Biblica_yoOBYO17/20PROyoOBYO17.SFM

3439 lines
122 KiB
Plaintext
Raw Permalink Blame History

This file contains ambiguous Unicode characters

This file contains Unicode characters that might be confused with other characters. If you think that this is intentional, you can safely ignore this warning. Use the Escape button to reveal them.

\id PRO - Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible (Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
\rem Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
\h Òwe
\toc1 Ìwé Òwe
\toc2 Òwe
\toc3 Òw
\mt1 Ìwé Òwe
\c 1
\s1 Èròǹgbà àti kókó-ọ̀rọ̀
\p
\v 1 Àwọn òwe ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli.
\q1
\v 2 Láti le ní ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́,
\q2 láti ní òye àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀.
\q1
\v 3 Láti gba ẹ̀kọ́ ọgbọ́n, òdodo,
\q2 àti ìdájọ́, àti àìṣègbè;
\q1
\v 4 láti fi òye fún onírẹ̀lẹ̀,
\q2 ìmọ̀ àti ìṣọ́ra fún àwọn èwe.
\q1
\v 5 Jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n tẹ́tí kí ó sì ní ìmọ̀ kún ìmọ̀,
\q2 sì jẹ́ kí ẹni òye gba ìtọ́sọ́nà.
\q1
\v 6 Láti mọ ìtumọ̀ òwe àti ìtán-dòwe,
\q2 àwọn ọ̀rọ̀ àti àlọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n.
\b
\q1
\v 7 Ìbẹ̀rù \nd Olúwa\nd* ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀,
\q2 ṣùgbọ́n aláìgbọ́n kẹ́gàn ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́.
\s1 Ọ̀rọ̀ ìyànjú láti ṣàfẹ́rí ọgbọ́n
\q1
\v 8 Tẹ́tí, ìwọ ọmọ mi sí ẹ̀kọ́ baba rẹ,
\q2 má ṣe kọ ẹ̀kọ́ màmá rẹ sílẹ̀.
\q1
\v 9 Wọn yóò jẹ́ òdòdó ẹ̀yẹ olóòórùn dídùn lórí rẹ
\q2 àti ọ̀ṣọ́ tí ó dára yí ọrùn rẹ ká.
\b
\q1
\v 10 Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́,
\q2 má ṣe gbà fún wọn.
\q1
\v 11 Bí wọn bá wí pé, “Wá pẹ̀lú wa;
\q2 jẹ́ kí á ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan,
\q2 jẹ́ kí á lúgọ ní ìkọ̀kọ̀ de aláìṣẹ̀ ní àìnídìí;
\q1
\v 12 jẹ́ ká gbé wọn mì láààyè, bí ibojì òkú,
\q2 àti lódidi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò;
\q1
\v 13 a ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lórí
\q2 a ó sì fi ìkógun kún inú ilé wa,
\q1
\v 14 da ìpín rẹ pọ̀ mọ́ àárín wa,
\q2 a ó sì jọ pawó sínú àpò kan náà,”
\q1
\v 15 ọmọ mi, má ṣe bá wọn lọ,
\q2 má ṣe rìn ní ojú ọ̀nà wọn.
\q1
\v 16 Nítorí ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí ẹ̀ṣẹ̀,
\q2 wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.
\q1
\v 17 Wàhálà asán ni kí ènìyàn máa dẹ àwọ̀n sílẹ̀,
\q2 ní ojú ẹyẹ!
\q1
\v 18 Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń lúgọ fún ẹ̀jẹ̀ ara wọn.
\q2 Ara wọn ni wọ́n ń dá lọ́nà.
\q1
\v 19 Báyìí ni ìgbẹ̀yìn gbogbo àwọn tí ń wá èrè àìtọ́;
\q2 yóò mú ẹ̀mí gbogbo ẹni tí ó rí i lọ.
\s1 Ìkìlọ̀ láti má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀
\q1
\v 20 \x - \xo 1.20,21: \xt Òw 8.1-3.\x*Ọgbọ́n kígbe sókè ní pópó
\q2 ó gbé ohùn rẹ̀ sókè láàrín ọjà;
\q1
\v 21 láàrín ọjà ni ó ti kígbe jáde
\q2 ní ibodè ìlú ni ó ti sọ̀rọ̀ ọ rẹ̀:
\b
\q1
\v 22 “Yóò ha ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin aláìmọ̀kan yóò fi fẹ́ àìmọ̀kan yín tó?
\q2 Yóò ha ti pẹ́ tó tí àwọn ẹlẹ́gàn yóò ṣe inú dídùn sí ìpẹ̀gàn tó?
\q2 Àwọn aláìgbọ́n kórìíra ìmọ̀?
\q1
\v 23 Bí ẹ bá ti gbọ́ ìbáwí ì mi ni,
\q2 ǹ bá ti tú ohun tí ó wà nínú ọkàn mi jáde fún yín
\q2 kí n sì fi inú mi hàn sí i yín.
\q1
\v 24 Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ ti kọ ìpè ní ìgbà tí mo pè
\q2 kò sì sí ẹni tí ó kọ ibi ara sí mi gbà tí mo na ọwọ́ sí wọn,
\q1
\v 25 níwọ́n bí ẹ ti kọ gbogbo ìmọ̀ràn mi,
\q2 tí ẹ̀yin kò sì gba ìbáwí mi,
\q1
\v 26 Èmi pẹ̀lú yóò fi ìdààmú yín rẹ́rìn-ín;
\q2 èmi yóò ṣẹ̀fẹ̀ nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín.
\q1
\v 27 Nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín bí ìjì líle,
\q2 nígbà tí ìdààmú bá dé bá ọ bí ààjà,
\q2 nígbà tí wàhálà àti ìbànújẹ́ ọkàn bá bò ọ́ mọ́lẹ̀.
\b
\q1
\v 28 “Nígbà náà ni wọn yóò ké pè mí ṣùgbọ́n, èmi kò ní dáhùn;
\q2 wọn yóò fi ara balẹ̀ wá mi ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí mi.
\q1
\v 29 Níwọ́n bí wọ́n ti kórìíra ìmọ̀
\q2 tí wọ́n sì kọ̀ láti bẹ̀rù \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 30 Níwọ́n bí wọn kò ti gbà ìmọ̀ràn mi
\q2 tí wọ́n sì kẹ́gàn ìmọ̀ràn mi,
\q1
\v 31 wọn yóò jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn
\q2 wọn yóò sì jèrè èso ètè wọn ní kíkún.
\q1
\v 32 Nítorí ìrìnkurìn àwọn aláìmọ̀kan ni yóò pa wọ́n
\q2 ìkáwọ́gbera aláìgbọ́n ni yóò pa á run;
\q1
\v 33 ṣùgbọ́n ẹnìkan tí ó bá fetí sí mi, yóò gbé láìléwu
\q2 yóò sì wà nínú ìdẹ̀ra, láìsí ìbẹ̀rù ìpalára.”
\c 2
\s2 Èrè ìwà rere tí ọgbọ́n ń mú wá
\q1
\v 1 Ọmọ mi, bí ìwọ bá gba ọ̀rọ̀ mi,
\q2 tí ìwọ sì pa òfin mi mọ́ sí inú rẹ,
\q1
\v 2 tí ìwọ dẹtí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n
\q2 tí ìwọ sì fi ọkàn rẹ sí òye,
\q1
\v 3 àní, bí ìwọ bá ké tọ ìmọ̀ lẹ́yìn,
\q2 tí ìwọ sì gbé ohùn rẹ sókè fún òye
\q1
\v 4 bí ìwọ bá ṣàfẹ́rí rẹ̀ bí i fàdákà
\q2 tí ìwọ sì wa kiri bí ìṣúra tí a fi pamọ́.
\q1
\v 5 Nígbà náà ni ìwọ yóò bẹ̀rù \nd Olúwa\nd*,
\q2 ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run.
\q1
\v 6 Nítorí \nd Olúwa\nd* ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n,
\q2 láti ẹnu rẹ̀ sì ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá.
\q1
\v 7 Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo,
\q2 Òun ni asà fún àwọn tí ń rìn déédé,
\q1
\v 8 Ó pa ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́
\q2 Ó sì ń pa ọ̀nà àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́.
\b
\q1
\v 9 Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ òdodo àti ìdájọ́,
\q2 àti àìṣègbè—gbogbo ipa ọ̀nà rere.
\q1
\v 10 Nítorí ọgbọ́n yóò wọ inú ọkàn rẹ
\q2 ìmọ̀ yóò sì jẹ́ ìtura fún ọkàn rẹ.
\q1
\v 11 Ìmòye yóò pa ọ mọ́
\q2 òye yóò sì máa ṣọ́ ọ.
\b
\q1
\v 12 Ọgbọ́n yóò gbà ọ́ là kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú,
\q2 lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí ọrọ̀ ọ wọn jẹ́ àyídáyidà,
\q1
\v 13 ẹni tí ó kúrò ní ọ̀nà ìdúró ṣinṣin
\q2 láti rìn ní ọ̀nà tí ó ṣókùnkùn,
\q1
\v 14 ẹni tí ó yọ̀ nínú ṣíṣe búburú,
\q2 tí ó ṣe inú dídùn sí àyídáyidà àwọn ènìyàn ibi,
\q1
\v 15 ọ̀nà ẹni tí ó wọ́
\q2 tí wọ́n sì jẹ́ alárékérekè ní ọ̀nà wọn.
\b
\q1
\v 16 Yóò gba ìwọ pẹ̀lú là kúrò lọ́wọ́ àwọn àjèjì obìnrin,
\q2 àní, lọ́wọ́ obìnrin àjèjì tí ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ tannijẹ,
\q1
\v 17 ẹni tí ó ti kọ ọkọ àkọ́fẹ́ ìgbà èwe rẹ̀ sílẹ̀
\q2 tí ó sì gbàgbé májẹ̀mú tí ó ti dá níwájú Ọlọ́run rẹ̀.
\q1
\v 18 Nítorí ilé rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà sí ikú
\q2 ipa ọ̀nà rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn òkú.
\q1
\v 19 Kò sẹ́ni tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó padà
\q2 bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í dé ọ̀nà ìyè.
\b
\q1
\v 20 Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rere
\q2 kí ìwọ kí ó sì pa ọ̀nà àwọn olódodo mọ́.
\q1
\v 21 Nítorí ẹni dídúró ṣinṣin yóò gbé ní ilé náà
\q2 àwọn aláìlẹ́gàn sì ni yóò máa wà nínú rẹ̀.
\q1
\v 22 Ṣùgbọ́n a ó ké ènìyàn búburú kúrò lórí ilẹ̀ náà
\q2 a ó sì fa àwọn aláìṣòótọ́ tu kúrò lórí rẹ̀.
\c 3
\s2 Àwọn àǹfààní ọgbọ́n mìíràn
\q1
\v 1 Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ mi.
\q2 Ṣùgbọ́n pa òfin mi mọ́ sí ọkàn rẹ.
\q1
\v 2 Nítorí ọjọ́ gígùn, ẹ̀mí gígùn, àti àlàáfíà,
\q2 ni wọn yóò fi kùn un fún ọ.
\b
\q1
\v 3 Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláé
\q2 so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ,
\q2 kọ wọ́n sí wàláà àyà rẹ.
\q1
\v 4 \x - \xo 3.4: \xt Ro 12.17.\x*Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojúrere àti orúkọ rere
\q2 ní ojú Ọlọ́run àti lójú ènìyàn.
\b
\q1
\v 5 Gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd* pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ
\q2 má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ.
\q1
\v 6 Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ
\q2 òun yóò sì máa tọ́ ipa ọ̀nà rẹ.
\b
\q1
\v 7 \x - \xo 3.7: \xt Ro 12.16.\x*Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ
\q2 bẹ̀rù \nd Olúwa\nd* kí o sì kórìíra ibi.
\q1
\v 8 Èyí yóò mú ìlera fún ara rẹ
\q2 àti okun fún àwọn egungun rẹ.
\b
\q1
\v 9 Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún \nd Olúwa\nd*,
\q2 pẹ̀lú àkọ́so oko rẹ,
\q1
\v 10 nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnya
\q2 àgbá rẹ yóò kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún wáìnì tuntun.
\b
\q1
\v 11 \x - \xo 3.11,12: \xt Hb 12.5,6.\x*Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí \nd Olúwa\nd*
\q2 má sì ṣe bínú nígbà tí ó bá ń bá ọ wí,
\q1
\v 12 nítorí \nd Olúwa\nd* a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wí
\q2 bí baba ti í bá ọmọ tí ó bá nínú dídùn sí wí.
\b
\q1
\v 13 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀,
\q2 ẹni tí ó tún ní òye sí i,
\q1
\v 14 nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ
\q2 ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ.
\q1
\v 15 Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ;
\q2 kò sí ohunkóhun tí a lè fiwé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.
\q1
\v 16 Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;
\q2 ní ọwọ́ òsì rẹ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.
\q1
\v 17 Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ ọ̀nà ìtura,
\q2 òpópónà rẹ sì jẹ́ ti àlàáfíà.
\q1
\v 18 Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbà á;
\q2 àwọn tí ó bá sì dìímú yóò rí ìbùkún gbà.
\b
\q1
\v 19 Nípa ọgbọ́n, \nd Olúwa\nd* fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn;
\q1
\v 20 nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní yà,
\q2 àwọsánmọ̀ sì ń sẹ ìrì.
\b
\q1
\v 21 Ọmọ mi, pa ọgbọ́n tí ó yè kooro àti ìmòye mọ́,
\q2 má jẹ́ kí wọn lọ kúrò ní ibi tí ojú rẹ ti le tó wọn.
\q1
\v 22 Wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọ,
\q2 àti ẹ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ.
\q1
\v 23 Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìléwu,
\q2 ìwọ kì yóò sì kọsẹ̀.
\q1
\v 24 Nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò bẹ̀rù,
\q2 nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, oorun rẹ yóò jẹ́ oorun ayọ̀.
\q1
\v 25 Má ṣe bẹ̀rù ìdààmú òjijì,
\q2 tàbí ti ìparun tí ó ń dé bá àwọn ènìyàn búburú.
\q1
\v 26 Nítorí \nd Olúwa\nd* yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ,
\q2 kì yóò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ bọ́ sínú pàkúté.
\b
\q1
\v 27 Má ṣe fa ọwọ́ ìre sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ṣe tìrẹ,
\q2 nígbà tí ó bá wà ní ìkápá rẹ láti ṣe ohun kan.
\q1
\v 28 Má ṣe wí fún aládùúgbò rẹ pé,
\q2 “Padà wá nígbà tó ṣe díẹ̀; èmi yóò fi fún ọ ní ọ̀la,”
\q2 nígbà tí o ní i pẹ̀lú rẹ nísinsin yìí.
\q1
\v 29 Má ṣe pète ohun búburú fún aládùúgbò rẹ,
\q2 ti o gbé nítòsí rẹ, tí ó sì fọkàn tán ọ.
\q1
\v 30 Má ṣe fẹ̀sùn kan ènìyàn láìnídìí,
\q2 nígbà tí kò ṣe ọ́ ní ibi kankan rárá.
\b
\q1
\v 31 Má ṣe ṣe ìlara ènìyàn jàgídíjàgan
\q2 tàbí kí o yàn láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
\b
\q1
\v 32 Nítorí \nd Olúwa\nd* kórìíra ènìyàn aláyídáyidà
\q2 ṣùgbọ́n a máa fọkàn tán ẹni dídúró ṣinṣin.
\q1
\v 33 Ègún \nd Olúwa\nd* ń bẹ lórí ilé ènìyàn búburú,
\q2 ṣùgbọ́n ó bùkún fún ilé olódodo.
\q1
\v 34 \x - \xo 3.34: \xt (Gk): Jk 4.6; 1Pt 5.5.\x*Ó fi àwọn ẹlẹ́yà ṣe yẹ̀yẹ́,
\q2 ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún onírẹ̀lẹ̀.
\q1
\v 35 Ọlọ́gbọ́n jogún iyì,
\q2 ṣùgbọ́n àwọn aṣiwèrè ni yóò ru ìtìjú wọn.
\c 4
\s2 Ọgbọ́n ni o ga jùlọ
\q1
\v 1 Tẹ́tí, ẹ̀yin ọmọ mi, sí ẹ̀kọ́ baba; fetísílẹ̀ kí o sì ní òye sí i.
\q1
\v 2 Mo fún ọ ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro,
\q2 nítorí náà, má ṣe kọ ẹ̀kọ́ mi sílẹ̀.
\q1
\v 3 Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ní ilé baba à mí,
\q2 mo jẹ́ èwe, tí mo sì jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi.
\q1
\v 4 Ó kọ́ mi ó sì wí pé,
\q2 “Jẹ́ kí àyà rẹ kí ó gba ọ̀rọ̀ mi dúró,
\q1 pa òfin mi mọ́, kí ìwọ kí ó sì yè.
\q1
\v 5 Gba ọgbọ́n, gba òye,
\q2 má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ mi tàbí kí o yẹsẹ̀ kúrò nínú rẹ̀.
\q1
\v 6 Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́,
\q2 fẹ́ràn rẹ̀, yóò sì bojútó ọ.
\q1
\v 7 Ọgbọ́n ni ó ga jù; nítorí náà gba ọgbọ́n.
\q2 Bí ó tilẹ̀ ná gbogbo ohun tí o ní, gba òye.
\q1
\v 8 Gbé e ga, yóò sì gbé ọ ga
\q2 dìrọ̀ mọ́ ọn, yóò sì bu iyì fún ọ.
\q1
\v 9 Yóò fi òdòdó ọ̀ṣọ́ ẹwà sí orí rẹ
\q2 yóò sì fi adé ẹlẹ́wà fún ọ.”
\b
\q1
\v 10 Tẹ́tí, ọmọ mi, gba ohun tí mo sọ,
\q2 ọjọ́ ayé è rẹ yóò sì gùn.
\q1
\v 11 Mo tọ́ ọ ṣọ́nà ní ọ̀nà ti ọgbọ́n
\q2 mo sì mú ọ lọ ní ọ̀nà ti tààrà.
\q1
\v 12 Nígbà tí o rìn, ìgbésẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́
\q2 nígbà tí o bá sáré, ìwọ kì yóò kọsẹ̀.
\q1
\v 13 Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ;
\q2 tọ́jú u rẹ̀ dáradára nítorí òun ni ìyè rẹ.
\q1
\v 14 Má ṣe gbé ẹsẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburú
\q2 tàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.
\q1
\v 15 Yẹra fún un, má ṣe rìn níbẹ̀;
\q2 yàgò fún un kí o sì bá ọ̀nà tìrẹ lọ.
\q1
\v 16 Nítorí wọn kò le sùn àyàfi tí wọ́n bá ṣe ibi,
\q2 wọn kò ní tòògbé àyàfi tí wọ́n bá gbé ẹlòmíràn ṣubú.
\q1
\v 17 Wọ́n ń jẹ oúnjẹ ìwà búburú
\q2 wọ́n sì ń mu wáìnì ìwà ìkà.
\b
\q1
\v 18 Ipa ọ̀nà olódodo dàbí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn
\q2 tí ń tànmọ́lẹ̀ sí i títí ọjọ́ fi kanrí
\q1
\v 19 ṣùgbọ́n ọ̀nà ènìyàn búburú dàbí òkùnkùn biribiri;
\q2 wọn kò mọ ohun tí ó ń mú wọn kọsẹ̀.
\b
\q1
\v 20 Ọmọ mi, tẹ́tí sí ohun tí mo sọ;
\q2 fetísílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi.
\q1
\v 21 Má ṣe jẹ́ kí wọ́n rá mọ́ ọ lójú
\q2 pa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ,
\q1
\v 22 nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó rí wọn
\q2 àti ìlera fún gbogbo ara ènìyàn.
\q1
\v 23 Ju gbogbo nǹkan tókù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́,
\q2 nítorí òun ni orísun ìyè.
\q1
\v 24 Mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ;
\q2 sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ jìnnà réré sí ẹnu rẹ.
\q1
\v 25 Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo iwájú,
\q2 jẹ́ kí ìwo ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán iwájú rẹ sá á.
\q1
\v 26 \x - \xo 4.26: \xt (Gk): Hb 12.13.\x*Kíyèsi ìrìn ẹsẹ̀ rẹ
\q2 sì rìn ní àwọn ọ̀nà tí ó dára nìkan.
\q1
\v 27 Má ṣe yà sọ́tùn ún tàbí sósì;
\q2 pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú ibi.
