Biblica_yoOBYO17/23ISAyoOBYO17.SFM

6360 lines
292 KiB
Plaintext
Raw Permalink Blame History

This file contains invisible Unicode characters

This file contains invisible Unicode characters that are indistinguishable to humans but may be processed differently by a computer. If you think that this is intentional, you can safely ignore this warning. Use the Escape button to reveal them.

This file contains Unicode characters that might be confused with other characters. If you think that this is intentional, you can safely ignore this warning. Use the Escape button to reveal them.

\id ISA - Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible (Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
\rem Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
\h Isaiah
\toc1 Ìwé Wòlíì Isaiah
\toc2 Isaiah
\toc3 Isa
\mt1 Ìwé Wòlíì Isaiah
\c 1
\p
\v 1 Ìran sí Juda àti Jerusalẹmu èyí tí Isaiah ọmọ Amosi rí ní àsìkò ìjọba Ussiah, Jotamu, Ahasi àti Hesekiah àwọn ọba Juda.
\b
\s1 Ọlọ̀tẹ̀ orílẹ̀-èdè kan
\q1
\v 2 Gbọ́ ẹ̀yin ọ̀run! Fi etí sílẹ̀, ìwọ ayé!
\q2 Nítorí \nd Olúwa\nd* ti sọ̀rọ̀:
\q1 “Mo tọ́ àwọn ọmọ dàgbà,
\q2 ṣùgbọ́n wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi.
\q1
\v 3 Màlúù mọ olówó rẹ̀,
\q2 kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ olówó rẹ̀,
\q1 ṣùgbọ́n Israẹli kò mọ̀,
\q2 òye kò yé àwọn ènìyàn mi.”
\b
\q1
\v 4 Á à! Orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀,
\q2 àwọn ènìyàn tí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lẹ́rù,
\q1 ìran àwọn aṣebi,
\q2 àwọn ọmọ tó ti di aṣèbàjẹ́!
\q1 Wọn ti kọ \nd Olúwa\nd* sílẹ̀
\q2 wọn ti gan Ẹni Mímọ́ Israẹli,
\q1 wọn sì ti kẹ̀yìn sí i.
\b
\q1
\v 5 Èéṣe tí a ó fi tún lù yín mọ́?
\q2 Èéṣe tí ẹ ò dẹ́kun ọ̀tẹ̀ ṣíṣe?
\q1 Gbogbo orí yín jẹ́ kìkì ọgbẹ́,
\q2 gbogbo ọkàn yín sì ti pòruurù.
\q1
\v 6 Láti àtẹ́lẹsẹ̀ yín dé àtàrí yín
\q2 kò sí àlàáfíà rárá,
\q1 àyàfi ọgbẹ́ òun ìfarapa
\q2 àti ojú egbò,
\q2 tí a kò nù kúrò tàbí kí á dì tàbí kí a kùn ún ní òróró.
\b
\q1
\v 7 Orílẹ̀-èdè yín dahoro,
\q2 a dáná sun àwọn ìlú yín,
\q1 oko yín ni àwọn àjèjì ti jẹ run
\q2 lójú ara yín náà,
\q1 ni gbogbo rẹ̀ ṣòfò bí èyí tí
\q2 àwọn àjèjì borí rẹ̀.
\q1
\v 8 Ọmọbìnrin Sioni ni a fi sílẹ̀
\q2 gẹ́gẹ́ bí àtíbàbà nínú ọgbà àjàrà,
\q1 gẹ́gẹ́ bí abà nínú oko ẹ̀gúnsí,
\q2 àti bí ìlú tí a dó tì.
\q1
\v 9 Àyàfi bí \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun
\q2 bá ṣẹ́ díẹ̀ kù fún wà,
\q1 a ò bá ti rí bí Sodomu,
\q2 a ò bá sì ti dàbí Gomorra.
\b
\q1
\v 10 Gbọ́ ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd*,
\q2 ẹ̀yin aláṣẹ Sodomu,
\q1 tẹ́tí sí òfin Ọlọ́run wa,
\q2 ẹ̀yin ènìyàn Gomorra!
\q1
\v 11 “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín
\q2 kín ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín jásí fún mi?” ni \nd Olúwa\nd* wí.
\q1 “Mo ti ní ànító àti àníṣẹ́kù ẹbọ sísun
\q2 ti àgbò àti ọ̀rá ẹran àbọ́pa,
\q1 Èmi kò ní inú dídùn
\q2 nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù, ti àgùntàn àti ti òbúkọ.
\q1
\v 12 Nígbà tí ẹ wá farahàn níwájú mi,
\q2 ta ni ó béèrè èyí lọ́wọ́ yín,
\q2 gìrì gìrì ẹsẹ̀ nínú àgbàlá mi?
\q1
\v 13 Ẹ má mú ọrẹ asán wá mọ́!
\q2 Ìríra ni tùràrí yín jásí fún mi,
\q1 oṣù tuntun àti ọjọ́ ìsinmi àti àwọn àpéjọ,
\q2 Èmi kò lè faradà á, ẹ̀ṣẹ̀ ni àpéjọ yín wọ̀nyí.
\q1
\v 14 Ayẹyẹ oṣù tuntun yín àti àjọ̀dún tí a yàn,
\q2 ni ọkàn mi kórìíra.
\q1 Wọ́n ti di àjàgà sí mi ní ọrùn,
\q2 Ó sú mi láti fi ara dà wọ́n.
\q1
\v 15 Nígbà tí ẹ bá tẹ́ ọwọ́ yín sókè ni àdúrà,
\q2 Èmi yóò fi ojú mi pamọ́ fún un yín,
\q1 kódà bí ẹ bá gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà,
\q2 Èmi kò ni tẹ́tí sí i.
\b
\q1 “Ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀.
\b
\q1
\v 16 “Wẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí ara yín mọ́.
\q2 Ẹ mú ìwà ibi yín kúrò níwájú mi!
\q2 Dáwọ́ àìṣedéédéé dúró,
\q1
\v 17 kọ́ láti ṣe rere!
\q2 Wá ìdájọ́ òtítọ́,
\q1 tu àwọn tí a ń pọ́n lójú nínú.
\q2 Ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,
\q2 gbà ẹjọ́ opó rò.
\b
\q1
\v 18 “Ẹ wá ní ìsinsin yìí, ẹ jẹ́ kí a jọ ṣàṣàrò,”
\q2 ni \nd Olúwa\nd* wí.
\q1 “Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín bá rí bí osùn,
\q2 wọn ó sì funfun bí i yìnyín,
\q1 bí wọn bá sì pọ́n bí ẹ̀jẹ̀,
\q2 wọn ó sì dàbí ẹ̀gbọ̀n òwú.
\q1
\v 19 Tí ẹ̀yin bá fẹ́, tí ẹ sì gbọ́rọ̀,
\q2 ẹ̀yin yóò sì jẹ ojúlówó adùn ilẹ̀ náà.
\q1
\v 20 Ṣùgbọ́n tí ẹ bá kọ̀ tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀,
\q2 idà ni a ó fi pa yín run.”
\q1 Nítorí ẹnu \nd Olúwa\nd* la ti sọ ọ́.
\b
\q1
\v 21 Wo bí ìlú òtítọ́ ṣe di àgbèrè!
\q2 Ó ti kún fún ìdájọ́ òtítọ́ nígbà kan rí,
\q1 òdodo ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí,
\q2 ṣùgbọ́n báyìí àwọn apànìyàn!
\q1
\v 22 Fàdákà rẹ ti di ìpẹ́pẹ́,
\q2 ààyò wáìnì rẹ la ti bu omi là.
\q1
\v 23 Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn aláṣẹ yín,
\q2 akẹgbẹ́ àwọn olè,
\q1 gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀
\q2 wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri.
\q1 Wọ́n kì í ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,
\q2 ẹjọ́ opó kì í sì í dé iwájú wọn.
\b
\q1
\v 24 Nítorí náà ni Olúwa, \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun,
\q2 alágbára kan ṣoṣo tí Israẹli sọ wí pé:
\q1 “Á à! Èmi yóò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá mi
\q2 n ó sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi.
\q1
\v 25 Èmi yóò pa ọwọ́ mi dà sí ọ,
\q2 èmi ó sì ku ìpẹ́pẹ́ rẹ dànù,
\q2 n ó sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò.
\q1
\v 26 Èmi yóò mú àwọn adájọ́ rẹ bọ̀ sí ipò gẹ́gẹ́ bí i ti àtijọ́,
\q2 àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ bí i ti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.
\q2 Lẹ́yìn náà ni a ó pè ọ ní ìlú òdodo, ìlú òtítọ́.”
\b
\q1
\v 27 A ó fi ìdájọ́ òtítọ́ ra Sioni padà,
\q2 àti àwọn tí ó ronúpìwàdà pẹ̀lú òdodo.
\q1
\v 28 Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni a ó parun.
\q2 Àwọn tí ó bá sì kọ \nd Olúwa\nd* sílẹ̀ ni yóò ṣègbé.
\b
\q1
\v 29 “Ojú yóò tì yín nítorí igi óákù mímọ́
\q2 èyí tí ẹ ní inú dídùn sí,
\q1 a ó kàn yín lábùkù nítorí àwọn ọgbà yìí
\q2 tí ẹ ti yàn fúnra yín.
\q1
\v 30 Ẹ ó sì dàbí igi óákù tí ewé rẹ̀ ti rọ,
\q2 bí ọgbà tí kò ní omi.
\q1
\v 31 Alágbára ọkùnrin náà yóò sì dàbí ohun ìdáná,
\q2 iṣẹ́ rẹ̀ bí ẹ̀ṣẹ́-iná,
\q1 àwọn méjèèjì ni yóò jóná papọ̀,
\q2 láìsí ẹni tí yóò lè pa iná yìí.”
\c 2
\s1 Òkè \nd Olúwa\nd*
\p
\v 1 Èyí ni ohun tí Isaiah ọmọ Amosi rí nípa Juda àti Jerusalẹmu.
\b
\p
\v 2 \x - \xo 2.2-4: \xt Mt 4.1-3.\x*Ní ìgbẹ̀yìn ọjọ́
\q1 òkè tẹmpili \nd Olúwa\nd* ni a ó fi ìdí rẹ̀ kalẹ̀
\q2 gẹ́gẹ́ bí olú nínú àwọn òkè,
\q1 a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ,
\q2 gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì máa sàn sínú un rẹ̀.
\p
\v 3 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò wá, wọn yóò sì wí pé,
\q1 “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá \nd Olúwa\nd*,
\q2 àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu.
\q1 Òun yóò kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀,
\q2 kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.”
\q1 Òfin yóò jáde láti Sioni wá,
\q2 àti ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* láti Jerusalẹmu.
\q1
\v 4 Òun ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
\q2 yóò sì parí aáwọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn.
\q1 Wọn yóò fi idà wọn rọ ọkọ́ ìtulẹ̀,
\q2 wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé.
\q1 Orílẹ̀-èdè kì yóò sì gbé idà sí orílẹ̀-èdè mọ́,
\q2 bẹ́ẹ̀ ní wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.
\b
\q1
\v 5 Wá, ẹ̀yìn ará ilé e Jakọbu,
\q2 ẹ jẹ́ kí a rìn nínú ìmọ́lẹ̀ \nd Olúwa\nd*.
\s1 Ọjọ́ \nd Olúwa\nd*
\q1
\v 6 Ìwọ ti kọ àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀,
\q2 ìwọ ilé Jakọbu.
\q1 Wọ́n kún fún ìgbàgbọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí ó ti ìlà-oòrùn wá,
\q2 wọ́n ń wo iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn Filistini,
\q2 wọ́n ń pa ọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn abọ̀rìṣà.
\q1
\v 7 Ilẹ̀ wọn kún fún fàdákà àti wúrà,
\q2 ìṣúra wọn kò sì ní òpin.
\q1 Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ẹṣin,
\q2 kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lópin.
\q1
\v 8 Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ère,
\q2 wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn,
\q2 èyí tí ìka ọwọ́ àwọn tìkára wọn ti ṣe.
\q1
\v 9 Nítorí náà ni a ó ṣe rẹ ènìyàn sílẹ̀
\q2 ìran ọmọ ènìyàn ni yóò sì di onírẹ̀lẹ̀,
\q2 má ṣe dáríjì wọ́n.
\b
\q1
\v 10 Wọ inú àpáta lọ,
\q2 fi ara pamọ́ nínú erùpẹ̀
\q1 kúrò nínú ìpayà \nd Olúwa\nd*,
\q2 àti ògo ọláńlá rẹ̀!
\q1
\v 11 Ojú agbéraga ènìyàn ni a ó rẹ̀ sílẹ̀
\q2 a ó sì tẹrí ìgbéraga ènìyàn ba,
\q2 \nd Olúwa\nd* nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà.
\b
\q1
\v 12 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan ní ìpamọ́
\q2 fún gbogbo agbéraga àti ọlọ́kàn gíga
\q2 nítorí gbogbo àwọn tí a gbéga (ni a ó rẹ̀ sílẹ̀),
\q1
\v 13 nítorí gbogbo igi kedari Lebanoni, tó ga tó rìpó
\q2 àti gbogbo óákù Baṣani,
\q1
\v 14 nítorí gbogbo òkè gíga ńlá ńlá
\q2 àti àwọn òkè kéékèèké,
\q1
\v 15 fún ilé ìṣọ́ gíga gíga
\q2 àti àwọn odi ìdáàbòbò,
\q1
\v 16 fún gbogbo ọkọ̀ àwọn oníṣòwò
\q2 àwọn ọkọ̀ tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.
\q1
\v 17 Ìgbéraga ènìyàn ni a ó tẹ̀ lórí ba
\q2 a ó sì rẹ ìgbéraga ènìyàn sílẹ̀,
\q2 \nd Olúwa\nd* nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà,
\q1
\v 18 gbogbo ère òrìṣà yóò pòórá.
\b
\q1
\v 19 Àwọn ènìyàn yóò sálọ sínú ihò àpáta
\q2 àti sínú ihò ilẹ̀
\q1 kúrò lọ́wọ́ ìpayà \nd Olúwa\nd*
\q2 àti ògo ọláńlá rẹ̀,
\q2 nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.
\q1
\v 20 Ní ọjọ́ náà ni àwọn ènìyàn yóò máa sọ
\q2 àwọn ère fàdákà àti ère wúrà
\q1 tí wọ́n ti yá fún bíbọ
\q2 sí èkúté àti àwọn àdán.
\q1
\v 21 Wọn yóò sálọ sínú ihò ìsàlẹ̀ àpáta
\q2 àti sínú ihò pàlàpálá àpáta
\q1 kúrò lọ́wọ́ ìpayà \nd Olúwa\nd*
\q2 àti ògo ọláńlá rẹ̀,
\q2 nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.
\b
\q1
\v 22 Dẹ́kun à ń gba ènìyàn gbọ́,
\q2 èémí ẹni tó wà ní ihò imú rẹ̀.
\q1 Nítorí nínú kín ni a lè kà á sí?
\c 3
\s1 Ìdájọ́ lórí i Jerusalẹmu àti Juda
\q1
\v 1 Kíyèsi i, Olúwa,
\q2 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun,
\q1 fẹ́ mú ìpèsè àti ìrànlọ́wọ́ kúrò ní Jerusalẹmu àti Juda
\q2 gbogbo ìpèsè oúnjẹ àti ìpèsè omi.
\q1
\v 2 Àwọn akíkanjú àti jagunjagun,
\q2 adájọ́ àti wòlíì,
\q2 aláfọ̀ṣẹ àti alàgbà,
\q1
\v 3 balógun àádọ́ta àti àwọn ènìyàn, onípò gíga;
\q2 olùdámọ̀ràn, oníṣọ̀nà tí ó dáńtọ́ àti ògbójú oníṣègùn.
\b
\q1
\v 4 “Èmi ó sọ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin di aláṣẹ wọn,
\q2 ọ̀dọ́mọdé lásán làsàn ni yóò sì
\q2 máa jẹ ọba lórí i wọn.”
\b
\q1
\v 5 Àwọn ènìyàn yóò sì máa pọ́n ọmọnìkejì,
\q2 wọn lójú ẹnìkan sí ẹnìkejì rẹ̀, aládùúgbò sí aládùúgbò rẹ̀.
\q1 Àwọn ọ̀dọ́ yóò gbógun ti àwọn àgbàgbà,
\q2 àwọn mẹ̀kúnnù yóò dìde sí ọlọ́lá.
\b
\q1
\v 6 Ọkùnrin kan yóò di ọ̀kan nínú àwọn
\q2 arákùnrin rẹ̀ mú,
\q1 nínú ilé baba rẹ̀, yóò sì wí pé,
\q2 “Ìwọ́ ní aṣọ, ìwọ máa ṣe olórí wa,
\q2 sì mójútó àwọn ahoro wọ̀nyí!”
\q1
\v 7 Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà ni yóò figbe bọnu pé,
\q2 “Èmi kò ní àtúnṣe kan.
\q1 Èmi kò ní oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni n ó ní aṣọ nílé,
\q2 ẹ má fi mí ṣe olórí àwọn ènìyàn náà.”
\b
\q1
\v 8 Jerusalẹmu ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n
\q2 Juda ń ṣubú lọ,
\q1 ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn lòdì sí \nd Olúwa\nd*,
\q2 láti mú ojú ògo rẹ̀ bínú.
\q1
\v 9 Ìwò ojú wọn ń jẹ́rìí lòdì sí wọn,
\q2 wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí i Sodomu;
\q1 wọn ò fi pamọ́!
\q2 Ègbé ni fún wọn!
\q2 Wọ́n ti mú ìparun wá sórí ara wọn.
\b
\q1
\v 10 Ẹ sọ fún olódodo pé yóò dára fún wọn,
\q2 nítorí ní àjẹgbádùn ni wọn yóò jẹ èso iṣẹ́ ẹ wọn.
\q1
\v 11 Ègbé ni fún ènìyàn búburú! Ìparun wà lórí i wọn,
\q2 a ó sì san èrè iṣẹ́ tí ọwọ́ wọn ti ṣe fún wọn.
\b
\q1
\v 12 Àwọn ọ̀dọ́mọdé ni o ń pọ́n àwọn ènìyàn mi lójú
\q2 àwọn obìnrin ń jẹ ọba lé wọn lórí.
\q1 Háà! Ènìyàn mi àwọn afinimọ̀nà yín ti ṣì yín lọ́nà,
\q2 wọn sì mú yín kúrò ní ipa ọ̀nà yín.
\b
\q1
\v 13 \nd Olúwa\nd* bọ sí ipò rẹ̀ ní ìtẹ́ ìdájọ́
\q2 Ó dìde láti dá àwọn ènìyàn lẹ́jọ́.
\q1
\v 14 \nd Olúwa\nd* dojú ẹjọ́ kọ
\q2 àwọn àgbàgbà àti àwọn olórí àwọn ènìyàn rẹ̀.
\q1 “Ẹ̀yin ni ẹ ti run ọgbà àjàrà mi,
\q2 ogún àwọn tálákà ń bẹ̀ nínú ilé yín.
\q1
\v 15 Kín ni èrò yín láti máa run àwọn ènìyàn mi túútúú
\q2 tí ẹ sì fojú àwọn tálákà ni gbolẹ̀?”
\q2 ni Olúwa wí, \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun.
\b
\q1
\v 16 \nd Olúwa\nd* wí pé,
\q2 “Àwọn obìnrin Sioni jẹ́ agbéraga,
\q1 wọn ń rìn lọ pẹ̀lú ọrùn tí ó nà tàntàn,
\q2 tí wọn ń fojú pe ọkùnrin,
\q1 tí wọn ń sọ̀dí bí wọ́n ti ń yan lọ
\q2 pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ tí ń mì wọnjanwọnjan lọ́rùn ẹsẹ̀ wọn.
\q1
\v 17 Nítorí náà Olúwa yóò mú egbò wá sórí àwọn obìnrin Sioni,
\q2 \nd Olúwa\nd* yóò sì pá wọn ní agbárí.”
\p
\v 18 Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò já ọ̀ṣọ́ wọn gbà kúrò ti ọwọ́ àti gèlè àti ẹ̀gbà ọrùn tí ó dàbí òṣùpá
\v 19 gbogbo yẹtí, ẹ̀gbà ọwọ́ àti ìbòjú,
\v 20 gbogbo gèlè, ẹ̀gbà ọrùn, ẹsẹ̀ àti àyà, àwọn ìgò tùràrí àti òògùn,
\v 21 òrùka ọwọ́ àti ti imú,
\v 22 àwọn àtàtà aṣọ, àwọ̀lékè, agbádá àti àpamọ́wọ́,
\v 23 dígí wọn, aṣọ funfun nigínnigín ìbòrí àti ìbòjú.
\q1
\v 24 Dípò òórùn dídùn, òórùn búburú ni yóò wá,
\q2 okùn ni yóò wà dípò àmùrè,
\q1 orí pípá ni yóò dípò irun ti a ṣe ní ọ̀ṣọ́
\q2 aṣọ ọ̀fọ̀ ni yóò dípò aṣọ ẹ̀yẹ ìjóná dípò ẹwà.
\q1
\v 25 Àwọn ọkùnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú,
\q2 àti àwọn jagunjagun rẹ̀ lójú ogun.
\q1
\v 26 Àwọn bodè Sioni yóò sọkún kíkorò, wọn ó ṣọ̀fọ̀,
\q2 nítorí ó dahoro, yóò jókòó ní orí ilẹ̀.
\c 4
\q1
\v 1 Ní ọjọ́ náà, obìnrin méje
\q2 yóò dì mọ́ ọkùnrin kan
\q1 yóò sì wí pé, “Àwa ó máa jẹ oúnjẹ ara wa
\q2 a ó sì pèsè aṣọ ara wa;
\q1 sá à jẹ́ kí a máa fi orúkọ rẹ̀ pè wá.
\q2 Mú ẹ̀gàn wa kúrò!”
\s1 Ẹ̀ka \nd Olúwa\nd* náà
\p
\v 2 \x - \xo 4.2: \xt Jr 23.5; 33.15; Sk 3.8; 6.12.\x*Ní ọjọ́ náà, ẹ̀ka \nd Olúwa\nd* yóò ní ẹwà àti ògo, èso ilẹ̀ náà yóò sì jẹ́ ìgbéraga àti ògo àwọn ti ó sálà ní Israẹli.
\v 3 Àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Sioni, àwọn tí o kù ní Jerusalẹmu, ni a ó pè ní mímọ́, orúkọ àwọn ẹni tí a kọ mọ́ àwọn alààyè ní Jerusalẹmu.
\v 4 Olúwa yóò wẹ ẹ̀gbin àwọn obìnrin Sioni kúrò yóò sì fọ gbogbo àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ kúrò ní Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹ̀mí ìdájọ́ àti ẹ̀mí iná.
\v 5 Lẹ́yìn náà, \nd Olúwa\nd* yóò dá sórí òkè Sioni àti sórí i gbogbo àwọn tí ó péjọpọ̀ síbẹ̀, kurukuru èéfín ní ọ̀sán àti ìtànṣán ọ̀wọ́-iná ní òru, lórí gbogbo ògo yìí ni ààbò yóò wà.
\v 6 Èyí ni yóò jẹ́ ààbò àti òjìji kúrò lọ́wọ́ ooru ọ̀sán, àti ààbò òun ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ ìjì àti òjò.
\c 5
\s1 Orin ọgbà àjàrà náà
\q1
\v 1 \x - \xo 5.1-7: \xt Mt 21.33-46; Mk 12.1-12; Lk 20.9-19.\x*Èmi yóò kọrin fún ẹni tí mo fẹ́ràn
\q2 orin kan nípa ọgbà àjàrà rẹ̀.
\q1 Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kan
\q2 ní ẹ̀gbẹ́ òkè ẹlẹ́tù lójú.
\q1
\v 2 Ó tu ilẹ̀ rẹ̀, ó ṣa òkúta ibẹ̀ kúrò
\q2 ó sì gbin àyànfẹ́ àjàrà sí i.
\q1 Ó kọ́ ilé ìṣọ́ sí inú rẹ̀
\q2 ó sì ṣe ìfúntí kan síbẹ̀ pẹ̀lú.
\q1 Lẹ́yìn náà, ó ń retí èso àjàrà dáradára,
\q2 ṣùgbọ́n èso búburú ni ó ti ibẹ̀ wá.
\b
\q1
\v 3 “Ní ìsinsin yìí ẹ̀yin olùgbé Jerusalẹmu
\q2 àti ẹ̀yin ènìyàn Juda
\q1 ẹ ṣe ìdájọ́ láàrín èmi àti
\q2 ọgbà àjàrà mi.
\q1
\v 4 Kín ni ó kù tí n ò bá túnṣe sí ọgbà àjàrà mi.
\q2 Ju èyí tí mo ti ṣe lọ?
\q1 Nígbà tí mo ń wá èso dáradára,
\q2 èéṣe tí ó fi so kíkan?
\q1
\v 5 Ní ìsinsin yìí, èmi yóò wí fún ọ
\q2 ohun tí n ó ṣe sí ọgbà àjàrà mi.
\q1 Èmi yóò gé igi inú rẹ̀ kúrò,
\q2 a ó sì pa á run,
\q1 Èmi yóò wó ògiri rẹ̀ lulẹ̀
\q2 yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.
\q1
\v 6 Èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro
\q2 láì kọ ọ́ láì ro ó,
\q1 ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún ni yóò hù níbẹ̀.
\q2 Èmi yóò sì pàṣẹ fún kurukuru
\q2 láti má ṣe rọ̀jò sórí i rẹ̀.”
\b
\q1
\v 7 Ọgbà àjàrà \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun
\q2 ni ilé Israẹli
\q1 àwọn ọkùnrin Juda
\q2 sì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀.
\q1 Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọ́n, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni ó rí.
\q2 Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ́ ẹkún ìpayínkeke.
\s1 Ègún àti ìdájọ́
\q1
\v 8 Ègbé ni fún àwọn tí ń kọ́lé mọ́lé
\q2 tí ó sì ń ra ilẹ̀ mọ́lẹ̀
\q1 tó bẹ́ẹ̀ tí ààyè kò ṣẹ́kù
\q2 tí ó sì nìkan gbé lórí ilẹ̀.
\p
\v 9 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun ti sọ ọ́ sí mi létí:
\q1 “Ó dájú pé àwọn ilé ńlá ńlá
\q2 yóò di ahoro, àwọn ilé dáradára yóò wà láìní olùgbé.
\q1
\v 10 Ọgbà àjàrà sáré oko mẹ́wàá yóò mú
\q2 ìkòkò wáìnì kan wá,
\q1 nígbà tí òsùwọ̀n homeri kan yóò mú
\q2 agbọ̀n irúgbìn kan wá.”
\b
\q1
\v 11 Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n dìde
\q2 ní kùtùkùtù òwúrọ̀
\q1 láti lépa ọtí líle,
\q2 tí wọ́n sì mu ún títí alẹ́ fi lẹ́
\q2 títí wọ́n fi gbinájẹ pẹ̀lú wáìnì.
\q1
\v 12 Wọ́n ní dùùrù àti ohun èlò orin olókùn níbi àsè wọn,
\q2 ṣaworo òun fèrè àti wáìnì,
\q1 ṣùgbọ́n wọn kò ka iṣẹ́ \nd Olúwa\nd* sí,
\q2 wọn kò sí bọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
\q1
\v 13 Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò lọ sí ìgbèkùn
\q2 nítorí òye kò sí fún wọn,
\q1 ebi ni yóò pa àwọn ọlọ́lá wọn kú;
\q2 ẹgbàágbèje wọn ni òǹgbẹ yóò sì gbẹ.
\q1
\v 14 Nítorí náà isà òkú ti ń dátọ́mì gidigidi,
\q2 ó sì ti ya ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbagada,
\q1 nínú rẹ̀ ni àwọn gbajúmọ̀ àti mẹ̀kúnnù yóò sọ̀kalẹ̀ sí
\q2 pẹ̀lú ọlá àti ògo wọn.
\q1
\v 15 Báyìí, ènìyàn yóò di ìrẹ̀sílẹ̀
\q2 àti ọmọ ènìyàn ni a sọ di onírẹ̀lẹ̀
\q2 ojú agbéraga ni a sì rẹ̀ sílẹ̀.
\q1
\v 16 Ṣùgbọ́n \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun ni a ó gbéga nípa ẹ̀tọ́ rẹ̀,
\q2 Ọlọ́run ẹni mímọ́ yóò sì fi ara rẹ̀ hàn ní mímọ́ nípa òdodo rẹ̀.
\q1
\v 17 Nígbà náà ni àwọn àgùntàn yóò máa jẹ́ ko ní ibùgbé e wọn,
\q2 àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yóò máa jẹ nínú ahoro àwọn ọlọ́rọ̀.
\b
\q1
\v 18 Ègbé ni fún àwọn tí ń fi ohun asán fa ẹ̀ṣẹ̀,
\q2 àti àwọn tí o dàbí ẹni pé wọ́n ń fi okùn kẹ̀kẹ́ ẹ̀sìn fa ẹsẹ̀,
\q1
\v 19 sí àwọn tí ó sọ pé, “Jẹ́ kí Ọlọ́run ṣe kíákíá,
\q2 jẹ́ kí ó yára ṣiṣẹ́ rẹ̀ kí a lè rí i,
\q2 jẹ́ kí ó súnmọ́ bí
\q1 jẹ́ kí ètò ẹni mímọ́ Israẹli kí ó dé,
\q2 kí àwa kí ó le mọ̀ ọ́n.”
\b
\q1
\v 20 Ègbé ni fún àwọn tí ń pe ibi ní rere, àti rere ní ibi,
\q2 tí ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn,
\q2 tí ń fi ìkorò ṣe adùn àti adùn ṣe ìkorò.
\b
\q1
\v 21 Ègbé ni fún àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn
\q2 tí wọ́n jáfáfá lójú ara wọn.
\b
\q1
\v 22 Ègbé ni fún àwọn akọni nínú wáìnì mímu
\q2 àti àwọn akíkanjú nínú àdàlú ọtí,
\q1
\v 23 tí wọ́n dá ẹlẹ́bi sílẹ̀ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀,
\q2 tí wọn sì du aláre ní ẹ̀tọ́.
\q1
\v 24 Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ahọ́n iná ṣe ń jó àgékù koríko run
\q2 àti bí koríko ṣe rẹlẹ̀ wẹ̀sì nínú iná,
\q1 bẹ́ẹ̀ ni egbò wọn yóò jẹrà
\q2 tí òdodo wọn yóò sì fẹ́ lọ bí eruku:
\q1 nítorí pé wọ́n ti kọ òfin \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun sílẹ̀
\q2 wọ́n sì gan ọ̀rọ̀ Ẹni mímọ́ Israẹli.
\q1
\v 25 Nítorí náà, ìbínú \nd Olúwa\nd* gbóná si àwọn ènìyàn rẹ̀,
\q2 ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì lù wọ́n bolẹ̀.
\q1 Àwọn òkè sì wárìrì,
\q2 òkú wọn sì dàbí ààtàn ní àárín ìgboro.
\q1 Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò,
\q2 ṣùgbọ́n ọ̀wọ́ rẹ̀ sì ná jáde síbẹ̀.
\b
\q1
\v 26 Yóò sì gbé ọ̀págun sókè sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà,
\q2 yóò sì kọ sí wọn tí ó wà ní ìpẹ̀kun ilẹ̀.
\q2 Sì kíyèsi, wọ́n yóò yára wá kánkán.
\q1
\v 27 Kò sí ẹni tí yóò rẹ̀ nínú wọn, tàbí tí yóò kọsẹ̀,
\q2 kò sí ẹni tí yóò tòògbé tàbí tí yóò sùn;
\q1 bẹ́ẹ̀ ni àmùrè ẹ̀gbẹ́ wọn kì yóò tú,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni okùn sálúbàtà wọn kì yóò ja.
\q1
\v 28 Àwọn ọfà wọn múná,
\q2 gbogbo ọrun wọn sì le;
\q1 pátákò àwọn ẹṣin wọn le bí òkúta akọ,
\q2 àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ wọn sì dàbí ìjì líle.
\q1
\v 29 Bíbú wọn dàbí tí kìnnìún,
\q2 wọ́n bú bí ẹgbọrọ kìnnìún,
\q1 wọ́n ń kọ bí wọ́n ti di ẹran ọdẹ wọn mú
\q2 tí wọn sì gbé e lọ láìsí ẹni tí yóò gbà á là.
\q1
\v 30 Ní ọjọ́ náà, wọn yóò hó lé e lórí
\q2 gẹ́gẹ́ bí i rírú omi Òkun.
\q1 Bí ènìyàn bá sì wo ilẹ̀,
\q2 yóò rí òkùnkùn àti ìbànújẹ́;
\q2 pẹ̀lúpẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn pẹ̀lú kurukuru rẹ̀.
\c 6
\s1 Ìpè sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ Isaiah
\p
\v 1 Ní ọdún tí ọba Ussiah kú, mo rí Olúwa tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga tí a gbé sókè, ìṣẹ́tí aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili.
\v 2 Àwọn Serafu wà ní òkè rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà, wọ́n fi ìyẹ́ méjì bo ojú wọn, wọ́n fi méjì bo ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sí ń fi méjì fò.
\v 3 \x - \xo 6.3: \xt If 4.8.\x*Wọ́n sì ń kọ sí ara wọn wí pé,
\q1 “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun
\q2 gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”
\m
\v 4 \x - \xo 6.4: \xt If 15.8.\x*Nípa ìró ohùn un wọn, òpó ìlẹ̀kùn àti gbogbo ògiri ilé náà sì mì tìtì, gbogbo inú tẹmpili sì kún fún èéfín.
\p
\v 5 Mo kígbe pé, “Ègbé ni fún mi! Mo ti gbé!” Nítorí mo jẹ́ ènìyàn aláìmọ́ ètè, mo sì ń gbé láàrín àwọn ènìyàn aláìmọ́ ètè, ojú mi sì ti rí ọba, \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun jùlọ.
\p
\v 6 Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn Serafu wọ̀nyí fò wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹ̀yín iná ní ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó ti fi ẹ̀mú mú ní orí pẹpẹ.
\v 7 Èyí ni ó fi kàn mí ní ẹnu tí ó sì wí pé, “Wò ó, èyí ti kan ètè rẹ; a ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù.”
\p
\v 8 Nígbà náà ni mo sì gbọ́ ohùn Olúwa wí pé, “Ta ni èmi yóò rán? Ta ni yóò sì lọ fún wa?”
\p Nígbà náà ni èmi sì wí pé, “Èmi nìyí, rán mi!”
\p
\v 9 \x - \xo 6.9-10: \xt Mt 13.14-15; Mk 4.12; Lk 8.10; Jh 12.39-41; Ap 28.26-27.\x*Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn yìí lọ kí o sì wí fún wọn pé,
\q1 “Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín;
\q2 ní rí rí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.
\q1
\v 10 Mú kí àyà àwọn ènìyàn wọ̀nyí yigbì,
\q2 mú kí etí wọn kí ó wúwo,
\q2 kí o sì dìwọ́n ní ojú.
\q1 Kí wọn kí ó má ba fi ojú wọn ríran,
\q2 kí wọn kí ó má ba fi etí wọn gbọ́rọ̀,
\q1 kí òye kí ó má ba yé ọkàn wọn,
\q2 kí wọn kí ó má ba yípadà
\q2 kí a má ba mú wọn ní ara dá.”
\p
\v 11 Nígbà náà ni mo wí pé, “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó \nd Olúwa\nd*?”
\p Òun sì dáhùn pé:
\q1 “Títí àwọn ìlú ńlá yóò fi dahoro,
\q2 láìsí olùgbé nínú rẹ̀ mọ́,
\q1 títí tí àwọn ilé yóò fi wà láìsí ènìyàn,
\q2 títí tí ilẹ̀ yóò fi dahoro pátápátá.
\q1
\v 12 Títí tí \nd Olúwa\nd* yóò fi rán gbogbo wọn jìnnà réré
\q2 tí ilẹ̀ náà sì di ìkọ̀sílẹ̀ pátápátá.
\q1
\v 13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdámẹ́wàá ṣẹ́kù lórí ilẹ̀ náà,
\q2 yóò sì tún pàpà padà di rírun.
\q1 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí igi tẹrẹbinti àti igi óákù,
\q2 ti í fi kùkùté sílẹ̀ nígbà tí a bá gé wọn lulẹ̀,
\q1 bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni irúgbìn mímọ́ náà yóò di kùkùté ní ilẹ̀ náà.”
\c 7
\s1 Àmì ti Emmanueli
\p
\v 1 Nígbà tí Ahasi ọmọ Jotamu ọmọ Ussiah jẹ́ ọba Juda, ọba Resini ti Aramu àti Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli gòkè wá láti bá Jerusalẹmu jà, ṣùgbọ́n wọn kò sì le è borí i rẹ̀.
\p
\v 2 Báyìí, a sọ fún ilé Dafidi pé, “Aramu mà ti lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Efraimu”; fún ìdí èyí, ọkàn Ahasi àti àwọn ènìyàn rẹ̀ wárìrì gẹ́gẹ́ bí igi oko ṣe ń wárìrì níwájú afẹ́fẹ́.
\p
\v 3 Lẹ́yìn èyí, \nd Olúwa\nd* sọ fún Isaiah pé, “Jáde, ìwọ àti ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ Ṣeari-Jaṣubu láti pàdé Ahasi ní ìpẹ̀kun ìṣàn omi ti adágún òkè, ní òpópó ọ̀nà tí ó lọ sí pápá Alágbàfọ̀.
\v 4 Sọ fún un, Ṣọ́ra à rẹ, fi ọkàn balẹ̀, kí o má ṣe bẹ̀rù. Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí kùkùté igi ìdáná méjèèjì yìí, nítorí ìbínú gbígbóná Resini àti Aramu àti ti ọmọ Remaliah.
\v 5 Aramu, Efraimu àti Remaliah ti dìtẹ̀ ìparun rẹ, wọ́n wí pé,
\v 6 “Jẹ́ kí a kọlu Juda; jẹ́ kí a fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kí a sì pín in láàrín ara wa, kí a sì fi ọmọ Tabeli jẹ ọba lórí i rẹ̀.”
\v 7 Síbẹ̀ èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd* Olódùmarè wí:
\q1 “Èyí kò ní wáyé
\q2 èyí kò le ṣẹlẹ̀,
\q1
\v 8 nítorí Damasku ni orí Aramu,
\q2 orí Damasku sì ni Resini.
\q1 Láàrín ọdún márùnlélọ́gọ́ta
\q2 Efraimu yóò ti fọ́ tí kì yóò le jẹ́ ènìyàn mọ́.
\q1
\v 9 Orí Efraimu sì ni Samaria,
\q2 orí Samaria sì ni ọmọ Remaliah.
\q1 Bí ẹ̀yin kí yóò bá gbàgbọ́,
\q2 lóòtítọ́, a kì yóò fi ìdí yín múlẹ̀.’ ”
\p
\v 10 Bákan náà \nd Olúwa\nd* tún bá Ahasi sọ̀rọ̀,
\v 11 “Béèrè fún àmì lọ́wọ́ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ, bóyá ní ọ̀gbun tí ó jì jùlọ tàbí àwọn òkè tí ó ga jùlọ.”
\p
\v 12 Ṣùgbọ́n Ahasi sọ pé, “Èmi kì yóò béèrè; Èmi kò ní dán \nd Olúwa\nd* wò.”
\p
\v 13 Lẹ́yìn náà Isaiah sọ pé, “Gbọ́ ní ìsinsin yìí, ìwọ ilé Dafidi, kò ha tọ́ láti tán ènìyàn ní sùúrù, ìwọ yóò ha tan Ọlọ́run ní sùúrù bí?
\v 14 \x - \xo 7.14: \xt Mt 1.23.\x*Nítorí náà, Olúwa fúnra ara rẹ̀ ni yóò fún ọ ní àmì kan. Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli.
\v 15 Òun yóò jẹ wàrà àti oyin nígbà tí ó bá ní ìmọ̀ tó láti kọ ẹ̀bi àti láti yan rere.
\v 16 Ṣùgbọ́n kí ọ̀dọ́mọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń kọ ẹ̀bi àti láti yan rere, ilẹ̀ àwọn ọba méjèèjì tí ń bà ọ́ lẹ́rù wọ̀nyí yóò ti di ahoro.
\v 17 \nd Olúwa\nd* yóò mú àsìkò mìíràn wá fún ọ àti àwọn ènìyàn rẹ àti lórí ilé baba rẹ irú èyí tí kò sí láti ìgbà tí Efraimu ti yà kúrò ní Juda, yóò sì mú ọba Asiria wá.”
\p
\v 18 Ní ọjọ́ náà ni \nd Olúwa\nd* yóò súfèé pe àwọn eṣinṣin láti àwọn odò tó jìnnà ní Ejibiti wá, àti fún àwọn oyin láti ilẹ̀ Asiria.
\v 19 Gbogbo wọn yóò sì wá dó sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè àti pàlàpálá òkúta, lára koríko ẹ̀gún àti gbogbo ibi ihò omi.
\v 20 Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò lo abẹ fífẹ́lẹ́ tí a yá láti ìkọjá odò Eufurate, ọba Asiria, láti fá irun orí àti ti àwọn ẹsẹ̀ ẹ yín, àti láti mú irùngbọ̀n yín kúrò pẹ̀lú.
\v 21 Ní ọjọ́ náà, ọkùnrin kan yóò máa sin ọ̀dọ́ abo màlúù kan àti ewúrẹ́ méjì.
\v 22 Àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà tí wọn yóò máa fún un, yóò ní wàràǹkàṣì láti jẹ. Gbogbo àwọn tí ó bá kù ní ilẹ̀ náà yóò jẹ wàràǹkàṣì àti oyin.
\v 23 Ní ọjọ́ náà, ni gbogbo ibi tí àjàrà tí ó tó ẹgbẹ̀rún (1,000) ṣékélì fàdákà, ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n nìkan ni yóò wà níbẹ̀.
\v 24 Àwọn ènìyàn yóò máa lọ síbẹ̀ pẹ̀lú ọrun àti ọfà nítorí pé ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n ni yóò bo gbogbo ilẹ̀ náà.
\v 25 Àti ní orí àwọn òkè kéékèèké tí a ti ń fi ọkọ́ ro nígbà kan rí, ẹ kò ní lọ síbẹ̀ mọ́ nítorí ìbẹ̀rù ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n, wọn yóò di ibi tí a ń da màlúù lọ, àti ibi ìtẹ̀mọ́lẹ̀ fún àwọn àgùntàn kéékèèké.
\c 8
\s1 Isaiah àti ọmọ rẹ jẹ àmì
\p
\v 1 \nd Olúwa\nd* sọ fún mi pé, mú ìwé ńlá kan, kí o sì fi kálàmù ìkọ̀wé lásán kọ Maha-Ṣalali-Haṣi-Basi.
\v 2 Èmi yóò sì mú Uriah àlùfáà àti Sekariah ọmọ Jeberekiah gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí òtítọ́ wá sí ọ̀dọ̀ mi.
\p
\v 3 Lẹ́yìn náà, mo lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì obìnrin náà, ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. \nd Olúwa\nd* sì wí fún mi pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Maha-Ṣalali-Haṣi-Basi.
\v 4 Kí ọmọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń sọ pé, Baba mi tàbí Ìyá mi, gbogbo ọrọ̀ Damasku àti ìkógun ti Samaria ni ọba àwọn Asiria yóò ti kó lọ.”
\p
\v 5 \nd Olúwa\nd* sì tún sọ fún mi pé,
\q1
\v 6 “Nítorí pé àwọn ènìyàn yìí ti kọ
\q2 omi Ṣiloa tí ń sàn jẹ́ẹ́jẹ́ sílẹ̀
\q1 tí wọ́n sì ń yọ̀ nínú Resini
\q2 àti ọmọ Remaliah,
\q1
\v 7 ǹjẹ́ nítorí náà kíyèsi i, Olúwa ń fa omi odò tí ó le,
\q2 tí ó sì pọ̀ wá sórí wọn,
\q1 àní, ọba Asiria àti gbogbo ògo rẹ̀,
\q2 yóò sì wá sórí gbogbo ọ̀nà odò rẹ̀,
\q2 yóò sì gun orí gbogbo bèbè rẹ̀,
\q1
\v 8 yóò sì gbá àárín Juda kọjá,
\q2 yóò sì ṣàn bò ó mọ́lẹ̀, yóò sì mú un dọ́rùn.
\q1 Nínà ìyẹ́ apá rẹ̀ yóò sì bo gbogbo ìbú ilẹ̀ rẹ̀,
\q2 ìwọ Emmanueli.”
\b
\q1
\v 9 Ké ariwo ogun, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, kí a sì fọ́ ọ yín túútúú,
\q2 fetísílẹ̀, ẹ̀yin ilẹ̀ jíjìn réré.
\q2 Ẹ palẹ̀mọ́ fún ogun, kí a sì fọ́ ọ túútúú!
\q1
\v 10 Ẹ gbìmọ̀ pọ̀, yóò sì di asán,
\q2 ẹ gbèrò ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n kì yóò dúró,
\q2 nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa.
\s1 Bẹ̀rù Ọlọ́run
\p
\v 11 \nd Olúwa\nd* bá mi sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀ o ìkìlọ̀ fún mi pé, èmi kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Ó wí pé,
\q1
\v 12 \x - \xo 8.12-13: \xt 1Pt 3.14-15.\x*“Má ṣe pe èyí ní ọ̀tẹ̀
\q2 gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn yìí pè ní ọ̀tẹ̀,
\q1 má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n bá bẹ̀rù,
\q2 má sì ṣe fòyà rẹ̀.
\q1
\v 13 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun ni Ẹni tí ìwọ yóò kà sí mímọ́,
\q2 Òun ni kí o bẹ̀rù
\q2 Òun ni kí àyà rẹ̀ fò ọ́,
\q1
\v 14 \x - \xo 8.14: \xt Ro 9.32-33; 1Pt 2.8.\x*Òun yóò sì jẹ́ ibi mímọ́
\q2 ṣùgbọ́n fún ilé Israẹli méjèèjì ni yóò jẹ́, òkúta tí í mú ni kọsẹ̀
\q1 àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú
\q2 àti fún àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ni yóò jẹ́ tàkúté àti ìdẹ̀kùn.
\q1
\v 15 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni yóò kọsẹ̀,
\q2 wọn yóò ṣubú wọn yóò sì fọ́ yángá,
\q2 okùn yóò mú wọn, ọwọ́ yóò sì tẹ̀ wọ́n.”
\b
\q1
\v 16 Di májẹ̀mú náà
\q2 kí o sì fi èdìdì di òfin náà láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi.
\q1
\v 17 \x - \xo 8.17-18: \xt Hb 2.13.\x*Èmi yóò dúró de \nd Olúwa\nd*,
\q2 ẹni tí ó ń fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún ilé Jakọbu.
\q2 Mo fi ìgbẹ́kẹ̀lé mi sínú rẹ.
\p
\v 18 Èmi nìyí, àti àwọn ọmọ tí \nd Olúwa\nd* fi fún mi. Àwa jẹ́ àmì àti àpẹẹrẹ ní Israẹli láti ọ̀dọ̀ \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun, ẹni tí ó ń gbé ní òkè Sioni.
\p
\v 19 Nígbà tí àwọn ènìyàn bá sọ fún un yín pé kí ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀ àti àwọn oṣó, ti máa ń kún tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ǹjẹ́ kò ha yẹ kí àwọn ènìyàn béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run wọn bí? Èéṣe tí ẹ fi ń bá òkú sọ̀rọ̀ ní orúkọ alààyè?
\v 20 Sí òfin àti májẹ̀mú! Bí wọn kò bá sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò rí ìmọ́lẹ̀ ọjọ́.
\v 21 Nínú ìnilára àti ebi, ni wọn yóò máa kọjá lọ láàrín ilẹ̀ náà, nígbà tí ebi bá pa wọ́n, nígbà yìí ni wọn yóò máa kanra, wọn yóò wòkè, wọn yóò sì fi ọba àti Ọlọ́run wọn ré.
\v 22 Nígbà náà ni wọn yóò sì wolẹ̀, wọn yóò sì rí ìpọ́njú, òkùnkùn àti ìpòrúru tí ó ba ni lẹ́rù, a ó sì sọ wọ́n sínú òkùnkùn biribiri.
\c 9
\s1 A bí ọmọ kan fún wa
\p
\v 1 \x - \xo 9.1-2: \xt Mt 4.15-16; Lk 1.79.\x*Síbẹ̀síbẹ̀, kò ní sí ìpòrúru kankan mọ́ fún àwọn tí ó wà nínú ìbànújẹ́. Nígbà kan rí ó rẹ ilẹ̀ Sebuluni sílẹ̀ àti ilẹ̀ Naftali pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ iwájú, yóò bu ọ̀wọ̀ fún Galili ti àwọn aláìkọlà, ní ọ̀nà Òkun, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ Jordani.
\q1
\v 2 Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùn
\q2 ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá;
\q1 lórí àwọn tí ń gbé nínú ilẹ̀ òjìji ikú,
\q2 ní ara wọn ni ìmọ́lẹ̀ mọ́ sí.
\q1
\v 3 Ìwọ ti sọ orílẹ̀-èdè di ńlá;
\q2 wọ́n sì yọ̀ níwájú rẹ
\q1 gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ti í yọ ayọ̀ ìkórè,
\q2 gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti í yọ̀
\q2 nígbà tí à ń pín ìkógun.
\q1
\v 4 Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí a ṣẹ́gun Midiani,
\q2 ìwọ ti fọ́ ọ túútúú
\q1 àjàgà ti ń pa wọ́n lẹ́rù,
\q2 ọ̀pá tí ó dábùú èjìká wọn,
\q2 ọ̀gọ aninilára wọn.
\q1
\v 5 Gbogbo bàtà jagunjagun tí a ti lò lójú ogun
\q2 àti gbogbo ẹ̀wù tí a yí nínú ẹ̀jẹ̀,
\q1 ni yóò wà fún ìjóná,
\q2 àti ohun èlò iná dídá.
