Biblica_yoOBYO17/19PSAyoOBYO17.SFM

9535 lines
348 KiB
Plaintext
Raw Permalink Blame History

This file contains ambiguous Unicode characters

This file contains Unicode characters that might be confused with other characters. If you think that this is intentional, you can safely ignore this warning. Use the Escape button to reveal them.

\id PSA - Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible (Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
\rem Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
\h Saamu
\toc1 Ìwé Saamu
\toc2 Saamu
\toc3 Sm
\mt1 Ìwé Saamu
\c 1
\ms ÌWÉ KÌN-ÍN-NÍ
\mr Saamu 141
\cl Saamu 1
\q1
\v 1 \x - \xo 1.1-3: \xt Jr 17.7-8.\x*Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,
\q2 tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,
\q1 ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
\q2 tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.
\q1
\v 2 Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin \nd Olúwa\nd*
\q2 àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.
\q1
\v 3 Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,
\q2 tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀
\q1 tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.
\q2 Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.
\b
\q1
\v 4 Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!
\q2 Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà
\q2 tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.
\q1
\v 5 Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.
\b
\q1
\v 6 Nítorí \nd Olúwa\nd* ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo,
\q2 ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.
\c 2
\cl Saamu 2
\q1
\v 1 \x - \xo 2.1-2: \xt Ap 4.25-26.\x*Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀,
\q2 àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán?
\q1
\v 2 Àwọn ọba ayé péjọpọ̀
\q2 àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀
\q2 sí \nd Olúwa\nd* àti sí ẹni àmì òróró rẹ̀.
\q1
\v 3 Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já,
\q2 kí a sì ju ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”
\b
\q1
\v 4 Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín;
\q2 Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.
\q1
\v 5 Nígbà náà ni yóò bá wọn wí ní ìbínú rẹ̀
\q2 yóò sì dẹ́rùbà wọ́n ní ìrunú rẹ̀, ó wí pé,
\q1
\v 6 “Èmi ti fi ọba mi sí ipò
\q2 lórí Sioni, òkè mímọ́ mi.”
\p
\v 7 \x - \xo 2.7: \xt Mt 3.17; Ap 13.33; Hb 1.5; 5.5; 2Pt 1.17.\x*Èmi yóò sì kéde ìpinnu \nd Olúwa\nd*:
\q1 Ó sọ fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi;
\q2 lónìí, èmi ti di baba rẹ.
\q1
\v 8 \x - \xo 2.8-9: \xt If 2.26; 12.5; 19.15.\x*Béèrè lọ́wọ́ mi,
\q2 Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè di ìní rẹ,
\q2 òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún rẹ.
\q1
\v 9 Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn
\q2 ìwọ yóò sì rún wọn wómúwómú bí ìkòkò amọ̀.”
\b
\q1
\v 10 Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n;
\q2 ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé.
\q1
\v 11 Ẹ sin \nd Olúwa\nd* pẹ̀lú ìbẹ̀rù
\q2 ẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì.
\q1
\v 12 Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínú,
\q2 kí ó má ba à pa yín run ní ọ̀nà yín,
\q1 nítorí ìbínú rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan.
\q2 Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi í ṣe ibi ìsádi wọn.
\c 3
\cl Saamu 3
\d Saamu ti Dafidi. Nígbà ti ó sá fún ọmọ rẹ̀ Absalomu.
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd*, báwo ni àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó báyìí!
\q2 Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!
\q1
\v 2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé
\q2 “Ọlọ́run kò nígbà á là.” \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 3 Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, \nd Olúwa\nd*;
\q2 ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.
\q1
\v 4 \nd Olúwa\nd* ni mo kígbe sókè sí,
\q2 ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 5 Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn;
\q2 mo sì tún padà jí, nítorí \nd Olúwa\nd* ni ó ń gbé mi ró.
\q1
\v 6 Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn
\q2 tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.
\b
\q1
\v 7 Dìde, \nd Olúwa\nd*!
\q2 Gbà mí, Ọlọ́run mi!
\q1 Lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní àgbọ̀n;
\q2 kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú.
\b
\q1
\v 8 Láti ọ̀dọ̀ \nd Olúwa\nd* ni ìgbàlà ti wá.
\q2 Kí ìbùkún rẹ wà lórí àwọn ènìyàn rẹ. \qs Sela.\qs*
\c 4
\cl Saamu 4
\d Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Dafidi.
\q1
\v 1 Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́,
\q2 ìwọ Ọlọ́run òdodo mi.
\q1 Fún mi ní ìdáǹdè nínú ìpọ́njú mi;
\q2 ṣàánú fún mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi.
\b
\q1
\v 2 Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, tí ẹ ó ṣe sọ ògo mi di ìtìjú?
\q2 Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, tí ẹ̀yin yóò ṣe fẹ́ràn ìtànjẹ àti tí ẹ̀yin yóò fi máa wá ọlọ́run èké?
\q1
\v 3 Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, \nd Olúwa\nd* ti ya ẹni olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀;
\q2 \nd Olúwa\nd* yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.
\b
\q1
\v 4 \x - \xo 4.4: \xt Ef 4.26.\x*Ẹ bínú ẹ má ṣe ṣẹ̀,
\q2 nígbà tí ẹ bá wà lórí ibùsùn yín,
\q2 ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀, kí ó sì dákẹ́ jẹ́.
\q1
\v 5 Ẹ rú ẹbọ òdodo
\q2 kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1
\v 6 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń béèrè pé, “Ta ni yóò ṣe rere fún wa?”
\q2 \nd Olúwa\nd*, jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí wa lára,
\q1
\v 7 Ìwọ ti fi ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi
\q2 ju ìgbà tí hóró irúgbìn àti wáìnì tuntun wọ́n pọ̀ fún mi lọ.
\b
\q1
\v 8 Èmi yóò dùbúlẹ̀, èmi ó sì sùn ní àlàáfíà,
\q2 nítorí ìwọ nìkan, \nd Olúwa\nd*,
\q2 ni o mú mi gbé láìléwu.
\c 5
\cl Saamu 5
\d Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin fífọn. Saamu ti Dafidi.
\q1
\v 1 Fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, \nd Olúwa\nd*,
\q2 kíyèsi àròyé mi.
\q1
\v 2 Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́,
\q2 ọba mi àti Ọlọ́run mi,
\q2 nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí.
\b
\q1
\v 3 Ní òwúrọ̀, \nd Olúwa\nd*, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi;
\q2 ní òwúrọ̀, èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú rẹ̀
\q2 èmi yóò sì dúró ní ìrètí.
\q1
\v 4 Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú;
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé.
\q1
\v 5 Àwọn agbéraga kò le è dúró
\q2 níwájú rẹ̀.
\q1 Ìwọ kórìíra gbogbo àwọn aṣebi;
\q2
\v 6 ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run.
\q1 Apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyàn
\q2 ni \nd Olúwa\nd* yóò kórìíra.
\q1
\v 7 Ṣùgbọ́n èmi, nípa títóbi àánú rẹ̀,
\q2 èmi yóò wá sínú ilé rẹ̀;
\q1 ní tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni èmi yóò tẹríba
\q2 sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀.
\b
\q1
\v 8 Tọ́ mi, \nd Olúwa\nd*, nínú òdodo rẹ,
\q2 nítorí àwọn ọ̀tá mi,
\q2 mú ọ̀nà rẹ tọ́ níwájú mi.
\q1
\v 9 \x - \xo 5.9: \xt Ro 3.13.\x*Kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ẹnu wọn tí a lè gbàgbọ́;
\q2 ọkàn wọn kún fún ìparun.
\q1 Ọ̀nà ọ̀fun wọn ni isà òkú tí ó ṣí sílẹ̀;
\q2 pẹ̀lú ahọ́n wọn ni wọ́n ń sọ ẹ̀tàn.
\q1
\v 10 Dá wọn lẹ́bi Ọlọ́run!
\q2 Jẹ́ kí rìkíṣí wọn jẹ́ ìṣubú wọn.
\q1 Lé wọn jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
\q2 nítorí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.
\q1
\v 11 Ṣùgbọ́n, jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó sádi ọ́ kí ó yọ̀;
\q2 jẹ kí wọn máa kọrin fún ayọ̀ títí.
\q1 Tan ààbò rẹ sórí wọn,
\q2 àti àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ yóò máa yọ̀ nínú rẹ.
\b
\q1
\v 12 Dájúdájú, \nd Olúwa\nd*, ìwọ bùkún olódodo;
\q2 ìwọ fi ojúrere rẹ yí wọn ká bí asà.
\c 6
\cl Saamu 6
\d Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin olókùn. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi.
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd*, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ
\q2 kí ìwọ má ṣe nà mí nínú gbígbóná ìrunú rẹ.
\q1
\v 2 Ṣàánú fún mi, \nd Olúwa\nd*, nítorí èmi ń kú lọ;
\q2 \nd Olúwa\nd*, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira.
\q1
\v 3 Ọkàn mi wà nínú ìrora.
\q2 Yóò ti pẹ́ tó, \nd Olúwa\nd*, yóò ti pẹ́ tó?
\b
\q1
\v 4 Yípadà, \nd Olúwa\nd*, kí o sì gbà mí;
\q2 gbà mí là nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í ṣákì í.
\q1
\v 5 Ẹnikẹ́ni kò ni rántí rẹ nígbà tí ó bá kú.
\q2 Ta ni yóò yìn ọ́ láti inú isà òkú?
\b
\q1
\v 6 Agara ìkérora mi dá mi tán.
\b
\q1 Gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkún,
\q2 mo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé.
\q1
\v 7 Ojú mi di aláìlera pẹ̀lú ìbànújẹ́;
\q2 wọ́n kùnà nítorí gbogbo ọ̀tá mi.
\b
\q1
\v 8 \x - \xo 6.8: \xt Mt 7.23; Lk 13.27.\x*Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi,
\q2 nítorí \nd Olúwa\nd* ti gbọ́ igbe mi.