\c 5
\s2 Ìkìlọ̀ láti yàgò fún àgbèrè
\q1
\v 1 Ọmọ mi, fiyèsí ọgbọ́n mi,
\q2 kí o sì dẹtí rẹ sí òye mi,
\q1
\v 2 kí ìwọ sì lè ní ìṣọ́ra
\q2 kí ètè rẹ sì le pa ìmọ̀ mọ́.
\q1
\v 3 Nítorí ètè àwọn àjèjì obìnrin a máa sun bi oyin,
\q2 ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì kúnná ju òróró lọ.
\q1
\v 4 Ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, ó korò ju òróǹró lọ,
\q2 ó mú bí idà olójú méjì.
\q1
\v 5 Ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà ikú
\q2 ìgbésẹ̀ rẹ̀ lọ tààrà sí ibojì òkú.
\q1
\v 6 Kí ìwọ má ba à já ipa ọ̀nà ìyè;
\q2 ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla, ṣùgbọ́n kò tilẹ̀ mọ́.
\b
\q1
\v 7 Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ dẹtí sí mi,
\q2 kí ẹ̀yin kí ó má ṣe yàgò kúrò nínú ọ̀rọ̀ tí mo sọ.
\q1
\v 8 Rìn ní ọ̀nà tí ó jìnnà sí ti rẹ̀,
\q2 má ṣe súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀,
\q1
\v 9 àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò gbé gbogbo ọlá rẹ lé ẹlòmíràn lọ́wọ́
\q2 àti ọjọ́ ayé rẹ fún ìkà ènìyàn.
\q1
\v 10 Kí a má ba à fi ọrọ̀ rẹ fún àjèjì ènìyàn,
\q2 kí làálàá rẹ sì sọ ilé ẹlòmíràn di ọlọ́rọ̀.
\q1
\v 11 Ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ ìwọ yóò kérora,
\q2 nígbà tí agbára rẹ àti ara rẹ bá ti joro tán.
\q1
\v 12 Ìwọ yóò wí pé, “Mo ti kórìíra ẹ̀kọ́ tó!
\q2 Ọkàn mi ṣe wá kórìíra ìbáwí!
\q1
\v 13 N kò gbọ́rọ̀ sí àwọn olùkọ́ mi lẹ́nu,
\q2 tàbí kí n fetí sí àwọn tí ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́.
\q1
\v 14 Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìparun pátápátá
\q2 ní àárín gbogbo àwùjọ ènìyàn.”
\b
\q1
\v 15 Mu omi láti inú kànga tìrẹ,
\q2 omi tí ń sàn láti inú kànga rẹ.
\q1
\v 16 Ó ha yẹ kí omi ìsun rẹ kún àkúnya sí ojú ọ̀nà
\q2 àti odò tí ń sàn lọ sí àárín ọjà?
\q1
\v 17 Jẹ́ kí wọn jẹ́ tìrẹ nìkan,
\q2 má ṣe ṣe àjọpín wọn pẹ̀lú àjèjì láéláé.
\q1
\v 18 Jẹ́ kí orísun rẹ kí ó ní ìbùkún;
\q2 kí ìwọ ó sì máa yọ nínú aya ìgbà èwe rẹ.
\q1
\v 19 Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọ,
\q2 jẹ́ kí ọmú rẹ̀ kí ó máa fi ayọ̀ fún ọ nígbà gbogbo,
\q2 kí o sì máa yọ̀ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbàkígbà.
\q1
\v 20 Ọmọ mi, èéṣe tí ìwọ ó fi máa yọ̀ nínú ìfẹ́ obìnrin panṣágà,
\q2 tí ìwọ ó sì fi dì mọ́ ìyàwó ẹlòmíràn?
\b
\q1
\v 21 Nítorí ọ̀nà ènìyàn kò fi ara sin rárá fún \nd Olúwa\nd*
\q2 Ó sì ń gbé gbogbo ọ̀nà rẹ̀ yẹ̀ wò.
\q1
\v 22 Ìwà búburú ènìyàn búburú ni yóò mú kó bọ́ sínú okùn;
\q2 okùn ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀ yóò sì dìímú.
\q1
\v 23 Yóò kú ní àìgba ẹ̀kọ́
\q2 ìwà òmùgọ̀ ara rẹ̀ yóò sì mú kí ó máa ṣìnà kiri.
\c 6
\s2 Ìkìlọ̀ láti ṣọ́ra fún ìwà òmùgọ̀
\q1
\v 1 Ọmọ mi, bí ìwọ bá ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ,
\q2 bí ìwọ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún àjèjì ènìyàn,
\q1
\v 2 bí a bá ti fi ọ̀rọ̀ tí ó sọ dẹkùn mú ọ,
\q2 tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ti kó ọ sí pàkúté.
\q1
\v 3 Nígbà náà, ṣe èyí, ìwọ ọmọ mi, láti gba ara rẹ
\q2 níwọ̀n bí o ti kó ṣọ́wọ́ aládùúgbò rẹ:
\q1 lọ kí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀;
\q2 bẹ aládùúgbò rẹ dáradára.
\q1
\v 4 Má ṣe jẹ́ kí oorun kí ó kùn ọ́,
\q2 tàbí kí o tilẹ̀ tòògbé rárá.
\q1
\v 5 Gba ara rẹ sílẹ̀, bí abo èsúró kúrò lọ́wọ́ ọdẹ,
\q2 bí ẹyẹ kúrò nínú okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ.
\b
\q1
\v 6 Tọ èèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ;
\q2 kíyèsi ìṣe rẹ̀, kí o sì gbọ́n!
\q1
\v 7 Kò ní olùdarí,
\q2 kò sí alábojútó tàbí ọba,
\q1
\v 8 síbẹ̀, a kó ìpèsè rẹ̀ jọ ní àsìkò òjò
\q2 yóò sì kó oúnjẹ rẹ̀ jọ ní àsìkò ìkórè.
\b
\q1
\v 9 Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò dùbúlẹ̀, ìwọ ọ̀lẹ?
\q2 Nígbà wo ni ìwọ yóò jí kúrò lójú oorun rẹ?
\q1
\v 10 Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,
\q2 ìkáwọ́gbera láti sinmi díẹ̀.
\q1
\v 11 Òsì yóò sì wá sórí rẹ bí ìgárá ọlọ́ṣà
\q2 àti àìní bí adigunjalè.
\b
\q1
\v 12 Ènìyànkénìyàn àti ènìyàn búburú,
\q2 tí ń ru ẹnu àrékérekè káàkiri,
\q1
\v 13 tí ó ń ṣẹ́jú pàkòpàkò,
\q2 ó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀
\q2 ó sì ń fi ìka ọwọ́ rẹ̀ júwe,
\q1
\v 14 tí ó ń pète búburú pẹ̀lú ẹ̀tàn nínú ọkàn rẹ̀
\q2 ìgbà gbogbo ni ó máa ń dá ìjà sílẹ̀.
\q1
\v 15 Nítorí náà ìdààmú yóò dé bá a ní ìṣẹ́jú akàn;
\q2 yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe.
\b
\li1
\v 16 Àwọn ohun mẹ́fà wà tí \nd Olúwa\nd* kórìíra,
\li2 ohun méje ní ó jẹ́ ìríra sí i,
\li3
\v 17 Ojú ìgbéraga,
\li3 ahọ́n tó ń parọ́
\li3 ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,
\li3
\v 18 ọkàn tí ń pète ohun búburú,
\li3 ẹsẹ̀ tí ó yára láti sáré sínú ìwà ìkà,
\li3
\v 19 ajẹ́rìí èké tí ń tú irọ́ jáde lẹ́nu
\li3 àti ènìyàn tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrín àwọn ọmọ ìyá kan.
\s1 Ìkìlọ̀ nítorí àgbèrè
\q1
\v 20 Ọmọ mi, pa àṣẹ baba rẹ mọ́
\q2 má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀.
\q1
\v 21 Jẹ́ kí wọn wà nínú ọkàn rẹ láéláé
\q2 so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ.
\q1
\v 22 Nígbà tí ìwọ bá ń rìn, wọn yóò ṣe amọ̀nà rẹ;
\q2 nígbà tí ìwọ bá sùn, wọn yóò máa ṣe olùṣọ́ rẹ;
\q2 nígbà tí o bá jí, wọn yóò bá ọ sọ̀rọ̀.
\q1
\v 23 Nítorí àwọn àṣẹ yìí jẹ́ fìtílà,
\q2 ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìmọ́lẹ̀,
\q2 àti ìtọ́nisọ́nà ti ìbáwí
\q2 ni ọ̀nà sí ìyè.
\q1
\v 24 Yóò pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin búburú,
\q2 kúrò lọ́wọ́ ẹnu dídùn obìnrin àjèjì.
\b
\q1
\v 25 Má ṣe ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ si nínú ọkàn rẹ nítorí ẹwà rẹ
\q2 tàbí kí o jẹ́ kí ó fi ojú rẹ̀ fà ọ́ mọ́ra.
\b
\q1
\v 26 Nítorí pé nípasẹ̀ àgbèrè obìnrin ni ènìyàn fi ń di oníṣù-àkàrà kan,
\q2 ṣùgbọ́n àyà ènìyàn a máa wá ìyè rẹ̀ dáradára.
\q1
\v 27 Ǹjẹ́ ọkùnrin ha le è gbé iná lé orí itan
\q2 kí aṣọ rẹ̀ má sì jóná?
\q1
\v 28 Ǹjẹ́ ènìyàn le è máa rìn lórí iná?
\q2 Kí ẹsẹ̀ rẹ̀ sì má jóná?
\q1
\v 29 Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sùn pẹ̀lú aya aláya;
\q2 kò sí ẹni tí ó fọwọ́ kàn án tí yóò lọ láìjìyà.
\b
\q1
\v 30 Àwọn ènìyàn kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jalè
\q2 nítorí àti jẹun nígbà tí ebi bá ń pa á.
\q1
\v 31 Síbẹ̀ bí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, ó gbọdọ̀ san ìlọ́po méje
\q2 bí ó tilẹ̀ kó gbogbo ohun tó ní nílé tà.
\q1
\v 32 Ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbèrè kò nírònú;
\q2 ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ó ń pa ara rẹ̀ run ni.
\q1
\v 33 Ìfarapa àti ìtìjú ni tirẹ̀,
\q2 ẹ̀gàn rẹ̀ kì yóò sì kúrò láéláé.
\b
\q1
\v 34 Nítorí owú yóò ru ìbínú ọkọ sókè,
\q2 kì yóò sì ṣàánú nígbà tí ó bá ń gbẹ̀san.
\q1
\v 35 Kò nígbà nǹkan kan bí ohun ìtánràn;
\q2 yóò kọ àbẹ̀tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó.
\c 7
\s2 Ìkìlọ̀ nítorí àwọn aṣẹ́wó
\q1
\v 1 Ọmọ mi, pa ọ̀rọ̀ mi mọ́,
\q2 sì fi àwọn òfin mi pamọ́ sínú ọkàn rẹ.
\q1
\v 2 Pa òfin mi mọ́, ìwọ yóò sì yè
\q2 tọ́jú ẹ̀kọ́ mi bí ẹyinlójú rẹ.
\q1
\v 3 Kọ wọ́n sí ọwọ́ òsì rẹ, má ṣe fi jẹun
\q2 kọ wọ́n sí inú wàláà àyà rẹ.
\q1
\v 4 Wí fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arábìnrin mi,”
\q2 sì pe òye ní ìbátan rẹ.
\q1
\v 5 Wọn yóò pa ó mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin alágbèrè,
\q2 kúrò lọ́wọ́ àjèjì obìnrin àti ọ̀rọ̀ ìtànjẹ rẹ̀.
\b
\q1
\v 6 Ní ojú fèrèsé ilé è mi
\q2 mo wo ìta láti ojú fèrèsé.
\q1
\v 7 Mo rí i láàrín àwọn aláìmọ̀kan
\q2 mo sì kíyèsi láàrín àwọn ọ̀dọ́kùnrin,
\q2 ọ̀dọ́ kan tí ó ṣe aláìgbọ́n.
\q1
\v 8 Ó ń lọ ní pópónà ní tòsí i ilé alágbèrè obìnrin náà,
\q2 ó ń rìn lọ sí ọ̀nà ilé e rẹ̀.
\q1
\v 9 Ní ìrọ̀lẹ́ bí oòrùn ṣe ń wọ̀,
\q2 bí òkùnkùn ṣe ń bo ni lára.
\b
\q1
\v 10 Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan jáde wá láti pàdé rẹ̀,
\q2 ó múra bí panṣágà pẹ̀lú ètè búburú.
\q1
\v 11 (Ó jẹ́ aláriwo àti alágídí,
\q2 ìdí rẹ̀ kì í jókòó nílé;
\q1
\v 12 bí ó ti ń já níhìn-ín ní ó ń já lọ́hùn ún
\q2 gbogbo orígun ni ó ti ń ba ní ibùba.)
\q1
\v 13 Ó dìímú, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu
\q1 pẹ̀lú ojú díndín ó wí pé,
\b
\q1
\v 14 “Mo ní ọrẹ àlàáfíà ní ilé;
\q2 lónìí ni mo san ẹ̀jẹ́ mi.
\q1
\v 15 Nítorí náà ni n o ṣe jáde wá pàdé è rẹ;
\q2 mo wá ọ káàkiri mo sì ti rí ọ!
\q1
\v 16 Mo ti tẹ́ ibùsùn mi
\q2 pẹ̀lú aṣọ aláràbarà láti ilẹ̀ Ejibiti.
\q1
\v 17 Mo ti fi nǹkan olóòórùn dídùn sí ibùsùn mi
\q2 bí i òjìá, aloe àti kinamoni.
\q1
\v 18 Wá, jẹ́ kí a lo ìfẹ́ papọ̀ ní kíkún títí di àárọ̀;
\q2 jẹ́ kí a gbádùn ara wa pẹ̀lú ìfẹ́!
\q1
\v 19 Ọkọ ọ̀ mi ò sí nílé;
\q2 ó ti lọ sí ìrìnàjò jíjìn.
\q1
\v 20 Ó mú owó púpọ̀ lọ́wọ́
\q2 kò sì ní darí dé kí ó tó di ọ̀sán.”
\b
\q1
\v 21 Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn ó sì í lọ́nà;
\q2 ó tàn án jẹ pẹ̀lú ẹnu dídùn.
\q1
\v 22 Òun sì tọ̀ ọ́ lọ lẹsẹ̀ kan náà,
\q2 bí i màlúù tí ń lọ sí ibi pípa,
\q2 tàbí bí àgbọ̀nrín tí ń lọ sí ibi okùn ìso.
\q1
\v 23 Títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀,
\q2 bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn,
\q2 láìmọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun.
\b
\q1
\v 24 Nítorí náà báyìí ẹ̀yin ọmọ mi, tẹ́tí sí mi
\q2 fọkàn sí nǹkan tí mo sọ.
\q1
\v 25 Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yà sí ọ̀nà rẹ̀,
\q2 tàbí kí ó rìn lọ sí ipa ọ̀nà rẹ̀.
\q1
\v 26 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó ti fà lulẹ̀.
\q2 Ogunlọ́gọ̀ àwọn alágbára ni ó ti pa.
\q1
\v 27 Ilé e rẹ̀ ni ọ̀nà tààrà sí isà òkú,
\q2 tí ó lọ tààrà sí àgbàlá ikú.
\c 8
\s2 Ọgbọ́n n fi ìpè síta
\q1
\v 1 \x - \xo 8.1-3: \xt Òw 1.20,21.\x*Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta?
\q2 Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè?
\q1
\v 2 Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà,
\q2 ní ìkóríta, ní ó dúró;
\q1
\v 3 ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú,
\q2 ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè:
\q1
\v 4 “Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè;
\q2 mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn.
\q1
\v 5 Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ kọ́gbọ́n;
\q2 ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹ gba òye.
\q1
\v 6 Ẹ gbọ́, nítorí tí èmi ó sọ̀rọ̀ ohun iyebíye;
\q2 Èmí ṣí ètè mi láti sọ ohun tí ó tọ́,
\q1
\v 7 ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́,
\q2 nítorí ètè mi kórìíra ibi.
\q1
\v 8 Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi ni ó tọ́,
\q2 kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyidà níbẹ̀.
\q1
\v 9 Fún olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà;
\q2 wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀.
\q1
\v 10 Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà,
\q2 ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn,
\q1
\v 11 nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù iyùn lọ,
\q2 kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fiwé e.
\b
\q1
\v 12 “Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye;
\q2 mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú.
\q1
\v 13 Ìbẹ̀rù \nd Olúwa\nd* ni ìkórìíra ibi
\q2 mo kórìíra ìgbéraga àti agídí,
\q2 ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
\q1
\v 14 Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmi
\q2 mo ní òye àti agbára.
\q1
\v 15 Nípasẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkóso
\q2 tí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára.
\q1
\v 16 Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ-aládé ń ṣàkóso,
\q2 àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé.
\q1
\v 17 Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi,
\q2 àwọn tí ó sì wá mi rí mi.
\q1
\v 18 Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà,
\q2 ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere.
\q1
\v 19 Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ;
\q2 ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.
\q1
\v 20 Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo,
\q2 ní ojú ọ̀nà òtítọ́,
\q1
\v 21 mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mi
\q2 mo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún.
\b
\q1
\v 22 “Èmi ni \nd Olúwa\nd* kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀.
\q2 Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́;
\q1
\v 23 a ti yàn mí láti ayérayé,
\q2 láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀.
\q1
\v 24 Nígbà tí kò tí ì sí Òkun, ni a ti bí mi,
\q2 nígbà tí kò tí ì sí ìsun tí ó ní omi nínú;
\q1
\v 25 kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn,
\q2 ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi,
\q1
\v 26 kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀
\q2 tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé.
\q1
\v 27 Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn,
\q2 nígbà tí ó fi òsùwọ̀n àyíká sórí ibú omi,
\q1
\v 28 nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfúrufú lókè
\q2 tí ó sì fi orísun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹsẹ̀,
\q1
\v 29 nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi Òkun
\q2 kí omi má ba à kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀,
\q2 àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé.
\q1
\v 30 Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀
\q2 mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́,
\q2 mo ń yọ̀ nígbà gbogbo níwájú rẹ̀.
\q1
\v 31 Mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dá
\q2 mo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn.
\b
\q1
\v 32 “Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi,
\q2 ìbùkún ni fún àwọn tí ó pa ọ̀nà mi mọ́.
\q1
\v 33 Fetí sí ìtọ́sọ́nà mi kí o sì gbọ́n;
\q2 má ṣe pa á tì sápá kan.
\q1
\v 34 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetísílẹ̀ sí mi,
\q2 tí ń ṣọ́nà ní ẹnu-ọ̀nà mi lójoojúmọ́,
\q2 tí ń dúró ní ẹnu-ọ̀nà mi.
\q1
\v 35 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi rí ìyè
\q2 ó sì rí ojúrere gbà lọ́dọ̀ \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 36 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ lára
\q2 gbogbo ẹni tí ó kórìíra mi fẹ́ ikú.”
\c 9
\s2 Ìpè ti ọgbọ́n àti àìgbọ́n
\q1
\v 1 Ọgbọ́n ti kọ́ ilé rẹ̀,
\q2 ó ti gbẹ́ òpó o rẹ̀ méjèèjì,
\q1
\v 2 ó ti fi ilé pọn tí, ó ti fọ̀nà rokà.
\q2 Ó sì ti ṣètò o tábìlì oúnjẹ rẹ̀
\q1
\v 3 ó ti rán àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ jáde, ó sì ń pè,
\q2 láti ibi tí ó ga jù láàrín ìlú.
\q1
\v 4 “Jẹ́ kí gbogbo àwọn aláìgbọ́n wọ ibí wá!”
\q2 Ó ń wí fún àwọn tí kò lọ́gbọ́n pé,
\q1
\v 5 “Wá, ẹ wá jẹ́ oúnjẹ mi
\q2 sì mu wáìnì tí mo ti pò.
\q1
\v 6 Fi ìwà àìmọ̀kan rẹ sílẹ̀ ìwọ yóò sì yè;
\q2 rìn ní ọ̀nà òye.
\b
\q1
\v 7 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹlẹ́gàn wí, kọ lẹ́tà sí àbùkù
\q2 ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹni búburú wí kọ lẹ́tà sí èébú.
\q1
\v 8 Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ.
\q2 Bá ọlọ́gbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ;
\q1
\v 9 kọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì gbọ́n sí i
\q2 kọ́ olódodo ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì fi kún ìmọ̀ rẹ̀.
\b
\q1
\v 10 “Ìbẹ̀rù \nd Olúwa\nd* ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n,
\q2 ìmọ̀ nípa Ẹni Mímọ́ ni òye.