\q1
\v 6 Nítorí a bí ọmọ kan fún wa,
\q2 a fi ọmọkùnrin kan fún wa,
\q2 ìjọba yóò sì wà ní èjìká rẹ̀.
\q1 A ó sì máa pè é ní
\q2 Ìyanu Olùdámọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára,
\q2 Baba ayérayé, Ọmọ ọba aládé Àlàáfíà.
\q1
\v 7 Ní ti gbígbòòrò Ìjọba rẹ̀ àti àlàáfíà rẹ̀ ni kì yóò ní ìpẹ̀kun.
\q2 Yóò jẹ ọba lórí ìtẹ́ Dafidi
\q1 àti lórí ẹ̀kún un rẹ̀ gbogbo,
\q2 nípa ìfìdímúlẹ̀ àti ìgbéró rẹ̀,
\q1 pẹ̀lú òtítọ́ àti òdodo
\q2 láti ìgbà náà lọ àti títí láéláé.
\q1 Ìtara \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun
\q2 ni yóò mú èyí ṣẹ.
\s1 Ìbínú \nd Olúwa\nd* Sí Israẹli
\q1
\v 8 Olúwa ti dojú iṣẹ́ kan kọ Jakọbu;
\q2 yóò sì wá sórí Israẹli.
\q1
\v 9 Gbogbo ènìyàn ni yóò sì mọ̀ ọ́n—
\q2 Efraimu àti gbogbo olùgbé Samaria—
\q1 tí ó sọ pẹ̀lú ìgbéraga
\q2 àti gààrù àyà pé.
\q1
\v 10 Àwọn bíríkì ti wó lulẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n a ó tún un kọ́ pẹ̀lú òkúta dídán,
\q1 a ti gé àwọn igi sikamore lulẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n igi kedari ní a ó fi dípò wọn.
\q1
\v 11 Ṣùgbọ́n \nd Olúwa\nd* fún àwọn ọ̀tá Resini ní agbára láti dojúkọ wọ́n
\q2 ó sì ti rú àwọn ọ̀tá wọn sókè.
\q1
\v 12 Àwọn ará Aramu láti ìlà-oòrùn àti Filistini láti ìwọ̀-oòrùn.
\q1 Wọ́n sì fi gbogbo ẹnu jẹ Israẹli run.
\b
\q2 Ní gbogbo èyí ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò
\q2 ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀.
\b
\q1
\v 13 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tí ì yípadà
\q2 sí ẹni náà tí ó lù wọ́n
\q2 bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò wá \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun.
\q1
\v 14 Nítorí náà ni \nd Olúwa\nd* yóò ṣe ké àti orí àti ìrù
\q2 kúrò ní Israẹli,
\q2 àti ọ̀wá ọ̀pẹ àti koríko odò ní ọjọ́ kan ṣoṣo,
\q1
\v 15 àwọn àgbàgbà, àti àwọn gbajúmọ̀ ní orí,
\q2 àwọn wòlíì tí ń kọ́ni ní irọ́ ni ìrù.
\q1
\v 16 Àwọn tí ó ń tọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣì wọ́n lọ́nà,
\q2 àwọn tí a sì tọ́ ni a ń sin sí ìparun.
\q1
\v 17 Nítorí náà, Olúwa kì yóò dunnú sí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin
\q2 tàbí kí ó káàánú àwọn aláìní baba àti opó,
\q1 nítorí pé gbogbo wọn jẹ́ ìkà àti aláìmọ Ọlọ́run,
\q2 ibi ni ó ti ẹnu wọn jáde.
\b
\q1 Síbẹ̀, fún gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò
\q2 ọwọ́ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.
\b
\q1
\v 18 Nítòótọ́ ìwà búburú ń jóni bí iná,
\q2 yóò jó ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún run,
\q1 yóò sì rán nínú pàǹtí igbó,
\q2 tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi gòkè lọ bí ọ̀wọ́n èéfín ti í gòkè.
\q1
\v 19 Nípasẹ̀ ìbínú \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun
\q2 ilẹ̀ náà yóò di gbígbẹ
\q1 àwọn ènìyàn yóò sì di ohun ìdáná,
\q2 ẹnìkan kì yóò sì dá arákùnrin rẹ̀ sí.
\q1
\v 20 Ní apá ọ̀tún wọn yóò jẹrun,
\q2 síbẹ̀ ebi yóò sì máa pa wọ́n,
\q1 ní apá òsì, wọn yóò jẹ,
\q2 ṣùgbọ́n, kò ní tẹ́ wọn lọ́rùn.
\q1 Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò sì máa jẹ ẹran-ara apá rẹ̀.
\q1
\v 21 Manase yóò máa jẹ Efraimu, nígbà tí Efraimu yóò jẹ Manase
\q2 wọn yóò parapọ̀ dojúkọ Juda.
\b
\q1 Síbẹ̀síbẹ̀, ìbínú un rẹ̀ kò yí kúrò
\q2 Ọwọ́ọ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.
\b
\b
\c 10
\q1
\v 1 Ègbé ni fún àwọn ti ń ṣe òfin àìṣòdodo,
\q1
\v 2 láti dún àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọn
\q2 àti láti fa ọwọ́ ìdájọ́ sẹ́yìn kúrò níwájú àwọn olùpọ́njú ènìyàn mi,
\q1 wọ́n sọ àwọn ọ̀pọ̀ di ìjẹ fún wọn,
\q2 wọ́n sì ń ja àwọn aláìní baba lólè.
\q1
\v 3 Kí ni ìwọ yóò ṣe ní ọjọ́ ìṣirò
\q2 nígbà tí ìparun bá ti ọ̀nà jíjìn wá?
\q1 Ta ni ìwọ yóò sá tọ̀ fún ìrànlọ́wọ́?
\q2 Níbo ni ìwọ yóò fi ọrọ̀ rẹ sí?
\q1
\v 4 Ohunkóhun kò ní ṣẹ́kù mọ́ bí kò ṣe láti tẹ̀ ba láàrín àwọn ìgbèkùn
\q2 tàbí kí o ṣubú sáàrín àwọn tí a pa.
\b
\q1 Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìbínú rẹ̀ kò kúrò,
\q2 ọwọ́ rẹ̀ sì tún gbé sókè.
\s1 Ìdájọ́ Ọlọ́run Lórí Asiria
\q1
\v 5 \x - \xo 10.5-34: \xt Nh; Sf 2.13-15.\x*“Ègbé ni fún àwọn ará Asiria, ọ̀gọ ìbínú mi,
\q2 ní ọwọ́ ẹni tí kùmọ̀ ìbínú mi wà!
\q1
\v 6 Mo rán an sí orílẹ̀-èdè aláìní Ọlọ́run,
\q2 mo dojú rẹ̀ kọ àwọn ènìyàn tí ó mú mi bínú
\q1 láti já ẹrù gbà, àti láti kó ìkógun
\q2 láti tẹ̀ mọ́lẹ̀ bí amọ̀ ní ojú òpópó.
\q1
\v 7 Ṣùgbọ́n, èyí kì í ṣe ohun tí ó fẹ́ ṣe,
\q2 èyí kọ́ ni ohun tí ó ní lọ́kàn;
\q1 èrò rẹ̀ ni láti parun,
\q2 láti fi òpin sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.
\q1
\v 8 Kì í ha ṣe pé ọba ni gbogbo àwọn aláṣẹ mi? ni Olúwa wí.
\q1
\v 9 Kì í ha ṣe pé Kalno dàbí i Karkemiṣi?
\q2 Hamati kò ha dàbí i Arpadi,
\q2 àti Samaria bí i Damasku?
\q1
\v 10 Gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ti gbá ìjọba àwọn òrìṣà mú,
\q2 ìjọba tí ère rẹ̀ pọ̀ ju ti Jerusalẹmu àti Samaria lọ.
\q1
\v 11 Èmi kì yóò a bá Jerusalẹmu wí àti àwọn ère rẹ̀?’ ”
\q2 Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe sí Samaria àti àwọn ère rẹ̀?
\p
\v 12 Nígbà tí Olúwa ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ sí òkè Sioni àti Jerusalẹmu, yóò sọ wí pé, “Èmi yóò fi ìyà jẹ ọba Asiria nítorí gààrù àyà rẹ̀ àti ìgbéraga ojú rẹ̀.
\v 13 Nítorí ó sọ pé:
\q1 “Pẹ̀lú agbára ọwọ́ mi ni mo fi ṣe èyí
\q2 àti pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀n mi, nítorí mo ní òye.
\q1 Mo mú ààlà àwọn orílẹ̀-èdè kúrò,
\q2 mo sì ti kó ìṣúra wọn.
\q2 Gẹ́gẹ́ bí alágbára kan, mo borí àwọn ọba wọn.
\q1
\v 14 Bí ènìyàn ti í tọwọ́ bọ ìtẹ́ ẹyẹ,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi tẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè.
\q1 Bí ènìyàn ti í kó ẹyin tí a kọ̀sílẹ̀,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni mo kó àwọn orílẹ̀-èdè
\q1 kò sí èyí tí ó fi apá lu apá,
\q2 tàbí kí ó ya ẹnu láti dún.’ ”
\b
\q1
\v 15 Ǹjẹ́ àáké le gbé ara rẹ̀ sókè kọjá ẹni tí ó ń fì í,
\q2 tàbí kí ayùn fọ́nnu sí ẹni tí ó ń lò ó?
\q1 Àfi bí ẹni pé ọ̀pá ó na ẹni tí ó gbé e sókè,
\q2 tàbí kí kùmọ̀ lu èyí tí kì í ṣe igi.
\q1
\v 16 Nítorí náà, ni Olúwa, \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun,
\q2 yóò rán ààrùn ìrẹ̀dànù sórí
\q1 àwọn akíkanjú jagunjagun,
\q2 lábẹ́ ògo rẹ̀ ni iná kan yóò ti sọ
\q2 gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun.
\q1
\v 17 Ìmọ́lẹ̀ Israẹli yóò di iná,
\q2 Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ ọ̀wọ́-iná,
\q1 ní ọjọ́ kan ṣoṣo yóò jó yóò sì run
\q2 àti ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n.
\q1
\v 18 Gbogbo ẹwà igbó o rẹ̀, àti àwọn pápá ọlọ́ràá
\q2 gbogbo rẹ̀ ni yóò run pátápátá,
\q1 gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ṣàìsàn ti í ṣòfò dànù.
\q1
\v 19 Àwọn igi tí yóò kù nínú igbó o rẹ̀
\q2 yóò kéré níye,
\q2 tí ọ̀dọ́mọdé yóò fi le kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
\s1 Àwọn ìyókù Israẹli
\q1
\v 20 Ní ọjọ́ náà, àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli,
\q2 àwọn tí ó yè ní ilé e Jakọbu,
\q1 kò ní gbẹ́kẹ̀lé ẹni náà
\q2 tí ó lù wọ́n bolẹ̀,
\q1 ṣùgbọ́n ní òtítọ́ yóò gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd*,
\q2 Ẹni Mímọ́ Israẹli.
\q1
\v 21 Àwọn ìyókù yóò padà, àwọn ìyókù ti Jakọbu
\q2 yóò padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Alágbára.
\q1
\v 22 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ Israẹli dàbí yanrìn ní Òkun,
\q2 ẹni díẹ̀ ni yóò padà.
\q1 A ti pàṣẹ ìparun,
\q2 àkúnwọ́sílẹ̀ àti òdodo.
\q1
\v 23 Olúwa, \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú un ṣẹ,
\q2 ìparun tí a ti pàṣẹ rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ náà.
\p
\v 24 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa, \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí,
\q2 “Ẹ̀yin ènìyàn mi tí ó ń gbé Sioni,
\q1 ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn Asiria,
\q2 tí ó ń fi ọ̀pá lù yín,
\q1 tí wọ́n sì ń gbé ọ̀gọ tì yín bí
\q2 Ejibiti ti ṣe.
\q1
\v 25 Láìpẹ́, ìbínú mi sí i yín yóò wá sí òpin
\q2 n ó sì dojú ìrunú mi kọ wọ́n, fún ìparun wọn.”
\b
\q1
\v 26 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun yóò nà wọ́n ní ẹgba.
\q2 Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe lu Midiani ní òkè Orebu,
\q1 yóò sì gbé ọ̀pá rẹ̀ lé orí omi
\q2 gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Ejibiti.
\q1
\v 27 Ní ọjọ́ náà, a ó gbé ẹrù wọn kúrò ní èjìká a yín,
\q2 àti àjàgà a wọn kúrò ní ọrùn un yín
\q1 a ó fọ́ àjàgà náà,
\q2 nítorí pé ẹ̀yin ó ti sanra.
\b
\q1
\v 28 Wọ́n wọ Aiati,
\q2 wọ́n gba Migroni kọjá,
\q2 wọ́n kó nǹkan pamọ́ sí Mikmasi.
\q1
\v 29 Wọ́n ti rékọjá ọ̀nà, wọ́n wí pé,
\q2 “Àwa ó tẹ̀dó sí Geba lóru yìí.”
\q1 Rama mì tìtì
\q2 Gibeah ti Saulu sálọ.
\q1
\v 30 Gbé ohùn rẹ sókè, ìwọ ọmọbìnrin Galimu!
\q2 Dẹ etí sílẹ̀, ìwọ Laiṣa!
\q2 Ìwọ òtòṣì Anatoti!
\q1
\v 31 Madmena ti fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ,
\q2 àwọn ènìyàn Gebimu ti fi ara pamọ́.
\q1
\v 32 Ní ọjọ́ yìí, wọn yóò dúró ní Nobu
\q2 wọn yóò kan sáárá,
\q1 ní òkè ọmọbìnrin Sioni
\q2 ní òkè Jerusalẹmu.
\b
\q1
\v 33 Wò ó, Olúwa, \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun,
\q2 yóò kán ẹ̀ka náà sọnù pẹ̀lú agbára.
\q1 Àwọn igi ọlọ́lá ni a ó gé lulẹ̀
\q2 àwọn tí ó ga gogoro ni a ó rẹ̀ sílẹ̀.
\q1
\v 34 Òun yóò gé igbó dídí pẹ̀lú àáké,
\q2 Lebanoni yóò ṣubú níwájú Alágbára náà.
\c 11
\s1 Ẹ̀ka láti ọ̀dọ̀ Jese
\q1
\v 1 \x - \xo 11.1: \xt Isa 11.10; Ro 15.12.\x*Èèkàn kan yóò sọ láti ibi kùkùté Jese,
\q2 láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kan yóò ti so èso.
\q1
\v 2 \x - \xo 11.2: \xt 1Pt 4.14.\x*Ẹ̀mí \nd Olúwa\nd* yóò sì bà lé e,
\q2 ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye,
\q2 ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára,
\q2 ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 3 Òun yóò sì ní inú dídùn nínú ìbẹ̀rù \nd Olúwa\nd*.
\b
\q2 Òun kì yóò ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ohun tí ó fi ojú u rẹ̀ rí,
\q2 tàbí pẹ̀lú ohun tí ó fi etí i rẹ̀ gbọ́,
\q1
\v 4 ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní,
\q2 pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu
\q1 fún àwọn aláìní ayé.
\q2 Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀,
\q2 pẹ̀lú èémí ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà.
\q1
\v 5 \x - \xo 11.5: \xt Ef 6.14.\x*Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀
\q2 àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ká.
\b
\q1
\v 6 \x - \xo 11.6-9: \xt Isa 65.25; Hk 2.14.\x*Ìkookò yóò sì máa bá ọmọ àgùntàn gbé,
\q2 ẹkùn yóò sì sùn ti ewúrẹ́
\q1 ọmọ màlúù òun ọmọ kìnnìún
\q2 àti ọmọ ẹran ó wà papọ̀
\q2 ọ̀dọ́mọdé yóò sì máa dà wọ́n.
\q1
\v 7 Màlúù àti beari yóò máa jẹun pọ̀,
\q2 àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pọ̀,
\q1 kìnnìún yóò sì máa jẹ koríko
\q2 gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù.
\q1
\v 8 Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká,
\q2 ọmọdé yóò ki ọwọ́ rẹ̀ bọ ìtẹ́ paramọ́lẹ̀.
\q1
\v 9 Wọn kò ní ṣe ni léṣe tàbí pa ni run
\q2 ní gbogbo òkè mímọ́ mi,
\q1 nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ \nd Olúwa\nd*
\q2 gẹ́gẹ́ bí omi ti bo Òkun.
\p
\v 10 \x - \xo 11.10: \xt Isa 11.1; Ro 15.12.\x*Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àsíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀-èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo.
\v 11 Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò na ọwọ́ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Asiria wá, láti ìsàlẹ̀ Ejibiti àti òkè Ejibiti, láti Kuṣi, láti Elamu láti Babiloni, láti Hamati àti láti àwọn erékùṣù inú Òkun.
\q1
\v 12 Òun yóò gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè,
\q2 yóò sì kó àwọn ìgbèkùn Israẹli jọ,
\q1 yóò kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda tí a ti fọ́n káàkiri jọ,
\q2 láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé.
\q1
\v 13 Owú jíjẹ Efraimu yóò pòórá,
\q2 àwọn ọ̀tá Juda ni a ó ké kúrò,
\q1 Efraimu kò ní jowú Juda,
\q2 tàbí Juda kó dojúkọ Efraimu.
\q1
\v 14 Wọn yóò fò mọ́ èjìká Filistini
\q2 sí apá ìwọ̀-oòrùn,
\q1 wọn yóò pawọ́pọ̀ kọlu àwọn
\q2 ènìyàn apá ìlà-oòrùn.
\q1 Wọn yóò gbé ọwọ́ wọn lé Edomu àti Moabu,
\q2 àwọn ará Ammoni yóò sì di ìwẹ̀fà wọn.
\q1
\v 15 \nd Olúwa\nd* yóò sọ di gbígbé
\q2 àyasí Òkun Ejibiti,
\q1 pẹ̀lú atẹ́gùn gbígbóná ni yóò na ọwọ́ rẹ̀,
\q2 kọjá lórí odò Eufurate.
\q1 Òun yóò sì sọ ọ́ di ọmọdò méje
\q2 tó fi jẹ́ pé àwọn ènìyàn
\q2 yóò máa là á kọjá pẹ̀lú bàtà.
\q1
\v 16 Ọ̀nà gidi yóò wà fún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù
\q2 tí ó kù sílẹ̀ ní Asiria,
\q1 gẹ́gẹ́ bí ó ti wà fún Israẹli
\q2 nígbà tí wọ́n gòkè láti Ejibiti wá.
\c 12
\s1 Orin ìyìn
\p
\v 1 Ní ọjọ́ náà ni ìwọ ó wí pé,
\q1 “Èmi ó yìn ọ́, \nd Olúwa\nd*.
\q2 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ò ti bínú sí mi
\q1 ìbínú rẹ ti yí kúrò níbẹ̀
\q1 ìwọ sì ti tù mí nínú.
\q1
\v 2 Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi,
\q2 èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù.
\q1 \nd Olúwa\nd*, \nd Olúwa\nd* náà ni agbára à mi àti orin ìn mi,
\q2 òun ti di ìgbàlà mi.”
\q1
\v 3 Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omi
\q2 láti inú kànga ìgbàlà.
\p
\v 4 Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé,
\q1 “Fi ọpẹ́ fún \nd Olúwa\nd*, ké pe orúkọ rẹ̀,
\q2 jẹ́ kí ó di mí mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
\q1 ohun tí ó ti ṣe
\q2 kí o sì kéde pé a ti gbé
\q2 orúkọ rẹ̀ ga.
\q1
\v 5 Kọ orin sí \nd Olúwa\nd*, nítorí ó ti ṣe ohun tí ó lógo,
\q2 jẹ́ kí èyí di mí mọ̀ fún gbogbo ayé.
\q1
\v 6 Kígbe sókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Sioni,
\q2 nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kan ṣoṣo
\q2 ti Israẹli láàrín yín.”
\c 13
\s1 Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Babeli
\p
\v 1 \x - \xo 13.114.23: \xt Isa 47; Jr 5051; Hk 12.\x*Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Babeli èyí tí Isaiah ọmọ Amosi rí.
\q1
\v 2 Gbé àsíá sókè ní orí òkè gbẹrẹfu,
\q2 kígbe sí wọn,
\q1 pè wọ́n
\q2 láti wọlé sí ẹnu-ọ̀nà àwọn ọlọ́lá.
\q1
\v 3 Mo ti pàṣẹ fún àwọn ẹni mímọ́ mi,
\q2 mo ti pe àwọn jagunjagun mi
\q1 láti gbé ìbínú mi jáde
\q2 àwọn tí ń yọ̀ nínú ìṣẹ́gun mi.
\b
\q1
\v 4 Gbọ́ ohùn kan ní àwọn orí òkè,
\q2 gẹ́gẹ́ bí i ti ogunlọ́gọ̀ ènìyàn.
\q1 Gbọ́ ìdàrúdàpọ̀ láàrín àwọn ìjọba,
\q2 gẹ́gẹ́ bí i ti ìkórajọ àwọn orílẹ̀-èdè!
\q1 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun ti kó ogun rẹ̀ jọ
\q2 àwọn jagunjagun fún ogun.
\q1
\v 5 Wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn réré,
\q2 láti ìpẹ̀kun ọ̀run wá
\q1 \nd Olúwa\nd* pẹ̀lú àwọn ohun ìjà ìbínú rẹ̀,
\q2 láti pa gbogbo orílẹ̀-èdè náà run.
\b
\q1
\v 6 Ẹ hu, nítorí ọjọ́ \nd Olúwa\nd* súnmọ́ tòsí,
\q2 yóò sì wá gẹ́gẹ́ bí ìparun láti ọ̀dọ̀ Alágbára jùlọ.
\q1
\v 7 Nítorí èyí, gbogbo ọwọ́ ni yóò rọ,
\q2 ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò rẹ̀wẹ̀sì.
\q1
\v 8 Ẹ̀rù yóò gbá wọn mú,
\q2 ìrora àti ìpayínkeke yóò dìwọ́n mú,
\q1 wọn yóò kérora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí.
\q2 Ẹnìkínní yóò wo ẹnìkejì rẹ̀ pẹ̀lú ìpayà
\q2 ojú wọn á sì gbinájẹ.
\b
\q1
\v 9 Kíyèsi i, ọjọ́ \nd Olúwa\nd* ń bọ̀
\q2 ọjọ́ búburú, pẹ̀lú ìbínú àti ìrunú gbígbóná—
\q1 láti sọ ilẹ̀ náà dahoro,
\q2 àti láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú rẹ̀ run.
\q1
\v 10 \x - \xo 13.10: \xt Mt 24.29; Mk 13.24; If 6.12; 8.12.\x*Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti ìkójọpọ̀ wọn
\q2 kò sì ní fi ìmọ́lẹ̀ wọn hàn.
\q1 Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn yóò di òkùnkùn
\q2 àti òṣùpá kò ní fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn.
\q1
\v 11 Èmi yóò jẹ ayé ní ìyà nítorí ibi rẹ̀,
\q2 àwọn ìkà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
\q1 Èmi yóò fi òpin sí gààrù àwọn agbéraga
\q2 èmi ó sì rẹ ìgbéraga àwọn aláìláàánú sílẹ̀.
\q1
\v 12 Èmi yóò jẹ́ kí ọkùnrin kí ó wọn
\q2 ju ojúlówó wúrà lọ,
\q2 yóò sì ṣọ̀wọ́n ju wúrà Ofiri lọ.
\q1
\v 13 Nítorí náà èmi yóò jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó wárìrì;
\q2 ayé yóò sì mì tìtì ní ibùjókòó rẹ̀
\q1 láti ọwọ́ ìbínú \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun,
\q2 ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ.
\b
\q1
\v 14 Gẹ́gẹ́ bí egbin tí à ń dọdẹ rẹ̀,
\q2 gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́,
\q1 ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò padà tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ,
\q2 ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò sá padà sí ilẹ̀ abínibí i rẹ̀.
\q1
\v 15 Ẹnikẹ́ni tí a bá gbámú ni a ó wọ́ nílẹ̀ tuurutu,
\q2 gbogbo àwọn tí ọwọ́ bá tẹ̀ ni yóò ti ipa idà kú.
\q1
\v 16 Àwọn ọ̀dọ́mọdé wọn ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́ níṣojú wọn,
\q2 gbogbo ilẹ̀ wọn ni a ó kó
\q2 àwọn aya wọn ni a ó sì bá dàpọ̀.
\b
\q1
\v 17 Kíyèsi i, èmi yóò ru àwọn Media sókè sí wọn,
\q2 àwọn tí kò bìkítà fún fàdákà
\q2 tí kò sì ní inú dídùn sí wúrà.
\q1
\v 18 Ọrùn wọn yóò ré àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin lulẹ̀;
\q2 wọn kò ní ṣàánú àwọn ọ̀dọ́mọdé
\q2 tàbí kí wọn síjú àánú wo àwọn ọmọdé.
\q1
\v 19 Babeli, ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ìjọba
\q2 ògo ìgbéraga àwọn ará Babeli
\q1 ni Ọlọ́run yóò da ojú rẹ̀ bolẹ̀
\q2 gẹ́gẹ́ bí Sodomu àti Gomorra.
\q1
\v 20 A kì yóò tẹ̀ ibẹ̀ dó mọ́
\q2 tàbí kí á gbé inú rẹ̀ láti ìrandíran;
\q2 ará Arabia kì yóò pa àgọ́ níbẹ̀ mọ́,
\q2 olùṣọ́-àgùntàn kan kì yóò kó ẹran rẹ̀ sinmi níbẹ̀.
\q1
\v 21 \x - \xo 13.21: \xt If 18.2.\x*Ṣùgbọ́n àwọn ẹranko igbó ni yóò dùbúlẹ̀ níbẹ̀,
\q2 àwọn ajáko yóò kún inú ilé wọn,
\q1 níbẹ̀ ni àwọn òwìwí yóò máa gbé
\q2 níbẹ̀ ni àwọn ewúrẹ́ igbó yóò ti máa bẹ́ kiri.
\q1
\v 22 Ìkookò yóò máa gbó ní ibùba wọn,
\q2 àwọn ajáko nínú arẹwà ààfin wọn.
\b
\b
\c 14
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd* yóò fi àánú hàn fún Jakọbu,
\q2 yóò tún Israẹli yàn lẹ́ẹ̀kan sí i
\q2 yóò sì fi ìdí wọn kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn tìkára wọn.
\q1 Àwọn àjèjì yóò darapọ̀ mọ́ wọn,
\q2 wọn yóò sì fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé e Jakọbu.
\q1
\v 2 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbà wọ́n
\q2 wọn yóò sì mú wọn wá sí ààyè e wọn.
\q1 Ilé Israẹli yóò gba àwọn orílẹ̀-èdè
\q2 gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin
\q1 ní ilẹ̀ \nd Olúwa\nd*.
\q2 Wọn yóò kó àwọn akónilẹ́rú wọn ní ìgbèkùn
\q2 wọn yóò sì jẹ ọba lórí àwọn amúnisìn wọn.
\p
\v 3 Ní ọjọ́ tí \nd Olúwa\nd* yóò fi ìtura fún un yín kúrò nínú ìpọ́njú àti ìyà àti ìdè ìkà,
\v 4 ẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù yìí kan ọba Babeli pé,
\q1 báwo ni amúnisìn ṣe wá sí òpin!
\q2 Báwo ni ìbínú rẹ̀ ṣe parí!
\q1
\v 5 \nd Olúwa\nd* ti dá ọ̀pá ìkà náà,
\q2 ọ̀pá àwọn aláṣẹ,
\q1
\v 6 èyí tí ó ti lu àwọn ènìyàn bolẹ̀
\q2 pẹ̀lú ti kò dáwọ́ dúró,
\q1 nínú ìrunú ni ó ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè
\q2 pẹ̀lú ìgbónára tí kò lópin.
\q1
\v 7 Gbogbo ilẹ̀ ni ó wà ní ìsinmi àti àlàáfíà,
\q2 wọ́n bú sí orin.
\q1
\v 8 Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn igi junifa àti àwọn
\q2 igi kedari ti Lebanoni
\q1 ń yọ̀ lórí rẹ wí pé,
\q2 “Níwọ́n bí a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ báyìí,
\q2 kò sí agégi tí yóò wá láti gé wa lulẹ̀.”
\b
\q1
\v 9 Ibojì tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni a ru sókè
\q2 láti pàdé rẹ ní ìpadàbọ̀ rẹ̀
\q1 ó ru ẹ̀mí àwọn tí ó ti lọ sókè láti wá kí ọ
\q2 gbogbo àwọn tí ó jẹ́ olórí ní ayé
\q1 ó mú kí wọn dìde lórí ìtẹ́ wọn
\q2 gbogbo àwọn tí ó jẹ ọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè.
\q1
\v 10 Gbogbo wọn yóò dáhùn,
\q2 wọn yóò wí fún ọ wí pé,
\q1 “Ìwọ pẹ̀lú ti di aláìlera, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú
\q2 ìwọ náà ti dàbí wa.”
\q1
\v 11 Gbogbo rẹ̀ ni ó di ìrẹ̀sílẹ̀ lọ sí ibojì,
\q2 pẹ̀lú ariwo àwọn dùùrù rẹ,
\q1 àwọn ìdin ni wọ́n fọ́nkálẹ̀ lábẹ́ rẹ
\q2 àwọn ekòló sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀.
\b
\q1
\v 12 Báwo ni ìwọ ṣe ṣubú lulẹ̀ láti ọ̀run wá,
\q2 ìwọ ìràwọ̀ òwúrọ̀, ọmọ òwúrọ̀ náà!
\q1 A ti sọ ọ́ sílẹ̀ sínú ayé,
\q2 ìwọ tí o ti tẹ orí àwọn orílẹ̀-èdè ba rí!
\q1
\v 13 Ìwọ sọ nínú ọkàn rẹ pé,
\q2 “Èmi yóò gòkè lọ sí ọ̀run;
\q1 èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sókè
\q2 ga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run,
\q1 Èmi yóò gúnwà ní orí òkè àpéjọ
\q2 ní ṣóńṣó orí òkè mímọ́.
\q1
\v 14 Èmi yóò gòkè lọ rékọjá àwọn àwọsánmọ̀;
\q2 èmi yóò ṣe ara mi gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá-ògo.”
\q1
\v 15 Ṣùgbọ́n a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ wọ inú ibojì lọ
\q2 lọ sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun.
\b
\q1
\v 16 Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjúmọ́ ọ,
\q2 wọ́n ronú nípa àtubọ̀tán rẹ:
\q1 “Ǹjẹ́ èyí ni ẹni tí ó mi ayé tìtì
\q2 tí ó sì jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.
\q1
\v 17 Ẹni tí ó sọ ayé di aginjù,
\q2 tí ó sì pa ìlú ńlá ńlá rẹ̀ run
\q2 tí kò dá àwọn òǹdè rẹ̀ sílẹ̀ láti padà sílé?”
\b
\q1
\v 18 Gbogbo àwọn ọba orílẹ̀-èdè ni a tẹ́ sílẹ̀
\q2 ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ibojì tirẹ̀.
\q1
\v 19 Ṣùgbọ́n a jù ọ́ síta kúrò nínú ibojì
\q2 gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka igi tí a kọ̀sílẹ̀,
\q1 àwọn tí a pa ni ó bò ọ́ mọ́lẹ̀,
\q2 àwọn tí idà ti gún,
\q1 àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkúta inú ọ̀gbun.
\q2 Gẹ́gẹ́ bí òkú ó di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní abẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀,
\q1
\v 20 a kò ní sin ọ́ pẹ̀lú wọn,
\q2 nítorí pé o ti ba ilẹ̀ rẹ jẹ́
\q2 o sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ.
\b
\b
\q1 Ìran àwọn ìkà
\q2 ni a kì yóò dárúkọ wọn mọ́.
\q1
\v 21 Tọ́jú ibìkan tí a ó ti pa àwọn ọmọkùnrin rẹ
\q2 nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn,
\q2 wọn kò gbọdọ̀ dìde láti jogún ilẹ̀
\q2 kí wọ́n sì bo orí ilẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlú u wọn.
\b
\q1
\v 22 “Èmi yóò dìde sókè sí wọn,”
\q2 ni \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí.
\q1 “Èmi yóò ké orúkọ rẹ̀ kúrò ní Babeli àti àwọn tí ó sálà,
\q2 àwọn ọmọ àti ìran rẹ̀,”
\q2 ni \nd Olúwa\nd* wí.
\q1
\v 23 Èmi yóò yí i padà sí ibùgbé àwọn òwìwí
\q2 àti sí irà;
\q1 Èmi yóò fi ọwọ́ ìparun gbá a,
\q2 ni \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí.
\s1 Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Asiria
\p
\v 24 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun ti búra,
\q1 “Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣètò, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí,
\q2 àti bí mo ti pinnu, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì dúró.
\q1
\v 25 Èmi yóò run Asiria ní ilẹ̀ mi,
\q2 ní àwọn orí òkè mi ni èmi yóò ti rún un mọ́lẹ̀.
\q2 Àjàgà rẹ̀ ni a ó mú kúrò lọ́rùn àwọn ènìyàn mi,
\q2 ẹrù u rẹ̀ ni ó mú kúrò ní èjìká wọn.”
\b
\q1
\v 26 Èyí ni ètò tí a pinnu rẹ̀ fún gbogbo ayé,
\q2 èyí ni ọwọ́ tí a nà jáde káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè.
\q1
\v 27 Nítorí \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun ti pète,
\q2 ta ni yóò sì ká a lọ́wọ́ kò?
\q2 Ọwọ́ọ rẹ ti nà jáde, ta ni ó sì le è fà á padà?
\s1 Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì àwọn Filistini
\p
\v 28 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yí wá ní ọdún tí ọba Ahasi kú.
\q1
\v 29 \x - \xo 14.29-31: \xt Jr 47; El 25.15-17; Jl 3.4-8; Am 1.6-8; Sf 2.4-7; Sk 9.5-7.\x*Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Filistia,
\q2 pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá;
\q1 láti ibi gbòǹgbò ejò náà ni paramọ́lẹ̀
\q2 yóò ti hù jáde,
\q2 èso rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tí í jóni.
\q1
\v 30 Ẹni tí ó kúṣẹ̀ẹ́ jù yóò ní pápá oko,
\q2 àwọn aláìní yóò sì dùbúlẹ̀ láìléwu.
\q1 Ṣùgbọ́n gbòǹgbò o rẹ̀ ni èmi ó fi ìyàn parun,
\q2 yóò sì ké àwọn ẹni rẹ tí ó sálà kúrò.
\b
\q1
\v 31 Hu, ìwọ ẹnu-ọ̀nà! Kígbe, ìwọ ìlú!
\q2 Yọ́ kúrò, gbogbo ẹ̀yin Filistia!
\q1 Èéfín kurukuru kan ti àríwá wá,
\q2 kò sì ṣí amóríbọ́ kan nínú ẹgbẹ́ wọn.
\q1
\v 32 Kí ni ìdáhùn tí a ó fún
\q2 agbẹnusọ orílẹ̀-èdè náà?
\q1 “\nd Olúwa\nd* ti fi ìdí Sioni kalẹ̀,
\q2 àti nínú rẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ̀ tí
\q2 a ti pọ́n ọn lójú yóò ti rí ààbò o wọn.”
\c 15
\s1 Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Moabu
\p
\v 1 \x - \xo 15.116.14: \xt Isa 25.10-12; Jr 48; El 25.8-11; Am 2.1-3; Sf 2.8-11.\x*Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Moabu,
\q1 a pa Ari run ní Moabu,
\q2 òru kan ní a pa á run!
\q1 A pa Kiri run ní Moabu,
\q2 òru kan ní a pa á run!
\q1
\v 2 Diboni gòkè lọ sí tẹmpili rẹ̀,
\q2 sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti sọkún,
\q1 Moabu pohùnréré lórí Nebo àti Medeba.
\q2 Gbogbo orí ni a fá
\q2 gbogbo irùngbọ̀n ni a gé dànù.
\q1
\v 3 Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà,
\q2 ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede ìlú.
\q1 Wọ́n pohùnréré,
\q2 wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún.
\q1
\v 4 Heṣboni àti Eleale ké sóde,
\q2 ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jahasi.
\q1 Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ogun Moabu ṣe kígbe
\q2 tí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.
\b
\q1
\v 5 Ọkàn mi kígbe sókè lórí Moabu;
\q2 àwọn ìsáǹsá rẹ sálà títí dé Soari,
\q1 títí fi dé Eglati-Ṣeliṣi.
\q2 Wọ́n gòkè lọ títí dé Luhiti
\q1 wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ,
\q2 ní òpópónà tí ó lọ sí Horonaimu
\q2 wọ́n ń pohùnréré ìparun wọn.
\q1
\v 6 Gbogbo omi Nimrimu ni ó ti gbẹ
\q2 àwọn koríko sì ti gbẹ,
\q1 gbogbo ewéko ti tán
\q2 ewé tútù kankan kò sí mọ́.
\q1
\v 7 Báyìí gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n ti ní tí wọ́n sì tò jọ
\q2 wọ́n ti kó wọn kọjá lọ lórí i gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ odò Poplari.
\q1
\v 8 Gbohùngbohùn ń gba igbe wọn dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ Moabu;
\q2 ìpohùnréré wọn lọ títí dé Eglaimu,
\q2 igbe ẹkún wọn ni a gbọ́ títí dé kànga Elimu.
\q1
\v 9 Omi Dimoni kún fún ẹ̀jẹ̀,
\q2 síbẹ̀ èmi ó tún mu ohun tí ó jù báyìí lọ wá sórí Dimoni—
\q1 kìnnìún kan wá sórí àwọn ìsáǹsá Moabu
\q2 àti lórí àwọn tí ó tún ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ náà.
\b
\b
\c 16
\q1
\v 1 Fi ọ̀dọ́-àgùntàn ṣe ẹ̀bùn
\q2 ránṣẹ́ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà,
\q1 láti Sela, kọjá ní aginjù,
\q2 lọ sí orí òkè ọ̀dọ́mọbìnrin Sioni.
\q1
\v 2 Gẹ́gẹ́ bí alárìnkiri ẹyẹ
\q2 tí a tì jáde kúrò nínú ìtẹ́,
\q1 bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn obìnrin Moabu
\q2 ní àwọn ìwọdò Arnoni.
\b
\q1
\v 3 “Fún wa ní ìmọ̀ràn
\q2 ṣe ìpinnu fún wa.
\q1 Jẹ́ kí òjìji rẹ dàbí òru,
\q2 ní ọ̀sán gangan.
\q1 Fi àwọn ìsáǹsá pamọ́,
\q2 má ṣe fi àwọn aṣàtìpó han.
\q1
\v 4 Jẹ́ kí àwọn ìsáǹsá Moabu gbé pẹ̀lú rẹ,
\q2 jẹ́ ààbò fún wọn kúrò lọ́wọ́ ìparun.”
\b
\q1 Aninilára yóò wá sí òpin,
\q2 ìparun yóò dáwọ́ dúró;
\q2 òfinràn yóò pòórá kúrò lórí ilẹ̀.
\q1
\v 5 Nínú ìfẹ́ a ó fi ìdí ìjọba kan múlẹ̀,
\q2 ní òdodo ọkùnrin kan yóò jókòó lórí rẹ̀
\q1 ẹnìkan láti ilé Dafidi wá.
\q2 Ẹni yóò ṣe ìdájọ́, yóò sì máa wá ìdájọ́,
\q2 yóò sì máa yára wá ohun tí í ṣe òdodo.
\b
\q1
\v 6 Àwa ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu,
\q2 ìwọ̀sí ìgbéraga rẹ̀ àti fùlenge fùlenge,
\q1 gààrù rẹ̀ àti àfojúdi rẹ̀,
\q2 ṣùgbọ́n ìfọ́nnu rẹ̀ jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.
\q1
\v 7 Nítorí náà ni àwọn ará Moabu hu,
\q2 wọ́n jùmọ̀ hu lórí Moabu.
\q1 Sọkún kí o sì banújẹ́
\q2 fún àkàrà díndín Kiri-Hareseti.
\q1
\v 8 Gbogbo pápá oko Heṣboni ti gbẹ,
\q2 bákan náà ni àjàrà Sibma rí.
\q1 Àwọn aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè
\q2 wọ́n tẹ àwọn àyànfẹ́ àjàrà mọ́lẹ̀,
\q1 èyí tí ó ti fà dé Jaseri
\q2 ó sì ti tàn dé agbègbè aginjù.
\q1 Àwọn èhíhù rẹ̀ fọ́n jáde,
\q2 ó sì lọ títí ó fi dé Òkun.
\q1
\v 9 Nítorí náà mo sọkún, gẹ́gẹ́ bí Jaseri ṣe sọkún,
\q2 fún àwọn àjàrà Sibma.
\q1 Ìwọ Heṣboni, ìwọ Eleale,
\q2 mo bomirin ọ́ pẹ̀lú omi ojú!
\q1 Igbe ayọ̀ lórí àwọn èso pípọ́n rẹ
\q2 àti lórí ìkórè èyí tí o ti mọ́wọ́ dúró.
\q1
\v 10 Ayọ̀ àti ìdùnnú ni a ti mú kúrò
\q2 nínú ọgbà-igi eléso rẹ;
\q1 kò sí ẹnìkan tí ó kọrin tàbí
\q2 kígbe nínú ọgbà àjàrà:
\q1 ẹnikẹ́ni kò fún ọtí níbi ìfúntí,
\q2 nítorí mo ti fi òpin sí gbogbo igbe.
\q1
\v 11 Ọkàn mi kérora fún Moabu gẹ́gẹ́ bí i dùùrù,
\q2 àní tọkàntọkàn mi fún ìlú Kiri-Hareseti.
\q1
\v 12 Nígbà tí Moabu farahàn ní ibi gíga rẹ̀,
\q2 ó ṣe ara rẹ̀ ní wàhálà lásán;
\q1 nígbà tí ó lọ sí ojúbọ rẹ̀ láti gbàdúrà
\q2 òfo ni ó jásí.
\p
\v 13 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí \nd Olúwa\nd* ti sọ nípa Moabu.
\v 14 Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí \nd Olúwa\nd* wí pé, “Láàrín ọdún mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ìdè ọgbà rẹ̀ ti máa kà á, ògo Moabu àti àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn rẹ̀ ni a ó kẹ́gàn, àwọn tí ó sálà nínú rẹ̀ yóò kéré níye, wọn yóò sì jẹ́ akúrẹtẹ̀.”
\c 17
\s1 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ ní ti Damasku
\p
\v 1 \x - \xo 17.1-3: \xt Jr 49.23-27; Am 1.3-5; Sk 9.1.\x*Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Damasku:
\q1 “Kíyèsi i, Damasku kò ní jẹ́ ìlú mọ́
\q2 ṣùgbọ́n yóò padà di ààtàn.
\q1
\v 2 Àwọn ìlú Aroeri ni a ó kọ̀sílẹ̀
\q2 fún àwọn agbo ẹran tí yóò máa sùn síbẹ̀,
\q2 láìsí ẹni tí yóò dẹ́rùbà wọ́n.
\q1
\v 3 Ìlú olódi ni yóò pòórá kúrò ní Efraimu,
\q2 àti agbára ọba kúrò ní Damasku;
\q1 àwọn àṣẹ́kù Aramu yóò dá
\q2 gẹ́gẹ́ bí ògo ti àwọn Israẹli,”
\q2 ni \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí.
\b
\q1
\v 4 “Ní ọjọ́ náà ni ògo Jakọbu yóò sá;
\q2 ọ̀rá ara rẹ̀ yóò ṣòfò dànù.
\q1
\v 5 Yóò sì dàbí ìgbà tí olùkórè kó àwọn
\q2 irúgbìn tí ó dúró jọ
\q1 tí ó sì ń kórè irúgbìn pẹ̀lú apá rẹ̀—
\q2 àti gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn pa ọkà ní àfonífojì ti Refaimu.
\q1
\v 6 Síbẹ̀síbẹ̀ irúgbìn díẹ̀ yóò ṣẹ́kù,
\q2 gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a gbọn igi olifi,
\q1 tí èso olifi méjì tàbí mẹ́ta ṣẹ́kù
\q2 sórí ẹ̀ka tí ó ga jùlọ,
\q1 mẹ́rin tàbí márùn-ún lórí ẹ̀ka tí ó so jù,”
\q2 ni \nd Olúwa\nd* wí, àní Ọlọ́run Israẹli.
\b
\q1
\v 7 Ní ọjọ́ náà, àwọn ènìyàn yóò gbójú sókè sí Ẹlẹ́dàá wọn,
\q2 wọn yóò sì síjú wo Ẹni Mímọ́ Israẹli.
\q1
\v 8 Wọn kò ní wo àwọn pẹpẹ mọ́,
\q2 èyí tí í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wọn,
\q1 wọn kò sì ní kọbi ara sí ère Aṣerah mọ́
\q2 tàbí pẹpẹ tùràrí tí ìka ọwọ́ wọn ti ṣe.
\p
\v 9 Ní ọjọ́ náà àwọn ìlú alágbára rẹ̀, yóò dàbí ẹ̀ka ìkọ̀sílẹ̀, àti ẹ̀ka téńté òkè tí wọ́n fi sílẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Gbogbo wọn yóò sì di ahoro.
\q1
\v 10 Nítorí ìwọ ti gbàgbé Ọlọ́run ìgbàlà rẹ;
\q2 tí ìwọ kò sì náání àpáta ìgbàlà rẹ̀,
\q2 nítorí náà ni ìwọ ti gbin ọ̀gbìn dáradára
\q2 ìwọ sì tọ́ àjèjì ẹ̀ka sínú rẹ̀.
\q1
\v 11 Nítorí náà, bí ẹ tilẹ̀ mú àṣàyàn igi tí ẹ sì gbin àjàrà tí ó ti òkèrè wá,
\q2 bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ tí ẹ kó wọn jáde ẹ mú wọn hù jáde,
\q1 àti ní òwúrọ̀ tí ẹ gbìn wọ́n
\q2 ẹ mú kí wọ́n rúdí,
\q1 síbẹ̀síbẹ̀ ìkórè kò ní mú nǹkan wá
\q2 ní ọjọ́ ààrùn àti ìrora tí kò gbóògùn.
\b
\q1
\v 12 Kíyèsi i, ìrunú àwọn orílẹ̀-èdè—
\q2 wọ́n ń runú bí ìgbì Òkun!
\q1 Kíyèsi i, rògbòdìyàn tí ogunlọ́gọ̀ ènìyàn
\q2 wọ́n bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ariwo odò ńlá!
\q1
\v 13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń bú
\q2 ramúramù gẹ́gẹ́ bí ìrúmi odò,
\q1 nígbà tí ó bá wọn wí wọ́n sálọ jìnnà réré,
\q2 a tì wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò ní orí òkè,
\q2 àti gẹ́gẹ́ bí ewéko níwájú ìjì líle.
\q1
\v 14 Ní aginjù, ìpayà òjijì!
\q2 Kí ó tó di òwúrọ̀, a ò rí wọn mọ́!
\q1 Èyí ni ìpín àwọn tí ó jí wa lẹ́rù,
\q2 àti ìpín àwọn tí ó fi ogun kó wa.
\c 18
\s1 Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Kuṣi
\q1
\v 1 \x - \xo 18.1-7: \xt Sf 2.12.\x*Ègbé ni fún ilẹ̀ tí ó kún fún ariwo ìyẹ́ eṣú,
\q2 ní àwọn ipadò Kuṣi,
\q1
\v 2 tí ó rán àwọn ikọ̀ lórí Òkun
\q2 lórí omi nínú ọkọ̀-ọpọ́n tí a fi eèsún papirusi ṣe.
\b
\q1 Ẹ lọ, ẹ̀yin ikọ̀ tí ó yára,
\q2 sí àwọn ènìyàn gíga tí àwọ̀ ara wọn jọ̀lọ̀,
\q1 sí àwọn ènìyàn tí a ń bẹ̀rù káàkiri,
\q2 orílẹ̀-èdè aláfojúdi alájèjì èdè,
\q2 tí odò pín ilẹ̀ rẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ.
\b
\q1
\v 3 Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ayé,
\q2 tí ó ń gbé orílẹ̀ ayé,
\q1 nígbà tí a bá gbé àsíá kan sókè lórí òkè,
\q2 ẹ ó rí i,
\q1 nígbà tí a bá fun fèrè kan
\q2 ẹ ó gbọ́ ọ.
\q1
\v 4 Èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd* sọ fún mi:
\q2 “Èmi yóò dákẹ́ jẹ́ẹ́, èmi yóò sì máa wo òréré
\q1 láti ibùgbé e mi wá,
\q2 gẹ́gẹ́ bí ooru gbígbóná nínú ìtànṣán oòrùn,
\q2 gẹ́gẹ́ bí òjò-dídì ní àárín gbùngbùn ìkórè.”
\q1
\v 5 Nítorí, kí ìkórè tó bẹ̀rẹ̀,
\q2 nígbà tí ìrudí bá kún,
\q1 nígbà tí ìtànná bá di èso àjàrà pípọ́n.
\q2 Òun yóò sì fi dòjé rẹ́ ẹ̀ka tuntun,
\q1 yóò sì mu kúrò,
\q2 yóò sì gé ẹ̀ka lulẹ̀.
\q1
\v 6 A ó fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ẹyẹ òkè ńlá
\q2 àti fún àwọn ẹranko búburú;
\q1 àwọn ẹyẹ yóò fi wọ́n ṣe oúnjẹ nínú ẹ̀ẹ̀rùn
\q2 àti àwọn ẹranko búburú nígbà òjò.
\p
\v 7 Ní àkókò náà ni a ó mú ẹ̀bùn wá fún \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun
\q1 láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn gíga tí ẹran-ara wọn jọ̀lọ̀,
\q2 láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí a bẹ̀rù níbi gbogbo,
\q1 orílẹ̀-èdè aláfojúdi àti alájèjì èdè,
\q2 ilẹ̀ ẹni tí omi pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ—
\m a ó mú àwọn ẹ̀bùn náà wá sí òkè Sioni, ibi tí orúkọ \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun gbé wà.
