Biblica_yoOBYO17/37HAGyoOBYO17.SFM

71 lines
8.2 KiB
Plaintext
Raw Permalink Blame History

This file contains invisible Unicode characters

This file contains invisible Unicode characters that are indistinguishable to humans but may be processed differently by a computer. If you think that this is intentional, you can safely ignore this warning. Use the Escape button to reveal them.

This file contains Unicode characters that might be confused with other characters. If you think that this is intentional, you can safely ignore this warning. Use the Escape button to reveal them.

\id HAG - Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible (Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
\rem Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
\h Hagai
\toc1 Ìwé Wòlíì Hagai
\toc2 Hagai
\toc3 Hg
\mt1 Ìwé Wòlíì Hagai
\c 1
\s1 Ìpè láti tún ilé \nd Olúwa\nd* kọ́
\p
\v 1 Ní ọdún kejì ọba Dariusi ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹfà, ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* wá nípasẹ̀ wòlíì Hagai sí Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, baálẹ̀ Juda, àti sọ́dọ̀ Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà.
\p
\v 2 Báyìí ni \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí: “Àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí pé, Kò tí ì tó àkókò láti kọ́ ilé \nd Olúwa\nd*.’ ”
\p
\v 3 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* wá láti ọ̀dọ̀ wòlíì Hagai wí pé,
\v 4 “Ǹjẹ́ àkókò ni fún ẹ̀yin fúnra yín láti máa gbé ní ilé tí a ṣe ní ọ̀ṣọ́ nígbà tí ilé yìí wà ni ahoro?”
\p
\v 5 Nísìnsinyìí, èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín.
\v 6 Ẹ̀yin ti gbìn ohun ti ó pọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kórè díẹ̀ níbẹ̀. Ẹ̀yin jẹun, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yó. Ẹ̀yin mu ṣùgbọ́n kò tẹ́ ẹ yín lọ́run; ẹ̀yin wọ aṣọ, ṣùgbọ́n kò mú òtútù yin lọ; ẹyin gba owó iṣẹ́ ṣùgbọ́n ẹ ń gbà á sínú ajádìí àpò.”
\p
\v 7 Báyìí ni \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín.
\v 8 Ẹ gun orí àwọn òkè ńlá lọ, kí ẹ sì mú igi wá pẹ̀lú yín. Kí ẹ sì kọ́ ilé náà, kí inú mi bà le è dùn sí i, kí a sì yín mí lógo,” ni \nd Olúwa\nd* wí.
\v 9 “Ẹyin ti ń retí ọ̀pọ̀, ṣùgbọ́n kíyèsi i, o yípadà sí díẹ̀. Ohun tí ẹ̀yin mú wa ilé, èmi sì fẹ́ ẹ dànù. Nítorí kí ni?” ni \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí. “Nítorí ilé mi tí ó dahoro; tí olúkúlùkù yín sì ń sáré fún ilé ara rẹ̀.
\v 10 Nítorí yín ni àwọn ọ̀run ṣe dá ìrì dúró tí ilẹ̀ sì kọ̀ láti mu èso jáde.
\v 11 Mo sì ti pe ọ̀dá sórí ilẹ̀ àti sórí àwọn òkè ńlá, sórí ọkà àti sórí wáìnì tuntun, sórí òróró àti sórí ohun ti ilẹ̀ ń mú jáde, sórí ènìyàn, sórí ẹran àti sórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín.”
\b
\p
\v 12 Nígbà náà ni Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ìyókù, gba ohùn \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wọn gbọ́ àti ọ̀rọ̀ wòlíì Hagai, nítorí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run ni ó rán an. Àwọn ènìyàn sì bẹ̀rù \nd Olúwa\nd*.
\p
\v 13 Nígbà náà ni Hagai ìránṣẹ́ \nd Olúwa\nd* ń jíṣẹ́ \nd Olúwa\nd* fún àwọn ènìyàn pé, “Èmí wà pẹ̀lú yín,” ni \nd Olúwa\nd* wí.
\v 14 Nítorí náà, \nd Olúwa\nd* ru ẹ̀mí Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli sókè, baálẹ̀ Juda àti ẹ̀mí Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà àti ẹ̀mí gbogbo ènìyàn ìyókù. Wọ́n sì wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ lórí ilé \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run wọn,
\v 15 ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹfà ní ọdún kejì ọba Dariusi.
\c 2
\s1 Ẹwà Tẹmpili tuntun náà
\p
\v 1 Ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù keje, ni ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* wá nípasẹ̀ wòlíì Hagai wí pé,
\v 2 “Sọ fún Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, baálẹ̀ Juda, àti Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn yòókù. Béèrè lọ́wọ́ wọn pé,
\v 3 Ta ni nínú yín tí ó kù tí ó sì ti rí ilé yìí ní ògo rẹ̀ àkọ́kọ́? Báwo ni ó ṣe ri sí yín nísinsin yìí? Ǹjẹ́ kò dàbí asán lójú yín?
