283 lines
12 KiB
Plaintext
283 lines
12 KiB
Plaintext
\id HAB - Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible (Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
|
||
\rem Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
|
||
\h Habakuku
|
||
\toc1 Ìwé Wòlíì Habakuku
|
||
\toc2 Habakuku
|
||
\toc3 Hk
|
||
\mt1 Ìwé Wòlíì Habakuku
|
||
\c 1
|
||
\p
|
||
\v 1 Àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Habakuku rí.
|
||
\b
|
||
\s1 Ìráhùn Habakuku
|
||
\q1
|
||
\v 2 \x - \xo 1.2: \xt Isa 13.1–14.23; 47; Jr 50–51.\x*\nd Olúwa\nd*, èmi yóò ti ké pẹ́ tó fún ìrànlọ́wọ́,
|
||
\q2 ṣùgbọ́n ti ìwọ kò ni fetí sí mi?
|
||
\q1 Tàbí kígbe sí ọ ní ti, “Ìwà ipá!”
|
||
\q2 Ṣùgbọ́n tí ìwọ kò sì gbàlà?
|
||
\q1
|
||
\v 3 Èéṣe tí ìwọ fi mú mi rí àìṣedéédéé?
|
||
\q2 Èéṣe tí ìwọ sì fi ààyè gba ìwà ìkà?
|
||
\q1 Ìparun àti ìwà ipá wà ní iwájú mi;
|
||
\q2 ìjà ń bẹ, ìkọlù sì wà pẹ̀lú.
|
||
\q1
|
||
\v 4 Nítorí náà, òfin di ohun àìkàsí,
|
||
\q2 ìdájọ́ òdodo kò sì borí.
|
||
\q1 Àwọn ẹni búburú yí àwọn olódodo ká,
|
||
\q2 nítorí náà ni ìdájọ́ òdodo ṣe yí padà.
|
||
\s1 Ìdáhùn \nd Olúwa\nd*
|
||
\q1
|
||
\v 5 \x - \xo 1.5: \xt Ap 13.41.\x*“Ẹ wo inú àwọn kèfèrí, ki ẹ sí wòye,
|
||
\q2 kí háà kí ó sì ṣe yin gidigidi.
|
||
\q1 Nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín
|
||
\q2 tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́,
|
||
\q2 bí a tilẹ̀ sọ fún yin.
|
||
\q1
|
||
\v 6 \x - \xo 1.6: \xt If 20.9.\x*Nítorí pé, èmi yóò gbé àwọn ara Babeli dìde,
|
||
\q2 àwọn aláìláàánú àti onínú-fùfù ènìyàn
|
||
\q1 tí ó rin gbogbo ilẹ̀ ayé já
|
||
\q2 láti fi agbára gbà àwọn ibùgbé tí kì í ṣe tiwọn.
|
||
\q1
|
||
\v 7 Wọn jẹ́ ènìyàn ti a bẹ̀rù, tí a sì páyà,
|
||
\q2 ìdájọ́ wọn, àti ọláńlá wọn,
|
||
\q2 yóò máa ti inú wọn jáde.
|
||
\q1
|
||
\v 8 Ẹṣin wọn yára ju ẹkùn lọ,
|
||
\q2 wọ́n sì gbóná jú ìkookò àṣálẹ́ lọ
|
||
\q1 àwọn ẹlẹ́ṣin wọn yóò sí tan ara wọn ká;
|
||
\q2 wọn yóò sì wá láti ọ̀nà jíjìn réré,
|
||
\q1 wọn yóò sí fò bí ẹyẹ igún tí ń wá láti jẹrun,
|
||
\q2
|
||
\v 9 gbogbo wọn sì wà fún ìwà ipá
|
||
\q1 ìwò ojú wọn yóò sì wá síwájú;
|
||
\q2 wọn sì ko ìgbèkùn jọ bí iyanrìn.
|
||
\q1
|
||
\v 10 Wọn ó si máa fi àwọn ọba ṣẹ̀sín
|
||
\q2 wọn ó sì tún kẹ́gàn àwọn aládé.
|
||
\q1 Wọn yóò sì fi gbogbo ìlú odi alágbára nì rẹ́rìn-ín;
|
||
\q2 nítorí pé, wọn yóò ko erùpẹ̀ jọ, wọn yóò sì gbà á.
