẹ ó jẹ, tàbí ohun tí ẹ ó mu, kí ẹ má sì ṣe ṣe àníyàn nínú ọkàn.\wj*
\v 30 \x - \xo 12.30: \xt Mt 6.8.\x*\wj Nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè ayé ń wá kiri. Baba yín sì mọ̀ pé, ẹ̀yin ń fẹ́ nǹkan wọ̀nyí.\wj*
\v 31 \wj Ṣùgbọ́n ẹ máa wá ìjọba Ọlọ́run, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.\wj*
\p
\v 32 \x - \xo 12.32: \xt Jh 21.15-17.\x*\wj “Má bẹ̀rù, agbo kékeré, nítorí dídùn inú Baba yín ni láti fi ìjọba fún yín.\wj*
\v 33 \x - \xo 12.33-34: \xt Mt 6.19-21; Lk 18.22.\x*\wj Ẹ ta ohun tí ẹ̀yin ní, kí ẹ sì tọrẹ àánú kí ẹ sì pèsè àpò fún ara yín, tí kì í gbó, ìṣúra ní ọ̀run tí kì í tán, ní ibi tí olè kò lè súnmọ́, àti ibi tí kòkòrò kì í bà á jẹ́.\wj*
\v 34 \wj Nítorí ní ibi tí ìṣúra yín gbé wà, níbẹ̀ ni ọkàn yín yóò gbé wà pẹ̀lú.\wj*
\s1 Ẹ máa ṣọ́nà
\p
\v 35 \x - \xo 12.35: \xt Ef 6.14; Mt 25.1-13; Mk 13.33-37.\x*\wj “Ẹ di àmùrè yín, kí fìtílà yín sì máa jó.\wj*
\v 36 \wj Kí ẹ̀yin tìkára yín dàbí ẹni tí ń retí olúwa wọn, nígbà tí òun ó padà ti ibi ìgbéyàwó dé, pé nígbà tí ó bá dé, tí ó sì kànkùn, kí wọn lè ṣí i sílẹ̀ fún un lọ́gán.\wj*
\v 37 \x - \xo 12.37: \xt Jh 13.3-5; Mt 24.42; Lk 21.36.\x*\wj Ìbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà nígbà tí olúwa náà bá dé tí yóò bá wọn tí wọn ń ṣọ́nà; lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò di ara rẹ̀ ní àmùrè yóò sì mú wọn jókòó láti jẹun, yóò sì jáde wá láti ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.\wj*
\v 38 \wj Bí olúwa wọn bá sì dé nígbà ìṣọ́ kejì, tàbí tí ó sì dé nígbà ìṣọ́ kẹta, tí ó sì bá wọn bẹ́ẹ̀, ìbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà.\wj*
\v 39 \x - \xo 12.39-40: \xt Mt 24.43-44; 1Tẹ 5.2; If 3.3; 16.15; 2Pt 3.10.\x*\wj Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, baálé ilé ìbá mọ wákàtí tí olè yóò wá, òun ìbá máa ṣọ́nà, kì bá tí jẹ́ kí a já wọ inú ilé òun.\wj*
\v 40 \wj Nítorí náà, kí ẹ̀yin múra pẹ̀lú, nítorí Ọmọ Ènìyàn ń bọ̀ ní wákàtí tí ẹ̀yin kò nírètí.”\wj*
\p
\v 41 Peteru sì wí pé, “Olúwa, ìwọ pa òwe yìí fún wa, tàbí fún gbogbo ènìyàn?”
\p
\v 42 \x - \xo 12.42-46: \xt Mt 24.45-51.\x*\x - \xo 12.42: \xt Lk 7.13.\x*Olúwa sì dáhùn wí pé, \wj “Ta ni olóòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n ìríjú náà, tí olúwa rẹ̀ fi jẹ olórí agbo ilé rẹ̀, láti máa fi ìwọ̀n oúnjẹ wọ́n fún wọn ní àkókò?\wj*
\v 43 \wj Ìbùkún ni fún ọmọ ọ̀dọ̀ náà, nígbà tí olúwa rẹ̀ bá dé, tí yóò bá a kí ó máa ṣe bẹ́ẹ̀.\wj*
\v 44 \wj Lóòótọ́ ni mo wí fún yín yóò fi jẹ olórí ohun gbogbo tí ó ní.\wj*
\v 45 \wj Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà bá wí ní ọkàn rẹ̀, pé, Olúwa mi fi ìgbà bíbọ̀ rẹ̀ falẹ̀! Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lu àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ àti sí mu àmupara:\wj*
\v 46 \wj Olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà yóò dé ní ọjọ́ tí kò retí rẹ̀, àti ní wákàtí tí kò dábàá, yóò sì jẹ ẹ́ ní yà gidigidi, yóò sì yan ipò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.\wj*
\p
\v 47 \x - \xo 12.47-48: \xt De 25.2-3; Nu 15.29-30; Lk 8.18; 19.26.\x*\wj “Àti ọmọ ọ̀dọ̀ náà, tí ó mọ ìfẹ́ olúwa rẹ̀, tí kò sì múra sílẹ̀, tí kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, òun ni a ó nà púpọ̀.\wj*
\v 48 \wj Ṣùgbọ́n èyí tí kò mọ̀, tí ó ṣe ohun tí ó yẹ sí lílù, òun ni a ó lù níwọ̀n. Nítorí ẹnikẹ́ni tí a fún ní púpọ̀, lọ́dọ̀ rẹ̀ ni a ó gbé béèrè púpọ̀: lọ́dọ̀ ẹni tí a bá gbé fi púpọ̀ sí, lọ́dọ̀ rẹ ni a ó gbé béèrè sí i.\wj*
\s1 Àlàáfíà kọ́ ṣùgbọ́n ìyapa
\p
\v 49 \x - \xo 12.49: \xt Lk 22.15.\x*\wj “Iná ni èmi wá láti sọ sí ayé; kín ni èmi sì ń fẹ́ bí kò ṣe kí iná náà ti jo!\wj*
\v 50 \x - \xo 12.50: \xt Mk 10.38-39; Jh 12.27.\x*\wj Ṣùgbọ́n èmi ní bamitiisi kan tí a ó fi bamitiisi mi; ara ti ń ni mí tó títí yóò fi parí!\wj*
\v 51 \x - \xo 12.51-53: \xt Mt 10.34-36; Lk 21.16; Mt 7.6.\x*\wj Ẹ̀yin ṣe bí àlàáfíà ni èmi fi sí ayé? Mo wí fún yín, bẹ́ẹ̀ kọ́; ṣùgbọ́n bí kò ṣe ìyapa.\wj*
\v 52 \wj Nítorí láti ìsinsin yìí lọ, ènìyàn márùn-ún yóò wà ní ilé kan náà tí a ó yà ní ipa, mẹ́ta sí méjì, àti méjì sí mẹ́ta.\wj*
\v 53 \wj A ó ya baba nípa sí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ ọkùnrin sí baba; ìyá sí ọmọbìnrin, àti ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀, ìyá ọkọ sí ìyàwó ọmọ, àti ìyàwó ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀.”\wj*
\s1 Ògbufọ̀ àwọn àkókò
\p
\v 54 \x - \xo 12.54-56: \xt Mt 16.2-3.\x*Ó sì wí fún ìjọ ènìyàn pẹ̀lú pé, \wj “Nígbà tí ẹ̀yin bá rí àwọsánmọ̀ tí ó ṣú ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, lọ́gán ni ẹ̀yin yóò sọ pé, Ọ̀wààrà òjò ń bọ̀, a sì rí bẹ́ẹ̀.\wj*
\v 55 \wj Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúúsù bá ń fẹ́, ẹ̀yin á ní, Oòrùn yóò mú, yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀.\wj*
\v 56 \wj Ẹ̀yin àgàbàgebè! Ẹ̀yin le mòye ojú ọ̀run àti ti ayé. Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin kò mọ àkókò yìí?\wj*
\p
\v 57 \x - \xo 12.57-59: \xt Mt 5.25-26.\x*\wj “Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin tìkára yín kò fi ro ohun tí ó tọ́?\wj*
\v 58 \wj Nígbà tí ìwọ bá bá ọ̀tá rẹ lọ sọ́dọ̀ onídàájọ́, rí i pé o bá a parí ọ̀rọ̀ ní ọ̀nà kí ó má ba à fà ọ́ fún adájọ́, adájọ́ a fi ọ́ lé ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́, òun a sì tì ọ́ sínú túbú.\wj*
\v 59 \wj Kí èmi wí fún ọ, ìwọ kì yóò jáde kúrò níbẹ̀, títí ìwọ ó fi san ẹyọ owó kan tí ó kù!”\wj*
\c 13
\s1 Ẹ ronúpìwàdà kí ẹ má bà á ṣègbé
\p
\v 1 Àwọn kan sì wá ní àkókò náà tí ó sọ ti àwọn ará Galili fún un, ẹ̀jẹ̀ ẹni tí Pilatu dàpọ̀ mọ́ ẹbọ wọn.
\v 2 \x - \xo 13.2: \xt Jh 9.1-3.\x*Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, \wj “Ẹ̀yin ṣe bí àwọn ará Galili wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo àwọn ará Galili lọ, nítorí wọ́n jẹ irú ìyà bá-wọ̀n-ọn-nì?\wj*
\v 3 \wj Mo wí fún yín, bí kò ṣe pé ẹ̀yin pẹ̀lú ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.\wj*
\v 4 \wj Tàbí àwọn méjìdínlógún, tí ilé ìṣọ́ ní Siloamu wó lù, tí ó sì pa wọ́n, ẹ̀yin ṣe bí wọ́n ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ ní Jerusalẹmu lọ?\wj*
\v 5 \wj Mo wí fún yín, bí kò ṣe pé ẹ̀yin ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.”\wj*
\p
\v 6 \x - \xo 13.6-9: \xt Mt 21.18-20; Mk 11.12-14,20-21.\x*Ó sì pa òwe yìí fún wọn pé, \wj “Ọkùnrin kan ní igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tí a gbìn sí ọgbà àjàrà rẹ̀; ó sì dé, ó ń wá èso lórí rẹ̀, kò sì rí nǹkan.\wj*
\v 7 \x - \xo 13.7: \xt Mt 3.10; 7.19; Lk 3.9.\x*\wj Ó sì wí fún olùṣọ́gbà rẹ̀ pé, Sá à wò ó, láti ọdún mẹ́ta ni èmi ti ń wá í wo èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí, èmi kò sì rí nǹkan: ké e lulẹ̀; èéṣe tí ó fi ń gbilẹ̀ lásán pẹ̀lú?\wj*
\p
\v 8 \wj “Ó sì dáhùn ó wí fún un pé, Olúwa, jọ̀wọ́ rẹ̀ ní ọdún yìí pẹ̀lú, títí èmi ó fi tu ilẹ̀ ìdí rẹ̀ yíká, títí èmi ó sì fi bu ìlẹ̀dú sí i.\wj*
\v 9 \wj Bí ó bá sì so èso, o dara bẹ́ẹ̀: bí kò bá sì so, ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí nì kí ìwọ kí ó ké e lulẹ̀.’ ”\wj*
\s1 A mú obìnrin arọ láradá ní ọjọ́ ìsinmi
\p
\v 10 Ó sì ń kọ́ni nínú Sinagọgu kan ní ọjọ́ ìsinmi.
\v 11 Sì kíyèsi i, obìnrin kan wà níbẹ̀ tí ó ní ẹ̀mí àìlera, láti ọdún méjìdínlógún wá, ẹni tí ó tẹ̀ tán, tí kò le gbé ara rẹ̀ sókè bí ó ti wù kí ó ṣe.
\v 12 Nígbà tí Jesu rí i, ó pè é sí ọ̀dọ̀, ó sì wí fún un pé, \wj “Obìnrin yìí, a tú ọ sílẹ̀ lọ́wọ́ àìlera rẹ.”\wj*
\v 13 Ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ lé e, Lójúkan náà a sì ti sọ ọ́ di títọ́, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo.
\p
\v 14 \x - \xo 13.14: \xt Ek 20.9-10; Lk 6.6-11; 14.1-6; Jh 5.1-18.\x*Olórí Sinagọgu sì kún fún ìrunú, nítorí tí Jesu mú ni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì wí fún ìjọ ènìyàn pé, ọjọ́ mẹ́fà ní ń bẹ tí a fi í ṣiṣẹ́, nínú wọn ni kí ẹ̀yin kí ó wá kí á ṣe dídá ara yín, kí ó má ṣe ní ọjọ́ ìsinmi.
\p
\v 15 \x - \xo 13.15: \xt Lk 7.13; 14.5; Mt 12.11.\x*Nígbà náà ni Olúwa dáhùn, ó sì wí fún un pé, \wj “Ẹ̀yin àgàbàgebè, olúkúlùkù yín kì í tú màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ kúrò ní ibùso, kì í sì í fà á lọ mu omi ní ọjọ́ ìsinmi.\wj*
\v 16 \x - \xo 13.16: \xt Lk 19.9.\x*\wj Kò sì yẹ kí a tú obìnrin yìí tí í ṣe ọmọbìnrin Abrahamu sílẹ̀ ní ìdè yìí ní ọjọ́ ìsinmi, ẹni tí Satani ti dè, sá à wò ó láti ọdún méjìdínlógún yìí wá?”\wj*
\p
\v 17 Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí, ojú ti gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀, gbogbo ìjọ ènìyàn sì yọ̀ fún ohun ìyanu gbogbo tí ó ṣe.
\s1 Òwe irúgbìn tó kéré jùlọ àti ohun tí n mú ìyẹ̀fun wú
\p
\v 18 \x - \xo 13.18-19: \xt Mt 13.31-32; Mk 4.30-32.\x*Ó sì wí pé, \wj “Kín ni ìjọba Ọlọ́run jọ? Kín ni èmi ó sì fiwé?\wj*
\v 19 \wj Ó dàbí hóró musitadi, tí ọkùnrin kan mú, tí ó sì sọ sínú ọgbà rẹ̀; tí ó sì hù, ó sì di igi ńlá; àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé orí ẹ̀ka rẹ̀.”\wj*
\p
\v 20 \x - \xo 13.20-21: \xt Mt 13.33.\x*Ó sì tún wí pé, \wj “Kín ni èmi ìbá fi ìjọba Ọlọ́run wé?\wj*
\v 21 \wj Ó dàbí ìwúkàrà, tí obìnrin kan mú, tí ó fi sínú òsùwọ̀n ìyẹ̀fun mẹ́ta, títí gbogbo rẹ̀ ó fi di wíwú.”\wj*
\s1 Ọ̀nà tóóró
\p
\v 22 \x - \xo 13.22: \xt Lk 9.51; 17.11; 18.31; 19.11.\x*Ó sì ń la àárín ìlú àti ìletò lọ, ó ń kọ́ni, ó sì ń rìn lọ sí Jerusalẹmu.
\v 23 \x - \xo 13.23-24: \xt Mt 7.13-14; Jh 10.7.\x*Ẹnìkan sì bi í pé, Olúwa, díẹ̀ ha kọ ni àwọn tí a ó gbàlà?
\p Ó sì wí fún wọn pé,
\v 24 \wj “Ẹ làkàkà láti gba ojú ọ̀nà tóóró wọlé, nítorí mo wí fún yín, ènìyàn púpọ̀ ni yóò wá ọ̀nà láti wọ̀ ọ́, wọn kì yóò sì lè wọlé.\wj*
\v 25 \x - \xo 13.25: \xt Mt 25.10-12.\x*\wj Nígbà tí baálé ilé bá dìde lẹ́ẹ̀kan fùú, tí ó bá sí ti ìlẹ̀kùn, ẹ̀yin ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dúró lóde, tí ẹ ó máa kan ìlẹ̀kùn, wí pé, Olúwa, Olúwa, ṣí i fún wa!\wj*
\p \wj “Òun ó sì dáhùn wí fún yín pé, Èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mọ̀ yín.\wj*
\p
\v 26 \x - \xo 13.26-27: \xt Mt 7.21-23; 25.41; Lk 6.46.\x*\wj “Nígbà náà ni ẹ̀yin ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, Àwa ti jẹ, àwa sì ti mu níwájú rẹ, ìwọ sì kọ́ni ní ìgboro ìlú wa.\wj*
\p
\v 27 \wj “Òun ó sì wí pé, Èmi wí fún yín èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá; ẹ lọ kúrò lọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.\wj*
\p
\v 28 \x - \xo 13.28-29: \xt Mt 8.11-12.\x*\wj “Níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò wà, nígbà tí ẹ̀yin ó rí Abrahamu, àti Isaaki, àti Jakọbu, àti gbogbo àwọn wòlíì, ní ìjọba Ọlọ́run, tí a ó sì ti ẹ̀yin sóde.\wj*
\v 29 \wj Wọn ó sì ti ilẹ̀ ìlà-oòrùn, àti ìwọ̀-oòrùn wá, àti láti àríwá, àti gúúsù wá, wọn ó sì jókòó ní ìjọba Ọlọ́run.\wj*
\v 30 \x - \xo 13.30: \xt Mt 19.30; Mk 10.31.\x*\wj Sì wò ó, àwọn ẹni ẹ̀yìn ń bẹ tí yóò di ẹni iwájú, àwọn ẹni iwájú ń bẹ tí yóò di ẹni ẹ̀yìn.”\wj*
\s1 Jesu káàánú fún Jerusalẹmu
\p
\v 31 Ní wákàtí kan náà, díẹ̀ nínú àwọn Farisi tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Jáde, kí ìwọ sì lọ kúrò níhìn-ín yìí: nítorí Herodu ń fẹ́ pa ọ́.”