\v 4 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, múra gírí, ìwọ Serubbabeli, ni \nd Olúwa\nd* wí. Múra gírí, ìwọ Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà. Ẹ sì múra gírí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ náà, ni \nd Olúwa\nd* wí, kí ẹ sì ṣiṣẹ́. Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín, ni \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí.
\v 5 Èyí ni ohun tí Èmi fi bá a yín dá májẹ̀mú nígbà tí ẹ jáde kúrò ní Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí ì mi sì wà pẹ̀lú yín. Ẹ má ṣe bẹ̀rù.
\p
\v 6 “Báyìí ni \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí pé, Láìpẹ́ jọjọ, Èmi yóò mi àwọn ọrun àti ayé, Òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.
\v 7 Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè, ìfẹ́ gbogbo orílẹ̀-èdè yóò fà sí tẹmpili yìí, Èmi yóò sì kún ilé yìí pẹ̀lú ògo, ni \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí.
\v 8 Tèmi ni fàdákà àti wúrà, ni \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí.
\v 9 Ògo ìkẹyìn ilé yìí yóò pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ, ni \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí, Àti ní ìhín yìí ni Èmi ó sì fi àlàáfíà fún ni, ni \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí.”
\s1 Ìbùkún fún àwọn ènìyàn tí a sọ di àìmọ́
\p
\v 10 Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsànán ní ọdún kejì Dariusi, ni ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* tọ wòlíì Hagai wá pé,
\v 11 “Báyìí ni \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí, Béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà ohun tí òfin wí pé:
\v 12 Bí ẹnìkan bá gbé ẹran mímọ́ ní ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, tí ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀ kan àkàrà tàbí ọbẹ̀, wáìnì, òróró tàbí oúnjẹ mìíràn, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ mímọ́ bí?’ ”
\p Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.”
\p
\v 13 Nígbà náà ni Hagai wí pé, “Bí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífi ara kan òkú bá fi ara kan ọ̀kan lára nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ aláìmọ́?”
\p Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, yóò jẹ́ aláìmọ́.”
\p
\v 14 Nígbà náà ni Hagai dáhùn ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn wọ̀nyí rí, bẹ́ẹ̀ sì ni orílẹ̀-èdè yìí rí níwájú mi, ni \nd Olúwa\nd* wí. Bẹ́ẹ̀ sì ni olúkúlùkù iṣẹ́ ọwọ́ wọn; èyí tí wọ́n sì fi rú ẹbọ níbẹ̀ jẹ́ aláìmọ́.
\p
\v 15 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ ro èyí dáradára láti òní yìí lọ, ẹ kíyèsi bí nǹkan ṣe rí tẹ́lẹ̀, a to òkúta kan lé orí èkejì ní tẹmpili \nd Olúwa\nd*.
\v 16 Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi òkìtì òsùwọ̀n ogun, mẹ́wàá péré ni yóò ba níbẹ̀. Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi ìfúntí wáìnì láti wọn àádọ́ta ìwọ̀n, ogún péré ni yóò ba níbẹ̀.
\v 17 Mo fi ìrẹ̀dànù, ìmúwòdù àti yìnyín bá gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín jẹ; síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí ọ̀dọ̀ mi, ni \nd Olúwa\nd* wí.
\v 18 Láti òní lọ, láti ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsànán yìí kí ẹ kíyèsi, kí ẹ sì rò ó dáradára, ọjọ́ ti a fi ìpìlẹ̀ tẹmpili \nd Olúwa\nd* lélẹ̀, rò ó dáradára.
\v 19 Ǹjẹ́ èso ha wà nínú abà bí? Títí di àkókò yìí, àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ àti pomegiranate, àti igi olifi kò ì tí ì so èso kankan.
\p “Láti òní lọ ni èmi yóò bùkún fún un yin.’ ”
\s1 Serubbabeli òrùka èdìdì \nd Olúwa\nd*
\p
\v 20 Ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* sì tún tọ Hagai wá nígbà kejì, ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù náà pé,
\v 21 “Sọ fún Serubbabeli baálẹ̀ Juda pé èmi yóò mi àwọn ọ̀run àti ayé.
\v 22 Èmi yóò bi ìtẹ́ àwọn ìjọba ṣubú, Èmi yóò sì pa agbára àwọn aláìkọlà run, Èmi yóò sì dojú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun dé, àti àwọn tí ń gùn wọ́n; ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin yóò ṣubú; olúkúlùkù nípa idà arákùnrin rẹ̀.”
\p
\v 23 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Ní ọjọ́ náà, ìwọ ìránṣẹ́ mi Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, Èmi yóò mú ọ, Èmi yóò sì sọ ọ di bí òrùka èdìdì mi, nítorí mo ti yan ọ, ni \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí.”