\q1
\v 9 \nd Olúwa\nd* ti gbọ́ ẹkún mi fún àánú;
\q2 \nd Olúwa\nd* ti gba àdúrà mi.
\q1
\v 10 Gbogbo àwọn ọ̀tá mi lójú yóò tì, wọn yóò sì dààmú;
\q2 wọn yóò sì yípadà nínú ìtìjú àìròtẹ́lẹ̀.
\c 7
\cl Saamu 7
\d Ṣiggaioni ti Dafidi, èyí tí ó kọ sí \nd Olúwa\nd* nípa Kuṣi, ará Benjamini.
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run mi, ààbò mi wà nínú rẹ;
\q2 gba mí là kí o sì tú mi sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń lé mi,
\q1
\v 2 kí wọn ó má ba à fa ọkàn mi ya gẹ́gẹ́ bí kìnnìún,
\q2 wọ́n á ya á pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tí yóò gbà mí.
\b
\q1
\v 3 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run mi, tí èmi bá ṣe èyí
\q2 tí ẹ̀bi sì wà ní ọwọ́ mi.
\q1
\v 4 bí èmi bá ṣe ibi sí ẹni tí ń wá àlàáfíà pẹ̀lú mi,
\q2 tí mo ja ọ̀tá mi lólè láìnídìí,
\q1
\v 5 nígbà náà, jẹ́ kí ọ̀tá mi lé mi kí wọn sì mú mi;
\q2 jẹ́ kí òun kí ó tẹ ọkàn mi mọ́lẹ̀
\q2 kí wọn sì mú mi sùn nínú eruku. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 6 Dìde, \nd Olúwa\nd*, nínú ìbínú rẹ;
\q2 dìde lòdì sí ìrunú àwọn ọ̀tá mi.
\q2 Jí, Ọlọ́run mi; kéde òdodo.
\q1
\v 7 Kí ìpéjọ àwọn ènìyàn yíká.
\q2 Jọba lórí wọn láti òkè wá.
\q2
\v 8 Jẹ́ kí \nd Olúwa\nd* ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.
\q1 Ṣe ìdájọ́ mi, \nd Olúwa\nd*, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,
\q2 gẹ́gẹ́ bí ìwà òtítọ́, ẹni gíga jùlọ.
\q1
\v 9 \x - \xo 7.9: \xt If 2.23.\x*Ọlọ́run Olódodo,
\q2 Ẹni tí ó ń wo inú àti ọkàn,
\q1 tí ó ń mú òpin sí ìwà ipá ẹni búburú
\q2 tí ó sì ń pa àwọn olódodo mọ́.
\b
\q1
\v 10 Ààbò mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run,
\q2 ẹni tí ń ṣe ìgbàlà òtítọ́ ní àyà.
\q1
\v 11 Ọlọ́run ni onídàájọ́ òtítọ́,
\q2 Ọlọ́run tí ń sọ ìrunú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́.
\q1
\v 12 Bí kò bá yípadà,
\q2 Òun yóò pọ́n idà rẹ̀ mú;
\q2 ó ti fa ọrun rẹ̀ le ná, ó ti múra rẹ̀ sílẹ̀.
\q1
\v 13 Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀;
\q2 ó ti pèsè ọfà iná sílẹ̀.
\b
\q1
\v 14 Ẹni tí ó lóyún ohun búburú,
\q2 tí ó sì lóyún wàhálà, ó bí èké jáde.
\q1
\v 15 Ẹni tí ó gbẹ́ ọ̀fìn, tí ó kó o jáde
\q2 jì sí kòtò tí ó gbẹ́ sílẹ̀.
\q1
\v 16 Wàhálà tí ó fà padà sórí rẹ̀;
\q2 ìwà ipá rẹ̀ padà sórí ara rẹ̀.
\b
\q1
\v 17 Èmi ó fi ọpẹ́ fún \nd Olúwa\nd* nítorí òdodo rẹ̀,
\q2 èmi ó kọrin ìyìn sí \nd Olúwa\nd* Ọ̀gá-ògo jùlọ.
\c 8
\cl Saamu 8
\d Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Saamu ti Dafidi.
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd*, Olúwa wa,
\q2 orúkọ rẹ̀ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!
\b
\q1 Ìwọ ti gbé ògo rẹ ga
\q2 ju àwọn ọ̀run lọ.
\q1
\v 2 \x - \xo 8.2: \xt Mt 21.16.\x*Láti ẹnu ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ọmú
\q2 ni o ti yan ìyìn nítorí àwọn ọ̀tá rẹ,
\q2 láti pa àwọn ọ̀tá àti àwọn olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.
\q1
\v 3 Nígbà tí mo ro ọ̀run rẹ,
\q2 iṣẹ́ ìka rẹ,
\q1 òṣùpá àti ìràwọ̀,
\q2 tí ìwọ tí gbé kalẹ̀,
\q1
\v 4 kí ni ènìyàn tí ìwọ ń rò nípa rẹ̀,
\q2 àní ọmọ ènìyàn tí ìwọ ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀?
\b
\q1
\v 5 Ìwọ ṣe é ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju Ọlọ́run lọ,
\q2 ìwọ sì dé e ní adé ògo àti ọlá.
\q1
\v 6 Ìwọ mú un jẹ ọba lórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ;
\q2 ìwọ sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:
\q1
\v 7 àwọn agbo àgùntàn àti àwọn màlúù,
\q2 àti ẹranko igbó,
\q1
\v 8 ẹyẹ ojú ọrun,
\q2 àti ẹja inú Òkun,
\q2 àti ohun tí ń wẹ nínú ipa Òkun.
\b
\q1
\v 9 \nd Olúwa\nd*, Olúwa wa,
\q2 orúkọ rẹ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!
\c 9
\cl Saamu 9
\d Fún adarí orin. Ní ti ohun orin. “Ní ti ikú ọmọ.” Saamu ti Dafidi.
\q1
\v 1 Èmi ó yìn ọ́, \nd Olúwa\nd*, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;
\q2 èmi ó sọ ti ìyanu rẹ gbogbo.
\q1
\v 2 Inú mi yóò dùn, èmi yóò sì yọ̀ nínú rẹ;
\q2 èmi ó kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.
\b
\q1
\v 3 Àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà;
\q2 wọ́n kọsẹ̀ wọn sì ṣègbé níwájú rẹ.
\q1
\v 4 Nítorí ìwọ ti di òtítọ́ àti ọ̀ràn mi mú;
\q2 ìwọ ti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ, láti ṣe ìdájọ́ òdodo.
\q1
\v 5 Ìwọ ti bá orílẹ̀-èdè wí, Ìwọ sì ti pa ẹni búburú run;
\q2 Ìwọ ti yọ orúkọ wọn kúrò láé àti láéláé.
\q1
\v 6 Ìparun àìlópin ti borí àwọn ọ̀tá,
\q2 ìwọ ti fa àwọn ìlú wọn tu;
\q2 àní ìrántí wọn sì ti ṣègbé.
\b
\q1
\v 7 \nd Olúwa\nd* jẹ ọba títí láé;
\q2 ó ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́.
\q1
\v 8 \x - \xo 9.8: \xt Ap 17.31.\x*Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ ayé ní òdodo;
\q2 yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo.
\q1
\v 9 \nd Olúwa\nd* ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,
\q2 ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú.
\q1
\v 10 Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀lé ọ,
\q2 nítorí, \nd Olúwa\nd*, kò kọ àwọn tó ń wá a sílẹ̀.
\b
\q1
\v 11 Kọ orin ìyìn sí \nd Olúwa\nd*, tí o ń jẹ ọba ní Sioni;
\q2 kéde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ṣe.
\q1
\v 12 Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí;
\q2 òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.
\b
\q1
\v 13 \nd Olúwa\nd*, wo bí àwọn ọ̀tá ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi!
\q2 Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu-ọ̀nà ikú,
\q1
\v 14 kí èmi kí ó lè sọ ti ìyìn rẹ
\q2 ni ẹnu-ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Sioni
\q2 àti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.
\b
\q1
\v 15 Àwọn orílẹ̀-èdè ti jì sí kòtò tí wọn ti gbẹ́;
\q2 ẹsẹ̀ wọn ni àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ kọ́.
\q1
\v 16 A mọ \nd Olúwa\nd* nípa òdodo rẹ̀;
\q2 àwọn ènìyàn búburú ni a dẹ́kun mú nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
\q1
\v 17 Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú,
\q2 àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run.
\q1
\v 18 Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a kò ní gbàgbé láéláé,
\q2 ìrètí àwọn ti ó tálákà ni a kì yóò gbàgbé láéláé.
\b
\q1
\v 19 Dìde, \nd Olúwa\nd*, má ṣe jẹ́ kí ènìyàn borí;
\q2 jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ni iwájú rẹ.
\q1
\v 20 Lù wọ́n pẹ̀lú ìpayà, \nd Olúwa\nd*;
\q2 jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé ènìyàn lásán ni wọ́n. \qs Sela.\qs*
\c 10
\cl Saamu 10
\q1
\v 1 Èéha ti ṣe, \nd Olúwa\nd*, tí ìwọ fi dúró ní òkè réré?
\q2 Èéha ti ṣe, tí ìwọ fi ara rẹ pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú?
\b
\q1
\v 2 Nínú àrékérekè ni ènìyàn búburú tí mu aláìlera,
\q2 ẹni ti ó mú nínú ìdẹ̀kùn àrékérekè rẹ̀.
\q1
\v 3 Nítorí ènìyàn búburú ń ṣògo ìfẹ́ inú ọkàn rẹ̀;
\q2 Ó bùkún olójúkòkòrò, ó sì ń kẹ́gàn \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 4 Ènìyàn búburú kò lè rí nínú ìgbéraga rẹ̀;
\q2 kò sí ààyè fún Ọlọ́run nínú gbogbo èrò rẹ̀.