\p
\v 32 \x - \xo 13.32: \xt Hb 2.10; 7.28.\x*Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Ẹ lọ, kí ẹ̀yin sì sọ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà pé, Kíyèsi i, èmi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, èmi ń ṣe ìmúláradá lónìí àti lọ́la, àti ní ọjọ́ mẹ́ta èmi ó ṣe àṣepé.\wj*
\v 33 \wj Ṣùgbọ́n èmi kò jẹ́ má rìn lónìí, àti lọ́la, àti ní ọ̀túnla: dájúdájú wòlíì kan ki yóò ṣègbé lẹ́yìn odi Jerusalẹmu.\wj*
\p
\v 34 \x - \xo 13.34-35: \xt Mt 23.37-39; Lk 19.41.\x*\wj “Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìwọ tí o pa àwọn wòlíì, tí o sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí ọ pa; nígbà mélòó ni èmi ń fẹ́ ràgà bo àwọn ọmọ rẹ, bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í ràgà bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ apá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́!\wj*
\v 35 \x - \xo 13.35: \xt Jr 22.5; Sm 118.26; Lk 19.38.\x*\wj Sá wò ó, a fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro. Lóòtítọ́ ni mo sì wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi títí yóò fi di àkókò tí ẹ̀yin ó wí pé, Olùbùkún ni ẹni tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa.’ ”\wj*
\c 14
\s1 Jesu ní ilé Farisi kan
\p
\v 1 \x - \xo 14.1: \xt Lk 7.36; 11.37; Mk 3.2.\x*Nígbà tí ó wọ ilé ọ̀kan nínú àwọn olórí Farisi lọ ní ọjọ́ ìsinmi láti jẹun, wọ́n sì ń ṣọ́ ọ.
\v 2 Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí ó ní ara wíwú níwájú rẹ̀.
\v 3 \x - \xo 14.3: \xt Mt 12.10; Mk 3.4; Lk 6.9.\x*Jesu sì dáhùn ó wí fún àwọn amòfin àti àwọn Farisi pé, \wj “Ǹjẹ́ ó tọ́ láti mú ni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, tàbí kò tọ́?”\wj*
\v 4 Wọ́n sì dákẹ́. Ó sì mú un, ó mú un láradá, ó sì jẹ́ kí ó lọ.
\p
\v 5 \x - \xo 14.5: \xt Mt 12.11; Lk 13.15.\x*Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, \wj “Ta ni nínú yín tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí màlúù rẹ̀ yóò bọ́ sínú ihò, tí kì yóò sì fà á sókè lójúkan náà ní ọjọ́ ìsinmi?”\wj*
\v 6 Wọn kò sì lè dá a lóhùn mọ́ sí nǹkan wọ̀nyí.
\p
\v 7 Ó sì pa òwe kan fún àwọn tí ó pè é wá jẹun, nígbà tí ó ṣàkíyèsí bí wọ́n ti ń yan ipò ọlá; ó sì wí fún wọn pé,
\v 8 \x - \xo 14.8: \xt Òw 25.6-7; Lk 11.43; 20.46.\x*\wj “Nígbà tí ẹnìkan bá pè ọ́ wá sí ibi ìyàwó, má ṣe jókòó ní ipò ọlá; kí ó má ba à jẹ́ pé, a ó pe ẹni tí ó lọ́lá jù ọ́ lọ.\wj*
\v 9 \wj Nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ bá dé, a sì wí fún ọ pé, Fún ọkùnrin yìí ní ààyè! Ìwọ á sì wá fi ìtìjú mú ipò ẹ̀yìn.\wj*
\v 10 \wj Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá pè ọ́, lọ kí o sì jókòó ní ipò ẹ̀yìn; nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ bá dé, kí ó lè wí fún ọ pé, Ọ̀rẹ́, bọ́ sókè! Nígbà náà ni ìwọ ó ní ìyìn lójú àwọn tí ó bá ọ jókòó ti oúnjẹ.\wj*
\v 11 \x - \xo 14.11: \xt Mt 23.12; Lk 18.14; Mt 18.4; 1Pt 5.6.\x*\wj Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ni a ó sì gbéga.”\wj*
\p
\v 12 \x - \xo 14.12: \xt Jk 2.2-4.\x*Nígbà náà ni ó sì wí fún alásè tí ó pè é pé, \wj “Nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè má ṣe pe àwọn arákùnrin rẹ tàbí àwọn ìbátan rẹ, tàbí àwọn ọlọ́rọ̀ aládùúgbò rẹ̀; nítorí kí wọn má ṣe pè ọ́ padà láti san ẹ̀san padà.\wj*
\v 13 \x - \xo 14.13: \xt Lk 14.21.\x*\wj Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè, pe àwọn tálákà, àwọn alábùkún ara, àwọn amúnkùn ún, àti àwọn afọ́jú:\wj*
\v 14 \wj Ìwọ ó sì jẹ́ alábùkún fún; nítorí wọn kò ní ohun tí wọn ó fi san án fún ọ, ṣùgbọ́n a ó san án fún ọ ní àjíǹde, àwọn olóòtítọ́.”\wj*
\s1 Òwe nípa àsè ńlá
\p
\v 15 \x - \xo 14.15: \xt If 19.9.\x*Nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n jọ jókòó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó wí fún Jesu pé, “Alábùkún ni fún ẹni tí yóò jẹ oúnjẹ àsè ní ìjọba Ọlọ́run!”
\p
\v 16 \x - \xo 14.16-24: \xt Mt 22.1-10.\x*Jesu dá a lóhùn pé, \wj “Ọkùnrin kan ṣe àsè alẹ́ ńlá, ó sì pe ènìyàn púpọ̀.\wj*
\v 17 \wj Ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní wákàtí àsè alẹ́ náà láti sọ fún àwọn tí a ti pè pé, ‘Ẹ wá; nítorí ohun gbogbo ṣetán!\wj*
\p
\v 18 \wj “Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwáwí ohun kan. Èkínní wí fún un pé, mo ra ilẹ̀ kan, mo sì fẹ́ lọ wò ó wò, mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.\wj*
\p
\v 19 \wj “Èkejì sì wí pé, Mo ra àjàgà màlúù márùn-ún, mo sì ń lọ wò wọ́n wò: mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.\wj*
\p
\v 20 \x - \xo 14.20: \xt De 24.5; 1Kọ 7.33.\x*\wj “Ẹ̀kẹta sì wí pé, Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, nítorí náà ni èmi kò fi lè wá.\wj*
\p
\v 21 \x - \xo 14.21: \xt Lk 14.13.\x*\wj “Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì padà dé, ó sọ nǹkan wọ̀nyí fún olúwa rẹ̀. Nígbà náà ni baálé ilé bínú, ó wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, Jáde lọ sí ìgboro, àti sí òpópó ọ̀nà, kí o sì mú àwọn tálákà, àti àwọn amúnkùn ún, àti àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú wá sí ìhín yìí.\wj*
\p
\v 22 \wj “Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì wí pé, Olúwa a ti ṣe bí o ti pàṣẹ, ààyè sì ń bẹ síbẹ̀.\wj*
\p
\v 23 \wj “Olúwa náà sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ náà pé, Jáde lọ sí òpópó, àti sí ọ̀nà ọgbà, kí o sì rọ̀ wọ́n láti wọlé wá, kí ilé mi lè kún.\wj*
\v 24 \wj Nítorí mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí a ti pè, kì yóò tọ́wò nínú àsè ńlá mi!’ ”\wj*
\s1 Àmúyẹ láti jẹ ọmọ-ẹ̀yìn
\p
\v 25 Àwọn ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ń bá a lọ; ó sì yípadà, ó sì wí fún wọn pé,
\v 26 \x - \xo 14.26-27: \xt Mt 10.37-38.\x*\wj “Bí ẹnìkan bá tọ̀ mí wá, tí kò sì kórìíra baba àti ìyá, àti aya, àti ọmọ, àti arákùnrin, àti arábìnrin, àní àti ọkàn ara rẹ̀ pẹ̀lú, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.\wj*
\v 27 \x - \xo 14.27: \xt Mt 16.24; Mk 8.34; Lk 9.23.\x*\wj Ẹnikẹ́ni tí kò bá ru àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.\wj*
\p
\v 28 \wj “Nítorí ta ni nínú yín tí ń pète láti kọ́ ilé ìṣọ́, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó kí ó ṣírò iye owó rẹ̀, bí òun ní tó tí yóò fi parí rẹ̀.\wj*
\v 29 \wj Kí ó má ba à jẹ́ pé nígbà tí ó bá fi ìpìlẹ̀ ilé sọlẹ̀ tan, tí kò lè parí rẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn tí ó rí i a bẹ̀rẹ̀ sí í fi í ṣe ẹlẹ́yà.\wj*
\v 30 \wj Wí pé, Ọkùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé, kò sì lè parí rẹ̀.\wj*
\p
\v 31 \wj “Tàbí ọba wo ni ó ń lọ bá ọba mìíràn jà, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbèrò bí yóò lè fi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) pàdé ẹni tí ń mú ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) bọ̀ wá ko òun lójú?\wj*
\v 32 \wj Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, nígbà tí onítọ̀hún bá sì wà ní òkèrè, òun a rán ikọ̀ sí i, a sì bẹ̀rẹ̀ àdéhùn àlàáfíà.\wj*
\v 33 \x - \xo 14.33: \xt Lk 18.29-30; Fp 3.7.\x*\wj Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó ṣe nínú yín, tí kò kọ ohun gbogbo tí ó ní sílẹ̀, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.\wj*
\p
\v 34 \x - \xo 14.34-35: \xt Mt 5.13; Mk 9.49-50; Mt 11.15.\x*\wj “Iyọ̀ dára: ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu, kín ni a ó fi mú un dùn?\wj*
\v 35 \wj Kò yẹ fún ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ fún ààtàn; bí kò ṣe pé kí a kó o dànù.\wj*
\p \wj “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́.”\wj*
\c 15
\s1 Òwe àgùntàn tó sọnù
\p
\v 1 \x - \xo 15.1-2: \xt Lk 5.29-30; 19.7.\x*Gbogbo àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sì súnmọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.
\v 2 Àti àwọn Farisi àti àwọn akọ̀wé ń kùn pé, “Ọkùnrin yìí ń gba ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì ń bá wọn jẹun.”
\p
\v 3 Ó sì pa òwe yìí fún wọn, pé,
\v 4 \x - \xo 15.4-7: \xt Mt 18.10-14.\x*\wj “Ọkùnrin wo ni nínú yín, tí ó ní ọgọ́rùn-ún àgùntàn, bí ó bá sọ ọ̀kan nù nínú wọn, tí kì yóò fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún yokù sílẹ̀ ni ijù tí kì yóò sì tọ ipasẹ̀ èyí tí ó nù lọ, títí yóò fi rí i?\wj*
\v 5 \wj Nígbà tí ó bá sì rí i tán, yóò gbé e lé èjìká rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀.\wj*
\v 6 \wj Nígbà tí ó bá sì dé ilé yóò pe àwọn ọ̀rẹ́ àti aládùúgbò rẹ̀ jọ, yóò sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ bá mí yọ̀; nítorí tí mo ti rí àgùntàn mi tí ó nù.\wj*
\v 7 \x - \xo 15.7: \xt Jk 5.20; Lk 19.10; 15.10.\x*\wj Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ yóò wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà, ju lórí olóòtítọ́ mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún lọ, tí kò nílò ìrònúpìwàdà.\wj*
\s1 Òwe owó tó sọnù
\p
\v 8 \wj “Tàbí obìnrin wo ni ó ní owó fàdákà mẹ́wàá bí ó bá sọ ọ̀kan nù, tí kì yóò tan fìtílà, kí ó fi gbá ilé, kí ó sì wá a gidigidi títí yóò fi rí i?\wj*
\v 9 \wj Nígbà tí ó sì rí i, ó pe àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, ó wí pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀; nítorí mo rí owó fàdákà tí mo ti sọnù.\wj*
\v 10 \wj Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ń bẹ níwájú àwọn angẹli Ọlọ́run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà.”\wj*
\s1 Òwe ọmọ tó sọnù
\p
\v 11 \x - \xo 15.11: \xt Mt 21.28.\x*Ó sì wí pé ọkùnrin kan ní ọmọ méjì:
\v 12 \x - \xo 15.12: \xt De 21.15-17.\x*\wj “Èyí àbúrò nínú wọn wí fún baba rẹ̀ pé, Baba, fún mi ní ìní tí ó kàn mí. Ó sì pín ohun ìní rẹ̀ fún wọn.\wj*
\p
\v 13 \wj “Kò sì tó ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, èyí àbúrò kó ohun gbogbo tí ó ní jọ, ó sì mú ọ̀nà àjò rẹ̀ pọ̀n lọ sí ilẹ̀ òkèrè, níbẹ̀ ni ó sì gbé fi ìwà wọ̀bìà ná ohun ìní rẹ̀ ní ìnákúnàá.\wj*
\v 14 \wj Nígbà tí ó sì ba gbogbo rẹ̀ jẹ́ tan, ìyàn ńlá wá mú ní ilẹ̀ náà; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí di aláìní.\wj*
\v 15 \wj Ó sì fi ara rẹ sọfà fun ọ̀kan lára àwọn ọmọ ìlú náà; òun sì rán an lọ sí oko rẹ̀ láti tọ́jú ẹlẹ́dẹ̀.\wj*
\v 16 \wj Ayọ̀ ni ìbá fi jẹ oúnjẹ tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ ní àjẹyó, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni kò sì fi fún un.\wj*
\p
\v 17 \wj “Ṣùgbọ́n nígbà tí ojú rẹ̀ wálẹ̀, ó ní Mélòó mélòó àwọn alágbàṣe baba mí ni ó ní oúnjẹ àjẹyó, àti àjẹtì, èmi sì ń kú fún ebi níhìn-ín.\wj*
\v 18 \wj Èmi ó dìde, èmi ó sì tọ baba mi lọ, èmi ó sì wí fún un pé, Baba, èmí ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ̀run, àti níwájú rẹ,\wj*
\v 19 \wj èmi kò sì yẹ, ní ẹni tí à bá pè ní ọmọ rẹ mọ́; fi mí ṣe ọ̀kan nínú àwọn alágbàṣe rẹ.\wj*
\v 20 \wj Ó sì dìde, ó sì tọ baba rẹ̀ lọ.\wj*
\p \wj “Ṣùgbọ́n nígbà tí ó sì wà ní òkèrè, baba rẹ̀ rí i, àánú ṣe é, ó sì súré, ó rọ̀ mọ́ ọn ní ọrùn, ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu.\wj*
\p
\v 21 \wj “Ọmọ náà sì wí fún un pé, Baba, èmi ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ̀run, àti níwájú rẹ, èmi kò yẹ ní ẹni tí à bá pè ní ọmọ rẹ mọ́!\wj*
\p
\v 22 \x - \xo 15.22: \xt Gẹ 41.42; Sk 3.4.\x*\wj “Ṣùgbọ́n baba náà wí fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, Ẹ mú ààyò aṣọ wá kánkán, kí ẹ sì fi wọ̀ ọ́; ẹ sì fi òrùka bọ̀ ọ́ lọ́wọ́, àti bàtà sí ẹsẹ̀ rẹ̀:\wj*
\v 23 \wj Ẹ sì mú ẹgbọrọ màlúù àbọ́pa wá, kí ẹ sì pa á, kí a máa ṣe àríyá.\wj*
\v 24 \x - \xo 15.24: \xt 1Tm 5.6; Ef 2.1; Lk 9.60.\x*\wj Nítorí ọmọ mi yìí ti kú, ó sì tún yè, ó ti nù, a sì rí i. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àríyá.\wj*
\p
\v 25 \wj “Ṣùgbọ́n ọmọ rẹ̀ èyí ẹ̀gbọ́n ti wà ní oko: bí ó sì ti ń bọ̀, tí ó súnmọ́ etí ilé, ó gbọ́ orin àti ijó.\wj*
\v 26 \wj Ó sì pe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ wọn, ó béèrè, kín ni a mọ nǹkan wọ̀nyí sí?\wj*
\v 27 \wj Ó sì wí fún un pé, Arákùnrin rẹ dé, baba rẹ sì pa ẹgbọrọ màlúù àbọ́pa, nítorí tí ó rí i padà ní àlàáfíà àti ní ìlera.\wj*
\p
\v 28 \wj “Ó sì bínú, ó sì kọ̀ láti wọlé; baba rẹ̀ sì jáde, ó sì wá í ṣìpẹ̀ fún un.\wj*
\v 29 \wj Ó sì dáhùn ó wí fún baba rẹ̀ pé, Wò ó, láti ọdún mélòó wọ̀nyí ni èmi ti ń sìn ọ́, èmi kò sì rú òfin rẹ rí, ìwọ kò sì tí ì fi ọmọ ewúrẹ́ kan fún mi, láti fi bá àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣe àríyá.\wj*
\v 30 \wj Ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ rẹ yìí dé, ẹni tí ó fi panṣágà fi ọrọ̀ rẹ̀ ṣòfò, ìwọ sì ti pa ẹgbọrọ màlúù àbọ́pa fún un.\wj*
\p
\v 31 \wj “Ó sì wí fún un pé, Ọmọ, nígbà gbogbo ni ìwọ ń bẹ lọ́dọ̀ mi, ohun gbogbo tí mo sì ní, tìrẹ ni.\wj*
\v 32 \wj Ó yẹ kí a ṣe àríyá kí a sì yọ̀: nítorí arákùnrin rẹ yìí ti kú, ó sì tún yè; ó ti nù, a sì rí i.’ ”\wj*
\c 16
\s1 Òwe ọlọ́gbọ́n òṣìṣẹ́
\p
\v 1 Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pẹ̀lú pé, \wj “Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ní ìríjú kan; òun náà ni wọ́n fi sùn ún pé, ó ti ń fi ohun ìní rẹ̀ ṣòfò.\wj*
\v 2 \wj Nígbà tí ó sì pè é, ó wí fún un pé, Èéṣe tí èmi fi ń gbọ́ èyí sí ọ? Ṣírò iṣẹ́ ìríjú rẹ; nítorí ìwọ kò lè ṣe ìríjú mi mọ́.\wj*
\p
\v 3 \wj “Ìríjú náà sì wí nínú ara rẹ̀ pé, Èwo ni èmi ó ṣe? Nítorí tí olúwa mi gba iṣẹ́ ìríjú lọ́wọ́ mi: èmi kò le ṣiṣẹ́ oko, bẹ́ẹ̀ ni ojú ń tì mí láti ṣagbe.\wj*
\v 4 \wj Mo mọ èyí tí èmi yóò ṣe, nígbà tí a bá mú mi kúrò níbi iṣẹ́ ìríjú, kí àwọn ènìyàn le gbà mí sínú ilé wọn.\wj*
\p
\v 5 \wj “Ó sì pe àwọn ajigbèsè olúwa rẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún èkínní pé, Èló ni ìwọ jẹ olúwa mi?\wj*
\p
\v 6 \wj “Ó sì wí pé, Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) òsùwọ̀n òróró.\wj*
\p \wj “Ó sì wí fún un pé, Mú ìwé rẹ, sì jókòó nísinsin yìí, kí o sì kọ àádọ́ta lé ní irinwó (450).\wj*
\p
\v 7 \wj “Nígbà náà ni ó sì bi ẹnìkejì pé, Èló ni ìwọ jẹ?\wj*
\p \wj “Òun sì wí pé, Ẹgbẹ̀rún (1,000) òsùwọ̀n alikama.\wj*
\p \wj “Ó sì wí fún un pé, Mú ìwé rẹ, kí o sì kọ ẹgbẹ̀rin (800).\wj*
\p
\v 8 \x - \xo 16.8: \xt 1Tẹ 5.5; Ef 5.8; Lk 20.34; Jh 12.36.\x*\wj “Olúwa rẹ̀ sì yin aláìṣòótọ́ ìríjú náà, nítorí tí ó fi ọgbọ́n ṣe é, àwọn ọmọ ayé yìí sá à gbọ́n ní ìran wọn ju àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ lọ.\wj*
\v 9 \x - \xo 16.9: \xt Lk 12.33; 18.22.\x*\wj Èmi sì wí fún yín, ẹ fi ọrọ̀ ayé yìí yan ọ̀rẹ́ fún ara yín pé, nígbà tí o ba lọ, kí wọn kí ó le gbà yín sí ibùjókòó wọn títí ayé.\wj*
\p
\v 10 \x - \xo 16.10: \xt Mt 25.21; Lk 19.17.\x*\wj “Ẹni tí ó bá ṣe olóòtítọ́ nínú ohun kínkínní, ó ṣe olóòtítọ́ ní púpọ̀ pẹ̀lú: ẹni tí ó bá sì ṣe aláìṣòótọ́ ní ohun kínkínní, ó ṣe aláìṣòótọ́ ní ohun púpọ̀ pẹ̀lú.\wj*
\v 11 \wj Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò bá ti jẹ́ olóòtítọ́ nínú ọrọ̀ ayé yìí, ta ni yóò fi ọ̀rọ̀ tòótọ́ fún yín?\wj*
\v 12 \wj Bí ẹ̀yin kò bá sì ti jẹ́ olóòtítọ́ nínú ohun tí í ṣe ti ẹlòmíràn, ta ni yóò fún yín ní ohun tí í ṣe ti ẹ̀yin tìkára yín?\wj*
\p
\v 13 \x - \xo 16.13: \xt Mt 6.24.\x*\wj “Kò sì í ẹnìkan tí ó lè sin ọ̀gá méjì. Òun yóò yà kórìíra ọ̀kan tí yóò fẹ́ràn èkejì, tàbí kí ó fi ara mọ́ ọ̀kan kí ó sì yan èkejì ní ìpọ̀sí. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run àti owó papọ̀.”\wj*
\p
\v 14 Àwọn Farisi, tí wọ́n ní ojúkòkòrò sì gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì yọ ṣùtì sí i.