|
||
\q1
|
||
\v 11 Nígbà náà ni inú rẹ̀ yóò yípadà,
|
||
\q2 yóò sì rékọjá, yóò si ṣẹ̀ ní kíka agbára rẹ̀ yìí sí iṣẹ́ òrìṣà rẹ̀.”
|
||
\s1 Ìráhùn lẹ́ẹ̀kejì Habakuku
|
||
\q1
|
||
\v 12 \nd Olúwa\nd*, ǹjẹ́ láti ayérayé kọ ni ìwọ tí wà?
|
||
\q2 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run mi. Ẹni mímọ́ mi, àwa kì yóò kú
|
||
\q1 \nd Olúwa\nd*, ìwọ tí yàn wọn fún ìdájọ́;
|
||
\q2 Ọlọ́run alágbára, ìwọ tí fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ fún ìbáwí.
|
||
\q1
|
||
\v 13 Ojú rẹ mọ́ tónítóní láti wo ibi;
|
||
\q2 ìwọ kò le gbà ìwà ìkà
|
||
\q1 nítorí kí ni ìwọ ṣe gba àwọn alárékérekè láààyè?
|
||
\q2 Nítorí kí ni ìwọ ṣe dákẹ́ nígbà tí ẹni búburú ń pa
|
||
\q2 ẹni tí i ṣe olódodo ju wọn lọ run?
|
||
\q1
|
||
\v 14 Ìwọ sì tí sọ ènìyàn di bí ẹja inú Òkun,
|
||
\q2 bí ohun tí ń rákò tí wọn ko ni alákòóso.
|
||
\q1
|
||
\v 15 Àwọn ènìyàn búburú fi àwọ̀n wọn gbé wọn sókè
|
||
\q2 ó sì kó wọn jọ nínú àwọ̀n ńlá rẹ̀;
|
||
\q2 nítorí náà, ó dunnú, ó sì yọ̀ pẹ̀lú.
|
||
\q1
|
||
\v 16 Nítorí náà, ó rú ẹbọ sí àwọ̀n rẹ̀,
|
||
\q2 ó sì ń sun tùràrí fún àwọ̀n ńlá rẹ̀
|
||
\q1 nítorí pẹ̀lú àwọ̀n rẹ̀ ni ó fi ń gbé ní ìgbádùn
|
||
\q2 tí ó sì ń gbádùn pẹ̀lú oúnjẹ tí ó bá wù ú.
|
||
\q1
|
||
\v 17 Ǹjẹ́ wọn yóò ha máa pa àwọ̀n wọn mọ́ ní òfìfo bí,
|
||
\q2 tí wọn yóò sì pa orílẹ̀-èdè run láìsí àánú?
|
||
\c 2
|
||
\s1 Ìdáhùn Ọlọ́run sí ìráhùn wòlíì Habakuku
|
||
\q1
|
||
\v 1 \x - \xo 2.1: \xt Isa 21.8.\x*Èmi yóò dúró lórí ibusọ́ mi láti máa wòye,
|
||
\q2 èmi yóò sì gbé ara mi ka orí alóre,
|
||
\q1 èmi yóò si ṣọ́ láti gbọ́ ohun tí yóò sọ fún mi
|
||
\q2 àti èsì ti èmi yóò fún ẹ̀sùn yìí nígbà tó bá ń bá mi wí.
|
||
\s1 Ìdáhùn \nd Olúwa\nd*
|
||
\p
|
||
\v 2 Nígbà náà ni \nd Olúwa\nd* dáhùn pé,
|
||
\q1 “Kọ ìṣípayá náà sílẹ̀
|
||
\q2 kí o sì fi hàn ketekete lórí wàláà
|
||
\q2 kí ẹni tí ń kà á, lè máa sáré.
|
||
\q1
|
||
\v 3 \x - \xo 2.3: \xt Hb 10.37.\x*Nítorí ìṣípayá náà jẹ́ tí ìgbà kan tí a múra sílẹ̀ dè;
|
||
\q2 yóò máa yára sí ìgbẹ̀yìn
|
||
\q2 kí yóò sìsọ èké.
|
||
\q1 Bí o tilẹ̀ lọ́ra, dúró dè é;
|
||
\q2 nítorí, dájúdájú, yóò dé, kí yóò sí pẹ́.”