\q1
\v 11 Nítorí nípasẹ̀ mi ọjọ́ rẹ yóò gùn
\q2 ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yóò sì kún ọjọ́ ayé rẹ.
\q1
\v 12 Bí ìwọ bá gbọ́n, ọgbọ́n rẹ yóò fún ọ ní èrè:
\q2 bí ìwọ bá jẹ́ ẹlẹ́gàn, ìwọ nìkan ni yóò jìyà.”
\b
\q1
\v 13 Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo;
\q2 ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìní ìmọ̀.
\q1
\v 14 Ó jókòó ní ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀
\q2 lórí ìjókòó níbi tí ó ga jù láàrín ìlú,
\q1
\v 15 ó ń pe àwọn tí ó ń kọjá lọ,
\q2 tí wọn ń lọ tààrà ní ọ̀nà wọn.
\q1
\v 16 “Jẹ́ kí gbogbo ẹni tí ó jẹ́ aláìlóye súnmọ́ bí!”
\q2 Ni ó wí fún ẹni tí òye kù díẹ̀ ká à tó fún.
\q1
\v 17 “Omi tí a jí mu dùn
\q2 oúnjẹ tí a jẹ ní ìkọ̀kọ̀ a máa ládùn!”
\q1
\v 18 Ṣùgbọ́n wọn ò funra pé àwọn òkú wà níbẹ̀,
\q2 pé àwọn àlejò rẹ̀ wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ isà òkú.
\c 10
\ms1 Àwọn òwe Solomoni
\p
\v 1 Àwọn òwe Solomoni.
\q1 Ọlọ́gbọ́n ọmọ ń mú inú baba rẹ̀ dùn,
\q2 ṣùgbọ́n aṣiwèrè ọmọ ń ba inú ìyá rẹ̀ jẹ́.
\b
\q1
\v 2 Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrè,
\q2 ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú.
\b
\q1
\v 3 \nd Olúwa\nd* kì í jẹ́ kí ebi máa pa olódodo,
\q2 ṣùgbọ́n ó ba ète àwọn ènìyàn búburú jẹ́.
\b
\q1
\v 4 Ọwọ́ tí ó lẹ máa ń sọ ènìyàn di tálákà,
\q2 ṣùgbọ́n ọwọ́ tí ó múra ṣíṣẹ́ a máa sọ ni di ọlọ́rọ̀.
\b
\q1
\v 5 Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ,
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ.
\b
\q1
\v 6 Ìbùkún ní ó máa ń kún orí olódodo,
\q2 ṣùgbọ́n ìwà ipá máa ń kún ẹnu ènìyàn búburú.
\b
\q1
\v 7 Ìrántí olódodo yóò jẹ́ ìbùkún,
\q2 ṣùgbọ́n orúkọ ènìyàn búburú yóò jẹrà.
\b
\q1
\v 8 Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹ,
\q2 ṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun.
\b
\q1
\v 9 Ẹni tí ó ń rìn déédé, ń rìn láìléwu,
\q2 ṣùgbọ́n àṣírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú.
\b
\q1
\v 10 Ẹni tí ń ṣẹ́jú pàkòpàkò fún ibi ń fa àìbalẹ̀ ọkàn,
\q2 aláìgbọ́n tí ń ṣàròyé kiri yóò parun.
\b
\q1
\v 11 Ẹnu olódodo jẹ́ orísun ìyè,
\q2 ṣùgbọ́n ìwà ipá ni ó gba gbogbo ẹnu ènìyàn búburú.
\b
\q1
\v 12 Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀,
\q2 ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀.
\b
\q1
\v 13 Ọgbọ́n ni a ń bá lẹ́nu àwọn olóye,
\q2 ṣùgbọ́n kùmọ̀ wà fún ẹ̀yìn àwọn aláìlóye.
\b
\q1
\v 14 Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kó ìmọ̀ jọ,
\q2 ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n a máa ṣokùnfà ìparun.
\b
\q1
\v 15 Ọrọ̀ àwọn olódodo ni ìlú olódi wọn,
\q2 ṣùgbọ́n òsì ni ìparun aláìní.
\b
\q1
\v 16 Èrè olódodo ń mú ìyè wá fún wọn,
\q2 ṣùgbọ́n èrè ènìyàn búburú ń mú ìjìyà wá fún wọn.
\b
\q1
\v 17 Ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí fi ọ̀nà sí ìyè hàn,
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ ìbáwí mú àwọn mìíràn ṣìnà.
\b
\q1
\v 18 Ẹni tí ó pa ìkórìíra rẹ̀ mọ́ jẹ́ òpùrọ́
\q2 ẹni tí ó sì ń ba ni jẹ́ jẹ́ aláìgbọ́n.
\b
\q1
\v 19 Nínú ọ̀rọ̀ púpọ̀ a kò le fẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kù
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n.
\b
\q1
\v 20 Ètè olódodo jẹ́ ààyò fàdákà,
\q2 ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú kò níye lórí.
\b
\q1
\v 21 Ètè olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀,
\q2 ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ń kú nítorí àìlóye.
\b
\q1
\v 22 Ìbùkún \nd Olúwa\nd* ń mú ọrọ̀ wá,
\q2 kì í sì í fi ìdààmú sí i.
\b
\q1
\v 23 Aláìgbọ́n a máa ní inú dídùn sí ìwà búburú,
\q2 ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa ní inú dídùn sí ọgbọ́n.
\b
\q1
\v 24 Ohun tí ènìyàn búburú bẹ̀rù yóò dé bá a;
\q2 olódodo yóò rí ohun tí ó fẹ́ gbà.
\b
\q1
\v 25 Nígbà tí ìjì bá ti jà kọjá, ènìyàn búburú a kọjá lọ,
\q2 ṣùgbọ́n olódodo yóò dúró ṣinṣin láéláé.
\b
\q1
\v 26 Bí ọtí kíkan sí eyín, àti èéfín sí ojú,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ sí ẹni tí ó rán an níṣẹ́.
\b
\q1
\v 27 Ìbẹ̀rù \nd Olúwa\nd* ń mú ọjọ́ ayé gígùn wá,
\q2 ṣùgbọ́n a gé ọjọ́ ayé ènìyàn búburú kúrú.
\b
\q1
\v 28 Ìrètí olódodo ni ayọ̀,
\q2 ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú jásí òfo.
\b
\q1
\v 29 Ọ̀nà \nd Olúwa\nd* jẹ́ ààbò fún olódodo,
\q2 ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń ṣe ibi.
\b
\q1
\v 30 A kì yóò fa olódodo tu láéláé,
\q2 ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kì yóò dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.
\b
\q1
\v 31 Ẹnu olódodo ń mú ọgbọ́n jáde wá,
\q2 ṣùgbọ́n ètè àyípadà ni a ó gé kúrò.
\b
\q1
\v 32 Ètè olódodo mọ ohun ìtẹ́wọ́gbà,
\q2 ṣùgbọ́n ètè ènìyàn búburú kò mọ̀ ju èké lọ.
\b
\c 11
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd* kórìíra òsùwọ̀n èké,
\q2 ṣùgbọ́n òsùwọ̀n òtítọ́ jẹ́ inú dídùn un rẹ̀.
\b
\q1
\v 2 Nígbà tí ìgbéraga bá dé, nígbà náà ni ìdójútì dé,
\q2 ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ni ọgbọ́n ń wá.
\b
\q1
\v 3 Òtítọ́ inú ẹni dídúró ṣinṣin ń ṣe amọ̀nà rẹ̀,
\q2 ṣùgbọ́n aláìṣòótọ́ yóò parun nípasẹ̀ àìṣòótọ́ wọn.
\b
\q1
\v 4 Ọ̀rọ̀ kò níláárí ní ọjọ́ ìbínú,
\q2 ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú.
\b
\q1
\v 5 Òdodo aláìlẹ́gàn ṣe ọ̀nà tààrà fún wọn,
\q2 ṣùgbọ́n ìwà búburú ènìyàn búburú yóò fà á lulẹ̀.
\b
\q1
\v 6 Òdodo ẹni ìdúró ṣinṣin gbà wọ́n là,
\q2 ṣùgbọ́n ìdẹ̀kùn ètè búburú mú aláìṣòótọ́.
\b
\q1
\v 7 Nígbà tí ènìyàn búburú bá kú, ìrètí rẹ̀ a parun;
\q2 gbogbo ohun tó ń fojú ṣọ́nà fún nípa agbára rẹ̀ já ṣófo.
\b
\q1
\v 8 A gba olódodo kúrò lọ́wọ́ ibi dípò o rẹ̀,
\q2 ibi wá sórí ènìyàn búburú.
\b
\q1
\v 9 Aláìmọ Ọlọ́run fi ẹnu rẹ̀ ba aládùúgbò rẹ̀ jẹ́,
\q2 ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìmọ̀ olódodo sá àsálà.
\b
\q1
\v 10 Nígbà tí olódodo ń gbèrú, ìlú a yọ̀;
\q2 nígbà tí ènìyàn búburú parun, ariwo ayọ̀ gba ìlú kan.
\b
\q1
\v 11 Nípasẹ̀ ìbùkún, olódodo a gbé ìlú ga:
\q2 ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹnu ènìyàn búburú, a pa ìlú run.
\b
\q1
\v 12 Ẹni tí kò gbọ́n fojú kékeré wo aládùúgbò rẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ó ní òye pa ẹnu rẹ̀ mọ́.
\b
\q1
\v 13 Olófòófó tú àṣírí ìkọ̀kọ̀
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a pa àṣírí mọ́.
\b
\q1
\v 14 Nítorí àìní ìtọ́sọ́nà orílẹ̀-èdè ṣubú
\q2 ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn ìṣẹ́gun dájú.
\b
\q1
\v 15 Ẹni tí ó ṣe onígbọ̀wọ́ fún àlejò yóò rí ìyọnu,
\q2 ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kọ̀ láti ṣe onígbọ̀wọ́ yóò wà láìléwu.
\b
\q1
\v 16 Obìnrin oníwà rere gba ìyìn
\q2 ṣùgbọ́n alágbára aláìbìkítà ènìyàn gba ọrọ̀ nìkan.
\b
\q1
\v 17 Ènìyàn rere ń ṣe ara rẹ̀ lóore
\q2 ṣùgbọ́n ènìyàn ìkà ń mú ìyọnu wá sórí ara rẹ̀.
\b
\q1
\v 18 Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹ
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tó fúnrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú.
\b
\q1
\v 19 Olódodo tòótọ́ rí ìyè
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa ibi lé e sí ibi ikú ara rẹ̀.
\b
\q1
\v 20 \nd Olúwa\nd* kórìíra àwọn ènìyàn ọlọ́kàn búburú
\q2 ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn tí ọ̀nà wọn kò lábùkù.
\b
\q1
\v 21 Mọ èyí dájú pé, ènìyàn búburú kì yóò lọ láìjìyà,
\q2 ṣùgbọ́n àwọn olódodo yóò lọ láìjìyà.
\b
\q1
\v 22 Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀
\q2 ni arẹwà obìnrin tí kò lọ́gbọ́n.
\b
\q1
\v 23 Ìfẹ́ inú olódodo yóò yọrí sí ohun rere
\q2 ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú yóò yọrí sí ìbínú.
\b
\q1
\v 24 Ènìyàn kan ń fún ni lọ́fẹ̀ẹ́, síbẹ̀ ó ń ní sí i;
\q2 òmíràn ń háwọ́ ju bí ó ti yẹ ṣùgbọ́n ó di aláìní.
\b
\q1
\v 25 Ẹni tí ń ṣoore yóò máa gbèrú sí i;
\q2 ẹni tí ó tu ẹlòmíràn lára yóò ní ìtura.
\b
\q1
\v 26 Àwọn ènìyàn a ṣẹ́ èpè lé ènìyàn tí ń kó oúnjẹ pamọ́
\q2 ṣùgbọ́n ìbùkún a máa wá sórí ẹni tí ó ṣetán láti tà.
\b
\q1
\v 27 Ẹni tí ń lépa ohun rere yóò rí ohun rere
\q2 ṣùgbọ́n ibi yóò dé bá ẹni tí ń lépa ibi.
\b
\q1
\v 28 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóò ṣubú;
\q2 ṣùgbọ́n olódodo yóò gbilẹ̀ bí i koríko tútù.
\b
\q1
\v 29 Ẹni tí ó ń mú ìdààmú dé bá ìdílé rẹ̀ yóò jogún afẹ́fẹ́ lásán
\q2 aláìgbọ́n yóò sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún ọlọ́gbọ́n.
\b
\q1
\v 30 Èso òdodo ni igi ìyè
\q2 ẹni tí ó sì jèrè ọkàn jẹ́ ọlọ́gbọ́n.
\b
\q1
\v 31 \x - \xo 11.31: \xt (Gk): 1Pt 4.18.\x*Bí àwọn olódodo bá gba ìpín wọn lórí ilẹ̀ ayé
\q2 mélòó mélòó ni ènìyàn búburú àti àwọn tó dẹ́ṣẹ̀!
\b
\c 12
\q1
\v 1 Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ ẹ̀kọ́ fẹ́ ìmọ̀,
\q2 ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kórìíra ìbáwí jẹ́ aláìgbọ́n.
\b
\q1
\v 2 Ènìyàn rere gba ojúrere lọ́dọ̀ \nd Olúwa\nd*
\q2 ṣùgbọ́n ènìyàn ètè búburú ni yóò dá lẹ́bi.
\b
\q1
\v 3 A kò lè fi ẹsẹ̀ ènìyàn múlẹ̀ nípa ìwà búburú
\q2 ṣùgbọ́n a kò le è fa olódodo tu.
\b
\q1
\v 4 Aya oníwà rere ni adé ọkọ rẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n aya adójútini dàbí inú egungun rẹ̀ jẹrà.
\b
\q1
\v 5 Èrò àwọn olódodo tọ́,
\q2 ṣùgbọ́n ìgbìmọ̀ ènìyàn búburú jẹ́ ẹ̀tàn.
\b
\q1
\v 6 Ọ̀rọ̀ ènìyàn búburú lúgọ de ẹ̀jẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ àwọn olódodo gbà wọ́n là.
\b
\q1
\v 7 A ṣí àwọn ènìyàn búburú ní ìdí, wọn kò sì sí mọ́;
\q2 ṣùgbọ́n ilé olódodo dúró ṣinṣin.
\b
\q1
\v 8 A ń yín ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ọgbọ́n rẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ọlọ́pọlọ wúruwùru ni a kẹ́gàn.
\b
\q1
\v 9 Ó sàn kí a má jẹ́ ènìyàn pàtàkì kí a sì ní ìránṣẹ́
\q2 ju kí a díbọ́n pé a jẹ́ ẹni pàtàkì láìní oúnjẹ.
\b
\q1
\v 10 Olódodo ènìyàn ń ṣe aájò ohun tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ nílò,
\q2 ṣùgbọ́n ìyọ́nú àwọn ènìyàn búburú, ìkà ni.
\b
\q1
\v 11 Ẹni tí ó bá dá oko yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ,
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa òjìji lásán làsàn kò gbọ́n.
\b
\q1
\v 12 Ènìyàn búburú ń fẹ́ ìkógun àwọn ènìyàn ìkà
\q2 ṣùgbọ́n gbòǹgbò olódodo ń gbilẹ̀.
\b
\q1
\v 13 A mú ènìyàn búburú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n olódodo bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdààmú.
\b
\q1
\v 14 Láti inú èso rẹ̀, ènìyàn kún fún onírúurú ohun rere
\q2 bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ti ń pín in lérè dájúdájú.
\b
\q1
\v 15 Ọ̀nà aláìgbọ́n dára lójú ara rẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa gba ìmọ̀ràn.
\b
\q1
\v 16 Aláìgbọ́n ènìyàn fi ìbínú un rẹ̀ hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀,
\q2 ṣùgbọ́n olóye ènìyàn fojú fo ìyànjẹ.
\b
\q1
\v 17 Ẹni tí ó jẹ́ ajẹ́rìí òtítọ́ jẹ́rìí ohun tí ojú rẹ̀ rí
\q2 ṣùgbọ́n ajẹ́rìí èké máa ń parọ́.
\b
\q1
\v 18 Ọ̀rọ̀ tí a kò rò jinlẹ̀ máa ń gún ni bí ọ̀kọ̀
\q2 ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń mú ìwòsàn wá.
\b
\q1
\v 19 Ètè tí ń ṣọ òtítọ́ yóò wà láéláé
\q2 ṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́.
\b
\q1
\v 20 Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn àwọn tí ń pète búburú
\q2 ṣùgbọ́n ayọ̀ wà fún àwọn tí ń mú kí àlàáfíà gbilẹ̀.
\b
\q1
\v 21 Ibi kì í ṣubú lu olódodo rárá
\q2 ṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn.
\b
\q1
\v 22 \nd Olúwa\nd* kórìíra ètè tí ń parọ́
\q2 ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn olóòtítọ́.
\b
\q1
\v 23 Ènìyàn olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde.
\b
\q1
\v 24 Ọwọ́ àìṣọ̀lẹ yóò jẹ ọba
\q2 ṣùgbọ́n ọ̀lẹ ṣíṣe a máa yọrí sí ẹrú ṣíṣe.
\b
\q1
\v 25 Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodò
\q2 ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀.
\b
\q1
\v 26 Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́
\q2 ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn ṣìnà.
\b
\q1
\v 27 Ọ̀lẹ ènìyàn kò sun ẹran tí ó pa lóko ọdẹ
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí kì í ṣe ọ̀lẹ máa ń díwọ̀n ohun ìní rẹ̀.
\b
\q1
\v 28 Ní ọ̀nà àwọn olódodo ni ìyè wà
\q2 ní ọ̀nà náà ni àìkú wà.
\b
\c 13
\q1
\v 1 Ọlọ́gbọ́n ọmọ gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀,
\q2 ṣùgbọ́n ẹlẹ́gàn kò gbọ́ ìbáwí.
\b
\q1
\v 2 Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ènìyàn ń gbádùn ohun rere,
\q2 ṣùgbọ́n, ìfẹ́ ọkàn aláìṣòótọ́ ní ìwà ipá.
\b
\q1
\v 3 Ẹnikẹ́ni tí ó ṣọ́ ẹnu rẹ̀ pa ẹnu ara rẹ̀ mọ́,
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ gbàù gbàù yóò parun.
\b
\q1
\v 4 Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́, ṣùgbọ́n kò rí nǹkan kan,
\q2 ṣùgbọ́n ọkàn àwọn ti kì í ṣe ọ̀lẹ rí ìtẹ́lọ́rùn.
\b
\q1
\v 5 Olódodo kórìíra ohun tí í ṣe irọ́,
\q2 ṣùgbọ́n ènìyàn búburú hu ìwà ìríra àti ìtìjú.
\b
\q1
\v 6 Òdodo ń ṣamọ̀nà ènìyàn olóòtítọ́ inú,
\q2 ṣùgbọ́n ìwà búburú ṣí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ipò.
\b
\q1
\v 7 Ènìyàn kan díbọ́n bí ẹni tí ó ní ọrọ̀ síbẹ̀ kò ní nǹkan kan
\q2 ẹlòmíràn díbọ́n bí i tálákà, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ púpọ̀.
\b
\q1
\v 8 Ọrọ̀ ènìyàn le è ra ẹ̀mí rẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n tálákà kì í gbọ́ ìdẹ́rùbà.
\b
\q1
\v 9 Ìmọ́lẹ̀ olódodo tàn roro,
\q2 ṣùgbọ́n fìtílà ènìyàn búburú ni a pa kú.
\b
\q1
\v 10 Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ ni
\q2 ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn.
\b
\q1
\v 11 Owó tí a fi ọ̀nà èrú kójọ yóò ṣí lọ,
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀díẹ̀ yóò pọ̀ sí i.
\b
\q1
\v 12 Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè.
\b
\q1
\v 13 Ẹni tí ó kẹ́gàn ẹ̀kọ́ yóò jìyà rẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa àṣẹ mọ́ gba èrè rẹ̀.
\b
\q1
\v 14 Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè,
\q2 tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹ̀kùn ikú.
\b
\q1
\v 15 Òye pípé ń mú ni rí ojúrere,
\q2 ṣùgbọ́n ọ̀nà aláìṣòótọ́ kì í tọ́jọ́.
\b
\q1
\v 16 Gbogbo olóye ènìyàn máa ń hùwà pẹ̀lú ìmọ̀,
\q2 ṣùgbọ́n aláìgbọ́n a fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.
\b
\q1
\v 17 Ìránṣẹ́ búburú bọ́ sínú ìdààmú
\q2 ṣùgbọ́n aṣojú olóòtítọ́ mú ìwòsàn wá.