\q1
\v 5 Ọ̀nà rẹ̀ ń gún régé nígbà gbogbo;
\q2 òun ń gbéraga, òfin rẹ̀ sì jìnnà sí i;
\q2 òun kẹ́gàn àwọn ọ̀tá rẹ̀.
\q1
\v 6 O wí fún ara rẹ̀, “Kò sí ohun tí ó lè mì mí.
\q2 Inú mi yóò máa dùn nígbà gbogbo, èmi kò sì ní ní wàhálà.”
\b
\q1
\v 7 \x - \xo 10.7: \xt Ro 3.14.\x*Ẹnu rẹ̀ kún fún ègún àti irọ́ àti ìtànjẹ;
\q2 wàhálà àti ohun búburú wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.
\q1
\v 8 Ó lúgọ ní bùba nítòsí ìletò.
\q2 Ò gọ níbi ìkọ̀kọ̀ láti pa aláìṣẹ̀.
\q1 Ojú rẹ̀ ń ṣọ́ àwọn tálákà ní ìkọ̀kọ̀.
\q2
\v 9 Ó ba ní ní bùba bí i kìnnìún nínú pàǹtí;
\q1 Ó ba ní bùba láti mú àwọn aláìní ìrànwọ́;
\q2 ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n rẹ̀.
\q1
\v 10 Ó ba, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀;
\q2 kí tálákà ba à le bọ́ sí ọwọ́ agbára rẹ̀.
\q1
\v 11 Ó wí fún ara rẹ̀, “Ọlọ́run ti gbàgbé;
\q2 Ó pa ojú rẹ̀ mọ́, òun kì yóò rí i láéláé.”
\b
\q1
\v 12 Dìde, \nd Olúwa\nd*! Gbé ọwọ́ rẹ sókè, Ọlọ́run.
\q2 Má ṣe gbàgbé àwọn olùpọ́njú.
\q1
\v 13 Èéṣe tí ènìyàn búburú ṣe ń kẹ́gàn Ọlọ́run?
\q2 Èéṣe tí o fi wí nínú ọkàn ara rẹ̀,
\q2 “Kò ní pè mí láti ṣe ìṣirò”?
\q1
\v 14 Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni ó rí wàhálà àti ìrora;
\q2 Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ rẹ.
\q1 Tálákà fi ara rẹ̀ jì fún ọ;
\q2 Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba.
\q1
\v 15 Ṣẹ́ apá àwọn ènìyàn búburú àti ènìyàn ibi;
\q2 pè é láti wá ṣírò fún ìwà ìkà rẹ̀
\q2 tí a kò le è rí.
\b
\q1
\v 16 \nd Olúwa\nd* ń jẹ ọba láé àti láéláé;
\q2 àwọn orílẹ̀-èdè yóò ṣègbé lórí ilé rẹ.
\q1
\v 17 Ìwọ́ gbọ́, \nd Olúwa\nd*, ìfẹ́ àwọn tí a ni lára;
\q2 Ìwọ gbà wọ́n níyànjú, ó sì gbọ́ igbe wọn,
\q1
\v 18 láti ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní baba àti àwọn ti a ni lára,
\q2 kí ọkùnrin, tí ó wà ní ayé,
\q2 kí ó má ṣe dẹ́rùbà ni mọ́.
\c 11
\cl Saamu 11
\d Fún adarí orin. Ti Dafidi.
\q1
\v 1 Ìgbẹ́kẹ̀lé mi wà nínú \nd Olúwa\nd*.
\q2 Báwo ní ẹ̀yin ó ṣe sọ fún ọkàn mi pé,
\q2 “Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè rẹ.
\q1
\v 2 Wò ó nítorí náà, ènìyàn búburú fa ọfà rẹ̀;
\q2 wọn ti fi ọfà wọn sí ojú okùn
\q1 láti tafà níbi òjìji
\q2 sí àyà ẹni ìdúró ṣinṣin.
\q1
\v 3 Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́
\q2 kí ni olódodo yóò ṣe?”
\b
\q1
\v 4 \nd Olúwa\nd* ń bẹ nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀;
\q2 \nd Olúwa\nd* ń bẹ lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run.
\q1 Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn;
\q2 ojú rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò.
\q1
\v 5 \nd Olúwa\nd* ń yẹ olódodo wò,
\q2 ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ́ ìwà ipá
\q2 ni ọkàn rẹ̀ kórìíra.
\q1
\v 6 Sí orí àwọn ènìyàn búburú ni yóò rọ̀jò
\q2 ẹ̀yín iná àti imí-ọjọ́ tí ń jó;
\q2 àti ìjì gbígbóná ní yóò jẹ ìpín wọn.
\b
\q1
\v 7 Nítorí, olódodo ní \nd Olúwa\nd*,
\q2 o fẹ́ràn òdodo;
\q2 ẹni ìdúró ṣinṣin yóò sì rí i.
\c 12
\cl Saamu 12
\d Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi.
\q1
\v 1 Ràn wá lọ́wọ́, \nd Olúwa\nd*, nítorí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kò sí mọ́;
\q2 olóòtítọ́ tí pòórá kúrò láàrín àwọn ènìyàn.
\q1
\v 2 Olúkúlùkù ń parọ́ fún aládùúgbò rẹ̀;
\q2 ètè èké wọn ń sọ ẹ̀tàn.
\b
\q1
\v 3 Kí \nd Olúwa\nd* kí ó gé ètè èké wọn
\q2 àti gbogbo ahọ́n ìfọ́nnu
\q1
\v 4 tí ó wí pé,
\q2 “Àwa ó borí pẹ̀lú ahọ́n wa;
\q2 àwa ní ètè wa, ta ni ọ̀gá wa?”
\b
\q1
\v 5 “Nítorí ìnilára àwọn aláìlágbára àti ìkérora àwọn aláìní,
\q2 Èmi yóò dìde nísinsin yìí,” ni \nd Olúwa\nd* wí.
\q2 “Èmi yóò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe àrankàn wọn.”
\q1
\v 6 Ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* sì jẹ aláìlábùkù,
\q2 gẹ́gẹ́ bí fàdákà tí a yọ́ nínú ìléru amọ̀,
\q2 tí a sọ di mímọ́ nígbà méje.
\b
\q1
\v 7 \nd Olúwa\nd*, ìwọ yóò pa wá mọ́
\q2 kí o sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí títí láé.
\q1
\v 8 Àwọn ènìyàn búburú ń rin ìrìn fáàrí kiri
\q2 nígbà tí wọn ń bọ̀wọ̀ fún òsì láàrín àwọn ènìyàn.
\c 13
\cl Saamu 13
\d Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
\q1
\v 1 Yóò ti pẹ́ tó, \nd Olúwa\nd*? Ìwọ o ha gbàgbé mi títí láé?
\q2 Yóò tí pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?
\q1
\v 2 Yóò ti pẹ́ tó tí èmi ó máa bá èrò mi jà,
\q2 àti ní ojoojúmọ́ ni èmi ń ní ìbànújẹ́ ní ọkàn mi?
\q2 Yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ọ̀tá mi yóò máa borí mi?
\b
\q1
\v 3 Wò mí kí o sì dá mi lóhùn, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run mi.
\q2 Fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú mi, kí èmi ó má sún oorun ikú.
\q1
\v 4 Ọ̀tá mi wí pé, “Èmi ti ṣẹ́gun rẹ̀,”
\q2 àwọn ọ̀tá mi yóò yọ̀ tí mo bá ṣubú.
\b
\q1
\v 5 Ṣùgbọ́n mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà;
\q2 ọkàn mi ń yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.
\q1
\v 6 Èmi ó máa kọrin sí \nd Olúwa\nd*,
\q2 nítorí ó dára sí mi.
\c 14
\cl Saamu 14
\d Fún adarí orin. Ti Dafidi.
\q1
\v 1 \x - \xo 14.1-3: \xt Ro 3.10-12.\x*\x - \xo 14.1-7: \xt Sm 53.1-6.\x*Aṣiwèrè wí nínú ọkàn rẹ̀ pé,
\q2 “Ko sí Ọlọ́run.”
\q1 Wọ́n díbàjẹ́, iṣẹ́ wọn sì burú;
\q2 kò sí ẹnìkan tí yóò ṣe rere.
\b
\q1
\v 2 \nd Olúwa\nd* sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wá
\q2 lórí àwọn ọmọ ènìyàn
\q1 bóyá ó le rí ẹni tí òye yé,
\q2 ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run.
\q1
\v 3 Gbogbo wọn sì ti yípadà, gbogbo wọn sì ti díbàjẹ́;
\q2 kò sì ṣí ẹni tí ó ń ṣe rere,
\q2 kò sí ẹnìkan.
\b
\q1
\v 4 Ǹjẹ́ olùṣe búburú kò ha ní ìmọ̀?
\b
\q1 Àwọn tí ó ń pa ènìyàn mi jẹ bí ẹní jẹun;
\q2 wọn kò sì ké pe \nd Olúwa\nd*?
\q1
\v 5 Wọ́n wà níbẹ̀, tí a bò mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù,
\q2 nítorí Ọlọ́run wà ní àwùjọ àwọn olódodo.
\q1
\v 6 Ẹ̀yin olùṣe búburú da èrò àwọn tálákà rú,
\q2 ṣùgbọ́n \nd Olúwa\nd* ni ààbò wọn.
\b
\q1
\v 7 Ìgbàlà àwọn Israẹli yóò ti Sioni wá!
\q2 Nígbà tí \nd Olúwa\nd* bá mú ìkólọ àwọn ènìyàn rẹ̀ padà,
\q2 jẹ́ kí Jakọbu kí ó yọ̀, kí inú Israẹli kí ó dùn!