|
||
\b
|
||
\b
|
||
\q1
|
||
\v 4 \x - \xo 2.4: \xt Ro 1.17; Ga 3.11; Hb 10.38-39.\x*“Kíyèsi, ọkàn rẹ tí ó gbéga,
|
||
\q2 ìfẹ́ rẹ̀ kò dúró ṣinṣin nínú rẹ̀,
|
||
\q2 ṣùgbọ́n olódodo yóò wa nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.
|
||
\q1
|
||
\v 5 Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú, nítorí tí ọtí wáìnì ni ẹ̀tàn,
|
||
\q2 agbéraga ènìyàn òun, kò sì ní sinmi
|
||
\q1 ẹni tí ó sọ ìwọra rẹ di gbígbòòrò bí isà òkú,
|
||
\q2 ó sì dàbí ikú, a kò sì le tẹ́ ẹ lọ́rùn,
|
||
\q1 ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí ọ̀dọ̀
|
||
\q2 ó sì gba gbogbo ènìyàn jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.
|
||
\p
|
||
\v 6 “Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì yóò máa pa òwe sí i tí wọn yóò sì máa kọ orin òwe sí i wí pé,
|
||
\q1 “ ‘Ègbé ni fún ẹni tí ń mu ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ pọ̀ sí i!
|
||
\q2 Tí ó sì sọ ara rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ ìlọ́nilọ́wọ́gbà!
|
||
\q2 Eléyìí yóò ha ti pẹ́ tó?’
|
||
\q1
|
||
\v 7 Ǹjẹ́ ẹni ti ó yọ ọ́ lẹ́nu, kí yóò ha dìde ní òjijì?
|
||
\q2 Àti àwọn tí ó wàhálà rẹ kì yóò jí, kí wọn ó sì dẹ́rùbà ọ́?
|
||
\q2 Nígbà náà ni ìwọ yóò wa dí ìkógun fún wọn.
|
||
\q1
|
||
\v 8 Nítorí ìwọ ti kó Orílẹ̀-èdè púpọ̀,
|
||
\q2 àwọn ènìyàn tókù yóò sì kó ọ
|
||
\q1 nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; nítorí ẹ̀jẹ̀,
|
||
\q2 ìwọ tí pa ilẹ̀ àti ìlú ńlá run
|
||
\q2 àti gbogbo ènìyàn to ń gbé inú rẹ̀.
|
||
\b
|
||
\q1
|
||
\v 9 “Ègbé ni fún ẹni tí ń jẹ èrè ìjẹkújẹ sí ilé rẹ̀,
|
||
\q2 tí o sí gbé ìtẹ́ rẹ̀ lórí ibi gíga,
|
||
\q2 kí a ba le gbà á sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ibi!
|
||
\q1
|
||
\v 10 Ìwọ ti gbìmọ̀ ìtìjú sí ilé rẹ
|
||
\q2 nípa kíké ènìyàn púpọ̀ kúrò;
|
||
\q2 ìwọ sì ti pàdánù ẹ̀mí rẹ.
|
||
\q1
|
||
\v 11 Nítorí tí òkúta yóò kígbe jáde láti inú ògiri wá,
|
||
\q2 àti ìtí igi láti inú igi rírẹ́ wá yóò sì dá a lóhùn.
|
||
\b
|
||
\q1
|
||
\v 12 “Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ kọ́ ìlú,
|
||
\q2 tí o sì fi àìṣedéédéé tẹ ìlú ńlá dó?
|
||
\q1
|
||
\v 13 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun kò ha ti ṣètò rẹ̀ pé
|
||
\q2 làálàá àwọn ènìyàn jẹ́ epo fún iná
|
||
\q2 kí àwọn orílẹ̀-èdè náà sì máa ṣe wàhálà fún asán?
|
||
\q1
|
||
\v 14 Nítorí tí ayé yóò kún fún ìmọ̀ ògo \nd Olúwa\nd*,
|
||
\q2 bí omi ti bo Òkun.
|
||
\b
|
||
\q1
|
||
\v 15 “Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ohun mímu fún aládùúgbò rẹ̀,
|
||
\q2 tí ó sì fi ọtí-lílé rẹ̀ fún un, tí o sì jẹ́ kó mu àmupara,
|
||
\q2 kí ìwọ kí ó ba lè wo ìhòhò wọn.”