\b
\q1
\v 18 Ẹni tí ó kọ ìbáwí yóò di tálákà yóò sì rí ìtìjú,
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí ni yóò rí ọlá.
\b
\q1
\v 19 Ìfẹ́ tí a mú ṣẹ dùn mọ́ ọkàn
\q2 ṣùgbọ́n ìríra ni fún aṣiwèrè láti kúrò nínú ibi.
\b
\q1
\v 20 Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára.
\b
\q1
\v 21 Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀,
\q2 ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo.
\b
\q1
\v 22 Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀,
\q2 ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo.
\b
\q1
\v 23 Ilẹ̀ ẹ tálákà le è mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìre oko wá
\q2 ṣùgbọ́n àìṣòdodo gbá gbogbo rẹ̀ lọ.
\b
\q1
\v 24 Ẹni tí ó fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóò máa bá a wí.
\b
\q1
\v 25 Olódodo jẹ́wọ́ títí ó fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn
\q2 ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ikùn ènìyàn búburú.
\b
\c 14
\q1
\v 1 Ọlọ́gbọ́n obìnrin kọ́ ilé e rẹ̀,
\q2 ṣùgbọ́n aṣiwèrè obìnrin fi ọwọ́ ara rẹ̀ fà á lulẹ̀.
\b
\q1
\v 2 Ẹni tí ń rìn déédé bẹ̀rù \nd Olúwa\nd*,
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ kò tọ́ kẹ́gàn \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1
\v 3 Ọ̀rọ̀ aṣiwèrè a máa ṣokùnfà pàṣán fún ẹ̀yìn rẹ̀,
\q2 ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ètè ọlọ́gbọ́n a máa dáàbò bò ó.
\b
\q1
\v 4 Níbi tí kò sí ẹran, ibùjẹ ẹran a máa mọ́ tónítóní,
\q2 ṣùgbọ́n, nípa agbára akọ màlúù ni ọ̀pọ̀ ìkórè ti ń wá.
\b
\q1
\v 5 Ẹlẹ́rìí tí ń ṣọ òtítọ́ kì í tan ni
\q2 ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké a máa tú irọ́ jáde.
\b
\q1
\v 6 Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n kò sì rí rárá,
\q2 ṣùgbọ́n ìmọ̀ máa ń wà fún olóye.
\b
\q1
\v 7 Má ṣe súnmọ́ aláìgbọ́n ènìyàn,
\q2 nítorí ìwọ kì yóò rí ìmọ̀ ní ètè rẹ̀.
\b
\q1
\v 8 Ọgbọ́n olóye ni láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà wọn
\q2 ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ aṣiwèrè ni ìtànjẹ.
\b
\q1
\v 9 Aláìgbọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí ó ṣe àtúnṣe ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n láàrín àwọn olódodo ni a ti rí ojúrere.
\b
\q1
\v 10 Ọkàn kọ̀ọ̀kan ló mọ ẹ̀dùn ọkàn tirẹ̀
\q2 kò sì ṣí ẹnìkan tó le è bá ọkàn mìíràn pín ayọ̀ rẹ̀.
\b
\q1
\v 11 A ó pa ilé ènìyàn búburú run,
\q2 ṣùgbọ́n àgọ́ olódodo yóò máa gbèrú sí i.
\b
\q1
\v 12 Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn,
\q2 ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, a máa jásí ikú.
\b
\q1
\v 13 Kódà nígbà tí a ń rẹ́rìn-ín, ọkàn le è máa kérora;
\q2 ayọ̀ sì le è yọrí sí ìbànújẹ́.
\b
\q1
\v 14 A ó san án lẹ́kùnrẹ́rẹ́ fún aláìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀,
\q2 ènìyàn rere yóò sì gba èrè fún tirẹ̀.
\b
\q1
\v 15 Òpè ènìyàn gba ohun gbogbo gbọ́
\q2 ṣùgbọ́n olóye ènìyàn ronú lórí àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀.
\b
\q1
\v 16 Ọlọ́gbọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kórìíra ibi
\q2 ṣùgbọ́n aláìgbọ́n jẹ́ alágídí àti aláìṣọ́ra.
\b
\q1
\v 17 Ẹni tí ó máa ń tètè bínú máa ń hùwà aṣiwèrè,
\q2 a sì kórìíra eléte ènìyàn.
\b
\q1
\v 18 Òpè jogún ìwà òmùgọ̀
\q2 ṣùgbọ́n a dé ọlọ́gbọ́n ní adé ìmọ̀.
\b
\q1
\v 19 Ènìyàn ìkà yóò tẹríba níwájú àwọn ènìyàn rere
\q2 àti ènìyàn búburú níbi ìlẹ̀kùn àwọn olódodo.
\b
\q1
\v 20 Kódà àwọn aládùúgbò tálákà kò fẹ́ràn rẹ̀,
\q2 ṣùgbọ́n, ọlọ́rọ̀ ní ọ̀rẹ́ púpọ̀.
\b
\q1
\v 21 Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò o rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ẹni tí ó ṣàánú àwọn aláìní.
\b
\q1
\v 22 Ǹjẹ́ àwọn tí ń pète ibi kì í ṣìnà bí?
\q2 Ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbèrò ohun rere ń rí ìfẹ́ àti òtítọ́.
\b
\q1
\v 23 Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló máa ń mú èrè wá,
\q2 ṣùgbọ́n ẹjọ́ rírò lásán máa ń ta ni lósì ni.
\b
\q1
\v 24 Ọrọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni adé orí wọn
\q2 ṣùgbọ́n ìwà aláìgbọ́n ń mú ìwà òmùgọ̀ wá.
\b
\q1
\v 25 Ẹlẹ́rìí tí ó ṣọ òtítọ́ gba ẹ̀mí là
\q2 ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké jẹ́ ẹlẹ́tàn.
\b
\q1
\v 26 Nínú ìbẹ̀rù \nd Olúwa\nd* ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó lágbára,
\q2 yóò sì tún jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀.
\b
\q1
\v 27 Ìbẹ̀rù \nd Olúwa\nd* jẹ́ orísun ìyè,
\q2 tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú.
\b
\q1
\v 28 Ènìyàn púpọ̀ ní ìlú jẹ́ ògo ọba,
\q2 ṣùgbọ́n láìsí ìjòyè, ọba á parun.
\b
\q1
\v 29 Onísùúrù ènìyàn ní òye tí ó pọ̀,
\q2 ṣùgbọ́n onínú-fùfù ènìyàn máa ń fi ìwà aṣiwèrè hàn.
\b
\q1
\v 30 Ọkàn tí ó lálàáfíà fi ìyè mú kí ọjọ́ ayé gùn fún ara,
\q2 ṣùgbọ́n ìlara mú kí egungun jẹrà.
\b
\q1
\v 31 Ẹni tí ó fi ìyà jẹ aláìní ń fi ìkórìíra hàn
\q2 ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó ṣoore fún aláìní bu ọlá fún Ọlọ́run.
\b
\q1
\v 32 Nígbà tí ìyọnu bá dé, a fa àwọn búburú lulẹ̀,
\q2 kódà nínú ikú àwọn olódodo ni ààbò.
\b
\q1
\v 33 Ọgbọ́n wà nínú ọkàn olóye
\q2 kódà láàrín àwọn aláìlóye, ó jẹ́ kí wọn mọ òun.
\b
\q1
\v 34 Òdodo a máa gbé orílẹ̀-èdè lékè,
\q2 ṣùgbọ́n ìtìjú ni ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ fún àwùjọ káwùjọ.
\b
\q1
\v 35 Ọba a máa ní inú dídùn sí ìránṣẹ́ tí ó gbọ́n
\q2 ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ wá sórí ìránṣẹ́ adójútini.
\b
\c 15
\q1
\v 1 Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padà
\q2 ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ líle máa ń ru ìbínú sókè.
\b
\q1
\v 2 Ahọ́n ọlọ́gbọ́n a máa gbé ìmọ̀ jáde
\q2 ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń tú ọ̀rọ̀ ọ òmùgọ̀ jáde.
\b
\q1
\v 3 Ojú \nd Olúwa\nd* wà níbi gbogbo,
\q2 Ó ń wo àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.
\b
\q1
\v 4 Ahọ́n tí ń mú ìtura wá jẹ́ igi ìyè
\q2 ṣùgbọ́n ahọ́n ẹ̀tàn ń pa ẹ̀mí run.
\b
\q1
\v 5 Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọ́gbọ́n.
\b
\q1
\v 6 Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra,
\q2 ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn.
\b
\q1
\v 7 Ètè olódodo ń tan ìmọ̀ kalẹ̀;
\q2 ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún ọkàn aláìgbọ́n.
\b
\q1
\v 8 \nd Olúwa\nd* kórìíra ìrúbọ àwọn ènìyàn búburú
\q2 ṣùgbọ́n àdúrà olódodo tẹ́ ẹ lọ́rùn.
\b
\q1
\v 9 \nd Olúwa\nd* kórìíra ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú,
\q2 ṣùgbọ́n ó fẹ́ràn àwọn tí ń lépa òdodo.
\b
\q1
\v 10 Ẹni tí ó kúrò lójú ọ̀nà yóò rí ìbáwí gan an,
\q2 ẹni tí ó kórìíra ìbáwí yóò kú.
\b
\q1
\v 11 Ikú àti ìparun ṣí sílẹ̀ níwájú \nd Olúwa\nd*,
\q2 mélòó mélòó ní nínú ọkàn àwọn ènìyàn.
\b
\q1
\v 12 Ẹlẹ́gàn kò fẹ́ ẹni tí ń ba wí:
\q2 kò ní gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ọlọ́gbọ́n.
\b
\q1
\v 13 Inú dídùn máa ń mú kí ojú túká
\q2 ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ọkàn máa ń pa ẹ̀mí run.
\b
\q1
\v 14 Ọkàn olóye ń wá ìmọ̀
\q2 ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń fẹ́ ìwà òmùgọ̀ bí ẹní jẹun.
\b
\q1
\v 15 Gbogbo ọjọ́ àwọn olùpọ́njú jẹ́ ibi,
\q2 ṣùgbọ́n onínúdídùn ń jẹ àlàáfíà ní ìgbà gbogbo.
\b
\q1
\v 16 Ó sàn kí ó má pọ̀, kí ìbẹ̀rù \nd Olúwa\nd* sì wà
\q2 ju ọrọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú ìyọnu.
\b
\q1
\v 17 Oúnjẹ ewébẹ̀ níbi tí ìfẹ́ wà
\q2 sàn ju àbọ́pa màlúù tòun ti ìríra.
\b
\q1
\v 18 Ènìyàn onínú ríru dá ìjà sílẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n onísùúrù paná ìjà.
\b
\q1
\v 19 Ọ̀nà ọ̀lẹ ni ẹ̀gún dí,
\q2 ṣùgbọ́n ọ̀nà olódodo já geerege ni.
\b
\q1
\v 20 Ọlọ́gbọ́n ọmọ mú inú baba rẹ̀ dùn,
\q2 ṣùgbọ́n aṣiwèrè ènìyàn kẹ́gàn ìyá rẹ̀.
\b
\q1
\v 21 Inú ènìyàn aláìlóye a máa dùn sí ìwà òmùgọ̀;
\q2 ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa rin ọ̀nà tààrà.
\b
\q1
\v 22 Ìgbèrò a máa dasán níbi tí kò sí ìmọ̀ràn;
\q2 ṣùgbọ́n a máa yege níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn wà.
\b
\q1
\v 23 Inú ènìyàn a máa dùn nígbà tí ó bá fèsì tó yẹ
\q2 ọ̀rọ̀ tí ó bá sì wá lásìkò tó yẹ dára púpọ̀!
\b
\q1
\v 24 Ọ̀nà ìyè ń lọ sókè fún ọlọ́gbọ́n
\q2 láti sọ kí ó má bá à sọ̀kalẹ̀ lọ sí ipò òkú.
\b
\q1
\v 25 \nd Olúwa\nd* fa ilé onígbèéraga ya lulẹ̀,
\q2 ṣùgbọ́n ó pa ààlà opó onírẹ̀lẹ̀ mọ́ láìyẹ̀.
\b
\q1
\v 26 \nd Olúwa\nd* kórìíra èrò ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n mímọ́ ni ọ̀rọ̀ ẹni pípé.
\b
\q1
\v 27 Ọ̀kánjúwà ènìyàn mú ìyọnu bá ilé rẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò yè.
\b
\q1
\v 28 Ọkàn olódodo ń wọn ìdáhùn wò
\q2 ṣùgbọ́n ẹnu ènìyàn búburú ń tú ibi jáde.
\b
\q1
\v 29 \nd Olúwa\nd* jìnnà sí ènìyàn búburú
\q2 ṣùgbọ́n ó ń gbọ́ àdúrà olódodo.
\b
\q1
\v 30 Ojú tó túká máa ń mú ayọ̀ wá fún ọkàn,
\q2 ìròyìn ayọ̀ sì ń mú ìlera wá sínú egungun.
\b
\q1
\v 31 Ẹni tí ó fetí sí ìbáwí tí ń fún ni ní ìyè,
\q2 yóò wà ní àpéjọpọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n.
\b
\q1
\v 32 Ẹni tí ó kọ̀ ìbáwí kẹ́gàn ara rẹ̀,
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí yóò ní ìmọ̀ sí i.
\b
\q1
\v 33 Ìbẹ̀rù \nd Olúwa\nd* kọ́ ènìyàn ní ọgbọ́n,
\q2 ìrẹ̀lẹ̀ sì ni ó máa ń ṣáájú ọlá.
\b
\c 16
\q1
\v 1 Ti ènìyàn ni ìgbèrò inú ọkàn
\q2 ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ \nd Olúwa\nd* ni ìdáhùn ahọ́n ti ń wá.
\b
\q1
\v 2 Gbogbo ọ̀nà ènìyàn ni ó dàbí i pé ó dára lójú ara rẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n \nd Olúwa\nd* ló ń díwọ̀n èrò inú ọkàn.
\b
\q1
\v 3 Fi ohun gbogbo tí o bá ṣe lé \nd Olúwa\nd* lọ́wọ́,
\q2 èrò rẹ yóò sì ṣe é ṣe.
\b
\q1
\v 4 \nd Olúwa\nd* ti ṣe ohun gbogbo láti mú kí ó rí bí ó ṣe fẹ́
\q2 kódà ènìyàn búburú fún ọjọ́ ìpọ́njú.
\b
\q1
\v 5 \nd Olúwa\nd* kórìíra gbogbo ẹni tí ń gbéraga lọ́kàn rẹ̀
\q2 mọ èyí dájú pé wọn kò ní lọ láìjìyà.
\b
\q1
\v 6 Nípasẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀
\q2 nípasẹ̀ ìbẹ̀rù \nd Olúwa\nd* ènìyàn sá fún ibi.
\b
\q1
\v 7 Nígbà tí ọ̀nà ènìyàn bá tẹ́ \nd Olúwa\nd* lọ́rùn,
\q2 yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ gàn án bá a gbé ní àlàáfíà.
\b
\q1
\v 8 Ó sàn kí ó kéré pẹ̀lú òdodo
\q2 ju èrè púpọ̀ pẹ̀lú èrú lọ.
\b
\q1
\v 9 Ènìyàn a máa pète ọ̀nà ara rẹ̀ lọ́kàn an rẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n \nd Olúwa\nd* ní í pinnu ìgbésẹ̀ rẹ̀.
\b
\q1
\v 10 Ètè ọba a máa sọ̀rọ̀ nípa àṣẹ sí i
\q2 ẹnu rẹ̀ kò gbọdọ̀ ṣèké.
\b
\q1
\v 11 Òdínwọ̀n àti òsùwọ̀n òtítọ́ wá láti ọ̀dọ̀ \nd Olúwa\nd*;
\q2 gbogbo wíwúwo àpò jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀.
\b
\q1
\v 12 Àwọn ọba kórìíra ìwà àìtọ́
\q2 nítorí òdodo ní í fi ìdí ìtẹ́ múlẹ̀.
\b
\q1
\v 13 Àwọn ọba ní inú dídùn sí ètè tí ń ṣọ òtítọ́,
\q2 wọ́n sì fẹ́ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ òtítọ́.
\b
\q1
\v 14 Ìránṣẹ́ ikú ni ìbínú ọba jẹ́
\q2 ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn yóò tù ú nínú.
\b
\q1
\v 15 Nígbà tí ojú ọba bá túká, ó túmọ̀ sí ìyè;
\q2 ojúrere rẹ̀ dàbí i ṣíṣú òjò ní ìgbà òjò.
\b
\q1
\v 16 Ó ti dára tó láti ní ọgbọ́n ju wúrà lọ
\q2 àti láti yan òye dípò o fàdákà!
\b
\q1
\v 17 Òpópó ọ̀nà àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yàgò fún ibi,
\q2 ẹni tí ó ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀, ṣọ́ ẹnu ara rẹ̀.
\b
\q1
\v 18 Ìgbéraga ní í ṣáájú ìparun,
\q2 agídí ọkàn ní í ṣáájú ìṣubú.
\b
\q1
\v 19 Ó sàn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn láàrín àwọn olùpọ́njú
\q2 jù láti máa pín ìpín pẹ̀lú àwọn agbéraga.
\b
\q1
\v 20 Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀kọ́ yóò rí ìre,
\q2 ìbùkún sì ni fún ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1
\v 21 Àwọn tí ó gbọ́n nínú ọkàn là ń pè ní olóye
\q2 ọ̀rọ̀ ìtura sì ń mú ẹ̀kọ́ gbèrú.
\b
\q1
\v 22 Òye jẹ́ orísun ìyè fún àwọn tí ó ní i,
\q2 ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ ń kó ìyà jẹ aláìgbọ́n.
\b
\q1
\v 23 Ọkàn ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa ṣọ́ ẹnu rẹ̀
\q2 ètè rẹ̀ sì ń mú kí ẹ̀kọ́ dàgbà.
\b
\q1
\v 24 Ọ̀rọ̀ ìtura dàbí afárá oyin
\q2 ó dùn fún ọkàn, ó sì fi ìlera fún egungun.
\b
\q1
\v 25 Ọ̀nà kan tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn
\q2 ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn a ṣokùnfà ikú.
\b
\q1
\v 26 Ọkàn alágbàṣe ń ṣiṣẹ́ fún ara rẹ̀;
\q2 nítorí ebi rẹ̀ mú kí ó máa ṣiṣẹ́ lọ.
\b
\q1
\v 27 Ènìyàn búburú ń pète
\q2 ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì dàbí i iná tí ń jóni.
\b
\q1
\v 28 Aláyídáyidà ènìyàn dá ìjà sílẹ̀
\q2 olófòófó a sì máa pín ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ní yà.
\b
\q1
\v 29 Oníjàgídíjàgan ènìyàn tan aládùúgbò rẹ̀
\q2 ó sì mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà tí kò dára.
\b
\q1
\v 30 Ẹni tí ń ṣẹ́jú ń pètekéte;
\q2 ẹni tí ó ṣu ẹnu jọ ń pète aburú.
\b
\q1
\v 31 Adé ògo ni ewú orí jẹ́,
\q2 ìgbé ayé òdodo ní í mú ni dé bẹ̀.
\b
\q1
\v 32 Ó sàn láti jẹ́ onísùúrù ju ajagun ènìyàn lọ,
\q2 ẹni tí ó pa ìbínú mọ́ra ju ajagun ṣẹ́gun ìlú lọ.
\b
\q1
\v 33 A ṣẹ́ kèké si ìṣẹ́po aṣọ,
\q2 ṣùgbọ́n gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ \nd Olúwa\nd*.
\b
\c 17
\q1
\v 1 Òkèlè gbígbẹ tòun tàlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ sàn
\q2 ju ilé tí ó kún fọ́fọ́ fún ẹran àti ìjà.
\b
\q1
\v 2 Ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́ yóò ṣàkóso adójútini ọmọ,
\q2 yóò sì pín ogún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ.
\b
\q1
\v 3 Iná ni a fi fọ́ fàdákà àti wúrà,
\q2 ṣùgbọ́n \nd Olúwa\nd* ló ń dán ọkàn wò.
\b
\q1
\v 4 Ènìyàn búburú ń tẹ́tí sí ètè tí ń sọ ibi;
\q2 òpùrọ́ a máa fetí sí ahọ́n búburú.
\b
\q1
\v 5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sín olùpọ́njú jẹ, ó gan Ẹlẹ́dàá rẹ̀,
\q2 ẹnikẹ́ni tí ń yọ̀ sí ìyọnu kò ní lọ láìjìyà.