\c 15
\cl Saamu 15
\d Saamu ti Dafidi.
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd*, ta ni yóò máa ṣe àtìpó nínú àgọ́ rẹ?
\q2 Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?
\b
\q1
\v 2 Ẹni tí ń rìn déédé
\q2 tí ó sì ń sọ òtítọ́,
\q2 láti inú ọkàn rẹ̀;
\q1
\v 3 tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn,
\q2 tí kò ṣe ibi sí aládùúgbò rẹ̀
\q2 tí kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ẹnìkejì rẹ̀,
\q1
\v 4 ní ojú ẹni tí ènìyànkénìyàn di gígàn
\q2 ṣùgbọ́n ó bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù \nd Olúwa\nd*,
\q1 ẹni tí ó búra sí ibi ara rẹ̀
\q2 àní tí kò sì yípadà,
\q1
\v 5 tí ó ń yá ni lówó láìsí èlé
\q2 tí kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lòdì sí aláìlẹ́ṣẹ̀.
\b
\q1 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyí
\q2 ni a kì yóò mì láéláé.
\c 16
\cl Saamu 16
\d Miktamu ti Dafidi.
\q1
\v 1 Pa mí mọ́, Ọlọ́run,
\q2 nítorí nínú rẹ ni ààbò mi wà.
\b
\q1
\v 2 Mo sọ fún \nd Olúwa\nd*, “Ìwọ ni Olúwa mi,
\q2 lẹ́yìn rẹ èmi kò ní ìre kan.”
\q1
\v 3 Sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ayé,
\q2 àwọn ni ológo nínú èyí tí ayọ̀ mí wà.
\q1
\v 4 Ìṣòro àwọn wọ̀n-ọn-nì yóò pọ̀ sí i, àní àwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn.
\q2 Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi.
\b
\q1
\v 5 \nd Olúwa\nd*, ni ìpín ìní mi tí mo yàn àti ago mi,
\q2 ó ti pa ohun tí í ṣe tèmi mọ́.
\q1
\v 6 Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára;
\q2 nítòótọ́ mo ti ní ogún rere.
\q1
\v 7 Èmi yóò yin \nd Olúwa\nd*, ẹni tí ó gbà mí ní ìyànjú;
\q2 ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀.
\q1
\v 8 \x - \xo 16.8-11: \xt Ap 2.25-28,31.\x*Mo ti gbé \nd Olúwa\nd* síwájú mi ní ìgbà gbogbo.
\q2 Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.
\b
\q1
\v 9 Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀;
\q2 ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,
\q1
\v 10 \x - \xo 16.10: \xt Ap 13.35.\x*nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú isà òkú,
\q2 tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́.
\q1
\v 11 Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí;
\q2 Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní iwájú rẹ,
\q2 pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
\c 17
\cl Saamu 17
\d Àdúrà ti Dafidi.
\q1
\v 1 Gbọ́, \nd Olúwa\nd*, ẹ̀bẹ̀ òtítọ́ mi;
\q2 fi etí sí igbe mi.
\q1 Tẹ́tí sí àdúrà mi
\q2 tí kò ti ètè ẹ̀tàn jáde.
\q1
\v 2 Kí ìdáláre mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ;
\q2 kí ojú rẹ kí ó rí ohun tí ó tọ́.
\b
\q1
\v 3 Ìwọ ti dán àyà mi wò,
\q2 ìwọ sì bẹ̀ mí wò ní òru, o sì ti wádìí mi,
\q1 ìwọ kì yóò rí ohunkóhun èmi ti pinnu pé,
\q2 ẹnu mi kì yóò ṣẹ̀.
\q1
\v 4 Bí ó ṣe ti iṣẹ́ ènìyàn nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ,
\q2 èmi ti pa ara mi mọ́
\q2 kúrò ní ọ̀nà àwọn ìkà.
\q1
\v 5 Ìrìn mí ti jẹ mọ́ ọ̀nà rẹ;
\q2 ẹsẹ̀ mi kì yóò yọ̀.
\b
\q1
\v 6 Èmi ké pè ọ́, Ọlọ́run, nítorí tí ìwọ yóò dá mi lóhùn
\q2 dẹ etí rẹ sí mi kí o sì gbọ́ àdúrà mi.
\q1
\v 7 Fi ìṣeun ìyanu ìfẹ́ ńlá rẹ hàn
\q2 ìwọ tí ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là
\q2 lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn.
\q1
\v 8 Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú rẹ;
\q2 fi mí pamọ́ sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ,
\q1
\v 9 lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú tí ń fóròó mi,
\q2 kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká.
\b
\q1
\v 10 Wọ́n pa ọkàn aláìláàánú wọn mọ́,
\q2 wọ́n sì fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ ìgbéraga.
\q1
\v 11 Wọ́n sì mú mi mọ́lẹ̀, wọ́n sì yí mi ká,
\q2 pẹ̀lú ojú ìṣọ́ra láti ṣọ́ mi sílẹ̀.
\q1
\v 12 Wọn dàbí i kìnnìún tí ebi ń pa fún ìjẹ,
\q2 àní bí kìnnìún ńlá tí ó ń ba níbi ìkọ̀kọ̀.
\b
\q1
\v 13 Dìde, \nd Olúwa\nd*, dojúkọ wọ́n, rẹ̀ wọ́n sílẹ̀;
\q2 gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹni búburú nípa idà rẹ.
\q1
\v 14 \nd Olúwa\nd*, nípa ọwọ́ rẹ, gbà mí kúrò lọ́wọ́ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀,
\q2 kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ayé yìí, tí èrè wọn wà nínú ayé yìí.
\q1 Ìwọ ń pa ebi àwọn tí ìwọ fẹ́ràn lẹ́nu mọ́;
\q2 àwọn ọmọ wọn sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀,
\q2 wọ́n sì kó ọrọ̀ jọ fún àwọn ọmọ wọn.
\b
\q1
\v 15 Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò máa wo ojú rẹ ní òdodo;
\q2 nígbà tí èmi bá jí, èmi yóò ní ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí èmi bá rí àwòrán rẹ.
\c 18
\cl Saamu 18
\d Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ \nd Olúwa\nd* tí ó kọ sí \nd Olúwa\nd*, ọ̀rọ̀ orin tí ó kọ sí \nd Olúwa\nd* fún ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ Saulu ọ̀tá rẹ̀. Ó wí pé.
\q1
\v 1 \x - \xo 18.1-50: \xt 2Sa 22.2-51.\x*Mo fẹ́ ọ, \nd Olúwa\nd*, agbára mi.
\b
\q1
\v 2 \nd Olúwa\nd* ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi;
\q2 Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi.
\q2 Òun ni àpáta ààbò àti ìwo ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi.
\b
\q1
\v 3 Mo ké pe \nd Olúwa\nd*, ẹni tí ìyìn yẹ fún,
\q2 a ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi.
\q1
\v 4 Ìrora ikú yí mi kà,
\q2 àti ìṣàn omi àwọn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí.
\q1
\v 5 Okùn isà òkú yí mi ká,
\q2 ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí.
\b
\q1
\v 6 Nínú ìpọ́njú mo ké pe \nd Olúwa\nd*;
\q2 mo sọkún sí \nd Olúwa\nd* mi fún ìrànlọ́wọ́.
\q1 Láti inú tẹmpili rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi;
\q2 ẹkún mi wá sí iwájú rẹ̀, sí inú etí rẹ̀.
\q1
\v 7 Ayé wárìrì, ó sì mì tìtì,
\q2 ìpìlẹ̀ àwọn òkè gíga sì ṣídìí;
\q2 wọ́n wárìrì nítorí tí ó ń bínú.
\q1
\v 8 Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá;
\q2 iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá,
\q2 ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀.
\q1
\v 9 Ó pín àwọn ọ̀run, Ó sì jáde wá;
\q2 àwọsánmọ̀ dúdú sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
\q1
\v 10 Ó gun orí kérúbù, ó sì fò;
\q2 ó ń rábàbà lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́.
\q1
\v 11 Ó fi òkùnkùn ṣe ibojì rẹ̀, ó fi ṣe ìbòrí yí ara rẹ̀ ká
\q2 kurukuru òjò dúdú ní ojú ọ̀run.
\q1
\v 12 Nípa ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀, àwọsánmọ̀ ṣíṣú dudu rẹ kọjá lọ
\q2 pẹ̀lú yìnyín àti ẹ̀yín iná
\q1
\v 13 \nd Olúwa\nd* sán àrá láti ọ̀run wá;
\q2 Ọ̀gá-ògo sì fọ ohun rẹ̀; yìnyín àti ẹ̀yin iná.
\q1
\v 14 Ó ta àwọn ọfà rẹ̀, ó sì tú àwọn ọ̀tá náà ká,
\q2 ọfà mọ̀nàmọ́ná ńlá sì dà wọ́n rú.
\q1
\v 15 A sì fi ìsàlẹ̀ àwọn òkun hàn,
\q2 a sì rí àwọn ìpìlẹ̀ ayé
\q1 nípa ìbáwí rẹ, \nd Olúwa\nd*,
\q2 nípa fífún èémí ihò imú rẹ.
\b
\q1
\v 16 Ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi gíga, ó sì dì mímú;
\q2 Ó fà mí jáde láti inú omi jíjìn.
\q1
\v 17 Ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,
\q2 láti ọwọ́ àwọn ọ̀tá, ti ó lágbára jù fún mi.
\q1
\v 18 Wọ́n dojúkọ mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi;
\q2 ṣùgbọ́n \nd Olúwa\nd* ni alátìlẹ́yìn mi.
\q1
\v 19 Ó mú mi jáde wá sínú ibi ńlá;
\q2 Ó gbà mí nítorí tí ó ní inú dídùn sí mi.
\b
\q1
\v 20 \nd Olúwa\nd* ti hùwà sí mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;
\q2 gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi, ó ti fi èrè fún mi.