|
||
\q1
|
||
\v 16 Ìtìjú yóò bò ọ́ dípò ògo, ìwọ náà mu pẹ̀lú
|
||
\q2 kí ìhòhò rẹ kí ó lè hàn,
|
||
\q1 ago ọwọ́ ọ̀tún \nd Olúwa\nd*, yóò yípadà sí ọ,
|
||
\q2 ìtìjú yóò sì bo ògo rẹ.
|
||
\q1
|
||
\v 17 Nítorí ìwà ipá tí ó tí hù sí Lebanoni yóò bò ọ́,
|
||
\q2 àti ìparun àwọn ẹranko yóò dẹ́rùbà ọ́ mọ́lẹ̀.
|
||
\q1 Nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀;
|
||
\q2 ìwọ tí pa ilẹ̀ náà àti ìlú ńlá run àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
|
||
\b
|
||
\q1
|
||
\v 18 “Èrè kí ni òrìṣà ni, tí oníṣọ̀nà rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ,
|
||
\q2 ère dídá ti ń kọ ni èké?
|
||
\q1 Nítorí ti ẹni ti ó dá a gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé ohun tí ó fúnra rẹ̀ dá;
|
||
\q2 ó sì mọ ère tí kò le fọhùn.
|
||
\q1
|
||
\v 19 Ègbé ni fún ẹni ti ń sọ fún igi pé, ‘Di alààyè?’
|
||
\q2 Fún òkúta tí kò lè fọhùn pé, ‘Dìde.’
|
||
\q1 Ǹjẹ́ òun lè tọ́ ni sí ọ̀nà?
|
||
\q2 Wúrà àti fàdákà ni a fi bò ó yíká;
|
||
\q2 kò sì sí èémí kan nínú rẹ.”
|
||
\b
|
||
\q1
|
||
\v 20 \x - \xo 2.20: \xt Sf 1.7; Sk 2.13.\x*Ṣùgbọ́n \nd Olúwa\nd* wà nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀;
|
||
\q2 ẹ jẹ́ kí gbogbo ayé parọ́rọ́ níwájú rẹ.
|
||
\c 3
|
||
\s1 Àdúrà Habakuku
|
||
\d
|
||
\v 1 Àdúrà wòlíì Habakuku gẹ́gẹ́ bí \tl sígónótì.\tl* Ohun èlò orin.
|
||
\q1
|
||
\v 2 \nd Olúwa\nd* mo tí gbọ́ ohùn rẹ;
|
||
\q2 ẹ̀rù sì ba mi fún iṣẹ́ rẹ \nd Olúwa\nd*
|
||
\q1 sọ wọn di ọ̀tún ní ọjọ́ ti wa,
|
||
\q2 ní àkókò tiwa, jẹ́ kó di mí mọ̀;
|
||
\q2 ni ìbínú, rántí àánú.
|
||
\b
|
||
\q1
|
||
\v 3 Ọlọ́run yóò wa láti Temani,
|
||
\q2 ibi mímọ́ jùlọ láti òkè Parani
|
||
\q1 ògo rẹ̀ sí bo àwọn ọ̀run,
|
||
\q2 ilé ayé sì kún fún ìyìn rẹ.
|
||
\q1
|
||
\v 4 Dídán rẹ sí dàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn
|
||
\q2 ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ jáde wa láti ọwọ́ rẹ,
|
||
\q2 níbi tí wọn fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí.
|
||
\q1
|
||
\v 5 Àjàkálẹ̀-ààrùn ń lọ ni iwájú rẹ;
|
||
\q2 ìyọnu sí ń tọ ẹsẹ̀ rẹ lọ.
|
||
\q1
|
||
\v 6 Ó dúró, ó sì mi ayé;
|
||
\q2 ó wò, ó sì mú àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì
|
||
\q1 a sì tú àwọn òkè ńlá ayérayé ká,
|
||
\q2 àwọn òkè kéékèèké ayérayé sì tẹríba:
|
||
\q2 ọ̀nà rẹ ayérayé ni.
|
||
\q1
|
||
\v 7 Mo rí àgọ́ Kuṣani nínú ìpọ́njú
|
||
\q2 àti àwọn ibùgbé Midiani nínú ìrora.