\b
\q1
\v 6 Ọmọ ọmọ ni adé orí arúgbó,
\q2 ògo àwọn ọmọ sì ni òbí jẹ.
\b
\q1
\v 7 Ọ̀rọ̀ dídùn kò yẹ aṣiwèrè,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ètè èké kò yẹ ọmọ-aládé!
\b
\q1
\v 8 Òkúta iyebíye jẹ́ ẹ̀bùn ní ojú ẹni tí ó ni í,
\q2 ibikíbi tí ó yí sí, á ṣe rere.
\b
\q1
\v 9 Ẹni tí ó fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ ẹ́ mú kí ìfẹ́ gbòòrò sí i.
\q2 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yóò pín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ méjì ní yà.
\b
\q1
\v 10 Ọ̀rọ̀ ìbáwí dun olóye ènìyàn
\q2 ju ọgọ́rùn-ún pàṣán lọ lẹ́yìn òmùgọ̀.
\b
\q1
\v 11 Orí kunkun ni ènìyàn ìkà máa ń ṣe,
\q2 ìjòyè aláìláàánú ni a ó rán sí i.
\b
\q1
\v 12 Ó sàn kí ènìyàn pàdé beari tí a ti kó lọ́mọ
\q2 jù aláìgbọ́n nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.
\b
\q1
\v 13 Bí ènìyàn kan bá fi ibi san ìre,
\q2 ibi kì yóò kúrò nílé rẹ̀ láéláé.
\b
\q1
\v 14 Bíbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí ẹni tí ó dá ojú fún adágún omi;
\q2 nítorí náà mẹ́nu kúrò nínú ọ̀rọ̀ kí ó tó di ìjà.
\b
\q1
\v 15 Gbígbé ẹ̀bi fún aláre àti dídá ẹni jàre lẹ́bi,
\q2 \nd Olúwa\nd* kórìíra méjèèjì.
\b
\q1
\v 16 Kí ni ìwúlò owó lọ́wọ́ aṣiwèrè,
\q2 níwọ̀n bí kò ti ní èròǹgbà láti rí ọgbọ́n?
\b
\q1
\v 17 Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo,
\q2 arákùnrin sì wà fún ìgbà ìpọ́njú.
\b
\q1
\v 18 Ènìyàn aláìgbọ́n ṣe ìbúra,
\q2 ó sì ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀.
\b
\q1
\v 19 Ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀;
\q2 ẹni tí ó kọ́ ibodè gígàn ń wá ìparun.
\b
\q1
\v 20 Ènìyàn aláyídáyidà ọkàn kì í gbèrú,
\q2 ẹni tí ó ní ahọ́n ẹ̀tàn bọ́ sínú ìyọnu.
\b
\q1
\v 21 Láti bí aláìgbọ́n lọ́mọ a máa fa ìbànújẹ́ ọkàn,
\q2 kò sí ayọ̀ fún baba ọmọ tí kò gbọ́n.
\b
\q1
\v 22 Ọkàn tí ó túká jẹ́ oògùn gidi,
\q2 ṣùgbọ́n ọkàn tí ó bàjẹ́ a máa mú kí egungun gbẹ.
\b
\q1
\v 23 Ènìyàn búburú a gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀
\q2 láti yí ìdájọ́ po.
\b
\q1
\v 24 Olóye ènìyàn gbójú wo ọgbọ́n níwájú,
\q2 ṣùgbọ́n ojú aláìgbọ́n ń wò káàkiri ilẹ̀ ayé.
\b
\q1
\v 25 Aṣiwèrè ọmọ mú ìbànújẹ́ bá baba rẹ̀
\q2 àti ìkorò fún ẹni tí ó bí i lọ́mọ.
\b
\q1
\v 26 Kò dára láti fìyà jẹ ènìyàn tí kò ṣẹ̀,
\q2 tàbí láti na ìjòyè lórí òtítọ́ inú wọn.
\b
\q1
\v 27 Ènìyàn tó ní ìmọ̀ máa ń ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ,
\q2 ènìyàn olóye sì máa ń ní sùúrù.
\b
\q1
\v 28 Kódà aláìgbọ́n máa ń dàbí ọlọ́gbọ́n bí ó bá dákẹ́,
\q2 àti bí olóye bí ó bá fètèmétè.
\b
\c 18
\q1
\v 1 Ènìyàn tí kò ba ni rẹ́ a máa lépa ìmọ̀ ara rẹ̀;
\q2 ó kọjú ìjà sí gbogbo ìdájọ́ òdodo.
\b
\q1
\v 2 Aláìgbọ́n kò rí inú dídùn sí òye
\q2 ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí sísọ èrò tirẹ̀.
\b
\q1
\v 3 Nígbà ti ènìyàn búburú dé ni ẹ̀gàn dé,
\q2 nígbà ti ẹ̀gàn dé ni ìtìjú dé.
\b
\q1
\v 4 Ọ̀rọ̀ ẹnu ènìyàn jẹ́ omi jíjìn,
\q2 ṣùgbọ́n orísun ọgbọ́n jẹ́ odò tí ń sàn.
\b
\q1
\v 5 Kò dára kí ènìyàn ṣe ojúsàájú fún ènìyàn búburú
\q2 tàbí kí a fi ìdájọ́ òdodo du aláìṣẹ̀.
\b
\q1
\v 6 Ètè aláìgbọ́n dá ìjà sílẹ̀
\q2 ẹnu rẹ̀ sì ń ṣokùnfà ẹgba.
\b
\q1
\v 7 Ẹnu aláìgbọ́n ni ó ba tirẹ̀ jẹ́,
\q2 ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹ̀kùn fún ọkàn rẹ̀.
\b
\q1
\v 8 Ọ̀rọ̀ olófòófó dàbí oúnjẹ àdídùn;
\q2 wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ.
\b
\q1
\v 9 Ẹni tí kò ṣe déédé nínú iṣẹ́ rẹ̀
\q2 arákùnrin ló jẹ́ fún apanirun.
\b
\q1
\v 10 Orúkọ \nd Olúwa\nd*, ilé ìṣọ́ agbára ni;
\q2 olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ìgbàlà.
\b
\q1
\v 11 Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọn;
\q2 wọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni.
\b
\q1
\v 12 Ṣáájú ìṣubú ọkàn ènìyàn a kọ́kọ́ máa gbéraga,
\q2 ṣùgbọ́n ìrẹ̀lẹ̀ ni ó máa ń ṣáájú ọlá.
\b
\q1
\v 13 Ẹni tí ó ń fèsì kí ó tó gbọ́,
\q2 èyí ni ìwà òmùgọ̀ àti ìtìjú rẹ̀.
\b
\q1
\v 14 Ọkàn ènìyàn a máa gbé e ró nígbà àìsàn,
\q2 ṣùgbọ́n ta ni ó le forí ti ọkàn tí ó rẹ̀wẹ̀sì.
\b
\q1
\v 15 Ọkàn olóye ní i gba ìmọ̀;
\q2 etí ọlọ́gbọ́n ní í ṣe àwárí rẹ̀.
\b
\q1
\v 16 Ẹ̀bùn máa ń ṣí ọ̀nà fún ẹni tí ń fún ni lẹ́bùn
\q2 a sì mú un wọlé sí ọ̀dọ̀ àwọn olókìkí.
\b
\q1
\v 17 Ẹni tí ó kọ́kọ́ rọjọ́ máa ń dàbí i pé ó jàre,
\q2 títí ẹlòmíràn yóò fi bọ́ síwájú kí ó sì tú àṣírí gbogbo.
\b
\q1
\v 18 Ìbò dídì máa ń parí ìjà
\q2 a sì mú kí àwọn alátakò méjì jìnnà sí ara wọn.
\b
\q1
\v 19 Arákùnrin tí a ṣẹ̀ sí ṣòro yípadà ju ìlú olódi lọ,
\q2 ìjà wọ sì dàbí ọ̀pá ìdábùú ààfin.
\b
\q1
\v 20 Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ikùn ènìyàn a yó;
\q2 láti inú ìkórè ẹnu rẹ̀ ni ó ti jẹ yó.
\b
\q1
\v 21 Ikú àti ìyè ń bẹ nípa ahọ́n wọn,
\q2 àwọn tí ó sì fẹ́ràn rẹ̀ yóò jẹ ẹ́.
\b
\q1
\v 22 Ẹni tí ó rí aya fẹ́, rí ohun rere,
\q2 o sì gba ojúrere lọ́dọ̀ \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1
\v 23 Tálákà ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú,
\q2 ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ a dáhùn pẹ̀lú ìkanra.
\b
\q1
\v 24 Ènìyàn tí ó ní ọ̀rẹ́ púpọ̀ le è parun,
\q2 ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan wà tí ó súnmọ́ ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin.
\b
\c 19
\q1
\v 1 Ó sàn kí ènìyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkù
\q2 ju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà.
\b
\q1
\v 2 Kò dára láti ní ìtara láìní ìmọ̀,
\q2 tàbí kí ènìyàn kánjú kí ó sì ṣìnà.
\b
\q1
\v 3 Ìwà òmùgọ̀ ènìyàn fúnra rẹ̀ a pa ẹ̀mí rẹ̀ run;
\q2 síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ yóò máa bínú sí \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1
\v 4 Ọrọ̀ máa ń fa ọ̀rẹ́ púpọ̀;
\q2 ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ tálákà tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
\b
\q1
\v 5 Ajẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà,
\q2 ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde kò ní lọ lọ́fẹ̀ẹ́.
\b
\q1
\v 6 Ọ̀pọ̀ ń wá ojúrere olórí;
\q2 gbogbo ènìyàn sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ó lawọ́.
\b
\q1
\v 7 Gbogbo ará ilé e tálákà ni ó pa á tì,
\q2 mélòó mélòó ni ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń sá fún un!
\q2 Bí ó tilẹ̀ ń lé wọn kiri pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀,
\q2 kò tilẹ̀ le rí wọn rárá.
\b
\q1
\v 8 Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀;
\q2 ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú.
\b
\q1
\v 9 Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyà
\q2 ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun.
\b
\q1
\v 10 Kò yẹ aláìgbọ́n láti máa gbé nínú ọláńlá,
\q2 mélòó mélòó bí ó ti burú tó fún ẹrú láti jẹ ọba lórí ọmọ-aládé.
\b
\q1
\v 11 Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní sùúrù;
\q2 fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá.
\b
\q1
\v 12 Ìbínú ọba dàbí kíké e kìnnìún,
\q2 ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko.
\b
\q1
\v 13 Aṣiwèrè ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀,
\q2 aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ òjò.
\b
\q1
\v 14 A máa ń jogún ilé àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ òbí,
\q2 ṣùgbọ́n aya olóye láti ọ̀dọ̀ \nd Olúwa\nd* ni.
\b
\q1
\v 15 Ọ̀lẹ ṣíṣe máa ń fa oorun sísùn fọnfọn,
\q2 ebi yóò sì máa pa ènìyàn tí ó lọ́ra.
\b
\q1
\v 16 Ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ pa ẹnu rẹ̀ mọ́,
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kẹ́gàn ọ̀nà rẹ̀ yóò kú.
\b
\q1
\v 17 Ẹni tí ó ṣàánú tálákà, \nd Olúwa\nd* ní ó yá,
\q2 yóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe.
\b
\q1
\v 18 Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà;
\q2 àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú ìparun un rẹ̀.
\b
\q1
\v 19 Ènìyàn onínú-fùfù gbọdọ̀ gba èrè ìwà rẹ̀;
\q2 bí ìwọ bá gbà á là, ìwọ yóò tún ní láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i.
\b
\q1
\v 20 Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́,
\q2 ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n.
\b
\q1
\v 21 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyàn,
\q2 ṣùgbọ́n ìfẹ́ \nd Olúwa\nd* ní ó máa ń borí.
\b
\q1
\v 22 Ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀;
\q2 ó sàn láti jẹ́ tálákà ju òpùrọ́ lọ.
\b
\q1
\v 23 Ìbẹ̀rù \nd Olúwa\nd* ń mú ìyè wá;
\q2 nígbà náà ọkàn ń balẹ̀, láìsí ewu.
\b
\q1
\v 24 Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ;
\q2 kò tilẹ̀ ní mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.
\b
\q1
\v 25 Na ẹlẹ́gàn, òpè yóò sì kọ́gbọ́n;
\q2 bá olóye ènìyàn wí, yóò sì ní ìmọ̀ sí i.
\b
\q1
\v 26 Ẹni tí ó ṣìkà sí baba rẹ̀, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jáde
\q1 òun ni ọmọ tí ń ṣe ìtìjú, tí ó sì mú ẹ̀gàn wá.
\b
\q1
\v 27 Ọmọ mi, dẹ́kun láti tẹ́tí sí ẹ̀kọ́,
\q2 tí í mú ni ṣìnà kúrò nínú ọ̀rọ̀-ìmọ̀.
\b
\q1
\v 28 Ẹlẹ́rìí búburú fi ìdájọ́ ṣẹ̀sín,
\q2 ẹnu ènìyàn búburú sì ń gbé ibi mì.
\b
\q1
\v 29 A ti pèsè ìjìyà sílẹ̀ fún ẹlẹ́gàn;
\q2 àti pàṣán fún ẹ̀yìn àwọn aṣiwèrè.
\b
\c 20
\q1
\v 1 Ẹlẹ́yà ni ọtí wáìnì, aláriwo sì ní ọtí líle;
\q2 ẹnikẹ́ni tí ó bá fi tànjẹ kò gbọ́n.
\b
\q1
\v 2 Ìbẹ̀rù ọba dàbí kíké e kìnnìún;
\q2 ẹnikẹ́ni tí ó bá mú un bínú ba ayé ara rẹ̀ jẹ́.
\b
\q1
\v 3 Iyì ni ó jẹ́ fún ènìyàn láti sá fún ìjà,
\q2 ṣùgbọ́n gbogbo aláìgbọ́n a máa tètè wá ìjà.
\b
\q1
\v 4 Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹ,
\q2 nítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan.
\b
\q1
\v 5 Ète ọkàn ènìyàn dàbí omi jíjìn;
\q2 ṣùgbọ́n ènìyàn olóye á wá wọn jáde.
\b
\q1
\v 6 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n máa ń sọ pe àwọn ní ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn,
\q2 ṣùgbọ́n kò rọrùn láti rí ènìyàn olóòtítọ́.
\b
\q1
\v 7 Olódodo ènìyàn a máa gbé ìgbé ayé àìlábùkù
\q2 ìbùkún ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.
\b
\q1
\v 8 Nígbà tí ọba bá jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀ láti ṣe ìdájọ́
\q2 yóò fẹ́ gbogbo ibi dànù pẹ̀lú ojú rẹ̀.
\b
\q1
\v 9 Ta ni ó le è wí pé, “Mo ti ṣe ọkàn mi ní mímọ́,
\q2 mo mọ́, n kò sì lẹ́ṣẹ̀”?
\b
\q1
\v 10 Ìwọ̀n èké àti òsùwọ̀n ìrẹ́jẹ
\q2 \nd Olúwa\nd* kórìíra méjèèjì.
\b
\q1
\v 11 Kódà a mọ ọmọdé nípa iṣẹ́ rẹ̀
\q2 nípa pe bóyá iṣẹ́ rẹ mọ́ tàbí pé ó tọ̀nà.
\b
\q1
\v 12 Etí tí ó ń gbọ́ àti ojú tí ó ń ríran
\q2 \nd Olúwa\nd* ni ó dá méjèèjì.
\b
\q1
\v 13 Má ṣe fẹ́ràn oorun, àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò di tálákà.
\q2 Ma ṣe sùn ìwọ yóò sì ní oúnjẹ láti tún fi tọrọ.
\b
\q1
\v 14 “Kò dára, kò dára!” ní ẹni tó ra ọjà máa ń wí;
\q2 nígbà tí ó bá kúrò níbẹ̀ tán,
\q2 yóò máa yangàn bí òun tí ṣe rí rà sí.
\b
\q1
\v 15 Wúrà wà, iyùn sì wà rẹpẹtẹ,
\q2 ṣùgbọ́n, ahọ́n tí ń sọ ìmọ̀ gan an ni ọ̀ṣọ́ iyebíye.
\b
\q1
\v 16 Gba abọ́ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àlejò;
\q2 mú un lọ́wọ́ bí ìbúra bí ó bá ṣe é fún obìnrin onírìnkurìn.
\b
\q1
\v 17 Oúnjẹ tí a fi ọ̀nà èrú rí máa ń dùn lẹ́nu ènìyàn,
\q2 ṣùgbọ́n, a yọrí sí ibi ẹnu tí ó kún fún erùpẹ̀.
\b
\q1
\v 18 Pa ètè rẹ mọ́ nípa wíwá ìmọ̀ràn
\q2 bí o bá ń jagun, gba ìtọ́sọ́nà.
\b
\q1
\v 19 Olófòófó a máa tú àṣírí
\q2 nítorí náà yẹra fún ènìyàn tí ń rojọ́ púpọ̀.
\b
\q1
\v 20 Bí ènìyàn kan bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀,
\q2 ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ni a ó pa kú nínú òkùnkùn biribiri.
\b
\q1
\v 21 Ogún tí a kójọ kíákíá ní ìbẹ̀rẹ̀
\q2 kì yóò ní ìbùkún ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín.
\b
\q1
\v 22 Má ṣe wí pé, “N ó sẹ̀san àṣìṣe rẹ yìí fún ọ.”
\q2 Dúró de \nd Olúwa\nd* yóò sì gbà ọ́ là.
\b
\q1
\v 23 \nd Olúwa\nd* kórìíra òdínwọ̀n èké.
\q2 Òsùwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn.
\b
\q1
\v 24 \nd Olúwa\nd* ni ó ń ṣe olùdarí ìgbésẹ̀ ènìyàn.
\q2 Báwo wá ni òye gbogbo ọ̀nà ènìyàn ṣe le yé ni?
\b
\q1
\v 25 Ìdẹ̀kùn ni fún ènìyàn láti ṣe ìlérí kíákíá
\q2 nígbà tí ó bá sì yá kí ó máa ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wò.
\b
\q1
\v 26 Ọlọ́gbọ́n ọba tú ènìyàn búburú ká;
\q2 Ó sì fi òòlọ ìpakà lọ̀ wọ́n.
\b
\q1
\v 27 Àtùpà \nd Olúwa\nd* ń ṣe àwárí ẹ̀mí ènìyàn
\q2 a máa ṣàwárí ibi ìkọ̀kọ̀ inú.
\b
\q1
\v 28 Ìfẹ́ àti òdodo pa ọba mọ́,
\q2 nípa ìfẹ́, ìtẹ́ rẹ̀ wà láìléwu.
\b
\q1
\v 29 Ògo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ni agbára wọn,
\q2 ewú orí ni iyì arúgbó.
\b
\q1
\v 30 Ìgbájú ìgbámú àti ìfarapa máa ń mú ibi lọ,
\q2 pàṣán sì máa ń ṣe àfọ̀mọ́ ibi ìkọ̀kọ̀ inú.
\b
\c 21
\q1
\v 1 Ọkàn ọba ń bẹ lọ́wọ́ \nd Olúwa\nd*;
\q2 a máa darí rẹ̀ lọ ibi tí ó fẹ́ bí ipa omi.
\b
\q1
\v 2 Gbogbo ọ̀nà ènìyàn dàbí i pé ó dára lójú rẹ̀,
\q2 ṣùgbọ́n, \nd Olúwa\nd* ló ń díwọ̀n ọkàn.
\b
\q1
\v 3 Ṣíṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ̀nà
\q2 ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà sí \nd Olúwa\nd* ju ẹbọ lọ.
\b
\q1
\v 4 Ojú tí ó gbéga àti ọkàn ìgbéraga,
\q2 ìmọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, ẹ̀ṣẹ̀ ni!
\b
\q1
\v 5 Ètè àwọn olóye jásí èrè
\q2 bí ìkánjú ṣe máa ń fa òsì kíákíá.
\b
\q1
\v 6 Ìṣúra tí a kójọ nípasẹ̀ ahọ́n tí ń parọ́
\q2 jẹ́ ìrì lásán àti ìkẹ́kùn ikú.
\b
\q1
\v 7 Ìwà ipá àwọn ènìyàn búburú yóò wọ́ wọn lọ,
\q2 nítorí wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́.
\b
\q1
\v 8 Ọ̀nà ẹlẹ́ṣẹ̀ kún fún ìwà ẹ̀ṣẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n iṣẹ́ onínú funfun jẹ́ títọ́.