\q1
\v 21 Nítorí mo ti pa ọ̀nà \nd Olúwa\nd* mọ́;
\q2 èmi kò ṣe búburú nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi.
\q1
\v 22 Gbogbo òfin rẹ̀ ni ó wà níwájú mi;
\q2 èmi kò sì yípadà kúrò nínú ìlànà rẹ̀.
\q1
\v 23 Mo ti jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú rẹ̀;
\q2 mo sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.
\q1
\v 24 \nd Olúwa\nd* san ẹ̀san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;
\q2 gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi níwájú rẹ̀.
\b
\q1
\v 25 Fún olóòtítọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní olóòtítọ́,
\q2 sí aláìlẹ́bi, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìlẹ́bi,
\q1
\v 26 sí ọlọ́kàn mímọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní ọlọ́kàn mímọ́,
\q2 ṣùgbọ́n sí ọlọ́kàn-wíwọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní òǹrorò.
\q1
\v 27 O pa onírẹ̀lẹ̀ mọ́,
\q2 ṣùgbọ́n ó rẹ àwọn ti ń gbéraga sílẹ̀.
\q1
\v 28 Ìwọ, \nd Olúwa\nd*, jẹ́ kí fìtílà mi
\q2 kí ó máa tàn; Ọlọ́run mi, yí òkùnkùn mi padà sí ìmọ́lẹ̀.
\q1
\v 29 Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, èmi sáré tọ ogun lọ;
\q2 pẹ̀lú Ọlọ́run mi mo lè fo odi kan.
\b
\q1
\v 30 Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà rẹ̀ pé,
\q2 a ti rídìí ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd*
\q2 òun ni àpáta ààbò fún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò.
\q1
\v 31 Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe \nd Olúwa\nd*?
\q2 Ta ní àpáta bí kò ṣe \nd Olúwa\nd* wa?
\q1
\v 32 Ọlọ́run ni ẹni tí ó fi agbára dì mí ní àmùrè
\q2 ó sì mú ọ̀nà mi pé.
\q1
\v 33 Ó ṣe ẹsẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bi ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín;
\q2 ó jẹ́ ki n lè dúró lórí ibi gíga.
\q1
\v 34 Ó kọ́ ọwọ́ mi ni ogun jíjà;
\q2 apá mi lè tẹ ọrùn idẹ.
\q1
\v 35 Ìwọ fi asà ìṣẹ́gun rẹ̀ fún mi,
\q2 ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé mí dúró;
\q2 àti ìwà pẹ̀lẹ́ rẹ̀ sọ mí di ńlá.
\q1
\v 36 Ìwọ sọ ìrìn ẹsẹ̀ mi di ńlá ní ìsàlẹ̀ mi,
\q2 kí kókó-ẹsẹ̀ mi má ṣe yẹ̀.
\b
\q1
\v 37 Èmi lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì bá wọn
\q2 èmi kò sì padà lẹ́yìn wọn títí a fi run wọ́n.
\q1
\v 38 Èmi sá wọn ní ọgbẹ́ tí wọn ko fi le è dìde;
\q2 wọ́n ṣubú ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi.
\q1
\v 39 Nítorí ìwọ fi agbára dì mí ní àmùrè fún ogun náà;
\q2 ìwọ ti mú àwọn tí ó dìde si mí tẹríba ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi.
\q1
\v 40 Ìwọ yí ẹ̀yìn àwọn ọ̀tá mí padà sí mi
\q2 èmi sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.
\q1
\v 41 Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbà wọ́n,
\q2 àní sí \nd Olúwa\nd*, ṣùgbọ́n kò dá wọn lóhùn.
\q1
\v 42 Mo lù wọ́n gẹ́gẹ́ bí eruku níwájú afẹ́fẹ́;
\q2 mo dà wọ́n síta gẹ́gẹ́ bí ẹrọ̀fọ̀.
\q1
\v 43 Ìwọ ti gbà mí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ènìyàn;
\q2 Ìwọ ti fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè.
\q1 Àwọn ènìyàn ti èmi kò mọ, yóò sì máa sìn mí,
\q2
\v 44 ni wéré ti wọ́n gbọ́ ohùn mi, wọ́n pa àṣẹ mi mọ́;
\q2 àwọn ọmọ àjèjì yóò tẹríba fún mi.
\q1
\v 45 Àyà yóò pá àlejò;
\q2 wọn yóò sì fi ìbẹ̀rù jáde láti ibi kọ́lọ́fín wọn.
\b
\q1
\v 46 \nd Olúwa\nd* wà láààyè! Olùbùkún ni àpáta mi!
\q2 Gbígbéga ní Ọlọ́run Olùgbàlà mi.
\q1
\v 47 Òun ni Ọlọ́run tí ó ń gbẹ̀san mi,
\q2 tí ó sì ń ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní abẹ́ mi,
\q2
\v 48 tí ó pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mí.
\q1 Ìwọ gbé mi ga ju àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí mi lọ;
\q2 lọ́wọ́ àwọn ènìyàn alágbára ni ìwọ ti gbà mí.
\q1
\v 49 \x - \xo 18.49: \xt Ro 15.9.\x*Títí láéláé, èmi yóò máa yìn ọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ \nd Olúwa\nd*;
\q2 èmi yóò sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.
\b
\q1
\v 50 Ó fún ọba rẹ̀ ni ìṣẹ́gun ńlá;
\q2 ó fi ìkáàánú àìṣẹ̀tàn fún ẹni àmì òróró rẹ̀,
\q2 fún Dafidi àti ìran rẹ̀ títí láé.
\c 19
\cl Saamu 19
\d Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
\q1
\v 1 Àwọn ọ̀run ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run;
\q2 àwọsánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
\q1
\v 2 Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́;
\q2 wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́.
\q1
\v 3 Kò sí ohùn tàbí èdè
\q2 níbi tí a kò gbé gbọ́ ìró wọn.
\q1
\v 4 \x - \xo 19.4: \xt Ro 10.18.\x*Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀ ayé,
\q2 ọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ilẹ̀ ayé.
\q1 Ó ti kọ́ àgọ́ fún oòrùn nínú àwọn ọ̀run.
\q2
\v 5 Tí ó dàbí ọkọ ìyàwó tí ó ń jáde ti yàrá rẹ̀ wá,
\q2 òun yọ bí alágbára ọkùnrin tí ó ń sáré ìje.
\q1
\v 6 Ìjáde lọ rẹ̀ ni láti òpin ọ̀run wá
\q2 àti àyíká rẹ̀ sì dé ìpínlẹ̀ rẹ̀;
\q2 kò sì sí ohun tí ó pamọ́ kúrò nínú oore rẹ̀.
\b
\q1
\v 7 Pípé ni òfin \nd Olúwa\nd*,
\q2 ó ń yí ọkàn padà.
\q1 Ẹ̀rí \nd Olúwa\nd* dánilójú,
\q2 ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.
\q1
\v 8 Ìlànà \nd Olúwa\nd* tọ̀nà,
\q2 ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn.
\q1 Àṣẹ \nd Olúwa\nd* ni mímọ́,
\q2 ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú.
\q1
\v 9 Ìbẹ̀rù \nd Olúwa\nd* mọ́,
\q2 ó ń faradà títí láéláé.
\q1 Ìdájọ́ \nd Olúwa\nd* dájú
\q2 òdodo ni gbogbo wọn.
\b
\q1
\v 10 Wọn ṣọ̀wọ́n ju wúrà lọ,
\q2 ju wúrà tí o dára jùlọ,
\q1 wọ́n dùn ju oyin lọ,
\q2 àti ju afárá oyin lọ.
\q1
\v 11 Nípa wọn ni a ti ṣí ìránṣẹ́ rẹ̀ létí;
\q2 nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.
\q1
\v 12 Ta ni ó lè mọ àṣìṣe rẹ̀?
\q2 Dáríjì mí nínú àṣìṣe mi tí ó pamọ́.
\q1
\v 13 Wẹ ìránṣẹ́ rẹ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́n-mọ̀-dá;
\q2 má ṣe jẹ kí wọn kí ó jẹ ọba lórí mi.
\q1 Nígbà náà ní èmi yóò dúró ṣinṣin,
\q2 èmi yóò sì ṣe aláìlẹ́bi kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.
\b
\q1
\v 14 Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mi
\q2 kí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ,
\q2 Ìwọ \nd Olúwa\nd* àpáta mi, àti Olùdáǹdè mi.
\c 20
\cl Saamu 20
\d Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
\q1
\v 1 Kí \nd Olúwa\nd* kí ó gbóhùn rẹ ní ọjọ́ ìpọ́njú;
\q2 kí orúkọ Ọlọ́run Jakọbu kí ó dáàbò bò ọ́.
\q1
\v 2 Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́
\q2 kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá.
\q1
\v 3 Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ rẹ
\q2 kí ó sì gba ẹbọ sísun rẹ. \qs Sela.\qs*
\q1
\v 4 Kí ó fi fún ọ gẹ́gẹ́ bi ti èrò ọkàn rẹ
\q2 kí ó sì mú gbogbo ìmọ̀ rẹ ṣẹ.
\q1
\v 5 Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gun
\q2 àwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa.
\b
\q1 Kí \nd Olúwa\nd* kí ó mú gbogbo ìbéèrè rẹ̀ ṣẹ.
\b
\q1
\v 6 Nísinsin yìí, èmi mọ̀ wí pé,
\q2 \nd Olúwa\nd* pa ẹni àmì òróró rẹ̀ mọ́.
\q1 Yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wá
\q2 pẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
\q1
\v 7 Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé kẹ̀kẹ́, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé ẹṣin,
\q2 ṣùgbọ́n àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa.
\q1
\v 8 Wọ́n wólẹ̀, ní eékún, wọ́n sì ṣubú,
\q2 ṣùgbọ́n àwa dìde, a sì dúró ṣinṣin.