\c 19
\s1 Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Ejibiti
\p
\v 1 \x - \xo 19.1-25: \xt Jr 46; El 2932; Sk 14.18-19.\x*Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Ejibiti.
\q1 Kíyèsi i, \nd Olúwa\nd* gun àwọsánmọ̀ tí ó yára lẹ́ṣin
\q2 ó sì ń bọ̀ wá sí Ejibiti.
\q1 Àwọn ère òrìṣà Ejibiti wárìrì níwájú rẹ̀,
\q2 ọkàn àwọn ará Ejibiti sì ti domi nínú wọn.
\b
\q1
\v 2 “Èmi yóò rú àwọn ará Ejibiti sókè sí ara wọn
\q2 arákùnrin yóò bá arákùnrin rẹ̀ jà,
\q1 aládùúgbò yóò dìde sí aládùúgbò rẹ̀,
\q2 ìlú yóò dìde sí ìlú,
\q2 ilẹ̀ ọba sí ilẹ̀ ọba.
\q1
\v 3 Àwọn ará Ejibiti yóò sọ ìrètí nù,
\q2 èmi yóò sì sọ èrò wọn gbogbo di òfo;
\q1 wọn yóò bá àwọn òrìṣà àti ẹ̀mí àwọn òkú sọ̀rọ̀,
\q2 àwọn awoṣẹ́ àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀.
\q1
\v 4 Èmi yóò fi Ejibiti lé agbára
\q2 àwọn ìkà amúnisìn lọ́wọ́,
\q1 ọba aláìláàánú ni yóò jẹ ọba lé wọn lórí,”
\q2 ni Olúwa, \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí.
\b
\q1
\v 5 Gbogbo omi inú odò ni yóò gbẹ,
\q2 gbogbo ilẹ̀ àyíká odò ni yóò gbẹ tí yóò sì sáàpá.
\q1
\v 6 Adágún omi yóò sì di rírùn;
\q2 àwọn odò ilẹ̀ Ejibiti yóò máa dínkù
\q1 wọn yóò sì gbẹ.
\q2 Àwọn koríko odò àti ìrẹ̀tẹ̀ yóò gbẹ,
\q1
\v 7 àwọn igi ipadò Naili pẹ̀lú,
\q2 tí ó wà ní orísun odò,
\q1 gbogbo oko tí a dá sí ipadò Naili
\q2 yóò gbẹ dànù tí yóò sì fẹ́ dànù
\q2 tí kò sì ní sí mọ́.
\q1
\v 8 Àwọn apẹja yóò sọkún kíkorò,
\q2 àti gbogbo àwọn tí ó ń ju ìwọ̀ sínú odò;
\q2 odò náà yóò sì máa rùn.
\q1
\v 9 Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ yóò kọminú
\q2 àwọn ahunṣọ ọ̀gbọ̀ yóò sọ ìrètí nù.
\q1
\v 10 Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ aṣọ yóò rẹ̀wẹ̀sì,
\q2 gbogbo àwọn oníṣẹ́ oṣù ni àìsàn ọkàn yóò ṣe.
\b
\q1
\v 11 Àwọn oníṣẹ́ Ṣoani ti di aláìgbọ́n,
\q2 àwọn ọlọ́gbọ́n olùdámọ̀ràn Farao
\q1 ń mú ìmọ̀ràn àìgbọ́n wá.
\q2 Báwo ló ṣe lè sọ fún Farao pé,
\q1 “Mo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn,
\q2 ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn ọba àtijọ́.”
\b
\q1
\v 12 Níbo ni àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn rẹ wà báyìí?
\q2 Jẹ́ kí wọn fihàn ọ́ kí wọn sì sọ ọ́ di mí mọ̀
\q1 ohun tí \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun
\q2 ti pinnu lórí Ejibiti.
\q1
\v 13 Àwọn ọmọ-aládé Ṣoani ti di aṣiwèrè,
\q2 a ti tan àwọn ọmọ-aládé Memfisi jẹ;
\q1 àwọn òkúta igun ilé tí í ṣe ti ẹ̀yà rẹ
\q2 ti ṣi Ejibiti lọ́nà.
\q1
\v 14 \nd Olúwa\nd* ti da ẹ̀mí òòyì sínú wọn;
\q2 wọ́n mú Ejibiti ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú
\q1 ohun gbogbo tí ó ń ṣe,
\q2 gẹ́gẹ́ bí ọ̀mùtí ti í ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú èébì rẹ̀.
\q1
\v 15 Kò sí ohun tí Ejibiti le ṣe—
\q2 orí tàbí ìrù, ọ̀wá ọ̀pẹ tàbí koríko odò.
\p
\v 16 Ní ọjọ́ náà ni àwọn ará Ejibiti yóò dàbí obìnrin. Wọn yóò gbọ̀n jìnnìjìnnì pẹ̀lú ẹ̀rù nítorí ọwọ́ \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun tí a gbé sókè sí wọn.
\v 17 Ilẹ̀ Juda yóò sì di ẹ̀rù fún Ejibiti; gbogbo àwọn tí a bá ti dárúkọ Juda létí wọn ni yóò wárìrì, nítorí ohun tí \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun gbèrò láti ṣe sí wọn.
\p
\v 18 Ní ọjọ́ náà ìlú márùn-ún ní ilẹ̀ Ejibiti yóò sọ èdè àwọn ará Kenaani, wọn yóò sì búra àtìlẹ́yìn fún \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun. Ọ̀kan nínú wọn ni a ó sì máa pè ní ìlú ìparun.
\p
\v 19 Ní ọjọ́ náà pẹpẹ kan yóò wà fún \nd Olúwa\nd* ní àárín gbùngbùn Ejibiti, àti ọ̀wọ́n kan fún \nd Olúwa\nd* ní etí bodè rẹ̀.
\v 20 Yóò sì jẹ́ àmì àti ẹ̀rí sí \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun ní ilẹ̀ Ejibiti. Nígbà tí wọ́n bá ké pe \nd Olúwa\nd* nítorí àwọn aninilára wọn, yóò rán olùgbàlà àti olùgbèjà kan sí wọn tí yóò sì gbà wọ́n sílẹ̀.
\v 21 Báyìí ni \nd Olúwa\nd* yóò sọ ara rẹ̀ di mí mọ̀ fún àwọn ará Ejibiti àti ní ọjọ́ náà ni wọn yóò gba \nd Olúwa\nd* gbọ́. Wọn yóò sìn ín pẹ̀lú ẹbọ ọrẹ ìyẹ̀fun, wọn yóò jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún \nd Olúwa\nd* wọn yóò sì mú un ṣẹ.
\v 22 \nd Olúwa\nd* yóò fi àjàkálẹ̀-ààrùn kan bá Ejibiti jà; yóò bá wọn jà yóò sì tún wò wọ́n sàn. Wọn yóò yípadà sí \nd Olúwa\nd*, Òun yóò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn yóò sì wò wọ́n sàn.
\p
\v 23 Ní ọjọ́ náà òpópónà kan yóò wá láti Ejibiti lọ sí Asiria. Àwọn ará Asiria yóò lọ sí Ejibiti àti àwọn ará Ejibiti lọ sí Asiria. Àwọn ará Ejibiti àti ará Asiria yóò jọ́sìn papọ̀.
\v 24 Ní ọjọ́ náà Israẹli yóò di ẹ̀kẹta pẹ̀lú Ejibiti àti Asiria, àní orísun ìbùkún ní ilẹ̀ ayé.
\v 25 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun yóò bùkún wọn yóò wí pé, “Ìbùkún ni fún Ejibiti ènìyàn mi, Asiria iṣẹ́ ọwọ́ mi, àti Israẹli ìní mi.”
\c 20
\s1 Àsọtẹ́lẹ̀ tó lòdì sí Ejibiti àti Kuṣi
\p
\v 1 Ní ọdún tí olórí ogun, tí Sagoni ọba Asiria rán an, wá sí Aṣdodu, ó kọlù ú ó sì kó o—
\v 2 ní àkókò náà ni ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* ti ẹnu Isaiah ọmọ Amosi jáde. Ó sọ fún un pé, “Mú aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò ní ara rẹ kí o sì bọ́ sálúbàtà kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó ń lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà.
\p
\v 3 Lẹ́yìn náà ni \nd Olúwa\nd* wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ mi Isaiah ti lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà fún ọdún mẹ́ta, gẹ́gẹ́ bí àmì àti àpẹẹrẹ sí Ejibiti àti Kuṣi,
\v 4 bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọba Asiria yóò kó àwọn ìgbèkùn Ejibiti lọ ní ìhòhò àti láì wọ bàtà pẹ̀lú àwọn àtìpó Kuṣi, ọ̀dọ́ àti àgbà, pẹ̀lú ìbàdí ìhòhò—bí àbùkù Ejibiti.
\v 5 Gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Kuṣi tí wọ́n sì ń fi Ejibiti yangàn ni ẹ̀rù yóò dé bá tí a ó sì dójútì wọ́n.
\v 6 Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn tí ó ń gbé ní etí Òkun yóò wí pé, Wo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí a ti gbẹ́kẹ̀lé, àwọn tí a sá tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́ àti ìtúsílẹ̀ láti ọwọ́ ọba Asiria! Báwo ni a ó ṣe sálà?’ ”
\c 21
\s1 Àsọtẹ́lẹ̀ tó lòdì sí Babeli
\p
\v 1 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan aginjù lẹ́bàá Òkun.
\q1 Gẹ́gẹ́ bí ìjì líle ti í jà kọjá ní gúúsù,
\q2 akógunjàlú kan wá láti aginjù,
\q2 láti ilẹ̀ ìpayà.
\b
\q1
\v 2 Ìran tí a ń fojú ṣọ́nà fún ni a ti fihàn mí
\q2 ọlọ̀tẹ̀ ti tu àṣírí, fọ́lé fọ́lé ti kẹ́rù.
\q1 Elamu kojú ìjà! Media ti tẹ̀gùn!
\q2 Èmi yóò mú gbogbo ìpayínkeke dópin,
\q1 ni ó búra.
\b
\q1
\v 3 Pẹ̀lú èyí, ìrora mu mi lára gírígírí,
\q2 ìrora gbá mi mú, gẹ́gẹ́ bí i ti
\q1 obìnrin tí ń rọbí,
\q2 mo ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nítorí ohun tí mo gbọ́,
\q2 ọkàn mi pòruurù nípa ohun tí mo rí.
\q1
\v 4 Ọkàn mí dàrú,
\q2 ẹ̀rù mú jìnnìjìnnì bá mi,
\q1 ìmọ́lẹ̀ tí mo ti ń fẹ́ ẹ́ rí
\q2 ti wá di ìpayà fún mi.
\b
\q1
\v 5 Wọ́n tẹ́ tábìlì,
\q2 wọ́n tẹ́ ẹní àtẹ́ẹ̀ká,
\q1 wọ́n jẹ, wọ́n mu!
\q2 Dìde nílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ-aládé,
\q2 ẹ fi òróró kún asà yín!
\p
\v 6 Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:
\q1 “Lọ, kí o bojúwòde
\q2 kí o sì wá sọ ohun tí ó rí.
\q1
\v 7 Nígbà tí ó bá rí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun
\q2 àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin,
\q1 àwọn tó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
\q2 tàbí àwọn tí ó gun ìbákasẹ,
\q1 jẹ́ kí ó múra sílẹ̀,
\q2 àní ìmúra gidigidi.”
\p
\v 8 Òun sì kígbe pé, kìnnìún kan,
\q1 “Láti ọjọ́ dé ọjọ́, olúwa mi, mo dúró lórí ilé ìṣọ́ ní ọ̀sán,
\q2 a sì fi mí ìṣọ́ mi ní gbogbo òru.
\q1
\v 9 Wò ó, ọkùnrin kan ni ó ń bọ̀ wá yìí nínú kẹ̀kẹ́ ogun
\q2 àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin.
\q1 Ó sì mú ìdáhùn padà wá:
\q2 Babeli ti ṣubú, ó ti ṣubú!
\q1 Gbogbo àwọn ère òrìṣà rẹ̀
\q2 ló fọ́nká sórí ilẹ̀!’ ”
\b
\q1
\v 10 Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí a gún mọ́lẹ̀ ní ilẹ̀ ìpakà,
\q2 mo sọ ohun tí mo ti gbọ́
\q1 láti ọ̀dọ̀ \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun,
\q2 láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Israẹli.
\s1 Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Edomu
\p
\v 11 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Dumahi.
\q1 Ẹnìkan ké sí mi láti Seiri wá,
\q2 “Alóre, kí ló kù nínú òru náà?”
\q1
\v 12 Alóre náà dáhùn wí pé,
\q2 “Òwúrọ̀ súnmọ́ tòsí, àti òru náà pẹ̀lú.
\q1 Bí ìwọ yóò bá béèrè, béèrè;
\q2 kí o sì tún padà wá.”
\s1 Àsọtẹ́lẹ̀ tó lòdì sí Arabia
\p
\v 13 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Arabia.
\q1 Ẹ̀yin ẹgbẹ́ èrò ti Dedani,
\q2 tí ó pàgọ́ sínú igbó Arabia,
\q1
\v 14 gbé omi wá fún àwọn tí òǹgbẹ ń gbẹ;
\q2 ẹ̀yin tí ó ń gbé Tema,
\q2 gbé oúnjẹ wá fún àwọn ìsáǹsá.
\q1
\v 15 Wọ́n sá kúrò lọ́wọ́ idà,
\q2 kúrò lọ́wọ́ idà tí a fàyọ,
\q1 kúrò lọ́wọ́ ọrun tí a fàyọ
\q2 àti kúrò nínú ìgbóná ogun.
\p
\v 16 Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Láàrín ọdún kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ọgbà, í ti í kà á, gbogbo ògo ìlú Kedari yóò wá sí òpin.
\v 17 Àwọn tafàtafà tí ó sálà, àwọn jagunjagun ìlú Kedari kò ní tó nǹkan.” \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run Israẹli ni ó ti sọ̀rọ̀.
\c 22
\s1 Àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Jerusalẹmu
\p
\v 1 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó jẹ mọ́ àfonífojì ìran.
\q1 Kí ni ó ń dààmú yín báyìí,
\q2 tí gbogbo yín fi gun orí òrùlé lọ?
\q1
\v 2 Ìwọ ìlú tí ó kún fún rúkèrúdò,
\q2 ìwọ ìlú àìtòrò òun rògbòdìyàn
\q1 a kò fi idà pa àwọn òkú rẹ,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kú ní ojú ogun.
\q1
\v 3 Gbogbo àwọn olórí i yín ti jùmọ̀ sálọ;
\q2 a ti kó wọn nígbèkùn láìlo ọfà.
\q1 Ẹ̀yin tí a mú ni a ti kó lẹ́rú papọ̀,
\q2 lẹ́yìn tí ẹ ti sá nígbà tí ọ̀tá ṣì wà
\q2 lọ́nà jíjìn réré.
\q1
\v 4 Nítorí náà ni mo wí pé, “Yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi:
\q2 jẹ́ kí n sọkún kíkorò.
\q1 Má ṣe gbìyànjú àti tù mí nínú
\q2 nítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.”
\b
\q1
\v 5 Olúwa, \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan
\q2 tí rúkèrúdò àti rògbòdìyàn àti ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀
\q2 ní àfonífojì ìmọ̀,
\q1 ọjọ́ tí a ń wó ògiri lulẹ̀
\q2 àti sísun ẹkún lọ sí àwọn orí òkè.
\q1
\v 6 Elamu mú apó-ọfà lọ́wọ́,
\q2 pẹ̀lú àwọn agun-kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹṣin,
\q2 Kiri yọ àpáta rẹ̀ síta.
\q1
\v 7 Àyànfẹ́ àfonífojì rẹ kún fún kẹ̀kẹ́ ogun,
\q2 àwọn ẹlẹ́ṣin ni a gbá jọ sí ẹnu-bodè ìlú.
\b
\q1
\v 8 Gbogbo ààbò Juda ni a ti ká kúrò.
\q1 Ìwọ sì gbójú sókè ní ọjọ́ náà
\q2 sí àwọn ohun ìjà ní ààfin ti inú aginjù.
\q1
\v 9 Ìwọ rí i pé ìlú u Dafidi
\q2 ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ààyè níbi ààbò rẹ̀,
\q1 ìwọ ti tọ́jú omi
\q2 sínú adágún ti ìsàlẹ̀.
\q1
\v 10 Ìwọ ka àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu
\q2 ó sì wó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé lulẹ̀ láti fún ògiri lágbára.
\q1
\v 11 Ìwọ mọ agbemi sí àárín ògiri méjì
\q2 fún omi inú adágún àtijọ́,
\q1 ṣùgbọ́n ìwọ kò wo ẹni tí ó ṣe é tẹ́lẹ̀
\q2 tàbí kí o kọbi ara sí ẹni tí ó
\q2 gbèrò rẹ̀ ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.
\b
\q1
\v 12 \nd Olúwa\nd*, àní \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun,
\q2 pè ọ́ ní ọjọ́ náà
\q1 láti sọkún kí o sì pohùnréré,
\q2 kí o tu irun rẹ dànù kí o sì
\q2 da aṣọ ọ̀fọ̀ bora.
\q1
\v 13 Ṣùgbọ́n wò ó, ayọ̀ àti ayẹyẹ wà;
\q2 màlúù pípa àti àgùntàn pípa,
\q2 ẹran jíjẹ àti ọtí wáìnì mímu!
\q1 Ẹ̀yin wí pé, “Jẹ́ kí a jẹ kí a mu,
\q2 nítorí pé lọ́la àwa ó kú!”
\p
\v 14 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun ti sọ èyí di mí mọ̀ létí ì mi: “Títí di ọjọ́ ikú yín a kò ní ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yìí,” ni Olúwa wí, àní \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun.
\p
\v 15 Èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd*, àní \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí,
\q1 “Lọ, sọ fún ìríjú yìí pé,
\q2 fún Ṣebna, ẹni tí ààfin wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.
\q1
\v 16 Kí ni ohun tí ò ń ṣe níhìn-ín yìí àti pé
\q2 ta ni ó sì fún ọ ní àṣẹ
\q1 láti gbẹ́ ibojì kan fún ara rẹ níhìn-ín yìí,
\q2 tí ó gbẹ́ ibojì ní ibi gíga
\q2 tí ó sì gbẹ́ ibi ìsinmi rẹ nínú àpáta?
\b
\q1
\v 17 “Kíyèsára, \nd Olúwa\nd* fẹ́ gbá ọ mú gírígírí
\q2 kí ó sì jù ọ́ nù, ìwọ ọkùnrin alágbára.
\q1
\v 18 Òun yóò ká ọ rúgúdù bí i òkìtì
\q2 yóò sì sọ ọ́ sí orílẹ̀-èdè ńlá kan.
\q1 Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí
\q2 àti níbẹ̀ pẹ̀lú ni àwọn kẹ̀kẹ́ ogun
\q1 àràmọ̀ǹdà rẹ yóò wà—
\q2 ìwọ di ìtìjú sí ilé ọ̀gá rẹ!
\q1
\v 19 Èmi yóò yọ ọ́ kúrò ní ipò rẹ,
\q2 a ó sì lé ọ kúrò ní ipò rẹ.
\p
\v 20 “Ní ọjọ́ náà. Èmi yóò ké sí ọmọ ọ̀dọ̀ mi, Eliakimu ọmọ Hilkiah.
\v 21 Èmi yóò fi aṣọ rẹ wọ̀ ọ́, n ó sì so ẹ̀wọ̀n rẹ mọ́ ọn ní ọrùn, èmi ó sì gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́. Òun yó sì jẹ́ baba fún gbogbo olùgbé e Jerusalẹmu àti fún ilé e Juda.
\v 22 \x - \xo 22.22: \xt If 3.7.\x*Èmi yóò sì fi kọ́kọ́rọ́ ilé e Dafidi lé e ní èjìká; ohunkóhun tí ó bá ṣí, ẹnikẹ́ni kì yóò lè ti, ohunkóhun tí ó bá sì tì, ẹnikẹ́ni kì yóò le è ṣí.
\v 23 Èmi yóò sì kàn mọ́lẹ̀ bí èèkàn tí ó dúró gírígírí ní ààyè e rẹ̀; òun yóò sì jẹ́ ibùjókòó ọlá fún ilé baba rẹ̀.
\v 24 Gbogbo ògo ìdílé rẹ̀ ni wọn yóò sì fi kọ ní ọrùn: ìran rẹ̀ àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀, gbogbo ohun èlò ife, títí dé orí ago ọtí.
\p
\v 25 “Ní ọjọ́ náà,” ni \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí, “Èèkàn tí a kàn mọ́lẹ̀ gírígírí ní ààyè e rẹ̀ yóò yẹrí, yóò dẹ̀gbẹ́ yóò sì fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ àti ẹrù tí ó létéńté lórí i rẹ̀ ni a ó gé lulẹ̀.” \nd Olúwa\nd* ni ó ti sọ ọ́.
\c 23
\s1 Àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Tire
\p
\v 1 \x - \xo 23.1-18: \xt El 26.128.19; Jl 3.4-8; Am 1.9-10; Sk 9.3-4.\x*Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Tire.
\q1 Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi!
\q2 Nítorí a ti pa Tire run
\q1 láìsí ilé tàbí èbúté.
\q2 Láti ilẹ̀ Saipurọsi ni
\q2 ọ̀rọ̀ ti wá sọ́dọ̀ wọn.
\b
\q1
\v 2 Dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù
\q2 àti ẹ̀yin oníṣòwò ti Sidoni,
\q2 ẹ̀yin tí àwọn a wẹ Òkun ti sọ dọlọ́rọ̀.
\q1
\v 3 Láti orí àwọn omi ńlá
\q2 ni irúgbìn ìyẹ̀fun ti ilẹ̀ Ṣihori ti wá;
\q1 ìkórè ti odò Naili ni owóòná Tire,
\q2 òun sì ti di ibùjókòó ọjà fún àwọn orílẹ̀-èdè.
\b
\q1
\v 4 Kí ojú kí ó tì ọ́, ìwọ Sidoni àti ìwọ
\q2 àní ìwọ ilé ààbò ti Òkun,
\q1 nítorí Òkun ti sọ̀rọ̀.
\q2 “Èmi kò tí ì wà ní ipò ìrọbí tàbí ìbímọ rí
\q1 Èmi kò tí ì wo àwọn ọmọkùnrin
\q2 tàbí kí n tọ́ àwọn ọmọbìnrin dàgbà rí.”
\q1
\v 5 Nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dé Ejibiti,
\q2 wọn yóò wà ní ìpayínkeke nípa
\q2 ìròyìn láti Tire.
\b
\q1
\v 6 Kọjá wá sí Tarṣiṣi;
\q2 pohùnréré, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù.
\q1
\v 7 Ǹjẹ́ èyí náà ni ìlú àríyá yín,
\q2 ògbólógbòó ìlú náà,
\q1 èyí tí ẹsẹ̀ rẹ̀ ti sìn ín lọ
\q2 láti lọ tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré.
\q1
\v 8 Ta ló gbèrò èyí sí Tire,
\q2 ìlú aládé,
\q1 àwọn oníṣòwò ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-aládé
\q2 tí àwọn oníṣòwò wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀míká
\q2 ní orílẹ̀ ayé?
\q1
\v 9 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun ti ṣètò rẹ̀,
\q2 láti tẹrí ìgbéraga àti ògo rẹ ba
\q1 àti láti rẹ gbogbo àwọn ọlọ́lá
\q2 ilé ayé sílẹ̀.
\b
\q1
\v 10 Tu ilẹ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí i ti ipadò odò Ejibiti,
\q2 ìwọ ọmọbìnrin Tarṣiṣi,
\q2 nítorí ìwọ kò ní èbúté mọ́.
\q1
\v 11 \nd Olúwa\nd* ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí orí Òkun
\q2 ó sì mú kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.
\q1 Ó ti pa àṣẹ kan tí ó kan Kenaani
\q2 pé kí a pa ilé ààbò rẹ̀ run.
\q1
\v 12 Ó wí pé, “Kò sí àríyá fún ọ mọ́,
\q2 ìwọ wúńdíá ti Sidoni, tí a ti tẹ̀ mọ́lẹ̀ báyìí!
\b
\q1 “Gbéra, rékọjá lọ sí Saipurọsi,
\q2 níbẹ̀ pẹ̀lú o kì yóò ní ìsinmi.”
\q1
\v 13 Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Babeli,
\q2 àwọn ènìyàn tí kò jámọ́ nǹkan kan báyìí.
\q1 Àwọn Asiria ti sọ ọ́ di
\q2 ibùgbé àwọn ohun ẹranko aginjù;
\q1 wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gùn wọn sókè,
\q2 wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòhò
\q2 wọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn.
\b
\q1
\v 14 Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi;
\q2 wọ́n ti pa odi rẹ̀ run!
\p
\v 15 Ní àkókò náà a ó gbàgbé Tire fún àádọ́rin ọdún, ọjọ́ ayé ọba kan. Ṣùgbọ́n ní òpin àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tire gẹ́gẹ́ bí orin àgbèrè:
\q1
\v 16 “Mú dùùrù kan, rìn kọjá láàrín ìlú,
\q2 ìwọ àgbèrè tí a ti gbàgbé;
\q1 lu dùùrù dáradára, kọ ọ̀pọ̀ orin,
\q2 kí a lè ba à rántí rẹ.”
\p
\v 17 \x - \xo 23.17: \xt If 17.2.\x*Ní òpin àádọ́rin ọdún náà, \nd Olúwa\nd* yóò bá Tire jà. Òun yóò sì padà sí àyálò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí panṣágà, yóò sì máa ṣe òwò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ọba tí ó wà ní ilẹ̀ ayé.
\v 18 Síbẹ̀síbẹ̀ èrè rẹ̀ àti owó iṣẹ́ rẹ̀ ni a ó yà sọ́tọ̀ fún \nd Olúwa\nd*; a kò ní kó wọn pamọ́ tàbí kí a há wọn mọ́wọ́. Ère rẹ̀ ni a ó fi fún àwọn tí ó ń gbé níwájú \nd Olúwa\nd*, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ àti aṣọ.
\c 24
\s1 Ìparun \nd Olúwa\nd* lórí ilẹ̀ ayé
\q1
\v 1 Kíyèsi i, \nd Olúwa\nd* yóò sọ ohun
\q2 gbogbo dòfo ní ilẹ̀ ayé
\q1 yóò sì pa á run
\q2 òun yóò pa ojú u rẹ̀ rẹ́
\q2 yóò sì fọ́n àwọn olùgbé ibẹ̀ káàkiri—
\q1
\v 2 bákan náà ni yóò sì rí
\q2 fún àlùfáà àti àwọn ènìyàn,
\q1 fún ọ̀gá àti ọmọ ọ̀dọ̀,
\q2 fún ìyá-ilé àti ọmọbìnrin,
\q1 fún olùtà àti olùrà,
\q2 fún ayáni àti atọrọ
\q2 fún ayánilówó àti onígbèsè.
\q1
\v 3 Ilé ayé ni a ó sọ di ahoro pátápátá
\q2 a ó sì jẹ gbogbo rẹ̀ run.
\q2 \nd Olúwa\nd* ni ó ti sọ ọ̀rọ̀ yìí.
\b
\q1
\v 4 Ilẹ̀ ayé ti gbẹ ó sì sá,
\q2 ayé ń ṣòjòjò, àárẹ̀ mú un,
\q2 àwọn ẹni gíga ilẹ̀ ayé wà nínú ìpọ́njú
\q1
\v 5 àwọn ènìyàn ayé ti bà á jẹ́;
\q2 wọ́n ti pa àwọn òfin run
\q1 wọ́n ṣe lòdì sí àwọn ìlànà
\q2 wọ́n sì ti ba májẹ̀mú ayérayé jẹ́.
\q1
\v 6 Nítorí náà, ègún kan ti jẹ ayé run;
\q2 àwọn ènìyàn rẹ̀ ní láti ru ẹ̀bi wọn.
\q1 Nítorí náà, àwọn olùgbé ayé ti gbiná dànù,
\q2 àwọn ẹ̀tàhóró ló sì kù.
\q1
\v 7 Wáìnì tuntun ti gbẹ, àjàrà sì ti rọ,
\q2 gbogbo àwọn aláríyá sì kérora.
\q1
\v 8 \x - \xo 24.8: \xt If 18.22.\x*Àríyá ti ṣaworo ti dákẹ́
\q2 ariwo àwọn tí ń ṣàjọyọ̀ ti dáwọ́ dúró
\q2 ayọ̀ dùùrù ti dákẹ́ jẹ́ẹ́.
\q1
\v 9 Kò ṣe é ṣe fún wọn láti máa mu wáìnì pẹ̀lú orin kíkọ mọ́
\q2 ọtí líle ti di ìkorò fún àwọn ọ̀mu.
\q1
\v 10 Ìlú tí a run ti dahoro,
\q2 ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé kọ̀ọ̀kan ni a dí pa.
\q1
\v 11 Ní òpópónà ni wọ́n ti ń kígbe fún wáìnì
\q2 gbogbo ayọ̀ ọ wọn ti di ìbànújẹ́,
\q2 gbogbo àríyá ni a lé kúrò lórí ilẹ̀ ayé.
\q1
\v 12 Ìlú ni a ti fi sílẹ̀ ní ahoro,
\q2 ìlẹ̀kùn rẹ̀ ni a sì tì pa bámú bámú.
\q1
\v 13 Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí ní orí ilẹ̀ ayé
\q2 àti láàrín àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú,
\q1 gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a lu igi olifi,
\q2 tàbí gẹ́gẹ́ bí i pàǹtí tí ó ṣẹ́kù lẹ́yìn
\q2 tí a kórè èso tán.
\b
\q1
\v 14 Wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì hó fún ayọ̀;
\q2 láti ìwọ̀-oòrùn ni wọn yóò ti polongo
\q2 ọláńlá \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 15 Nítorí náà ní ìlà-oòrùn ẹ fi ògo fún \nd Olúwa\nd*;
\q2 gbé orúkọ \nd Olúwa\nd* ga, àní
\q1 Ọlọ́run Israẹli,
\q2 ní àwọn erékùṣù ti inú Òkun.
\q1
\v 16 Láti òpin ayé wá ni a ti gbọ́ orin;
\q2 “Ògo ni fún olódodo n nì.”
\q2 Ṣùgbọ́n mo wí pé, “Mo ṣègbé, mo ṣègbé!
\b
\q1 “Ègbé ni fún mi!
\q2 Alárékérekè dalẹ̀!
\q2 Pẹ̀lú ìhàlẹ̀ ni àgàbàgebè fi dalẹ̀!”
\q1
\v 17 Ìpayà, isà òkú, àti ìdẹ̀kùn ń dúró dè ọ́,
\q2 ìwọ ènìyàn ilẹ̀ ayé.
\q1
\v 18 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá nítorí ariwo ìpayà
\q2 yóò ṣubú sínú ihò,
\q1 ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yọ́ jáde nínú ihò
\q2 ni ìdẹ̀kùn yóò gbámú.
\b
\q1 Ibodè ọ̀run ti wà ní ṣíṣí sílẹ̀,
\q2 ìpìlẹ̀ ayé mì tìtì.
\q1
\v 19 Ilẹ̀ ayé ti fọ́
\q2 ilẹ̀ ayé ti fọ́ dànù,
\q2 a ti mi ilẹ̀ ayé rìrìrìrì.
\q1
\v 20 Ilẹ̀ ayé yí gbiri bí ọ̀mùtí,
\q2 ó bì síwá sẹ́yìn bí ahéré nínú afẹ́fẹ́;
\q1 ẹ̀bi ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ ń pa á lẹ́rù
\q2 tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣubú láìní lè dìde mọ́.
\b
\q1
\v 21 Ní ọjọ́ náà ni \nd Olúwa\nd* yóò jẹ ẹ́ ní yà
\q2 gbogbo agbára tí ó wà lókè lọ́run
\q2 àti àwọn ọba tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé.
\q1
\v 22 A ó sì kó wọn jọ pọ̀,
\q2 gẹ́gẹ́ bí ará túbú jọ sínú ihò,
\q1 a ó tì wọ́n mọ́ inú túbú,
\q2 a ó sì bẹ̀ wọ́n wò lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́.
\q1
\v 23 A ó rẹ òṣùpá sílẹ̀, ojú yóò sì ti oòrùn;
\q2 nítorí \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun yóò jẹ ọba
\q1 ní orí òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu,
\q2 àti níwájú àwọn àgbàgbà rẹ ní ògo.
\c 25
\s1 Ẹ yin \nd Olúwa\nd*
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd*, ìwọ ni Ọlọ́run mi;
\q2 èmi yóò gbé ọ ga èmi ó sì
\q1 fi ìyìn fún orúkọ rẹ
\q2 nítorí nínú òtítọ́ aláìlẹ́gbẹ́
\q1 o ti ṣe ohun ńlá,
\q2 àwọn ohun tí o ti gbèrò o rẹ̀ lọ́jọ́ pípẹ́.
\q1
\v 2 Ìwọ ti sọ ìlú di àkójọ àlàpà,
\q2 ìlú olódi ti di ààtàn,
\q1 ìlú olódi fún àwọn àjèjì ni kò sí mọ́;
\q2 a kì yóò tún un kọ́ mọ́.
\q1
\v 3 Nítorí náà àwọn ènìyàn alágbára yóò
\q2 bọ̀wọ̀ fún ọ;
\q1 àwọn ìlú orílẹ̀-èdè aláìláàánú
\q2 yóò bu ọlá fún ọ.
\q1
\v 4 Ìwọ ti jẹ́ ààbò fún àwọn òtòṣì
\q2 ààbò fún aláìní nínú ìpọ́njú rẹ̀
\q1 ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì
\q2 bòòji kúrò lọ́wọ́ ooru.
\q1 Nítorí pé èémí àwọn ìkà
\q2 dàbí ìjì tí ó bì lu ògiri
\q1
\v 5 àti gẹ́gẹ́ bí ooru ní aginjù.
\q2 O mú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ bá rògbòdìyàn àwọn àjèjì,
\q1 gẹ́gẹ́ bí òjìji kurukuru ṣe ń dín ooru kù,
\q2 bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni orin àwọn ìkà yóò dákẹ́.
\b
\q1
\v 6 Ní orí òkè yìí ni \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun
\q2 yóò ti pèsè
\q1 àsè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyàn
\q2 àpèjẹ ti ọtí wáìnì àtijọ́
\q1 ti ẹran tí ó dára jù àti ti ọtí wáìnì
\q2 tí ó gbámúṣé.
\q1
\v 7 Ní orí òkè yìí ni yóò pa
\q2 aṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn,
\q2 abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀,
\q1
\v 8 \x - \xo 25.8: \xt 1Kọ 15.54; If 7.17; 21.4.\x*Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé.
\q2 \nd Olúwa\nd* Olódùmarè yóò sì nu gbogbo omijé nù,
\q1 kúrò ní ojú gbogbo wọn,
\q2 Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò
\q1 ní gbogbo ilẹ̀ ayé.
\q2 \nd Olúwa\nd* ni ó ti sọ ọ́.
\p
\v 9 Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé,
\q1 “Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa;
\q2 àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, òun sì gbà wá là.
\q1 Èyí ni \nd Olúwa\nd*, àwa gbẹ́kẹ̀lé e,
\q2 ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”
\b
\q1
\v 10 \x - \xo 25.10-12: \xt Isa 1516; Jr 48; El 25.8-11; Am 2.1-3; Sf 2.8-11.\x*Ọwọ́ \nd Olúwa\nd* yóò sinmi lé orí òkè yìí
\q2 ṣùgbọ́n a ó tẹ Moabu mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀;
\q2 gẹ́gẹ́ bí a ti gún koríko mọ́lẹ̀ di ajílẹ̀.
\q1
\v 11 Wọn yóò na ọwọ́ wọn jáde nínú rẹ̀,
\q2 gẹ́gẹ́ bí òmùwẹ̀ tí ń na ọwọ́ rẹ̀
\q1 jáde láti lúwẹ̀ẹ́.
\q2 Ọlọ́run yóò mú ìgbéraga wọn wálẹ̀
\q2 bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣeféfé wà ní ọwọ́ wọn.
\q1
\v 12 Òun yóò sì bi gbogbo ògiri gíga alágbára yín lulẹ̀
\q2 wọn yóò sì wà nílẹ̀,
\q1 Òun yóò sì mú wọn wá si ilẹ̀,
\q2 àní sí erùpẹ̀ lásán.
\c 26
\s1 Orin ìyìn kan
\p
\v 1 Ní ọjọ́ náà ni a ó kọ orin yìí ní ilẹ̀ Juda.
\q1 Àwa ní ìlú alágbára kan,
\q2 Ọlọ́run fi ìgbàlà ṣe
\q2 ògiri àti ààbò rẹ̀.
\q1
\v 2 Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn
\q2 kí àwọn olódodo orílẹ̀-èdè kí ó lè wọlé,
\q2 orílẹ̀-èdè tí ó pa ìgbàgbọ́ mọ́.
\q1
\v 3 Ìwọ yóò pa á mọ́ ní àlàáfíà pípé
\q2 ọkàn ẹni tí ó dúró ṣinṣin,
\q2 nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
\q1
\v 4 Gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd* títí láé,
\q2 nítorí \nd Olúwa\nd*, \nd Olúwa\nd* ni àpáta ayérayé náà.
\q1
\v 5 Ó sọ àwọn tí ó ń gbé ní òkè di onírẹ̀lẹ̀
\q2 ó rẹ ìlú agbéraga náà nílẹ̀;
\q1 ó sọ ọ́ di ilẹ̀ pẹrẹsẹ
\q2 ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.
\q1
\v 6 Ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀
\q2 ẹsẹ̀ aninilára n nì,
\q2 ipasẹ̀ àwọn òtòṣì.
\b
\q1
\v 7 Ipa ọ̀nà àwọn olódodo tẹ́jú,
\q2 ìwọ tó dúró ṣinṣin, ìwọ mú ọ̀nà
\q2 àwọn olódodo ṣe geere.
\q1
\v 8 Bẹ́ẹ̀ ni, \nd Olúwa\nd*, rírìn ní ọ̀nà òfin rẹ
\q2 àwa dúró dè ọ́;
\q1 orúkọ rẹ àti òkìkí rẹ
\q2 àwọn ni ohun tí ọkàn wa ń fẹ́.
\q1
\v 9 Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru;
\q2 ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ.
\q1 Nígbà tí ìdájọ́ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayé
\q2 àwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo.
\q1
\v 10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi oore-ọ̀fẹ́ hàn sí àwọn ìkà
\q2 wọn kò kọ́ láti sọ òdodo;
\q1 kódà ní ilẹ̀ àwọn tí ó dúró ṣinṣin wọ́n
\q2 tẹ̀síwájú láti máa ṣe ibi
\q2 wọn kò sì ka ọláńlá \nd Olúwa\nd* sí.
\q1
\v 11 \nd Olúwa\nd*, ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè
\q2 ṣùgbọ́n àwọn kò rí i.
\q1 Jẹ́ kí wọ́n rí ìtara rẹ fún àwọn ènìyàn rẹ
\q2 kí ojú kí ó tì wọ́n;
\q1 jẹ́ kí iná tí a fi pamọ́ fún àwọn
\q2 ọ̀tá rẹ jó wọn run.
\b
\q1
\v 12 \nd Olúwa\nd*, ìwọ fi àlàáfíà lélẹ̀ fún wa;
\q2 ohun gbogbo tí a ti ṣe yọrí ìwọ ni
\q2 ó ṣe é fún wa.
\q1
\v 13 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa, àwọn olúwa mìíràn
\q2 lẹ́yìn rẹ ti jẹ ọba lé wa lórí,
\q2 ṣùgbọ́n orúkọ rẹ nìkan ni àwa fi ọ̀wọ̀ fún.
\q1
\v 14 Wọ́n ti kú báyìí, wọn ò sí láààyè mọ́;
\q2 gbogbo ẹ̀mí tí ó ti kọjá lọ wọ̀nyí kò le dìde mọ́.
\q1 Ìwọ jẹ́ wọ́n ní ìyà o sì sọ wọ́n di asán,
\q2 ìwọ pa gbogbo ìrántí wọn rẹ́ pátápátá.
\q1
\v 15 Ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè gbòòrò, \nd Olúwa\nd*;
\q2 ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè bí sí i.
\q1 Ìwọ ti gba ògo fún ara rẹ;
\q2 ìwọ ti sún gbogbo àwọn ààlà ilẹ̀ sẹ́yìn.
\b
\q1
\v 16 \nd Olúwa\nd*, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ nínú ìpọ́njú wọn;
\q2 nígbà tí ìbáwí rẹ wà lára wọn,
\q2 wọ́n gbàdúrà kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́.
\q1
\v 17 Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó lóyún tí ó sì fẹ́rẹ̀ bímọ
\q2 tí í rúnra tí ó sì ń sọkún nínú ìrora rẹ̀,
\q2 bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwa rí níwájú rẹ \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 18 Àwa wà nínú oyún, a wà nínú ìrora,
\q2 ṣùgbọ́n, afẹ́fẹ́ ni a bí lọ́mọ.
\q1 Àwa kò mú ìgbàlà wá sí ilẹ̀ ayé;
\q2 àwa kọ́ ni a bí àwọn ènìyàn tí ó wà láyé.
\b
\q1
\v 19 Ṣùgbọ́n àwọn òkú yín yóò wà láààyè
\q2 ara wọn yóò dìde.
\q1 Ìwọ tí o wà nínú erùpẹ̀,
\q2 dìde nílẹ̀ kí o sì ké igbe ayọ̀.
\q1 Ìrì rẹ dàbí ìrì òwúrọ̀,
\q2 ayé yóò bí àwọn òkú rẹ̀ lọ́mọ.
\b
\q1
\v 20 Ẹ lọ, ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ wọ ìyẹ̀wù yín lọ
\q2 kí ẹ sì ti àwọn ìlẹ̀kùn lẹ́yìn yín,
\q1 ẹ fi ara yín pamọ́ fún ìgbà díẹ̀
\q2 títí tí ìbínú rẹ̀ yóò fi rékọjá.
\q1
\v 21 Kíyèsi i, \nd Olúwa\nd* ń jáde bọ̀ láti ibùgbé rẹ̀
\q2 láti jẹ àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé ní ìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
\q1 Ayé yóò sì sọ àwọn ẹ̀jẹ̀ tí a ta sí orí rẹ̀;
\q2 kì yóò sì fi àwọn tí a ti pa pamọ́ mọ́.
\c 27
\s1 Ìdáǹdè Israẹli
\p
\v 1 Ní ọjọ́ náà,
\q1 \nd Olúwa\nd* yóò fi idà rẹ̀ jẹ ni ní yà
\q2 idà rẹ̀ a mú bí iná tí ó tóbi tí ó sì lágbára
\q1 Lefitani ejò tí ń yọ̀ tẹ̀ẹ̀rẹ̀ n nì,
\q2 Lefitani ejò tí ń lọ́ bìrìkìtì;
\q2 Òun yóò sì pa ẹ̀mí búburú inú Òkun náà.
\p
\v 2 Ní ọjọ́ náà,
\q1 “Kọrin nípa ọgbà àjàrà eléso kan.
\q2
\v 3 Èmi \nd Olúwa\nd* ń bojútó o,
\q1 Èmi ó bomirin ín láti ìgbàdégbà.
\q2 Èmi ó ṣọ́ ọ tọ̀sán tòru
\q2 kí ẹnikẹ́ni má ba à pa á lára.
\q1
\v 4 Inú kò bí mi.
\q2 Bí ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n bá dojú ìjà kọ mí!
\q1 Èmi yóò dìde sí wọn ní ogun,
\q2 Èmi yóò sì dáná sun gbogbo wọn.
\q1
\v 5 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí wọn wá sọ́dọ̀ mi fún ààbò;
\q2 jẹ́ kí wọ́n wá àlàáfíà pẹ̀lú mi,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí wọn wá àlàáfíà pẹ̀lú mi.”
\b
\q1
\v 6 Ní ọjọ́ iwájú Jakọbu yóò ta gbòǹgbò,
\q2 Israẹli yóò tanná yóò sì rudi
\q2 èso rẹ̀ yóò sì kún gbogbo ayé.
\b
\q1
\v 7 Ǹjẹ́ \nd Olúwa\nd* ti lù ú
\q2 gẹ́gẹ́ bí ó ti lu àwọn tí ó lù ú bolẹ̀?
\q1 Ǹjẹ́ a ti pa á
\q2 gẹ́gẹ́ bí a ti pa àwọn tí ó pa á?
\q1
\v 8 Nípa ogun jíjà àti ìjìyà ti o le ni ó
\q2 fi dojúkọ ọ́
\q1 pẹ̀lú ìjì gbígbóná ni ó lé e jáde,
\q2 gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn fẹ́.
\q1
\v 9 Nítorí èyí báyìí ni ètùtù yóò ṣe wà
\q2 fún ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu,
\q1 èyí ni yóò sì jẹ́ èso kíkún ti
\q2 ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.
\q1 Nígbà tí ó bá mú kí àwọn òkúta pẹpẹ
\q2 dàbí òkúta ẹfun tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́,
\q1 kì yóò sí ère Aṣerah tàbí pẹpẹ tùràrí
\q2 tí yóò wà ní ìdúró.
\q1
\v 10 Ìlú olódi náà ti dahoro,
\q2 ibùdó ìkọ̀sílẹ̀, tí a kọ̀ tì
\q1 gẹ́gẹ́ bí aginjù;
\q2 níbẹ̀ ni àwọn ọmọ màlúù ti ń jẹ oko
\q1 níbẹ̀ ni wọn ń sùn sílẹ̀;
\q2 wọn sì jẹ gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ tán.
\q1
\v 11 Nígbà tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ bá rọ, a ó ya wọn dànù
\q2 àwọn obìnrin dé, wọ́n sì fi wọ́n dáná
\q1 nítorí aláìlóye ènìyàn ni wọn jẹ́,
\q2 nítorí náà ni ẹni tí ó dá wọn kì yóò ṣàánú fún wọn;
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó mọ wọn kì yóò sì fi ojúrere wò wọ́n.
\p
\v 12 Ní ọjọ́ náà \nd Olúwa\nd* yóò sì kó oore láti ìṣàn omi odo Eufurate wá títí dé Wadi ti Ejibiti, àti ìwọ, ìwọ ọmọ Israẹli, ni a ó kójọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.
\v 13 \x - \xo 27.13: \xt Mt 24.31; 1Kọ 15.52; 1Tẹ 4.16.\x*Àti ní ọjọ́ náà, a ó fun fèrè ńlá kan. Gbogbo àwọn tí ń ṣègbé lọ ní Asiria àti àwọn tí ń ṣe àtìpó ní Ejibiti yóò wá sin \nd Olúwa\nd* ní òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu.
\c 28
\s1 Ègbé ni fún Efraimu
\q1
\v 1 Ègbé ni fún adé ìgbéraga,
\q2 fún àwọn ọ̀mùtí Efraimu,
\q1 àti fún ìtànná rírọ, ẹwà ògo rẹ̀,
\q2 tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú
\q2 àti sí ìlú náà
\q2 ìgbéraga àwọn tí ọtí wáìnì ń pa tí a rẹ̀ sílẹ̀.
\q1
\v 2 Kíyèsi i, Olúwa ní ẹnìkan tí ó le, tí ó sì lágbára,
\q2 gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ yìnyín àti bí ìjì apanirun,
\q1 gẹ́gẹ́ bí àrọ̀dá òjò àti òjò tí ó mú ìkún omi wá,
\q2 òun yóò fi tipátipá sọ ọ́ sílẹ̀.
\q1
\v 3 Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efraimu,
\q2 ni a ó fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.
\q1
\v 4 Òdòdó tí ó ń rọ náà tí í ṣe ẹwà ògo rẹ̀,
\q2 tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú,
\q1 yóò dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó pọ́n ṣáájú ìkórè
\q2 bí ẹnikẹ́ni bá ti rí i tí ó sì mú un ní ọwọ́ rẹ̀,
\q2 òun a sì mì ín.
\b
\q1
\v 5 Ní ọjọ́ náà \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun
\q2 yóò jẹ́ adé tí ó lógo,
\q1 àti adé tí ó lẹ́wà
\q2 fún àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù.
\q1
\v 6 Òun yóò sì jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́ òdodo
\q2 fún ẹni tí ó jókòó ní ìtẹ́ ìdájọ́
\q1 àti orísun agbára
\q2 fún àwọn ẹni tí ó ń dá ogun padà ní ẹnu ibodè.
\b
\q1
\v 7 Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí wáìnì
\q2 wọ́n pòòrì fún ọtí líle,
\q1 àwọn àlùfáà àti wòlíì ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí líle
\q2 wọ́n ta gíẹ́ gíẹ́ fún ọtí wáìnì
\q1 wọ́n ń lọ́ bìrì bìrì fún ọtí líle,
\q2 wọ́n ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nígbà tí wọ́n ń ríran,
\q2 wọ́n kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń mú ìpinnu wá.
\q1
\v 8 Gbogbo orí tábìlì ni ó kún fún èébì
\q2 kò sì ṣí ibìkan tí kò sí ẹ̀gbin.
\b
\q1
\v 9 “Ta ni ẹni náà tí ó ń gbìyànjú àti kọ́?
\q2 Ta ni ó sì ń ṣàlàyé ìròyìn in rẹ̀ fún?
\q1 Sí àwọn ọmọdé tí a já lẹ́nu ọmú wọn,
\q2 sí àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́nu ọmú.
\q1
\v 10 Nítorí tí í ṣe: báyìí ni orí,
\q2 ṣe, kí o si túnṣe, ṣe kí o si túnṣe,
\q2 àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ;
\q2 díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn.”
\b
\q1
\v 11 \x - \xo 28.11-12: \xt 1Kọ 14.21.\x*Ó dára báyìí, pẹ̀lú ètè àjèjì àti ahọ́n àìmọ̀
\q2 Ọlọ́run yóò bá àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀
\q1
\v 12 \x - \xo 28.12: \xt Mt 11.29.\x*àwọn tí ó sọ fún wí pé,
\q2 “Èyí ni ibi ìsinmi, jẹ́ kí àwọn aláàárẹ̀ sinmi”;
\q1 àti pé, “Èyí ni ibi ìsinmi”;
\q2 ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sílẹ̀.