|
||
\b
|
||
\q1
|
||
\v 8 Ǹjẹ́ ìwọ ha ń bínú sí àwọn odò nì, \nd Olúwa\nd*?
|
||
\q2 Ǹjẹ́ ìbínú rẹ wa lórí àwọn odò ṣíṣàn bí?
|
||
\q1 Ìbínú rẹ ha wá sórí Òkun
|
||
\q2 tí ìwọ fi ń gun ẹṣin,
|
||
\q2 àti kẹ̀kẹ́ ìgbàlà rẹ?
|
||
\q1
|
||
\v 9 A ṣí ọrun rẹ sílẹ̀ pátápátá,
|
||
\q2 gẹ́gẹ́ bí ìbúra àwọn ẹ̀yà, àní ọ̀rọ̀ rẹ,
|
||
\q1 ìwọ sì fi odò pín ilẹ̀ ayé.
|
||
\q2
|
||
\v 10 Àwọn òkè ńlá ri ọ wọn sì wárìrì
|
||
\q1 àgbàrá òjò ń sàn án kọjá lọ;
|
||
\q2 ibú ń ké ramúramù
|
||
\q2 ó sì gbé irú omi sókè.
|
||
\b
|
||
\q1
|
||
\v 11 Òòrùn àti Òṣùpá dúró jẹ́ẹ́jẹ́ ni ibùgbé wọn,
|
||
\q2 pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ ọfà rẹ ni wọn yára lọ,
|
||
\q2 àti ni dídán ọ̀kọ̀ rẹ ti ń kọ mànà.
|
||
\q1
|
||
\v 12 Ní ìrunú ni ìwọ rin ilẹ̀ náà já,
|
||
\q2 ní ìbínú ni ìwọ tí tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè rẹ.
|
||
\q1
|
||
\v 13 Ìwọ jáde lọ láti tú àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀,
|
||
\q2 àti láti gba ẹni àmì òróró rẹ là,
|
||
\q1 Ìwọ ti run àwọn olórí kúrò nínú ilẹ̀ àwọn ènìyàn búburú,
|
||
\q2 ó sì bọ ìhámọ́ra rẹ láti orí de ẹsẹ̀.
|
||
\q1
|
||
\v 14 Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ kí ó fi gún orí rẹ
|
||
\q2 nígbà tí àwọn jagunjagun rẹ̀
|
||
\q1 jáde láti tú wá ká,
|
||
\q2 ayọ̀ wọn sì ni láti jẹ tálákà run ní ìkọ̀kọ̀.
|
||
\q1
|
||
\v 15 Ìwọ fi ẹṣin rẹ rìn Òkun já,
|
||
\q2 ó sì da àwọn omi ńlá ru.
|
||
\b
|
||
\q1
|
||
\v 16 Mo gbọ́, ọkàn mi sì wárìrì,
|
||
\q2 ètè mi sì gbọ̀n sí ìró náà;
|
||
\q1 ìbàjẹ́ sì wọ inú egungun mi lọ,
|
||
\q2 ẹsẹ̀ mi sì wárìrì,
|
||
\q1 mo dúró ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ fún ọjọ́ ìdààmú
|
||
\q2 láti de sórí àwọn ènìyàn tó ń dojúkọ wá.
|
||
\q1
|
||
\v 17 Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ ko tilẹ̀ tanná,
|
||
\q2 tí èso kò sí nínú àjàrà;
|
||
\q1 tí igi olifi ko le so,
|
||
\q2 àwọn oko ko sì mú oúnjẹ wá;
|
||
\q1 tí a sì ké agbo ẹran kúrò nínú agbo,
|
||
\q2 tí kò sì sí ọwọ́ ẹran ni ibùso mọ́,
|
||
\q1
|
||
\v 18 síbẹ̀, èmi ó láyọ̀ nínú \nd Olúwa\nd*,
|
||
\q2 èmi yóò sí máa yọ nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.
|
||
\b
|
||
\q1
|
||
\v 19 \nd Olúwa\nd* Olódùmarè ni agbára mi,
|
||
\q2 òun yóò sí ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín,
|
||
\q2 yóò sí mú mi rìn lórí ibi gíga.
|
||
\d Sí olórí akọrin lórí ohun èlò orin olókùn mi.
|