\q1
\v 9 \nd Olúwa\nd*, fi ìṣẹ́gun fún ọba!
\q2 Dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń kígbe pè!
\c 21
\cl Saamu 21
\d Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
\q1
\v 1 Háà! \nd Olúwa\nd*, ọba yóò yọ̀ nínú agbára rẹ,
\q2 àti ní ìgbàlà rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó!
\b
\q1
\v 2 Nítorí pé ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ fún un,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì dùn ún ní ìbéèrè ẹnu rẹ̀. \qs Sela.\qs*
\q1
\v 3 Ìwọ ti fi àwọn ìbùkún oore kò ó ni ọ̀nà
\q2 ìwọ fi adé wúrà dé e ní orí.
\q1
\v 4 Ó béèrè fún ìyè, ìwọ sì fi fún un,
\q2 àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé.
\q1
\v 5 Ògo rẹ̀ pọ̀ nípasẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún un;
\q2 ìwọ sì jẹ́ kí iyì ọláńlá rẹ̀ wà lára rẹ.
\q1
\v 6 Dájúdájú, ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún un:
\q2 ìwọ sì mú inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u rẹ̀.
\q1
\v 7 Ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú \nd Olúwa\nd*;
\q2 nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọ̀gá-ògo tí kì í kùnà
\q2 kì yóò sípò padà.
\b
\q1
\v 8 Ọwọ́ rẹ yóò wá gbogbo àwọn ọ̀tá a rẹ rí;
\q2 ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò wá àwọn tí o kórìíra rẹ rí.
\q1
\v 9 Nígbà tí ìwọ bá yọ
\q2 ìwọ yóò mú wọn dàbí iná ìléru.
\q1 \nd Olúwa\nd* yóò gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀,
\q2 àti pé iná rẹ̀ yóò jó wọn run.
\q1
\v 10 Ìwọ yóò pa ìrandíran wọn run kúrò lórí ilẹ̀,
\q2 àti irú-ọmọ wọn kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn.
\q1
\v 11 Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n ro èrò ibi sí ọ
\q2 wọ́n sì ń pète ìwà ìkà, wọn kì yóò ṣe àṣeyọrí.
\q1
\v 12 Nítorí pé ìwọ yóò mú wọn yí ẹ̀yìn wọn padà
\q2 nígbà tí o bá pinnu láti ta wọ́n ní ọfà.
\b
\q1
\v 13 Gbígbéga ni ọ́ \nd Olúwa\nd*, nínú agbára rẹ;
\q2 a ó kọrin, a ó yín agbára a rẹ̀.
\c 22
\cl Saamu 22
\d Fún adarí orin. Tí ohùn orin “àgbọ̀nrín òwúrọ̀.” Saamu ti Dafidi.
\q1
\v 1 \x - \xo 22.1: \xt Mt 27.46; Mk 15.34.\x*Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?
\q2 Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là,
\q2 àní sí igbe ìkérora mi?
\q1
\v 2 Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn:
\q2 àti ní òru èmi kò dákẹ́.
\b
\q1
\v 3 Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹni mímọ́ ni Ìwọ;
\q2 ẹni tí ó tẹ ìyìn Israẹli dó.
\q1
\v 4 Àwọn baba ńlá wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ;
\q2 wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì gbà wọ́n.
\q1
\v 5 Ìwọ ni wọ́n sun ẹkún sí, wọ́n sì ní ìgbàlà;
\q2 ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, a kò sì dójútì wọ́n.
\b
\q1
\v 6 Ṣùgbọ́n kòkòrò ní mo jẹ́, kì í sì í ṣe ènìyàn;
\q2 mo di ẹlẹ́gàn àwọn ènìyàn, ẹlẹ́yà àwọn ènìyàn.
\q1
\v 7 Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà;
\q2 wọ́n yọ ètè ẹ̀gàn wọn sí mi, wọ́n sì ń mi orí wọn pé.
\q1
\v 8 “Ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé \nd Olúwa\nd*;
\q2 jẹ́ kí \nd Olúwa\nd* gbà á là.
\q1 Jẹ́ kí ó gbà á là,
\q2 nítorí pé, ó ní ayọ̀ nínú rẹ̀.”
\b
\q1
\v 9 Síbẹ̀ ìwọ ni ó ti mú mi wá láti inú;
\q2 ìwọ ni ó mú mi wà láìléwu, nígbà tí mo rọ̀ mọ́ ọmú ìyá mi.
\q1
\v 10 Ìwọ ni a fi mí lé lọ́wọ́ láti inú ìyá mi wá,
\q2 nígbà tí ìyá mí sì ti bí mi, ìwọ ni Ọlọ́run mi.
\b
\q1
\v 11 Má ṣe jìnnà sí mi,
\q2 nítorí pé ìyọnu súnmọ́ tòsí
\q2 kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́.
\b
\q1
\v 12 Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká;
\q2 àwọn màlúù alágbára Baṣani rọ̀gbà yí mi ká.
\q1
\v 13 Wọ́n ya ẹnu wọn sì mi bí i kìnnìún tí ń dọdẹ kiri,
\q2 tí ń ké ramúramù.
\q1
\v 14 A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi,
\q2 gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé rẹ̀.
\q1 Ọkàn mi sì dàbí i ìda;
\q2 tí ó yọ́ láàrín inú mi.
\q1
\v 15 Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì,
\q2 ahọ́n mí sì tilẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi;
\q2 ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú.
\b
\q1
\v 16 Àwọn ajá yí mi ká;
\q2 ìjọ àwọn ènìyàn ibi ti ká mi mọ́,
\q2 wọ́n gún mi lọ́wọ́, wọ́n sì gún mi lẹ́sẹ̀.
\q1
\v 17 Mo lè ka gbogbo àwọn egungun mi;
\q2 àwọn tìkára wọn ń wò, wọ́n dójú lé mi.
\q1
\v 18 Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn
\q2 àní lórí aṣọ mi ni wọ́n ṣẹ́ gègé.
\b
\q1
\v 19 Ṣùgbọ́n ìwọ, \nd Olúwa\nd*, má ṣe jìnnà sí mi.
\q2 Háà! Olùrànlọ́wọ́ ọ̀ mi, yára wá fún àtìlẹ́yìn mi!
\q1
\v 20 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ idà,
\q2 àní ẹ̀mí mi lọ́wọ́ agbára àwọn ajá.
\q1
\v 21 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ kìnnìún;
\q2 kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwo àgbáǹréré.
\b
\q1
\v 22 Èmi yóò kéde orúkọ rẹ láàrín arákùnrin àti arábìnrin mi;
\q2 nínú ìjọ ni èmi yóò máa yìn ọ́.
\q1
\v 23 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù \nd Olúwa\nd*, ẹ yìn ín!
\q2 Gbogbo ẹ̀yin ìran Jakọbu, ẹ fi ògo fún un!
\q2 Ẹ dìde fún un tẹ̀rù tẹ̀rù, ẹ̀yin irú-ọmọ Israẹli!
\q1
\v 24 Nítorí pé òun kò ṣátá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíra
\q2 ìpọ́njú àwọn tí a ni lára;
\q1 kò sì fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún mi
\q2 ṣùgbọ́n ó gbọ́ nígbà tí mo ké pè é.
\b
\q1
\v 25 Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìyìn mi yóò ti wá nínú àjọ ńlá;
\q2 ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù rẹ̀
\q1
\v 26 tálákà yóò jẹ yóò sì yó;
\q2 àwọn tí n wá \nd Olúwa\nd* yóò yin
\q2 jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ wà láààyè títí ayérayé!
\b
\q1
\v 27 Gbogbo òpin ayé ni yóò rántí
\q2 wọn yóò sì yípadà sí \nd Olúwa\nd*,
\q1 àti gbogbo ìdílé orílẹ̀-èdè
\q2 ni wọn yóò jọ́sìn níwájú rẹ̀,
\q1
\v 28 nítorí ìjọba ni ti \nd Olúwa\nd*.
\q2 Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè.
\b
\q1
\v 29 Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn olówó ayé wọn yóò ṣe àsè, wọn yóò sì sìn;
\q2 gbogbo àwọn tí ó wọ inú ilẹ̀ lọ yóò kúnlẹ̀ ní iwájú rẹ̀
\q2 àti ẹni tí kò lè pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ ni ààyè.
\q1
\v 30 Irú-ọmọ rẹ̀ yóò sìn ín;
\q2 a ó sọ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ nípa \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 31 Wọn yóò polongo òdodo rẹ̀
\q2 sí àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí,
\q2 wí pé, òun ni ó ṣe èyí.
\c 23
\cl Saamu 23
\d Saamu ti Dafidi.
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd* ni olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.
\q2
\v 2 \x - \xo 23.2: \xt If 7.17.\x*Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù,
\q1 Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́,
\q2
\v 3 Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò.
\q1 Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo
\q2 nítorí orúkọ rẹ̀.
\q1
\v 4 Bí mo tilẹ̀ ń rìn
\q2 láàrín àfonífojì òjìji ikú,
\q1 èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan,
\q2 nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;
\q1 ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ,
\q2 wọ́n ń tù mí nínú.
\b
\q1
\v 5 Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi
\q2 ní ojú àwọn ọ̀tá à mi.
\q1 Ìwọ ta òróró sí mi ní orí;
\q2 ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.
\q1
\v 6 Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn
\q2 ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo,
\q1 èmi yóò sì máa gbé inú ilé \nd Olúwa\nd*
\q2 títí láéláé.
\c 24
\cl Saamu 24
\d Ti Dafidi. Saamu.
\q1
\v 1 \x - \xo 24.1: \xt 1Kọ 10.26.\x*Ti \nd Olúwa\nd* ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀,
\q2 ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀;
\q1
\v 2 nítorí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí òkun
\q2 ó sì gbé e kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.