\v 15 \x - \xo 16.15: \xt 1Sa 16.7; Òw 21.2; Ap 1.24; Lk 10.29.\x*Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Ẹ̀yin ni àwọn tí ń dá àre fún ara yín níwájú ènìyàn; ṣùgbọ́n Ọlọ́run mọ ọkàn yín, nítorí ohun ti a gbéga lójú ènìyàn, ìríra ni níwájú Ọlọ́run.\wj*
\s1 Àfikún àwọn ẹ̀kọ́
\p
\v 16 \x - \xo 16.16: \xt Mt 11.12-13.\x*\wj “Òfin àti àwọn wòlíì ń bẹ títí di ìgbà Johanu, Láti ìgbà náà wá ni a ti ń wàásù ìròyìn ayọ̀ ìjọba Ọlọ́run, olúkúlùkù sì ń fi ipá wọ inú rẹ̀.\wj*
\v 17 \x - \xo 16.17: \xt Mt 5.17-18; Lk 21.33.\x*\wj Ṣùgbọ́n ó rọrùn fún ọ̀run òun ayé láti kọjá lọ, ju kí èyí tí ó kéré jù nínú òfin kí ó yẹ.\wj*
\p
\v 18 \x - \xo 16.18: \xt Mt 5.31-32; 19.9; Mk 10.11-12; 1Kọ 7.10-11.\x*\wj “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì gbé ẹlòmíràn ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà: ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé, ẹni tí ọkọ rẹ̀ kọ̀sílẹ̀ ní ìyàwó náà, ó ṣe panṣágà.\wj*
\s1 Ọlọ́rọ̀ kan àti Lasaru
\p
\v 19 \wj “Ǹjẹ́ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ń wọ aṣọ elése àlùkò àti aṣọ àlà dáradára, a sì máa jẹ dídùndídùn lójoojúmọ́.\wj*
\v 20 \x - \xo 16.20: \xt Jh 11.1-44; 12.1,9.\x*\wj Alágbe kan sì wà tí à ń pè ní Lasaru, tí wọ́n máa ń gbé wá kalẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà ilé rẹ̀, ó kún fún ooju,\wj*
\v 21 \wj Òun a sì máa fẹ́ kí a fi èérún tí ó ti orí tábìlì ọlọ́rọ̀ bọ́ sílẹ̀ bọ́ òun, àwọn ajá sì wá, wọ́n sì fá a ní ooju lá.\wj*
\p
\v 22 \x - \xo 16.22: \xt Jh 13.23.\x*\wj “Ó sì ṣe, alágbe kú, a sì ti ọwọ́ àwọn angẹli gbé e lọ sí oókan àyà Abrahamu: ọlọ́rọ̀ náà sì kú pẹ̀lú, a sì sin ín;\wj*
\v 23 \wj Ní ipò òkú ni ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ń bẹ nínú ìjìyà oró, ó sì rí Abrahamu ní òkèrè, àti Lasaru ní oókan àyà rẹ̀.\wj*
\v 24 \wj Ó sì ké, ó wí pé, Baba Abrahamu, ṣàánú fún mi, kí o sì rán Lasaru, kí ó tẹ orí ìka rẹ̀ bọ omi, kí ó sì fi tù mí ní ahọ́n; nítorí èmi ń joró nínú ọ̀wọ́n iná yìí.\wj*
\p
\v 25 \x - \xo 16.25: \xt Lk 6.24.\x*\wj “Ṣùgbọ́n Abrahamu wí pé, Ọmọ, rántí pé, nígbà ayé rẹ, ìwọ ti gba ohun rere tìrẹ, àti Lasaru ohun búburú, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ara rọ̀ ọ́, ìwọ sì ń joró.\wj*
\v 26 \wj Àti pẹ̀lú gbogbo èyí, a gbé ọ̀gbun ńlá kan sí agbede-méjì àwa àti ẹ̀yin, kí àwọn tí ń fẹ́ má ba á le rékọjá láti ìhín lọ sọ́dọ̀ yín, kí ẹnikẹ́ni má sì le ti ọ̀hún rékọjá tọ̀ wá wá.\wj*
\p
\v 27 \wj “Ó sì wí pé, Ǹjẹ́ mo bẹ̀ ọ́, baba, kí ìwọ kí ó rán Lasaru lọ sí ilé baba mi,\wj*
\v 28 \wj nítorí mo ní arákùnrin márùn-ún; kí ó lè rò fún wọn kí àwọn kí ó má ba á wá sí ibi oró yìí pẹ̀lú.\wj*
\p
\v 29 \x - \xo 16.29: \xt Jh 5.45-47; Ap 15.21; Lk 4.17.\x*\wj “Abrahamu sì wí fún un pé, Wọ́n ní Mose àti àwọn wòlíì; kí wọn kí ó gbọ́ tiwọn.\wj*
\p
\v 30 \x - \xo 16.30: \xt Lk 3.8; 19.9.\x*\wj “Ó sì wí pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́, Abrahamu baba; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ti inú òkú tọ̀ wọ́n lọ, wọn ó ronúpìwàdà.\wj*
\p
\v 31 \wj “Ó sì wí fún un pé, Bí wọn kò bá gbọ́ ti Mose àti ti àwọn wòlíì, a kì yóò yí wọn ní ọkàn padà bí ẹnìkan tilẹ̀ ti inú òkú dìde.’ ”\wj*
\c 17
\s1 Ẹ̀ṣẹ̀, ìgbàgbọ́, àti iṣẹ́
\p
\v 1 \x - \xo 17.1-2: \xt Mt 18.6-7; Mk 9.42; 1Kọ 8.12.\x*Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, \wj “Kò le ṣe kí ohun ìkọ̀sẹ̀ máa wa, ṣùgbọ́n ègbé ni fún ẹni tí ó ti ipasẹ̀ rẹ̀ dé.\wj*
\v 2 \wj Ìbá sàn fún un kí a so ọlọ mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì gbé e jù sínú Òkun, ju kí ó mú ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kọsẹ̀.\wj*
\v 3 \x - \xo 17.3-4: \xt Mt 18.15,21-22.\x*\wj Ẹ máa kíyèsára yín.\wj*
\p \wj “Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀, bá a wí; bí ó bá sì ronúpìwàdà, dáríjì ín.\wj*
\v 4 \wj Bí ó bá sì ṣẹ̀ ọ́ ní igba méje ní òòjọ́, tí ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ìgbà méje ní òòjọ́ pé, Mo ronúpìwàdà, dáríjì ín.”\wj*
\p
\v 5 \x - \xo 17.5-6: \xt Mt 17.20; 21.21; Mk 11.22-23.\x*\x - \xo 17.5: \xt Lk 7.13.\x*Àwọn aposteli sì wí fún Olúwa pé, “Bù sí ìgbàgbọ́ wa.”
\p
\v 6 Olúwa sì wí pé, \wj “Bí ẹ̀yin bá ní ìgbàgbọ́ bí hóró irúgbìn musitadi, ẹ̀yin yóò lè wí fún igi sikamine yìí pé, Di fi fà á tu, kí a sì gbìn ọ́ sínú Òkun, yóò sì gbọ́ tiyín.\wj*
\p
\v 7 \wj “Ṣùgbọ́n ta ni nínú yín, tí ó ní ọmọ ọ̀dọ̀, tí ó ń tulẹ̀, tàbí tí ó ń bọ́ ẹran, tí yóò wí fún un lójúkan náà tí ó bá ti oko dé pé, Lọ í jókòó láti jẹun?\wj*
\v 8 \x - \xo 17.8: \xt Lk 12.37; Jh 13.3-5.\x*\wj Tí kì yóò kúkú wí fún un pé, Pèsè ohun tí èmi yóò jẹ, sì di àmùrè, kí ìwọ kí ó máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi, títí èmi ó fi jẹ kí èmi ó sì mu tán; lẹ́yìn náà ni ìwọ ó sì jẹ, tí ìwọ ó sì mu?\wj*
\v 9 \wj Òun ó ha máa dá ọpẹ́ lọ́wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ náà, nítorí ó ṣe ohun tí a pàṣẹ fún un bí? Èmi kò rò bẹ́ẹ̀.\wj*
\v 10 \wj Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo tí a pàṣẹ fún yín tán, ẹ wí pé, Aláìlérè ọmọ ọ̀dọ̀ ni wá: èyí tí í ṣe iṣẹ́ wa láti ṣe, ní àwa ti ṣe.’ ”\wj*
\s1 Ìwòsàn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá
\p
\v 11 \x - \xo 17.11: \xt Lk 9.51; 13.22; 19.11.\x*Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ sí Jerusalẹmu, ó kọjá láàrín Samaria Galili.
\v 12 \x - \xo 17.12: \xt Le 13.45-46.\x*Bí ó sì ti ń wọ inú ìletò kan lọ, àwọn ọkùnrin adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá pàdé rẹ̀, wọ́n dúró ní òkèrè,
\v 13 \x - \xo 17.13: \xt Lk 5.5; 8.24,45; 9.33,49.\x*wọ́n sì kígbe sókè wí pé, “Jesu, Olùkọ́, ṣàánú fún wa.”
\p
\v 14 \x - \xo 17.14: \xt Lk 5.14; Mt 8.4; Mk 1.44; Le 14.2-32.\x*Nígbà tí ó rí wọn, ó wí fún wọn pé, \wj “Ẹ lọ í fi ara yín hàn fún àwọn àlùfáà.”\wj* Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n sì di mímọ́.
\p
\v 15 Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn rí i pé a mú òun láradá ó padà, ó sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run lógo.
\v 16 Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ń dúpẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀: ará Samaria ni òun í ṣe.