\b
\q1
\v 9 Ó sàn láti máa gbé ní kọ̀rọ̀ orí òrùlé
\q2 ju láti ṣe àjọpín ilé pẹ̀lú aya oníjà.
\b
\q1
\v 10 Ènìyàn búburú ń fẹ́ ibi
\q2 aládùúgbò rẹ̀ kì í rí àánú kankan gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.
\b
\q1
\v 11 Nígbà tí a bá ń fìyà jẹ ẹlẹ́gàn,
\q2 òpè a máa kọ́gbọ́n,
\q2 nígbà tí a bá sì kọ́ ọlọ́gbọ́n yóò ní ìmọ̀.
\b
\q1
\v 12 Olódodo ṣàkíyèsí ilé ènìyàn búburú
\q2 ó sì mú ènìyàn búburú wá sí ìparun.
\s1 Ìṣúra ẹni tí o gbọ́n
\q1
\v 13 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti di etí rẹ̀ sí igbe olùpọ́njú,
\q2 òun tìkára rẹ̀ yóò ké pẹ̀lú;
\q2 ṣùgbọ́n a kì yóò gbọ́.
\b
\q1
\v 14 Ọ̀rẹ́ ìkọ̀kọ̀, mú ìbínú kúrò:
\q2 àti owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti ibi ìkọ̀kọ̀ wá,
\q2 dẹ́kun ìbínú líle.
\b
\q1
\v 15 Ayọ̀ ni fún olódodo láti ṣe ìdájọ́:
\q2 ṣùgbọ́n ìparun ni fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
\b
\q1
\v 16 Ẹni tí ó bá yà kúrò ní ọ̀nà òye,
\q2 yóò máa gbé inú ìjọ àwọn òkú.
\b
\q1
\v 17 Ẹni tí ó bá fẹ́ afẹ́, yóò di tálákà:
\q2 ẹni tí ó fẹ́ ọtí wáìnì pẹ̀lú òróró kò le lọ́rọ̀.
\b
\q1
\v 18 Ènìyàn búburú ni yóò ṣe owó ìràpadà fún olódodo,
\q2 àti olùrékọjá fún ẹni dídúró ṣinṣin.
\b
\q1
\v 19 Ó sàn láti jókòó ní aginjù ju pẹ̀lú
\q2 oníjà obìnrin àti òṣónú lọ.
\b
\q1
\v 20 Ìṣúra iyebíye àti òróró wà ní ibùgbé ọlọ́gbọ́n;
\q2 ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn n bà á jẹ́.
\b
\q1
\v 21 Ẹni tí ó bá tẹ̀lé òdodo àti àánú yóò rí ìyè,
\q2 òdodo, àti ọlá.
\b
\q1
\v 22 Ọlọ́gbọ́n gòkè odi ìlú àwọn alágbára,
\q2 ó sì bi ibi gíga agbára ìgbẹ́kẹ̀lé wọn ṣubú.
\b
\q1
\v 23 Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹnu àti ahọ́n rẹ̀ mọ́,
\q2 ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìyọnu.
\b
\q1
\v 24 Agbéraga àti alágídí ènìyàn ń gan orúkọ ara rẹ̀ nítorí ó ń hùwà nínú ìwà ìgbéraga rẹ̀,
\q2 àti nínú ìbínú púpọ̀púpọ̀.
\b
\q1
\v 25 Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé, àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò parun láé;
\q2 nítorí tí ọwọ́ rẹ̀ kọ iṣẹ́ ṣíṣe.
\q1
\v 26 Ó ń fi ìlara ṣe ojúkòkòrò ní gbogbo ọjọ́:
\q2 ṣùgbọ́n olódodo a máa fi fún ni kì í sì í dáwọ́ dúró.
\b
\q1
\v 27 Ẹbọ ènìyàn búburú, ìríra ni:
\q2 mélòó mélòó ni nígbà tí ó mú un wá pẹ̀lú èrò ìwà ibi?
\b
\q1
\v 28 Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé:
\q2 ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ẹni tí ó gbọ́, yóò dúró.
\b
\q1
\v 29 Ènìyàn búburú mú ojú ara rẹ̀ le:
\q2 ṣùgbọ́n ẹni ìdúró ṣinṣin ni ó ń mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́.
\b
\q1
\v 30 Kò sí ọgbọ́n, kò sí ìmòye,
\q2 tàbí ìmọ̀ràn tí ó le mókè níwájú \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1
\v 31 A ń múra ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun:
\q2 ṣùgbọ́n ìṣẹ́gun jẹ́ ti \nd Olúwa\nd*.
\c 22
\s2 Orúkọ rere sàn ju ọrọ̀ lọ
\q1
\v 1 Yíyan orúkọ rere sàn ju púpọ̀ ọrọ̀ lọ,
\q2 àti ojúrere dára ju fàdákà àti wúrà lọ.
\b
\q1
\v 2 Ọlọ́rọ̀ àti tálákà péjọpọ̀:
\q2 \nd Olúwa\nd* ni ẹlẹ́dàá gbogbo wọn.
\b
\q1
\v 3 Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀,
\q2 ó ṣé ara rẹ̀ mọ́:
\q2 ṣùgbọ́n àwọn òpè tẹ̀síwájú, a sì jẹ wọ́n ní yà.
\b
\q1
\v 4 Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù \nd Olúwa\nd* ni ọrọ̀ ọlá, àti ìyè.
\b
\q1
\v 5 Ègún àti ìdẹ̀kùn ń bẹ ní ọ̀nà aláyídáyidà:
\q2 ẹni tí ó bá pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóò jìnnà sí wọn.
\b
\q1
\v 6 Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀:
\q2 nígbà tí ó bá dàgbà, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.
\b
\q1
\v 7 Ọlọ́rọ̀ ṣe olórí olùpọ́njú,
\q2 ajigbèsè sì ṣe ìránṣẹ́ fún ẹni tí a jẹ ní gbèsè.
\b
\q1
\v 8 \x - \xo 22.8: \xt (Gk): 1Kọ 9.7.\x*Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn ẹ̀ṣẹ̀, yóò ká asán:
\q2 ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò kùnà.
\b
\q1
\v 9 Ẹni tí ó ní ojú àánú ni a ó bùkún fún;
\q2 nítorí tí ó fi nínú oúnjẹ rẹ̀ fún olùpọ́njú.
\b
\q1
\v 10 Lé ẹlẹ́gàn sí ìta, ìjà yóò sì jáde;
\q2 nítòótọ́ ìjà àti ẹ̀gàn yóò dẹ́kun.
\b
\q1
\v 11 Ẹni tí ó fẹ́ ìwà funfun ti àyà,
\q2 tí ó sì ń sọ̀rọ̀ iyì jáde, ọba yóò ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀.
\b
\q1
\v 12 Ojú \nd Olúwa\nd* pa ìmọ̀ mọ́,
\q2 ó sì yí ọ̀rọ̀ olùrékọjá pò.
\b
\q1
\v 13 Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún ń bẹ lóde!
\q2 Yóò pa mí ní ìgboro!”
\b
\q1
\v 14 Ẹnu àwọn àjèjì obìnrin, ihò jíjìn ni;
\q2 ẹni tí a ń bínú sí láti ọ̀dọ̀ \nd Olúwa\nd* wá ni yóò ṣubú sínú rẹ̀.
\b
\q1
\v 15 Àyà ọmọdé ni ìwà wèrè dì sí;
\q2 ṣùgbọ́n pàṣán ìtọ́ni ni yóò lé e jìnnà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
\b
\q1
\v 16 Ẹni tó ń ni tálákà lára láti ní ọrọ̀,
\q2 tí ó sì ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ,
\q1 yóò di aláìní bí ó ti wù kó rí.
\q2 Gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn.
\ms1 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́gbọ́n
\q1
\v 17 Dẹtí rẹ sílẹ̀,
\q2 kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n,
\q2 kí o sì fi àyà rẹ sí ẹ̀kọ́ mi.
\q1
\v 18 Nítorí ohun dídùn ni bí ìwọ bá pa wọ́n mọ́ ní inú rẹ;
\q2 nígbà tí a sì pèsè wọn tán ní ètè rẹ.
\q1
\v 19 Kí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ lè wà ní ti \nd Olúwa\nd*,
\q2 èmi fihàn ọ́ lónìí, àní fún ọ.
\q1
\v 20 Èmi kò ha ti kọ̀wé ohun dáradára
\q2 sí ọ ní ti ìmọ̀ràn àti ní ti ẹ̀kọ́,
\q1
\v 21 kí ó lè mú ọ mọ ìdájú ọ̀rọ̀ òtítọ́;
\q2 kí ìwọ le máa fi ìdáhùn òtítọ́
\q2 fún àwọn tí ó rán ọ?
\b
\q1
\v 22 Má ṣe ja tálákà ní olè, nítorí tí ó jẹ́ tálákà:
\q2 bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe ni olùpọ́njú lára ní ibodè,
\q1
\v 23 nítorí \nd Olúwa\nd* yóò gbèjà wọn,
\q2 yóò sì gba ọkàn àwọn tí ń gba tiwọn náà.
\b
\q1
\v 24 Má ṣe bá oníbìínú ènìyàn ṣe ọ̀rẹ́;
\q2 má sì ṣe bá ọkùnrin onínú-fùfù rìn.
\q1
\v 25 Kí ìwọ má ba à kọ́ ìwà rẹ̀, ìwọ a sì gba ìkẹ́kùn fún ara rẹ.
\b
\q1
\v 26 Má ṣe wà nínú àwọn tí ń ṣe ìgbọ̀nwọ́,
\q2 tàbí nínú àwọn tí ó dúró fún gbèsè.
\q1
\v 27 Bí ìwọ kò bá ní nǹkan tí ìwọ ó fi san,
\q2 nítorí kín ni yóò ṣe gba ẹni rẹ kúrò lábẹ́ rẹ?
\b
\q1
\v 28 Má ṣe yẹ ààlà ilẹ̀ ìgbàanì,
\q2 tí àwọn baba rẹ ti pa.
\b
\q1
\v 29 Ìwọ ha rí ènìyàn tí ó ń fi àìṣe ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ rẹ̀?
\q2 Òun yóò dúró níwájú àwọn ọba;
\q2 òun kì yóò dúró níwájú àwọn ènìyàn lásán.
\c 23
\s2 Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ohun àdídùn
\q1
\v 1 Nígbà tí ìwọ bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun,
\q2 kíyèsi ohun tí ó wà níwájú rẹ gidigidi.
\q1
\v 2 Ìwọ a sì fi ọ̀bẹ lé ara rẹ ní ọ̀fun,
\q2 bí ìwọ bá jẹ́ òkúndùn ènìyàn.
\q1
\v 3 Má ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀:
\q2 nítorí pé oúnjẹ ẹ̀tàn ni.
\b
\q1
\v 4 Má ṣe ṣe làálàá láti lọ́rọ̀:
\q2 ṣíwọ́ kúrò nínú ọgbọ́n ara rẹ.
\q1
\v 5 Ìwọ ó ha fi ojú rẹ lépa ohun tí kò sí?
\q2 Nítorí tí ọ̀rọ̀ hu ìyẹ́ apá fún ara rẹ̀,
\q2 ó sì ń fò bí idì ní ojú ọ̀run.
\b
\q1
\v 6 Má ṣe jẹ oúnjẹ ẹni tí ó háwọ́,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀.
\q1
\v 7 Nítorí pé bí ẹni tí ń ṣírò ní ọkàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí:
\q2 “Máa jẹ, kí o sì máa mu,” ni ó ń wí fún ọ;
\q2 ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò pẹ̀lú rẹ.
\q1
\v 8 Òkèlè tí ìwọ jẹ ni ìwọ ó pọ̀ jáde,
\q2 ìwọ a sì sọ ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀ nù.
\b
\q1
\v 9 Má ṣe sọ̀rọ̀ ní etí aṣiwèrè;
\q2 nítorí tí yóò gan ọgbọ́n ọ̀rọ̀ rẹ.
\b
\q1
\v 10 Má ṣe ṣí ààlà àtijọ́ kúrò;
\q2 má sì ṣe bọ́ sínú oko aláìní baba.
\q1
\v 11 Nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára;
\q2 yóò gba ìjà wọn jà sí ọ.
\b
\q1
\v 12 Fi àyà sí ẹ̀kọ́,
\q2 àti etí rẹ sí ọ̀rọ̀-ìmọ̀.
\b
\q1
\v 13 Má ṣe fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kúrò lára ọmọdé,
\q2 nítorí pé bí ìwọ bá fi pàṣán nà án, òun kì yóò kú.
\q1
\v 14 Bí ìwọ fi pàṣán nà án,
\q2 ìwọ ó sì gbà ọkàn rẹ̀ là kúrò ní ọ̀run àpáàdì.
\s2 Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n fún ọmọ rere
\q1
\v 15 Ọmọ mi, bí ọkàn rẹ bá gbọ́n,
\q2 ọkàn mi yóò yọ̀, àní èmi pẹ̀lú.
\q1
\v 16 Inú mi yóò sì dùn nígbà tí ètè rẹ̀ bá ń sọ̀rọ̀ títọ́.
\b
\q1
\v 17 Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ ó ṣe ìlara sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
\q2 ṣùgbọ́n kí ìwọ ó wà ní ìbẹ̀rù \nd Olúwa\nd*,
\q2 ní ọjọ́ gbogbo.
\q1
\v 18 Nítorí pé ìgbẹ̀yìn ń bẹ nítòótọ́;
\q2 ìrètí rẹ̀ kì yóò sì gé kúrò.
\b
\q1
\v 19 Gbọ́, ìwọ ọmọ mi, kí o sì gbọ́n,
\q2 kí o sì máa tọ́ àyà rẹ sí ọ̀nà títọ́.
\q1
\v 20 Má ṣe wà nínú àwọn ọ̀mùtí;
\q2 àti àwọn wọ̀bìà alájẹkì ọ̀jẹun;
\q1
\v 21 nítorí pé ọ̀mùtí àti ọ̀jẹun ni yóò di tálákà;
\q2 ìmúni-tòògbé ní sì ń fi àkísà wọ ọkùnrin láṣọ.
\b
\q1
\v 22 Fetí sí ti baba rẹ tí ó bí ọ,
\q2 má sì ṣe gan ìyá rẹ, nígbà tí o bá gbó.
\q1
\v 23 Ra òtítọ́, kí o má sì ṣe tà á;
\q2 ra ọgbọ́n pẹ̀lú àti ẹ̀kọ́ àti òye.
\q1
\v 24 Baba olódodo ni yóò yọ̀ gidigidi:
\q2 ẹni tí ó sì bí ọmọ ọlọ́gbọ́n,
\q2 yóò ní ayọ̀ nínú rẹ̀.
\q1
\v 25 Jẹ́ kí baba rẹ àti ìyá rẹ ó yọ̀,
\q2 sì jẹ́ kí inú ẹni tí ó bí ọ dùn.
\b
\q1
\v 26 Ọmọ mi, fi àyà rẹ fún mi,
\q2 kí o sì jẹ́ kí ojú rẹ ní inú dídùn sí ọ̀nà mi.
\q1
\v 27 Nítorí pé panṣágà obìnrin ọ̀gbun jíjìn ni;
\q2 àti àjèjì obìnrin kànga híhá ni.
\q1
\v 28 Òun á sì ba ní bùba bí olè,
\q2 a sì sọ àwọn olùrékọjá di púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn.
\b
\q1
\v 29 Ta ni ó ni òsì? Ta ni ó ni ìbànújẹ́?
\q2 Ta ni ó ni ìjà? Ta ni ó ni asọ̀? Ta ni ó ni ọgbẹ́ láìnídìí?
\q1
\v 30 Àwọn tí ó dúró pẹ́ níbi ọtí wáìnì;
\q2 àwọn tí ń lọ láti dán ọtí wáìnì àdàlú wò.
\q1
\v 31 Ìwọ má ṣe wò ọtí wáìnì nígbà tí ó pọ́n,
\q2 nígbà tí ó bá ń fi àwọ̀ rẹ̀ hàn nínú ago,
\q2 tí a gbé e mì, tí ó ń dùn.
\q1
\v 32 Níkẹyìn òun á bu ni ṣán bí ejò,
\q2 a sì bunijẹ bí i paramọ́lẹ̀.
\q1
\v 33 Ojú rẹ yóò wò àwọn àjèjì obìnrin,
\q2 àyà rẹ yóò sì sọ̀rọ̀ àyídáyidà.
\q1
\v 34 Nítòótọ́, ìwọ ó dàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ ní àárín Òkun,
\q2 tàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ lókè-ọkọ̀.
\q1
\v 35 Ìwọ ó sì wí pé, “Wọ́n lù mí; kò dùn mí;
\q2 wọ́n lù mí, èmi kò sì mọ̀:
\q1 nígbà wo ni èmi ó jí?
\q2 Èmi ó tún máa wá òmíràn láti mu.”
\b
\c 24
\q1
\v 1 Má ṣe ṣe ìlara àwọn ènìyàn búburú
\q2 má ṣe jẹ́ kí àwùjọ wọn wù ọ́;
\q1
\v 2 nítorí ọkàn wọn ń gbèrò ohun búburú,
\q2 ètè wọn sì ń sọ̀rọ̀ nípa dídá rúgúdù sílẹ̀.
\b
\q1
\v 3 Nípa ọgbọ́n ni ilé di kíkọ́
\q2 nípa òye sì ni ó ti fìdímúlẹ̀;
\q1
\v 4 nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ kún
\q2 pẹ̀lú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà tí ó sì ṣọ̀wọ́n.
\b
\q1
\v 5 Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára púpọ̀,
\q2 ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ sì ń ní agbára sí i.
\q1
\v 6 Láti jagun, ó nílò ìtọ́sọ́nà:
\q2 nínú ìṣẹ́gun ni ọ̀pọ̀ onígbìmọ̀.
\b
\q1
\v 7 Ọgbọ́n ga ju fún aṣiwèrè
\q2 àti gbọ̀ngàn ìlú níbi ibodè kò ní ohun tí yóò wí.
\b
\q1
\v 8 Ẹni tí ń pète ibi
\q2 ni a ó mọ̀ bí ènìyàn ibi.
\q1
\v 9 Ète òmùgọ̀ ènìyàn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
\q2 àwọn ènìyàn sì kórìíra ẹlẹ́gàn.
\b
\q1
\v 10 Bí ìwọ bá dákú lásìkò ìdààmú
\q2 báwo ni agbára rẹ ha ti kéré tó!
\q1
\v 11 Gba àwọn tí a ń wọ́ lọ sí ibi ikú là;
\q2 fa àwọn tó ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lọ sí ibi ìparun padà.
\q1
\v 12 Bí ìwọ bá wí pé, “Ṣùgbọ́n a kò mọ nǹkan kan nípa èyí,”
\q2 ǹjẹ́ ẹni tí ń díwọ̀n ọkàn kò kíyèsi i? Ǹjẹ́ ẹni tí ń ṣọ́ ẹ̀mí rẹ kò mọ̀ ọ́n?
\q2 Ǹjẹ́ kò ní san án fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ti ṣe?
\b
\q1
\v 13 Jẹ oyin, ìwọ ọmọ mi, nítorí tí ó dára,
\q2 oyin láti inú afárá oyin dùn lẹ́nu.
\q1
\v 14 Mọ̀ pẹ̀lú pé ọgbọ́n pẹ̀lú dùn fún ọkàn rẹ
\q2 bí ìwọ bá rí i ìrètí ọjọ́ iwájú wà fún ọ
\q2 ìrètí rẹ kì yóò sì já ṣófo.
\b
\q1
\v 15 Má ṣe ba ní ibùba bí ènìyàn búburú
\q2 láti gba ibùjókòó olódodo,
\q2 má ṣe fi ibi ìsinmi rẹ̀ ṣe ìjẹ;
\q1
\v 16 nítorí bí olódodo ènìyàn bá tilẹ̀ ṣubú ní ìgbà méje, yóò tún padà dìde sá á ni,
\q2 ṣùgbọ́n ìdààmú yóò fa ènìyàn búburú lulẹ̀.
\b
\q1
\v 17 Má ṣe yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú;
\q1 nígbà tí ó bá kọsẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yọ̀.
\q1
\v 18 Àìṣe bẹ́ẹ̀ \nd Olúwa\nd* yóò rí i yóò sì bínú
\q2 yóò sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
\b
\q1
\v 19 Má ṣe fòyà nítorí àwọn ènìyàn ibi
\q2 tàbí jowú àwọn ènìyàn búburú,
\q1
\v 20 nítorí ẹni ibi kò ní ìrètí ọjọ́ iwájú
\q2 a ó sì pa fìtílà àwọn ènìyàn búburú kú.