\b
\q1
\v 3 Ta ni yóò gun orí òkè \nd Olúwa\nd* lọ?
\q2 Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?
\q1
\v 4 \x - \xo 24.4: \xt Mt 5.8.\x*Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun,
\q2 ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán
\q2 tí kò sì búra èké.
\b
\q1
\v 5 Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ \nd Olúwa\nd*,
\q2 àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.
\q1
\v 6 Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀,
\q2 tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 7 Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà;
\q2 kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé!
\q2 Kí ọba ògo le è wọlé.
\q1
\v 8 Ta ni ọba ògo náà?
\q2 \nd Olúwa\nd* tí ó lágbára tí ó sì le,
\q2 \nd Olúwa\nd* gan an, tí ó lágbára ní ogun.
\q1
\v 9 Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà;
\q2 kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,
\q2 kí Ọba ògo le è wọlé wá.
\q1
\v 10 Ta ni Ọba ògo náà?
\q2 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun
\q2 Òun ni Ọba ògo náà. \qs Sela.\qs*
\c 25
\cl Saamu 25
\d Ti Dafidi.
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd*,
\q2 ìwọ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí.
\b
\q1
\v 2 Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ;
\q2 má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì mí
\q2 má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí.
\q1
\v 3 Ẹni tí ó dúró tì ọ́
\q2 ojú kì yóò tì í,
\q1 àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí
\q2 ni kí ojú kí ó tì.
\b
\q1
\v 4 Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, \nd Olúwa\nd*,
\q2 kọ mi ní ipa tìrẹ;
\q1
\v 5 ṣe amọ̀nà mi nínú òtítọ́ ọ̀ rẹ, kí o sì kọ́ mi,
\q2 nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi;
\q2 ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́.
\q1
\v 6 Rántí, \nd Olúwa\nd* àánú àti ìfẹ́ ẹ̀ rẹ̀ ńlá,
\q2 torí pé wọ́n ti wà ní ìgbà àtijọ́.
\q1
\v 7 Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi
\q2 tàbí ìrékọjá mi;
\q1 gẹ́gẹ́ bí i ìfẹ́ ẹ rẹ̀ rántí mi
\q2 nítorí tí ìwọ dára, Ìwọ! \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1
\v 8 Rere àti ẹni ìdúró ṣinṣin ní \nd Olúwa\nd*:
\q2 nítorí náà, ó kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọ̀nà náà.
\q1
\v 9 Ó ṣe amọ̀nà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó dára,
\q2 ó sì kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀nà rẹ̀.
\q1
\v 10 Gbogbo ipa ọ̀nà \nd Olúwa\nd* ni ìfẹ́ àti òdodo tí ó dúró ṣinṣin,
\q2 fún àwọn tí ó pa májẹ̀mú àti ẹ̀rí rẹ̀ mọ́.
\q1
\v 11 Nítorí orúkọ rẹ, \nd Olúwa\nd*,
\q2 dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, nítorí tí ó tóbi.
\b
\q1
\v 12 Àwọn wo ni ó bẹ̀rù \nd Olúwa\nd*?
\q2 Yóò kọ́ wọn ní ọ̀nà èyí tí wọn yóò yàn.
\q1
\v 13 Wọn yóò lo ọjọ́ wọn nínú àlàáfíà,
\q2 àwọn ọmọ wọn yóò sì gba ilẹ̀ náà.
\q1
\v 14 \nd Olúwa\nd* fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u rẹ̀;
\q2 ó sọ májẹ̀mú rẹ̀ di mí mọ̀ fún wọn.
\q1
\v 15 Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ \nd Olúwa\nd*,
\q2 nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà.
\b
\q1
\v 16 Yípadà sí mi, kí o sì ṣe oore fún mi;
\q2 nítorí pé mo nìkan wà, mo sì di olùpọ́njú.
\q1
\v 17 Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi;
\q2 kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú mi.
\q1
\v 18 Kíyèsi ìjìyà àti wàhálà mi,
\q2 kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.
\q1
\v 19 Kíyèsi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tá mi,
\q2 tí wọn kórìíra mi pẹ̀lú ìwà ìkà wọn.
\b
\q1
\v 20 Pa ọkàn mi mọ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀;
\q2 má ṣe jẹ́ kí a fi mí sínú ìtìjú,
\q2 nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi mi.
\q1
\v 21 Jẹ́ kí òtítọ́ inú àti ìdúró ṣinṣin kí ó pa mí mọ́;
\q2 nítorí pé mo dúró tì ọ́.
\b
\q1
\v 22 Ra Israẹli padà, Ìwọ Ọlọ́run,
\q2 nínú gbogbo ìṣòro rẹ̀!
\c 26
\cl Saamu 26
\d Ti Dafidi.
\q1
\v 1 Ṣe ìdájọ́ mi, \nd Olúwa\nd*,
\q2 nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi,
\q1 mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú \nd Olúwa\nd*,
\q2 ǹjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀.
\q1
\v 2 Wádìí mi wò, Ìwọ \nd Olúwa\nd*, kí o sì dán mi wò,
\q2 dán àyà àti ọkàn mi wò;
\q1
\v 3 nítorí ìfẹ́ ẹ̀ rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi,
\q2 èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ rẹ.
\b
\q1
\v 4 Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìṣòótọ́,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé.
\q1
\v 5 Èmi ti kórìíra àwùjọ àwọn ènìyàn búburú
\q2 èmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó.
\q1
\v 6 Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ rẹ ká \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 7 Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́,
\q2 èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.
\b
\q1
\v 8 Háà \nd Olúwa\nd*, èmí ń fẹ́ ilé rẹ níbi tí ìwọ ń gbé,
\q2 àní níbi tí ògo rẹ̀ wà.
\q1
\v 9 Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
\q2 tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ,
\q1
\v 10 àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi,
\q2 tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
\q1
\v 11 Ṣùgbọ́n èmi ó máa rìn nínú ìwà títọ́;
\q2 rà mí padà, kí o sì ṣàánú fún mi.
\b
\q1
\v 12 Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú;
\q2 nínú ìjọ ńlá èmi yóò fi ìbùkún fún \nd Olúwa\nd*.
\c 27
\cl Saamu 27
\d Ti Dafidi.
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd* ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi;
\q2 ta ni èmi yóò bẹ̀rù?
\q1 \nd Olúwa\nd* ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi,
\q2 ẹ̀rù ta ni yóò bà mí?
\b
\q1
\v 2 Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi
\q2 láti jẹ ẹran-ara mi,
\q1 àní àwọn ọ̀tá mi àti àwọn abínúkú mi,
\q2 wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.
\q1
\v 3 Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi,
\q2 ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù;
\q1 bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi,
\q2 nínú èyí ni ọkàn mi yóò le.
\b
\q1
\v 4 Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ \nd Olúwa\nd*,
\q2 òhun ni èmi yóò máa wá kiri:
\q1 kí èmi kí ó le wà ní ilé \nd Olúwa\nd*
\q2 ní ọjọ́ ayé mi gbogbo,
\q1 kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà \nd Olúwa\nd*,
\q2 kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀.
\q1
\v 5 Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú
\q2 òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀;
\q1 níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́;
\q2 yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta.
\b
\q1
\v 6 Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè
\q2 ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká;
\q1 èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀;
\q2 èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1
\v 7 Gbọ́ ohùn mi nígbà tí ẹ̀mí bá à ń pè, \nd Olúwa\nd*,
\q2 ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn,
\q1
\v 8 Ọkàn mi wí pé, “Wá ojú u rẹ̀!”
\q2 Ojú rẹ, \nd Olúwa\nd*, ni ti èmí ń wá.
\q1
\v 9 Má ṣe fi ojú rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi,
\q2 má ṣe fi ìbínú sá ìránṣẹ́ rẹ tì;
\q2 ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi,
\q1 Má ṣe fi mí sílẹ̀, má sì ṣe kọ̀ mí,
\q2 háà! Ọlọ́run ìgbàlà mi.
\q1
\v 10 Bí ìyá àti baba bá kọ̀ mí sílẹ̀,
\q2 \nd Olúwa\nd* yóò tẹ́wọ́ gbà mí.
\q1
\v 11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, \nd Olúwa\nd*,
\q2 kí o sì sìn mi lọ sí ọ̀nà tí ó tẹ́jú
\q2 nítorí àwọn ọ̀tá mi.
\q1
\v 12 Má ṣe fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́,
\q2 nítorí àwọn ẹlẹ́rìí èké ti dìde sí mi,
\q2 wọ́n sì mí ìmí ìkà.
\b
\q1
\v 13 Èmi ní ìgbàgbọ́ pé,
\q2 èmi yóò rí ìre \nd Olúwa\nd*
\q2 ní ilẹ̀ alààyè.
\q1
\v 14 Dúró de \nd Olúwa\nd*;
\q2 kí ó jẹ alágbára, kí o sì mú ọkàn le
\q2 àní dúró de \nd Olúwa\nd*.
\c 28
\cl Saamu 28
\d Ti Dafidi.
\q1
\v 1 Ìwọ \nd Olúwa\nd*,
\q2 mo ké pe àpáta mi.
\q2 Má ṣe kọ etí dídi sí mi.
\q1 Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi,
\q2 èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun.
\q1
\v 2 Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú,
\q2 bí mo ṣe ń ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,
\q1 bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókè
\q2 sí Ibi Mímọ́ rẹ Jùlọ.
\b
\q1
\v 3 Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti,
\q2 pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
\q1 tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn
\q2 ṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn.
\q1
\v 4 San ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn
\q2 àti fún iṣẹ́ ibi wọn;
\q1 gba ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn;
\q2 kí o sì san ẹ̀san wọn bí ó ti tọ́.