\p
\v 17 Jesu sì dáhùn wí pé, \wj “Àwọn mẹ́wàá kí a sọ di mímọ́? Àwọn mẹ́sàn-án ìyókù ha dà?\wj*
\v 18 \wj A kò rí ẹnìkan tí ó padà wá fi ògo fún Ọlọ́run, bí kò ṣe àlejò yìí?”\wj*
\v 19 \x - \xo 17.19: \xt Mt 9.22; Mk 5.34; Lk 8.48; 18.42.\x*Ó sì wí fún un pé, \wj “Dìde, kí o sì máa lọ, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.”\wj*
\s1 Bíbọ̀ ìjọba Ọlọ́run
\p
\v 20 \x - \xo 17.20: \xt Lk 19.11; 21.7; Ap 1.6.\x*Nígbà tí àwọn Farisi bi í pé, nígbà wo ni ìjọba Ọlọ́run yóò dé, ó dá wọn lóhùn pé, \wj “Ìjọba Ọlọ́run kì í wá pẹ̀lú àmì.\wj*
\v 21 \wj Bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wí pé, Kíyèsi i níhìn-ín! tàbí Kíyèsi i lọ́hùn ún ni! sá à wò ó, ìjọba Ọlọ́run ń bẹ nínú yín.”\wj*
\p
\v 22 \x - \xo 17.22: \xt Mt 9.15; Mk 2.20; Lk 5.35.\x*Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, \wj “Ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí ẹ̀yin yóò fẹ́ láti rí ọ̀kan nínú ọjọ́ Ọmọ Ènìyàn, ẹ̀yin kì yóò sì rí i.\wj*
\v 23 \x - \xo 17.23: \xt Mt 24.23; Mk 13.21.\x*\wj Wọ́n sì wí fún yín pé, Wò ó níhìn-ín! tàbí Wò ó lọ́hùn ún! Ẹ máa lọ, ẹ má ṣe tẹ̀lé wọn.\wj*
\v 24 \x - \xo 17.24: \xt Mt 24.27; If 1.7.\x*\wj Nítorí gẹ́gẹ́ bí mọ̀nàmọ́ná ti í kọ ní apá kan lábẹ́ ọ̀run, tí sì í mọ́lẹ̀ ní apá kejì lábẹ́ ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ Ènìyàn yóò sì rí ní ọjọ́ rẹ̀.\wj*
\v 25 \x - \xo 17.25: \xt Lk 9.22.\x*\wj Ṣùgbọ́n kò lè ṣàìmá kọ́ jìyà ohun púpọ̀, kí a sì kọ̀ ọ́ lọ́dọ̀ ìran yìí.\wj*
\p
\v 26 \x - \xo 17.26-27: \xt Mt 24.37-39; Gẹ 6.5-8; 7.6-24.\x*\wj “Bí ó ti rí ní ọjọ́ Noa, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ Ọmọ Ènìyàn.\wj*
\v 27 \wj Wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń gbéyàwó, wọ́n sì ń fa ìyàwó fún ni, títí ó fi di ọjọ́ ti Noa wọ inú ọkọ̀ lọ, kíkún omi sì dé, ó sì run gbogbo wọn.\wj*
\p
\v 28 \x - \xo 17.28-30: \xt Gẹ 18.20-33; 19.24-25.\x*\wj “Bí ó sì ti rí ní ọjọ́ Lọti; wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń gbìn, wọ́n ń kọ́lé,\wj*
\v 29 \wj ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà tí Lọti jáde kúrò ní Sodomu, òjò iná àti sulfuru rọ̀ láti ọ̀run wá, ó sì run gbogbo wọn.\wj*
\p
\v 30 \wj “Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ náà tí Ọmọ Ènìyàn yóò farahàn.\wj*
\v 31 \x - \xo 17.31: \xt Mt 24.17-18; Mk 13.15-16; Lk 21.21.\x*\wj Ní ọjọ́ náà, ẹni tí ó bá wà lórí ilé, tí ẹrù rẹ̀ sì ń bẹ ní ilẹ̀, kí ó má ṣe sọ̀kalẹ̀ láti wá kó o; ẹni tí ó bá sì wà ní oko, kí ó má ṣe padà sẹ́yìn.\wj*
\v 32 \x - \xo 17.32: \xt Gẹ 19.26.\x*\wj Ẹ rántí aya Lọti.\wj*
\v 33 \x - \xo 17.33: \xt Mt 10.39; 16.25; Mk 8.35; Lk 9.24; Jh 12.25.\x*\wj Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wá àti gba ẹ̀mí rẹ̀ là yóò sọ ọ́ nù; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì sọ ọ́ nù yóò gbà á là.\wj*
\v 34 \x - \xo 17.34-35: \xt Mt 24.40-41.\x*\wj Mo wí fún yín, ní òru ọjọ́ náà, ènìyàn méjì yóò wà lórí àkéte kan; a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀.\wj*
\v 35 \wj Ènìyàn méjì yóò sì máa lọ ọlọ pọ̀; a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀.”\wj*\f + \fr 17.35 \ft Àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́ kan se àfikún ọ̀rọ̀ yìí \fqa sílẹ̀. \fv 36\fqa Àwọn ọkùnrin méjì yóò máa ṣiṣẹ́ nínú oko, a o mú ẹnìkan, a ó sì fi ẹni kejì sílẹ̀\ft .\f*
\p
\v 37 \x - \xo 17.37: \xt Mt 24.28.\x*Wọ́n sì dá a lóhùn, wọ́n bi í pé, “Níbo, Olúwa?”
\p Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Níbi tí òkú bá gbé wà, níbẹ̀ pẹ̀lú ni igún ìkójọpọ̀ sí.”\wj*
\c 18
\s1 Òwe ìforítì opó
\p
\v 1 \x - \xo 18.1-8: \xt Lk 11.5-8.\x*Ó sì pa òwe kan fún wọn láti fi yé wọn pe, ó yẹ kí a máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí a má sì ṣàárẹ̀.
\v 2 Wí pé, \wj “Onídàájọ́ kan wà ní ìlú kan, tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí kò sì ṣe ojúsàájú ènìyàn.\wj*
\v 3 \wj Opó kan sì wà ní ìlú náà, ó sì ń tọ̀ ọ́ wá, wí pé, Gbẹ̀san mi lára ọ̀tá mi!\wj*
\p
\v 4 \wj “Lákọ̀ọ́kọ́ kò dá a lóhùn, ṣùgbọ́n níkẹyìn ó wí nínú ara rẹ̀ pé, Bí èmi kò tilẹ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run, tí èmi kò sì ṣe ojúsàájú ènìyàn,\wj*
\v 5 \wj Ṣùgbọ́n nítorí tí opó yìí ń yọ mí lẹ́nu, èmi ó gbẹ̀san rẹ̀, kí ó má ba à fi wíwá rẹ̀ nígbàkígbà dá mi lágara.’ ”\wj*
\p
\v 6 \x - \xo 18.6: \xt Lk 7.13.\x*Olúwa sì wí pé, \wj “Ẹ gbọ́ bí aláìṣòótọ́ onídàájọ́ ti wí!\wj*
\v 7 \x - \xo 18.7: \xt If 6.10; Mt 24.22; Ro 8.33; 1Kọ 3.12; 2Tm 2.10.\x*\wj Ọlọ́run kì yóò ha sì gbẹ̀san àwọn àyànfẹ́ rẹ̀, tí ń fi ọ̀sán àti òru kígbe pè é, tí ó sì mú sùúrù fún wọn?\wj*
\v 8 \wj Mo wí fún yín, yóò gbẹ̀san wọn kánkán! Ṣùgbọ́n nígbà tí Ọmọ Ènìyàn bá dé yóò ha rí ìgbàgbọ́ ní ayé bí?”\wj*
\s1 Òwe Farisi àti agbowó òde
\p
\v 9 Ó sì pa òwe yìí fún àwọn kan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ara wọn pé, àwọn ni olódodo, tí wọ́n sì ń gan àwọn ẹlòmíràn,
\v 10 pé, \wj “Àwọn ọkùnrin méjì gòkè lọ sí tẹmpili láti gbàdúrà, ọ̀kan jẹ́ Farisi, èkejì sì jẹ́ agbowó òde.\wj*
\v 11 \x - \xo 18.11: \xt Mt 6.5; Mk 11.25.\x*\wj Èyí Farisi dìde, ó sì ń gbàdúrà nínú ara rẹ̀ báyìí pé, Ọlọ́run mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí èmi kò rí bí àwọn ará ìyókù, àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà, aláìṣòótọ́, panṣágà, tàbí bí agbowó òde yìí.\wj*
\v 12 \x - \xo 18.12: \xt Lk 5.33; 11.42.\x*\wj Èmi ń gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì ní ọ̀sẹ̀, mo ń san ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí mo ní.\wj*
\p
\v 13 \wj “Ṣùgbọ́n agbowó òde dúró lókèèrè, kò tilẹ̀ jẹ́ gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ṣùgbọ́n ó lu ara rẹ̀ ní oókan àyà, ó wí pé, Ọlọ́run ṣàánú fún mi, èmi ẹlẹ́ṣẹ̀!\wj*
\p
\v 14 \x - \xo 18.14: \xt Mt 18.4; 23.12; Lk 14.11; 1Pt 5.6.\x*\wj “Mo wí fún yín, ọkùnrin yìí sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀ ní ìdáláre ju èkejì lọ: nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, òun ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá sì rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ òun ni a ó gbéga.”\wj*
\s1 Àwọn ọmọdé àti Jesu
\p
\v 15 \x - \xo 18.15-17: \xt Mt 19.13-15; 18.3; Mk 10.13-16.\x*Wọ́n sì gbé àwọn ọmọ ọwọ́ tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rí i, wọ́n ń bá wọn wí.
\v 16 Ṣùgbọ́n Jesu pè wọ́n sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, \wj “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì ṣe dá wọn lẹ́kun, nítorí tí irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run.\wj*
\v 17 \wj Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí kò bá gbà ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré, kì yóò wọ inú rẹ̀ bí ó ti wù kí ó rí.”\wj*
\s1 Ọlọ́rọ̀ alákòóso
\p
\v 18 \x - \xo 18.18-23: \xt Mt 19.16-22; Mk 10.17-22.\x*\x - \xo 18.18: \xt Lk 10.25.\x*Ìjòyè kan sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, wí pé, “Olùkọ́ rere, kín ni èmi ó ṣe tí èmi ó fi jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”
\p
\v 19 Jesu wí fún un pé, \wj “Èéṣe tí ìwọ fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí bí kò ṣe ẹnìkan, èyí sì ni Ọlọ́run.\wj*
\v 20 \x - \xo 18.20: \xt Ek 20.12-16; De 5.16-20; Ro 13.9; Jk 2.11.\x*\wj Ìwọ mọ̀ àwọn òfin: Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà, ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe jalè, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe jẹ́rìí èké, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.’ ”\wj*
\p
\v 21 Ó sì wí pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti pamọ́ láti ìgbà èwe mi wá.”
\p
\v 22 \x - \xo 18.22: \xt Lk 12.33; Ap 2.45; 4.32.\x*Nígbà tí Jesu sì gbọ́ èyí, ó wí fún un pé, \wj “Ohun kan ni ó kù fún ọ síbẹ̀: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o sì pín in fún àwọn tálákà, ìwọ ó sì ní ìṣúra ní ọ̀run: sì wá, kí o máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”\wj*
\p
\v 23 Nígbà tí ó sì gbọ́ èyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi, nítorí tí ó ní ọrọ̀ púpọ̀.
\v 24 \x - \xo 18.24-27: \xt Mt 19.23-26; Mk 10.23-27.\x*Nígbà tí Jesu rí i pé inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi, ó wí pé, \wj “Yóò ti ṣòro tó fún àwọn tí ó ní ọrọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run!\wj*
\v 25 \wj Nítorí ó rọrùn fún ìbákasẹ láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run lọ.”\wj*
\p
\v 26 Àwọn tí ó sì gbọ́ wí pé, “Ǹjẹ́ ta ni ó ha lè là?”
\p
\v 27 \x - \xo 18.27: \xt Gẹ 18.14; Jb 42.2; Jr 32.17; Lk 1.37.\x*Ó sì wí pé, \wj “Ohun tí ó ṣòro lọ́dọ̀ ènìyàn kò ṣòro lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”\wj*
\p
\v 28 \x - \xo 18.28-30: \xt Mt 19.27-30; Mk 10.28-31; Lk 5.1-11.\x*Peteru sì wí pé, “Sá wò ó, àwa ti fi ilé wa sílẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn!”
\p
\v 29 Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kò sí ẹni tí ó fi ilé, tàbí aya, tàbí ará, tàbí òbí, tàbí ọmọ sílẹ̀, nítorí ìjọba Ọlọ́run,\wj*
\v 30 \wj tí kì yóò gba ìlọ́po púpọ̀ sí i ní ayé yìí, àti ní ayé tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.”\wj*
\s1 Jesu tún sọ nípa ikú rẹ̀
\p
\v 31 \x - \xo 18.31-34: \xt Mt 20.17-19; Mk 10.32-34; Lk 9.22,44-45; 17.25.\x*Nígbà náà ni ó pe àwọn méjìlá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, \wj “Sá wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, a ó sì mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ láti ọwọ́ àwọn wòlíì, nítorí Ọmọ Ènìyàn.\wj*
\v 32 \wj Nítorí tí a ó fi lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́, a ó fi ṣe ẹlẹ́yà, a ó sì fi ṣe ẹ̀sín, a ó sì tutọ́ sí i lára.\wj*
\v 33 \wj Wọn ó sì nà án, wọn ó sì pa á, ní ọjọ́ kẹta yóò sì jíǹde.”\wj*
\p
\v 34 Ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí kò sì yé wọn, ọ̀rọ̀ yìí sì pamọ́ fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì mọ ohun tí a wí.
\s1 Afọ́jú alágbe gba ìwòsàn
\p
\v 35 \x - \xo 18.35-43: \xt Mt 20.29-34; Mk 10.46-52; Mt 9.27-31; Mk 8.22; Jh 9.1-7.\x*Bí ó ti súnmọ́ Jeriko, afọ́jú kan jókòó lẹ́bàá ọ̀nà ó ń ṣagbe.
\v 36 Nígbà tí ó gbọ́ tí ọ̀pọ̀ ń kọjá lọ, ó béèrè pé, kín ni ìtumọ̀ èyí.
\v 37 Wọ́n sì wí fún un pé, “Jesu ti Nasareti ni ó ń kọjá lọ.”
\p
\v 38 Ó sì kígbe pé, “Jesu, ìwọ ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi!”
\p
\v 39 Àwọn tí ń lọ níwájú bá a wí, pé, kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n òun sì kígbe sókè sí í pé, “Ìwọ Ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi!”
\p
\v 40 Jesu sì dúró, ó ní, kí á mú un tọ òun wá nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn, ó bi í
\v 41 wí pé, \wj “Kí ni ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe fún ọ?”\wj*
\p Ó sì wí pé, “Olúwa jẹ́ kí èmi ríran.”
\p
\v 42 \x - \xo 18.42: \xt Mt 9.22; Mk 5.34; 10.52; Lk 7.50; 8.48; 17.19.\x*Jesu sì wí fún un pé, \wj “Ríran; ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.”\wj*
\v 43 Lójúkan náà ó sì ríran, ó sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo àti gbogbo ènìyàn nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọ́run.
\c 19
\s1 Sakeu agbowó òde
\p
\v 1 \x - \xo 19.1: \xt Mk 10.46.\x*Jesu sì wọ Jeriko lọ, ó sì ń kọjá láàrín rẹ̀.
\v 2 Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan wà tí a ń pè ní Sakeu, ó sì jẹ́ olórí agbowó òde kan, ó sì jẹ́ ọlọ́rọ̀.
\v 3 Ó sì ń fẹ́ láti rí ẹni tí Jesu jẹ́: kò sì lè rí i, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti nítorí tí òun jẹ́ ènìyàn kúkúrú.
\v 4 Ó sì súré síwájú, ó gun orí igi sikamore kan, kí ó bà lè rí i: nítorí tí yóò kọjá lọ níhà ibẹ̀.
\p
\v 5 Nígbà tí Jesu sì dé ibẹ̀, ó gbé ojú sókè, ó sì rí i, ó sì wí fún un pé, \wj “Sakeu! Yára, kí o sì sọ̀kalẹ̀; nítorí pé èmi yóò wọ ilé rẹ lónìí.”\wj*
\v 6 Ó sì yára, ó sọ̀kalẹ̀, ó sì fi ayọ̀ gbà á.
\p
\v 7 \x - \xo 19.7: \xt Lk 5.29-30; 15.1-2.\x*Nígbà tí wọ́n sì rí i, gbogbo wọn ń kùn, wí pé, “Ó lọ bá ọkùnrin ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ní àlejò.”
\p
\v 8 \x - \xo 19.8: \xt Lk 7.13; 3.14; Ek 22.1; Le 6.5; Nu 5.6-7.\x*Sakeu sì dìde, ó sì wí fún Olúwa pé, “Wò ó, Olúwa, ààbọ̀ ohun ìní mi ni mo fi fún tálákà; bí mo bá sì fi èké gba ohun kan lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, èmi san án padà ní ìlọ́po mẹ́rin!”
\p
\v 9 \x - \xo 19.9: \xt Lk 3.8; 13.16; Ro 4.16.\x*Jesu sì wí fún un pé, \wj “Lónìí ni ìgbàlà wọ ilé yìí, níwọ̀n bí òun pẹ̀lú ti jẹ́ ọmọ Abrahamu.\wj*
\v 10 \wj Nítorí Ọmọ Ènìyàn dé láti wá àwọn tí ó nù kiri, àti láti gbà wọ́n là.”\wj*
\s1 Òwe mina mẹ́wàá
\p
\v 11 \x - \xo 19.11: \xt Lk 9.51; 13.22; 17.11; 18.31; 9.27.\x*Nígbà tí wọ́n sì ń gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó sì tẹ̀síwájú láti pa òwe kan, nítorí tí ó súnmọ́ Jerusalẹmu, àti nítorí tí wọn ń rò pé, ìjọba Ọlọ́run yóò farahàn nísinsin yìí.