\q1
\v 13 Fún ìdí èyí, ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* sí wọn yóò di pé,
\q2 ṣe èyí, ṣe ìyẹn,
\q2 àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ;
\q2 díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn,
\q1 bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò lọ tí wọn yóò tún ṣubú sẹ́yìn,
\q2 wọn yóò fi ara pa, wọn yóò bọ́ sínú okùn a ó sì gbá wọn mú.
\b
\q1
\v 14 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd*, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,
\q2 tí ń jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Jerusalẹmu.
\q1
\v 15 Ẹ fọ́n pé, “Àwa ti bá ikú mulẹ̀,
\q2 pẹ̀lú ibojì ni àwa ti jọ ṣe àdéhùn.
\q1 Nígbà tí ìbáwí gbígbóná fẹ́ kọjá,
\q2 kò le kàn wá lára,
\q1 nítorí a ti fi irọ́ ṣe ààbò o wa
\q2 àti àìṣòótọ́ ibi ìpamọ́ wa.”
\p
\v 16 \x - \xo 28.16: \xt Ro 9.33; 10.11; 1Pt 2.4-6.\x*Nítorí náà, báyìí ni \nd Olúwa\nd* Olódùmarè wí:
\q1 “Kíyèsi i, èmi gbé òkúta kan lélẹ̀ ní Sioni, òkúta tí a dánwò,
\q2 òkúta igun ilé iyebíye fún ìpìlẹ̀ tí ó dájú;
\q1 ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé
\q2 kì yóò ní ìfòyà.
\q1
\v 17 Èmi yóò fi ìdájọ́ ṣe okùn òsùwọ̀n
\q2 àti òdodo òjé òsùwọ̀n;
\q1 yìnyín yóò gbá ààbò yín dànù àti irọ́,
\q2 omi yóò sì kún bo gbogbo ibi tí
\q2 ẹ ń fi ara pamọ́ sí mọ́lẹ̀.
\q1
\v 18 Májẹ̀mú yín tí ẹ bá ikú dá ni a ó fa igi lé;
\q2 àdéhùn yín pẹ̀lú ibojì ni kì yóò dúró.
\q1 Nígbà tí ìbínú gbígbóná náà bá fẹ́ kọjá,
\q2 a ó ti ipa rẹ̀ lù yín bolẹ̀.
\q1
\v 19 Nígbàkígbà tí ó bá ti wá ni
\q2 yóò máa gbé ọ lọ,
\q1 ni àràárọ̀, ní ọ̀sán àti ní òru,
\q2 ni yóò máa fẹ́ kọjá lọ.”
\b
\q1 Ìmòye ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yìí
\q2 yóò máa mú ìpayà ńlá wá.
\q1
\v 20 Ibùsùn kúrú púpọ̀ fún ìnara lé lórí,
\q2 ìbora kò fẹ̀ tó láti yí ara yín ká.
\q1
\v 21 \nd Olúwa\nd* yóò dìde sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe
\q2 ní òkè Perasimu
\q1 yóò ru ara rẹ̀ sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe
\q2 ní àfonífojì Gibeoni—
\q1 láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, abàmì iṣẹ́ ẹ rẹ̀,
\q2 yóò ṣe iṣẹ́ rẹ̀, àní àjèjì iṣẹ́ rẹ̀.
\q1
\v 22 Ní ìsinsin yìí ẹ dákẹ́ ẹlẹ́yà ṣíṣe,
\q2 bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìdè e yín yóò le sí i;
\q1 \nd Olúwa\nd*, àní \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun ti sọ fún mi
\q2 nípa àṣẹ ìparun ti ó ti pa lórí gbogbo ilẹ̀ náà.
\b
\q1
\v 23 Tẹ́tí kí o sì gbọ́ ohùn mi,
\q2 fi ara balẹ̀ kí o sì gbọ́ ohun tí mo sọ.
\q1
\v 24 Nígbà tí àgbẹ̀ kan bá tu ilẹ̀ láti gbìn
\q2 yóò ha máa tulẹ̀ títí bi?
\q1 Ǹjẹ́ yóò ha máa tu ilẹ̀ kí
\q2 ó sì máa jọ̀ ọ́ títí lọ bí?
\q1
\v 25 Nígbà tí òun bá ti tẹ́ ojú ilẹ̀ rẹ̀ pẹrẹsẹ
\q2 òun kò ha ń fúnrúgbìn dílì
\q1 kí ó sì fúnrúgbìn kummini ká?
\q2 Kí ó sì gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ,
\q1 barle tí a yàn,
\q2 àti spelti ní ipò rẹ̀?
\q1
\v 26 Ọlọ́run rẹ̀ tọ́ ọ ṣọ́nà
\q2 ó sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀nà tó tọ́.
\b
\q1
\v 27 Nítorí a kò fi ohun èlò ìpakà dili,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni a kì í yí kẹ̀kẹ́ ẹrù kiri lórí kummini;
\q1 ṣùgbọ́n ọ̀pá ni a fi ń pa dili jáde,
\q2 ọ̀gọ ni a sì lu kummini.
\q1
\v 28 A gbọdọ̀ lọ ìyẹ̀fun kí a tó ṣe àkàrà;
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì í máa pa á lọ títí láé.
\q1 Bí ó tilẹ̀ yí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ìpakà a rẹ̀ lórí i rẹ̀,
\q2 àwọn ẹṣin rẹ̀ kò le lọ̀ ọ́.
\q1
\v 29 Gbogbo èyí pẹ̀lú ti ọ̀dọ̀ \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wá,
\q2 oníyanu ní ìmọ̀ràn àti ológo ní ọgbọ́n.
\c 29
\s1 Ègbé ni fún ìlú Dafidi
\q1
\v 1 Ègbé ni fún ọ, Arieli, Arieli,
\q2 ìlú níbi tí Dafidi tẹ̀dó sí!
\q1 Fi ọdún kún ọdún
\q2 sì jẹ́ kí àwọn àkọlùkọgbà àjọ̀dún un rẹ tẹ̀síwájú.
\q1
\v 2 Síbẹ̀síbẹ̀ èmi yóò dó ti Arieli
\q2 òun yóò ṣọ̀fọ̀ yóò sì sọkún,
\q2 òun yóò sì dàbí pẹpẹ ọkàn sí mi.
\q1
\v 3 Èmi yóò sì wà ní bùba yí ọ ká níbi gbogbo,
\q2 Èmi yóò sì fi ilé ìṣọ́ yí ọ ká,
\q2 Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìdó ti ni mi dojúkọ ọ́.
\q1
\v 4 Ní ìrẹ̀sílẹ̀, ìwọ ó sì máa sọ̀rọ̀ láti ilẹ̀ wá;
\q2 ọ̀rọ̀ rẹ yóò sì máa kùn jáde láti inú erùpẹ̀.
\q1 Ohun rẹ yóò máa jáde bí i ti ẹnìkan tó ní ẹ̀mí àfọ̀ṣẹ láti ilẹ̀ jáde wá,
\q2 láti inú erùpẹ̀ ni ohùn rẹ
\q2 yóò máa wá wúyẹ́wúyẹ́.
\b
\q1
\v 5 Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá rẹ, yóò dàbí yanrìn kíkúnná,
\q2 agbo àwọn aláìláàánú bí ìyàngbò tí a fẹ́ dànù.
\q2 Lójijì, ní ìṣẹ́jú kan,
\q1
\v 6 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun yóò wá
\q2 pẹ̀lú àrá àti ilẹ̀-rírì àti ariwo ńlá,
\q2 àti ẹ̀fúùfù líle àti iná ajónirun.
\q2
\v 7 Lẹ́yìn náà,
\q2 ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn tí gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó bá Arieli jà,
\q1 tí ó dojú ìjà kọ òun àti ilé olódi rẹ̀
\q2 tí ó sì dó tì í,
\q1 yóò dàbí ẹni pé nínú àlá,
\q2 bí ìran ní òru
\q1
\v 8 àti bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa ń lá àlá pé òun ń jẹun,
\q2 ṣùgbọ́n ó jí, ebi rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀;
\q1 tàbí bí ìgbà tí ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ lá àlá pé òun ń mu omi,
\q2 ṣùgbọ́n nígbà tí ó jí, sì wò ó, ó dákú, òǹgbẹ sì ń gbẹ ọkàn rẹ̀.
\q1 Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè
\q2 tí ń bá òkè Sioni jà.
\b
\q1
\v 9 Ẹ bẹ̀rù kí ẹnu kí ó yà yín,
\q2 ẹ fọ́ ara yín lójú kí ẹ má sì ríran;
\q1 ẹ mutí yó kì í ṣe ọtí wáìnì,
\q2 ẹ ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n, ṣùgbọ́n kì í ṣe ti ọtí líle.
\q1
\v 10 \nd Olúwa\nd* ti mú oorun ìjìká wá sórí i yín:
\q2 ó ti dì yín lójú ẹ̀yin wòlíì;
\q2 ó ti bo orí yín ẹ̀yin aríran.
\p
\v 11 Fún un yín gbogbo ìran yìí kò yàtọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi èdìdì dì sínú ìwé kíká. Bí ẹ bá sì fún ẹni tí ó lè ka ìwé kíká náà, tí ẹ sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò lè kà á; a ti dì í ní èdìdì.”
\v 12 Tàbí bí ẹ bá fún ẹni tí kò lè ka ìwé kíká náà tí ẹ sì sọ pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n kà.”
\p
\v 13 \x - \xo 29.13: \xt Mt 15.8-9; Mk 7.6-7.\x*Olúwa wí pé:
\q1 “Àwọn ènìyàn yìí súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹnu wọn,
\q2 wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ètè wọn,
\q1 ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí mi.
\q2 Ìsìn wọn si mi
\q1 ni a gbé ka orí òfin tí àwọn
\q2 ọkùnrin kọ́ ni.
\q1
\v 14 \x - \xo 29.14: \xt 1Kọ 1.19.\x*Nítorí náà lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò ya
\q2 àwọn ènìyàn yìí lẹ́nu
\q1 pẹ̀lú ìyanu lórí ìyanu;
\q2 ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ni yóò ṣègbé,
\q2 ìmọ̀ àwọn onímọ̀ ni yóò pòórá.”
\q1
\v 15 Ègbé ni fún àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun
\q2 láti fi ètò wọn pamọ́ kúrò lójú \nd Olúwa\nd*,
\q1 tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ẹ wọn nínú òkùnkùn
\q2 tí wọ́n sì rò pé,
\q2 “Ta ló rí wa? Ta ni yóò mọ̀?”
\q1
\v 16 \x - \xo 29.16: \xt Isa 45.9; Ro 9.20.\x*Ẹ̀yin dojú nǹkan délẹ̀,
\q2 bí ẹni pé wọ́n rò pé amọ̀kòkò dàbí amọ̀!
\q1 Ǹjẹ́ ohun tí a ṣe le sọ fún olùṣe pé,
\q2 “Òun kọ́ ló ṣe mí”?
\q1 Ǹjẹ́ ìkòkò lè sọ nípa amọ̀kòkò pé,
\q2 “Kò mọ nǹkan”?
\b
\q1
\v 17 Ní àìpẹ́ jọjọ, ǹjẹ́
\q2 a kò ní sọ Lebanoni di pápá ẹlẹ́tù lójú
\q2 àti pápá ẹlẹ́tù lójú yóò dàbí aginjù?
\q1
\v 18 \x - \xo 29.18-19: \xt Mt 11.5.\x*Ní ọjọ́ náà adití yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwé kíká náà,
\q2 láti inú fìrífìrí àti òkùnkùn
\q2 ni àwọn ojú afọ́jú yóò ríran.
\q1
\v 19 Lẹ́ẹ̀kan sí i àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóò yọ̀ nínú \nd Olúwa\nd*:
\q2 àwọn aláìní yóò yọ̀ nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.
\q1
\v 20 Aláìláàánú yóò pòórá,
\q2 àwọn tí ń ṣẹlẹ́yà yóò di àwátì,
\q2 gbogbo àwọn tí ó ní ojú ibi ni a ó ké lulẹ̀—
\q1
\v 21 àwọn tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ kan mú ẹnìkan di ẹlẹ́bi,
\q2 ẹni tí ń dẹkùn mú olùgbèjà ní ilé ẹjọ́
\q2 tí ẹ fi ẹ̀rí èké dun aláìṣẹ̀ ní ìdájọ́.
\p
\v 22 Nítorí náà, èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd*, ẹni tí ó ra Abrahamu padà sọ sí ilé Jakọbu:
\q2 “Ojú kì yóò ti Jakọbu mọ́;
\q2 ojú wọn kì yóò sì rẹ̀wẹ̀sì mọ́.
\q1
\v 23 Nígbà tí wọ́n bá rí i láàrín àwọn ọmọ wọn,
\q2 àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mi,
\q1 wọn yóò ya orúkọ mi sí mímọ́,
\q2 wọn yóò tẹ́wọ́gbà mímọ́ Ẹni Mímọ́ Jakọbu
\q2 wọn yóò dìde dúró ní ìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Israẹli.
\q1
\v 24 Gbogbo àwọn tí ń rìn ségesège ní yóò jèrè ìmọ̀;
\q2 gbogbo àwọn tí ń ṣe àròyé yóò gba ìtọ́sọ́nà.”
\b
\c 30
\q1
\v 1 “Ègbé ni àwọn ọmọ fún orílẹ̀-èdè alágídí,”
\q2 ni \nd Olúwa\nd* wí,
\q1 “Fún àwọn tí ó gbé ètò jáde tí kì í ṣe tèmi,
\q2 tí wọ́n ń gbìmọ̀ pọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa Ẹ̀mí mi,
\q2 tí wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀;
\q1
\v 2 tí wọ́n lọ sí Ejibiti
\q2 láìṣe fún mi,
\q1 tí ó ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Farao fún ààbò,
\q2 sí òjìji Ejibiti fún ibi ìsádi.
\q1
\v 3 Ṣùgbọ́n ààbò Farao yóò jásí ìtìjú fún un yín,
\q2 òjìji Ejibiti yóò mú àbùkù bá a yín.
\q1
\v 4 Bí àwọn olórí rẹ tilẹ̀ wà ní Ṣoani,
\q2 tí àwọn ikọ̀ wọn sì ti dé sí Hanisi,
\q1
\v 5 gbogbo wọn ni a ó dójútì,
\q2 nítorí àwọn ènìyàn kan tí kò wúlò fún wọn,
\q1 tí kò mú ìrànlọ́wọ́ tàbí àǹfààní wá,
\q2 bí kò ṣe àbùkù àti ìdójúti ni.”
\p
\v 6 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ sí àwọn ẹranko tí ó wà ní gúúsù.
\q1 Láàrín ilẹ̀ ìnira àti ìpọ́njú,
\q2 ti kìnnìún àti abo kìnnìún
\q1 ti paramọ́lẹ̀ àti ejò olóró,
\q2 àwọn ikọ̀ náà kó ẹrù àti ọrọ̀
\q1 wọn lẹ́yìn àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,
\q2 àwọn ohun ìní wọn ní orí àwọn ìbákasẹ,
\q2 sí orílẹ̀-èdè aláìlérè,
\q1
\v 7 sí Ejibiti tí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀
\q2 kò wúlò rárá.
\q1 Nítorí náà mo pè é ní
\q2 Rahabu aláìlẹ́ṣẹ̀ nǹkan kan.
\b
\q1
\v 8 Lọ nísinsin yìí, kí o sì kọ ọ́ sí ara wàláà fún wọn,
\q2 tẹ̀ ẹ́ sí ara ìwé kíká,
\q1 pé fún àwọn ọjọ́ tí ó ń bọ̀
\q2 kí ó sì lè jẹ́ ẹ̀rí ayérayé.
\q1
\v 9 Àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn
\q2 àti ẹlẹ́tanu ọmọ,
\q1 àwọn ọmọ tí wọn kò ṣetán láti tẹ́tí sí
\q2 ìtọ́ni \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 10 Wọ́n sọ fún àwọn aríran pé,
\q2 “Ẹ má ṣe rí ìran mọ́!”
\q1 Àti fún àwọn wòlíì,
\q2 “Ẹ má ṣe fi ìran ohun tí ó tọ́ hàn wá mọ́!
\q1 Ẹ sọ ohun tí ó tura fún wa,
\q2 ẹ sàsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn.
\q1
\v 11 Ẹ fi ọ̀nà yìí sílẹ̀,
\q2 ẹ kúrò ní ọ̀nà yìí
\q1 ẹ dẹ́kun à ń dojú ìjà kọ wá
\q2 pẹ̀lú Ẹni Mímọ́ Israẹli!”
\p
\v 12 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ẹni Mímọ́ Israẹli wí:
\q1 “Nítorí pé ẹ ti kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀,
\q2 ẹ gbára lé ìnilára
\q2 kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé ẹ̀tàn,
\q1
\v 13 ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóò rí fún ọ
\q2 gẹ́gẹ́ bí ògiri gíga, tí ó sán tí ó sì fì
\q2 tí ó sì wó lójijì, àti ní ìṣẹ́jú kan.
\q1
\v 14 Yóò sì fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ bí àpáàdì
\q2 tí a fọ́ pátápátá
\q1 àti pé a kò ní rí ẹ̀rún kan nínú àfọ́kù rẹ̀,
\q2 fún mímú èédú kúrò nínú ààrò
\q2 tàbí gbígbọ́n omi jáde kúrò nínú àmù.”
\p
\v 15 Èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd* Olódùmarè, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli wí:
\q1 “Nínú ìrònúpìwàdà àti ìsinmi ni ìgbàlà rẹ wà,
\q2 ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé ni agbára rẹ wà,
\q2 ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò ní ọ̀kankan nínú wọn.
\q1
\v 16 Ẹ̀yin wí pé, Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò sálọ lórí ẹṣin.
\q2 Nítorí náà ẹ̀yin yóò sá!
\q1 Ẹ̀yin wí pé, Àwa yóò gun àwọn ẹṣin tí ó yára lọ.
\q2 Nítorí náà àwọn tí ń lé e yín yóò yára!
\q1
\v 17 Ẹgbẹ̀rún (1,000) yóò sá
\q2 nípa ìdẹ́rùbà ẹnìkan;
\q1 nípa ìdẹ́rùbà ẹni márùn-ún
\q2 gbogbo yín lẹ ó sálọ,
\q1 títí a ó fi yín sílẹ̀
\q2 àti gẹ́gẹ́ bí igi àsíá ní orí òkè,
\q2 gẹ́gẹ́ bí àsíá lórí òkè.”
\b
\q1
\v 18 Síbẹ̀síbẹ̀ \nd Olúwa\nd* sì fẹ́ síjú àánú wò ọ́;
\q2 ó dìde láti ṣàánú fún ọ.
\q1 Nítorí \nd Olúwa\nd* jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́.
\q2 Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó dúró dè é!
\p
\v 19 Ẹ̀yin ènìyàn Sioni, tí ń gbé ní Jerusalẹmu, ìwọ kì yóò sọkún mọ́. Báwo ni àánú rẹ̀ yóò ti pọ̀ tó nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́! Bí ó bá ti gbọ́, òun yóò dá ọ lóhùn.
\v 20 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fún ọ ní àkàrà ìyà àti omi ìpọ́njú, àwọn olùkọ́ rẹ kì yóò fi ara sin mọ́; pẹ̀lú ojú rẹ ni ìwọ ó rí wọn.
\v 21 Bí o bá yí sápá ọ̀tún tàbí apá òsì, etí rẹ yóò máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn rẹ, wí pé, “Ọ̀nà nìyìí, máa rìn nínú rẹ̀.”
\v 22 Lẹ́yìn náà ni ẹ ó ba àwọn ère yín jẹ́ àwọn tí ẹ fi fàdákà bò àti àwọn ère tí ẹ fi wúrà bò pẹ̀lú, ẹ ó sọ wọ́n nù bí aṣọ tí obìnrin fi ṣe nǹkan oṣù ẹ ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kúrò níbí!”
\p
\v 23 Òun yóò sì rọ òjò fún un yín sí àwọn irúgbìn tí ẹ gbìn sórí ilẹ̀, oúnjẹ tí yóò ti ilẹ̀ náà wá yóò ní ọ̀rá yóò sì pọ̀. Ní ọjọ́ náà ni àwọn ẹran ọ̀sìn yín yóò máa jẹ koríko ní pápá oko tútù tí ó tẹ́jú.
\v 24 Àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ń tú ilẹ̀ yóò jẹ oúnjẹ àdídùn tí a fi àmúga àti ṣọ́bìrì fọ́nkálẹ̀.
\v 25 Ní ọjọ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò sọ ẹ̀mí wọn nù nígbà tí ilé ìṣọ́ yóò wó lulẹ̀, odò omi yóò sàn lórí òkè gíga àti lórí àwọn òkè kékeré.
\v 26 Òṣùpá yóò sì tàn bí oòrùn, àti ìtànṣán oòrùn yóò mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po méje, gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ odidi ọjọ́ méje, nígbà tí \nd Olúwa\nd* yóò di ojú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ tí yóò sì wo ọgbẹ́ tí ó ti dá sí wọn lára sàn.
\q1
\v 27 Kíyèsi i, orúkọ \nd Olúwa\nd* ti òkèèrè wá
\q2 pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti kurukuru
\q1 èéfín tí ó nípọn;
\q2 ètè rẹ̀ kún fún ìbínú
\q2 ahọ́n rẹ̀ sì jẹ́ iná ajónirun.
\q1
\v 28 Èémí rẹ̀ sì dàbí òjò alágbára,
\q2 tí ó rú sókè dé ọ̀run.
\q1 Ó jọ àwọn orílẹ̀-èdè nínú kọ̀ǹkọ̀sọ̀;
\q2 ó sì fi sí ìjánu ní àgbọ̀n àwọn ènìyàn
\q2 láti ṣì wọ́n lọ́nà.
\q1
\v 29 Ẹ̀yin ó sì kọrin
\q2 gẹ́gẹ́ bí i ti alẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe àjọyọ̀ àpéjọ mímọ́,
\q1 ọkàn yín yóò yọ̀
\q2 gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àwọn ènìyàn gòkè lọ pẹ̀lú fèrè
\q1 sí orí òkè \nd Olúwa\nd*,
\q2 àní sí àpáta Israẹli.
\q1
\v 30 \nd Olúwa\nd* yóò jẹ́ kí wọn ó gbọ́ ohùn ògo rẹ̀
\q2 yóò sì jẹ́ kí wọ́n rí apá rẹ̀ tí ó ń bọ̀ wálẹ̀
\q1 pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti iná ajónirun,
\q2 pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná, àrá àti yìnyín.
\q1
\v 31 Ohùn \nd Olúwa\nd* yóò fọ́ Asiria túútúú,
\q2 pẹ̀lú ọ̀pá aládé rẹ̀ ni yóò lù wọ́n bolẹ̀.
\q1
\v 32 Ẹgba kọ̀ọ̀kan tí \nd Olúwa\nd* bá gbé lé wọn
\q2 pẹ̀lú ọ̀pá ìjẹníyà rẹ̀
\q1 yóò jẹ́ ti ṣaworo àti ti dùùrù,
\q2 gẹ́gẹ́ bí ó ti ń bá wọn jà lójú ogun
\q2 pẹ̀lú ìkùùkuu láti apá rẹ̀.
\q1
\v 33 A ti tọ́jú Tofeti sílẹ̀ tipẹ́tipẹ́,
\q2 a ti tọ́jú rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba.
\q1 Ojú ààrò rẹ̀ ni a ti gbẹ́ jì tí ó sì fẹ̀,
\q2 pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ iná àti igi ìdáná;
\q1 èémí \nd Olúwa\nd*,
\q2 gẹ́gẹ́ bí ìṣàn sulfuru ń jó ṣe mú un gbiná.
\c 31
\s1 Ègbé ni fún àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé Ejibiti
\q1
\v 1 Ègbé ni fún àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí
\q2 Ejibiti fún ìrànlọ́wọ́,
\q1 tí wọn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin
\q2 tí wọ́n fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́-ẹṣin wọn
\q1 àti agbára ńlá àwọn ẹlẹ́ṣin wọn,
\q2 ṣùgbọ́n tiwọn kò bojú wo Ẹni Mímọ́ Israẹli n nì,
\q2 tàbí kí wọn wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 2 Síbẹ̀síbẹ̀ òun pẹ̀lú jẹ́ ọlọ́gbọ́n ó sì lè mú ìparun wá;
\q2 òun kì í kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ.
\q1 Òun yóò dìde sí ilé àwọn ìkà,
\q2 àti sí àwọn tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún aṣebi.
\q1
\v 3 Ṣùgbọ́n ènìyàn lásán ni àwọn ará Ejibiti
\q2 wọn kì í ṣe Ọlọ́run;
\q1 ẹran-ara ni àwọn ẹṣin wọn, kì í ṣe ẹ̀mí.
\q2 Nígbà tí \nd Olúwa\nd* bá na ọwọ́ rẹ̀ jáde,
\q1 ẹni náà tí ó ń ṣèrànwọ́ yóò kọsẹ̀,
\q2 ẹni náà tí à ń ràn lọ́wọ́ yóò ṣubú;
\q2 àwọn méjèèjì yóò sì jùmọ̀ parun.
\p
\v 4 Èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd* sọ fún mi:
\q1 “Gẹ́gẹ́ bí i kìnnìún ti í ké
\q2 àní kìnnìún ńlá lórí ẹran ọdẹ rẹ̀
\q1 bí a tilẹ̀ rí ẹgbẹ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn
\q2 tí a sì pè wọ́n papọ̀ láti kojú rẹ̀,
\q1 ẹ̀rù kò lè bà á pẹ̀lú igbe wọn
\q2 akitiyan wọn kò sì lè dí i lọ́wọ́
\q1 bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun yóò sọ̀kalẹ̀ wá
\q2 láti jagun lórí òkè Sioni àti lórí ibi gíga rẹ̀.
\q1
\v 5 Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹyẹ ti ń rábàbà lókè
\q2 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bo Jerusalẹmu,
\q1 Òun yóò dáàbò bò ó, yóò sì tú u sílẹ̀
\q2 Òun yóò ré e kọjá yóò sì gbà á sílẹ̀.”
\p
\v 6 Ẹ padà sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣọ̀tẹ̀ sí gidigidi, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.
\q1
\v 7 Nítorí ní ọjọ́ náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò kọ àwọn ère fàdákà àti wúrà tí ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín ti ṣe.
\q1
\v 8 “Asiria yóò ṣubú lọ́wọ́ idà kan tí kò ti ọwọ́ ènìyàn wá;
\q2 idà tí kì í ṣe ti ẹ̀dá alààyè ni yóò pa wọ́n.
\q1 Wọn yóò sì sá níwájú idà náà
\q2 àti àwọn ọmọkùnrin wọn ni a ó fún ní iṣẹ́ ipá ṣe.
\q1
\v 9 Àpáta rẹ yóò kọjá lọ fún ẹ̀rù;
\q2 àwọn olórí rẹ yóò bẹ̀rù asia náà,”
\q2 ni \nd Olúwa\nd* wí,
\q1 ẹni tí iná rẹ̀ ń bẹ ní Sioni,
\q2 ẹni tí ìléru rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu.
\c 32
\s1 Ìjọba òdodo náà
\q1
\v 1 Wò ó, ọba kan yóò jẹ nínú òdodo
\q2 àwọn olórí yóò máa fi ìdájọ́ ṣe àkóso.
\q1
\v 2 Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò jẹ́ bí ibi ìṣápamọ́ kúrò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́
\q2 àti ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì,
\q1 gẹ́gẹ́ bí odò omi ní ilẹ̀ aṣálẹ̀,
\q2 àti bí òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ gbígbẹ.
\b
\q1
\v 3 Nígbà náà ni ojú àwọn tí ó rí kò ní padé mọ́,
\q2 àti etí àwọn tí ó gbọ́ yóò tẹ́tí sílẹ̀.
\q1
\v 4 Ọkàn àwọn oníwàdùwàdù ni yóò là tí yóò sì yè,
\q2 àti ahọ́n tí ń kólòlò ni yóò là geerege.
\q1
\v 5 A kò ní pe òmùgọ̀ ní ọlọ́lá mọ́
\q2 tàbí kí a fi ọ̀wọ̀ tí ó ga jù fún aláìlóòótọ́ ènìyàn.
\q1
\v 6 Nítorí òmùgọ̀ sọ̀rọ̀ òmùgọ̀,
\q2 ọkàn rẹ̀ kún fún ìwà ibi:
\q1 òun hùwà àìwà-bí-Ọlọ́run
\q2 ó sì ń tan àṣìṣe tí ó kan \nd Olúwa\nd* kalẹ̀;
\q1 ẹni ebi ń pa ló fi sílẹ̀ lófo
\q2 àti fún àwọn tí òǹgbẹ ń gbẹ
\q2 ni ó mú omi kúrò.
\q1
\v 7 Ibi ni gbogbo ọgbọ́n àwọn ìkà ènìyàn jẹ́,
\q2 ó ń gba èrò búburú
\q1 láti fi ọ̀rọ̀ èké pa tálákà run,
\q2 bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀bẹ̀ aláìní sì tọ̀nà.
\q1
\v 8 Ṣùgbọ́n ọlọ́lá ènìyàn a máa pète ohun ńlá
\q2 àti nípa èrò rere ni yóò dúró.
\s1 Àwọn obìnrin Jerusalẹmu
\q1
\v 9 Ẹ̀yin obìnrin tí ẹ ti gba ìtẹ́lọ́rùn gidi
\q2 ẹ dìde kí ẹ tẹ́tí sí mi,
\q1 ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ọkàn yín ti balẹ̀,
\q2 ẹ gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ!
\q1
\v 10 Ní ó lé díẹ̀ ní ọdún kan
\q2 ẹ̀yin tí ọkàn an yín balẹ̀ yóò wárìrì;
\q1 ìkórè àjàrà kò ní múnádóko,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ìkórè èso kò ní sí.
\q1
\v 11 Wárìrì, ẹ̀yin obìnrin onítẹ̀lọ́rùn;
\q2 bẹ̀rù, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ẹ rò pé ọkàn yín balẹ̀!
\q1 Ẹ bọ́ aṣọ yín kúrò,
\q2 ẹ ró aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ yín.
\q1
\v 12 Ẹ lu ọmú yín fún pápá ìgbádùn náà,
\q2 fún àwọn àjàrà eléso
\q1
\v 13 àti fún ilẹ̀ àwọn ènìyàn mi,
\q2 ilẹ̀ tí ó ti kún fún ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n,
\q1 bẹ́ẹ̀ ni, kẹ́dùn fún gbogbo ilé ìtura
\q2 àti fún ìlú àríyá yìí.
\q1
\v 14 Ilé olódi ni a ó kọ̀sílẹ̀,
\q2 ìlù aláriwo ni a ó kọ̀ tì;
\q1 ilé olódi àti ilé ìṣọ́ ni yóò di ihò títí láéláé,
\q2 ìdùnnú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti pápá
\q1 oko fún àwọn ẹran ọ̀sìn,
\q1
\v 15 títí a ó fi tú Ẹ̀mí sí wa lórí láti òkè wá,
\q2 àti ti aṣálẹ̀ tí yóò dí pápá oko ọlọ́ràá
\q2 àti tí pápá ọlọ́ràá yóò dàbí ẹgàn.
\q1
\v 16 Ẹ̀tọ́ yóò máa gbé ní inú aṣálẹ̀
\q2 àti òdodo yóò sì máa gbé ní pápá oko ọlọ́ràá.
\q1
\v 17 Èso òdodo náà yóò sì jẹ́ àlàáfíà;
\q2 àbájáde òdodo yóò sì jẹ́ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé títí láé.
\q1
\v 18 Àwọn ènìyàn mi yóò máa gbé ní ibùgbé àlàáfíà,
\q2 ní ibùgbé ìdánilójú,
\q2 ní àwọn ibi ìsinmi tí ó parọ́rọ́.
\q1
\v 19 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé yìnyín ti tẹ́jú igbó pẹrẹsẹ
\q2 àti tí ojú ìlú ti tẹ́ pẹrẹsẹ pátápátá,
\q1
\v 20 báwo ni ẹ ó ti jẹ́ alábùkún tó,
\q2 nípa gbígbin irúgbìn sí ipa odò gbogbo,
\q1 àti nípa jíjẹ́ kí àwọn màlúù yín àti
\q2 àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jẹ láìsí ìdíwọ́.
\c 33
\s1 Ìpọ́njú àti ìrànlọ́wọ́
\q1
\v 1 Ègbé ni fún ọ, ìwọ apanirun,
\q2 ìwọ tí a kò tí ì parun!
\q1 Ègbé ni fún ọ, ìwọ ọ̀dàlẹ̀,
\q2 ìwọ tí a kò tí ì dà ọ́!
\q1 Nígbà tí o bá dẹ́kun à ń pa ni run;
\q2 a ó pa ìwọ náà run,
\q1 nígbà tí o bá dẹ́kun à ń dani,
\q2 a ó da ìwọ náà.
\b
\q1
\v 2 \nd Olúwa\nd* ṣàánú fún wa
\q2 àwa ń ṣàfẹ́rí i rẹ.
\q1 Máa jẹ́ agbára wa ní òròòwúrọ̀
\q2 ìgbàlà wa ní àsìkò ìpọ́njú.
\q1
\v 3 Ní ìkérara ohùn rẹ, àwọn ènìyàn sá,
\q2 nígbà tí o dìde sókè, àwọn orílẹ̀-èdè fọ́nká.
\q1
\v 4 Ìkógun rẹ, ìwọ orílẹ̀-èdè ni a kórè
\q2 gẹ́gẹ́ bí i ti ọ̀dọ́ eṣú;
\q2 gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ eṣú, àwọn ènìyàn wọ ibẹ̀.
\b
\q1
\v 5 A gbé \nd Olúwa\nd* ga, nítorí pé ó ń gbé ibi gíga,
\q2 Òun yóò kún Sioni pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àti òdodo.
\q1
\v 6 Òun yóò jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún àkókò rẹ
\q2 ibùjókòó ìgbàlà kíkún àti ọgbọ́n òun ìmọ̀;
\q2 ìbẹ̀rù \nd Olúwa\nd* ni kọ́kọ́rọ́ sí ìṣúra yìí.
\b
\q1
\v 7 Wò ó, àwọn onígboyà ọkùnrin wọn pohùnréré
\q2 ẹkún ní òpópónà;
\q2 àwọn ikọ̀ àlàáfíà sọkún kíkorò.
\q1
\v 8 Àwọn ojú ọ̀nà ńlá ni a ṣá tì,
\q2 kò sí arìnrìn-àjò kankan ní ojú ọ̀nà.
\q1 A ti ba àdéhùn jẹ́,
\q2 a kẹ́gàn àwọn ẹlẹ́rìí,
\q2 a kò bu ọlá fún ẹnikẹ́ni.
\q1
\v 9 Ilẹ̀ ṣọ̀fọ̀ ó sì ṣòfò dànù,
\q2 ojú ti Lebanoni ó sì sá
\q1 Ṣaroni sì dàbí aginjù,
\q2 àti Baṣani òun Karmeli rẹ àwọn èwe wọn.
\b
\q1
\v 10 “Ní ìsinsin yìí ni èmi yóò dìde,” ni \nd Olúwa\nd* wí.
\q2 “Ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi ga,
\q2 ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi sókè.
\q1
\v 11 Ìwọ lóyún ìyàngbò,
\q2 o sì bí koríko;
\q2 èémí yín bí iná tí yóò jẹ yín run.
\q1
\v 12 A ó jó àwọn ènìyàn run bí eérú;
\q2 bí igbó ẹ̀gún tí a gé la ó dáná sí wọn.”
\b
\q1
\v 13 Ìwọ tí ó wà lọ́nà jíjìn, gbọ́ ohun tí mo ti ṣe;
\q2 ìwọ tí ò ń bẹ nítòsí, jẹ́rìí agbára mi!
\q1
\v 14 Ẹ̀rù ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní Sioni;
\q2 ìwárìrì bá àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́:
\q1 “Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná ajónirun?
\q2 Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná àìnípẹ̀kun?”
\q1
\v 15 Ẹni tí ó ń rìn lódodo
\q2 tí ó ń sọ ohun tí ó tọ́,
\q1 tí ó kọ èrè tí ó ti ibi ìlọ́nilọ́wọ́gbà wá,
\q2 tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,
\q1 tí ó di etí rẹ̀ sí ọ̀tẹ̀ láti pànìyàn
\q2 tí ó sì di ojú rẹ̀ sí à ti pète ibi,
\q1
\v 16 Òun náà yóò gbé ní ibi gíga,
\q2 ibi ààbò rẹ̀ yóò jẹ́ òkè ńlá olódi.
\q1 A ó mú oúnjẹ fún un,
\q2 omi rẹ̀ yóò sì dájú.
\b
\q1
\v 17 Ojú rẹ yóò rí ọba nínú ẹwà rẹ̀
\q2 yóò sì rí ilẹ̀ kan tí ó tẹ́ lọ rẹrẹẹrẹ.
\q1
\v 18 Nínú èrò rẹ ìwọ yóò rántí ẹ̀rù rẹ àtẹ̀yìnwá:
\q2 “Níbo ni ọ̀gá àgbà náà wà?
\q1 Níbo ni ẹni tí ń gba owó òde wà?
\q2 Níbo ni òṣìṣẹ́ ti ó ń mójútó ilé ìṣọ́ wà?”
\q1
\v 19 Ìwọ kì yóò rí àwọn agbéraga ènìyàn mọ́,
\q2 àwọn ènìyàn tí èdè wọn fi ara sin,
\q2 pẹ̀lú ahọ́n tí ó ṣàjèjì tí kò sì yé ni.
\b
\q1
\v 20 Gbójú sókè sí Sioni, ìlú àjọ̀dún wa,
\q2 ojú rẹ yóò rí Jerusalẹmu,
\q1 ibùgbé àlàáfíà n nì, àgọ́ tí a kò ní yí padà;
\q2 àwọn òpó rẹ̀ ni a kì yóò fàtu
\q2 tàbí èyíkéyìí nínú okùn rẹ̀ kí já.
\q1
\v 21 Níbẹ̀ ni \nd Olúwa\nd* yóò ti jẹ́ alágbára kan fún wa.
\q2 Yóò sì dàbí ibi àwọn odò ńlá ńlá àti odò kéékèèké.
\q1 Kì yóò sí ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú tí yóò kọjá lórí i wọn,
\q2 ọkọ̀ ojú omi ńlá ni a kì yóò tù lórí wọn.
\q1
\v 22 Nítorí \nd Olúwa\nd* ni onídàájọ́ wa,
\q2 \nd Olúwa\nd* ni onídàájọ́ wa,
\q1 \nd Olúwa\nd* òun ni ọba wa;
\q2 òun ni ẹni tí yóò gbà wá là.
\b
\q1
\v 23 Gbogbo okùn rẹ ni ó ti dẹ̀:
\q2 Ìgbókùnró kò fìdímúlẹ̀,
\q1 wọn kò taṣọ agbọ́kọ̀rìn,
\q2 lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkógun ni a ó pín
\q2 àní arọ pẹ̀lú yóò ru ìkógun lọ.
\q1
\v 24 Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ń gbé Sioni tí yóò wí pé, “Ara mi kò yá,”
\q2 a ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn tí ń gbé ibẹ̀ jì wọ́n.
\c 34
\s1 Ìdájọ́ Ọlọ́run lòdì sí àwọn orílẹ̀-èdè
\q1
\v 1 \x - \xo 34.1-17: \xt Isa 63.1-6; Jr 49.7-22; El 25.12-14; 35; Am 1.11-12; Od 1-14; Ml 1.2-5.\x*Súnmọ́ tòsí,
\q2 ẹ̀yin orílẹ̀-èdè láti gbọ́,
\q1 tẹ́tí sílẹ̀ ẹ̀yin ènìyàn
\q2 jẹ́ kí ayé gbọ́,
\q1 àti ẹ̀kún rẹ̀,
\q2 ayé àti ohun gbogbo tí ó ti inú rẹ̀ jáde.
\q1
\v 2 Nítorí ìbínú \nd Olúwa\nd* ń bẹ
\q2 lára gbogbo orílẹ̀-èdè,
\q1 àti ìrunú rẹ̀ lórí gbogbo ogun wọn:
\q2 o ti fi wọ́n fún pípa.
\q1
\v 3 Àwọn ti a pa nínú wọn
\q2 ni a ó sì jù sóde,
\q1 òórùn wọn yóò ti inú òkú wọn jáde,
\q2 àwọn òkè ńlá yóò sì yọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ wọn.
\q1
\v 4 \x - \xo 34.4: \xt If 6.13-14.\x*Gbogbo àwọn ogun ọ̀run ni yóò di yíyọ́,
\q2 a ó sì ká àwọn ọ̀run jọ bí i tákàdá,
\q1 gbogbo ogun wọn yóò si ṣubú lulẹ̀,
\q2 bí ewé ti n bọ́ kúrò lára àjàrà,
\q2 àti bí i bíbọ́ èso lára igi ọ̀pọ̀tọ́.
\b
\q1
\v 5 Nítorí ti a rẹ idà mi ní ọ̀run,
\q2 kíyèsi í, yóò sọ̀kalẹ̀ wá sórí Edomu,
\q2 sórí àwọn ènìyàn tí mo ti parun fún ìdájọ́.
\q1
\v 6 Idà \nd Olúwa\nd* kún fún ẹ̀jẹ̀
\q2 a mú un sanra fún ọ̀rá,
\q1 àti fún ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-àgùntàn àti ewúrẹ́,
\q2 fún ọ̀rá ìwé àgbò—
\q1 nítorí \nd Olúwa\nd* ni ìrúbọ kan ní Bosra,
\q2 àti ìpakúpa ńlá kan ní ilẹ̀ Edomu.
\q1
\v 7 Àti àwọn àgbáǹréré yóò
\q2 ba wọn sọ̀kalẹ̀ wá,
\q1 àti àwọn ẹgbọrọ màlúù
\q2 pẹ̀lú àwọn akọ màlúù,
\q1 ilé wọn ni a ó fi ẹ̀jẹ̀ rin,
\q2 a ó sì fi ọ̀rá sọ ekuru wọn di ọlọ́ràá.
\b
\q1
\v 8 Nítorí ọjọ́ ẹ̀san \nd Olúwa\nd* ni,
\q2 àti ọdún ìsanpadà,
\q2 nítorí ọ̀ràn Sioni.
\q1
\v 9 \x - \xo 34.9-10: \xt If 19.3.\x*Odò rẹ̀ ni a ó sì sọ di ọ̀dà,
\q2 àti eruku rẹ̀ di imí-ọjọ́,
\q2 ilẹ̀ rẹ̀ yóò sì di ọ̀dà tí ń jóná.
\q1
\v 10 A kì yóò pa á ní òru tàbí ní ọ̀sán;
\q2 èéfín rẹ̀ yóò gòkè láéláé:
\q1 yóò dahoro láti ìran dé ìran,
\q2 kò sí ẹnìkan tí yóò là á kọjá láé àti láéláé.
\q1
\v 11 Òwìwí aginjù, àti àkàlà ni yóò ni ín,
\q2 àti òwìwí àti ẹyẹ ìwò ni yóò máa gbé inú rẹ̀.
\q1 Ọlọ́run yóò sì na sórí Edomu
\q2 okùn ìwọ̀n ìparun
\q2 àti òkúta òfo.
\q1
\v 12 Ní ti àwọn ìjòyè rẹ̀
\q2 ẹnìkan kì yóò sí níbẹ̀
\q1 tiwọn ó pè wá sí ìjọba,
\q2 gbogbo àwọn olórí i rẹ̀ yóò sì di asán.
\q1
\v 13 Ẹ̀gún yóò sì hù jáde
\q2 nínú àwọn ààfin rẹ̀ wọ̀nyí,
\q1 ẹ̀gún ọ̀gán nínú ìlú olódi rẹ̀.
\q2 Yóò jẹ́ ibùgbé àwọn akátá
\q2 àti àgbàlá fún àwọn òwìwí.
\q1
\v 14 Àwọn ẹranko ijù àti àwọn ìkookò ni yóò pàdé,
\q1 àti ewúrẹ́ igbó kan yóò máa kọ sí èkejì rẹ̀,
\q2 iwin yóò máa gbé ibẹ̀ pẹ̀lú,
\q2 yóò sì rí ibi ìsinmi fún ara rẹ̀.
\q1
\v 15 Òwìwí yóò tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ síbẹ̀,
\q2 yóò yé, yóò sì pa,
\q1 yóò sì kójọ lábẹ́ òjìji rẹ̀:
\q2 àwọn gúnnugún yóò péjọ síbẹ̀ pẹ̀lú,
\q2 olúkúlùkù pẹ̀lú ẹnìkejì rẹ̀.
\p
\v 16 Ẹ wo ìwé \nd Olúwa\nd*, kí ẹ sì kà.
\q1 Ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí kì yóò yẹ̀,
\q2 kò sí ọ̀kan tí yóò fẹ́ èkejì rẹ̀ kù:
\q1 nítorí \nd Olúwa\nd* ti pàṣẹ
\q2 ẹnu rẹ̀ ló sì fi kó wọn jọ
\q2 Ẹ̀mí rẹ̀ ló sì fi tò wọ́n jọ.
\q1
\v 17 Ó ti di ìbò fún wọn,
\q2 ọwọ́ rẹ̀ sì ti pín in fún wọn
\q1 nípa títa okùn,
\q2 wọn ó jogún rẹ̀ láéláé,
\q1 láti ìran dé ìran
\q2 ni wọn ó máa gbé inú rẹ̀.
\c 35
\s1 Ayọ̀ àwọn ẹni ìràpadà
\q1
\v 1 Aginjù àti ìyàngbẹ ilẹ̀ yóò yọ̀ fún wọn;
\q2 aginjù yóò ṣe àjọyọ̀ yóò sì kún fún ìtànná.
\q2 Gẹ́gẹ́ bí ewéko,
\q1
\v 2 ní títanná yóò tanná;
\q2 yóò yọ ayọ̀ ńlá ńlá yóò sì kọrin.
\q1 Ògo Lebanoni ni a ó fi fún un,
\q2 ẹwà Karmeli àti Ṣaroni;
\q1 wọn yóò rí ògo \nd Olúwa\nd*,
\q2 àti ẹwà Ọlọ́run wa.
\b
\q1
\v 3 \x - \xo 35.3: \xt Hb 12.12.\x*Fún ọwọ́ àìlera lókun,
\q2 mú orúnkún tí ń yẹ̀ lókun.
\q1
\v 4 Sọ fún àwọn oníbẹ̀rù ọkàn pé,
\q2 “Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù;
\q1 Ọlọ́run yín yóò wá,
\q2 òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀san;
\q1 pẹ̀lú ìgbẹ̀san mímọ́
\q2 òun yóò wá láti gbà yín là.”
\b
\q1
\v 5 \x - \xo 35.5-6: \xt Mt 11.5; Lk 7.22.\x*Nígbà náà ni a ó la ojú àwọn afọ́jú
\q2 àti etí àwọn odi kì yóò dákẹ́.
\q1
\v 6 Nígbà náà ni àwọn arọ yóò máa fò bí àgbọ̀nrín,
\q2 àti ahọ́n odi yóò ké fún ayọ̀.
\q1 Odò yóò tú jáde nínú aginjù
\q2 àti àwọn odò nínú aṣálẹ̀.
\q1
\v 7 Ilẹ̀ iyanrìn yíyan yóò di àbàtà,
\q2 ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ yóò di orísun omi.
\q1 Ní ibùgbé àwọn dragoni,
\q2 níbi tí olúkúlùkù dùbúlẹ̀,
\q2 ni ó jẹ́ ọgbà fún eèsún àti papirusi.
\b
\q1
\v 8 Àti òpópónà kan yóò wà níbẹ̀:
\q2 a ó sì máa pè é ní ọ̀nà ìwà mímọ́.
\q1 Àwọn aláìmọ́ kì yóò tọ ọ̀nà náà;
\q2 yóò sì wà fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà náà,
\q2 àwọn ìkà búburú kì yóò gba ibẹ̀ kọjá.
\q1
\v 9 Kì yóò sí kìnnìún níbẹ̀,
\q2 tàbí kí ẹranko búburú kí ó dìde lórí i rẹ̀;
\q1 a kì yóò rí wọn níbẹ̀.
\q2 Ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìràpadà nìkan ni yóò rìn níbẹ̀,
\q1
\v 10 àwọn ẹni ìràpadà \nd Olúwa\nd* yóò padà wá.
\q2 Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin;
\q1 ayọ̀ ayérayé ni yóò dé wọn ní orí.
\q2 Ìdùnnú àti ayọ̀ ni yóò borí i wọn,
\q2 ìkorò àti ìtìjú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.
\c 36
\s1 Sennakeribu dẹ́rùba Jerusalẹmu
\p
\v 1 \x - \xo 36.138.8,21-22: \xt 2Ọb 18.1320.11; 2Ki 32.1-24.\x*Ní ọdún kẹrìnlá ìjọba Hesekiah, Sennakeribu ọba Asiria kọlu gbogbo àwọn ìlú olódi ní ilẹ̀ Juda ó sì kó gbogbo wọn.
\v 2 Lẹ́yìn náà, ọba Asiria rán olórí ogun rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ-ogun láti Lakiṣi sí ọba Hesekiah ní Jerusalẹmu. Nígbà tí ọ̀gágun náà dúró níbi ojúṣàn adágún ti apá òkè, ní ojú ọ̀nà sí pápá alágbàfọ̀,
\v 3 Ṣebna Eliakimu ọmọ Hilkiah alábojútó ààfin, Ṣebna akọ̀wé, àti Joah ọmọ Asafu akọ̀wé jáde lọ pàdé rẹ̀.