\b
\q1
\v 21 Bẹ̀rù \nd Olúwa\nd* àti ọba, ọmọ mi,
\q2 má sì ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí kunkun.
\q1
\v 22 Nítorí àwọn méjèèjì yóò rán ìparun òjijì sórí wọn,
\q2 ta ni ó sì mọ irú ìyọnu tí wọ́n lè mú wá?
\ms1 Àwọn ọrọ̀ ọlọ́gbọ́n mìíràn
\p
\v 23 Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú tún jẹ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n:
\q2 láti ṣe ojúsàájú níbi ìdájọ́ kò dára rárá.
\q1
\v 24 Ẹnikẹ́ni tí ó wí fún ẹlẹ́bi pé, “Ìwọ lo jàre,”
\q2 àwọn ènìyàn yóò ṣẹ́ èpè fún un àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì kọ̀ ọ́.
\q1
\v 25 Ṣùgbọ́n yóò dára fún àwọn tí ń dá ẹlẹ́bi lẹ́bi,
\q2 ọ̀pọ̀ ìbùkún yóò sì wá sórí wọn.
\b
\q1
\v 26 Ìdáhùn òtítọ́
\q2 dàbí ìfẹnukoni ní ẹnu.
\b
\q1
\v 27 Parí gbogbo iṣẹ́ ajé rẹ
\q2 sì rí i pé oko rẹ ti ṣe dáradára;
\q2 lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.
\b
\q1
\v 28 Má ṣe rojọ́ èké mọ́ aládùúgbò rẹ láìnídìí,
\q2 tàbí kí o fi ètè rẹ tannijẹ.
\q1
\v 29 Má ṣe wí pé, “Èmi yóò ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún mi;
\q2 Èmi yóò san ohun tí ó ṣe fún mi padà fún un.”
\b
\q1
\v 30 Mo kọjá níbi oko ọ̀lẹ,
\q2 mo kọjá níbi ọgbà àjàrà aláìgbọ́n ènìyàn;
\q1
\v 31 ẹ̀gún ti hù ní ibi gbogbo,
\q2 koríko ti gba gbogbo oko náà.
\q1
\v 32 Mo fi ọkàn mi sí nǹkan tí mo kíyèsi
\q2 mo sì kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tí mo rí;
\q1
\v 33 oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,
\q2 ìkáwọ́gbera díẹ̀ láti sinmi,
\q1
\v 34 òsì yóò sì dé bá ọ bí adigunjalè
\q2 àti àìní bí olè.
\c 25
\ms1 Àwọn òwe mìíràn ti Solomoni
\p
\v 1 Wọ̀nyí ni àwọn òwe mìíràn tí Solomoni pa, tí àwọn ọkùnrin Hesekiah ọba Juda dà kọ.
\q1
\v 2 Ògo Ọlọ́run ní láti fi ọ̀rọ̀ kan pamọ́;
\q2 láti rí ìdí ọ̀rọ̀ kan ni ògo àwọn ọba.
\q1
\v 3 Bí ọ̀run ṣe ga tó tí ayé sì jì
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ó ṣòro láti mọ èrò ọkàn ọba.
\b
\q1
\v 4 Mú ìdàrọ́ kúrò lára fàdákà
\q2 ohun èlò yóò sì jáde fún alágbẹ̀dẹ fàdákà.
\q1
\v 5 Mú ènìyàn búburú kúrò níwájú ọba
\q2 a ó sì fìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ nípasẹ̀ òdodo.
\b
\q1
\v 6 Má ṣe gbé ara rẹ ga níwájú ọba,
\q2 má sì ṣe jìjàdù ààyè láàrín àwọn ènìyàn pàtàkì,
\q1
\v 7 ó sàn kí ó wí fún ọ pé, “Gòkè wá síyìn-ín,”
\q2 ju wí pé kí ó dójútì ọ́ níwájú ènìyàn pàtàkì.
\b
\q1
\v 8 Ohun tí o ti fi ojú ara rẹ rí
\q2 má ṣe kánjú gbé e lọ sílé ẹjọ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe ní ìgbẹ̀yìn
\q2 bí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́?
\b
\q1
\v 9 Bí o bá ń ṣe àwíjàre rẹ níwájú aládùúgbò rẹ,
\q2 má ṣe tú àṣírí tí ẹlòmíràn ní lọ́dọ̀ rẹ,
\q1
\v 10 àìṣe bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ le dójútì ọ́
\q2 orúkọ búburú tí ìwọ bá sì gba kì yóò tán láéláé.
\b
\q1
\v 11 Ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó yẹ
\q2 ó dàbí èso wúrà nínú àpẹẹrẹ fàdákà.
\q1
\v 12 Bí i yẹtí wúrà tàbí ohun ọ̀ṣọ́ ti wúrà dáradára
\q2 ni ìbáwí ọlọ́gbọ́n fún etí tí ó bá fetísílẹ̀.
\b
\q1
\v 13 Bí títutù òjò yìnyín ní àsìkò ìkórè
\q2 ni ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olóòtítọ́ sí àwọn tí ó rán an
\q2 ó ń tu ọ̀gá rẹ̀ nínú.
\q1
\v 14 Bí ojú ṣíṣú àti afẹ́fẹ́ láìsí òjò
\q2 ni ènìyàn tí ń yangàn nípa ẹ̀bùn tí kò fún ni.
\b
\q1
\v 15 Nípa sùúrù a lè yí ọba lọ́kàn padà
\q2 ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ rírọ̀ sí egungun.
\b
\q1
\v 16 Bí ìwọ bá rí oyin, jẹ ẹ́ ní ìwọ̀nba
\q2 bí o bá jẹ ẹ́ jù, ìwọ yóò sì bì í.
\q1
\v 17 Má ṣe máa lọ sí ilé aládùúgbò rẹ nígbà gbogbo
\q2 tàbí kí ó máa lọ síbẹ̀ lálọ jù, yóò sì kórìíra rẹ.
\b
\q1
\v 18 Bí ọ̀pá, idà tàbí ọ̀kọ̀ tí ó mú
\q2 ni ènìyàn tí ó jẹ́rìí èké lòdì sí aládùúgbò rẹ̀.
\b
\q1
\v 19 Bí eyín tí ó bàjẹ́ tàbí ẹsẹ̀ tí ó rọ
\q2 ni ìgbẹ́kẹ̀lé lórí aláìṣòótọ́ ní àsìkò ìdààmú.
\q1
\v 20 Bí ẹni tí ó bọ́ra kalẹ̀ ní ọjọ́ tí òtútù mú,
\q2 tàbí, bí ọtí kíkan tí a dà sí ojú ọgbẹ́,
\q2 ní ẹni tí ń kọ orin fún ẹni tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́.
\b
\q1
\v 21 \x - \xo 25.21,22: \xt Ro 12.20.\x*Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ;
\q2 bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mú.
\q1
\v 22 Nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóò wa ẹ̀yín iná lé e lórí
\q2 \nd Olúwa\nd* yóò sì san ọ ní ẹ̀san rẹ̀ fún ọ.
\b
\q1
\v 23 Bí afẹ́fẹ́ gúúsù ti í mú òjò wá,
\q2 bí ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ṣe ń mú ojú ìbínú wá.
\b
\q1
\v 24 Ó sàn láti gbé ní ibi igun kan lórí òrùlé
\q2 ju láti bá aya oníjà gbé ilé pọ̀.
\b
\q1
\v 25 Bí omi tútù sí ọkàn tí ń ṣe àárẹ̀
\q2 ni ìròyìn ayọ̀ láti ọ̀nà jíjìn.
\b
\q1
\v 26 Bí ìsun tí ó di àbàtà tàbí kànga tí omi rẹ̀ bàjẹ́
\q2 ni olódodo tí ó fi ààyè gba ènìyàn búburú.
\b
\q1
\v 27 Kò dára láti jẹ oyin àjẹjù,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni kò pọ́n ni lé láti máa wá ọlá fún ara ẹni.
\b
\q1
\v 28 Bí ìlú tí odi rẹ̀ ti wó lulẹ̀
\q2 ni ènìyàn tí kò le kó ara rẹ̀ ní ìjánu.
\c 26
\q1
\v 1 Bí òjò-dídì tàbí òjò ní ìgbà ìkórè
\q2 ọlá kò yẹ aláìgbọ́n ènìyàn.
\q1
\v 2 Bí ológoṣẹ́ tí ń ṣí kiri tàbí alápáǹdẹ̀dẹ̀ tí ń rábàbà
\q2 èpè kò le è mọ́ ẹni tí kò ṣiṣẹ́ èpè
\q2 èpè kì í jani bí a kò bá ṣiṣẹ́ èpè.
\q1
\v 3 Ẹgba fún ẹṣin, ìjánu fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
\q2 àti pàṣán fún ẹ̀yìn aṣiwèrè.
\q1
\v 4 Má ṣe dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀
\q2 àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ pẹ̀lú yóò dàbí i rẹ̀.
\q1
\v 5 Dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀
\q2 àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò dàbí ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ̀.
\q1
\v 6 Bí ìgbà tí ènìyàn gé ẹsẹ̀ ara rẹ̀ tàbí mú ìwà ipá
\q2 ni kí a ránṣẹ́ nípasẹ̀ aṣiwèrè.
\q1
\v 7 Bí ẹsẹ̀ arọ tí ó ń mi dirodiro
\q2 ni òwe lẹ́nu aṣiwèrè.
\q1
\v 8 Bí ìgbà tí a so òkúta mọ́ okùn títa
\q2 ni fífún aláìgbọ́n ní ọlá.
\q1
\v 9 Bí ẹ̀gún èṣùṣú lọ́wọ́ ọ̀mùtí
\q2 ni òwe lẹ́nu aláìgbọ́n.
\q1
\v 10 Bí tafàtafà ti ń ṣe ni léṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan
\q2 ni ẹni tí ó gba aṣiwèrè ṣíṣẹ́ tàbí ẹni tí ń kọjá lọ.
\q1
\v 11 \x - \xo 26.11: \xt 2Pt 2.22.\x*Bí ajá ti í padà sí èébì rẹ̀
\q2 bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè tún ń hu ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.
\q1
\v 12 Ǹjẹ́ o rí ènìyàn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ̀?
\q2 Ìrètí ń bẹ fún aláìgbọ́n ènìyàn jù ú lọ.
\b
\q1
\v 13 Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún wà lójú ọ̀nà
\q2 kìnnìún búburú ń ké ní ojú ọ̀nà.”
\q1
\v 14 Bí ìlẹ̀kùn ti ń yí lórí ìsolẹ̀kùn rẹ̀,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ń yí lórí ibùsùn rẹ̀.
\q1
\v 15 Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ,
\q2 ó lẹ dé bi pé kò le è mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.
\q1
\v 16 Ọ̀lẹ gbọ́n ní ojú ara rẹ̀,
\q2 ju ènìyàn méje tí wọ́n le è fún un ní ìdáhùn ọlọ́gbọ́n.
\b
\q1
\v 17 Bí ènìyàn tí ó di ajá ní etí mú
\q2 ni ẹni tí ń kọjá lọ tí ó dá sí ọ̀rọ̀ ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀.
\b
\q1
\v 18 Bí i asínwín ti ń ju
\q2 ọfà àti ọfà tí ń ṣe kú pa ni
\q1
\v 19 ni ènìyàn tí ń tan aládùúgbò rẹ̀ jẹ
\q2 tí ó sì wí pé, “Àwàdà lásán ni mo ń ṣe.”
\b
\q1
\v 20 Láìsí igi, iná yóò kú
\q2 láìsí ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìjà máa ń parí.
\q1
\v 21 Bí èédú ti rí sí ẹyin iná, igi fún iná,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn oníjà fún ìjà dídá sílẹ̀.
\q1
\v 22 Ọ̀rọ̀ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn dàbí àṣàyàn òkèlè
\q2 wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ.
\b
\q1
\v 23 Ètè jíjóni, àti àyà búburú,
\q2 dà bí ìdàrọ́ fàdákà tí a fi bo ìkòkò.
\q1
\v 24 Ènìyàn tí ó kórìíra máa ń fi ètè rẹ̀ bo àṣírí ara rẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ ni ìtànjẹ wà.
\q1
\v 25 Bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ fanimọ́ra, má ṣe gbà á gbọ́
\q2 nítorí ìríra méje ni ó kún inú ọkàn rẹ̀.
\q1
\v 26 Ìkórìíra rẹ le è fi ara sin nípa ẹ̀tàn
\q2 ṣùgbọ́n àṣírí ìwà búburú rẹ̀ yóò tú ní gbangba.
\q1
\v 27 Bí ènìyàn kan bá gbẹ́ kòtò, yóò ṣubú sínú rẹ̀.
\q2 Bí ẹnìkan bá ju òkúta, yóò padà sọ́dọ̀ òun tìkára rẹ̀.
\q1
\v 28 Ahọ́n ẹ̀tàn máa ń kórìíra àwọn tí ó ṣe ní ìkà,
\q2 ẹnu ìtànjẹ sì máa ń pa ni run.
\b
\c 27
\q1
\v 1 Má ṣe yangàn nítorí ọ̀la
\q2 nítorí o kò mọ ohun tí ọjọ́ kan le è mú wáyé.
\b
\q1
\v 2 Jẹ́ kí ẹlòmíràn yìn ọ́ dípò ẹnu ara rẹ,
\q2 àní àlejò, kí ó má sì ṣe ètè ìwọ fúnra rẹ̀.
\b
\q1
\v 3 Òkúta wúwo, erùpẹ̀ sì wúwo
\q2 ṣùgbọ́n ìbínú aṣiwèrè wúwo ju méjèèjì lọ.
\b
\q1
\v 4 Ìbínú ni ìkà, ìrunú sì burú púpọ̀
\q2 ṣùgbọ́n ta ni ó le è dúró níwájú owú?
\b
\q1
\v 5 Ìbániwí gbangba sàn
\q2 ju ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ lọ.
\b
\q1
\v 6 Òtítọ́ ni ọgbẹ́ ọ̀rẹ́,
\q2 ṣùgbọ́n ìfẹnukonu ọ̀tá ni ẹ̀tàn.
\b
\q1
\v 7 Kódà oyin kò dùn lẹ́nu ẹni tí ó ti yó
\q2 ṣùgbọ́n òróǹró gan an dùn lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.
\b
\q1
\v 8 Bí ẹyẹ tí ó ṣáko lọ kúrò níbi ìtẹ́ rẹ̀
\q2 ni ènìyàn tí ó ṣáko lọ kúrò ní ilé rẹ̀.
\b
\q1
\v 9 Ìpara olóòórùn dídùn àti tùràrí ń mú ayọ̀ wá sínú ọkàn
\q2 bẹ́ẹ̀ ni inú dídùn láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ń wá láti inú ìmọ̀ràn tí ó ṣàkóso.
\b
\q1
\v 10 Má ṣe kọ ọ̀rẹ́ rẹ àti ọ̀rẹ́ baba rẹ sílẹ̀,
\q2 má sì ṣe lọ sílé arákùnrin rẹ nígbà tí ìdààmú dé bá ọ
\q2 ó sàn kí o jẹ́ aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni ju arákùnrin tí ó jìnnà sí ni.
\b
\q1
\v 11 Gbọ́n, ọmọ mi, kí o sì mú ayọ̀ wá sínú ọkàn mi
\q2 nígbà náà ni mo le dá gbogbo ẹni tí ó bá kẹ́gàn mi.
\b
\q1
\v 12 Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fi ara pamọ́
\q2 ṣùgbọ́n aláìgbọ́n rí, kàkà kí ó dúró ó tẹ̀síwájú, ó sì jìyà rẹ̀.
\b
\q1
\v 13 Gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àjèjì
\q2 fi ṣe ẹ̀rí ìdúró bí o bá ṣe onídùúró fún obìnrin oníṣekúṣe.
\b
\q1
\v 14 Bí ènìyàn kan ń kígbe súre fún aládùúgbò rẹ ní òwúrọ̀
\q2 a ó kà á sí bí èpè.
\b
\q1
\v 15 Àyà tí ó máa ń jà dàbí
\q2 ọ̀wààrà òjò ní ọjọ́ tí òjò ń rọ̀;
\q1
\v 16 dídá a lẹ́kun dàbí ìgbà tí ènìyàn ń dá afẹ́fẹ́ lẹ́kun
\q2 tàbí bí ẹni tí ó gbá òróró.
\b
\q1
\v 17 Bí irin tí ń pọ́n irin mú
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ń pọ́n ẹlòmíràn mú.
\b
\q1
\v 18 Ẹni tí ó tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóò jẹ èso rẹ̀
\q2 ẹni tí ó sì fojú tó ọ̀gá rẹ̀ yóò gba ọlá.
\b
\q1
\v 19 Bí omi tí ń ṣe àfihàn ojú, nígbà tí a bá wò ó
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ènìyàn ń ṣe àfihàn ènìyàn.
\b
\q1
\v 20 Kò tẹ́ ikú àti ìparun lọ́rùn rí
\q2 bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ojú ènìyàn kò rí ìtẹ́lọ́rùn rí.
\b
\q1
\v 21 Iná fún fàdákà iná ìléru fún wúrà,
\q2 ṣùgbọ́n a ń dán ènìyàn wò nípa ìyìn tí ó ń gbà.
\b
\q1
\v 22 Bí a tilẹ̀ gún aláìgbọ́n nínú odó,
\q2 fi ọmọ odó gún un bí èlùbọ́
\q2 ìwọ kì yóò le è yọ ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ kúrò ní inú rẹ̀.
\b
\q1
\v 23 Rí i dájú pé o mọ ipò tí àwọn agbo àgùntàn rẹ wà
\q2 bojútó àwọn agbo màlúù rẹ dáradára;
\q1
\v 24 nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí
\q2 adé kì í sì í wà lórí títí láéláé.
\b
\q1
\v 25 Nígbà tí a bá kó koríko, ewéko tuntun yóò sì hù jáde, a ó sì kó koríko àwọn orí òkè wọlé
\q1
\v 26 àwọn àgùntàn yóò pèsè aṣọ fún ọ,
\q2 àti ewúrẹ́ yóò pèsè owó oko.
\b
\q1
\v 27 Ìwọ yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà ewúrẹ́
\q2 láti bọ́ ọ àti ìdílé rẹ
\q2 àti láti tọ́jú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ.
\b
\c 28
\q1
\v 1 Ènìyàn búburú ń sá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkan kò lé e
\q2 ṣùgbọ́n olódodo láyà bí i kìnnìún.
\b
\q1
\v 2 Nígbà tí orílẹ̀-èdè bá ní orí kunkun, àwọn ọba rẹ̀ a máa pọ̀,
\q2 ṣùgbọ́n olóye àti onímọ̀ a máa pa òfin mọ́.
\b
\q1
\v 3 Ọba tí ó ni àwọn tálákà lára
\q2 dàbí àgbàrá òjò tí ó ń gbá gbogbo ọ̀gbìn lọ.
\b
\q1
\v 4 Àwọn tí ó kọ òfin sílẹ̀ a máa gbóríyìn fún ènìyàn búburú
\q2 ṣùgbọ́n àwọn tí ó pa òfin mọ́ kọjú ìjà sí ènìyàn búburú.
\b
\q1
\v 5 Òye ìdájọ́ òdodo kò yé àwọn ẹni ibi
\q2 ṣùgbọ́n ó yé àwọn tí ń wá \nd Olúwa\nd* dáradára.
\b
\q1
\v 6 Ó sàn láti jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ jẹ́ aláìlábùkù
\q2 ju ọlọ́rọ̀ tí ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla.
\b
\q1
\v 7 Ẹni tí ó pa òfin mọ́ jẹ́ olóye ọmọ
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ẹ́ jẹgúdújẹrá kẹ́gbẹ́ dójútì baba rẹ̀.
\b
\q1
\v 8 Ẹni tí ó mú ọrọ̀ rẹ̀ di púpọ̀ nípa èrè àjẹjù
\q2 ń kó jọ fún ẹlòmíràn, tí yóò ní àánú àwọn tálákà.
\b
\q1
\v 9 Bí ẹnikẹ́ni bá kọ etí ikún sí òfin,
\q2 kódà àdúrà rẹ̀ jẹ́ ìríra.
\b
\q1
\v 10 Ẹni tí ó mú olódodo rìn ọ̀nà búburú
\q2 yóò bọ́ sínú pàkúté ara rẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n aláìlẹ́gàn yóò gba ogún rere.