\v 12 \x - \xo 19.12-28: \xt Mt 25.14-30.\x*\x - \xo 19.12: \xt Mk 13.34.\x*Ó sì wí pé, \wj “Ọkùnrin ọlọ́lá kan lọ sí ìlú òkèrè láti gba ìjọba kí ó sì padà.\wj*
\v 13 \wj Ó sì pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fi owó mina mẹ́wàá fún wọn, ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ máa ṣòwò títí èmi ó fi dé!\wj*
\p
\v 14 \wj “Ṣùgbọ́n àwọn ará ìlù rẹ̀ kórìíra rẹ̀, wọ́n sì rán ikọ̀ tẹ̀lé e, wí pé, Àwa kò fẹ́ kí ọkùnrin yìí jẹ ọba lórí wa.\wj*
\p
\v 15 \wj “Nígbà tí ó gba ìjọba tan, tí ó padà dé, ó pàṣẹ pé, kí a pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ wọ̀nyí tí òun ti fi owó fún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí kí ó le mọ iye èrè tí olúkúlùkù ti jẹ nínú iṣẹ́ òwò wọn.\wj*
\p
\v 16 \wj “Èyí èkínní sì wá, ó wí pé, Olúwa, owó mina rẹ jèrè owó mina mẹ́wàá sí i.\wj*
\p
\v 17 \x - \xo 19.17: \xt Lk 16.10.\x*\wj “Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé, O ṣeun, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere! Nítorí tí ìwọ ṣe olóòtítọ́ ní ohun kínkínní, gba àṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá.\wj*
\p
\v 18 \wj “Èyí èkejì sì wá, ó wí pé, Olúwa, owó mina rẹ jèrè owó mina márùn.\wj*
\p
\v 19 \wj “Olúwa rẹ sì wí fún un pẹ̀lú pé, Ìwọ pẹ̀lú joyè ìlú márùn-ún!\wj*
\p
\v 20 \wj “Òmíràn sì wá, ó wí pé, Olúwa, wò ó owó mina rẹ tí ń bẹ lọ́wọ́ mi ni mo dì sínú aṣọ pélébé kan;\wj*
\v 21 \wj nítorí mo bẹ̀rù rẹ, àti nítorí tí ìwọ ṣe òǹrorò ènìyàn, ìwọ a máa mú èyí tí ìwọ kò fi lélẹ̀, ìwọ a sì máa ká èyí tí ìwọ kò gbìn!\wj*
\p
\v 22 \wj “Olúwa rẹ sì wí fún un pé, Ní ẹnu ara rẹ náà ni èmi ó ṣe ìdájọ́ rẹ, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé òǹrorò ènìyàn ni mí, pé, èmi a máa mú èyí tí èmi kò fi lélẹ̀ èmi a sì máa ká èyí tí èmi kò gbìn.\wj*
\v 23 \wj Èéha sì ti ṣe tí ìwọ kò fi owó mi pamọ́ sí ilé ìfowópamọ́, pé nígbà tí mo bá dé, èmi ìbá ti béèrè rẹ̀ pẹ̀lú èlé?\wj*
\p
\v 24 \wj “Ó sì wí fún àwọn tí ó dúró létí ibẹ̀ pé, ‘Ẹ gba owó mina náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì fi í fún ẹni tí ó ní owó mina mẹ́wàá.\wj*
\p
\v 25 \wj “Wọ́n sì wí fún un pé, Olúwa, ó ní owó mina mẹ́wàá.\wj*
\p
\v 26 \x - \xo 19.26: \xt Mt 13.12; Mk 4.25; Lk 8.18.\x*\wj “Mo wí fún yín pé, Ẹnikẹ́ni tí ó ní, ni a ó fi fún, àti lọ́dọ̀ ẹni tí kò ní èyí tí ó ní pàápàá a ó gbà á lọ́wọ́ rẹ̀.\wj*
\v 27 \wj Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá mi wọ̀nyí, tí kò fẹ́ kí èmi jẹ ọba lórí wọn ẹ mú wọn wá ìhín yìí, kí ẹ sì pa wọ́n níwájú mi!’ ”\wj*
\s1 Ó wọ ilé pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
\p
\v 28 \x - \xo 19.28: \xt Mk 10.32.\x*Nígbà tí ó sì ti wí nǹkan wọ̀nyí tan, ó lọ síwájú, ó ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu.
\v 29 \x - \xo 19.29-38: \xt Mt 21.1-9; Mk 11.1-10; Jh 12.12-18.\x*Ó sì ṣe, nígbà tí ó súnmọ́ Betfage àti Betani ní òkè tí a ń pè ní òkè olifi, ó rán àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
\v 30 Wí pé, \wj “Ẹ lọ sí ìletò tí ó kọjú sí yín; nígbà tí ẹ̀yin bá wọ̀ ọ́ lọ, ẹ̀yin ó rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí a so, tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí, ẹ tú u, kí ẹ sì fà á wá.\wj*
\v 31 \wj Bí ẹnikẹ́ni bá sì bi yín pé, Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tú u? Kí ẹ̀yin wí báyìí pé, Olúwa ń fẹ́ lò ó.’ ”\wj*
\p
\v 32 \x - \xo 19.32: \xt Lk 22.13.\x*Àwọn tí a rán sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó ti wí fún wọn.
\v 33 Bí wọ́n sì ti ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn Olúwa rẹ̀ bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà?”
\p
\v 34 \x - \xo 19.34: \xt Lk 7.13.\x*Wọ́n sì wí pé, “Olúwa fẹ́ lò ó.”
\p
\v 35 Wọ́n sì fà á tọ Jesu wá, wọ́n sì tẹ́ aṣọ sí ẹ̀yìn ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, wọ́n sì gbé Jesu kà á.
\v 36 \x - \xo 19.36: \xt 2Ọb 9.13.\x*Bí ó sì ti ń lọ wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà.
\p
\v 37 Bí ó sì ti súnmọ́ etí ibẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olifi, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀, wọ́n sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run, nítorí iṣẹ́ ńlá gbogbo tí wọ́n ti rí,
\q1
\v 38 \x - \xo 19.38: \xt Sm 118.26; Lk 13.35; 2.14.\x*wí pé, “Olùbùkún ni ọba tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa!”
\b
\q1 “Àlàáfíà ní ọ̀run, àti ògo ni òkè ọ̀run!”
\p
\v 39 \x - \xo 19.39-40: \xt Mt 21.15-16; Hb 2.11.\x*Àwọn kan nínú àwọn Farisi nínú àwùjọ náà sì wí fún un pé, “Olùkọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ wí.”
\p
\v 40 Ó sì dá wọn lóhùn, ó wí fún wọn pé, \wj “Mo wí fún yín, bí àwọn wọ̀nyí bá pa ẹnu wọn mọ́, àwọn òkúta yóò kígbe sókè.”\wj*
\p
\v 41 \x - \xo 19.41: \xt Lk 13.33-34.\x*Nígbà tí ó sì súnmọ́ etílé, ó síjú wo ìlú náà, ó sọkún sí i lórí,
\v 42 Ó ń wí pé, \wj “Ìbá ṣe pé ìwọ mọ̀, lónìí yìí, àní ìwọ, ohun tí í ṣe tí àlàáfíà rẹ! Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n pamọ́ kúrò lójú rẹ.\wj*
\v 43 \x - \xo 19.43: \xt Lk 21.21-24; 21.6; Isa 29.3; Jr 6.6; El 4.2.\x*\wj Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ fún ọ, tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò mọ odi bèbè yí ọ ká, àní tí wọn yóò sì yí ọ ká, wọn ó sì ká ọ mọ́ níhà gbogbo.\wj*
\v 44 \x - \xo 19.44: \xt 1Pt 2.12.\x*\wj Wọn ó sì wó ọ palẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ; wọn kì yóò sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí ara wọn; nítorí ìwọ kò mọ ọjọ́ ìbẹ̀wò rẹ.”\wj*
\s1 Jesu nínú tẹmpili
\p
\v 45 \x - \xo 19.45-46: \xt Mt 21.12-13; Mk 11.15-17; Jh 2.13-17.\x*Ó sì wọ inú tẹmpili lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tà nínú rẹ̀ sóde;
\v 46 Ó sì wí fún wọn pé, \wj “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, Ilé mi yóò jẹ́ ilé àdúrà? Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ihò àwọn ọlọ́ṣà.”\wj*
\p
\v 47 \x - \xo 19.47-48: \xt Mk 11.18; Lk 21.37; 22.53.\x*Ó sì ń kọ́ni lójoojúmọ́ ní tẹmpili, ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, àti àwọn olórí àwọn ènìyàn ń wá ọ̀nà láti pa á.
\v 48 Wọn kò sì rí nǹkan kan tí wọn ìbá ṣe; nítorí gbogbo ènìyàn ṣù mọ́ ọn láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.
\c 20
\s1 Wọ́n béèrè nípa àṣẹ Jesu
\p
\v 1 \x - \xo 20.1-8: \xt Mt 21.23-27; Mk 11.27-33.\x*Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tẹmpili tí ó sì ń wàásù ìyìnrere, àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, pẹ̀lú àwọn àgbàgbà dìde sí i.
\v 2 \x - \xo 20.2: \xt Jh 2.18.\x*Wọ́n sì wí fún un pé, “Sọ fún wa, àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Tàbí ta ni ó fún ọ ní àṣẹ yìí?”
\p
\v 3 Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, \wj “Èmi pẹ̀lú yóò sì bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan; ẹ sì fi ìdáhùn fún mi.\wj*
\v 4 \wj Ìtẹ̀bọmi Johanu, láti ọ̀run wá ni tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn?”\wj*
\p
\v 5 Wọ́n sì bá ara wọn gbèrò pé, “Bí àwa bá wí pé, Láti ọ̀run wá ni, òun yóò wí pé, Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́?
\v 6 \x - \xo 20.6: \xt Mt 14.5; Lk 7.29.\x*Ṣùgbọ́n bí àwa bá sì wí pé, Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn, gbogbo ènìyàn ni yóò sọ wá ní òkúta, nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé, wòlíì ni Johanu.”
\p
\v 7 Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Àwa kò mọ̀ ibi tí ó ti wá.”
\p
\v 8 Jesu sì wí fún wọn pé, \wj “Ǹjẹ́ èmi kì yóò wí fún yín àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.”\wj*
\s1 Òwe àwọn ayálégbé
\p
\v 9 \x - \xo 20.9-19: \xt Mt 21.33-46; Mk 12.1-12.\x*\x - \xo 20.9: \xt Isa 5.1-7; Mt 25.14.\x*Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa òwe yìí fún àwọn ènìyàn pé, \wj “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan, ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùṣọ́gbà, ó sì lọ sí àjò fún ìgbà pípẹ́.\wj*
\v 10 \wj Nígbà tí ó sì tó àkókò, ó rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ kan sí àwọn olùṣọ́gbà náà, kí wọn lè fún un nínú èso ọgbà àjàrà náà, ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú lù ú, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.\wj*
\v 11 \wj Ó sì tún rán ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn, wọ́n sì lù ú pẹ̀lú, wọ́n sì jẹ ẹ́ ní yà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.\wj*
\v 12 \wj Ó sì tún rán ẹ̀kẹta: wọ́n sì sá a lọ́gbẹ́ pẹ̀lú, wọ́n sì tì í jáde.\wj*
\p
\v 13 \wj “Nígbà náà ni Olúwa ọgbà àjàrà wí pé, Èwo ni èmi ó ṣe? Èmi ó rán ọmọ mi àyànfẹ́ lọ: bóyá nígbà tí wọ́n bá rí i, wọn yóò bu ọlá fún un.\wj*
\p
\v 14 \wj “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn alágbàtọ́jú náà rí i, wọ́n bá ara wọn gbèrò pé, Èyí ni àrólé; ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí ogún rẹ̀ lè jẹ́ ti wa.\wj*
\v 15 \wj Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tì í jáde sẹ́yìn ọgbà àjàrà, wọ́n sì pa á.\wj*
\p \wj “Ǹjẹ́ kín ni olúwa ọgbà àjàrà náà yóò ṣe sí wọn?\wj*
\v 16 \x - \xo 20.16: \xt Ap 13.46; 18.6; 28.28.\x*\wj Yóò wá, yóò sì pa àwọn alágbàtọ́jú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà náà fún àwọn ẹlòmíràn.”\wj*
\p Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n ní, “Kí a má ri i!”
\p
\v 17 \x - \xo 20.17: \xt Sm 118.22-23; Ap 4.11; 1Pt 2.6-7.\x*Nígbà tí ó sì wò wọ́n, ó ní, \wj “Èwo ha ni èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:\wj*
\q1 \wj “Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,\wj*
\q2 \wj òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé?\wj*
\m
\v 18 \x - \xo 20.18: \xt Isa 8.14-15.\x*\wj Ẹnikẹ́ni tí ó ṣubú lu òkúta náà yóò fọ́; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí òun bá ṣubú lù, yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.”\wj*
\p
\v 19 \x - \xo 20.19: \xt Lk 19.47.\x*Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà láti mú un ní wákàtí náà; ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé, ó pa òwe yìí mọ́ wọn.
\s1 Sísan owó orí fún Kesari
\p
\v 20 \x - \xo 20.20-26: \xt Mt 22.15-22; Mk 12.13-17.\x*Wọ́n sì ń ṣọ́ ọ, wọ́n sì rán àwọn ayọ́lẹ̀wò tí wọ́n ṣe ara wọn bí ẹni pé olóòtítọ́ ènìyàn, kí wọn ba à lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, kí wọn ba à lè fi í lé agbára àti àṣẹ Baálẹ̀ lọ́wọ́.
\v 21 \x - \xo 20.21: \xt Jh 3.2.\x*Wọ́n sì bí i, pé, “Olùkọ́ àwa mọ̀ pé, ìwọ a máa sọ̀rọ̀ fún ni, ìwọ a sì máa kọ́ni bí ó ti tọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í ṣe ojúsàájú ẹnìkan ṣùgbọ́n ìwọ ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run lóòtítọ́.
\v 22 Ǹjẹ́ ó tọ́ fún wa láti máa san owó òde fún Kesari, tàbí kò tọ́?”
\p
\v 23 Ṣùgbọ́n ó kíyèsi àrékérekè wọn, ó sì wí fún wọn pé,
\v 24 \wj “Ẹ fi owó idẹ kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ti ta ni ó wà níbẹ̀?”\wj*
\p Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ti Kesari ni.”
\p
\v 25 \x - \xo 20.25: \xt Mt 22.23-33; Mk 12.18-27.\x*Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Ǹjẹ́ ẹ fi ohun tí i ṣe ti Kesari fún Kesari, àti ohun tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”\wj*
\p
\v 26 Wọn kò sì lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú níwájú àwọn ènìyàn: ẹnu sì yà wọ́n sí ìdáhùn rẹ̀, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́.
\s1 Àjíǹde àti ìgbéyàwó
\p
\v 27 \x - \xo 20.27-38: \xt Mt 22.23-33; Mk 12.18-27.\x*\x - \xo 20.27: \xt Ap 4.1-2; 23.6-10.\x*Àwọn Sadusi kan sì tọ̀ ọ́ wá, àwọn tí wọ́n ń wí pé àjíǹde òkú kò sí wọ́n sì bi í,
\v 28 \x - \xo 20.28: \xt De 25.5.\x*wí pé, “Olùkọ́, Mose kọ̀wé fún wa pé, Bí arákùnrin ẹnìkan bá kú, ní àìlọ́mọ, tí ó sì ní aya, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó lè gbé irú-ọmọ dìde fún arákùnrin rẹ̀.
\v 29 Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan ti wà; èkínní gbé ìyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ.
\v 30 Èkejì sì ṣú u lópó: òun sì kú ní àìlọ́mọ.
\v 31 Ẹ̀kẹta sì ṣú u lópó: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn méjèèje pẹ̀lú: wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀, wọ́n sì kú.
\v 32 Nígbẹ̀yìn pátápátá obìnrin náà kú pẹ̀lú.
\v 33 Ǹjẹ́ ní àjíǹde òkú, aya ti ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Nítorí àwọn méjèèje ni ó sá à ni í ní aya.”
\p
\v 34 Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, \wj “Àwọn ọmọ ayé yìí a máa gbéyàwó, wọn a sì máa fa ìyàwó fún ni.\wj*
\v 35 \wj Ṣùgbọ́n àwọn tí a kà yẹ láti jogún ìyè ayérayé náà, àti àjíǹde kúrò nínú òkú, wọn kì í gbéyàwó, wọn kì í sì í fa ìyàwó fún ni.\wj*
\v 36 \wj Nítorí wọn kò lè kú mọ́; nítorí tí wọn bá àwọn angẹli dọ́gba; àwọn ọmọ Ọlọ́run sì ni wọ́n, nítorí wọ́n di àwọn ọmọ àjíǹde.\wj*
\v 37 \x - \xo 20.37: \xt Ek 3.6.\x*\wj Ní ti pé a ń jí àwọn òkú dìde, Mose tìkára rẹ̀ sì ti fihàn nínú igbó, nígbà tí ó pe Olúwa ni Ọlọ́run Abrahamu, àti Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu.\wj*
\v 38 \wj Bẹ́ẹ̀ ni òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè, nítorí gbogbo wọn wà láààyè fún un.”\wj*
\p
\v 39 \x - \xo 20.39: \xt Mk 12.28.\x*Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé dá a lóhùn, pé, “Olùkọ́ ìwọ wí rere!”
\v 40 \x - \xo 20.40: \xt Mk 12.34; Mt 22.46.\x*Wọn kò sì jẹ́ bi í léèrè ọ̀rọ̀ kan mọ́.
\s1 Ọmọ ta ni Jesu n ṣe
\p
\v 41 \x - \xo 20.41-44: \xt Mt 22.41-45; Mk 12.35-37; Sm 110.1.\x*Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Èéṣe tí wọ́n fi ń wí pé, ọmọ Dafidi ni Kristi?\wj*
\v 42 \wj Dafidi tìkára rẹ̀ sì wí nínú ìwé Saamu pé:\wj*
\q1 \wj “Olúwa sọ fún Olúwa mi pé:\wj*
\q2 \wj “Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi\wj*
\q1
\v 43 \wj títí èmi ó fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ\wj*
\q2 \wj di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’\wj*
\m
\v 44 \wj Ǹjẹ́ bí Dafidi bá pè é ní Olúwa. Òun ha sì ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”\wj*
\p
\v 45 \x - \xo 20.45-47: \xt Mk 12.38-40; Mt 23.6-7; Lk 11.43; 14.7-11.\x*Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní etí gbogbo ènìyàn pé,
\v 46 \wj “Ẹ máa kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn akọ̀wé, tí wọ́n fẹ́ láti máa rìn nínú aṣọ gígùn, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu, àti ipò ọlá ní ibi àsè;\wj*
\v 47 \wj Àwọn tí ó jẹ ilé àwọn opó run, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn, àwọn wọ̀nyí náà ni yóò jẹ̀bi pọ̀jù.”\wj*
\c 21
\s1 Oore opó
\p
\v 1 \x - \xo 21.1-4: \xt Mk 12.41-44.\x*Nígbà tí ó sì gbé ojú sókè, ó rí àwọn ọlọ́rọ̀ ń fi ẹ̀bùn wọn sínú àpótí ìṣúra.