\p
\v 4 Ọ̀gágun náà sọ fún wọn wí pé, “Ẹ sọ fún Hesekiah,
\pm “Èyí yìí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Asiria sọ pé: Lórí i kí ni ìwọ gbé ìgbẹ́kẹ̀lé tìrẹ yìí lé?
\v 5 Ìwọ sọ wí pé ìwọ ní ète àti agbára ogun—ṣùgbọ́n ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ asán. Ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tí ìwọ fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi?
\v 6 Wò ó nísinsin yìí, ìwọ gbẹ́kẹ̀lé Ejibiti ẹ̀rún igi ọ̀pá lásán tí í gún ni lọ́wọ́ tí í sì í dọ́gbẹ́ sí ni lára tí a bá gbára lé e! Bẹ́ẹ̀ ni Farao ọba Ejibiti sí àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé e.
\v 7 Bí o bá sì sọ fún mi pé, “Àwa gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa,” kì í ṣe òun ni Hesekiah ti mú àwọn ibi gíga àti pẹpẹ rẹ̀ kúrò, tí ó sì wí fún Juda àti Jerusalẹmu pé, “Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ yìí”?
\pm
\v 8 “ ‘Ẹ wá nísinsin yìí, bá ọ̀gá mi pa ìmọ̀ pọ̀, ọba Asiria, èmi yóò fún ọ ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹṣin bí ìwọ bá le è fi agẹṣin lé wọn lórí!
\v 9 Báwo ni ẹ ṣe lè lé ẹyọ kan ṣoṣo padà nínú èyí tí ó kéré jù nínú àwọn balógun olúwa mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé Ejibiti fún kẹ̀kẹ́-ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin?
\v 10 Síwájú sí i, ǹjẹ́ mo wa lè wá bá ilẹ̀ yìí jà kí n sì pa á run láìsí \nd Olúwa\nd*? \nd Olúwa\nd* fún rara rẹ̀ ló sọ pé kí n bá orílẹ̀-èdè yìí jà kí n sì pa á run.’ ”
\p
\v 11 Lẹ́yìn náà ni Eliakimu, Ṣebna àti Joah sọ fún ọ̀gágun náà pé, “Jọ̀wọ́ máa bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Aramaiki, nítorí pé àwa gbọ́ ọ. Má ṣe bá wa sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu ní etí àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ògiri mọ́.”
\p
\v 12 Ṣùgbọ́n aláṣẹ dáhùn pé, “Ṣé fún ọ̀gá rẹ àti ìwọ nìkan ní ọ̀gá mi rán mi sí láti sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí kì í sì í ṣe fún àwọn ọkùnrin tí ó jókòó lórí odi ni gẹ́gẹ́ bí ìwọ, ni yóò ní láti jẹ ìgbẹ́ ará wọn kí wọ́n sì mu ìtọ̀ ará wọn?”
\p
\v 13 Lẹ́yìn náà ni ọ̀gágun náà dìde tí ó sì ké síta ní èdè Heberu pé, “Ẹ gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Asiria!
\v 14 Ohun tí ọba wí nìyìí, Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah tàn yín jẹ. Òun kò le è gbà yín sílẹ̀!
\v 15 Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah rọ̀ yín láti gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd* nígbà tí ó sọ pé, \nd Olúwa\nd* yóò kúkú gbà wá; a kì yóò fi ìlú yìí lé ọba Asiria lọ́wọ́.
\p
\v 16 “Ẹ má ṣe tẹ́tí sí Hesekiah. Ohun tí ọba Asiria wí nìyìí. Ẹ fi ẹ̀bùn bá mi rẹ́, kí ẹ sì jáde tọ̀ mí wá. Lẹ́yìn náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò sì jẹ nínú àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni yóò sì mu omi nínú kànga rẹ̀,
\v 17 títí tí èmi yóò fi mú un yín lọ sí ilẹ̀ kan tí ó dàbí i tiyín, ilẹ̀ tí ó ní irúgbìn oníhóró àti wáìnì tuntun, ilẹ̀ tí ó ní àkàrà àti ọgbà àjàrà.
\p
\v 18 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah ṣì yín lọ́nà nígbà tí ó sọ wí pé, \nd Olúwa\nd* yóò gbà wá. Ǹjẹ́ ọlọ́run orílẹ̀-èdè kan ha ti gbà á kúrò lọ́wọ́ ọba Asiria bí?
\v 19 Níbo ni àwọn òrìṣà Hamati àti Arpadi ha wà? Níbo ni àwọn òrìṣà Sefarfaimi ha wà? Ǹjẹ́ wọn ti já Samaria gbà kúrò lọ́wọ́ mi bí?
\v 20 Èwo nínú àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ló ha ti dáàbò bo ilẹ̀ ẹ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi? Báwo ni \nd Olúwa\nd* ṣe wá le gba Jerusalẹmu kúrò lọ́wọ́ mi?”
\p
\v 21 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà dákẹ́ rọ́rọ́ wọn kò sì mú èsì kankan wá, nítorí ọba ti pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe dá a lóhùn.”
\p
\v 22 Lẹ́yìn náà ni Eliakimu ọmọ Hilkiah alákòóso ààfin, Ṣebna akọ̀wé àti Joah ọmọ Asafu akọ̀wé àkọsílẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekiah pẹ̀lú aṣọ wọn ní fífàya, wọ́n sì sọ ohun tí ọ̀gágun ti wí.
\c 37
\s1 A sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìdáǹdè Jerusalẹmu
\p
\v 1 Nígbà tí ọba Hesekiah gbọ́ èyí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara rẹ̀, ó sì wọ inú tẹmpili \nd Olúwa\nd* lọ.
\v 2 Òun sì rán Eliakimu alákòóso ààfin, Ṣebna akọ̀wé, àti aṣíwájú àwọn àlùfáà, gbogbo wọn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì Isaiah ọmọ Amosi.
\v 3 Wọ́n sọ fún un pé, “Báyìí ni Hesekiah wí, ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ ìbànújẹ́, ìbáwí àti ẹ̀gàn gẹ́gẹ́ bí ìgbà ìbí àwọn ọmọdé tí kò sì ṣí agbára láti bí wọn.
\v 4 Ó lè jẹ́ pé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀gágun ẹni tí ọ̀gá rẹ̀ ọba Asiria ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè ṣe ẹlẹ́yà, àti pé òun ni yóò bá a wí nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Nítorí náà gbàdúrà fún àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n sì wà láààyè.”
\p
\v 5 Nígbà tí àwọn ìjòyè ọba Hesekiah dé ọ̀dọ̀ Isaiah,
\v 6 Isaiah sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ fún ọ̀gá yín pé, Ohun tí \nd Olúwa\nd* sọ nìyìí. Má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba Asiria tí ó wà nínú ìdè ti fi sọ̀rọ̀-òdì sí mi.
\v 7 Tẹ́tí sílẹ̀! Èmi yóò fi ẹ̀mí kan sínú rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé bí o bá ti gbọ́ ìròyìn kan, òun yóò padà sí orílẹ̀-èdè rẹ̀, níbẹ̀ ni n ó sì ti jẹ́ kí wọn ké e lulẹ̀ pẹ̀lú idà.’ ”
\p
\v 8 Nígbà tí ọ̀gágun gbọ́ pé ọba Asiria ti fi Lakiṣi sílẹ̀, ó padà sẹ́yìn, ó sì bá ọba tí ń bá Libina jà.
\p
\v 9 Ní àkókò yìí Sennakeribu gbọ́ ìròyìn kan pé Tirakah ará Kuṣi ọba Ejibiti ń jáde bọ̀ wá bá òun jà. Nígbà tí ó gbọ́ èyí, ó rán oníṣẹ́ sí Hesekiah pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí,
\v 10 “Ẹ sọ fún Hesekiah ọba Juda pé: Má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tàn ọ́ jẹ nígbà tí ó sọ pé, A kì yóò jọ̀wọ́ Jerusalẹmu fún ọba Asiria.
\v 11 Dájúdájú, ìwọ ti gbọ́ ohun tí ọba Asiria ti ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó pa wọ́n run pátápátá. Ǹjẹ́ a ó ha dá ọ nídè bí?
\v 12 Ǹjẹ́ àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi parun ha gbà wọ́n sílẹ̀ bí àwọn òrìṣà Gosani, Harani, Reṣefu àti àwọn ènìyàn Edeni tí wọ́n wà ní Teli-Assari?
\v 13 Níbo ni ọba Hamati wà, ọba Arpadi, ọba ìlú Sefarfaimi tàbí Hena tàbí Iffa?”
\s1 Àdúrà Hesekiah
\p
\v 14 Hesekiah gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ ó sì kà á. Lẹ́yìn náà ni ó gòkè lọ sí tẹmpili \nd Olúwa\nd* ó sì tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú \nd Olúwa\nd*.
\v 15 Hesekiah sì gbàdúrà sí \nd Olúwa\nd*:
\v 16 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli, tí ó gúnwà láàrín àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run lórí i gbogbo ìjọba orílẹ̀ ayé. Ìwọ ti dá ọ̀run àti ayé.
\v 17 Tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ \nd Olúwa\nd*, kí o gbọ́, ya ojú rẹ, Ìwọ \nd Olúwa\nd*, kí o rí i; tẹ́tí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí Sennakeribu rán láti fi àbùkù kan Ọlọ́run alààyè.
\p
\v 18 “Òtítọ́ ni \nd Olúwa\nd* pé àwọn ọba Asiria ti sọ àwọn ènìyàn àti ilẹ̀ wọn di asán.
\v 19 Wọ́n ti da àwọn òrìṣà wọn sínú iná wọ́n sì ti pa wọ́n run, nítorí àwọn wọ̀nyí kì í ṣe ọlọ́run bí kò ṣe igi àti òkúta lásán, tí a ti ọwọ́ ènìyàn ṣe.
\v 20 Nísinsin yìí, ìwọ \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run wa, gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé yóò fi mọ̀ pé Ìwọ, Ìwọ nìkan, \nd Olúwa\nd* ni Ọlọ́run.”
\s1 Ìṣubú Sennakeribu
\p
\v 21 Lẹ́yìn náà Isaiah ọmọ Amosi rán iṣẹ́ kan sí Hesekiah: “Èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run Israẹli sọ pé, nítorí pé ìwọ ti gbàdúrà sí mi nípa Sennakeribu ọba Asiria,
\v 22 èyí ni ọ̀rọ̀ tí \nd Olúwa\nd* ti sọ nípa rẹ̀:
\q1 “Wúńdíá ọmọbìnrin Sioni
\q2 ti kẹ́gàn rẹ, ó sì ti fi ọ ṣe ẹlẹ́yà.
\q1 Ọmọbìnrin Jerusalẹmu
\q2 ti mi orí rẹ̀ bí ó ti ń sálọ.
\q1
\v 23 Ta ni ìwọ ti bú tí ìwọ sì ti sọ̀rọ̀-òdì sí?
\q2 Sí ta ní ìwọ ti gbé ohùn rẹ sókè
\q1 tí o sì gbé ojú rẹ sókè ní ìgbéraga?
\q2 Sí Ẹni Mímọ́ Israẹli!
\q1
\v 24 Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ,
\q2 ìwọ ti sọ̀rọ̀ búburú sí \nd Olúwa\nd*.
\q1 Tì wọ sì wí pé,
\q2 Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ mi
\q1 ni èmi sì fi dé orí àwọn òkè ńlá,
\q2 sí ibi gíga jùlọ Lebanoni.
\q1 Èmi a sì ké igi kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀,
\q2 àti ààyò igi firi rẹ̀.
\q1 Èmi ti dé ibi rẹ̀ tí ó ga jùlọ,
\q2 igbó rẹ̀ tí ó dára jùlọ.
\q1
\v 25 Èmi ti gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjì
\q2 mo sì mu omi ní ibẹ̀,
\q1 pẹ̀lú àtẹ́lẹsẹ̀ mi
\q2 Èmi ti gbẹ́ gbogbo omi àwọn odò Ejibiti.
\b
\q1
\v 26 “Ṣé o kò tí ì gbọ́?
\q2 Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti fìdí rẹ̀ mulẹ̀.
\q1 Láti ìgbà pípẹ́ ni mo ti ṣètò rẹ̀;
\q2 ní àkókò yìí ni mo mú wá sí ìmúṣẹ,
\q1 pé o ti sọ àwọn ìlú olódi di
\q2 àkójọpọ̀ àwọn òkúta.
\q1
\v 27 Àwọn ènìyàn, tí agbára ti wọ̀ lẹ́wù,
\q2 ni wọ́n banújẹ́ tí a sì dójútì.
\q1 Wọ́n dàbí ohun ọ̀gbìn nínú pápá,
\q2 gẹ́gẹ́ bí ọ̀jẹ̀lẹ̀ èhíhù tuntun,
\q1 gẹ́gẹ́ bí i koríko tí ó ń hù lórí òrùlé,
\q2 tí ó jóná kí ó tó dàgbàsókè.
\b
\q1
\v 28 “Ṣùgbọ́n mo mọ ibi tí o wà
\q2 àti ìgbà tí o wá tí o sì lọ
\q2 àti bí inú rẹ ṣe ru sí mi.
\q1
\v 29 Nítorí pé inú rẹ ru sí mi
\q2 àti nítorí pé orí kunkun rẹ ti
\q1 dé etí ìgbọ́ mi,
\q2 Èmi yóò fi ìwọ̀ mi sí ọ ní imú,
\q1 àti ìjẹ mi sí ọ lẹ́nu,
\q2 èmi yóò sì jẹ́ kí o padà
\q2 láti ọ̀nà tí o gbà wá.
\p
\v 30 “Èyí ni yóò ṣe àmì fún ọ, ìwọ Hesekiah:
\q1 “Ní ọdún yìí, ìwọ yóò jẹ ohun tí ó hù fúnra rẹ̀,
\q2 àti ní ọdún kejì ohun tí ó jáde láti ara rẹ.
\q1 Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, ẹ gbìn kí ẹ sì kórè,
\q2 ẹ gbin ọgbà àjàrà kí ẹ sì jẹ èso wọn.
\q1
\v 31 Lẹ́ẹ̀kan sí i, àṣẹ́kù láti ilé Juda
\q2 yóò ta gbòǹgbò nísàlẹ̀ yóò sì ṣo èso lókè.
\q1
\v 32 Nítorí láti Jerusalẹmu ni àwọn àṣẹ́kù yóò ti wá,
\q2 àti láti òkè Sioni ni ikọ̀ àwọn tí ó sálà.
\q2 Ìtara \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyí ṣẹ.
\p
\v 33 “Nítorí náà, èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd* wí nípa ọba Asiria,
\q1 “Òun kì yóò wọ ìlú yìí wá
\q2 tàbí ta ẹyọ ọfà kan níhìn-ín
\q1 Òun kì yóò wá síwájú rẹ pẹ̀lú asà
\q2 tàbí kí ó kó dágunró sílẹ̀ fún un.
\q1
\v 34 Nípa ọ̀nà tí ó gbà wá náà ni yóò padà lọ;
\q2 òun kì yóò wọ inú ìlú yìí,”
\q2 ni \nd Olúwa\nd* wí.
\q1
\v 35 “Èmi yóò dáàbò bo ìlú yìí èmi ó sì gbà á là,
\q2 nítorí mi àti nítorí Dafidi ìránṣẹ́ mi!”
\p
\v 36 Lẹ́yìn náà ni angẹli \nd Olúwa\nd* jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (185,000) ènìyàn ní i ibùdó àwọn Asiria. Nígbà tí àwọn ènìyàn yìí jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì gbogbo wọn ti dòkú!
\v 37 Nítorí náà Sennakeribu ọba Asiria fọ́ bùdó ó sì pẹsẹ̀dà. Òun sì padà sí Ninefe, ó sì dúró síbẹ̀.
\p
\v 38 Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń jọ́sìn nínú tẹmpili Nisroki òrìṣà rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ Adrameleki àti Ṣareseri gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n sì sálọ sí ilẹ̀ Ararati. Bẹ́ẹ̀ ni Esarhadoni ọmọ rẹ̀ sì gba ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
\c 38
\s1 Àìsàn Hesekiah
\p
\v 1 Ní ọjọ́ náà ni Hesekiah ṣe àìsàn dé ojú ikú. Wòlíì Isaiah ọmọ Amosi sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ohun tí \nd Olúwa\nd* wí nìyìí: Palẹ̀ ilé è rẹ mọ́, bí ó ti yẹ nítorí pé ìwọ yóò kú; ìwọ kì yóò dìde àìsàn yìí.”
\p
\v 2 Hesekiah yí ojú u rẹ̀ sí ara ògiri, ó sì gba àdúrà sí \nd Olúwa\nd*,
\v 3 “Rántí, Ìwọ \nd Olúwa\nd*, bí mo ti rìn pẹ̀lú òtítọ́ níwájú rẹ, àti bí mo ti fi ọkàn dídúró ṣinṣin ṣe ohun tí ó dára ní ojú ù rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Hesekiah sì sọkún kíkorò.
\p
\v 4 Lẹ́yìn náà ni ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* tọ Isaiah wá pé,
\v 5 “Lọ kí o sì sọ fún Hesekiah pé, Ohun tí \nd Olúwa\nd* wí nìyìí, Ọlọ́run Dafidi baba rẹ sọ pé, Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ, Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kún ọjọ́ ayé rẹ.
\v 6 Èmi yóò sì gba ìwọ àti ìlú yìí sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ọba Asiria. Èmi yóò sì dáàbò bo ìlú yìí.
\p
\v 7 “Èyí yìí ni àmì tí \nd Olúwa\nd* fún ọ láti fihàn wí pé \nd Olúwa\nd* yóò mú ìpinnu rẹ̀ ṣẹ.
\v 8 Èmi yóò mú òjìji oòrùn kí ó padà sẹ́yìn ní ìṣísẹ̀ mẹ́wàá nínú èyí tí ó fi sọ̀kalẹ̀ ní ibi àtẹ̀gùn ti Ahasi.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni oòrùn padà sẹ́yìn ní ìṣísẹ̀ mẹ́wàá sí ibi tí ó ti dé tẹ́lẹ̀.
\p
\v 9 Ìwé tí Hesekiah ọba Juda kọ lẹ́yìn àìsàn rẹ̀ nígbà tí ó ti gbádùn tán.
\q1
\v 10 Èmi wí pé, “Ní àárín gbùngbùn ọjọ́ ayé mi
\q2 èmi ó ha kọjá lọ ní ibodè ikú
\q2 kí a sì dùn mí ní àwọn ọdún mi tí ó ṣẹ́kù?”
\q1
\v 11 Èmi wí pé, “Èmi kì yóò lè tún rí \nd Olúwa\nd* mọ́,
\q2 àní \nd Olúwa\nd*, ní ilẹ̀ àwọn alààyè;
\q1 èmi kì yóò lè síjú wo ọmọ ènìyàn mọ́,
\q2 tàbí kí n wà pẹ̀lú àwọn tí ó sì ń
\q2 gbe orílẹ̀ ayé báyìí.
\q1
\v 12 Gẹ́gẹ́ bí àgọ́ olùṣọ́-àgùntàn,
\q2 ilé mi ni a ti wó lulẹ̀ tí a sì gbà kúrò lọ́wọ́ mi.
\q1 Gẹ́gẹ́ bí ahunṣọ mo ti ká ayé mi nílẹ̀,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni òun sì ti ké mi kúrò lára àṣà;
\q2 ọ̀sán àti òru ni ìwọ ṣe òpin mi.
\q1
\v 13 Èmi fi sùúrù dúró títí di àfẹ̀mọ́júmọ́,
\q2 ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí kìnnìún ó ti fọ́ gbogbo egungun mi;
\q2 ọ̀sán àti òru ni ìwọ fi ṣe òpin mi.
\q1
\v 14 Èmi dún gẹ́gẹ́ bí àkọ̀ tàbí alápáǹdẹ̀dẹ̀,
\q2 èmi káàánú gẹ́gẹ́ bí aṣọ̀fọ̀ àdàbà.
\q1 Ojú mi rẹ̀wẹ̀sì gẹ́gẹ́ bí mo ti ń wo àwọn ọ̀run.
\q1 Ìdààmú bá mi, Ìwọ \nd Olúwa\nd*, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi!”
\b
\q1
\v 15 Ṣùgbọ́n kí ni èmi lè sọ?
\q2 Òun ti bá mi sọ̀rọ̀ àti pé òun
\q1 tìkára rẹ̀ ló ti ṣe èyí.
\q2 Èmi yóò máa rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ mi
\q2 nítorí ìpọ́njú ẹ̀mí mi yìí.
\q1
\v 16 \nd Olúwa\nd*, nípa nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn ń gbé;
\q2 àti pé ẹ̀mí mi rí iyè nínú wọn pẹ̀lú.
\q1 Ìwọ dá ìlera mi padà
\q2 kí o sì jẹ́ kí n wà láààyè.
\q1
\v 17 Nítòótọ́ fún àlàáfíà ara mi ni,
\q2 ní ti pé mo ní ìkorò ńlá.
\q1 Nínú ìfẹ́ rẹ ìwọ pa mí mọ́,
\q2 kúrò nínú ọ̀gbun ìparun;
\q2 ìwọ sì ti fi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.
\q1
\v 18 Nítorí pé isà òkú kò le è yìn ọ́,
\q2 ipò òkú kò le è kọ orin ìyìn rẹ;
\q1 àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ sínú ọ̀gbun
\q2 kò lè ní ìrètí fún òtítọ́ rẹ.
\q1
\v 19 Alààyè, àwọn alààyè wọ́n ń yìn ọ́,
\q2 gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń ṣe lónìí;
\q2 àwọn baba sọ fún àwọn ọmọ wọn nípa òtítọ́ rẹ.
\b
\q1
\v 20 \nd Olúwa\nd* yóò gbà mí là
\q2 bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò sì kọrin pẹ̀lú ohun èlò olókùn
\q1 ní gbogbo ọjọ́ ayé wa
\q2 nínú tẹmpili ti \nd Olúwa\nd*.
\p
\v 21 Isaiah ti sọ pé, “Pèsè ìṣù ọ̀pọ̀tọ́ (ohun gbígbóná tí a dì mọ́ ojú egbò) kí o sì fi sí ojú oówo náà, òun yóò sì gbádùn.”
\p
\v 22 Hesekiah sì béèrè pé, “Kí ni yóò jẹ́ àmì pé èmi yóò gòkè lọ sí tẹmpili \nd Olúwa\nd*?”
\c 39
\s1 Àwọn ikọ̀ ọba láti Babeli
\p
\v 1 \x - \xo 39.1-8: \xt 2Ọb 20.12-19; 2Ki 32.31.\x*Ní àkókò náà ni Merodaki-Baladani ọmọ Baladani ọba Babeli fi ìwé àti ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Hesekiah, nítorí ó gbọ́ pé ó ṣàìsàn ó sì gbádùn.
\v 2 Hesekiah gba àwọn ikọ̀ yìí tayọ̀tayọ̀, ó sì fi àwọn nǹkan tí ó wà nínú yàrá ìkẹ́rù sí mọ́ hàn wọ́n—fàdákà, wúrà, ohun olóòórùn dídùn, òróró dídára, gbogbo nǹkan ogun rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìṣúra rẹ̀ kò sí ohunkóhun tí ó wà nínú ààfin rẹ̀ tàbí ní ìjọba rẹ̀ tí Hesekiah kò fihàn wọ́n.
\p
\v 3 Lẹ́yìn náà wòlíì Isaiah lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekiah ọba ó sì béèrè pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí, níbo ni wọ́n sì ti wá?”
\p “Láti ilẹ̀ jíjìnnà,” ni èsì Hesekiah. “Wọ́n wá sọ́dọ̀ mi láti Babeli.”
\p
\v 4 Wòlíì náà sì béèrè pé, “Kí ni wọ́n rí nínú ààfin rẹ?”
\p Hesekiah si dáhùn pe, “Wọ́n rí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin mi. Kò sí ohun kankan nínú ìṣúra mi tí èmi kò fihàn wọ́n.”
\p
\v 5 Lẹ́yìn náà ni Isaiah sọ fún Hesekiah pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun.
\v 6 Àsìkò ń bọ̀ nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin rẹ, àti ohun gbogbo tí àwọn baba rẹ ti kójọ títí di ọjọ́ òní yóò di kíkó lọ sí Babeli. Ohun kankan kò ní ṣẹ́kù ni \nd Olúwa\nd* wí.
\v 7 Àti díẹ̀ nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ, àwọn ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara rẹ tí a ó bí fún ọ ni a ó kó lọ, wọn yóò sì di ìwẹ̀fà nínú ààfin ọba Babeli.”
\p
\v 8 Hesekiah wí fún Isaiah pé, “Rere ni ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* tí ìwọ sọ.” Nítorí ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Àlàáfíà àti ààbò yóò wà ní ìgbà ayé tèmi.”
\c 40
\s1 Ìtùnú fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run
\q1
\v 1 Ẹ tù ú nínú, ẹ tu ènìyàn mi nínú,
\q2 ni Ọlọ́run yín wí.
\q1
\v 2 Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jerusalẹmu
\q2 kí o sì kéde fún un
\q1 pé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí,
\q2 pé à ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,
\q1 pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ \nd Olúwa\nd*
\q2 ìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
\b
\q1
\v 3 \x - \xo 40.3: \xt Mt 3.3; Mk 1.3; Lk 3.4; Jh 1.23.\x*Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù:
\q2 “Ẹ tún ọ̀nà \nd Olúwa\nd* ṣe,
\q2 ṣe òpópó tí ó tọ́ ní aginjù fún Ọlọ́run wa.
\q1
\v 4 \x - \xo 40.4-5: \xt Lk 3.5-6.\x*Gbogbo àfonífojì ni a ó gbé sókè,
\q2 gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀;
\q1 wíwọ́ ni a ó sọ di títọ́ àti
\q2 ọ̀nà pálapàla ni a óò sọ di títẹ́jú pẹrẹsẹ.
\q1
\v 5 Ògo \nd Olúwa\nd* yóò sì di mí mọ̀,
\q2 gbogbo ènìyàn lápapọ̀ ni yóò sì rí i.
\q2 Nítorí ẹnu \nd Olúwa\nd* ni ó ti sọ ọ́.”
\b
\q1
\v 6 \x - \xo 40.6-8: \xt 1Pt 1.24-25.\x*Ohùn kan wí pé, “Kígbe sókè.”
\q2 Èmi sì sọ pé, “Igbe kí ni èmi ó ké?”
\b
\q1 “Gbogbo ènìyàn dàbí i koríko,
\q2 àti gbogbo ògo wọn dàbí ìtànná igbó.
\q1
\v 7 Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,
\q2 nítorí èémí \nd Olúwa\nd* ń fẹ́ lù wọ́n.
\q2 Nítòótọ́ koríko ni àwọn ènìyàn.
\q1
\v 8 Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,
\q2 ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.”
\b
\q1
\v 9 \x - \xo 40.9: \xt Isa 52.7; Nh 1.15; Ap 10.36; Ro 10.15.\x*Ìwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Sioni,
\q2 lọ sí orí òkè gíga.
\q1 Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jerusalẹmu,
\q2 gbé ohùn rẹ sókè pẹ̀lú ariwo,
\q1 gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù;
\q2 sọ fún àwọn ìlú u Juda,
\q2 “Ọlọ́run rẹ nìyìí!”
\q1
\v 10 \x - \xo 40.10: \xt If 22.7,12.\x*Wò ó, \nd Olúwa\nd* Olódùmarè náà ń bọ̀ wá pẹ̀lú agbára,
\q2 apá rẹ̀ sì ń jẹ ọba fún un.
\q1 Wò ó, èrè rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀,
\q2 àti ìdápadà rẹ̀ tí ń bá a bọ̀ wá.
\q1
\v 11 Ó ń tọ́ àwọn agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn:
\q2 Ó kó àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ní apá rẹ̀.
\q1 Ó sì gbé wọn súnmọ́ oókan àyà rẹ̀;
\q2 ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ darí àwọn tí ó ní.
\b
\q1
\v 12 Ta ni ó tiwọn omi nínú kòtò ọwọ́ rẹ̀,
\q2 tàbí pẹ̀lú ìbú ọwọ́ rẹ̀
\q1 tí ó wọn àwọn ọ̀run?
\q2 Ta ni ó ti kó erùpẹ̀ ilẹ̀ ayé jọ nínú apẹ̀rẹ̀,
\q1 tàbí kí ó wọn àwọn òkè ńlá lórí ìwọ̀n
\q2 àti òkè kéékèèké nínú òsùwọ̀n?
\q1
\v 13 \x - \xo 40.13: \xt Ro 11.34; 1Kọ 2.16.\x*Ta ni ó ti mọ ọkàn \nd Olúwa\nd*,
\q2 tàbí tí ó ti tọ́ ọ ṣọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀?
\q1
\v 14 Ta ni \nd Olúwa\nd* ké sí kí ó là á lọ́yẹ
\q2 àti ta ni ó kọ́ òun ní ọ̀nà tí ó tọ́?
\q1 Ta ni ẹni náà tí ó kọ́ ọ ní ọgbọ́n
\q2 tàbí tí ó fi ipa ọ̀nà òye hàn án?
\b
\q1
\v 15 Nítòótọ́ àwọn orílẹ̀-èdè dàbí i ẹ̀kún omi nínú garawa;
\q2 a kà wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí eruku lórí ìwọ̀n;
\q2 ó wọn àwọn erékùṣù àfi bí eruku múnúmúnú ni wọ́n.
\q1
\v 16 Lebanoni kò tó fún pẹpẹ iná,
\q2 tàbí kí àwọn ẹranko rẹ̀ kí ó tó fún ẹbọ sísun.
\q1
\v 17 Níwájú rẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè dàbí ohun tí kò sí;
\q2 gbogbo wọn ló kà sí ohun tí kò wúlò
\q2 tí kò tó ohun tí kò sí.
\b
\q1
\v 18 Ta ni nígbà náà tí ìwọ yóò fi Ọlọ́run wé?
\q2 Ère wo ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé rẹ̀?
\q1
\v 19 Ní ti ère, oníṣọ̀nà ni ó dà á,
\q2 ti alágbẹ̀dẹ wúrà sì fi wúrà bò ó
\q2 tí a sì ṣe ẹ̀wọ̀n ọ̀nà sílífà fún un.
\q1
\v 20 Ọkùnrin kan tí ó tálákà jù kí ó lè mú
\q2 irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ wá,
\q1 wá igi tí kò le è rà.
\q2 Ó wá oníṣọ̀nà tí ó
\q2 láti ṣe àgbékalẹ̀ ère tí kì yóò le è ṣubú.
\b
\q1
\v 21 Ǹjẹ́ o kò tí ì mọ̀
\q2 ìwọ kò tí ì gbọ́?
\q1 A kò tí ì sọ fún ọ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá?
\q2 Ìwọ kò tí ì mọ láti ìgbà ìpìlẹ̀ ayé?
\q1
\v 22 Òun jókòó lórí ìtẹ́ ní òkè òbírí ilẹ̀ ayé,
\q2 àwọn ènìyàn rẹ̀ sì dàbí i láńtata.
\q1 Ó ta àwọn ọ̀run bí ìbòrí ìgúnwà,
\q2 ó sì nà wọ́n jáde gẹ́gẹ́ bí àgọ́ láti gbé.
\q1
\v 23 Ó sọ àwọn ọmọ ọba di asán
\q2 àti àwọn aláṣẹ ayé yìí ni ó ti sọ dòfo.
\q1
\v 24 Gẹ́rẹ́ tí a ti gbìn wọ́n,
\q2 kété tí a gbìn wọ́n,
\q1 kété tí wọ́n fi gbòǹgbò múlẹ̀,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ó fẹ́ atẹ́gùn lù wọ́n gbogbo wọn sì gbẹ,
\q2 bẹ́ ni ìjì líle sì gbá wọn lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò.
\b
\q1
\v 25 “Ta ni ẹ ó fi mi wé?
\q2 Tàbí ta ni ó bá mi dọ́gba?” ni Ẹni Mímọ́ wí.
\q1
\v 26 Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wo àwọn ọ̀run.
\q2 Ta ni ó dá àwọn wọ̀nyí?
\q1 Ẹni tí ó mú àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ jáde wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan
\q2 tí ó sì pè wọ́n ní orúkọ lọ́kọ̀ọ̀kan.
\q1 Nítorí agbára ńlá àti ipá rẹ̀,
\q2 ọ̀kan ṣoṣo nínú wọn kò sọnù.
\b
\q1
\v 27 Èéṣe tí o fi sọ, ìwọ Jakọbu?
\q2 Àti tí o ṣàròyé, ìwọ Israẹli,
\q1 “Ọ̀nà mi pamọ́ níwájú \nd Olúwa\nd*;
\q2 ìṣe mi ni a kò kọbi ara sí láti ọwọ́ Ọlọ́run mi”?
\q1
\v 28 Ìwọ kò tí ì mọ̀?
\q2 Ìwọ kò tí ì gbọ́?
\q1 \nd Olúwa\nd* òun ni Ọlọ́run ayérayé,
\q2 Ẹlẹ́dàá gbogbo ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé.
\q1 Agara kì yóò da bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣàárẹ̀,
\q2 àti òye rẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò le ṣe òdínwọ̀n rẹ̀.
\q1
\v 29 Ó ń fi agbára fún àwọn aláàárẹ̀
\q2 ó sì fi kún agbára àwọn tí agara dá.
\q1
\v 30 Àní, ó ń rẹ̀ wọ́n àwọn ọ̀dọ́, wọ́n ń rẹ̀wẹ̀sì,
\q2 àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì ń kọsẹ̀ wọ́n ṣubú;
\q1
\v 31 ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd*
\q2 yóò sọ agbára wọn di ọ̀tun.
\q1 Wọn yóò fìyẹ́ fò lókè bí idì;
\q2 wọn yóò sáré àárẹ̀ kò ní mú wọn,
\q2 wọn yóò rìn òòyì kò ní kọ́ wọn.
\c 41
\s1 Olùrànlọ́wọ́ fún Israẹli
\q1
\v 1 “Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú mi ẹ̀yin erékùṣù!
\q2 Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè tún agbára wọn ṣe!
\q1 Jẹ́ kí wọn wá síwájú kí wọn sọ̀rọ̀,
\q2 jẹ́ kí a pàdé pọ̀ ní ibi ìdájọ́.
\b
\q1
\v 2 “Ta ni ó ti ru ẹnìkan sókè láti ìlà-oòrùn wá,
\q2 tí ó pè é ní olódodo sí iṣẹ́ tirẹ̀?
\q1 Ó gbé àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́
\q2 ó sì ṣẹ́gun àwọn ọba níwájú rẹ̀.
\q1 Ó sọ wọ́n di erùpẹ̀ pẹ̀lú idà rẹ̀,
\q2 láti kù ú ní ìyàngbò pẹ̀lú ọrun rẹ̀.
\q1
\v 3 Ó ń lépa wọn ó sì ń kọjá ní àlàáfíà,
\q2 ní ojú ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò rìn rí.
\q1
\v 4 Ta ni ó ti ṣe èyí tí ó sì ti jẹ́ kí ó wáyé,
\q2 tí ó ti pe ìran-ìran láti àtètèkọ́ṣe?
\q1 Èmi \nd Olúwa\nd* pẹ̀lú ẹni kìn-ín-ní wọn
\q2 àti ẹni tí ó gbẹ̀yìn, Èmi náà ni.”
\b
\q1
\v 5 Àwọn erékùṣù ti rí i wọ́n bẹ̀rù;
\q2 ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé wárìrì.
\q1 Wọ́n súnmọ́ tòsí wọ́n sì wá síwájú;
\q2
\v 6 èkínní ran èkejì lọ́wọ́
\q2 ó sì sọ fún arákùnrin rẹ̀ pé, “Jẹ́ alágbára!”
\q1
\v 7 Oníṣọ̀nà gba alágbẹ̀dẹ wúrà níyànjú,
\q2 àti ẹni tí ó fi òòlù dán
\q2 mú òun lọ́kàn le, àní ẹni tí ó ń lu owú.
\q1 Ó sọ nípa àjópọ̀ náà pé, “Ó dára.”
\q2 Ó fi ìṣó kan ère náà mọ́lẹ̀ kí ó má ba à wó lulẹ̀.
\b
\q1
\v 8 \x - \xo 41.8: \xt Jk 2.23.\x*\x - \xo 41.8-9: \xt Lk 1.54; Hb 2.16.\x*“Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ Israẹli, ìránṣẹ́ mi,
\q2 Jakọbu, ẹni tí mo ti yàn,
\q2 ẹ̀yin ìran Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi,
\q1
\v 9 mo mú ọ láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé,
\q2 láti kọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó jìnnà jùlọ ni mo ti pè ọ́.
\q1 Èmi wí pé, Ìwọ ni ìránṣẹ́ mi;
\q2 Èmi ti yàn ọ́ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì tí ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
\q1
\v 10 \x - \xo 41.10: \xt Ap 18.10.\x*Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ;
\q2 má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ.
\q1 Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́.
\q2 Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi.
\b
\q1
\v 11 “Gbogbo àwọn tí ó bínú sí ọ
\q2 ni ojú yóò tì, tí wọn yóò sì di ẹlẹ́yà;
\q1 àwọn tó ń bá ọ jà
\q2 yóò dàbí asán, wọn yóò ṣègbé.
\q1
\v 12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yóò wá àwọn ọ̀tá rẹ,
\q2 ìwọ kì yóò rí wọn.
\q1 Gbogbo àwọn tí ó gbóguntì ọ́
\q2 yóò dàbí ohun tí kò sí.
\q1
\v 13 Nítorí Èmi ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ,
\q2 tí ó di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú
\q1 tí ó sì sọ fún ọ pé, má ṣe bẹ̀rù;
\q2 Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.
\q1
\v 14 Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu kòkòrò,
\q2 ìwọ Israẹli kékeré,
\q1 nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,”
\q2 ni \nd Olúwa\nd* wí,
\q2 olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.
\q1
\v 15 “Kíyèsi, Èmi yóò sọ ọ́ di òòlù ìpakà tuntun,
\q2 tí ó mú ti eyín rẹ̀ mú, ìwọ yóò lu àwọn òkè ńlá,
\q1 ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú,
\q2 a ó sì sọ òkè kékeré di ìyàngbò.
\q1
\v 16 Ìwọ yóò fẹ́ wọn, afẹ́fẹ́ yóò sì gbá wọn mú,
\q2 àti ẹ̀fúùfù yóò sì fẹ́ wọn dànù.
\q1 Ṣùgbọ́n ìwọ yóò yọ̀ nínú \nd Olúwa\nd*
\q2 ìwọ yóò sì ṣògo nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.
\b
\q1
\v 17 “Àwọn tálákà àti aláìní wá omi,
\q2 ṣùgbọ́n kò sí;
\q1 ahọ́n wọn gbẹ fún òǹgbẹ.
\q2 Ṣùgbọ́n Èmi \nd Olúwa\nd* yóò dá wọn lóhùn;
\q2 Èmi, Ọlọ́run Israẹli, kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
\q1
\v 18 Èmi yóò mú kí odò kí ó sàn ní ibi gíga
\q1 àti orísun omi ní àárín àfonífojì.
\q2 Èmi yóò sọ aṣálẹ̀ di adágún omi,
\q2 àti ilẹ̀ tí ó gbẹ gidigidi di orísun omi.
\q1
\v 19 Èmi yóò fi sínú aṣálẹ̀
\q2 igi kedari àti kasia, maritili àti olifi.
\q1 Èmi yóò gbin junifa sí inú aginjù,
\q2 igi firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀
\q1
\v 20 tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn yóò fi rí i tí wọn yóò sì fi mọ̀,
\q2 kí wọn ṣàkíyèsí kí ó sì yé wọn,
\q1 pé ọwọ́ \nd Olúwa\nd* ni ó ti ṣe èyí,
\q2 àti pé, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ti dá èyí.
\b
\q1
\v 21 “Mú ẹjọ́ wá,” ni \nd Olúwa\nd* wí.
\q2 “Tẹ́ àwọn àwíjàre rẹ sílẹ̀,” ni ọba Jakọbu wí,
\q1
\v 22 “Mú àwọn ère òrìṣà rẹ wọlé láti sọ fún wa
\q2 ohun tí yóò ṣẹlẹ̀.
\q1 Sọ fún wa ohun tí àwọn nǹkan àtijọ́ jẹ́,
\q2 kí àwa lè ṣe àgbéyẹ̀wò wọn
\q1 kí àwa sì mọ àbájáde wọn ní ìparí.
\q2 Tàbí kí o sọ fún wa ohun tí ó ń bọ̀ wá,
\q1
\v 23 ẹ sọ fún wa ohun ti ọjọ́ iwájú mú dání
\q2 kí àwa kí ó lè mọ̀ pé ọlọ́run ni yín.
\q1 Ẹ ṣe nǹkan kan, ìbá à ṣe rere tàbí búburú,
\q2 tó bẹ́ẹ̀ tí àyà yóò fi fò wá tí ẹ̀rù yóò sì fi kún inú wa.
\q1
\v 24 Ṣùgbọ́n ẹ̀yìn ko jásí nǹkan kan
\q2 iṣẹ́ yín ni kò sì wúlò fún ohunkóhun;
\q2 ẹni tí ó yàn yín jẹ́ ẹni ìríra.
\b
\q1
\v 25 “Èmi ti ru ẹnìkan sókè láti àríwá, òun sì ń bọ
\q2 ẹnìkan láti ìlà-oòrùn tí ó pe orúkọ mi.
\q1 Òun gun àwọn aláṣẹ mọ́lẹ̀ bí ẹni pé odò ni wọ́n,
\q2 àfi bí ẹni pé amọ̀kòkò nì ti ń gún amọ̀.
\q1
\v 26 Ta ni ó sọ èyí láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, tí àwa kò bá fi mọ̀,
\q2 tàbí ṣáájú àkókò, tí àwa kò bá fi wí pé, Òun sọ òtítọ́?
\q1 Ẹnikẹ́ni kò sọ nípa èyí,
\q2 ẹnikẹ́ni kò sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀,
\q2 ẹnikẹ́ni kò gbọ́ ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.
\q1
\v 27 Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó sọ fún Sioni pé, Wò ó, àwọn nìyìí!
\q2 Mo fún Jerusalẹmu ní ìránṣẹ́ ìrò ìròyìn ayọ̀ kan.
\q1
\v 28 Èmi wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan—
\q2 kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó lè mú ìmọ̀ràn wá,
\q2 kò sí ẹnìkan tí ó lè dáhùn nígbà tí mo bi wọ́n.
\q1
\v 29 Kíyèsi i, irọ́ ni gbogbo wọn!
\q2 Gbogbo ìṣe wọn jásí asán;
\q2 àwọn ère wọn kò ṣé kò yà fún afẹ́fẹ́ àti dàrúdàpọ̀.
\c 42
\s1 Ìránṣẹ́ \nd Olúwa\nd* náà
\q1
\v 1 \x - \xo 42.1-4: \xt Mt 12.18-21.\x*“Ìránṣẹ́ mi nìyìí, ẹni tí mo gbéró,
\q2 àyànfẹ́ mi nínú ẹni tí mo láyọ̀;
\q1 Èmi yóò fi Ẹ̀mí mi sínú rẹ̀
\q2 òun yóò sì mú ìdájọ́ wá sórí àwọn orílẹ̀-èdè.
\q1
\v 2 Òun kì yóò pariwo tàbí kígbe sókè,
\q2 tàbí kí ó gbóhùn rẹ̀ sókè ní òpópónà.
\q1
\v 3 Koríko odò títẹ̀ kan ni òun kì yóò fọ́,
\q2 àti òwú-fìtílà tí ń jó tan an lọ lòun kì yóò fẹ́ pa.
\q1 Ní òdodo ni yóò mú ìdájọ́ wá;
\q2
\v 4 òun kì yóò kọsẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ní rẹ̀wẹ̀sì
\q1 títí tí yóò fi fi ìdájọ́ múlẹ̀ ní ayé.
\q2 Nínú òfin rẹ̀ ni àwọn erékùṣù yóò fi ìrètí wọn sí.”
\b
\q1
\v 5 \x - \xo 42.5: \xt Ap 17.24-25.\x*Èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wí
\q2 Ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run tí ó sì tẹ́ wọ́n sóde,
\q1 tí ó tẹ́ ilẹ̀ ayé àti ohun gbogbo tí ó jáde nínú wọn,
\q2 Ẹni tí ó fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní èémí
\q2 àti ẹ̀mí fún gbogbo àwọn tí ń rìn nínú rẹ̀:
\q1
\v 6 \x - \xo 42.6: \xt Isa 49.6; Lk 2.32; Ap 13.47; 26.23.\x*“Èmi, \nd Olúwa\nd*, ti pè ọ́ ní òdodo,
\q2 Èmi yóò di ọwọ́ rẹ mú.
\q1 Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́
\q2 láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn
\q2 àti ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà
\q1
\v 7 \x - \xo 42.7,16: \xt Ap 26.18.\x*láti la àwọn ojú tí ó fọ́,
\q2 láti tú àwọn òǹdè kúrò nínú túbú
\q1 àti láti tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n
\q2 àwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn.
\b
\q1
\v 8 “Èmi ni \nd Olúwa\nd*; orúkọ mi nìyìí!
\q2 Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn
\q2 tàbí ìyìn mi fún ère òrìṣà.
\q1
\v 9 Kíyèsi i, àwọn nǹkan àtijọ́ ti wáyé,
\q2 àti àwọn nǹkan tuntun ni mo ti wí pé;
\q1 kí wọn tó hù jáde
\q2 mo ti kéde rẹ̀ fún ọ.”
\s1 Orin ìyìn sí \nd Olúwa\nd*
\q1
\v 10 Kọ orin tuntun sí \nd Olúwa\nd*
\q2 ìyìn rẹ̀ láti òpin ilẹ̀ ayé wá,
\q1 ẹ̀yin tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú Òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀,
\q2 ẹ̀yin erékùṣù, àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú wọn.
\q1
\v 11 Jẹ́ kí aginjù àti àwọn ìlú rẹ̀ kí ó gbé ohùn wọn sókè;
\q2 jẹ́ kí ibùdó ti àwọn ìlú Kedari ń gbé máa yọ̀.
\q1 Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Sela kọrin fún ayọ̀;
\q2 jẹ́ kí wọn pariwo láti orí òkè.
\q1
\v 12 Jẹ́ kí wọn fi ògo fún \nd Olúwa\nd*
\q2 àti kí wọn sì kéde ìyìn rẹ̀ ní erékùṣù.
\q1
\v 13 \nd Olúwa\nd* yóò rìn jáde gẹ́gẹ́ bí i ọkùnrin alágbára,
\q2 yóò ru owú sókè bí ológun;
\q1 yóò kígbe nítòótọ́, òun yóò ké igbe ogun,
\q2 òun yóò sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀.
\b
\q1
\v 14 “Fún ìgbà pípẹ́ ni mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́,
\q2 mo ti wà ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, mo sì kó ara ró.
\q1 Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí,
\q2 mo sọkún, mo sì ń mí hẹlẹ hẹlẹ.
\q1
\v 15 Èmi yóò sọ òkè ńlá àti kékeré di ahoro
\q2 tí n ó sì gbẹ gbogbo ewéko rẹ̀ dànù,
\q1 Èmi yóò sọ àwọn odò di erékùṣù
\q2 n ó sì gbẹ àwọn adágún.
\q1
\v 16 Èmi yóò tọ àwọn afọ́jú ní ọ̀nà tí wọn kò tí ì mọ̀,
\q2 ní ipa ọ̀nà tí ó ṣàjèjì sí wọn ni èmi yóò tọ́ wọn lọ;
\q1 Èmi yóò sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájú wọn
\q2 àti ibi pálapàla ni èmi ó sọ di kíkúnná.
\q1 Àwọn nǹkan tí máa ṣe nìyìí;
\q2 Èmi kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
\q1
\v 17 Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé òrìṣà,
\q2 tí wọ́n wí fún ère pé, Ẹ̀yin ni Ọlọ́run wa,
\q2 ni a ó dá padà pẹ̀lú ìtìjú.
\s1 Israẹli fọ́jú ó dití
\q1
\v 18 “Gbọ́, ìwọ adití,
\q2 wò ó, ìwọ afọ́jú, o sì rí!
\q1
\v 19 Ta ló fọ́jú bí kò ṣe ìránṣẹ́ mi,
\q2 àti odi gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ tí mo rán?
\q1 Ta ni ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a fi jìnmí,
\q2 ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ \nd Olúwa\nd*?
\q1
\v 20 Ẹ̀yin ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan, ṣùgbọ́n ẹ kò ṣe àkíyèsí;
\q2 etí yín yà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́ nǹkan kan.”
\q1
\v 21 Ó dùn mọ́ \nd Olúwa\nd*
\q2 nítorí òdodo rẹ̀
\q2 láti mú òfin rẹ lágbára àti ògo.
\q1
\v 22 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kan nìyìí tí a jà lógun
\q2 tí a sì kó lẹ́rú,
\q1 gbogbo wọn ni ó wà nínú ọ̀gbun,
\q2 tàbí tí a fi pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n.
\q1 Wọ́n ti di ìkógun,
\q2 láìsí ẹnìkan tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀;
\q1 wọ́n ti di ìkógun,
\q2 láìsí ẹni tí yóò sọ pé, “Dá wọn padà.”
\b
\q1
\v 23 Ta ni nínú yín tí yóò tẹ́tí sí èyí
\q2 tàbí kí ó ṣe àkíyèsí gidi ní àsìkò tí ó ń bọ̀?
\q1
\v 24 Ta ni ó fi Jakọbu lélẹ̀ fún ìkógun,
\q2 àti Israẹli sílẹ̀ fún onísùnmọ̀mí?
\q1 Kì í ha ṣe \nd Olúwa\nd* ni,
\q2 ẹni tí àwa ti ṣẹ̀ sí?
\q1 Nítorí pé wọn kò ní tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀;
\q2 wọn kò mú òfin rẹ̀ ṣẹ.
\q1
\v 25 Nítorí náà ni ó ṣe rọ̀jò ìbínú un rẹ̀ lé wọn lórí,
\q2 rògbòdìyàn ogun.