\b
\q1
\v 11 Ọlọ́rọ̀ ènìyàn le è gbọ́n lójú ara rẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n tálákà tí ó ní òye rí ìdí, rẹ̀.
\b
\q1
\v 12 Nígbà tí olódodo ń lékè ariwo ayọ̀ ta;
\q2 ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú gorí òye, àwọn ènìyàn a na pápá bora.
\b
\q1
\v 13 Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò ṣe rere,
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ máa ń rí àánú gbà.
\b
\q1
\v 14 Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run nígbà gbogbo
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ó sé ọkàn rẹ̀ le bọ́ sínú wàhálà.
\b
\q1
\v 15 Bí kìnnìún tí ń ké tàbí Beari tí ń halẹ̀
\q2 ni ènìyàn búburú tí ń jẹ ọba lórí àwọn aláìlágbára.
\b
\q1
\v 16 Ọmọ-aládé tí ó ṣe aláìmòye púpọ̀ ní ń ṣe ìwà ìkà púpọ̀ pẹ̀lú,
\q2 ṣùgbọ́n èyí tí ó kórìíra ojúkòkòrò yóò mú ọjọ́ rẹ̀ pẹ́.
\b
\q1
\v 17 Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn
\q2 yóò máa joró rẹ̀ títí ikú
\q2 má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ràn án lọ́wọ́.
\b
\q1
\v 18 Ẹni tí ń rìn déédéé ní yóò là,
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà ni yóò ṣubú lójijì.
\b
\q1
\v 19 Ẹni tí ó bá ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò ní oúnjẹ lọ́pọ̀lọ́pọ̀
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ń lé ohun asán yóò kún fún òsì.
\b
\q1
\v 20 Olóòtítọ́ ènìyàn yóò rí ìbùkún gbà gan an
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ojú ń kán láti di ọlọ́rọ̀ kì yóò lọ láìjìyà.
\b
\q1
\v 21 Ojúsàájú ṣíṣe kò dára,
\q2 síbẹ̀ ènìyàn kan ń ṣẹ̀ nítorí òkèlè oúnjẹ kan.
\b
\q1
\v 22 Ahun ń sáré àti là
\q2 kò sì funra pé òsì dúró de òun.
\b
\q1
\v 23 Ẹni tí ó bá ènìyàn kan wí yóò rí ojúrere ni nígbẹ̀yìn
\q2 ju ẹni tí ó ní ètè ẹ̀tàn lọ.
\b
\q1
\v 24 Ẹni tí ó ja baba tàbí ìyá rẹ̀ lólè
\q2 tí ó sì wí pé, “Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀,”
\q2 irú kan ni òun àti ẹni tí ń pa ni run.
\b
\q1
\v 25 Ọ̀kánjúwà ènìyàn a máa dá ìjà sílẹ̀,
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd* yóò gbilẹ̀.
\b
\q1
\v 26 Ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀ jẹ́ aláìgbọ́n
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ń rìn nínú ọgbọ́n wà láìléwu.
\b
\q1
\v 27 Ẹni tí ó ń fi fún tálákà kì yóò ṣe aláìní ohunkóhun,
\q2 ṣùgbọ́n ẹni tí ó di ojú rẹ̀ sí wọn gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ègún.
\b
\q1
\v 28 Nígbà tí ènìyàn búburú bá dórí ìjọba, àwọn ènìyàn a na pápá bora;
\q2 ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú bá ṣègbé,
\q2 àwọn olódodo ń gbilẹ̀ sí i.
\b
\c 29
\q1
\v 1 Ẹni tí ó sì ń ṣorí kunkun lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbáwí
\q2 yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe.
\b
\q1
\v 2 Nígbà tí olódodo bá ń gbilẹ̀, àwọn ènìyàn a yọ̀
\q2 nígbà tí ènìyàn búburú ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn ń kórìíra.
\b
\q1
\v 3 Ènìyàn tí ó fẹ́ràn ọgbọ́n mú kí baba rẹ̀ láyọ̀
\q2 ṣùgbọ́n ẹni ti ń bá panṣágà kẹ́gbẹ́ ba ọrọ̀ ọ rẹ̀ jẹ́.
\b
\q1
\v 4 Nípa ìdájọ́ òdodo ni ọba fi í mú ìlú tòrò nini,
\q2 ṣùgbọ́n èyí tí ń ṣe ojúkòkòrò àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fà á lulẹ̀.
\b
\q1
\v 5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá tan aládùúgbò rẹ̀
\q2 ó ń dẹ àwọ̀n de ẹsẹ̀ ẹ rẹ̀.
\b
\q1
\v 6 Ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn ibi ni ó jẹ́ ìdẹ̀kùn rẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n olódodo le è kọrin kí ó sì máa yọ̀.
\b
\q1
\v 7 Olódodo ń máa ro ọ̀rọ̀ tálákà,
\q2 ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kò sú sí i láti rò ó.
\b
\q1
\v 8 Àwọn ẹlẹ́yà a máa ru ìlú sókè,
\q2 ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn máa ń mú ìbínú kúrò.
\b
\q1
\v 9 Bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn bá lọ sí ilé ẹjọ́ pẹ̀lú aláìgbọ́n
\q2 aláìgbọ́n a máa bínú a sì máa jà, kò sì ní sí àlàáfíà.
\b
\q1
\v 10 Àwọn tí ó ń tàjẹ̀ sílẹ̀ kò rí ẹni dídúró ṣinṣin
\q2 wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa olódodo.
\b
\q1
\v 11 Aláìgbọ́n ènìyàn fi gbogbo ẹnu rẹ̀ bínú
\q2 ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa kó ìbínú rẹ̀ ní ìjánu.
\b
\q1
\v 12 Bí olórí bá fetí sí irọ́,
\q2 gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ a di ènìyàn búburú lójú rẹ̀.
\b
\q1
\v 13 Tálákà ènìyàn àti aninilára jọ ní àbùdá yìí,
\q2 \nd Olúwa\nd* jẹ́ kí ojú àwọn méjèèjì máa ríran.
\b
\q1
\v 14 Bí ọba kan bá ń ṣe ìdájọ́ tálákà pẹ̀lú òtítọ́
\q2 ìtẹ́ ìjọba rẹ yóò fìdímúlẹ̀ nígbà gbogbo.
\b
\q1
\v 15 Ọ̀pá ìbániwí ń fún ni ní ọgbọ́n
\q2 ṣùgbọ́n ọmọ tí a fi sílẹ̀ fúnra rẹ̀ a dójútì ìyá rẹ̀.
\b
\q1
\v 16 Nígbà tí ènìyàn búburú ń gbilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀ṣẹ̀ ń gbilẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n olódodo yóò rí ìṣubú wọn.
\b
\q1
\v 17 Bá ọmọ rẹ wí, yóò sì fún ọ ní àlàáfíà
\q2 yóò sì mú inú dídùn wá sí inú ọkàn rẹ.
\b
\q1
\v 18 Níbi tí kò ti sí ìfihàn, àwọn ènìyàn a gbé ìgbé ayé àìbìkítà,
\q2 ṣùgbọ́n ìbùkún ní fún àwọn tí ń pa òfin mọ́.
\b
\q1
\v 19 A kò le fi ọ̀rọ̀ lásán kìlọ̀ fún ìránṣẹ́
\q2 bí ó tilẹ̀ yé e, kò ní kọbi ara sí i.
\b
\q1
\v 20 Ǹjẹ́ ó rí ènìyàn tí ń kánjú sọ̀rọ̀?
\q2 Ìrètí wà fún aláìgbọ́n jù ú lọ.
\b
\q1
\v 21 Bí ènìyàn kan bá kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lákẹ̀ẹ́jù láti kékeré
\q2 yóò mú ìbànújẹ́ wá ní ìgbẹ̀yìn.
\b
\q1
\v 22 Oníbìínú ènìyàn a ru ìjà sókè,
\q2 onínú-fùfù ènìyàn a sì máa dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀.
\b
\q1
\v 23 Ìgbéraga ènìyàn a máa sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀
\q2 ṣùgbọ́n onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn a máa gba iyì kún iyì.
\b
\q1
\v 24 Ẹni tí ó ń kó ẹgbẹ́, olè kórìíra ọkàn ara rẹ̀,
\q2 ó ń gbọ́ èpè olóhun kò sì le è fọhùn.
\b
\q1
\v 25 Ìbẹ̀rù ènìyàn kan yóò sì di ìdẹ̀kùn
\q2 ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bẹ̀rù \nd Olúwa\nd* wà láìléwu.
\b
\q1
\v 26 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ń wá ojúrere alákòóso,
\q2 ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ \nd Olúwa\nd* ni ènìyàn tí ń gba ìdájọ́ òdodo.
\b
\q1
\v 27 Olódodo kórìíra àwọn aláìṣòótọ́:
\q2 ènìyàn búburú kórìíra olódodo.
\c 30
\ms1 Àwọn ọ̀rọ̀ tí Aguri sọ.
\p
\v 1 Àwọn ọ̀rọ̀ Aguri ọmọ Jake, ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ tí ọkùnrin yìí sọ fún Itieli.
\q1 Sí Itieli àti sí Ukali.
\b
\q1
\v 2 “Èmi ni aláìmòye ju nínú àwọn ènìyàn;
\q2 n kò ní òye ènìyàn.
\q1
\v 3 Èmi kò tilẹ̀ kọ́ ọgbọ́n
\q2 tàbí ní ìmọ̀ ẹni mímọ́ nì.
\q1
\v 4 Ta ni ó ti gòkè lọ sí ọ̀run tí ó sì padà sọ̀kalẹ̀?
\q2 Ta ni ó ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ihò àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀?
\q1 Ta ni ó ti ta kókó omi sétí aṣọ?
\q2 Ta ni ó fi gbogbo ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀?
\q1 Kí ni orúkọ rẹ̀, àti orúkọ ọmọ rẹ̀?
\q2 Sọ fún mi bí o bá mọ̀.
\b
\b
\q1
\v 5 “Gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ aláìlábùkù;
\q2 òun ni ààbò fún gbogbo ẹni fi í ṣe ibi ìpamọ́ wọn.
\q1
\v 6 Má ṣe fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀,
\q2 àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò bá ọ wí yóò sì sọ ọ́ di òpùrọ́.
\b
\q1
\v 7 “Ohun méjì ni mo ń béèrè lọ́wọ́ rẹ, \nd Olúwa\nd*;
\q2 má ṣe fi wọ́n dù mí kí ń tó kú.
\q1
\v 8 Mú èké ṣíṣe àti irọ́ jìnnà sí mi;
\q2 má ṣe fún mi ní òsì tàbí ọrọ̀,
\q2 ṣùgbọ́n fún mi ní oúnjẹ òòjọ́ mi nìkan.
\q1
\v 9 Àìṣe bẹ́ẹ̀, mo lè ní àníjù kí n sì gbàgbé rẹ
\q2 kí ń sì wí pé, Ta ni \nd Olúwa\nd*?
\q1 Tàbí kí ń di òtòṣì kí ń sì jalè
\q2 kí ń sì ṣe àìbọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run mi.
\b
\q1
\v 10 “Má ṣe ba ìránṣẹ́ lórúkọ jẹ́ lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀,
\q2 kí ó má ba fi ọ́ bú, kí ìwọ má ba jẹ̀bi.
\b
\q1
\v 11 “Àwọn kan wá ṣépè fún àwọn baba wọn
\q2 tí wọn kò sì súre fún àwọn ìyá wọn.
\q1
\v 12 Àwọn tí ó mọ́ ní ojú ara wọn
\q2 síbẹ̀ tí wọn kò sì mọ́ kúrò nínú èérí wọn;
\q1
\v 13 àwọn ẹni tí ojú wọn gbéga nígbà gbogbo,
\q2 tí ìwolẹ̀ wọn sì kún fún ìgbéraga.
\q1
\v 14 Àwọn ẹni tí eyín wọn jẹ́ idà
\q2 àwọn tí èrìgì wọn kún fún ọ̀bẹ
\q1 láti jẹ àwọn tálákà run kúrò ní ilẹ̀ ayé
\q2 àwọn aláìní kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn.
\b
\q1
\v 15 “Eṣúṣú ni ọmọbìnrin méjì.
\q2 Mú wá! Mú wá! ní wọn ń ké.
\b
\li1 “Àwọn nǹkan mẹ́ta kan wà tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn láéláé,
\li2 mẹ́rin tí kò jẹ́ wí láéláé pé, ‘Ó tó!:
\li3
\v 16 Ibojì, inú tí ó yàgàn,
\li3 ilẹ̀ tí omi kì í tẹ́lọ́rùn láéláé,
\li3 àti iná, tí kì í wí láéláé pé, ‘Ó tó!
\b
\q1
\v 17 “Ojú tí ń fi baba ṣẹ̀fẹ̀,
\q2 tí ó kẹ́gàn ìgbọ́ràn sí ìyá,
\q1 ẹyẹ ìwò ẹ̀bá odò ni yóò yọ ọ́,
\q2 igún yóò mú un jẹ.
\b
\li1
\v 18 “Àwọn nǹkan mẹ́ta wà tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi,
\li2 mẹ́rin tí kò yé mi,
\li3
\v 19 ipa ẹyẹ idì ní òfúrufú
\li3 ipa ejò lórí àpáta
\li3 ipa ọkọ̀ ojú omi lójú agbami Òkun
\li3 àti ipa ọ̀nà ọkùnrin tí ó mú wúńdíá lọ́wọ́.
\b
\q1
\v 20 “Èyí ni ọ̀nà alágbèrè obìnrin
\q2 ó jẹun ó sì nu ẹnu rẹ̀
\q2 ó sì wí pé, N kò ṣe ohunkóhun tí kò tọ́.
\b
\li1
\v 21 “Lábẹ́ nǹkan mẹ́ta ni ilé ayé ti ń wárìrì
\li2 lábẹ́ ohun mẹ́rin ni kò ti lè mí fín ín.
\li3
\v 22 Ìránṣẹ́ tí ó di ọba
\li3 aláìgbọ́n tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ,
\li3
\v 23 obìnrin tí gbogbo ènìyàn kórìíra tí ó sì wá lọ́kọ
\li3 ìránṣẹ́bìnrin tí ó gbọkọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.
\b
\li1
\v 24 “Àwọn ohun mẹ́rin ló kéré láyé
\li2 síbẹ̀ wọ́n gbọ́n gidigidi.
\li1
\v 25 Àwọn èèrà jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá,
\li3 síbẹ̀ wọ́n kó oúnjẹ wọn pamọ́ ní àsìkò òjò.
\li2
\v 26 Ehoro jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá;
\li3 síbẹ̀ wọ́n ń ṣe ihò wọn sí ibi pálapàla àpáta;
\li2
\v 27 àwọn eṣú kò ní ọba,
\li3 síbẹ̀ gbogbo wọ́n ń jáde lọ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́
\li2
\v 28 Ọmọnílé fi ọwọ́ rẹ̀ dì mú,
\li3 síbẹ̀ a ń rí i ní ààfin ọba.
\b
\li1
\v 29 “Àwọn ohun mẹ́ta ní ń bẹ tí ń rìn rere,
\li2 ohun mẹ́rin ni ó dára púpọ̀ ní ìrìn rírìn:
\li3
\v 30 Kìnnìún, alágbára láàrín ẹranko tí kì í sá fún ohunkóhun
\li3
\v 31 Ẹsin tí a dì lẹ́gbẹ̀ẹ́;
\li3 àti òbúkọ,
\li3 àti ọba láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
\b
\q1
\v 32 “Bí ìwọ bá ti hùwà aṣiwèrè nípa gbígbé ara rẹ ga,
\q2 tàbí tí o bá ti gbèrò ibi,
\q2 da ọwọ́ rẹ bo ẹnu rẹ!
\q1
\v 33 Nítorí bí fífún omi ọmú tí í mú wàrà wá,
\q2 tí fífún imú sì ń mú ẹ̀jẹ̀ jáde,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni rírú ìbínú sókè í mú ìjà wá.”
\c 31
\ms1 Àwọn ọ̀rọ̀ ọba Lemueli
\p
\v 1 Àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ ti Lemueli ọba, ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ìyá rẹ̀ kọ́ ọ,
\q1
\v 2 “Gbọ́ ìwọ ọmọ mi, gbọ́ ìwọ ọmọ inú mi!
\q2 Gbọ́ ìwọ ọmọ ẹ̀jẹ́ mi.
\q1
\v 3 Má ṣe lo agbára rẹ lórí obìnrin,
\q2 okun rẹ lórí àwọn tí ó pa àwọn ọba run.
\b
\q1
\v 4 “Kì í ṣe fún àwọn ọba, ìwọ Lemueli,
\q2 kì í ṣe fún ọba láti mu ọtí wáìnì,
\q2 kì í ṣe fún alákòóso láti máa wá ọtí líle,
\q1
\v 5 kí wọn má ba à mu ọtí yó kí wọn sì gbàgbé ohun tí òfin wí,
\q2 kí wọn sì fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ara ń ni dù wọ́n.
\q1
\v 6 Fi ọtí líle fún àwọn tí ń ṣègbé
\q2 wáìnì fún àwọn tí ó wà nínú ìrora.
\q1
\v 7 Jẹ́ kí wọn mu ọtí kí wọn sì gbàgbé òsì wọn
\q2 kí wọn má sì rántí òsì wọn mọ́.
\b
\q1
\v 8 “Sọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn tí kò le sọ̀rọ̀ fúnra wọn
\q2 fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹni tí ń parun.
\q1
\v 9 Sọ̀rọ̀ kí o sì ṣe ìdájọ́ àìṣègbè
\q2 jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà àti aláìní.”
\ms1 Ìkádìí: Aya oníwà rere
\q1
\v 10 Ta ni ó le rí aya oníwà rere?
\q2 Ó níye lórí ju iyùn lọ.
\q1
\v 11 Ọkọ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé púpọ̀ nínú rẹ̀
\q2 kò sì ṣí ìwà rere tí kò pé lọ́wọ́ rẹ̀.
\q1
\v 12 Ire ní ó ń ṣe fún un, kì í ṣe ibi
\q2 ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
\q1
\v 13 Ó sa aṣọ irun àgùntàn olówùú àti ọ̀gbọ̀
\q2 Ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyárí.
\q1
\v 14 Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò;
\q2 ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn.
\q1
\v 15 Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn;
\q2 ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀
\q2 àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀.
\q1
\v 16 Ó kíyèsi oko kan, ó sì rà á;
\q2 nínú ohun tí ó ń wọlé fún un ó gbin ọgbà àjàrà rẹ̀.
\q1
\v 17 Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tagbára tagbára
\q2 apá rẹ̀ le koko fún iṣẹ́.
\q1
\v 18 Ó rí i pé òwò òun pé
\q2 fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú ní òru.
\q1
\v 19 Ní ọwọ́ rẹ̀, ó di kẹ̀kẹ́ òwú mú
\q2 ó sì na ọwọ́ rẹ̀ di ìrànwú mú.
\q1
\v 20 O la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn tálákà
\q2 ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní.
\q1
\v 21 Nígbà tí òjò-dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀
\q2 nítorí gbogbo wọn ni ó wọ aṣọ tí ó nípọn.
\q1
\v 22 Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀;
\q2 ẹ̀wù dáradára àti elése àlùkò ni aṣọ rẹ̀.
\q1
\v 23 A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibodè ìlú
\q2 níbi tí ó ń jókòó láàrín àwọn àgbàgbà ìlú.
\q1
\v 24 Ó ń ṣe àwọn aṣọ dáradára ó sì ń tà wọ́n
\q2 ó sì ń kó ọjà fún àwọn oníṣòwò.
\q1
\v 25 Agbára àti ọlá ni ó wò ọ́ láṣọ
\q2 ó le fi ọjọ́ iwájú rẹ́rìn-ín.
\q1
\v 26 A sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n
\q2 ìkọ́ni òtítọ́ sì ń bẹ létè e rẹ̀
\q1
\v 27 Ó ń bojútó gbogbo ètò ilé rẹ̀
\q2 kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́.
\q1
\v 28 Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde wọ́n sì pè é ní alábùkún
\q2 ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ń gbóríyìn fún un.
\q1
\v 29 “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ní ń ṣe nǹkan ọlọ́lá
\q2 ṣùgbọ́n ìwọ ju gbogbo wọn lọ.”
\q1
\v 30 Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asán
\q2 nítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù \nd Olúwa\nd* yẹ kí ó gba oríyìn.
\q1
\v 31 Sì fún un ní èrè tí ó tọ́ sí i
\q2 kí o sì jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ̀ fún un ní ìyìn ní ẹnu ibodè ìlú.