\v 2 Ó sì rí tálákà opó kan pẹ̀lú, ó ń sọ owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì síbẹ̀.
\v 3 Ó sì wí pé, \wj “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, tálákà opó yìí fi sí i ju gbogbo wọn lọ,\wj*
\v 4 \wj nítorí gbogbo àwọn wọ̀nyí fi sínú ẹ̀bùn Ọlọ́run láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní wọn; ṣùgbọ́n òun nínú àìní rẹ̀ ó sọ gbogbo ohun ìní rẹ̀ tí ó ní sínú rẹ̀.”\wj*
\s1 Àwọn àmì ìkẹyìn ayé
\p
\v 5 \x - \xo 21.5-23: \xt Mt 24.1-19; Mk 13.1-17.\x*Bí àwọn kan sì ti ń sọ̀rọ̀ nípa tẹmpili, bí a ti fi òkúta dáradára àti ẹ̀bùn ṣe é ní ọ̀ṣọ́, fun Ọlọ́run, Jesu wí pé
\v 6 \x - \xo 21.6: \xt Lk 19.43-44; Mk 14.58; 15.29; Ap 6.14.\x*\wj “Ohun tí ẹ̀yin ń wò wọ̀nyí, ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.”\wj*
\p
\v 7 \x - \xo 21.7: \xt Lk 17.20; Ap 1.6.\x*Wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, pé, “Olùkọ́, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò rí bẹ́ẹ̀? Àti àmì kín ni yóò wà, nígbà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ?”
\p
\v 8 \x - \xo 21.8: \xt Lk 17.23; Mk 13.21; 1Jh 2.18.\x*Ó sì wí pé, \wj “Ẹ máa kíyèsára, kí a má bá à mú yín ṣìnà: nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ní orúkọ mi, tí yóò máa wí pé, Èmi ní Kristi náà àkókò náà sì kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹ má ṣe tọ̀ wọ́n lẹ́yìn.\wj*
\v 9 \wj Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá gbúròó ogun àti ìdágìrì, ẹ má ṣe fòyà; nítorí nǹkan wọ̀nyí ní láti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe lójúkan náà.”\wj*
\p
\v 10 \x - \xo 21.10: \xt 2Ki 15.6; Isa 19.2.\x*Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, \wj “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba.\wj*
\v 11 \wj Ilẹ̀-rírì ńlá yóò sì wà káàkiri, àti ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn; ohun ẹ̀rù, àti àmì ńlá yóò sì ti ọ̀run wá.\wj*
\p
\v 12 \x - \xo 21.12-17: \xt Mt 10.17-21.\x*\x - \xo 21.12: \xt Ap 25.24; Jh 16.2.\x*\wj “Ṣùgbọ́n ṣáájú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọn ó nawọ́ mú yín, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí yín, wọn ó mú yín lọ sí Sinagọgu, àti sínú túbú, wọn ó mú yín lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba àti àwọn ìjòyè nítorí orúkọ mi.\wj*
\v 13 \x - \xo 21.13: \xt Fp 1.12.\x*\wj Ẹ o si jẹ́rìí nípa mi.\wj*
\v 14 \x - \xo 21.14-15: \xt Lk 12.11-12.\x*\wj Nítorí náà ẹ pinnu rẹ̀ ní ọkàn yín pé ẹ ko ronú ṣáájú, bí ẹ ó ti dáhùn.\wj*
\v 15 \wj Nítorí tí èmi ó fún yín ní ẹnu àti ọgbọ́n, tí gbogbo àwọn ọ̀tá yín kì yóò lè sọ̀rọ̀-òdì sí, tí wọn kì yóò sì lè kò lójú.\wj*
\v 16 \x - \xo 21.16: \xt Lk 12.52-53.\x*\wj A ó sì fi yín hàn láti ọwọ́ àwọn òbí yín wá, àti àwọn arákùnrin, àti àwọn ìbátan, àti àwọn ọ̀rẹ́; òun ó sì mú kì a pa nínú yín.\wj*
\v 17 \x - \xo 21.17: \xt Mt 10.22; Jh 15.18-25.\x*\wj A ó sì kórìíra yín lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí orúkọ mi.\wj*
\v 18 \x - \xo 21.18: \xt Lk 12.7; Mt 10.30; Ap 27.34; 1Sa 14.45.\x*\wj Ṣùgbọ́n irun orí yín kan kì yóò ṣègbé.\wj*
\v 19 \x - \xo 21.19: \xt Mt 10.22; If 2.7.\x*\wj Nínú ìdúró ṣinṣin yín ni ẹ̀yin ó jèrè ọkàn yín.\wj*
\p
\v 20 \x - \xo 21.20-22: \xt Lk 19.41-44; 23.28-31; 17.31.\x*\wj “Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí ti a fi ogun yí Jerusalẹmu ká, ẹ mọ̀ nígbà náà pé, ìsọdahoro rẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀.\wj*
\v 21 \wj Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Judea sálọ sórí òkè; àti àwọn tí ń bẹ láàrín rẹ̀ kí wọn jáde kúrò; kí àwọn tí ó sì ń bọ̀ ní ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀ wá.\wj*
\v 22 \wj Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ni ọjọ́ wọ̀nyí, kì a lè mú ohun gbogbo tí a ti kọ̀wé rẹ̀ ṣẹ.\wj*
\v 23 \x - \xo 21.23: \xt Lk 23.29.\x*\wj Ṣùgbọ́n ègbé ni fún àwọn tí ó lóyún, àti àwọn tí ó fi ọyàn fún ọmọ mu ní ọjọ́ wọ̀nyí! Nítorí tí ìpọ́njú púpọ̀ yóò wà lórí ilẹ̀ àti ìbínú sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí.\wj*
\v 24 \x - \xo 21.24: \xt Ro 11.25; Isa 63.18; Da 8.13; If 11.2.\x*\wj Wọn ó sì ti ojú idà ṣubú, a ó sì dìwọ́n ní ìgbèkùn lọ sí orílẹ̀-èdè gbogbo; Jerusalẹmu yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aláìkọlà, títí àkókò àwọn aláìkọlà yóò fi kún.\wj*
\p
\v 25 \x - \xo 21.25-27: \xt Mt 24.29-30; Mk 13.24-26.\x*\x - \xo 21.25: \xt If 6.12-13; Isa 13.10; Jl 2.10; Sf 1.15.\x*\wj “Àmì yóò sì wà ní oorun, àti ní òṣùpá, àti ní ìràwọ̀; àti lórí ilẹ̀ ayé ìdààmú fún àwọn orílẹ̀-èdè nínú ìpayà híhó Òkun àti ìgbì omi.\wj*
\v 26 \wj Àyà àwọn ènìyàn yóò máa já fún ìbẹ̀rù, àti ìrètí nǹkan wọ̀nyí tí ń bọ̀ sórí ayé: nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì tìtì.\wj*
\v 27 \x - \xo 21.27: \xt Lk 9.27; Da 7.13-14.\x*\wj Nígbà náà ni wọn ó sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò máa bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.\wj*
\v 28 \x - \xo 21.28: \xt Lk 18.7-8.\x*\wj Ṣùgbọ́n nígbà tí nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ, ǹjẹ́ kí ẹ wo òkè, kí ẹ sì gbé orí yín sókè; nítorí ìdáǹdè yín kù sí dẹ̀dẹ̀.”\wj*
\p
\v 29 \x - \xo 21.29-33: \xt Mt 24.32-35; Mk 13.28-31.\x*Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, \wj “Ẹ kíyèsi igi ọ̀pọ̀tọ́, àti sí gbogbo igi.\wj*
\v 30 \wj Nígbà tí wọ́n bá rúwé, ẹ̀yin rí i, ẹ sì mọ̀ fúnra ara yín pé, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kù fẹ́ẹ́rẹ́.\wj*
\v 31 \wj Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin, nígbà tí ẹ̀yin bá rí nǹkan wọ̀nyí tí o ṣẹ, kí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀.\wj*
\p
\v 32 \x - \xo 21.32: \xt Lk 9.27.\x*\wj “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ìran yìí kì yóò rékọjá, títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ.\wj*
\v 33 \x - \xo 21.33: \xt Lk 16.17.\x*\wj Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá.\wj*
\p
\v 34 \x - \xo 21.34: \xt Lk 12.45; Mk 4.19; 1Tẹ 5.6-7.\x*\wj “Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsára yín, kí ọkàn yín má ṣe kún fún wọ̀bìà, àti fún ọtí àmupara, àti fún àníyàn ayé yìí, tí ọjọ́ náà yóò sì fi dé bá yín lójijì bí ìkẹ́kùn.\wj*
\v 35 \wj Nítorí bẹ́ẹ̀ ni yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé orí gbogbo ilẹ̀ ayé.\wj*
\v 36 \x - \xo 21.36: \xt Mk 13.33.\x*\wj Ǹjẹ́ kì ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ ba à lè la gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí yóò ṣẹlẹ̀, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ Ènìyàn.”\wj*
\p
\v 37 \x - \xo 21.37: \xt Lk 19.47; Mk 11.19.\x*Lọ́sàn án, Jesu a sì máa kọ́ni ní tẹmpili, lóru, a sì máa jáde lọ í wọ̀ ní òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi.
\v 38 Gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá ní tẹmpili ní kùtùkùtù òwúrọ̀, láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.
\c 22
\s1 Judasi gbà láti da Jesu
\p
\v 1 \x - \xo 22.1-2: \xt Mt 26.2-5; Mk 14.1-2; Jh 11.47-53.\x*Àjọ ọdún àìwúkàrà tí à ń pè ní Ìrékọjá sì kù fẹ́ẹ́rẹ́.
\v 2 Àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà tí wọn ìbá gbà pa á; nítorí tí wọn ń bẹ̀rù àwọn ènìyàn.
\v 3 Satani sì wọ inú Judasi, tí à ń pè ní Iskariotu, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá.
\v 4 Ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, ó lọ láti bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ gbèrò pọ̀, bí òun yóò tí fi í lé wọn lọ́wọ́.
\v 5 \x - \xo 22.5-6: \xt Mt 26.14-16; Mk 14.10-11; Jh 13.2.\x*Wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì bá a dá májẹ̀mú láti fún un ní owó.
\v 6 Ó sì gbà; ó sì ń wá àkókò tí ó wọ̀, láti fi í lé wọn lọ́wọ́ láìsí ariwo.
\s1 Oúnjẹ alẹ́ Olúwa
\p
\v 7 \x - \xo 22.7-13: \xt Mt 26.17-19; Mk 14.12-16.\x*\x - \xo 22.7: \xt El 12.18-20; De 16.5-8.\x*Ọjọ́ àìwúkàrà pé, nígbà tí wọ́n ní láti pa ọ̀dọ́-àgùntàn ìrékọjá fún ìrúbọ.
\v 8 \x - \xo 22.8: \xt Ap 3.1; Lk 19.29.\x*Ó sì rán Peteru àti Johanu, wí pé, \wj “Ẹ lọ pèsè ìrékọjá fún wa, kí àwa ó jẹ.”\wj*
\p
\v 9 Wọ́n sì wí fún un pé, “Níbo ni ìwọ ń fẹ́ kí á pèsè sílẹ̀?”
\p
\v 10 Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Kíyèsi i, nígbà tí ẹ̀yin bá ń wọ ìlú lọ, ọkùnrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóò pàdé yín, ẹ bá a lọ sí ilé tí ó bá wọ̀,\wj*
\v 11 \wj kí ẹ sì wí fún baálé ilé náà pé, Olùkọ́ wí fún ọ pé, níbo ni gbàngàn àpèjẹ náà gbé wà, níbi tí èmi ó gbé jẹ ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?\wj*
\v 12 \wj Òun ó sì fi gbàngàn ńlá kan lókè ilé hàn yín, tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin pèsè sílẹ̀.”\wj*
\p
\v 13 Wọ́n sì lọ wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó tí sọ fún wọn, wọ́n sì pèsè ìrékọjá sílẹ̀.
\p
\v 14 \x - \xo 22.14: \xt Mt 26.20; Mk 14.17; Jh 13.17.\x*Nígbà tí àkókò sì tó, ó jókòó àti àwọn aposteli pẹ̀lú rẹ̀.
\v 15 \x - \xo 22.15: \xt Lk 12.49-50.\x*Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Tinútinú ni èmi fẹ́ fi bá yín jẹ ìrékọjá yìí, kí èmi tó jìyà.\wj*
\v 16 \x - \xo 22.16: \xt Lk 14.15.\x*\wj Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò jẹ nínú rẹ̀ mọ́, títí a ó fi mú un ṣẹ ní ìjọba Ọlọ́run.”\wj*
\p
\v 17 \x - \xo 22.17: \xt Mt 26.27; Mk 14.23; 1Kọ 10.16.\x*Ó sì gba ago, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó wí pé, \wj “Gba èyí, kí ẹ sì pín in láàrín ara yín.\wj*
\v 18 \x - \xo 22.18: \xt Mt 26.29; Mk 14.25.\x*\wj Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò mu nínú èso àjàrà mọ́, títí ìjọba Ọlọ́run yóò fi dé.”\wj*
\p
\v 19 \x - \xo 22.19: \xt Mt 26.26; Mk 14.22; 1Kọ 10.16; 11.23-26; Lk 9.16.\x*Ó sì mú àkàrà, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́ ó bù ú, ó sì fi fún wọn, ó wí pé, \wj “Èyí ni ara mí tí a fi fún yín, ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”\wj*
\p
\v 20 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú ago wáìnì, ó wí pé, \wj “Ago yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, tí a ta sílẹ̀ fún yín.\wj*
\v 21 \x - \xo 22.21-23: \xt Mt 26.21-24; Mk 14.18-21; Sm 41.9; Jh 13.21-30.\x*\wj Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsi i, ọwọ́ ẹni tí yóò fi mí hàn wà pẹ̀lú mi lórí tábìlì.\wj*
\v 22 \wj Ọmọ Ènìyàn ń lọ nítòótọ́ bí a tí pinnu rẹ̀, ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà nípasẹ̀ ẹni tí a gbé ti fi í hàn.”\wj*
\v 23 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè láàrín ara wọn, ta ni nínú wọn tí yóò ṣe nǹkan yìí.
\p
\v 24 \x - \xo 22.24: \xt Lk 9.46; Mk 9.34.\x*Ìjà kan sì ń bẹ láàrín wọn, ní ti ẹni tí a kà sí olórí nínú wọn.
\v 25 \x - \xo 22.25-27: \xt Mt 20.25-28; Mk 10.42-45; Jh 13.3-16.\x*Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Àwọn ọba aláìkọlà a máa fẹlá lórí wọn, a sì máa pe àwọn aláṣẹ wọn ní olóore.\wj*
\v 26 \x - \xo 22.26: \xt Lk 9.48.\x*\wj Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba pọ̀jù nínú yín kí ó jẹ́ bí ẹni tí o kéré ju àbúrò; ẹni tí ó sì ṣe olórí, bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́.\wj*
\v 27 \wj Nítorí ta ni ó pọ̀jù, ẹni tí ó jókòó tí oúnjẹ, tàbí ẹni tí ó ń ṣe ìránṣẹ́. Ẹni tí ó jókòó ti oúnjẹ kọ́ bí? Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ láàrín yín bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́.\wj*
\v 28 \x - \xo 22.28-30: \xt Mt 19.28.\x*\x - \xo 22.28: \xt Lk 4.13; Hb 2.18; 4.15.\x*\wj Ẹ̀yin ni àwọn tí ó ti dúró tì mí nínú ìdánwò mi.\wj*
\v 29 \x - \xo 22.29: \xt Mk 14.24; Hb 9.20.\x*\wj Mo sì yan ìjọba fún yín, gẹ́gẹ́ bí Baba mi ti yàn fún mi.\wj*
\v 30 \x - \xo 22.30: \xt Mk 10.37; If 3.21; 20.4.\x*\wj Kí ẹ̀yin lè máa jẹ, kí ẹ̀yin sì lè máa mu lórí tábìlì mi ní ìjọba mi, kí ẹ̀yin lè jókòó lórí ìtẹ́, àti kí ẹ̀yin lè máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá.”\wj*
\p
\v 31 \x - \xo 22.31: \xt Jb 1.6-12; Am 9.9.\x*Olúwa sì wí pé, \wj “Simoni, Simoni, wò ó, Satani fẹ́ láti gbà ọ́, kí ó lè kù ọ́ bí alikama.\wj*
\v 32 \x - \xo 22.32: \xt Jh 17.15; 21.15-17.\x*\wj Ṣùgbọ́n mo ti gbàdúrà fún ọ, kí ìgbàgbọ́ rẹ má ṣe yẹ̀; àti ìwọ nígbà tí ìwọ bá sì padà bọ̀ sípò, mú àwọn arákùnrin rẹ lọ́kàn le.”\wj*
\p
\v 33 \x - \xo 22.33-34: \xt Mt 26.33-35; Mk 14.29-31; Jh 13.37-38.\x*Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, mo múra tán láti bá ọ lọ sínú túbú, àti sí ikú.”