\q1 Èyí tí ó fi ahọ́n iná yí wọn po, síbẹ̀ èdè kò yé wọn;
\q2 ó jó wọn run, síbẹ̀ wọn kò fi sọ́kàn wọn rárá.
\c 43
\s1 Olùgbàlà Israẹli kan ṣoṣo
\q1
\v 1 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, ohun tí \nd Olúwa\nd* wí nìyìí,
\q2 ẹni tí ó dá ọ, ìwọ Jakọbu,
\q2 ẹni tí ó mọ ọ́, ìwọ Israẹli:
\q1 “Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè;
\q2 Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ; tèmi ni ìwọ ṣe.
\q1
\v 2 Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá,
\q2 Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ;
\q1 àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá
\q2 wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀.
\q1 Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá,
\q2 kò ní jó ọ;
\q2 ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.
\q1
\v 3 Nítorí Èmi ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ,
\q2 Ẹni Mímọ́ Israẹli Olùgbàlà rẹ;
\q1 Èmi fi Ejibiti ṣe ìràpadà rẹ,
\q2 Kuṣi àti Seba dípò rẹ.
\q1
\v 4 Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi,
\q2 àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ,
\q1 Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ,
\q2 àti ènìyàn dípò ẹ̀mí rẹ.
\q1
\v 5 Má bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ;
\q2 Èmi yóò mú àwọn ọmọ rẹ láti ìlà-oòrùn wá
\q2 èmi ó sì kó ọ jọ láti ìwọ̀-oòrùn.
\q1
\v 6 Èmi yóò sọ fún àríwá pé, Fi wọ́n sílẹ̀!
\q2 Àti fún gúúsù, Má ṣe dá wọn dúró.
\q1 Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jíjìn wá
\q2 àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé—
\q1
\v 7 ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́,
\q2 tí mo dá fún ògo mi,
\q2 tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe.”
\b
\q1
\v 8 Sin àwọn tí ó ní ojú ṣùgbọ́n tí wọ́n fọ́jú jáde,
\q2 tí wọ́n ní etí ṣùgbọ́n tí wọn dití.
\q1
\v 9 Gbogbo orílẹ̀-èdè kó ra wọn jọ
\q2 àwọn ènìyàn sì kó ra wọn papọ̀.
\q1 Ta ni nínú wọn tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí
\q2 tí ó sì kéde fún wa àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀?
\q1 Jẹ́ kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn wọlé wá
\q2 láti fihàn pé wọ́n tọ̀nà
\q1 tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn mìíràn yóò gbọ́,
\q2 tí wọn yóò sọ pé, “Òtítọ́ ni.”
\q1
\v 10 “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni \nd Olúwa\nd* wí,
\q2 “Àti ìránṣẹ́ mi tí èmi ti yàn,
\q1 tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi mọ̀ àti tí ẹ̀yin ó fi gbà mí gbọ́
\q2 tí yóò sì yé e yín pé èmi ni ẹni náà.
\q1 Ṣáájú mi kò sí ọlọ́run tí a dá,
\q2 tàbí a ó wa rí òmíràn lẹ́yìn mi.
\q1
\v 11 Èmi, àní Èmi, Èmi ni \nd Olúwa\nd*,
\q2 yàtọ̀ sí èmi, kò sí olùgbàlà mìíràn.
\q1
\v 12 Èmi ti fihàn, mo gbàlà mo sì ti kéde
\q2 Èmi, kì í sì í ṣe àwọn àjèjì òrìṣà láàrín yín.
\q1 Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni \nd Olúwa\nd* wí, “Pé Èmi ni Ọlọ́run.
\q2
\v 13 Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà.
\q1 Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi.
\q2 Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà?”
\s1 Àánú Ọlọ́run àti àìṣòdodo Israẹli
\q1
\v 14 Èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd* wí,
\q2 olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli:
\q1 “Nítorí rẹ Èmi yóò ránṣẹ́ sí Babeli
\q2 láti mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá, gbogbo ará Babeli,
\q2 nínú ọkọ̀ ojú omi nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga.
\q1
\v 15 Èmi ni \nd Olúwa\nd*, Ẹni Mímọ́ rẹ,
\q2 Ẹlẹ́dàá Israẹli, ọba rẹ.”
\b
\q1
\v 16 Èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd* wí,
\q2 Ẹni náà tí ó la ọ̀nà nínú Òkun,
\q2 ipa ọ̀nà láàrín alagbalúgbú omi,
\q1
\v 17 ẹni tí ó wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jáde,
\q2 àwọn jagunjagun àti ohun ìjà papọ̀,
\q1 wọ́n sì sùn síbẹ̀, láìní lè dìde mọ́,
\q2 wọ́n kú pirá bí òwú-fìtílà:
\q1
\v 18 “Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá;
\q2 má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́.
\q1
\v 19 Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun!
\q2 Nísinsin yìí, ó ti yọ sókè; àbí o kò rí i bí?
\q1 Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀
\q2 àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá.
\q1
\v 20 Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi,
\q2 àwọn ajáko àti àwọn òwìwí,
\q1 nítorí pé mo pèsè omi nínú aṣálẹ̀
\q2 àti odò nínú ilẹ̀ sísá,
\q1 láti fi ohun mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi,
\q2
\v 21 àwọn ènìyàn tí mo dá fún ara mi
\q2 kí wọn kí ó lè kéde ìyìn mi.
\b
\q1
\v 22 “Síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ kò tí ì ké pè mí, ìwọ Jakọbu,
\q2 àárẹ̀ kò tí ì mú ọ nítorí mi ìwọ Israẹli.
\q1
\v 23 Ìwọ kò tí ì mú àgùntàn wá fún mi fún ẹbọ sísun,
\q2 tàbí kí o bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ẹbọ rẹ.
\q1 Èmi kò tí ì wàhálà rẹ pẹ̀lú ọrẹ ìyẹ̀fun
\q2 tàbí kí n dààmú rẹ pẹ̀lú ìbéèrè fún tùràrí.
\q1
\v 24 Ìwọ kò tí ì ra kalamusi olóòórùn dídùn fún mi,
\q2 tàbí kí o da ọ̀rá ẹbọ rẹ bò mí.
\q1 Ṣùgbọ́n ẹ ti wàhálà mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ yín
\q2 ẹ sì ti dààmú mi pẹ̀lú àìṣedéédéé yín.
\b
\q1
\v 25 “Èmi, àní Èmi, Èmi ni ẹni tí ó wẹ
\q2 àwọn àìṣedéédéé rẹ nù, nítorí èmi fún ara mi,
\q2 tí n kò sì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́.
\q1
\v 26 Bojú wo ẹ̀yìn rẹ fún mi,
\q2 jẹ́ kí a jọ ṣe àríyànjiyàn ọ̀rọ̀ náà papọ̀;
\q2 ro ẹjọ́ láti fihàn pé o kò lẹ́sẹ̀ lọ́rùn.
\q1
\v 27 Baba yín àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀;
\q2 àwọn agbẹnusọ yín ṣọ̀tẹ̀ sí mi.
\q1
\v 28 Nítorí náà, èmi ti sọ àwọn olórí ibi mímọ́ náà di àìmọ́,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni èmi ti fi Jakọbu fún ègún
\q2 àti Israẹli fún ẹ̀gàn.
\c 44
\s1 Israẹli tí a yàn
\q1
\v 1 “Ṣùgbọ́n gbọ́ nísinsin yìí, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi,
\q2 àti Israẹli, ẹni tí mo ti yàn.
\q1
\v 2 Ohun tí \nd Olúwa\nd* wí nìyìí
\q2 ẹni tí ó dá ọ, ẹni tí ó ti mọ̀ ọ́n
\q1 láti inú ìyá rẹ wá,
\q2 àti ẹni tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú.
\q1 Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu, ìránṣẹ́ mi,
\q2 Jeṣuruni ẹni tí mo ti yàn.
\q1
\v 3 Nítorí èmi yóò da omi sí ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ
\q2 àti àwọn odò ní ilẹ̀ gbígbẹ,
\q1 Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi sí ara àwọn ọmọ rẹ,
\q2 àti ìbùkún mi sórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ.
\q1
\v 4 Wọn yóò dàgbàsókè gẹ́gẹ́ bí i koríko nínú pápá oko tútù,
\q2 àti gẹ́gẹ́ bí igi Poplari létí odò tí ń sàn.
\q1
\v 5 Ọ̀kan yóò wí pé, Èmi jẹ́ ti \nd Olúwa\nd*;
\q2 òmíràn yóò pe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orúkọ Jakọbu;
\q1 bẹ́ẹ̀ ni òmíràn yóò kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀, Ti \nd Olúwa\nd*,
\q2 yóò sì máa jẹ́ orúkọ náà Israẹli.
\s1 \nd Olúwa\nd* ni, kì í ṣe ère òrìṣà
\q1
\v 6 \x - \xo 44.6: \xt Isa 48.12; If 1.17; 2.8; 22.13.\x*“Ohun tí \nd Olúwa\nd* wí nìyìí
\q2 ọba Israẹli àti Olùdáǹdè, àní
\q1 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun.
\q2 Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn,
\q2 lẹ́yìn mi kò sí Ọlọ́run kan.
\q1
\v 7 Ta ni ó dàbí ì mi? Jẹ́ kí o kéde rẹ̀.
\q2 Jẹ́ kí ó wí kí ó sì gbé síwájú mi
\q1 kí ni ó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí mo fi ìdí àwọn ènìyàn ìṣẹ̀ǹbáyé kalẹ̀,
\q2 àti kí ni ohun tí ń sì ń bọ̀,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí ń bọ̀ wá.
\q1
\v 8 Má ṣe wárìrì, má ṣe bẹ̀rù.
\q2 Ǹjẹ́ èmi kò ti kéde èyí tí mo sì ti sọ
\q1 àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tipẹ́tipẹ́?
\q2 Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan
\q1 ha ń bẹ lẹ́yìn mi?
\q2 Bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí àpáta mìíràn; Èmi kò mọ ọ̀kankan.”
\b
\q1
\v 9 Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère jásí asán,
\q2 àti àwọn ohun tí wọn ń kó pamọ́
\q1 kò jámọ́ nǹkan kan.
\q2 Àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ fún wọn fọ́ lójú;
\q2 wọ́n jẹ́ aláìmọ̀kan sí ìtìjú ara wọn.
\q1
\v 10 Ta ni ó mọ òrìṣà kan tí ó sì ya ère,
\q2 tí kò lè mú èrè kankan wá fún un?
\q1
\v 11 Òun àti nǹkan rẹ̀ wọ̀nyí ni a ó dójútì;
\q2 àwọn oníṣọ̀nà kò yàtọ̀, ènìyàn ni wọ́n.
\q1 Jẹ́ kí gbogbo wọn gbárajọ kí wọ́n sì
\q2 fi ìdúró wọn hàn;
\q2 gbogbo wọn ni a ó mú bọ́ sínú ìpayà àti àbùkù.
\b
\q1
\v 12 Alágbẹ̀dẹ mú ohun èlò,
\q2 ó fi ń ṣiṣẹ́ nínú èédú;
\q1 ó fi òòlù ya ère kan,
\q2 ó ṣe é pẹ̀lú agbára apá rẹ̀,
\q1 ebi ń pa á, àárẹ̀ sì mú un;
\q2 kò mu omi rárá, ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá a.
\q1
\v 13 Gbẹ́nàgbẹ́nà fi ìwọ̀n wọ́n ọ́n
\q2 ó sì fi lẹ́ẹ̀dì ṣe àmì sí ara rẹ̀,
\q1 Ó tún fi ìfà fá a jáde
\q2 ó tún fi òsùwọ̀n ṣe àmì sí i.
\q1 Ó gbẹ́ ẹ ní ìrí ènìyàn
\q2 gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nínú ògo rẹ̀,
\q2 kí ó lè máa gbé nínú ilé òrìṣà.
\q1
\v 14 Ó gé igi kedari lulẹ̀,
\q2 tàbí bóyá ó mú sípírẹ́ṣì tàbí igi óákù.
\q1 Ó jẹ́ kí ó dàgbà láàrín àwọn igi inú igbó,
\q2 ó sì le gbin igi páínì, èyí tí òjò mú kí ó dàgbà.
\q1
\v 15 Ohun èlò ìdáná ni fún ènìyàn;
\q2 díẹ̀ nínú rẹ̀ ni ó mú láti mú kí
\q1 ara rẹ̀ lọ́wọ́ọ́rọ́,
\q2 ó dá iná ó sì fi ṣe àkàrà.
\q1 Ṣùgbọ́n bákan náà ni ó ṣe òrìṣà tí ó sì ń sìn ín;
\q2 ó yá ère, ó sì ń foríbalẹ̀ fún un.
\q1
\v 16 Ìlàjì igi náà ni ó jó nínú iná;
\q2 lórí i rẹ̀ ni ó ti ń tọ́jú oúnjẹ rẹ̀,
\q1 ó dín ẹran rẹ̀ ó sì jẹ àjẹyó.
\q2 Ó tún mú ara rẹ̀ gbóná ó sì sọ pé,
\q2 “Á à! Ara mi gbóná, mo rí iná.”
\q1
\v 17 Nínú èyí tí ó kù ni ó ti ṣe òrìṣà, ère rẹ̀;
\q2 ó foríbalẹ̀ fún un, ó sì sìn ín.
\q1 Ó gbàdúrà sí i, ó wí pé,
\q2 “Gbà mí, ìwọ ni Ọlọ́run mi.”
\q1
\v 18 Wọn kò mọ nǹkan kan, nǹkan kan kò yé wọn;
\q2 a fi ìbòjú bo ojú wọn, wọn kò lè rí nǹkan kan;
\q2 bẹ́ẹ̀ ni àyà wọn sébọ́, wọn kò lè mọ nǹkan kan.
\q1
\v 19 Kò sí ẹni tí ó dúró láti ronú,
\q2 kò sí ẹni tí ó ní ìmọ̀ tàbí òye
\q1 láti sọ wí pé,
\q2 “Ìlàjì rẹ̀ ni mo fi dáná;
\q1 mo tilẹ̀ ṣe àkàrà lórí èédú rẹ̀,
\q2 mo dín ẹran, mo sì jẹ ẹ́.
\q1 Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí n ṣe ohun ìríra kan
\q2 nínú èyí tí ó ṣẹ́kù bí?
\q2 Ǹjẹ́ èmi yóò ha foríbalẹ̀ fún ìtì igi?”
\q1
\v 20 Ó ń jẹ eérú, ọkàn ẹlẹ́tàn ni ó ṣì í lọ́nà;
\q2 òun kò lè gba ara rẹ̀ là, tàbí kí ó wí pé,
\q2 “Ǹjẹ́ nǹkan tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún mi yìí irọ́ kọ́?”
\b
\q1
\v 21 “Rántí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ìwọ Jakọbu,
\q2 nítorí ìránṣẹ́ mi ni ìwọ, ìwọ Israẹli.
\q1 Èmi ti dá ọ, ìránṣẹ́ mi ni ìwọ ṣe,
\q2 ìwọ Israẹli, Èmi kì yóò gbàgbé rẹ.
\q1
\v 22 Èmi ti gbá gbogbo ìkùnà rẹ dànù bí i kurukuru,
\q2 àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bí ìrì òwúrọ̀.
\q1 Padà sọ́dọ̀ mi,
\q2 nítorí mo ti rà ọ́ padà.”
\b
\q1
\v 23 \x - \xo 44.23: \xt Jr 51.48; If 12.12; 18.20.\x*Kọrin fáyọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí \nd Olúwa\nd* ló ti ṣe èyí;
\q2 kígbe sókè, ìwọ ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀.
\q1 Bú sí orin, ẹ̀yin òkè ńlá,
\q2 ẹ̀yin igbó àti gbogbo igi yín,
\q1 nítorí \nd Olúwa\nd* ti ra Jakọbu padà,
\q2 ó ti fi ògo rẹ̀ hàn ní Israẹli.
\s1 A ó tún máa gbé Jerusalẹmu
\q1
\v 24 “Ohun tí \nd Olúwa\nd* wí nìyìí
\q2 Olùràpadà rẹ tí ó mọ ọ́
\q2 láti inú ìyá rẹ wá:
\b
\q1 “Èmi ni \nd Olúwa\nd*
\q2 tí ó ti ṣe ohun gbogbo
\q2 tí òun nìkan ti na àwọn ọ̀run
\q2 tí o sì tẹ́ ayé pẹrẹsẹ òun tìkára rẹ̀,
\q1
\v 25 \x - \xo 44.25: \xt 1Kọ 1.20.\x*ta ni ó ba àmì àwọn wòlíì èké jẹ́
\q2 tí ó sì sọ àwọn aláfọ̀ṣẹ di òmùgọ̀,
\q1 tí ó dojú ìmọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n délẹ̀
\q2 tí ó sì sọ wọ́n di òmùgọ̀,
\q1
\v 26 ẹni tí ó gbé ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jáde
\q2 tí ó sì mú àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìmúṣẹ,
\b
\q1 “ẹni tí ó wí nípa ti Jerusalẹmu pé, A ó máa gbé inú rẹ̀,
\q2 àti ní ti àwọn ìlú Juda, A ó tún kọ́,
\q2 àti àwọn ahoro rẹ̀, Èmi yóò mú un bọ̀ sípò,
\q1
\v 27 ta ni ó sọ fún omi jíjìn pé, Ìwọ gbẹ,
\q2 èmi yóò sì mú omi odò rẹ gbẹ,
\q1
\v 28 ta ni ó sọ nípa Kirusi pé, Òun ni Olùṣọ́-àgùntàn mi
\q2 àti pé òun yóò ṣe ohun gbogbo tí mo fẹ́;
\q1 òun yóò sọ nípa Jerusalẹmu pé, “Jẹ́ kí a tún kọ́,”
\q2 àti nípa tẹmpili, “Jẹ́ kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀.” ’ ”
\b
\b
\c 45
\q1
\v 1 “Èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd* sọ fún ẹni òróró rẹ̀,
\q2 sí Kirusi, ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí mo dì mú
\q1 láti dojú àwọn orílẹ̀-èdè bolẹ̀ níwájú rẹ̀
\q2 àti láti gba ohun ìjà àwọn ọba lọ́wọ́ wọn,
\q1 láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀
\q2 tí ó fi jẹ́ pé a kì yóò ti àwọn ẹnu-ọ̀nà.
\q1
\v 2 Èmi yóò lọ síwájú rẹ,
\q2 Èmi ó sì tẹ́ àwọn òkè ńlá pẹrẹsẹ
\q1 Èmi yóò fọ gbogbo ẹnu-ọ̀nà idẹ
\q2 èmi ó sì gé ọ̀pá irin.
\q1
\v 3 Èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ọrọ̀ ibi òkùnkùn,
\q2 ọrọ̀ tí a kó pamọ́ sí àwọn ibi tí ó fi ara sin,
\q1 tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi mọ̀ pé, Èmi ni \nd Olúwa\nd*,
\q2 Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ.
\q1
\v 4 Nítorí Jakọbu ìránṣẹ́ mi
\q2 àti Israẹli ẹni tí mo yàn,
\q1 Mo pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ,
\q2 mo sì gbé oyè kan kà ọ́ lórí
\q2 bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò gbà mí.
\q1
\v 5 Èmi ni \nd Olúwa\nd*, àti pé kò sí ẹlòmíràn;
\q2 yàtọ̀ sí èmi kò sí ọlọ́run kan,
\q1 Èmi yóò fún ọ ní okun,
\q2 bí o kò tilẹ̀ tí ì gbà mí,
\q1
\v 6 tí o fi jẹ́ pé láti ìlà-oòrùn
\q2 títí dé ibi ìwọ̀ rẹ̀
\q2 kí ènìyàn le mọ̀, kò sí ẹnìkan lẹ́yìn mi.
\q2 Èmi ni \nd Olúwa\nd*, lẹ́yìn mi kò sí ẹlòmíràn mọ́.
\q1
\v 7 Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn,
\q2 Mo mú àlàáfíà wá, Mo sì dá àjálù;
\q2 Èmi \nd Olúwa\nd* ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí.
\b
\q1
\v 8 “Ìwọ ọ̀run lókè rọ òjò òdodo sílẹ̀;
\q2 jẹ́ kí àwọsánmọ̀ kí ó rọ̀ ọ́ sílẹ̀.
\q1 Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó yanu gbagada,
\q2 jẹ́ kí ìgbàlà kí ó dìde sókè,
\q1 jẹ́ kí òdodo kí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀;
\q2 Èmi \nd Olúwa\nd* ni ó ti dá a.
\b
\q1
\v 9 \x - \xo 45.9: \xt Isa 29.16; Ro 9.20.\x*“Ègbé ni fún ènìyàn tí ó ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà,
\q2 ẹni tí òun jẹ́ àpáàdì kan láàrín àwọn àpáàdì tí ó wà lórí ilẹ̀.
\q1 Ǹjẹ́ amọ̀ lè sọ fún amọ̀kòkò, pé:
\q2 Kí ni ohun tí ò ń ṣe?
\q1 Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ lè sọ pé,
\q2 Òun kò ní ọwọ́?
\q1
\v 10 Ègbé ni fún ẹni tí ó sọ fún baba rẹ̀ pé,
\q2 Kí ni o bí?
\q1 tàbí sí ìyá rẹ̀,
\q2 Kí ni ìwọ ti bí?
\b
\q1
\v 11 “Ohun tí \nd Olúwa\nd* wí nìyìí,
\q2 Ẹni Mímọ́ Israẹli, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀.
\q1 Nípa ohun tí ó ń bọ̀,
\q2 ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi,
\q2 tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí?
\q1
\v 12 Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayé
\q2 tí ó sì da ọmọ ènìyàn sórí i rẹ̀.
\q1 Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀run;
\q2 mo sì kó àwọn àgbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta.
\q1
\v 13 Èmi yóò gbé Kirusi sókè nínú òdodo mi.
\q2 Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.
\q1 Òun yóò tún ìlú mi kọ́
\q2 yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀,
\q1 ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan,
\q2 ni \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí.”
\p
\v 14 \x - \xo 45.14: \xt 1Kọ 14.25.\x*Ohun tí \nd Olúwa\nd* wí nìyìí:
\q1 “Àwọn èròjà ilẹ̀ Ejibiti àti àwọn ọjà ilẹ̀ Kuṣi,
\q2 àti àwọn Sabeani—
\q1 wọn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ
\q2 wọn yóò sì jẹ́ tìrẹ;
\q1 wọn yóò máa wọ́ tẹ̀lé ọ lẹ́yìn,
\q2 wọn yóò máa wá lọ́wọ̀ọ̀wọ́.
\q1 Wọn yóò máa foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀,
\q2 wọn yóò sì máa bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ pé,
\q1 Nítòótọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ kò sì ṣí ẹlòmíràn;
\q2 kò sí ọlọ́run mìíràn.’ ”
\b
\q1
\v 15 Nítòótọ́ ìwọ jẹ́ Ọlọ́run tí ó fi ara rẹ̀ pamọ́,
\q2 Ìwọ Ọlọ́run àti Olùgbàlà Israẹli,
\q1
\v 16 Gbogbo àwọn tí ó ń gbẹ́ ère ni ojú yóò tì
\q2 wọn yóò sì kan àbùkù;
\q2 gbogbo wọn ni yóò bọ́ sínú àbùkù papọ̀.
\q1
\v 17 \x - \xo 45.17: \xt Hb 5.9.\x*Ṣùgbọ́n Israẹli ni a ó gbàlà láti ọwọ́ \nd Olúwa\nd*
\q2 pẹ̀lú ìgbàlà ayérayé;
\q1 a kì yóò kàn yín lábùkù tàbí kí a dójútì yín,
\q2 títí ayé àìnípẹ̀kun.
\b
\q1
\v 18 Nítorí èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd* wí,
\q2 ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run,
\q1 Òun ni Ọlọ́run;
\q2 ẹni tí ó mọ tí ó sì dá ayé,
\q1 Òun ló ṣe é;
\q2 Òun kò dá a láti wà lófo,
\q1 ṣùgbọ́n ó ṣe é kí a lè máa gbé ibẹ̀,
\q2 Òun wí pé:
\q1 “Èmi ni \nd Olúwa\nd*,
\q2 kò sì ṣí ẹlòmíràn.
\q1
\v 19 Èmi kò sọ̀rọ̀ níbi tí ó fi ara sin,
\q2 láti ibìkan ní ilẹ̀ òkùnkùn,
\q1 Èmi kò tí ì sọ fún àwọn ìran Jakọbu pé,
\q2 ‘Ẹ wá mi lórí asán.
\q1 Èmi \nd Olúwa\nd* sọ òtítọ́,
\q2 Mo sì sọ èyí tí ó tọ̀nà.
\b
\q1
\v 20 “Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ sì wá;
\q2 ẹ kórajọ, ẹ̀yin ìsáǹsá láti àwọn orílẹ̀-èdè wá.
\q1 Aláìmọ̀kan ni àwọn tí ó ń ru ère igi káàkiri,
\q2 tí wọ́n gbàdúrà sí àwọn òrìṣà tí kò le gba ni.
\q1
\v 21 \x - \xo 45.21: \xt Ap 15.18.\x*Jẹ́ kí a mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, fihàn wá,
\q2 jẹ́ kí wọn jọ dámọ̀ràn papọ̀.
\q1 Ta ló ti sọ èyí lọ́jọ́ tí o ti pẹ́,
\q2 ta ló ti wí èyí láti àtètèkọ́ṣe?
\q1 Kì í ha á ṣe Èmi, \nd Olúwa\nd*?
\q2 Àti pé kò sí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi,
\q1 Ọlọ́run olódodo àti olùgbàlà;
\q2 kò sí ẹlòmíràn àfi èmi.
\b
\q1
\v 22 “Yípadà sí mi kí a sì gbà ọ́ là,
\q2 ẹ̀yin ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé;
\q2 nítorí Èmi ni Ọlọ́run kò sì ṣí ẹlòmíràn.
\q1
\v 23 \x - \xo 45.23: \xt Ro 14.11; Fp 2.10-11.\x*Nípa èmi tìkára mi ni mo ti búra,
\q2 ẹnu mi ni ó ti sọ ọ́ pẹ̀lú gbogbo ipá mi,
\q1 ọ̀rọ̀ náà tí a kì yóò lè parẹ́.
\q2 Níwájú mi ni gbogbo orúnkún yóò wólẹ̀;
\q2 nípa mi ni gbogbo ahọ́n yóò búra.
\q1
\v 24 Wọn yóò sọ ní ti èmi, Nínú \nd Olúwa\nd* nìkan ni
\q2 òdodo àti agbára wà.’ ”
\q1 Gbogbo àwọn tí ó ti bínú sí;
\q2 yóò wá sọ́dọ̀ rẹ̀ a ó sì dójútì wọn.
\q1
\v 25 Ṣùgbọ́n nínú \nd Olúwa\nd* gbogbo àwọn ìran Israẹli
\q2 ni a ó rí ní òdodo, a o sì gbé wọn ga.
\c 46
\s1 Àwọn Ọlọ́run Babeli
\q1
\v 1 Beli tẹrí i rẹ̀ ba, Nebo bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀;
\q2 àwọn ère wọn ni àwọn ẹranko rù.
\q1 Àwọn ère tí wọ́n ń rù káàkiri ti di
\q2 àjàgà sí wọn lọ́rùn,
\q2 ẹrù fún àwọn tí àárẹ̀ mú.
\q1
\v 2 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ wọ́n sì foríbalẹ̀ papọ̀;
\q2 wọn kò lè gba ẹrù náà,
\q2 àwọn pẹ̀lú ni a kó lọ ní ìgbèkùn.
\b
\q1
\v 3 “Tẹ́tí sí mi, ìwọ ilé Jakọbu,
\q2 gbogbo ẹ̀yin tí ó ṣẹ́kù nínú ilé Israẹli,
\q1 ìwọ tí mo ti gbéró láti ìgbà tí o ti wà nínú oyún,
\q2 tí mo sì ti ń pọ̀n láti ìgbà tí a ti bí ọ.
\q1
\v 4 Pẹ̀lúpẹ̀lú sí àwọn arúgbó àti ewú orí yín,
\q2 Èmi ni ẹni náà, Èmi ni ẹni tí yóò gbé ọ ró.
\q1 Èmi ti mọ ọ́, èmi yóò sì gbé ọ;
\q2 Èmi yóò dì ọ́ mú èmi ó sì gbà ọ́ sílẹ̀.
\b
\q1
\v 5 “Ta ni ìwọ yóò fi mí wé tàbí ta ni èmi yóò bá dọ́gba?
\q2 Ta ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé mi
\q2 tí àwa yóò jọ fi ara wé ara?
\q1
\v 6 Ọ̀pọ̀ da wúrà sílẹ̀ nínú àpò wọn
\q2 wọ́n sì wọn fàdákà lórí òsùwọ̀n;
\q1 wọ́n bẹ alágbẹ̀dẹ lọ́wẹ̀ láti fi wọ́n ṣe òrìṣà,
\q2 wọn sì tẹríba láti sìn ín.
\q1
\v 7 Wọ́n gbé e lé èjìká wọn, wọ́n rù wọ́n,
\q2 wọ́n sì gbé e sí ààyè rẹ̀ níbẹ̀ ni ó sì dúró sí.
\q1 Láti ibẹ̀ náà kò le è paradà.
\q2 Bí ènìyàn tilẹ̀ pariwo lé e lórí, òun kò le è dáhùn;
\q2 òun kò lè gbà á nínú ìyọnu rẹ̀.
\b
\q1
\v 8 “Rántí èyí, fi í sí ọkàn rẹ,
\q2 fi sí ọkàn rẹ, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀.
\q1
\v 9 Rántí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, àwọn ti àtijọ́-tijọ́;
\q2 Èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn;
\q2 Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmíràn bí ì mi.
\q1
\v 10 Mo fi òpin hàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá,
\q2 láti àtètèkọ́ṣe, ohun tí ó sì ń bọ̀ wá.
\q1 Mo wí pé, Ète mi yóò dúró,
\q2 àti pé èmi yóò ṣe ohun tí ó wù mí.
\q1
\v 11 Láti ìlà-oòrùn wá ni mo ti pe ẹyẹ ajẹran wá;
\q2 láti ọ̀nà jíjìn réré, ọkùnrin kan tí yóò mú ète mi ṣẹ.
\q1 Ohun tí mo ti sọ, òun ni èmi yóò mú ṣẹ;
\q2 èyí tí mo ti gbèrò, òun ni èmi yóò ṣe.
\q1
\v 12 Gbọ́ tèmi, ẹ̀yin alágídí ọkàn,
\q2 ìwọ tí ó jìnnà sí òdodo.
\q1
\v 13 Èmi ń mú òdodo mi bọ̀ nítòsí,
\q2 kò tilẹ̀ jìnnà rárá;
\q1 àti ìgbàlà mi ni a kì yóò dádúró.
\q2 Èmi yóò fún Sioni ní ìgbàlà
\q2 ògo mi fún Israẹli.
\c 47
\s1 Ìṣubú Babeli
\q1
\v 1 \x - \xo 47.1-15: \xt Isa 13.114.23; Jr 50.151.64; Hk 12.\x*“Sọ̀kalẹ̀, jókòó nínú eruku,
\q2 wúńdíá ọmọbìnrin Babeli;
\q1 jókòó ní ilẹ̀ láìsí ìtẹ́,
\q2 ọmọbìnrin àwọn ará Babeli.
\q2 A kì yóò pè ọ́ ní aláìlókun àti ẹlẹgẹ́ mọ́.
\q1
\v 2 Mú òkúta-ọlọ kí o sì lọ ìyẹ̀fun;
\q2 mú ìbòjú rẹ kúrò.
\q1 Ká aṣọ ẹsẹ̀ rẹ sókè, ká aṣọ itan,
\q2 kí o sì la odò wọ̀n-ọn-nì kọjá.
\q1
\v 3 Ìhòhò rẹ ni a ó sí síta
\q2 àti ìtìjú rẹ ni a ó ṣí sílẹ̀.
\q1 Èmi yóò sì gba ẹ̀san,
\q2 Èmi kì yóò sì dá ẹnìkan sí.”
\b
\q1
\v 4 Olùràpadà wa \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀
\q2 òun ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.
\b
\q1
\v 5 “Jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, lọ sínú òkùnkùn,
\q2 ọmọbìnrin àwọn ará Babeli;
\q1 a kì yóò pè ọ́ ní ọbabìnrin
\q2 àwọn ilẹ̀ ọba mọ́.
\q1
\v 6 Inú bí mi sí àwọn ènìyàn mi
\q2 tí mo sì ba ogún mi jẹ́,
\q1 mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́,
\q2 Ìwọ kò sì síjú àánú wò wọ́n.
\q1 Lórí àwọn arúgbó pẹ̀lú
\q2 ní o gbé àjàgà tí ó wúwo lé.
\q1
\v 7 Ìwọ wí pé, Èmi yóò tẹ̀síwájú títí láé—
\q2 ọbabìnrin ayérayé!
\q1 Ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi nǹkan wọ̀nyí
\q2 tàbí kí o ronú nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀.
\b
\q1
\v 8 \x - \xo 47.8: \xt If 18.7.\x*“Nísinsin yìí, tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ oníwọ̀ra ẹ̀dá
\q2 tí o kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ nínú ààbò rẹ
\q1 tí o sì ń sọ fún ara rẹ pé,
\q2 Èmi ni, kò sì ṣí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.
\q1 Èmi kì yóò di opó
\q2 tàbí kí n pàdánù àwọn ọmọ.
\q1
\v 9 \x - \xo 47.9: \xt If 18.8.\x*Méjèèjì yìí ni yóò wá sórí rẹ
\q2 láìpẹ́ jọjọ, ní ọjọ́ kan náà:
\q1 pípàdánù ọmọ àti dídi opó.
\q2 Wọn yóò wá sórí rẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́,
\q1 pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìṣe oṣó rẹ
\q2 àti àwọn èpè rẹ tí ko lágbára.
\q1
\v 10 Ìwọ ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìwà ìkà rẹ
\q2 ó sì ti wí pé, Kò sí ẹni tí ó rí mi?
\q1 Ọgbọ́n àti òye rẹ ti ṣì ọ́ lọ́nà
\q2 nígbà tí o wí fún ara rẹ pé,
\q2 Èmi ni, kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.
\q1
\v 11 Ìparun yóò dé bá ọ
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò mọ ọ̀nà láti ré e kúrò.
\q1 Àjálù kan yóò ṣubú lù ọ́
\q2 tí o kì yóò le è fi ètùtù ré kúrò;
\q1 òfò kan tí o kò le faradà ni
\q2 yóò wá lójijì sí oríì rẹ.
\b
\q1
\v 12 “Tẹ̀síwájú nígbà náà, pẹ̀lú àfọ̀ṣẹ rẹ
\q2 àti pẹ̀lú ìwà oṣó rẹ gbogbo,
\q1 tí o ti ń ṣiṣẹ́ fún láti ìgbà èwe rẹ wá.
\q2 Bóyá o le è ṣàṣeyọrí,
\q2 bóyá o le è dá rúgúdù sílẹ̀.
\q1
\v 13 Gbogbo ìmọ̀ràn tí o ti gbà ni
\q2 ó ti sọ ọ́ di akúrẹtẹ̀!
\q1 Jẹ́ kí àwọn awòràwọ̀ rẹ bọ́ síwájú,
\q2 àwọn awòràwọ̀ tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀
\q1 láti oṣù dé oṣù,
\q2 jẹ́ kí wọ́n gbà ọ́ lọ́wọ́ ohun tí ó ń bọ̀ wá bá ọ.
\q1
\v 14 Lóòótọ́ wọ́n dàbí ìṣẹ́pẹ́ igi;
\q2 iná ni yóò jó wọn dànù.
\q1 Wọn kò kúkú lè gba ara wọn là
\q2 lọ́wọ́ agbára iná náà.
\q1 Kò sí èédú láti mú ara ẹnikẹ́ni gbóná
\q2 níhìn-ín kò sí iná tí ènìyàn le jókòó tì.
\q1
\v 15 Gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe fún ọ nìyìí
\q2 gbogbo èyí ní o tí ṣíṣẹ́ pẹ̀lú u rẹ̀
\q1 tí o sì ti ń rù kiri láti ìgbà èwe.
\q2 Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń lọ nínú àṣìṣe rẹ̀;
\q2 kò sí ẹyọ ẹnìkan tí ó lè gbà ọ́.
\c 48
\s1 Israẹli olórí kunkun
\q1
\v 1 “Tẹ́tí sí èyí, ìwọ ilé e Jakọbu,
\q2 ìwọ tí a ń pè pẹ̀lú orúkọ Israẹli
\q1 tí o sì wá láti ẹ̀ka Juda,
\q2 ìwọ tí ò ń búra ní orúkọ \nd Olúwa\nd*
\q1 tí o sì ń pe Ọlọ́run Israẹli
\q2 ṣùgbọ́n kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo,
\q1
\v 2 ìwọ tí ò ń pe ara rẹ ní ọmọ ìlú mímọ́ n nì
\q2 tí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Israẹli—
\q2 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
\q1
\v 3 Èmi sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀ lọ́jọ́ tó ti pẹ́,
\q2 ẹnu mi ló ti kéde wọn, mo sì sọ wọ́n di mí mọ̀;
\q2 lẹ́yìn náà lójijì mo gbé ìgbésẹ̀, wọ́n sì wá sí ìmúṣẹ.
\q1
\v 4 Nítorí mo mọ bí ẹ ti jẹ́ olórí kunkun tó;
\q2 àwọn iṣan ọrùn yín sì jẹ́ irin;
\q2 bẹ́ẹ̀ ni iwájú yín idẹ ni.
\q1
\v 5 Nítorí náà mo ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ọ
\q2 ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́;
\q1 kí wọn ó tó ṣẹlẹ̀ mo ti kéde wọn fún un yín
\q2 tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè sọ pé,
\q1 Àwọn ère mi ló ṣe wọ́n;
\q2 àwọn ère igi àti òrìṣà irin ló fọwọ́sí i.
\q1
\v 6 Ìwọ ti gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí; wo gbogbo wọn.
\q2 Ǹjẹ́ o kò nígbà wọ́n bí?
\b
\q1 “Láti ìsinsin yìí lọ, Èmi yóò máa sọ
\q2 fún ọ nípa nǹkan tuntun,
\q2 àwọn nǹkan tí ó fi ara sin tí ìwọ kò mọ̀.
\q1
\v 7 A dá wọn ní àkókò yìí kì í ṣe láti ìgbà pípẹ́
\q2 ìwọ kò tí ì gbọ́ nípa wọn títí di òní.
\q1 Nítorí náà, ìwọ kò lè sọ pé,
\q2 Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ nípa wọn.
\q1
\v 8 Ìwọ a ha ti gbọ́ tàbí ó ti yé ọ bí
\q1 láti ìgbà àtijọ́ etí kò ti di yíyà.
\q2 Ǹjẹ́ mo mọ̀ bí o ti jẹ́ alárékérekè tó;
\q2 a ń pè ọ́ ní ọlọ̀tẹ̀ láti ìgbà ìbí rẹ.
\q1
\v 9 Nítorí orúkọ ara mi, mo dáwọ́ ìbínú mi dúró;
\q2 nítorí ìyìn ara mi, mo fà á sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
\q2 kí a má ba à ké ọ kúrò.
\q1
\v 10 Wò ó, èmi ti tún ọ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé
\q2 kì í ṣe bí i fàdákà;
\q2 Èmi ti dán ọ wò nínú ìléru ìpọ́njú.
\q1
\v 11 Nítorí orúkọ mi, nítorí orúkọ mi, mo ṣe èyí.
\q2 Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí a ba orúkọ mi jẹ́.
\q2 Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn.
\s1 Israẹli dòmìnira
\q1
\v 12 \x - \xo 48.12: \xt Isa 44.6; If 1.17; 2.8; 22.13.\x*“Tẹ́tí sí mi, ìwọ Jakọbu
\q2 Israẹli ẹni tí mo pè.
\q1 Èmi ni ẹni náà;
\q2 Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn.
\q1
\v 13 Ọwọ́ mi pàápàá ni ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,
\q2 àti ọwọ́ ọ̀tún mi ni ó tẹ àwọn ọ̀run;
\q1 nígbà tí mo pè wọ́n,
\q2 gbogbo wọn dìde sókè papọ̀.
\b
\q1
\v 14 “Gbogbo yín, ẹ péjọ kí ẹ sì gbọ́.
\q2 Ta nínú wọn ni ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí.
\q1 \nd Olúwa\nd* ti fẹ́ ẹ,
\q2 yóò sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní Babiloni,
\q2 apá rẹ̀ ni yóò sì wà ní ará àwọn ará Kaldea.
\q1
\v 15 Èmi, àní Èmi ló ti sọ̀rọ̀;
\q2 bẹ́ẹ̀ ni, mo ti pè é.
\q1 Èmi yóò mú un wá,
\q2 òun yóò sì ṣe àṣeyọrí nínú ìrìnàjò rẹ̀.
\p
\v 16 “Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì dẹtí sí èyí:
\q1 “Láti ìgbà ìkéde àkọ́kọ́ èmi kò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀;
\q2 ní àsìkò tí ó sì ṣẹlẹ̀, Èmi wà níbẹ̀.”
\b
\q1 Àti ní àkókò yìí, \nd Olúwa\nd* Olódùmarè ni ó ti rán mi,
\q2 pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ̀.
\b
\q1
\v 17 Èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd* wí,
\q2 Olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli:
\q1 “Èmi ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ,
\q2 tí ó kọ́ ọ ní ohun tí ó dára fún ọ,
\q2 tí ó tọ́ ọ ṣọ́nà tí ó yẹ kí o máa rìn.
\q1
\v 18 Bí ó bá ṣe pé ìwọ bá ti tẹ́tí sílẹ̀ sí àṣẹ mi,
\q2 àlàáfíà rẹ kì bá ti dàbí ì ti odò,
\q2 àti òdodo rẹ bí ìgbì Òkun.
\q1
\v 19 Àwọn ọmọ rẹ ìbá ti dàbí iyanrìn,
\q2 àwọn ọmọ yín bí i hóró ọkà tí a kò lè kà tán;
\q1 orúkọ wọn ni a kì yóò ké kúrò
\q2 tàbí kí a pa wọ́n run níwájú mi.”
\b
\q1
\v 20 Fi Babeli sílẹ̀,
\q2 sá fún àwọn ará Babeli,
\q1 ṣe ìfilọ̀ èyí pẹ̀lú ariwo ayọ̀
\q2 kí o sì kéde rẹ̀.
\q1 Rán an jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé;
\q2 wí pé, “\nd Olúwa\nd* ti dá ìránṣẹ́ rẹ̀ Jakọbu nídè.”
\q1
\v 21 Òrùngbẹ kò gbẹ wọ́n nígbà tí ó kó wọn
\q2 kọjá nínú aginjù;
\q1 ó jẹ́ kí omi ó sàn fún wọn láti inú àpáta;
\q2 ó fọ́ àpáta
\q2 omi sì tú jáde.
\b
\q1
\v 22 “Kò sí àlàáfíà,” ni \nd Olúwa\nd* wí,
\q2 “Fún àwọn ìkà.”
\c 49
\s1 Ìránṣẹ́ \nd Olúwa\nd* Náà
\q1
\v 1 \x - \xo 49.1: \xt Jr 1.5; Ga 1.15.\x*Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin erékùṣù:
\q2 gbọ́ èyí, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè jíjìnnà réré:
\q1 kí a tó bí mi \nd Olúwa\nd* ti pè mí;
\q2 láti ìgbà bíbí mi ni ó ti dá orúkọ mi.
\q1
\v 2 Ó ṣe ẹnu mi bí idà tí a pọ́n,
\q2 ní abẹ́ òjìji ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti pa mí mọ́:
\q1 ó ṣe mí ní ọfà tí a ti dán,
\q2 ó sì fi mí pamọ́ sínú àpò rẹ̀.
\q1
\v 3 Ó sọ fún mi pé, “Ìránṣẹ́ mi ni ìwọ í ṣe,
\q2 Israẹli nínú ẹni tí n ó ti fi ògo mi hàn.”
\q1
\v 4 \x - \xo 49.4: \xt Fp 1.6.\x*Ṣùgbọ́n èmi sọ pé, “Mo ti ṣe wàhálà lórí asán;
\q2 mo ti lo gbogbo ipá mi lórí asán àti ìmúlẹ̀mófo.
\q1 Síbẹ̀síbẹ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi ṣì wà lọ́wọ́ \nd Olúwa\nd*,
\q2 èrè mi sì ń bẹ pẹ̀lú Ọlọ́run mi.”
\b
\q1
\v 5 Nísinsin yìí \nd Olúwa\nd* wí pé
\q2 ẹni tí ó mọ̀ mí láti inú wá láti jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀
\q1 láti mú Jakọbu padà tọ̀ mí wá
\q2 àti láti kó Israẹli jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,
\q1 nítorí pé a bọ̀wọ̀ fún mi ní ojú \nd Olúwa\nd*
\q2 Ọlọ́run mi sì ti jẹ́ agbára mi,
\q1
\v 6 \x - \xo 49.6: \xt Isa 42.6; Lk 2.32; Ap 13.47; 26.23.\x*Òun wí pé:
\q2 “Ó jẹ́ ohun kékeré fún ọ láti jẹ́ ìránṣẹ́ mi
\q1 láti mú ẹ̀yà Jakọbu padà bọ̀ sípò
\q2 àti láti mú àwọn ti Israẹli tí mo ti pamọ́.
\q1 Èmi yóò sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn kèfèrí,
\q2 kí ìwọ kí ó lè mú ìgbàlà mi wá
\q2 sí òpin ilẹ̀ ayé.”
\b
\q1
\v 7 Ohun tí \nd Olúwa\nd* wí nìyìí,
\q2 Olùdáǹdè àti Ẹni Mímọ́ Israẹli—
\q1 sí ẹni náà tí a gàn tí a sì kórìíra
\q2 lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,
\q1 sí ìránṣẹ́ àwọn aláṣẹ:
\q2 “Àwọn ọba yóò rí ọ wọn yóò sì dìde sókè,
\q1 àwọn ọmọ ọba yóò rí i wọn yóò sì wólẹ̀,
\q2 nítorí \nd Olúwa\nd* ẹni tí í ṣe olóòtítọ́,
\q2 Ẹni Mímọ́ Israẹli tí ó ti yàn ọ́.”
\s1 Ìmúpadàbọ̀sípò Israẹli
\p
\v 8 \x - \xo 49.8: \xt 2Kọ 6.2.\x*Ohun tí \nd Olúwa\nd* wí nìyìí:
\q1 “Ní àkókò ojúrere mi, èmi yóò dá ọ lóhùn,
\q2 àti ní ọjọ́ ìgbàlà, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́;
\q1 Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́
\q2 láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn,
\q1 láti mú ilẹ̀ padà bọ̀ sípò
\q2 àti láti ṣe àtúnpín ogún rẹ̀ tí ó ti dahoro,
\q1
\v 9 láti sọ fún àwọn ìgbèkùn pé, ‘Ẹ jáde wá,
\q2 àti fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn pé, ‘Ẹ gba òmìnira!
\b
\q1 “Wọn yóò máa jẹ ní ẹ̀bá ọ̀nà
\q2 àti koríko tútù lórí òkè aláìléwéko.
\q1
\v 10 \x - \xo 49.10: \xt If 7.16.\x*Ebi kì yóò pa wọ́n bẹ́ẹ̀ ni òǹgbẹ kì yóò gbẹ wọ́n,
\q2 tàbí kí ooru inú aṣálẹ̀ tàbí oòrùn kí ó pa wọ́n.
\q1 Ẹni tí ó ṣàánú fún wọn ni yóò máa tọ́ wọn,
\q2 tí yóò sì mú wọn lọ sí ibi orísun omi.
\q1
\v 11 Èmi yóò sọ gbogbo àwọn òkè ńlá mi di ojú ọ̀nà
\q2 àti gbogbo òpópónà mi ni a ó gbé sókè.
\q1
\v 12 Kíyèsi i, wọn yóò wá láti ọ̀nà jíjìn
\q2 àwọn díẹ̀ láti àríwá àti àwọn díẹ̀ láti ìwọ̀-oòrùn,
\q2 àwọn díẹ̀ láti ẹkùn Siene.”
\b
\q1
\v 13 \x - \xo 49.13: \xt Isa 44.23; Jr 51.48; If 12.12; 18.20.\x*Ẹ hó fún ayọ̀, ẹyin ọ̀run;
\q2 yọ̀, ìwọ ilẹ̀ ayé;
\q1 bú sórin, ẹ̀yin òkè ńlá!
\q2 Nítorí \nd Olúwa\nd* tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú
\q1 yóò sì ṣàánú fún àwọn ẹni
\q2 tí a ń pọ́n lójú.
\b
\q1
\v 14 Ṣùgbọ́n Sioni sọ pé, “\nd Olúwa\nd* ti kọ̀ mí sílẹ̀,
\q2 Olúwa ti gbàgbé è mi.”
\b
\q1
\v 15 “Ǹjẹ́ abiyamọ ha le gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀
\q2 kí ó má sì ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ó ti bí?
\q1 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun le gbàgbé,
\q2 Èmi kì yóò gbàgbé rẹ!
\q1
\v 16 Kíyèsi i, mo ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi
\q2 ògiri rẹ wà níwájú mi nígbà gbogbo.
\q1
\v 17 Àwọn ọmọ rẹ ti kánjú padà,
\q2 àti àwọn tí ó sọ ọ́ dahoro ti padà lẹ́yìn rẹ.
\q1
\v 18 Gbójú rẹ sókè kí o sì wò yíká;
\q2 gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ kórajọ
\q1 wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ.
\q2 Níwọ́n ìgbà tí mo bá wà láààyè,” ni \nd Olúwa\nd* wí,
\q1 “Ìwọ yóò wọ gbogbo wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀ṣọ́;
\q2 ìwọ yóò wọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìyàwó.