\p
\v 34 Ó sì wí pé, \wj “Mo wí fún ọ, Peteru, àkùkọ kì yóò kọ lónìí tí ìwọ ó fi sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, ìwọ kò mọ̀ mí.”\wj*
\p
\v 35 \x - \xo 22.35: \xt Lk 10.4; Mt 10.9.\x*Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Nígbà tí mo rán yín lọ láìní àpò-owó, àti àpò, àti bàtà, ọ̀dá ohun kan dá yín bí?”\wj*
\p Wọ́n sì wí pé, “Rárá!”
\p
\v 36 \x - \xo 22.36: \xt Lk 22.49-50.\x*Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, \wj “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹni tí ó bá ní àpò-owó kí ó mú un, àti àpò pẹ̀lú; ẹni tí kò bá sì ní idà, kí ó ta aṣọ rẹ̀, kí ó sì fi ra ọ̀kan.\wj*
\v 37 \x - \xo 22.37: \xt Isa 53.12.\x*\wj Nítorí mo wí fún yín pé, Èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ kò lè ṣe kí ó má ṣẹ lára mi, a sì kà á mọ́ àwọn arúfin. Nítorí àwọn ohun wọ̀nyí nípa ti èmi yóò ní ìmúṣẹ.”\wj* tí a sì kà á mọ́ àwọn alárékọjá.
\p
\v 38 Wọ́n sì wí pé, “Olúwa, sá wò ó, idà méjì ń bẹ níhìn-ín yìí!”
\p Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Ó tó.”\wj*
\s1 Jesu gbàdúrà lórí òkè olifi
\p
\v 39 \x - \xo 22.39: \xt Mt 26.30; Mk 14.26; Jh 18.1.\x*Ó sì jáde, ó sì lọ bí ìṣe rẹ̀ sí òkè olifi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
\v 40 \x - \xo 22.40-46: \xt Mt 26.36-46; Mk 14.32-42; Hb 5.7-8.\x*\x - \xo 22.40: \xt Lk 11.4.\x*Nígbà tí ó wà níbẹ̀, ó wí fún wọn pé, \wj “Ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwò.”\wj*
\v 41 Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níwọ̀n ìsọ-òkò kan, ó sì kúnlẹ̀ ó sì ń gbàdúrà.
\v 42 \x - \xo 22.42: \xt Mk 10.38; Jh 18.11; 5.30.\x*Wí pé, \wj “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, mu ago yìí kúrò lọ́dọ́ mi: ṣùgbọ́n ìfẹ́ ti èmi kọ́, bí kò ṣe tìrẹ ni kí à ṣe.”\wj*
\v 43 Angẹli kan sì yọ sí i láti ọ̀run wá, ó ń gbà á ní ìyànjú.
\v 44 Bí ó sì ti wà nínú gbígbóná ara ó ń gbàdúrà sí i kíkankíkan; òógùn rẹ̀ sì dàbí ìró ẹ̀jẹ̀ ńlá, ó ń kán sílẹ̀.
\p
\v 45 Nígbà tí ó sì dìde kúrò ní ibi àdúrà, tí ó sì tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, ó bá wọn, wọ́n ń sùn nítorí ìbànújẹ́ ti mu kí ó rẹ̀ wọ́n.
\v 46 Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Kí ni ẹ̀ yin ń sùn sí? Ẹ dìde, ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwò.”\wj*
\s1 Wọ́n mú Jesu
\p
\v 47 \x - \xo 22.47-53: \xt Mt 26.47-56; Mk 14.43-49; Jh 18.3-11.\x*Bí ó sì ti ń sọ lọ́wọ́, kíyèsi i, ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti ẹni tí a ń pè ní Judasi, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá, ó ṣáájú wọn, ó súnmọ́ Jesu láti fi ẹnu kò ó ní ẹnu.
\v 48 Jesu sì wí fún un pé, \wj “Judasi, ìwọ yóò ha fi ìfẹnukonu fi Ọmọ Ènìyàn hàn?”\wj*
\p
\v 49 \x - \xo 22.49: \xt Lk 22.38.\x*Nígbà tí àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ń wo bí nǹkan yóò ti jásí, wọ́n bi í pé, “Olúwa kí àwa fi idà sá wọn?”
\v 50 Ọ̀kan nínú wọn sì fi idà ṣá ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé etí ọ̀tún rẹ̀ sọnù.
\p
\v 51 Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn ó wí pé, \wj “Ko gbọdọ̀ ṣe èyí mọ.”\wj* Ó sì fi ọwọ́ tọ́ ọ ní etí, ó sì wò ó sàn.
\p
\v 52 Jesu wí fún àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili, àti àwọn alàgbà, tí wọ́n jáde tọ̀ ọ́ wá pé, \wj “Ẹ̀yin ha jáde wá pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ bí ẹni tọ ọlọ́ṣà wá?\wj*
\v 53 \x - \xo 22.53: \xt Lk 19.47.\x*\wj Nígbà tí èmi wà pẹ̀lú yín lójoojúmọ́ ní tẹmpili, ẹ̀yin kò na ọwọ́ mú mi, ṣùgbọ́n àkókò tiyín ni èyí, àti agbára òkùnkùn n jẹ ọba.”\wj*
\s1 Peteru sẹ́ Jesu
\p
\v 54 \x - \xo 22.54-55: \xt Mt 26.57-58; Mk 14.53-54; Jh 18.12-16.\x*Wọ́n sì gbá a mú, wọ́n sì fà á lọ, wọ́n sì mú un wá sí ilé olórí àlùfáà. Ṣùgbọ́n Peteru tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní òkèrè.
\v 55 Nígbà tí wọ́n sì ti dáná láàrín àgbàlá, tí wọ́n sì jókòó pọ̀, Peteru jókòó láàrín wọn.
\v 56 \x - \xo 22.56-62: \xt Mt 26.69-75; Mk 14.66-72; Jh 18.16-18,25-27.\x*Ọmọbìnrin kan sì rí i bí ó ti jókòó níbi ìmọ́lẹ̀ iná náà, ó sì tẹjúmọ́ ọn, ó ní, “Eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.”
\p
\v 57 Ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Obìnrin yìí, èmi kò mọ̀ ọ́n.”
\p
\v 58 Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ẹlòmíràn sì rí i, ó ní, “Ìwọ pẹ̀lú wà nínú wọn.”
\p Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kọ́.”
\p
\v 59 Ó sì tó bí i wákàtí kan síbẹ̀ ẹlòmíràn tẹnumọ́ ọn, wí pé, “Nítòótọ́ eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀: nítorí ará Galili ní í ṣe.”
\p
\v 60 Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kò mọ ohun tí ìwọ ń wí!” Lójúkan náà, bí ó tí ń wí lẹ́nu, àkùkọ kọ!
\v 61 \x - \xo 22.61: \xt Lk 7.13; 22.34.\x*Olúwa sì yípadà, ó wo Peteru. Peteru sì rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí fún un pé, \wj “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ ó sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta.”\wj*
\v 62 Peteru sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.
\s1 Àwọn ẹ̀ṣọ́ n gan Jesu
\p
\v 63 \x - \xo 22.63-65: \xt Mt 26.67-68; Mk 14.65; Jh 18.22-24.\x*Ó sì ṣe, àwọn ọkùnrin tí wọ́n mú Jesu, sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n lù ú.
\v 64 Nígbà tí wọ́n sì dì í ní ojú, wọ́n lù ú níwájú, wọ́n ń bi í pé, “Sọtẹ́lẹ̀! Ta ni ó lù ọ́?”
\v 65 Wọ́n sì sọ ọ̀pọ̀ ohun búburú mìíràn sí i, láti fi ṣe ẹlẹ́yà.
\s1 Jesu níwájú Pilatu àti Herodu
\p
\v 66 \x - \xo 22.66: \xt Mt 26.57; Mk 14.53; Lk 22.54.\x*Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìjọ àwọn alàgbà àwọn ènìyàn péjọpọ̀, àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, wọ́n sì fà á lọ sí àjọ wọn, wọ́n ń wí pé,
\v 67 \x - \xo 22.67-71: \xt Mt 26.63-66; Mk 14.61-64; Jh 18.19-21.\x*“Bí ìwọ bá jẹ́ Kristi náà? Sọ fún wa!”
\p Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Bí mo bá wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́,\wj*
\v 68 \wj bí mo bá sì bi yín léèrè pẹ̀lú, ẹ̀yin kì yóò dá mi lóhùn.\wj*
\v 69 \wj Ṣùgbọ́n láti ìsinsin yìí lọ ni Ọmọ Ènìyàn yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára Ọlọ́run.”\wj*
\p
\v 70 \x - \xo 22.70: \xt Lk 23.3; Mt 27.11.\x*Gbogbo wọn sì wí pé, “Ìwọ ha ṣe Ọmọ Ọlọ́run bí?”
\p Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Ẹ̀yin wí pé, èmi ni.”\wj*
\p
\v 71 Wọ́n sì wí pé, “Ẹ̀rí wo ni àwa tún ń fẹ́ àwa tìkára wa sá à ti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀!”
\c 23
\p
\v 1 \x - \xo 23.1: \xt Mt 27.1-2; Mk 15.1; Jh 18.28.\x*Gbogbo ìjọ ènìyàn sì dìde, wọ́n sì fà á lọ sí ọ̀dọ̀ Pilatu.
\v 2 \x - \xo 23.2: \xt Lk 20.25.\x*Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀sùn kàn án, wí pé, “Àwa rí ọkùnrin yìí ó ń yí orílẹ̀-èdè wa lọ́kàn padà, ó sì ń dá wọn lẹ́kun láti san owó òde fún Kesari, ó ń wí pé, òun tìkára òun ni Kristi ọba.”
\p
\v 3 \x - \xo 23.3: \xt Mt 27.11-12; Mk 15.2-3; Jh 18.29-38; Lk 22.70.\x*Pilatu sì bi í léèrè, wí pé, “Ìwọ ha ni ọba àwọn Júù?”
\p Ó sì dá a lóhùn wí pé, \wj “Ìwọ wí i.”\wj*
\p
\v 4 \x - \xo 23.4: \xt Lk 23.14,22,41; Mt 27.24; Jh 19.4,6; Ap 13.28.\x*Pilatu sì wí fún àwọn olórí àlùfáà àti fún ìjọ ènìyàn pé, “Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ ọkùnrin yìí.”
\p
\v 5 Wọ́n sì túbọ̀ tẹnumọ́ ọn pé, “Ó ń ru ènìyàn sókè, ó ń kọ́ni káàkiri gbogbo Judea, ó bẹ̀rẹ̀ láti Galili títí ó fi dé ìhín yìí!”
\p
\v 6 Nígbà tí Pilatu gbọ́ orúkọ Galili, ó béèrè bí ọkùnrin náà bá jẹ́ ará Galili.
\v 7 Nígbà tí ó sì mọ̀ pé ará ilẹ̀ abẹ́ àṣẹ Herodu ni, ó rán an sí Herodu, ẹni tí òun tìkára rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu ní àkókò náà.
\p
\v 8 \x - \xo 23.8: \xt Lk 9.9; Ap 4.27-28.\x*Nígbà tí Herodu, sì rí Jesu, ó yọ̀ gidigidi; nítorí tí ó ti ń fẹ́ rí i pẹ́ ó sá à ti ń gbọ́ ìròyìn púpọ̀ nítorí rẹ̀; ó sì ń retí láti rí i kí iṣẹ́ àmì díẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe.
\v 9 \x - \xo 23.9: \xt Mk 15.5.\x*Ó sì béèrè ọ̀rọ̀ púpọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀; ṣùgbọ́n kò da a lóhùn rárá.
\v 10 Àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé dúró, wọ́n sì ń fi ẹ̀sùn kàn án gidigidi.
\v 11 \x - \xo 23.11: \xt Mk 15.17-19; Jh 19.2-3.\x*Àti Herodu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n sì ń fi í ṣẹ̀sín, wọ́n wọ̀ ọ́ ní aṣọ dáradára, ó sì rán an padà tọ Pilatu lọ.
\v 12 Pilatu àti Herodu di ọ̀rẹ́ ara wọn ní ọjọ́ náà, nítorí látijọ́ ọ̀tá ara wọn ni wọ́n ti jẹ́ rí.
\p
\v 13 Pilatu sì pe àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí àti àwọn ènìyàn jọ.
\v 14 \x - \xo 23.14: \xt Lk 23.4,22,41.\x*Ó sọ fún wọn pé, “Ẹyin mú ọkùnrin yìí tọ̀ mí wá, bí ẹni tí ó ń yí àwọn ènìyàn ní ọkàn padà. Sì kíyèsi i, èmí wádìí ẹjọ́ rẹ̀ níwájú yín èmi kò sì rí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ ọkùnrin yìí, ní gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ẹ̀yin fi ẹ̀sùn rẹ̀ sùn.
\v 15 Àti Herodu pẹ̀lú; ó sá rán an padà tọ̀ wá wá; sì kíyèsi i, ohun kan tí ó yẹ sí ikú ni a kò ṣe láti ọwọ́ rẹ̀.
\v 16 \x - \xo 23.16: \xt Lk 23.22; Jh 19.12-14.\x*Ǹjẹ́ èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀ lọ.”\f + \fr 23.16 \ft Àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́ ìwé Luku kan se àfikún ọ̀rọ̀ yìí \fv 17 \fqa Ó jẹ́ àṣà gómìnà láti dá ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹ́wọ̀n Júù sílẹ̀ lọ́dọọdún, ní àsìkò àjọ̀dún ìrékọjá. Ẹnikẹ́ni tí àwọn ènìyàn bá ti fẹ́ ni\ft .\f*
\p
\v 18 \x - \xo 23.18-23: \xt Mt 27.20-23; Mk 15.11-14; Ap 3.13-14; Jh 18.38-40; 19.14-15.\x*Wọ́n sì kígbe sókè nígbà kan náà, pé, “Mú ọkùnrin yìí kúrò, kí o sì dá Baraba sílẹ̀ fún wa!”
\v 19 Ẹni tí a sọ sínú túbú nítorí ọ̀tẹ̀ kan tí a ṣe ní ìlú, àti nítorí ìpànìyàn.
\p
\v 20 Pilatu sì tún bá wọn sọ̀rọ̀, nítorí ó fẹ́ dá Jesu sílẹ̀.
\v 21 Ṣùgbọ́n wọ́n kígbe, wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú, kàn án mọ àgbélébùú!”
\p
\v 22 Ó sì wí fún wọn lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, “Èéṣe, búburú kín ni ọkùnrin yìí ṣe? Èmi kò rí ọ̀ràn ikú lára rẹ̀: nítorí náà èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀.”
\p
\v 23 \x - \xo 23.23-25: \xt Mt 27.26; Mk 15.15.\x*Wọ́n túbọ̀ tẹramọ́ igbe ńlá, wọ́n ń fẹ́ kí a kàn án mọ́ àgbélébùú, ohùn tiwọn àti ti àwọn olórí àlùfáà borí tirẹ̀.
\v 24 Pilatu sí fi àṣẹ sí i pé, kí ó rí bí wọ́n ti ń fẹ́.
\v 25 Ó sì dá ẹni tí wọ́n fẹ́ sílẹ̀ fún wọn, ẹni tí a tìtorí ọ̀tẹ̀ àti ìpànìyàn sọ sínú túbú; ṣùgbọ́n ó fi Jesu lé wọn lọ́wọ́.
\s1 Wọ́n kan Jesu mọ́ àgbélébùú
\p
\v 26 \x - \xo 23.26: \xt Mt 27.32; Mk 15.21; Jh 19.17.\x*Bí wọ́n sì ti ń fà á lọ, wọ́n mú ọkùnrin kan, Simoni ara Kirene, tí ó ń ti ìgbèríko bọ̀, òun ni wọ́n sì gbé àgbélébùú náà lé, kí ó máa rù ú lọ tẹ̀lé Jesu.
\v 27 Ìjọ ènìyàn púpọ̀ ni ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, àti àwọn obìnrin, tí ń pohùnréré ẹkún,
\v 28 \x - \xo 23.28-31: \xt Lk 21.23-24; 19.41-44.\x*ṣùgbọ́n Jesu yíjú padà sí wọn, ó sì wí pé, \wj “Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, ẹ má sọkún fún mi, ṣùgbọ́n ẹ sọkún fún ara yín, àti fún àwọn ọmọ yín.\wj*
\v 29 \wj Nítorí kíyèsi i, ọjọ́ ń bọ̀ ní èyí tí ẹ̀yin ó wí pé, Ìbùkún ni fún àgàn, àti fún inú tí kò bímọ rí, àti fún ọmú tí kò fún ni mu rí!\wj*
\v 30 \wj Nígbà náà ni\wj*
\q1 \wj “wọn ó bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn òkè kéékèèké pé, “Yí lù wá!”\wj*
\q2 \wj Sí àwọn òkè ńlá, “Bò wá mọ́lẹ̀!” ’\wj*
\m
\v 31 \wj Nítorí bí wọn bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí sára igi tútù, kín ni a ó ṣe sára igi gbígbẹ?”\wj*
\p
\v 32 Àwọn méjì mìíràn bákan náà, àwọn arúfin, ni wọ́n sì fà lọ pẹ̀lú rẹ̀ láti pa.