\b
\b
\q1
\v 19 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí run ọ́, a sì sọ ọ́ di ahoro
\q2 tí gbogbo ilẹ̀ rẹ sì di ìparun,
\q1 ní ìsinsin yìí, ìwọ yóò kéré jù fún àwọn ènìyàn rẹ,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ó jẹ ọ́ run ni yóò
\q2 wà láti ọ̀nà jíjìn réré.
\q1
\v 20 Àwọn ọmọ tí a bí ní àkókò ọ̀fọ̀ rẹ
\q2 yóò sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ,
\q1 Ibi yìí ti kéré jù fún wa;
\q2 ẹ fún wa láyè sí i tí a ó máa gbé.
\q1
\v 21 Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní ọkàn rẹ pé,
\q2 Ta ló bí àwọn yìí fún mi?
\q1 Mo ti ṣọ̀fọ̀ mo sì yàgàn;
\q2 a sọ mi di àtìpó a sì kọ̀ mí sílẹ̀.
\q1 Ta ló wo àwọn yìí dàgbà?
\q2 A fi èmi nìkan sílẹ̀,
\q2 ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí níbo ni wọ́n ti wá?’ ”
\p
\v 22 Ohun tí \nd Olúwa\nd* Olódùmarè wí nìyìí,
\q2 “Kíyèsi i, Èmi yóò ké sí àwọn aláìkọlà,
\q1 Èmi yóò gbé àsíá mi sókè sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn;
\q2 wọn yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín wá ní apá wọn
\q1 wọn yóò sì gbé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin
\q2 ní èjìká wọn.
\q1
\v 23 Àwọn ọba ni yóò jẹ́ alágbàtọ́ baba fún ọ,
\q2 àwọn ayaba wọn ni yóò sì jẹ́ ìyá-alágbàtọ́.
\q1 Wọn yóò foríbalẹ̀ ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ojú wọn dídàbolẹ̀;
\q2 wọn yóò máa lá erùpẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ.
\q1 Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé, Èmi ni \nd Olúwa\nd*;
\q2 gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìrètí nínú mi
\q2 ni a kì yóò jákulẹ̀.”
\b
\q1
\v 24 Ǹjẹ́ a le gba ìkógun lọ́wọ́ jagunjagun,
\q2 tàbí kí á gba ìgbèkùn lọ́wọ́ akíkanjú?
\p
\v 25 Ṣùgbọ́n ohun tí \nd Olúwa\nd* wí nìyìí:
\q1 “Bẹ́ẹ̀ ni, a ó gba àwọn ìgbèkùn lọ́wọ́ àwọn jagunjagun,
\q2 àti ìkógun lọ́wọ́ àwọn akíkanjú;
\q1 ẹni tí ó bá ọ jà ni èmi ó bá jà,
\q2 àti àwọn ọmọ rẹ ni èmi ó gbàlà.
\q1
\v 26 Èmi yóò mú kí àwọn aninilára rẹ̀ jẹ ẹran-ara wọn;
\q2 wọn yóò mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn yó bí ẹni mu wáìnì.
\q1 Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn yóò mọ̀
\q2 pé, Èmi, \nd Olúwa\nd*, èmi ni Olùgbàlà rẹ,
\q2 Olùdáǹdè rẹ, Alágbára kan ṣoṣo ti Jakọbu.”
\c 50
\s1 Ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli àti ìgbọ́ràn ìránṣẹ́
\p
\v 1 Ohun tí \nd Olúwa\nd* wí nìyìí:
\q1 “Níbo ni ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ ìyá rẹ wà
\q2 èyí tí mo fi lé e lọ?
\q1 Tàbí èwo nínú àwọn olùyánilówó mi
\q2 ni mo tà ọ́ fún?
\q1 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni a fi tà ọ́;
\q2 nítorí àìṣedéédéé rẹ ni a fi lé ìyá rẹ lọ.
\q1
\v 2 Nígbà tí mo wá, èéṣe tí a kò fi rí ẹnìkan?
\q2 Nígbà tí mo pè, èéṣe tí kò fi sí ẹnìkan láti dáhùn?
\q1 Ọwọ́ mi a kúrú láti gbà ọ́?
\q2 Èmi kò ha ní agbára láti gbà ọ́ bí?
\q1 Nípa ìbáwí lásán, Èmi gbẹ omi òkun,
\q2 Èmi yí àwọn odò sí aṣálẹ̀;
\q1 àwọn ẹja wọn rà fún àìsí omi
\q2 wọ́n sì kú fún òǹgbẹ.
\q1
\v 3 Èmi fi òkùnkùn bo sánmọ̀
\q2 mo sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ ṣe ìbòrí rẹ̀.”
\b
\q1
\v 4 \nd Olúwa\nd* Olódùmarè ti fún mi ni ahọ́n tí a fi iṣẹ́ rán,
\q2 láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé àwọn aláàárẹ̀ ró.
\q1 O jí mi láràárọ̀,
\q2 o jí etí mi láti gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí à ń kọ́.
\q1
\v 5 \nd Olúwa\nd* Olódùmarè ti ṣí mi ní etí,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ṣọ̀tẹ̀ rí;
\q2 Èmi kò sì padà sẹ́yìn.
\q1
\v 6 Mo ṣí ẹ̀yìn mi sílẹ̀ fún àwọn tí ó ń nà mí,
\q2 àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ń fa irùngbọ̀n mi;
\q1 Èmi kò fi ojú mi pamọ́
\q2 kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́yà àti ìyọṣùtì sí.
\q1
\v 7 Nítorí \nd Olúwa\nd* Olódùmarè ràn mí lọ́wọ́,
\q2 a kì yóò dójútì mí.
\q1 Nítorí náà ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí òkúta akọ
\q2 èmi sì mọ pé, ojú kò ní tì mí.
\q1
\v 8 Ẹni tí ó dá mi láre wà nítòsí.
\q2 Ta ni ẹni náà tí yóò fẹ̀sùn kàn mí?
\q1 Jẹ́ kí a kojú ara wa!
\q2 Ta ni olùfisùn mi?
\q2 Jẹ́ kí ó kò mí lójú!
\q1
\v 9 \nd Olúwa\nd* Olódùmarè ni ó ń ràn mí lọ́wọ́.
\q2 Ta ni ẹni náà tí yóò dá mi lẹ́bi?
\q1 Gbogbo wọn yóò gbó bí aṣọ;
\q2 kòkòrò ni yóò sì jẹ wọn run.
\b
\q1
\v 10 Ta ni nínú yín tí ó bẹ̀rù \nd Olúwa\nd*
\q2 tí ó sì ń gbọ́rọ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nu?
\q1 Jẹ́ kí ẹni tí ń rìn ní òkùnkùn
\q2 tí kò ní ìmọ́lẹ̀,
\q1 kí ó gbẹ́kẹ̀lé orúkọ \nd Olúwa\nd*
\q2 kí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹ̀.
\q1
\v 11 Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gbogbo ẹ̀yin ti ń tanná
\q2 tí ẹ sì ń fi pèsè iná ìléwọ́ fún ara yín,
\q1 ẹ lọ, kí ẹ sì máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín,
\q2 àti nínú ẹta iná tí ẹ ti dá.
\q1 Èyí ni yóò jẹ́ tiyín láti ọwọ́ mi wá.
\q2 Ẹ̀yin ó dùbúlẹ̀ nínú ìrora.
\c 51
\s1 Ìgbàlà ayérayé fún Sioni
\q1
\v 1 “Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ó ń lépa òdodo
\q2 àti ẹ̀yin tí ń wá \nd Olúwa\nd*.
\q1 Wo àpáta, nínú èyí tí a ti gé yín jáde
\q2 àti ihò òkúta níbi tí a ti gbẹ́ yín jáde;
\q1
\v 2 ẹ wo Abrahamu baba yín,
\q2 àti Sara, ẹni tó bí i yín.
\q1 Nígbà tí mo pè é, òun nìkan ni,
\q2 Èmi sì bùkún un, mo sì ṣọ́ ọ di ọ̀pọ̀lọpọ̀.
\q1
\v 3 Dájúdájú, \nd Olúwa\nd* yóò tu Sioni nínú
\q2 yóò sì bojú àánú wo gbogbo ahoro rẹ̀;
\q1 Òun yóò sọ gbogbo aṣálẹ̀ rẹ̀ di Edeni,
\q2 àti aṣálẹ̀ rẹ̀ yóò rí bí ọgbà \nd Olúwa\nd*.
\q1 Ayọ̀ àti inú dídùn ni a ó rí nínú rẹ̀,
\q2 ọpẹ́ àti ariwo orín kíkọ.
\b
\q1
\v 4 “Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ènìyàn mi;
\q2 gbọ́ tèmi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè mi.
\q1 Òfin yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde wá;
\q2 ìdájọ́ mi yóò di ìmọ́lẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè.
\q1
\v 5 Òdodo mi ń bọ̀ wá kíkankíkan,
\q2 ìgbàlà mi ń bọ̀ lójú ọ̀nà,
\q1 àti apá mi yóò sì mú ìdájọ́ wá
\q2 sí àwọn orílẹ̀-èdè.
\q1 Àwọn erékùṣù yóò wò mí
\q2 wọn yóò sì dúró ní ìrètí fún apá mi.
\q1
\v 6 \x - \xo 51.6: \xt Hb 1.11.\x*Gbé ojú rẹ sókè sí àwọn ọ̀run,
\q2 wo ilẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀;
\q1 àwọn ọ̀run yóò pòórá bí èéfín,
\q2 ilẹ̀ yóò sì gbó bí ẹ̀wù
\q1 àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò kú gẹ́gẹ́ bí àwọn eṣinṣin.
\q2 Ṣùgbọ́n ìgbàlà mi yóò wà títí láé,
\q2 òdodo mi kì yóò yẹ̀ láé.
\b
\q1
\v 7 “Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin tí ó mọ ohun òtítọ́,
\q2 ẹ̀yin ènìyàn tí ó ní òfin mi ní àyà yín.
\q1 Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn ènìyàn
\q2 tàbí kí ẹ̀rù èébú wọn já a yín láyà.
\q1
\v 8 Nítorí kòkòrò yóò mú wọn lá bí aṣọ,
\q2 ìdin yóò sì mú wọn jẹ bí ẹ̀gbọ̀n òwú.
\q1 Ṣùgbọ́n òdodo mi yóò wà títí ayérayé,
\q2 àti ìgbàlà mi láti ìrandíran.”
\b
\q1
\v 9 Dìde, dìde! Kí o sì wọ ara rẹ ní agbára
\q2 ìwọ apá \nd Olúwa\nd*;
\q1 dìde gẹ́gẹ́ bí i ti ọjọ́ ìgbà n nì,
\q2 àti gẹ́gẹ́ bí i ti ìran àtijọ́.
\q1 Ìwọ kọ́ lo ké Rahabu sí wẹ́wẹ́
\q2 tí o sì fa ẹ̀mí búburú ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ?
\q1
\v 10 Ìwọ kọ́ ni ó gbẹ omi Òkun bí
\q2 àti àwọn omi inú ọ̀gbun,
\q1 tí o sì ṣe ọ̀nà nínú ìsàlẹ̀ Òkun
\q2 tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹni ìràpadà yóò fi le là á kọjá?
\q1
\v 11 Àwọn ẹni ìràpadà \nd Olúwa\nd* yóò padà wá.
\q2 Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin kíkọ;
\q1 ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo orí wọn.
\q2 Ayọ̀ àti inú dídùn yóò sì bà lé wọn
\q2 ìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò.
\b
\q1
\v 12 “Èmi, àní Èmi, èmi ni ẹni tí ó tù ọ́ nínú.
\q2 Ta ni ọ́ tí o fi ń bẹ̀rù ènìyàn ẹlẹ́ran ara,
\q2 àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ koríko lásán,
\q1
\v 13 tí ìwọ sì gbàgbé \nd Olúwa\nd* ẹlẹ́dàá rẹ,
\q2 ẹni tí ó ta àwọn ọ̀run
\q1 tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,
\q2 tí ẹ sì ń gbé nínú ìpayà lójoojúmọ́
\q1 nítorí ìbínú àwọn aninilára,
\q2 tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀lé ìpanirun?
\q2 Nítorí ibo ni ìbínú àwọn aninilára gbé wà?
\q1
\v 14 Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ń ṣojo la ó dá sílẹ̀ ní àìpẹ́ jọjọ
\q2 wọn kò ní kú sínú túbú wọn,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣe aláìní àkàrà.
\q1
\v 15 Nítorí Èmi ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ,
\q2 tí ó ń ru Òkun sókè tó bẹ́ẹ̀ tí
\q1 ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo
\q2 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
\q1
\v 16 Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ
\q2 mo sì ti fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́,
\q1 Èmi tí mo tẹ́ àwọn ọ̀run sí ààyè rẹ̀,
\q2 ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀,
\q1 àti ẹni tí ó sọ fún Sioni pé,
\q2 Ẹ̀yin ni ènìyàn mi.’ ”
\s1 Ago ìbínú \nd Olúwa\nd*
\q1
\v 17 Jí, jí!
\q2 Gbéra nílẹ̀ ìwọ Jerusalẹmu,
\q1 ìwọ tí o ti mu láti ọwọ́ \nd Olúwa\nd*
\q2 ago ìbínú rẹ̀,
\q1 ìwọ tí o ti fà á mu dé gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀
\q2 tí ó n mú kí ènìyàn ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n.
\q1
\v 18 Nínú gbogbo ọmọ tí ó bí
\q2 kò sí ọ̀kankan tí ó lè tọ́ ọ ṣọ́nà
\q1 nínú gbogbo ọmọ tí ó tọ́
\q2 kò sí èyí tí ó le fà á lọ́wọ́.
\q1
\v 19 Àjálù ìlọ́po ìlọ́po yìí ti dé bá ọ—
\q2 ta ni yóò tù ọ́ nínú?
\q1 Ìparun àti ìdahoro, ìyàn àti idà
\q2 ta ni yó pẹ̀tù sí ọ lọ́kàn?
\q1
\v 20 Àwọn ọmọkùnrin rẹ ti dákú;
\q2 wọ́n sùn sí oríta gbogbo òpópónà,
\q1 gẹ́gẹ́ bí etu tí a dé mọ́nú àwọ̀n.
\q2 Ìbínú \nd Olúwa\nd* ti kún inú wọn fọ́fọ́
\q2 àti ìbáwí Ọlọ́run yín.
\b
\q1
\v 21 Nítorí náà ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí a ti ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́,
\q2 tí ọtí ń pa, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wáìnì.
\q1
\v 22 Ohun tí \nd Olúwa\nd* Olódùmarè yín wí nìyìí,
\q2 Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ń pa ènìyàn rẹ̀ mọ́,
\q1 “Kíyèsi i, mo ti mú un kúrò ní ọwọ́ rẹ
\q2 ago tí ó mú ọ ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n;
\q1 láti inú ago náà, ẹ̀kún ìbínú mi,
\q2 ni ìwọ kì yóò mu mọ́.
\q1
\v 23 Èmi yóò fi lé àwọn apọ́nilójú rẹ lọ́wọ́,
\q2 àwọn tí ó wí fún ọ pé,
\q1 Dọ̀bálẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí a ó fi máa rìn lórí rẹ.
\q2 Ìwọ náà ṣe ẹ̀yìn rẹ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀
\q2 gẹ́gẹ́ bí òpópónà láti máa rìn lórí i rẹ̀.”
\b
\b
\c 52
\q1
\v 1 \x - \xo 52.1: \xt If 21.27.\x*Jí, jí, ìwọ Sioni,
\q2 wọ ara rẹ ní agbára.
\q1 Gbé aṣọ ògo rẹ wọ̀,
\q2 ìwọ Jerusalẹmu, ìlú mímọ́ n nì.
\q1 Àwọn aláìkọlà àti aláìmọ́
\q2 kì yóò wọ inú rẹ mọ́.
\q1
\v 2 Gbọn eruku rẹ kúrò;
\q2 dìde sókè, kí o sì gúnwà, ìwọ Jerusalẹmu.
\q1 Bọ́ ẹ̀wọ̀n tí ń bẹ lọ́rùn rẹ kúrò,
\q2 ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin ìgbèkùn Sioni.
\p
\v 3 Nítorí èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd* wí,
\q2 “Ọ̀fẹ́ ni a tà ọ́,
\q2 láìsanwó ni a ó sì rà ọ́ padà.”
\p
\v 4 Nítorí èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd* Olódùmarè wí.
\q1 “Ní ìgbà àkọ́kọ́ àwọn ènìyàn mi sọ̀kalẹ̀
\q2 lọ sí Ejibiti láti gbé;
\q2 láìpẹ́ ni Asiria pọ́n wọn lójú.
\p
\v 5 \x - \xo 52.5: \xt Ro 2.24.\x*“Àti ní àkókò yìí, kí ni mo ní níbí?” ni \nd Olúwa\nd* wí.
\q1 “Nítorí a ti kó àwọn ènìyàn mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́,
\q2 àwọn tí ó sì ń jẹ ọba lórí wọn fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,”
\q2 ni \nd Olúwa\nd* wí.
\q1 “Àti ní ọjọọjọ́
\q2 orúkọ mi ni asọ̀rọ̀-òdì sí nígbà gbogbo.
\q1
\v 6 Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi;
\q2 nítorí ní ọjọ́ náà, wọn yóò mọ̀
\q1 pé, Èmi ni ó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀.
\q2 Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi ni.”
\b
\q1
\v 7 \x - \xo 52.7: \xt Ap 10.36; Ro 10.15; Ef 6.15.\x*Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkè
\q2 ẹsẹ̀ àwọn tí ó mú ìyìnrere ayọ̀ wá,
\q1 tí wọ́n kéde àlàáfíà,
\q2 tí ó mú ìyìnrere wá,
\q1 tí ó kéde ìgbàlà,
\q2 tí ó sọ fún Sioni pé,
\q2 “Ọlọ́run rẹ ń jẹ ọba!”
\q1
\v 8 Tẹ́tí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn sókè
\q2 wọ́n kígbe papọ̀ fún ayọ̀.
\q1 Nígbà tí \nd Olúwa\nd* padà sí Sioni,
\q2 wọn yóò rí i pẹ̀lú ojú u wọn.
\q1
\v 9 Ẹ bú sí orin ayọ̀ papọ̀,
\q2 ẹ̀yin ahoro Jerusalẹmu,
\q1 nítorí \nd Olúwa\nd* ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú,
\q2 ó sì ti ra Jerusalẹmu padà.
\q1
\v 10 \x - \xo 52.10: \xt Lk 2.30; 3.6.\x*\nd Olúwa\nd* yóò ṣí apá mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀
\q2 ní ojú gbogbo orílẹ̀-èdè,
\q1 àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò rí
\q2 ìgbàlà Ọlọ́run wa.
\b
\q1
\v 11 \x - \xo 52.11: \xt 2Kọ 6.17.\x*Ẹ túká, ẹ túká, ẹ jáde kúrò níhìn-ín yìí!
\q2 Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan!
\q1 Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ kí ẹ sì di mímọ́,
\q2 ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 12 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò yára kúrò
\q2 tàbí kí ẹ sáré lọ;
\q1 nítorí \nd Olúwa\nd* ni yóò síwájú yín lọ,
\q2 Ọlọ́run Israẹli ni yóò sì ṣe ààbò lẹ́yìn ín yín.
\s1 Ìpọ́njú àti ògo ìránṣẹ́ náà
\q1
\v 13 Kíyèsi i, ìránṣẹ́ mi yóò hùwà ọlọ́gbọ́n;
\q2 òun ni a ó gbé sókè tí a ó sì gbéga
\q2 a ó sì gbé e lékè gidigidi.
\q1
\v 14 Gẹ́gẹ́ bí a ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n ń bu ọlá fún un—
\q2 ìwò ojú rẹ ni a ti bàjẹ́ kọjá ti ẹnikẹ́ni àti ìrísí rẹ̀ ní a ti bàjẹ́ kọjá ohun tí ènìyàn ń fẹ́.
\q1
\v 15 \x - \xo 52.15: \xt Ro 15.21.\x*Bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe bomirin àwọn orílẹ̀-èdè ká,
\q2 àwọn ọba yóò sì pa ẹnu wọn mọ́ nítorí rẹ̀.
\q1 Nítorí ohun tí a kò sọ fún wọn, wọn yóò rí i,
\q2 àti ohun tí wọn kò tí ì gbọ́, ni yóò sì yé wọn.
\b
\c 53
\q1
\v 1 \x - \xo 53.1: \xt Jh 12.38; Ro 10.16.\x*Ta ni ó ti gba ìròyìn in wa gbọ́
\q2 àti ta ni a ti fi apá \nd Olúwa\nd* hàn fún?
\q1
\v 2 Òun dàgbàsókè níwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ irúgbìn,
\q2 àti gẹ́gẹ́ bí i gbòǹgbò tí ó jáde láti inú ìyàngbẹ ilẹ̀.
\q1 Òun kò ní ẹwà tàbí ògo láti fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀,
\q2 kò sí ohun kankan nínú àbùdá rẹ̀
\q2 tí ó fi yẹ kí a ṣàfẹ́rí i rẹ̀.
\q1
\v 3 A kẹ́gàn rẹ̀ àwọn ènìyàn sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
\q2 ẹni ìbànújẹ́, tí ó sì mọ bí ìpọ́njú ti rí.
\q1 Gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan tí àwọn ènìyàn ń fojú pamọ́ fún
\q2 a kẹ́gàn rẹ, a kò sì bu ọlá fún un rárá.
\b
\q1
\v 4 \x - \xo 53.4: \xt Mt 8.17.\x*Lóòtítọ́ ó ti ru àìlera wa lọ
\q2 ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa pẹ̀lú,
\q1 síbẹ̀ a kà á sí ẹni tí Ọlọ́run lù,
\q2 tí ó lù, tí a sì pọ́n lójú.
\q1
\v 5 \x - \xo 53.5-6: \xt 1Pt 2.24-25.\x*Ṣùgbọ́n a sá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedéédéé wa
\q2 a pa á lára nítorí àìṣòdodo wa;
\q1 ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lórí i rẹ̀,
\q2 àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi mú wa láradá.
\q1
\v 6 Gbogbo wa bí àgùntàn, ti ṣìnà lọ,
\q2 ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti yà sí ọ̀nà ara rẹ̀;
\q1 \nd Olúwa\nd* sì ti gbé e ka orí ara rẹ̀
\q2 gbogbo àìṣedéédéé wa.
\b
\q1
\v 7 \x - \xo 53.7-8: \xt Ap 8.32-33.\x*A jẹ ẹ́ ní yà, a sì pọ́n ọn lójú,
\q2 síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀;
\q1 a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà,
\q2 àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀,
\q2 síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀.
\q1
\v 8 Pẹ̀lú ìpọ́nlójú àti ìdánilẹ́jọ́ ni a mú un jáde lọ,
\q2 ta ni ó sì le sọ nípa ìrànlọ́wọ́ rẹ̀?
\q1 Nítorí a ké e kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè;
\q2 nítorí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn mi ni a ṣe lù ú.
\q1
\v 9 \x - \xo 53.9: \xt 1Pt 2.22.\x*A fún un ní ibojì pẹ̀lú àwọn ìkà,
\q2 àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀ ní ikú rẹ̀,
\q1 bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò hùwà jàgídíjàgan kan,
\q2 tàbí kí a rí ẹ̀tàn kan ní ẹnu rẹ̀.
\b
\q1
\v 10 Síbẹ̀, ó wu \nd Olúwa\nd* láti pa á lára
\q2 àti láti mú kí ó jìyà,
\q1 bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé \nd Olúwa\nd* fi ayé rẹ̀
\q2 fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,
\q1 Òun yóò rí àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àti ọjọ́ ayé
\q2 rẹ̀ yóò pẹ́ títí,
\q2 àti ète \nd Olúwa\nd* ni yóò gbèrú ní ọwọ́ rẹ̀.
\q1
\v 11 Lẹ́yìn ìpọ́njú ẹ̀mí rẹ̀,
\q2 òun yóò rí ìmọ́lẹ̀, ààyè yóò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn;
\q1 nípa ìmọ̀ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yóò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre,
\q2 Òun ni yóò sì ru àìṣedéédéé wọn.
\q1
\v 12 \x - \xo 53.12: \xt Lk 22.37.\x*Nítorí náà èmi yóò fún un ní ìpín pẹ̀lú àwọn ẹni ńlá
\q2 òun yóò sì pín ìkógun pẹ̀lú àwọn alágbára,
\q1 nítorí pé òun jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ fún ikú,
\q2 tí a sì kà á mọ́ àwọn alárékọjá.
\q1 Nítorí ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀,
\q2 ó sì ṣe ìlàjà fún àwọn alárékọjá.
\c 54
\s1 Ògo ọjọ́ iwájú ti Sioni
\q1
\v 1 \x - \xo 54.1: \xt Ga 4.27.\x*“Kọrin, ìwọ obìnrin àgàn,
\q2 ìwọ tí kò tí ì bímọ rí;
\q1 bú sí orin, ẹ hó fún ayọ̀,
\q2 ẹ̀yin tí kò tí ì rọbí rí;
\q1 nítorí pé púpọ̀ ni ọmọ àwọn obìnrin ìsọdahoro
\q2 ju ti ẹni tí ó ní ọkọ,”
\q2 ni \nd Olúwa\nd* wí.
\q1
\v 2 Fẹ ibi àgọ́ rẹ lójú sí i,
\q2 fẹ aṣọ àgọ́ rẹ kí ó gbòòrò sí i,
\q1 má ṣe dá a dúró;
\q2 sọ okùn rẹ di gígùn,
\q2 mú òpó rẹ lágbára sí i.
\q1
\v 3 Nítorí ìwọ ó fẹ̀ sọ́tùn àti sí òsì;
\q2 ìrandíran rẹ yóò jogún àwọn orílẹ̀-èdè,
\q2 wọn yóò sì dó sí ahoro àwọn ìlú wọn.
\b
\q1
\v 4 “Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́.
\q2 Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù.
\q1 Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe e rẹ,
\q2 ìwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìgba-opo rẹ mọ́.
\q1
\v 5 Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ
\q2 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀
\q1 Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ;
\q2 a sì ń pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.
\q1
\v 6 \nd Olúwa\nd* yóò pè ọ́ padà
\q2 àfi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀
\q1 tí a sì bà lọ́kàn jẹ́
\q2 obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́,
\q2 tí a sì wá jákulẹ̀,” ni \nd Olúwa\nd* wí.
\q1
\v 7 “Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
\q2 ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóò
\q2 mú ọ padà wá.
\q1
\v 8 Ní ríru ìbínú.
\q2 Mo fi ojú pamọ́ fún ọ fún ìṣẹ́jú kan,
\q1 ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú àìnípẹ̀kun
\q2 Èmi yóò síjú àánú wò ọ́,”
\q2 ni \nd Olúwa\nd* Olùdáǹdè rẹ wí.
\b
\q1
\v 9 “Sí mi, èyí dàbí i àwọn ọjọ́ Noa,
\q2 nígbà tí mo búra pé àwọn omi
\q1 Noa kì yóò tún bo ilẹ̀ ayé mọ́.
\q2 Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí mo ti búra láti má ṣe bínú sí ọ,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá ọ wí mọ́.
\q1
\v 10 Bí a tilẹ̀ mi àwọn òkè ńlá
\q2 tí a sì ṣí àwọn òkè kékeré nídìí,
\q1 síbẹ̀síbẹ̀ ìfẹ́ àìkùnà mi fún ọ kì yóò yẹ̀ láéláé
\q2 tàbí májẹ̀mú àlàáfíà ni a ó mú kúrò,”
\q2 ni \nd Olúwa\nd*, ẹni tí ó síjú àánú wò ọ́ wí.
\b
\q1
\v 11 \x - \xo 54.11-12: \xt If 21.19.\x*Ìwọ ìlú tí a pọ́n lójú, tí ìjì ń gbá kiri
\q2 tí a kò sì tù nínú,
\q1 Èmi yóò fi òkúta Tikuosi kọ́ ọ
\q2 àti ìpìlẹ̀ rẹ pẹ̀lú safire.
\q1
\v 12 Èmi yóò fi iyùn ṣe odi rẹ,
\q2 àwọn ẹnu-ọ̀nà ni a ó fi ohun èlò dáradára fún,
\q2 àti àwọn ògiri rẹ pẹ̀lú òkúta iyebíye.
\q1
\v 13 \x - \xo 54.13: \xt Jh 6.45.\x*Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ ni \nd Olúwa\nd* yóò kọ́,
\q2 àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò jẹ́ ńlá àti púpọ̀.
\q1
\v 14 Ní òdodo ni a ó fi ìdí rẹ kalẹ̀
\q2 ìwà ipá yóò jìnnà sí ọ
\q1 o kò ní bẹ̀rù ohunkóhun,
\q2 ìpayà la ó mú kúrò pátápátá;
\q2 kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.
\q1
\v 15 Bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ bá ọ jà, kò ní jẹ́ láti ọwọ́ mi;
\q2 ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ọ jà ni yóò túúbá fún ọ.
\b
\q1
\v 16 “Kíyèsi i, èmi ni ó dá alágbẹ̀dẹ
\q2 tí ń fẹ́ iná èédú iná
\q2 tí ó sì ń mú ohun èlò wá tí ó bá iṣẹ́ rẹ mu.
\q1 Èmi náà sì ni ẹni tí ó dá apanirun láti ṣe iṣẹ́ ibi;
\q2
\v 17 kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yóò lè ṣe nǹkan,
\q2 àti gbogbo ahọ́n tí ó dìde sí ọ ní ìdájọ́ ni ìwọ ó dá ní ẹ̀bi.
\q1 Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ \nd Olúwa\nd*,
\q2 èyí sì ni ìdáláre wọn láti ọ̀dọ̀ mi,”
\q2 ni \nd Olúwa\nd* wí.
\c 55
\s1 Ìpè sí àwọn tí òrùngbẹ n gbẹ
\q1
\v 1 \x - \xo 55.1: \xt If 21.6; 22.17.\x*“Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin tí òǹgbẹ ń gbẹ,
\q2 ẹ wá sí ibi omi;
\q1 àti ẹ̀yin tí kò ní owó;
\q2 ẹ wá, ẹ rà kí ẹ sì jẹ!
\q1 Ẹ wá ra wáìnì àti wàrà
\q2 láìsí owó àti láìdíyelé.
\q1
\v 2 Èéṣe tí ẹ fi ń ná owó fún èyí tí kì í ṣe àkàrà
\q2 àti làálàá yín lórí ohun tí kì í tẹ́nilọ́rùn?
\q1 Tẹ́tí sílẹ̀, tẹ́tí sí mi, kí ẹ sì jẹ èyí tí ó dára,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín yóò láyọ̀ nínú ọrọ̀ tí ó bójúmu.
\q1
\v 3 \x - \xo 55.3: \xt Ap 13.34; Hb 13.20.\x*Tẹ́tí sílẹ̀ kí o sì wá sọ́dọ̀ mi;
\q2 gbọ́ tèmi, kí ọkàn rẹ lè wà láààyè.
\q1 Èmi yóò dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú rẹ,
\q2 ìfẹ́ òtítọ́ tí mo ṣèlérí fún Dafidi.
\q1
\v 4 Kíyèsi i, mo ti fi òun ṣe ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn,
\q2 olórí àti apàṣẹ fún àwọn ènìyàn.
\q1
\v 5 Lóòtítọ́ ìwọ yóò ké sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀
\q2 àti orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀ ni yóò sáré tọ̀ ọ́ wá,
\q1 nítorí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ
\q2 Ẹni Mímọ́ Israẹli
\q2 nítorí pé ó ti fi ohun dídára dá ọ lọ́lá.”
\b
\q1
\v 6 Ẹ wá \nd Olúwa\nd* nígbà tí ẹ lè rí i;
\q2 ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.
\q1
\v 7 Jẹ́ kí ìkà kí ó kọ ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀
\q2 àti ènìyàn búburú èrò rẹ̀.
\q1 Jẹ́ kí ó yípadà sí \nd Olúwa\nd*, Òun yóò sì ṣàánú fún un,
\q2 àti sí Ọlọ́run wa, nítorí Òun yóò sì dáríjì.
\b
\q1
\v 8 “Nítorí èrò mi kì í ṣe èrò yín,
\q2 tàbí ọ̀nà yín a ha máa ṣe ọ̀nà mi,”
\q2 ni \nd Olúwa\nd* wí.
\q1
\v 9 “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín lọ
\q2 àti èrò mi ju èrò yín lọ.
\q1
\v 10 \x - \xo 55.10: \xt 2Kọ 9.10.\x*Gẹ́gẹ́ bí òjò àti yìnyín
\q2 ti wálẹ̀ láti ọ̀run
\q1 tí kì í sì padà sí ibẹ̀
\q2 láì bomirin ilẹ̀
\q1 kí ó sì mú kí ó tanná kí ó sì rudi,
\q2 tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi mú irúgbìn fún afúnrúgbìn
\q2 àti àkàrà fún ọ̀jẹun,
\q1
\v 11 bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó jáde láti ẹnu mi wá;
\q2 kì yóò padà sọ́dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo,
\q1 ṣùgbọ́n yóò ṣe ohun tí mo fẹ́,
\q2 yóò sì mú ète mi tí mo fi rán an wá sí ìmúṣẹ.
\q1
\v 12 Ẹ̀yin yóò jáde lọ ní ayọ̀
\q2 a ó sì darí i yín lọ ní àlàáfíà;
\q1 òkè ńlá ńlá àti kéékèèké
\q2 yóò bú sí orin níwájú yín
\q1 àti gbogbo igi inú pápá
\q2 yóò máa pàtẹ́wọ́.
\q1
\v 13 Dípò igi ẹ̀gún ni igi junifa yóò máa dàgbà,
\q2 àti dípò ẹ̀wọ̀n, maritili ni yóò yọ.
\q1 Èyí yóò wà fún òkìkí \nd Olúwa\nd*,
\q2 fún àmì ayérayé,
\q2 tí a kì yóò lè parun.”
\c 56
\s1 Ìgbàlà fún àwọn mìíràn
\p
\v 1 Èyí ni ohun ti \nd Olúwa\nd* sọ:
\q1 “Ẹ pa ìdájọ́ mọ́
\q2 ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ̀nà,
\q1 nítorí ìgbàlà mi súnmọ́ tòsí
\q2 àti òdodo mi ni a ó fihàn láìpẹ́ jọjọ.
\q1
\v 2 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣe èyí,
\q2 àti fún ọmọ ènìyàn tí ó dìímú ṣinṣin,
\q1 tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́,
\q2 tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi ṣíṣe.”
\b
\q1
\v 3 Má ṣe jẹ́ kí àjèjì kan tí ó ti di ara rẹ̀
\q2 mọ́ \nd Olúwa\nd* sọ wí pé,
\q1 “\nd Olúwa\nd* yóò yà mí sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.”
\q1 Àti kí ìwẹ̀fà kan ṣe àròyé pé,
\q2 “Igi gbígbẹ lásán ni mí.”
\p
\v 4 Nítorí pé báyìí ni \nd Olúwa\nd* wí:
\q1 “Sí àwọn ìwẹ̀fà yìí tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́,
\q2 tí wọ́n yan ohun tí ó dùn mọ́ mi
\q2 tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin
\q1
\v 5 fún wọn ni Èmi yóò fún nínú tẹmpili àti àgbàlá rẹ̀
\q2 ìrántí kan àti orúkọ kan
\q1 tí ó sàn ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin,
\q2 Èmi yóò fún wọn ní orúkọ ayérayé
\q2 tí a kì yóò ké kúrò.
\q1
\v 6 Àti àwọn àjèjì tí ó so ara wọn mọ́ \nd Olúwa\nd*
\q2 láti sìn ín,
\q1 láti fẹ́ orúkọ \nd Olúwa\nd*
\q2 àti láti foríbalẹ̀ fún un
\q1 gbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́
\q2 àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin—
\q1
\v 7 \x - \xo 56.7: \xt Mt 21.13; Mk 11.17; Lk 19.46.\x*àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mi,
\q2 èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi.
\q1 Ẹbọ sísun wọn àti ìrúbọ wọn,
\q2 ni a ó tẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi;
\q1 nítorí a ó máa pe ilé mi ní
\q2 ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀-èdè.”
\q1
\v 8 \nd Olúwa\nd* Olódùmarè sọ wí pé—
\q2 ẹni tí ó kó àwọn àtìpó Israẹli jọ:
\q1 “Èmi yóò kó àwọn mìíràn jọ pẹ̀lú wọn
\q2 yàtọ̀ sí àwọn tí a ti kójọ.”
\s1 Ẹ̀sùn tí Ọlọ́run fi kan àwọn ìkà
\q1
\v 9 Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú pápá,
\q2 ẹ wá jẹ àwọn ẹranko inú igbó run!
\q1
\v 10 Àwọn olùṣọ́ Israẹli fọ́jú,
\q2 gbogbo wọn ṣe aláìní ìmọ̀;
\q1 gbogbo wọn jẹ́ adití ajá,
\q2 wọn kò lè gbó;
\q1 wọ́n sùn sílẹ̀ wọ́n ń lálàá,
\q2 wọ́n fẹ́ràn láti máa sùn.
\q1
\v 11 Wọ́n jẹ́ àwọn ajá tí ó kúndùn púpọ̀;
\q2 wọn kì í ní ànító.
\q1 Wọ́n jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn tí kò ní òye;
\q2 olúkúlùkù ń yà ṣọ́nà ara rẹ̀,
\q2 ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sì wá ère tirẹ̀.
\q1
\v 12 Igbe ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ni wí pé, “Wá, fún mi ní ọtí wáìnì!
\q2 Jẹ́ kí a mu ọtí líle wa lámu yó
\q1 ọ̀la yóò sì dàbí òní,
\q2 tàbí kí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ.”
\b
\b
\c 57
\q1
\v 1 Olódodo ṣègbé
\q2 kò sí ẹnìkan tí ó rò ó lọ́kàn ara rẹ̀;
\q1 a mú àwọn ẹni mímọ́ lọ,
\q2 kò sì ṣí ẹni tó yé
\q1 pé a ti mú àwọn olódodo lọ
\q2 láti yọ wọ́n kúrò nínú ibi.
\q1
\v 2 Gbogbo àwọn tí ń rìn déédé
\q2 ń wọ inú àlàáfíà;
\q2 wọ́n rí ìsinmi bí wọ́n ti ń sùn nínú ikú.
\b
\q1
\v 3 “Ṣùgbọ́n ẹ súnmọ́ ìhìn-ín, ẹ̀yin ọmọ aláfọ̀ṣẹ,
\q2 ẹ̀yin irú-ọmọ panṣágà àti àgbèrè!
\q1
\v 4 Ta ni ó fi ń ṣẹlẹ́yà?
\q2 Ta ni o ń yọ ṣùtì sí
\q2 tí o sì yọ ahọ́n síta?
\q1 Ẹ̀yin kì í ha ṣe ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn bí,
\q2 àti ìran àwọn òpùrọ́?
\q1
\v 5 Ẹ gbinájẹ fún ìṣekúṣe láàrín igi óákù
\q2 àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀;
\q1 ẹ fi àwọn ọmọ yín rú ẹbọ nínú kòtò jíjìn
\q2 àti lábẹ́ àwọn pàlàpálá òkúta.
\q1
\v 6 Àwọn ère tí ó wà ní àárín òkúta dídán
\q2 wọ́n n nì, nínú kòtò jíjìn ni ìpín in yín;
\q1 àwọ̀n ni ìpín in yín.
\q2 Bẹ́ẹ̀ ni, sí wọn ni ẹ ti ta ọrẹ ohun mímu yín sílẹ̀
\q1 àti láti ta ọrẹ ìyẹ̀fun.
\q2 Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó yẹ
\q2 kí n dáwọ́ dúró?
\q1
\v 7 Ìwọ ti ṣe ibùsùn rẹ lórí òkè gíga tí ó rẹwà;
\q2 níbẹ̀ ni ẹ lọ láti lọ ṣe ìrúbọ yín.
\q1
\v 8 Lẹ́yìn àwọn ìlẹ̀kùn yín àti òpó ìlẹ̀kùn yín
\q2 níbẹ̀ ni ẹ fi àwọn àmì òrìṣà yín sí.
\q1 Ní kíkọ̀ mí sílẹ̀, ẹ ṣí ibùsùn yín sílẹ̀,
\q2 ẹ gun orí rẹ̀ lọ, ẹ sì ṣí i sílẹ̀ gbagada;
\q1 ẹ ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn tí ẹ fẹ́ràn ibùsùn wọn,
\q2 ẹ̀yin sì ń wo ìhòhò wọn.
\q1
\v 9 Ẹ̀yin lọ sí Moleki pẹ̀lú òróró olifi
\q2 ẹ sì fi kún òórùn dídùn yín.
\q1 Ẹ rán ikọ̀ yín lọ jìnnà réré;
\q2 ẹ sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú!
\q1
\v 10 Àwọn ọ̀nà yín gbogbo ti mú àárẹ̀ ba á yín,
\q1 ṣùgbọ́n ẹ kò ní sọ pé, Kò sí ìrètí mọ́?
\q2 Ẹ rí okun kún agbára yín,
\q2 nípa bẹ́ẹ̀ òòyì kò kọ́ ọ yín.
\b
\q1
\v 11 “Ta ni ó ń pá yín láyà tí ń bà yín lẹ́rù
\q2 tí ẹ fi ń ṣèké sí mi,
\q1 àti tí ẹ̀yin kò fi rántí mi
\q2 tàbí kí ẹ rò yí nínú ọkàn yín?
\q1 Ǹjẹ́ kì í ṣe nítorí dídákẹ́ jẹ́ẹ́ mi fún ìgbà pípẹ́
\q2 tí ẹ̀yin kò fi bẹ̀rù mi?
\q1
\v 12 Èmi yóò ṣí òdodo yín páyà àti iṣẹ́ yín,
\q2 wọn kì yóò sì ṣe yín ní àǹfààní.
\q1
\v 13 Nígbà tí ẹ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́
\q2 ẹ jẹ́ kí àkójọ àwọn ère yín gbà yín!
\q1 Atẹ́gùn yóò gbá gbogbo wọn lọ,
\q2 èémí lásán làsàn ni yóò gbá wọn lọ.
\q1 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi mí ṣe ààbò rẹ̀
\q2 ni yóò jogún ilẹ̀ náà
\q2 yóò sì jogún òkè mímọ́ mi.”
\s1 Ìtùnú fún àwọn oníròbìnújẹ́
\p
\v 14 A ó sì sọ wí pé:
\q1 “Tún mọ, tún mọ, tún ọ̀nà náà ṣe!
\q2 Ẹ mú àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi.”
\q1
\v 15 \x - \xo 57.15: \xt Mt 5.3.\x*Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí
\q2 ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́:
\q1 “Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́,
\q2 ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀,
\q1 láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí
\q2 àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí.
\q1
\v 16 Èmi kì yóò fẹ̀sùn kan ni títí láé,
\q2 tàbí kí n máa bínú sá á,
\q1 nítorí nígbà náà ni ọkàn ènìyàn yóò
\q2 rẹ̀wẹ̀sì níwájú mi
\q2 èémí ènìyàn tí mo ti dá.
\q1
\v 17 Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúwà rẹ̀;
\q2 mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojú mi pamọ́ ní ìbínú;
\q2 síbẹ̀, ó tẹ̀síwájú nínú tinú-mi-ni n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀.
\q1
\v 18 Èmi ti rí ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ṣùgbọ́n Èmi yóò wò ó sàn;
\q2 Èmi yóò tọ́ ọ ṣọ́nà n ó sì mú ìtùnú tọ̀ ọ́ wá,
\q1
\v 19 \x - \xo 57.19: \xt Ap 2.39; Ef 2.13,17.\x*ní dídá ìyìn sí ètè àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli.
\q2 Àlàáfíà, àlàáfíà fún àwọn tí ó wà lókèèrè àti nítòsí,”
\q2 ni \nd Olúwa\nd* wí, “Àti pé, Èmi yóò wo wọ́n sàn.”
\q1
\v 20 Ṣùgbọ́n àwọn ìkà dàbí i ríru Òkun
\q2 tí kò le è sinmi,
\q2 tí ìgbì rẹ̀ ń rú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ àti ẹrọ̀fọ̀ sókè.
\q1
\v 21 “Kò sí àlàáfíà fún àwọn ìkà,” ni Ọlọ́run mi wí.
\c 58
\s1 Àwẹ̀ tòótọ́
\q1
\v 1 “Kígbe rẹ̀ sókè, má ṣe fàsẹ́yìn.
\q2 Gbé ohùn rẹ sókè bí i ti fèrè.
\q1 Jẹ́ kí ó di mí mọ̀ fún àwọn ènìyàn mi, ọ̀tẹ̀ wọn,
\q2 àti fún ilé Jakọbu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
\q1
\v 2 Nítorí ọjọ́ dé ọjọ́ ni wọ́n ń wá mi kiri;
\q2 wọ́n ṣe bí ẹni ní ìtara láti mọ ọ̀nà mi,
\q1 àfi bí ẹni pé wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà
\q2 tí òun kò sì tí ì kọ àṣẹ Ọlọ́run rẹ̀.
\q1 Wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ mi fún ìpinnu nìkan
\q2 wọ́n sì ṣe bí ẹni ń tara fún Ọlọ́run láti súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn.
\q1
\v 3 Wọ́n wí pé, Èéṣe tí àwa fi ń gbààwẹ̀,
\q2 tí ìwọ kò sì tí ì rí?
\q1 Èéṣe tí àwa fi rẹra wa sílẹ̀,
\q2 tí ìwọ kò sì tí ì ṣe àkíyèsí?
\b
\q1 “Síbẹ̀síbẹ̀ ní ọjọ́ àwẹ̀ yín, ẹ̀yin ń ṣe bí ó ti wù yín
\q2 ẹ sì ń pọ́n àwọn òṣìṣẹ́ yín gbogbo lójú.
\q1
\v 4 Àwẹ̀ yín sì parí nínú ìjà àti asọ̀,
\q2 àti lílu ọmọnìkejì ẹni pa pẹ̀lú ìkùùkuu.
\q1 Ẹ̀yin kò le è gbààwẹ̀ bí ẹ ti ń ṣe lónìí
\q2 kí ẹ sì retí kí a gbọ́ ohùn un yín ní ibi gíga.
\q1
\v 5 Ǹjẹ́ èyí ha ni irú àwẹ̀ tí mo yàn bí,
\q2 ọjọ́ kan ṣoṣo fún ènìyàn láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀?
\q1 Ó ha jẹ pe kí ènìyàn tẹ orí rẹ̀ ba bí i koríko lásán ni bí
\q2 àti sísùn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú?
\q1 Ṣé ohun tí ẹ̀ ń pè ní àwẹ̀ nìyí,
\q2 ọjọ́ ìtẹ́wọ́gbà fún \nd Olúwa\nd*?
\b
\q1
\v 6 \x - \xo 58.6: \xt Ap 8.23.\x*“Ǹjẹ́ irú àwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí:
\q2 láti já gbogbo ẹ̀wọ̀n àìṣòdodo
\q1 àti láti tú gbogbo okùn àjàgà,
\q2 láti tú gbogbo àwọn ti à ń ni lára sílẹ̀
\q2 àti láti fọ́ gbogbo àjàgà?
\q1
\v 7 Kì í ha á ṣe láti pín oúnjẹ yín fún àwọn tí ebi ń pa
\q2 àti láti pèsè ibùgbé fún àwọn òtòṣì tí ń rìn káàkiri.
\q1 Nígbà tí ẹ bá rí ẹni tí ó wà níhòhò, láti daṣọ bò ó,
\q2 àti láti má ṣe lé àwọn ìbátan yín sẹ́yìn?
\q1
\v 8 Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ rẹ yóò tàn jáde bí òwúrọ̀
\q2 àti ìmúláradá rẹ yóò farahàn kíákíá;
\q1 nígbà náà ni òdodo rẹ yóò sì lọ níwájú rẹ,
\q2 ògo \nd Olúwa\nd* yóò sì jẹ́ ààbò lẹ́yìn rẹ.
\q1
\v 9 Nígbà yìí ni ẹ̀yin yóò pè, tí \nd Olúwa\nd* yóò sì dáhùn;
\q2 ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé, Èmi nìyí.
\b
\q1 “Bí ìwọ bá mú àjàgà aninilára,
\q2 nínà ìka àlébù àti sísọ ọ̀rọ̀ asán kúrò láàrín rẹ,
\q1
\v 10 àti bí ẹ̀yin bá ná ara yín bí owó nítorí àwọn tí ebi ń pa
\q2 tí ẹ sì tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí à ń ni lára lọ́rùn,
\q1 nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóò ràn nínú òkùnkùn,
\q2 àti òru yín yóò dàbí ọ̀sán gangan.
\q1
\v 11 \nd Olúwa\nd* yóò máa tọ́ ọ yín nígbà gbogbo;
\q2 òun yóò tẹ́ gbogbo àìní yín lọ́rùn ní ilẹ̀ tí oòrùn ń tan ìmọ́lẹ̀
\q1 yóò sì fún egungun rẹ lókun.
\q2 Ìwọ yóò sì dàbí ọgbà tí a bomirin dáradára,
\q2 àti bí orísun tí omi rẹ̀ kì í gbẹ.
\q1
\v 12 Àwọn ènìyàn rẹ yóò tún ahoro àtijọ́ kọ́
\q2 wọn yóò sì gbé ìpìlẹ̀ àtijọ́-tijọ́ ró
\q1 a ó sì pè ọ́ ní alátúnṣe ògiri tí ó ti wó
\q2 àti olùmúbọ̀sípò àwọn òpópónà tí ènìyàn gbé inú rẹ̀.
\b
\q1
\v 13 “Bí ìwọ bá pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú bíba ọjọ́ ìsinmi jẹ́,
\q2 àti ṣíṣe bí ó ti wù ọ́ ni ọjọ́ mímọ́ mi,
\q1 bí ìwọ bá pe ọjọ́ ìsinmi ní ohun dídùn
\q2 àti ọjọ́ mímọ́ \nd Olúwa\nd* ní ohun ọ̀wọ̀
\q1 àti bí ìwọ bá bu ọlá fún un láti máa bá ọ̀nà tìrẹ lọ
\q2 àti láti má ṣe bí ó ti wù ọ́ tàbí
\q2 kí o máa sọ̀rọ̀ aláìníláárí,
\q1
\v 14 nígbà náà ni ìwọ yóò ní ayọ̀ nínú \nd Olúwa\nd* rẹ,
\q2 èmi yóò sì jẹ́ kí ìwọ kí ó máa gun ibi gíga ilẹ̀ ayé,
\q1 àti láti máa jàdídùn ìní ti
\q2 Jakọbu baba rẹ.”
\q2 Ẹnu \nd Olúwa\nd* ni ó ti sọ̀rọ̀.
\c 59
\s1 Ẹ̀ṣẹ̀, ìjẹ́wọ́ àti ìràpadà
\q1
\v 1 Lódodo ọwọ́ \nd Olúwa\nd* kò kúrú láti gbàlà,
\q2 tàbí kí etí rẹ̀ wúwo láti gbọ́.
\q1
\v 2 Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yín ló ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run yín;
\q2 ẹ̀ṣẹ̀ yín ti fi ojú u rẹ̀ pamọ́ fún un yín
\q2 tó bẹ́ẹ̀ tí òun kò fi le gbọ́.
\q1
\v 3 Nítorí ọwọ́ yín di aláìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀,
\q2 àti ìka ọwọ́ yín fún ẹ̀bi.
\q1 Ètè yín ń pa irọ́ púpọ̀,
\q2 ahọ́n yín sì ń sọ̀rọ̀ nǹkan ibi.
\q1
\v 4 Kò sí ẹni tí ó béèrè fún ìdájọ́ òdodo;
\q2 kò sí ẹni tí ó ro ẹjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́.
\q1 Wọ́n gbẹ́kẹ̀lé àwíjàre asán àti ọ̀rọ̀ irọ́;
\q2 wọ́n lóyún ìkà, wọn sì bí wàhálà.
\q1
\v 5 Wọn ń pa ẹ̀yin paramọ́lẹ̀
\q2 wọn sì ń ta owú aláǹtakùn.
\q1 Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹyin wọn yóò kú,
\q2 àti nígbà tí a pa ọ̀kan, paramọ́lẹ̀ ni ó jáde.
\q1
\v 6 Òwú wọn kò wúlò fún aṣọ rírán;
\q2 wọn kò lè fi aṣọ tí wọ́n hun bo ara wọn.
\q2 Iṣẹ́ wọn jẹ́ ti ibi, ìwà jàǹdùkú sì kún ọwọ́ wọn.
\q1
\v 7 \x - \xo 59.7-8: \xt Ro 3.15-17.\x*Ẹsẹ̀ wọn yára bọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀;
\q2 wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.
\q1 Èrò wọn sì jẹ́ èrò ibi;
\q2 ìparun àti ìdahoro ni ó wà ní ṣíṣe àmì ọ̀nà wọn.
\q1
\v 8 Ọ̀nà àlàáfíà èyí ni wọn kò mọ̀;
\q2 kò sí òdodo ní ojú ọ̀nà wọn
\q1 wọ́n ti sọ wọ́n dì ọ̀nà kọ́rọkọ̀rọ,
\q2 kò sí ẹni tí ó tọ ọ̀nà yìí tí yóò rí àlàáfíà.
\b
\q1
\v 9 Nítorí èyí ni ẹ̀tọ́ fi jìnnà sí wa,
\q2 àti tí òdodo kò fi tẹ̀ wá lọ́wọ́.
\q1 A ń wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ jẹ́ òkùnkùn;
\q2 ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n à ń rìn nínú òjìji.
\q1
\v 10 Gẹ́gẹ́ bí afọ́jú à ń táràrà lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri
\q2 tí a ń wá ọ̀nà wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí kò ní ojú.
\q1 Ní ọ̀sán gangan ni à ń kọsẹ̀ bí ẹni pé alẹ́ ni;
\q2 láàrín alágbára àwa dàbí òkú.
\q1
\v 11 Gbogbo wa là ń ké bí i beari;
\q2 àwa pohùnréré ẹkún bí àdàbà.
\q1 A ń wá ìdájọ́ òdodo ṣùgbọ́n kò sí; à ń wọ́nà fún ìtúsílẹ̀,
\q2 ṣùgbọ́n ó jìnnà réré.
\b
\q1
\v 12 Nítorí àwọn àṣìṣe wa pọ̀ níwájú rẹ,
\q2 àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń jẹ́rìí takò wá.
\q1 Àwọn àìṣedéédéé wa sì wà pẹ̀lú wa,
\q2 àwa pẹ̀lú sì mọ àìṣedéédéé wa,
\q1
\v 13 ọ̀tẹ̀ àti àrékérekè wa sí \nd Olúwa\nd*,
\q2 kíkọ ẹ̀yìn wa sí Ọlọ́run,
\q1 dídá yánpọnyánrin àti ìnilára sílẹ̀,
\q2 pípààrọ̀ tí ọkàn wa ti gbèrò síta.
\q1
\v 14 Nítorí èyí ni a ṣe lé ìdájọ́ òdodo sẹ́yìn,
\q2 àti ti òdodo dúró lókèèrè;
\q1 òtítọ́ ti ṣubú ní òpópó ọ̀nà,
\q2 òdodo kò sì le è wọlé.
\q1
\v 15 A kò rí òtítọ́ mọ́,
\q2 àti ẹni tí ó bá sá fun ibi tì di ìjẹ.
\b
\q1 \nd Olúwa\nd* wò ó ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́
\q2 pé kò sí ìdájọ́ òdodo.
\q1
\v 16 Òun rí i pé kò sí ẹnìkan,
\q2 àyà fò ó pé kò sí ẹnìkan láti ṣèrànwọ́;
\q1 nítorí apá òun tìkára rẹ̀ ló ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún ara rẹ̀,
\q2 àti òdodo òun tìkára rẹ̀ ló gbé e ró.
\q1
\v 17 \x - \xo 59.17: \xt Ef 6.14,17; 1Tẹ 5.8.\x*Ó gbé òdodo wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbàyà rẹ̀,
\q2 àti àṣíborí ìgbàlà ní orí rẹ̀;
\q1 ó gbé ẹ̀wù ẹ̀san wọ̀
\q2 ó sì yí ara rẹ̀ ní ìtara bí ẹ̀wù.
\q1
\v 18 Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n ti ṣe,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni yóò san án
\q1 ìbínú fún àwọn ọ̀tá rẹ̀
\q2 àti ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀;
\q2 òun yóò san án fún àwọn erékùṣù ẹ̀tọ́ wọn.
\q1
\v 19 \x - \xo 59.19: \xt Mt 8.11; Lk 13.29.\x*Láti ìwọ̀-oòrùn, àwọn ènìyàn yóò bẹ̀rù orúkọ \nd Olúwa\nd*,
\q2 àti láti ìlà-oòrùn, wọn yóò bọ̀wọ̀ fún ògo rẹ̀.
\q1 Nítorí òun yóò wá gẹ́gẹ́ bí i rírú omi
\q2 èyí tí èémí \nd Olúwa\nd* ń tì lọ.
\b
\q1
\v 20 \x - \xo 59.20-21: \xt Ro 11.26-27.\x*“Olùdáǹdè yóò wá sí Sioni,
\q2 sí àwọn tí ó wà ní Jakọbu tí ó
\q2 ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni \nd Olúwa\nd* wí.
\p
\v 21 “Àti fún èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn nìyìí,” ni \nd Olúwa\nd* wí, “Ẹ̀mí mi, tí ó wà nínú yín, àti ọ̀rọ̀ mi tí mo ti fi sí ẹnu yín, kì yóò kúrò lẹ́nu yín, tàbí lẹ́nu àwọn ọmọ yín, tàbí láti ẹnu àwọn ìrandíran wọn láti àkókò yìí lọ àti títí láéláé,” ni \nd Olúwa\nd* wí.
\c 60
\s1 Ògo Sioni
\q1
\v 1 “Dìde, tànmọ́lẹ̀, nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé,
\q2 ògo \nd Olúwa\nd* sì ràdàbò ọ́.
\q1
\v 2 Kíyèsi i, òkùnkùn bo ilẹ̀ ayé
\q2 òkùnkùn biribiri sì wà lórí àwọn ènìyàn,
\q1 ṣùgbọ́n \nd Olúwa\nd* ràn bò ọ́
\q2 ògo rẹ̀ sì farahàn lórí i rẹ.
\q1
\v 3 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá sí ìmọ́lẹ̀ rẹ,
\q2 àti àwọn ọba sí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ rẹ.
\b
\q1
\v 4 “Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò.
\q2 Gbogbo wọn ṣa ara jọ pọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ;
\q1 àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò wá láti ọ̀nà jíjìn,
\q2 àwọn ọmọ rẹ obìnrin ni a ó tọ́jú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ.
\q1
\v 5 Nígbà náà ni ìwọ yóò wò tí ojú rẹ yóò máa dán,
\q2 ọkàn rẹ yó fò, yó sì kún fún ayọ̀;
\q1 ọrọ̀ inú Òkun ni a ó kò wá sọ́dọ̀ rẹ,
\q2 sí ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá.
\q1
\v 6 \x - \xo 60.6: \xt Mt 2.11.\x*Ọ̀wọ́ ìbákasẹ yóò bo gbogbo ilẹ̀ rẹ,
\q2 àwọn ọ̀dọ́ ìbákasẹ Midiani àti Efani.
\q1 Àti gbogbo wọn láti Ṣeba yóò wá,
\q2 wọn yóò mú wúrà àti tùràrí lọ́wọ́
\q2 tí wọn yóò sì máa kéde ìyìn \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 7 Gbogbo agbo ẹran ìlú Kedari ni a ó kójọ sọ́dọ̀ rẹ,
\q2 àwọn àgbò ti Nebaioti yóò sìn ọ́;
\q1 wọn yóò jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni n ó sì ṣe tẹmpili ògo mi lọ́ṣọ̀ọ́.
\b
\q1
\v 8 “Ta ni àwọn wọ̀nyí tí ń fò lọ bí i kurukuru,
\q2 gẹ́gẹ́ bí àwọn àdàbà sí ìtẹ́ wọn?
\q1
\v 9 Lóòtítọ́ àwọn erékùṣù bojú wò mí;
\q2 ní ìṣíwájú ni àwọn ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi;
\q1 mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn,
\q2 pẹ̀lú fàdákà àti wúrà wọn,
\q1 fún ti ọlá \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ,
\q2 Ẹni Mímọ́ Israẹli,
\q2 nítorí òun ti fi ohun dídára ṣe ó lọ́ṣọ̀ọ́.
\b
\b
\q1
\v 10 “Àwọn àjèjì yóò tún ògiri rẹ mọ
\q2 àwọn ọba wọn yóò sì sìn ọ́.
\q1 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ìbínú ni mo lù ọ́,
\q2 ní àánú èmi yóò ṣe inú rere sí ọ.
\q1
\v 11 \x - \xo 60.11: \xt If 21.25-26.\x*Gbogbo ẹnu-bodè rẹ ni yóò wà ní ṣíṣí sílẹ̀,
\q2 a kì yóò tì wọ́n ní ọ̀sán àti ní òru,
\q1 tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọkùnrin yóò le è kó
\q2 ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè wá
\q1 tí àwọn ọba wọn yóò ṣáájú ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ìṣẹ́gun.
\q1
\v 12 Nítorí pé orílẹ̀-èdè tàbí ilẹ̀ ọba tí kì yóò sìn ọ́ ni yóò parun;
\q2 pátápátá ni yóò sì dahoro.
\b
\q1
\v 13 “Ògo Lebanoni yóò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,
\q2 igi junifa, firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀,
\q1 láti bu ọlá fún ilé ìsìn mi;
\q2 àti pé èmi yóò sì ṣe ibi ẹsẹ̀ mi lógo.
\q1
\v 14 \x - \xo 60.14: \xt If 3.9.\x*Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àwọn apọ́nilójú rẹ yóò
\q2 wá foríbalẹ̀ fún ọ;
\q1 gbogbo àwọn tí ó ti kẹ́gàn rẹ ni wọn yóò tẹríba níwájú rẹ
\q2 wọn yóò sì pè ọ́ ní ìlú \nd Olúwa\nd*,
\q2 Sioni ti Ẹni Mímọ́ Israẹli.
\b
\q1
\v 15 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kórìíra rẹ, a sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
\q2 láìsí ẹnìkan tí ó ń gba ọ̀dọ̀ rẹ kọjá,
\q1 Èmi yóò ṣe ọ́ ní ìṣògo ayérayé
\q2 àti ayọ̀ àtìrandíran.
\q1
\v 16 Ìwọ yóò mu wàrà gbogbo orílẹ̀-èdè
\q2 a ó sì fun ọ́ ni ọmú àwọn ọba.
\q1 Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé, Èmi \nd Olúwa\nd*,
\q2 èmi ni Olùgbàlà rẹ,
\q2 Olùdáǹdè rẹ, Alágbára ti Jakọbu.
\q1
\v 17 Dípò idẹ, èmi ó mú wúrà wá fún ọ,
\q2 dípò fàdákà èmi ó mú irin wá. Dípò igi yóò mú idẹ wá fún ọ,
\q1 àti irin dípò òkúta.
\q2 Èmi yóò fi àlàáfíà ṣe àwọn ìjòyè rẹ
\q2 àti òdodo gẹ́gẹ́ bí alákòóso rẹ.
\q1
\v 18 A kì yóò gbọ́ nípa rògbòdìyàn ní ilẹ̀ rẹ mọ́,
\q2 tàbí ìdahoro àti ìparun nínú agbègbè rẹ,
\q1 ṣùgbọ́n ìwọ yóò pe ògiri rẹ ní ìgbàlà
\q2 àti àwọn ẹnu-bodè rẹ ní ìyìn.
\q1
\v 19 Òòrùn kì yóò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ní ọ̀sán mọ́,
\q2 tàbí kí ìtànṣán òṣùpá tún ràn sí ọ mọ́,
\q1 nítorí \nd Olúwa\nd* ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ayérayé,
\q2 àti Ọlọ́run rẹ yóò jẹ́ ògo rẹ.
\q1
\v 20 Òòrùn rẹ kì yóò sì wọ̀ mọ́,
\q2 àti òṣùpá rẹ kì yóò sì wọ òòkùn mọ́;
\q1 \nd Olúwa\nd* ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé rẹ,
\q2 àti àwọn ọjọ́ arò rẹ yóò sì dópin.
\q1
\v 21 Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn ènìyàn rẹ yóò di òdodo
\q2 àwọn ni yóò sì jogún ilẹ̀ náà títí ayé.
\q1 Àwọn ni irúgbìn tí mo ti gbìn,
\q2 iṣẹ́ ọwọ́ mi,
\q2 láti fi ọláńlá mi hàn.
\q1
\v 22 Èyí tí ó kéré jù nínú yín yóò di ẹgbẹ̀rún (1,000) kan,
\q2 èyí tí ó kéré yóò di orílẹ̀-èdè ńlá.
\q1 Èmi ni \nd Olúwa\nd*;
\q2 ní àkókò rẹ̀, Èmi yóò ṣe èyí kánkán.”
\c 61
\s1 Ọdún ojúrere \nd Olúwa\nd*
\q1
\v 1 \x - \xo 61.1-2: \xt Mt 11.5; Lk 4.18-19; 7.22.\x*Ẹ̀mí \nd Olúwa\nd* Olódùmarè wà lára mi
\q2 nítorí \nd Olúwa\nd* ti fi àmì òróró yàn mí
\q1 láti wàásù ìyìnrere fún àwọn tálákà.
\q2 Ó ti rán mi láti ṣe àwòtán oníròbìnújẹ́
\q1 láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn
\q2 àti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n,
\q1
\v 2 láti kéde ọdún ojúrere \nd Olúwa\nd*
\q2 àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa,
\q2 láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú,
\q1
\v 3 àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni
\q2 láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú,
\q1 òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀,
\q2 àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn.
\q1 A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo,
\q2 irúgbìn \nd Olúwa\nd*
\q2 láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.
\b
\q1
\v 4 Wọn yóò tún àwọn ahoro àtijọ́ kọ́
\q2 wọn yóò sì mú àwọn ibi ìparun àtijọ́-tijọ́ náà bọ̀ sípò;
\q1 wọn yóò jí àwọn ahoro ìlú náà padà
\q2 tí a ti parun láti ìrandíran sẹ́yìn.
\q1
\v 5 Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ;
\q2 àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ.
\q1
\v 6 A ó sì máa pè yín ní àlùfáà \nd Olúwa\nd*,
\q2 a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa.
\q1 Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè
\q2 àti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo.
\b
\q1
\v 7 Dípò àbùkù wọn
\q2 àwọn ènìyàn mi yóò gba ìlọ́po méjì,
\q1 àti dípò àbùkù wọn
\q2 wọn yóò yọ̀ nínú ìní wọn;
\q1 bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jogún ìlọ́po méjì ní ilẹ̀ wọn,
\q2 ayọ̀ ayérayé yóò sì jẹ́ tiwọn.
\b
\q1
\v 8 “Nítorí Èmi, \nd Olúwa\nd* fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo;
\q2 mo kórìíra olè jíjà àti ẹ̀ṣẹ̀.
\q1 Ní òtítọ́ mi èmi yóò sẹ̀san fún wọn
\q2 èmi yóò sì dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú wọn.
\q1
\v 9 A ó mọ ìrandíran wọn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
\q2 àti àwọn ìran wọn láàrín àwọn ènìyàn.
\q1 Gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn yóò mọ̀ pé
\q2 wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí \nd Olúwa\nd* ti bùkún.”
\b
\q1
\v 10 Èmi yọ̀ gidigidi nínú \nd Olúwa\nd*;
\q2 ọkàn mi yọ̀ nínú Ọlọ́run mi.
\q1 Nítorí ó ti wọ̀ mí ní aṣọ ìgbàlà
\q2 ó sì ṣe mí lọ́ṣọ̀ọ́ nínú aṣọ òdodo;
\q1 gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ti ṣe orí rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ bí àlùfáà,
\q2 àti bí ìyàwó ṣe ń ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́.
\q1
\v 11 Gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ti í mú irúgbìn jáde
\q2 àti bí ọgbà ṣe ń mú irúgbìn dàgbà,
\q1 bẹ́ẹ̀ ni \nd Olúwa\nd* Olódùmarè yóò ṣe mú òdodo àti ìyìn
\q2 kí ó ru sókè níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.
\c 62
\s1 Orúkọ Sioni tuntun
\q1
\v 1 Nítorí Sioni èmi kì yóò dákẹ́,
\q2 nítorí i Jerusalẹmu èmi kì yóò sinmi ẹnu,
\q1 títí tí òdodo rẹ̀ yóò fi tàn bí òwúrọ̀,
\q2 àti ìgbàlà rẹ̀ bí i fìtílà tí ń jó geere.
\q1
\v 2 \x - \xo 62.2: \xt If 2.17.\x*Àwọn orílẹ̀-èdè yóò rí òdodo rẹ,
\q2 àti gbogbo ọba ògo rẹ
\q1 a ó sì máa pè ọ́ ní orúkọ mìíràn
\q2 èyí tí ẹnu \nd Olúwa\nd* yóò fi fún un.
\q1
\v 3 Ìwọ yóò sì jẹ́ adé dídán ní ọwọ́ \nd Olúwa\nd*,
\q2 adé ọba ní ọwọ́ Ọlọ́run rẹ.
\q1
\v 4 Wọn kì yóò pè ọ́ ní ìkọ̀sílẹ̀ mọ́
\q2 tàbí kí wọ́n pe ilẹ̀ rẹ ní ahoro.
\q1 Ṣùgbọ́n a ó máa pè ọ́ ní Hẹfsiba,
\q2 àti ilẹ̀ rẹ ní Beula;
\q1 nítorí \nd Olúwa\nd* yóò yọ́nú sí ọ
\q2 àti ilẹ̀ rẹ ni a ó gbé níyàwó.
\q1
\v 5 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùnrin tí í gbé ọ̀dọ́mọbìnrin níyàwó,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò gbé ọ níyàwó
\q1 Gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ṣe é yọ̀ lórí ìyàwó rẹ̀,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run rẹ yóò yọ̀ lórí rẹ.
\b
\q1
\v 6 Èmi ti fi olùṣọ́ ránṣẹ́ sórí odi rẹ ìwọ Jerusalẹmu;
\q2 wọn kì yóò lè dákẹ́ tọ̀sán tòru.
\q1 Ẹ̀yin tí ń ké pe \nd Olúwa\nd*,
\q2 ẹ má ṣe fúnra yín ní ìsinmi,
\q1
\v 7 àti kí ẹ má ṣe fún òun pẹ̀lú ní ìsinmi
\q2 títí tí yóò fi fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀
\q2 tí yóò sì fi ṣe ìyìn orí ilẹ̀ ayé.
\b
\q1
\v 8 \nd Olúwa\nd* ti búra pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀
\q2 àti nípa agbára apá rẹ:
\q1 “Èmi kì yóò jẹ́ kí ìyẹ̀fun rẹ
\q2 di oúnjẹ fún ọ̀tá rẹ
\q1 bẹ́ẹ̀ ni àwọn àjèjì kì yóò mu wáìnì
\q2 tuntun rẹ mọ́
\q2 èyí tí ìwọ ti ṣe làálàá fún;
\q1
\v 9 ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá kóórè rẹ̀ ni yóò jẹ ẹ́,
\q2 tí wọn ó sì yin \nd Olúwa\nd*,
\q1 àti àwọn tí wọ́n bá kó àjàrà jọ ni wọn ó mú un,
\q2 nínú àgbàlá ilé mímọ́ mi.”
\b
\q1
\v 10 Ẹ kọjá, ẹ kọjá ní ẹnu ibodè náà!
\q2 Ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn ènìyàn.
\q1 Ẹ mọ ọ́n sókè, ṣe ojú ọ̀nà òpópó!
\q2 Ẹ ṣa òkúta kúrò.
\q2 Ẹ gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè.
\b
\q1
\v 11 \nd Olúwa\nd* ti ṣe ìkéde
\q2 títí dé òpin ilẹ̀ ayé:
\q1 “Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Sioni pé,
\q2 Kíyèsi i, Olùgbàlà rẹ ń bọ̀!
\q1 Kíyèsi i, èrè ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀,
\q2 àti ẹ̀san rẹ̀ pẹ̀lú n tẹ̀lé e lẹ́yìn.’ ”
\q1
\v 12 A ó sì pè wọ́n ní Ènìyàn Mímọ́,
\q2 ẹni ìràpadà \nd Olúwa\nd*;
\q1 a ó sì máa pè ọ́ ní ìwákiri,
\q2 ìlú tí a kì yóò kọ̀sílẹ̀.
\c 63
\s1 Ọjọ́ ẹ̀san àti ìràpadà Ọlọ́run
\q1
\v 1 \x - \xo 63.1-6: \xt Isa 34; Jr 49.7-22; El 25.12-14; 35; Am 1.11-12; Ml 1.2-5.\x*Ta nì eléyìí tí ó Edomu wá,
\q2 ti òun ti aṣọ àrẹpọ́n láti Bosra wá?
\q1 Ta nì eléyìí, tí ó ní ògo nínú aṣọ rẹ̀,
\q2 tí ó ń yan bọ̀ wá nínú ọláńlá agbára rẹ̀?
\b
\q2 “Èmi ni ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú òdodo
\q2 tí ó ní ipa láti gbàlà.”
\b
\q1
\v 2 Èéṣe tí aṣọ yín fi pupa
\q2 gẹ́gẹ́ bí i tàwọn tí ń ṣiṣẹ́ ní ìfúntí?
\b
\q1
\v 3 \x - \xo 63.3: \xt If 19.15.\x*“Èmi nìkan ti dá tẹ ìfúntí wáìnì;
\q2 láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹnikẹ́ni kò sì wà pẹ̀lú mi.
\q1 Mo tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ ní ìbínú mi
\q2 mo sì tẹ̀ wọ́n rẹ́ ní ìrunú mi
\q1 ẹ̀jẹ̀ wọn sì fọ́n sí aṣọ mi,
\q2 mo sì da àbàwọ́n sí gbogbo aṣọ mi.
\q1
\v 4 Nítorí ọjọ́ ẹ̀san wà ní ọkàn mi
\q2 àti pé ọdún ìràpadà mi ti dé.
\q1
\v 5 Mo wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti ṣe ìrànwọ́.
\q2 Àyà fò mí pé ẹnikẹ́ni kò ṣèrànwọ́;
\q1 nítorí náà apá mi ni ó ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún mi
\q2 àti ìrunú mi ni ó gbé mi ró.
\q1
\v 6 Mo tẹ orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀ nínú ìbínú mi;
\q2 nínú ìrunú mi mo jẹ́ kí wọ́n mu
\q2 mo sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ lórí erùpẹ̀.”
\s1 Ìyìn àti àdúrà
\q1
\v 7 Èmi yóò sọ nípa àánú \nd Olúwa\nd*,
\q2 ìṣe rẹ gbogbo tí ó yẹ kí a yìn ín fún,
\q2 gẹ́gẹ́ bí ohun tí \nd Olúwa\nd* ti ṣe fún wa,
\q1 bẹ́ẹ̀ ni, ohun rere gbogbo
\q2 tí ó ti ṣe fún ilé Israẹli,
\q2 gẹ́gẹ́ bí àánú àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore rẹ̀.
\q1
\v 8 Ó wí pé, “Lóòtítọ́ ènìyàn mi ni wọ́n,
\q2 àwọn ọmọ tí kì yóò jẹ́ òpùrọ́ fún mi”;
\q2 bẹ́ẹ̀ ni, ó sì di Olùgbàlà wọn.
\q1
\v 9 Nínú gbogbo ìpọ́njú wọn, inú òun pẹ̀lú bàjẹ́
\q2 àti angẹli tí ó wà níwájú rẹ̀ gbà wọ́n là.
\q1 Nínú ìfẹ́ àti àánú rẹ̀, ó rà wọ́n padà;
\q2 ó gbé wọn sókè ó sì pọ̀n wọ́n
\q2 ní gbogbo ọjọ́ ìgbà n nì.
\q1
\v 10 Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ṣọ̀tẹ̀
\q2 wọ́n sì ba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ nínú jẹ́.
\q1 Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà ó sì di ọ̀tá wọn
\q2 òun tìkára rẹ̀ sì bá wọn jà.
\b
\q1
\v 11 \x - \xo 63.11: \xt Hb 13.20.\x*Lẹ́yìn náà ni àwọn ènìyàn rẹ̀ rántí ọjọ́ ìgbà n nì,
\q2 àwọn ọjọ́ Mose àti àwọn ènìyàn rẹ̀
\q1 níbo ni ẹni náà wà tí ó mú wọn la Òkun já,
\q2 pẹ̀lú olùṣọ́-àgùntàn agbo ẹran rẹ̀?
\q1 Níbo ni ẹni náà wà tí ó rán
\q2 Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrín wọn,
\q1
\v 12 ta ni ó rán apá ògo ti agbára rẹ̀
\q2 láti wà ní apá ọ̀tún Mose,
\q1 ta ni ó pín omi ní yà níwájú wọn,
\q2 láti gba òkìkí ayérayé fún ara rẹ̀,
\q1
\v 13 ta ni ó síwájú wọn la àwọn ọ̀gbun nì já?
\q2 Gẹ́gẹ́ bí ẹṣin ni gbangba ìlú wọn tí kò sì kọsẹ̀;
\q1
\v 14 gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran tí ó lọ sí pápá oko,
\q2 a fún wọn ní ìsinmi láti ọwọ́ Ẹ̀mí \nd Olúwa\nd*.
\q1 Báyìí ni ẹ ṣe tọ́ àwọn ènìyàn yín
\q2 láti fún ara yín ní orúkọ kan tí ó lógo.
\b
\q1
\v 15 Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì rí i
\q2 láti ìtẹ́ ògo rẹ, mímọ́ àti ológo.
\q1 Níbo ni ìtara àti agbára rẹ wà?
\q2 Ìwà jẹ́ẹ́jẹ́ rẹ àti àánú rẹ ni a
\q2 ti mú kúrò níwájú wa.
\q1
\v 16 Ṣùgbọ́n ìwọ ni baba wa,
\q2 bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Abrahamu kò mọ̀ wá
\q1 tàbí Israẹli mọ ẹni tí à á ṣe;
\q2 ìwọ, \nd Olúwa\nd* ni Baba wa,
\q2 Olùràpadà wa láti ìgbà n nì ni orúkọ rẹ.
\q1
\v 17 Èéṣe \nd Olúwa\nd* tí o fi jẹ́ kí a ṣáko kúrò ní ojú ọ̀nà rẹ
\q2 tí o sì ṣé àyà wa le tó bẹ́ẹ̀ tí àwa kò fi bọ̀wọ̀ fún ọ?
\q1 Padà nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ,
\q2 àwọn ẹ̀yà tí ṣe ogún ìní rẹ.
\q1
\v 18 Fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ fi gba ibi mímọ́ rẹ,
\q2 ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwọn ọ̀tá wa ti tẹ ibi mímọ́ rẹ mọ́lẹ̀.
\q1
\v 19 Àwa jẹ́ tìrẹ láti ìgbà n nì;
\q2 ṣùgbọ́n ìwọ kò tí ì jẹ ọba lé wọn lórí,
\q2 a kò sì tí ì pè wọ́n mọ́ orúkọ rẹ.
\b
\b
\c 64
\q1
\v 1 Ìwọ ìbá fa ọ̀run ya kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá,
\q2 tí àwọn òkè ńlá yóò fi wárìrì níwájú rẹ!
\q1
\v 2 Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí iná mú ẹ̀ka igi jó
\q2 tí ó sì mú kí omi ó hó,
\q1 sọ̀kalẹ̀ wá kí orúkọ rẹ le di mí mọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ
\q2 kí o sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó wárìrì níwájú rẹ!
\q1
\v 3 Nítorí nígbà tí o bá ṣe àwọn ohun ẹ̀rù tí àwa kò nírètí,
\q2 o sọ̀kalẹ̀ wá, àwọn òkè ńlá sì wárìrì níwájú rẹ̀.
\q1
\v 4 \x - \xo 64.4: \xt 1Kọ 2.9.\x*Láti ìgbà àtijọ́ kò sí ẹni tí ó gbọ́ rí
\q2 kò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ,
\q1 kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ,
\q2 tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é.
\q1
\v 5 Ìwọ a máa wá fún ìrànlọ́wọ́ àwọn tí wọn
\q2 ń fi ayọ̀ ṣe ohun tó tọ́,
\q1 tí ó rántí ọ̀nà rẹ.
\q2 Ṣùgbọ́n nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀ sí wọn,
\q1 inú bí ọ.
\q2 Báwo ni a ó ṣe gbà wá là?
\q1
\v 6 Gbogbo wa ti dàbí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́,
\q2 gbogbo òdodo wa sì dàbí èkísà ẹlẹ́gbin;
\q1 gbogbo wa kákò bí ewé,
\q2 àti bí afẹ́fẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ wa ti gbá wa lọ kúrò.
\q1
\v 7 Ẹnikẹ́ni kò pe orúkọ rẹ
\q2 tàbí kí ó gbìyànjú láti dì ẹ́ mú;
\q1 nítorí ìwọ ti fi ojú rẹ pamọ́ fún wa
\q2 ó sì jẹ́ kí àwa ṣòfò dànù nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.
\b
\q1
\v 8 Síbẹ̀síbẹ̀, \nd Olúwa\nd*, ìwọ ni Baba wa.
\q2 Àwa ni amọ̀, ìwọ ni amọ̀kòkò;
\q2 gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
\q1
\v 9 Má ṣe bínú kọjá ààlà, ìwọ \nd Olúwa\nd*,
\q2 má ṣe rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa títí láé.
\q1 Jọ̀wọ́, bojú wò wá, ni a gbàdúrà,
\q2 nítorí ènìyàn rẹ ni gbogbo wa.
\q1
\v 10 Àwọn ìlú mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀;
\q2 Sioni pàápàá di aṣálẹ̀, Jerusalẹmu di ahoro.
\q1
\v 11 Tẹmpili mímọ́ ológo wa, níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́,
\q2 ni a ti fi iná sun,
\q2 àti ohun gbogbo tí í ṣe ìṣúra wa ti dahoro.
\q1
\v 12 Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí, \nd Olúwa\nd*, ìwọ ó ha sì tún fi ara rẹ pamọ́ bí?
\q2 Ìwọ ó ha dákẹ́ kí o sì fìyà jẹ wá kọjá ààlà bí?
\c 65
\s1 Ìdájọ́ àti ìgbàlà
\q1
\v 1 \x - \xo 65.1-2: \xt Ro 10.20-21.\x*“Èmi fi ara mi hàn fún àwọn tí kò béèrè fún mi;
\q2 àwọn tí kò wá mi ni wọ́n rí mi.
\q1 Sí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò pe orúkọ mi,
\q2 ni èmi wí pé, Èmi nìyìí, Èmi nìyìí.
\q1
\v 2 Gbogbo ọjọ́ ni mo ti nawọ́ mi síta
\q2 sí àwọn ènìyàn ọlọ́rùn líle,
\q1 tí wọn ń rìn lọ́nà tí kò dára,
\q2 tí wọ́n sì gbára lé èrò ara wọn
\q1
\v 3 àwọn ènìyàn tí wọ́n bí mi nínú nígbà gbogbo
\q2 lójú ara mi gan an,
\q1 wọ́n ń rú ẹbọ nínú ọgbà
\q2 wọ́n sì ń sun tùràrí lórí i pẹpẹ bíríkì;
\q1
\v 4 wọ́n ń jókòó láàrín ibojì
\q2 wọ́n sì ń lo òru wọn nínú ìṣọ́ ìkọ̀kọ̀;
\q1 tí wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀,
\q2 tí ìkòkò ọbẹ̀ wọn kún fún ẹran àìmọ́;
\q1
\v 5 tí ó wí pé, ‘Ẹ sún mẹ́yìn; ẹ má wá sọ́dọ̀ mi,
\q2 nítorí mo ti jẹ́ mímọ́ jù fún un yín!
\q1 Àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ èéfín nínú ihò imú mi
\q2 iná tí ń fi gbogbo ọjọ́ jó.
\b
\q1
\v 6 “Kíyèsi i, a ti kọ ọ́ síwájú mi,
\q2 Èmi kì yóò dákẹ́,
\q1 ṣùgbọ́n èmi yóò san án padà lẹ́kùnrẹ́rẹ́;
\q2 Èmi yóò san án padà sí àyà wọn
\q1
\v 7 àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín àti tàwọn baba yín,”
\q2 ni \nd Olúwa\nd* wí.
\q1 “Nítorí pé wọ́n sun ẹbọ ní orí òkè ńlá
\q2 wọ́n sì ṣe ẹ̀gbin sí mi ní òkè kékeré,
\q1 Èmi yóò wọ́n ọ́n sí itan wọn
\q2 ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀san ohun gbogbo tí wọ́n ṣe tẹ́lẹ̀.”
\p
\v 8 Báyìí ni \nd Olúwa\nd* wí:
\q1 “Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí oje sì tún wà nínú àpólà àjàrà
\q2 tí àwọn ènìyàn sì wí pé, Má ṣe bà á jẹ́,
\q1 nítorí ìbùkún ń bẹ nínú rẹ̀,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe nítorí ìránṣẹ́ mi;
\q2 Èmi kì yóò pa gbogbo wọn run.
\q1
\v 9 Èmi yóò mú ìrandíran wá láti ìdílé Jakọbu,
\q2 àti láti Juda àwọn tí yóò jogún òkè ńlá mi wọ̀n-ọn-nì;
\q1 àwọn àyànfẹ́ ènìyàn mi yóò jogún wọn,
\q2 ibẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ mi yóò sì gbé.
\q1
\v 10 Ṣaroni yóò di pápá oko fún ọ̀wọ́ ẹran,
\q2 àti àfonífojì Akori yóò di ibi ìsinmi fún agbo ẹran,
\q2 fún àwọn ènìyàn mi tí ó wá mi.
\b
\q1
\v 11 “Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó kọ \nd Olúwa\nd* sílẹ̀
\q2 tí ó sì gbàgbé òkè ńlá mímọ́ mi,
\q1 tí ó tẹ́ tábìlì fún Gadi
\q2 tí ẹ sì kún abọ́ pẹ̀lú ọtí wáìnì fún àtubọ̀tán,
\q1
\v 12 Èmi yóò yà ọ́ sọ́tọ̀ fún idà,
\q2 àti pé ẹ̀yin yóò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ fún àwọn tí a pa;
\q1 nítorí mo pè, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò dáhùn.
\q2 Mo sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò tẹ́tí sílẹ̀.
\q1 Ẹ̀yin ṣe búburú ní ojú mi
\q2 ẹ sì yan ohun tí ó bà mí lọ́kàn jẹ́.”
\p
\v 13 Nítorí náà, báyìí ni \nd Olúwa\nd* Olódùmarè wí:
\q1 “Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò jẹun;
\q2 ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ẹ̀yin,
\q1 àwọn ìránṣẹ́ mi yóò mu,
\q2 ṣùgbọ́n òǹgbẹ yóò máa gbẹ ẹ̀yin;
\q1 àwọn ìránṣẹ́ mi yóò ṣe àjọyọ̀,
\q2 ṣùgbọ́n a ó dójútì yin.
\q1
\v 14 Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò kọrin
\q2 láti inú ayọ̀ ọkàn wọn wá,
\q1 ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò kígbe sókè
\q2 láti inú ìrora ọkàn yín
\q2 àti ìpohùnréré ní ìròbìnújẹ́ ọkàn.
\q1
\v 15 Ẹ̀yin yóò fi orúkọ yín sílẹ̀
\q2 fún àwọn àyànfẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí ègún;
\q1 \nd Olúwa\nd* Olódùmarè yóò sì pa yín,
\q2 ṣùgbọ́n fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni òun
\q2 yóò fún ní orúkọ mìíràn.
\q1
\v 16 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàdúrà ìbùkún ní ilẹ̀ náà
\q2 yóò ṣe é nípasẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́;
\q1 Ẹni tí ó bá búra ní ilẹ̀ náà
\q2 yóò búra nípasẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́.
\q1 Nítorí ìyọnu àtijọ́ yóò di ìgbàgbé
\q2 yóò sì fi ara sin kúrò lójú mi.
\s1 Àwọn ọrun tuntun àti ayé tuntun
\q1
\v 17 “Kíyèsi i, Èmi yóò dá
\q2 àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun.
\q1 A kì yóò rántí ohun àtẹ̀yìnwá mọ́,
\q2 tàbí kí wọn wá sí ọkàn.
\q1
\v 18 Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ kí inú yín dùn títí láé
\q2 nínú ohun tí èmi yóò dá,
\q1 nítorí èmi yóò dá Jerusalẹmu láti jẹ́ ohun ìdùnnú
\q2 àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ohun ayọ̀.
\q1
\v 19 Èmi yóò ṣe àjọyọ̀ lórí Jerusalẹmu
\q2 n ó sì ní inú dídùn nínú àwọn ènìyàn mi;
\q1 ariwo ẹkún àti igbe
\q2 ni a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ mọ́.
\b
\q1
\v 20 “Títí láé a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀
\q2 ọmọ ọwọ́ tí yóò gbé fún ọjọ́ díẹ̀,
\q1 tàbí àgbàlagbà tí kì yóò lo ọjọ́ ayé rẹ̀ tán;
\q2 ẹni tí ó bá kú ní ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún
\q1 ni a ó pè ní ọ̀dọ́mọdé;
\q2 ẹni tí kò ba le pé ọgọ́rùn-ún kan
\q2 ni a ó pè ní ẹni ìfibú.
\q1
\v 21 Wọn yó ò kọ́ ilé, wọn yóò sì gbé nínú wọn
\q2 wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì jẹ èso wọn.
\q1
\v 22 Wọn kì yóò kọ́ ilé fún ẹlòmíràn láti gbé,
\q2 tàbí kí wọn gbìn fún ẹlòmíràn láti jẹ.
\q1 Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí igi kan,
\q2 bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí;
\q1 àwọn àyànfẹ́ mi yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́
\q2 wọn fún ìgbà pípẹ́.
\q1
\v 23 Wọn kì yóò ṣe iṣẹ́ lásán,
\q2 wọn kí yóò bímọ fún wàhálà;
\q2 nítorí wọn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn ti \nd Olúwa\nd* bùkún fún,
\q2 àwọn àti àwọn ìrandíran wọn pẹ̀lú wọn.
\q1
\v 24 Kí wọn tó pè, èmi yóò dáhùn;
\q2 nígbà tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, èmi yóò gbọ́.
\q1
\v 25 \x - \xo 65.25: \xt Isa 11.6-9.\x*Ìkookò àti ọ̀dọ́-àgùntàn yóò jẹun pọ̀,
\q2 kìnnìún yóò sì jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù,
\q1 ṣùgbọ́n erùpẹ̀ ni yóò jẹ́ oúnjẹ ejò.
\q2 Wọn kì yóò pa ni lára tàbí pa ni run
\q1 ní gbogbo òkè mímọ́ mi,”
\q2 ni \nd Olúwa\nd* wí.
\c 66
\s1 Ìdájọ́ àti ìrètí
\p
\v 1 \x - \xo 66.1-2: \xt Mt 5.34; Ap 7.49-50.\x*Báyìí ni \nd Olúwa\nd* wí:
\q1 “Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,
\q2 ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.
\q1 Níbo ni ilé tí ẹ ó kọ́ fún mi wà?
\q2 Níbo ní ibi ìsinmi mi yóò gbé wà?
\q1
\v 2 Kì í ha á ṣe ọwọ́ mi ló tí ṣe nǹkan wọ̀nyí,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì wà?”
\q2 ni \nd Olúwa\nd* wí.
\b
\q1 “Eléyìí ni ẹni tí mo kà sí:
\q2 ẹni náà tí ó rẹra rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì kẹ́dùn ní ọkàn rẹ̀,
\q2 tí ó sì wárìrì sí ọ̀rọ̀ mi.
\q1
\v 3 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fi akọ màlúù rú ẹbọ
\q2 ó dàbí ẹni tí ó pa ènìyàn kan
\q1 àti ẹni tí ó bá fi ọ̀dọ́-àgùntàn kan tọrẹ,
\q2 dàbí ẹni tí ó bẹ́ ajá kan lọ́rùn;
\q1 ẹnikẹ́ni tí ó bá fi irúgbìn ìyẹ̀fun tọrẹ
\q2 dàbí ẹni tí ó mú ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ wá,
\q1 ẹni tí ó bá sì sun tùràrí ìrántí,
\q2 dàbí ẹni tí ó súre fún òrìṣà.
\q1 Wọ́n ti yan ipa ọ̀nà tì wọ́n,
\q2 ọkàn wọn pẹ̀lú sì láyọ̀ nínú ohun ìríra wọn,
\q1
\v 4 fún ìdí èyí ni èmi pẹ̀lú yóò ṣe fi ọwọ́ líle mú wọn
\q2 n ó sì mú ohun tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀ wá sórí wọn.
\q1 Nítorí nígbà tí mo pè, kò sí ẹni tí ó dáhùn,
\q2 nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹnikẹ́ni kò tẹ́tí sílẹ̀.
\q1 Wọ́n ṣe ohun búburú ní ojú mi
\q2 wọ́n sì yan ohun tí mo kórìíra rẹ̀.”
\b
\q1
\v 5 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd*,
\q2 ẹ̀yin tí ẹ ń wárìrì nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀:
\q1 “Àwọn arákùnrin yín tí wọ́n kórìíra yín,
\q2 tí wọ́n ta yín nù nítorí orúkọ mi, wí pé,
\q2 Jẹ́ kí a yin \nd Olúwa\nd* lógo,
\q1 kí a le rí ayọ̀ yín!
\q2 Ṣùgbọ́n àwọn ni ojú yóò tì.
\q1
\v 6 \x - \xo 66.6: \xt If 16.1,17.\x*Gbọ́ rògbòdìyàn láti ìlú wá,
\q2 gbọ́ ariwo náà láti tẹmpili wá!
\q1 Ariwo tí \nd Olúwa\nd* ní í ṣe
\q2 tí ó ń san án fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ ohun
\q2 tí ó tọ́ sí wọn.
\b
\q1
\v 7 \x - \xo 66.7: \xt If 12.5.\x*“Kí ó tó lọ sí ìrọbí,
\q2 ó ti bímọ;
\q1 kí ó tó di pé ìrora dé bá a,
\q2 ó ti bí ọmọkùnrin.
\q1
\v 8 Ta ni ó ti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?
\q2 Ta ni ó ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?
\q1 Ǹjẹ́ a le bí orílẹ̀-èdè kan níjọ́ kan
\q2 tàbí kí orílẹ̀-èdè lalẹ̀hù ní ìṣẹ́jú kan?
\q1 Síbẹ̀síbẹ̀ Sioni bẹ̀rẹ̀ rírọbí
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ó sì bí àwọn ọmọ rẹ̀.
\q1
\v 9 Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọbí
\q2 kí èmi má sì mú ni bí?”
\q2 ni \nd Olúwa\nd* wí.
\q1 “Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọ
\q2 nígbà tí mo ń mú ìbí wá?”
\q2 Ni Ọlọ́run yín wí.
\q1
\v 10 “Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀ kí inú yín kí ó sì dùn sí i,
\q2 gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀;
\q1 ẹ yọ̀ gidigidi pẹ̀lú rẹ̀,
\q2 gbogbo ẹ̀yin tí ó ti kẹ́dùn fún un.
\q1
\v 11 Nítorí pé ẹ̀yin yóò mu ẹ o sì ní ìtẹ́lọ́rùn
\q2 nínú ọmú rẹ̀ tí ó tu ni lára,
\q1 ẹ̀yin yóò mu àmuyó
\q2 ẹ ó sì gbádùn nínú àkúnwọ́sílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀.”
\p
\v 12 Nítorí báyìí ni \nd Olúwa\nd* wí:
\q1 “Èmi yóò fún un ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí odò
\q2 àti ọrọ̀ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ìṣàn omi;
\q1 ẹ̀yin yóò mu ọmú, a ó sì gbé yín ní apá rẹ̀
\q2 a ó bá yín ṣeré ní orúkún rẹ̀.
\q1
\v 13 Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínú
\q2 a ó sì tù yín nínú lórí Jerusalẹmu.”
\b
\q1
\v 14 Nígbà tí ẹ bá rí èyí, inú yín yóò dùn
\q2 ẹ̀yin yóò sì gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i koríko;
\q1 ọwọ́ \nd Olúwa\nd* ni a ó sọ di mí mọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,
\q2 ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ ni a ó fihàn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.
\q1
\v 15 Kíyèsi i, \nd Olúwa\nd* ń bọ̀ pẹ̀lú iná
\q2 àti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ tí ó dàbí ìjì líle;
\q1 òun yóò mú ìbínú rẹ sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ìrunú,
\q2 àti ìbáwí rẹ̀ pẹ̀lú ahọ́n iná.
\q1
\v 16 Nítorí pẹ̀lú iná àti idà
\q2 ni \nd Olúwa\nd* yóò ṣe ìdájọ́ lórí i gbogbo ènìyàn,
\q2 àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí \nd Olúwa\nd* yóò pa.
\p
\v 17 “Gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì sọ ara wọn di mímọ́ láti lọ sínú ọgbà, tí wọ́n tẹ̀lé ẹni tí ó wà láàrín àwọn tí ó jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èkúté àti àwọn ohun ìríra mìíràn ni wọn yóò bá òpin wọn pàdé papọ̀,” ni \nd Olúwa\nd* wí.
\p
\v 18 “Àti Èmi, nítorí ìgbésẹ̀ wọn àti èrò wọn, èmi ti múra tán láti wá kó àwọn orílẹ̀-èdè àti ahọ́n jọ, wọn yóò sì wá wo ògo mi.
\p
\v 19 “Èmi yóò sì gbé àmì kan kalẹ̀ láàrín wọn, èmi yóò sì rán díẹ̀ nínú àwọn tí ó sálà lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè Tarṣiṣi, sí àwọn ará Libia àti Ludi, sí Tubali àti ará Giriki, àti sí àwọn erékùṣù tí ó jìnnà réré tí kò tí ìgbọ́ nípa òkìkí mi tàbí kí ó rí ògo mi. Wọn yóò kéde ògo mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.
\v 20 Wọn yóò sì mú àwọn arákùnrin yín wá, láti gbogbo orílẹ̀-èdè, sí òkè mímọ́ mi ní Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí \nd Olúwa\nd* lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́ ẹrù àti ọkọ̀-ẹṣin, àti lórí ìbáaka àti ìbákasẹ,” ni \nd Olúwa\nd* wí. “Wọn yóò kó wọn wá, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israẹli ti mú ọrẹ oníhóró wọn wá, sínú Tẹmpili \nd Olúwa\nd* nínú ohun èlò mímọ́.
\v 21 Àti pé èmi yóò sì yan àwọn kan nínú wọn pẹ̀lú láti jẹ́ àlùfáà àti Lefi,” ni \nd Olúwa\nd* wí.
\p
\v 22 \x - \xo 66.22: \xt Isa 65.17; 2Pt 3.13; If 21.1.\x*“Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun tí mo dá yóò ṣe wà níwájú mi títí láé,” ni \nd Olúwa\nd* wí, “Bẹ́ẹ̀ ni orúkọ yín àti ìrandíran yín yóò pegedé.
\v 23 Láti oṣù tuntun kan dé òmíràn àti láti ọjọ́ ìsinmi kan dé òmíràn, ni gbogbo ọmọ ènìyàn yóò wá, wọn yóò sì tẹríba níwájú mi,” ni \nd Olúwa\nd* wí.
\v 24 \x - \xo 66.24: \xt Mk 9.48.\x*“Wọn yóò sì jáde lọ wọn yóò sì lọ wo òkú àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ sí mi; kòkòrò wọn kì yóò kú, bẹ́ẹ̀ ni iná wọn ni a kì yóò pa, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jẹ́ ohun ìríra fún gbogbo ọmọ ènìyàn.”