\v 33 \x - \xo 23.33-39: \xt Mt 27.33-44; Mk 15.22-32; Jh 19.17-24.\x*Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí a ń pè ní Agbárí, níbẹ̀ ni wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn arúfin náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti ọ̀kan ní ọwọ́ òsì.
\v 34 \x - \xo 23.34: \xt Ap 7.60; Sm 22.18.\x*Jesu sì wí pé, \wj “Baba, dáríjì wọ́n; nítorí tí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.”\wj* Wọ́n di ìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn.
\p
\v 35 \x - \xo 23.35: \xt Lk 4.23.\x*Àwọn ènìyàn sì dúró láti wòran. Àti àwọn ìjòyè pẹ̀lú wọn, wọ́n ń yọ ṣùtì sí i, wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là; kí ó gbara rẹ̀ là, bí ó bá ṣe Kristi, àyànfẹ́ Ọlọ́run.”
\p
\v 36 \x - \xo 23.36: \xt Mk 15.23; Sm 69.21.\x*Àti àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n tọ̀ ọ́ wá, wọ́n ń fi ọtí kíkan fún un.
\v 37 Wọ́n sì ń wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe ọba àwọn Júù, gba ara rẹ là.”
\p
\v 38 Wọ́n sì kọ̀wé àkọlé sí ìgbèrí rẹ̀ ní èdè Giriki, àti ti Latin, àti tí Heberu pe:
\pc Èyí ni Ọba àwọn Júù.
\p
\v 39 Àti ọ̀kan nínú àwọn arúfin tí a gbé kọ́ ń fi ṣe ẹlẹ́yà wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Kristi, gba ara rẹ àti àwa náà là.”
\p
\v 40 Ṣùgbọ́n èyí èkejì dáhùn, ó ń bá a wí pé, “Ìwọ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ìwọ wà nínú ẹ̀bi kan náà?
\v 41 \x - \xo 23.41: \xt Lk 23.4,14,22.\x*Ní tiwa, wọ́n jàre nítorí èrè ohun tí àwa ṣe ni à ń jẹ, ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí kò ṣe ohun búburú kan.”
\p
\v 42 Ó sì wí pé, “Jesu, rántí mi nígbà tí ìwọ bá dé ìjọba rẹ.”
\p
\v 43 \x - \xo 23.43: \xt 2Kọ 12.3; If 2.7.\x*Jesu sì wí fún un pé, \wj “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, lónìí ni ìwọ ó wà pẹ̀lú mi ní Paradise!”\wj*
\s1 Ikú Jesu
\p
\v 44 \x - \xo 23.44-49: \xt Mt 27.45-56; Mk 15.33-41; Jh 19.25-30.\x*Ó sì tó ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́, òkùnkùn sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí ó fi di wákàtí kẹsànán ọjọ́.
\v 45 \x - \xo 23.45: \xt Ek 26.31-35; Hb 9.8; 10.19.\x*Òòrùn sì ṣú òòkùn, aṣọ ìkélé ti tẹmpili sì ya ní àárín méjì.
\v 46 \x - \xo 23.46: \xt Sm 31.5.\x*Nígbà tí Jesu sì kígbe lóhùn rara, ó ní, \wj “Baba, ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé!”\wj* Nígbà tí ó sì wí èyí tan, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.
\p
\v 47 Nígbà tí balógun ọ̀rún rí ohun tí ó ṣe, ó yin Ọlọ́run lógo, wí pé, “Dájúdájú olódodo ni ọkùnrin yìí!”
\v 48 Gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó péjọ láti rí ìran yìí, nígbà tí wọ́n rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ wọ́n lu ara wọn ní oókan àyà, wọ́n sì padà sí ilé.
\v 49 \x - \xo 23.49: \xt Lk 8.1-3; 23.55-56; 24.10.\x*Àti gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀, àti àwọn obìnrin tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Galili wá, wọ́n dúró lókèèrè, wọ́n ń wo nǹkan wọ̀nyí.
\s1 Ìsìnkú Jesu
\p
\v 50 \x - \xo 23.50-56: \xt Mt 27.57-61; Mk 15.42-47; Jh 19.38-42; Ap 13.29.\x*Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Josẹfu, láti ìlú àwọn Júù kan tí ń jẹ́ Arimatea. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ènìyàn rere, àti olóòtítọ́.
\v 51 Òun kò bá wọn fi ohùn sí ìmọ̀ àti ìṣe wọn; Ó wá láti Judea, ìlú àwọn ará Arimatea, òun pẹ̀lú ń retí ìjọba Ọlọ́run.
\v 52 Ọkùnrin yìí tọ Pilatu lọ, ó sì tọrọ òkú Jesu.
\v 53 Nígbà tí ó sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀, ó sì fi aṣọ àlà dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì tí a gbẹ́ nínú Òkúta, níbi tí a kò tẹ́ ẹnikẹ́ni sí rí.
\v 54 Ó sì jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́, ọjọ́ ìsinmi sì kù sí dẹ̀dẹ̀.
\p
\v 55 Àti àwọn obìnrin, tí wọ́n bá a ti Galili wá, tí wọ́n sì tẹ̀lé, wọ́n kíyèsi ibojì náà, àti bí a ti tẹ́ òkú rẹ̀ sílẹ̀.
\v 56 \x - \xo 23.56: \xt Mk 16.1; El 12.16; 20.10.\x*Nígbà tí wọ́n sì padà, wọ́n pèsè ohun olóòórùn dídùn, òróró ìkunra (àti tùràrí tútù); wọ́n sì sinmi ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí òfin.
\c 24
\s1 Àjíǹde náà
\p
\v 1 \x - \xo 24.1-9: \xt Mt 28.1-8; Mk 16.1-7; Jh 20.1,11-13.\x*Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ ọ̀sẹ̀, àwọn obìnrin wá sí ibojì, wọ́n sì mú ìkunra olóòórùn dídùn ti wọ́n tí pèsè sílẹ̀ wá.
\v 2 Òkúta ti yí kúrò ní ẹnu ibojì.
\v 3 Nígbà tí wọ́n sì wọ inú rẹ̀, wọn kò rí òkú Jesu Olúwa.
\v 4 Bí wọ́n ti dààmú kiri níhà ibẹ̀, kíyèsi i, àwọn ọkùnrin méjì aláṣọ dídán dúró tì wọ́n.
\v 5 Nígbà tí ẹ̀rù ń bà wọ́n, tí wọ́n sì dojúbolẹ̀, àwọn angẹli náà bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá alààyè láàrín àwọn òkú?
\v 6 \x - \xo 24.6: \xt Lk 9.22; 13.32-33.\x*Kò sí níhìn-ín yìí, ṣùgbọ́n ó jíǹde; ẹ rántí bí ó ti wí fún yín nígbà tí ó wà ní Galili.
\v 7 Pé, \wj A ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́, a ó sì kàn án mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta yóò sì jíǹde.’ ”\wj*
\v 8 Wọ́n sì rántí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
\p
\v 9 Wọ́n sì padà ti ibojì wá, wọ́n sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún àwọn mọ́kànlá, àti fún gbogbo àwọn ìyókù.
\v 10 \x - \xo 24.10: \xt Mk 16.1; Lk 8.1-3; Jh 20.2.\x*Maria Magdalene, àti Joanna, àti Maria ìyá Jakọbu, àti àwọn mìíràn pẹ̀lú wọn sì ni àwọn tí ó ròyìn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn aposteli.
\v 11 Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sì dàbí ìsọkúsọ lójú wọn, wọn kò sì gbà wọ́n gbọ́.
\v 12 Nígbà náà ni Peteru dìde, ó súré lọ sí ibojì; nígbà tí ó sì bẹ̀rẹ̀, ó rí aṣọ àlà lọ́tọ̀ fúnra wọn, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀, ẹnu yà á sí ohun tí ó ṣe.
\s1 Ní ojú ọnà sí Emmausi
\p
\v 13 Sì kíyèsi i, àwọn méjì nínú wọn ń lọ ní ọjọ́ náà sí ìletò kan tí a ń pè ní Emmausi, tí ó jìnnà sí Jerusalẹmu níwọ̀n ọgọ́ta ibùsọ̀.
\v 14 Wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣẹlẹ̀.
\v 15 Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń bá ara wọn jíròrò, Jesu tìkára rẹ̀ súnmọ́ wọn, ó sì ń bá wọn rìn lọ.
\v 16 \x - \xo 24.16: \xt Jh 20.14; 21.4.\x*Ṣùgbọ́n a rú wọn lójú, kí wọn má le mọ̀ ọ́n.
\p
\v 17 Ó sì bi wọ́n pé, \wj “Ọ̀rọ̀ kín ni ẹ̀yin ń bá ara yín sọ, bí ẹ̀yin ti ń rìn?”\wj*
\p Wọ́n sì dúró jẹ́, wọ́n fajúro.
\v 18 Ọ̀kan nínú wọn, tí a ń pè ní Kileopa, sì dáhùn wí fún un pé, “Àlejò sá à ni ìwọ ní Jerusalẹmu, tí ìwọ kò sì mọ ohun tí ó ṣẹ̀ níbẹ̀ ní ọjọ́ wọ̀nyí?”
\p
\v 19 \x - \xo 24.19: \xt Mt 21.11; Lk 7.16; 13.33; Ap 3.22.\x*Ó sì bi wọ́n pé, \wj “Kín ni?”\wj*
\p Wọ́n sì wí fún un pé, “Ní ti Jesu ti Nasareti, ẹni tí ó jẹ́ wòlíì, tí ó pọ̀ ní ìṣe àti ní ọrọ̀ níwájú Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn,
\v 20 àti bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà wa ti fi òun lé wọn lọ́wọ́ láti dá a lẹ́bi ikú, àti bí wọ́n ti kàn án mọ́ àgbélébùú.
\v 21 Bẹ́ẹ̀ ni òun ni àwa ti ní ìrètí pé, òun ni ìbá dá Israẹli ní ìdè. Àti pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, òní ni ó di ọjọ́ kẹta tí nǹkan wọ̀nyí ti ṣẹlẹ̀.
\v 22 Àwọn obìnrin kan pẹ̀lú nínú ẹgbẹ́ wa, tí wọ́n lọ si ibojì ní kùtùkùtù, sì wá yà wá lẹ́nu,
\v 23 nígbà tí wọn kò sì rí òkú rẹ̀, wọ́n wá wí pé, àwọn rí ìran àwọn angẹli tí wọ́n wí pé, ó wà láààyè.
\v 24 \x - \xo 24.24: \xt Jh 20.3-10.\x*Àti àwọn kan tí wọ́n wà pẹ̀lú wa lọ sí ibojì, wọ́n sì rí i gẹ́gẹ́ bí àwọn obìnrin náà ti wí, ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ ni wọn kò rí.”
\p
\v 25 Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Ẹ̀yin tí òye kò yé, tí ẹ sì yigbì ní àyà láti gba gbogbo èyí tí àwọn wòlíì ti wí gbọ́,\wj*
\v 26 \wj kò ha yẹ kí Kristi ó jìyà nǹkan wọ̀nyí kí ó sì wọ inú ògo rẹ̀ lọ.”\wj*
\v 27 \x - \xo 24.27: \xt Lk 24.44-45; Ap 28.23; 1Pt 1.11.\x*Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti Mose àti gbogbo àwọn wòlíì wá, ó sì túmọ̀ nǹkan fún wọn nínú ìwé mímọ́ gbogbo nípa ti ara rẹ̀.
\p
\v 28 \x - \xo 24.28: \xt Mk 6.48.\x*Wọ́n sì súnmọ́ ìletò tí wọ́n ń lọ, ó sì ṣe bí ẹni pé yóò lọ sí iwájú.
\v 29 Wọ́n sì rọ̀ ọ́, pé, “Bá wa dúró: nítorí ó di ọjọ́ alẹ́, ọjọ́ sì kọjá tán.” Ó sì wọlé lọ, ó bá wọn dúró.
\p
\v 30 \x - \xo 24.30: \xt Lk 9.16; 22.19.\x*Ó sì ṣe, bí ó ti bá wọn jókòó ti oúnjẹ, ó mú àkàrà, ó súre sí i, ó sì bù ú, ó sì fi fún wọn.
\v 31 Ojú wọn sì là, wọ́n sì mọ̀ ọ́n, ó sì nù mọ́ wọn ní ojú.
\v 32 Wọ́n sì bá ara wọn sọ pé, “Ọkàn wa kò ha gbiná nínú wa, nígbà tí ó ń bá wa sọ̀rọ̀ tí ó sì ń túmọ̀ ìwé mímọ́ fún wa!”
\p
\v 33 Wọ́n sì dìde ní wákàtí kan náà, wọ́n padà lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì bá àwọn mọ́kànlá péjọ, àti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn.
\v 34 \x - \xo 24.34: \xt 1Kọ 15.5.\x*Wọn si wí pé, “Olúwa jíǹde nítòótọ́, ó sì ti fi ara hàn fún Simoni!”
\v 35 Àwọn náà sì ròyìn nǹkan tí ó ṣe ní ọ̀nà, àti bí ó ti di mí mọ̀ fún wọn ní bíbu àkàrà.
\s1 Jesu fi ara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀
\p
\v 36 \x - \xo 24.36-43: \xt Jh 20.19-20,27; Jh 21.5,9-13; 1Kọ 15.5; Ap 10.40-41.\x*Bí wọ́n sì ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí Jesu tìkára rẹ̀ dúró láàrín wọn, ó sì wí fún wọn pé, \wj “Àlàáfíà fún yín.”\wj*
\p
\v 37 Ṣùgbọ́n àyà fò wọ́n, wọ́n sì wárìrì, wọ́n ṣe bí àwọn rí ẹ̀mí kan.
\v 38 Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Èéṣe tí ara yín kò lélẹ̀? Èé sì ti ṣe tí èròkerò fi ń sọ nínú ọkàn yín?\wj*
\v 39 \x - \xo 24.39: \xt 1Jh 1.1.\x*\wj Ẹ wo ọwọ́ mi àti ẹsẹ̀ mi, pé èmi tìkára mi ni! Ẹ dì mímú kí ẹ wò ó nítorí tí iwin kò ní ẹran àti egungun lára, bí ẹ̀yin ti rí tí èmi ní.”\wj*
\p
\v 40 Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó fi ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ hàn wọ́n.
\v 41 Nígbà tí wọn kò sì tí ì gbàgbọ́ fún ayọ̀, àti fún ìyanu, ó wí fún wọn pé, \wj “Ẹ̀yin ní ohunkóhun jíjẹ níhìn-ín yìí?”\wj*
\v 42 Wọ́n sì fún un ní ẹja tí a fi oyin sè.
\v 43 Ó sì gbà á, ó jẹ ẹ́ lójú wọn.
\p
\v 44 \x - \xo 24.44: \xt Lk 24.26-27; Ap 28.23.\x*Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín, nígbà tí èmí ti wà pẹ̀lú yín pé, a ní láti mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ nínú òfin Mose, àti nínú ìwé àwọn wòlíì, àti nínú Saamu, nípasẹ̀ mi.”\wj*
\p
\v 45 Nígbà náà ni ó ṣí wọn ní iyè, kí ìwé mímọ́ lè yé wọn.
\v 46 \x - \xo 24.46: \xt Ho 6.2; 1Kọ 15.3-4.\x*Ó sì wí fún wọn pé, \wj “Bẹ́ẹ̀ ni a ti kọ̀wé rẹ̀, pé: kí Kristi jìyà, àti kí ó sì jíǹde ní ọjọ́ kẹta kúrò nínú òkú,\wj*
\v 47 \x - \xo 24.47: \xt Ap 1.4-8; Mt 28.19.\x*\wj àti pé kí a wàásù ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lórúkọ rẹ̀, ní orílẹ̀-èdè gbogbo, bẹ̀rẹ̀ láti Jerusalẹmu lọ.\wj*
\v 48 \wj Ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí.\wj*
\v 49 \x - \xo 24.49: \xt Ap 2.1-4; Jh 14.26; 20.21-23.\x*\wj Èmi yóò rán ohun tí Baba mi ṣe ìlérí sí yín, ṣùgbọ́n ẹ jókòó ní ìlú Jerusalẹmu, títí a ó fífi agbára wọ̀ yín, láti òkè ọ̀run wá.”\wj*
\s1 Ìgòkè re ọ̀run
\p
\v 50 Ó sì mú wọn jáde lọ títí wọ́n fẹ́rẹ̀ dé Betani, nígbà tí ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó súre fún wọn.
\v 51 \x - \xo 24.51: \xt Ap 1.9-11.\x*Ó sì ṣe, bí ó ti ń súre fún wọn, ó yà kúrò lọ́dọ̀ wọn, a sì gbé e lọ sí ọ̀run.
\v 52 \x - \xo 24.52-53: \xt Ap 1.12-14.\x*Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un, wọ́n sì padà lọ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú ayọ̀ púpọ̀.
\v 53 Wọ́n sì wà ní tẹmpili nígbà gbogbo, wọ́n ń fi ìyìn, àti ìbùkún fún Ọlọ́run.