\b
\q1
\v 5 Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ \nd Olúwa\nd* sí,
\q2 tàbí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀
\q1 òun ó rún wọn wọlẹ̀
\q2 kì yóò sì gbé wọn ró mọ́.
\b
\q1
\v 6 Alábùkún fún ni \nd Olúwa\nd*!
\q2 Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
\q1
\v 7 \nd Olúwa\nd* ni agbára mi àti asà mi;
\q2 nínú rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́.
\q1 Ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀
\q2 àní pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un.
\b
\q1
\v 8 \nd Olúwa\nd* ni agbára àwọn ènìyàn rẹ̀
\q2 òun ni odi ìgbàlà àwọn ẹni àmì òróró rẹ̀.
\q1
\v 9 Ìwọ gba àwọn ènìyàn rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún rẹ;
\q2 di olùṣọ́-àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé.
\c 29
\cl Saamu 29
\d Saamu ti Dafidi.
\q1
\v 1 Ẹ fi fún \nd Olúwa\nd*, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,
\q2 ẹ fi fún \nd Olúwa\nd*, ògo àti alágbára.
\q1
\v 2 Fi fún \nd Olúwa\nd*, àní ògo orúkọ rẹ̀;
\q2 sin \nd Olúwa\nd* nínú ẹwà ìwà mímọ́.
\b
\q1
\v 3 Ohùn \nd Olúwa\nd* n ré àwọn omi kọjá;
\q2 Ọlọ́run ògo sán àrá,
\q2 \nd Olúwa\nd* san ara.
\q1
\v 4 Ohùn \nd Olúwa\nd* ní agbára;
\q2 ohùn \nd Olúwa\nd* kún fún ọláńlá.
\q1
\v 5 Ohùn \nd Olúwa\nd* fa igi kedari;
\q2 \nd Olúwa\nd* náà ló fọ́ igi kedari Lebanoni ya.
\q1
\v 6 Ó mú Lebanoni fo bí i ọmọ màlúù,
\q2 àti Sirioni bí ọmọ àgbáǹréré.
\q1
\v 7 Ohùn \nd Olúwa\nd* ń ya
\q2 bí ọwọ́ iná mọ̀nà.
\q1
\v 8 Ohùn \nd Olúwa\nd* ń mi aginjù.
\q2 \nd Olúwa\nd* mi aginjù Kadeṣi.
\q1
\v 9 Ohùn \nd Olúwa\nd* ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀nrín bí,
\q2 ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòhò.
\q1 Àti nínú tẹmpili rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé, “Ògo!”
\b
\q1
\v 10 \nd Olúwa\nd* jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi;
\q2 \nd Olúwa\nd* jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé.
\q1
\v 11 Kí \nd Olúwa\nd* fi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀;
\q2 bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.
\c 30
\cl Saamu 30
\d Saamu. Orin. Fún ìyàsímímọ́ Tẹmpili. Ti Dafidi.
\q1
\v 1 Èmi yóò kókìkí i rẹ, \nd Olúwa\nd*,
\q2 nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékè
\q2 tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí.
\q1
\v 2 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,
\q2 ìwọ sì ti wò mí sàn.
\q1
\v 3 \nd Olúwa\nd*, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú,
\q2 mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò.
\b
\q1
\v 4 Kọ orin ìyìn sí \nd Olúwa\nd*, ẹ̀yin olódodo;
\q2 kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́.
\q1
\v 5 Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀,
\q2 ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé;
\q1 ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́,
\q2 ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀.
\b
\q1
\v 6 Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé,
\q2 “a kì yóò ṣí mi ní ipò padà.”
\q1
\v 7 Nípa ojúrere rẹ, \nd Olúwa\nd*,
\q2 ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára;
\q1 ìwọ pa ojú rẹ mọ́,
\q2 àyà sì fò mí.
\b
\q1
\v 8 Sí ọ \nd Olúwa\nd*, ni mo ké pè é;
\q2 àti sí Olúwa ni mo sọkún fún àánú:
\q1
\v 9 “Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi,
\q2 nínú lílọ sí ihò mi?
\q1 Eruku yóò a yìn ọ́ bí?
\q2 Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo rẹ?
\q1
\v 10 Gbọ́, \nd Olúwa\nd*, kí o sì ṣàánú fún mi;
\q2 ìwọ \nd Olúwa\nd*, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi.”
\b
\q1
\v 11 Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi;
\q2 ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí,
\q1
\v 12 nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí o má sì ṣe dákẹ́.
\q2 Ìwọ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.
\c 31
\cl Saamu 31
\d Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
\q1
\v 1 Nínú rẹ̀, \nd Olúwa\nd* ni mo ti rí ààbò;
\q2 má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí;
\q2 gbà mí nínú òdodo rẹ.
\q1
\v 2 Tẹ́ etí rẹ sí mi,
\q2 gbà mí kíákíá;
\q1 jẹ́ àpáta ààbò mi,
\q2 jẹ́ odi alágbára láti gbà mí.
\q1
\v 3 Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi,
\q2 nítorí orúkọ rẹ, máa ṣe olùtọ́ mi, kí o sì ṣe amọ̀nà mi.
\q1
\v 4 Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi,
\q2 nítorí ìwọ ni ìsádi mi.
\q1
\v 5 Ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé;
\q2 ìwọ ni o ti rà mí padà, \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run òtítọ́.
\b
\q1
\v 6 Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fiyèsí òrìṣà tí kò níye lórí;
\q2 ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 7 Èmi yóò yọ̀, inú mi yóò dùn nínú ìfẹ́ ńlá rẹ,
\q2 nítorí ìwọ ti rí ìbìnújẹ́ mi
\q2 ìwọ ti mọ̀ ọkàn mi nínú ìpọ́njú.
\q1
\v 8 Pẹ̀lú, ìwọ kò sì fà mi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́
\q2 ìwọ ti fi ẹsẹ̀ mi lé ibi ààyè ńlá.
\b
\q1
\v 9 Ṣàánú fún mi, ìwọ \nd Olúwa\nd*, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú;
\q2 ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn,
\q2 ọkàn àti ara mi pẹ̀lú.
\q1
\v 10 Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ mi
\q2 àti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn;
\q1 agbára mi ti kùnà nítorí òsì mi,
\q2 egungun mi sì ti rún dànù.
\q1
\v 11 Èmi di ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ọ̀tá mi gbogbo,
\q2 pẹ̀lúpẹ̀lú láàrín àwọn aládùúgbò mi,
\q1 mo sì di ẹ̀rù fún àwọn ojúlùmọ̀ mi;
\q2 àwọn tí ó rí mi ní òde ń yẹra fún mi.
\q1
\v 12 Èmi ti di ẹni ìgbàgbé kúrò ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti kú;
\q2 èmi sì dàbí ohun èlò tí ó ti fọ́.
\q1
\v 13 \x - \xo 31.13: \xt Jr 6.25; 20.3,10; 46.5; 49.29.\x*Nítorí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpayà tí ó yí mi ká;
\q2 tí wọn gbìmọ̀ pọ̀ sí mi,
\q1 wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi
\q2 láti gba ẹ̀mí mi.
\b
\q1
\v 14 Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ \nd Olúwa\nd*;
\q2 mo sọ wí pé, “Ìwọ ní Ọlọ́run mi.”
\q1
\v 15 Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;
\q2 gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi
\q2 àti àwọn onínúnibíni.
\q1
\v 16 Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ lára;
\q2 gbà mí nínú ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.
\q1
\v 17 Má ṣe jẹ́ kí ojú ki ó tì mí, \nd Olúwa\nd*;
\q2 nítorí pé mo ké pè ọ́;
\q1 jẹ́ kí ojú kí ó ti ènìyàn búburú;
\q2 jẹ́ kí wọ́n lọ pẹ̀lú ìdààmú sí isà òkú.
\q1
\v 18 Jẹ́ kí àwọn ètè irọ́ kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́,
\q2 pẹ̀lú ìgbéraga àti ìkẹ́gàn,
\q2 wọ́n sọ̀rọ̀ àfojúdi sí olódodo.
\b
\q1
\v 19 Báwo ni títóbi oore rẹ̀ ti pọ̀ tó,
\q2 èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,
\q1 èyí tí ìwọ rọ̀jò rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn
\q2 tí wọ́n fi ọ́ ṣe ibi ìsádi wọn.
\q1
\v 20 Ní abẹ́ ìbòòji iwájú rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ sí
\q2 kúrò nínú ìdìmọ̀lù àwọn ènìyàn;
\q1 ní ibùgbé rẹ, o mú wọn kúrò nínú ewu
\q2 kúrò nínú ìjà ahọ́n.
\b
\q1
\v 21 Olùbùkún ni \nd Olúwa\nd*,
\q2 nítorí pé ó ti fi àgbà ìyanu ìfẹ́ tí ó ní sí mi hàn,
\q2 nígbà tí mo wà ní ìlú tí wọ́n rọ̀gbà yíká.
\q1
\v 22 Èmí ti sọ nínú ìdágìrì mi,
\q2 “A gé mi kúrò ní ojú rẹ!”
\q1 Síbẹ̀ ìwọ ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú
\q2 nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.
\b
\q1
\v 23 Ẹ fẹ́ \nd Olúwa\nd*, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́!
\q2 \nd Olúwa\nd* pa olódodo mọ́,
\q2 ó sì san án padà fún agbéraga ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
\q1
\v 24 Jẹ́ alágbára, yóò sì mú yín ní àyà le
\q2 gbogbo ẹ̀yin tí ó dúró de \nd Olúwa\nd*.
\c 32
\cl Saamu 32
\d Ti Dafidi. Maskili.
\q1
\v 1 \x - \xo 32.1-2: \xt Ro 4.7-8.\x*Ìbùkún ni fún àwọn
\q2 tí a dárí ìrékọjá wọn jì,
\q2 tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.
\q1
\v 2 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà
\q2 ẹni tí \nd Olúwa\nd* kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí i lọ́rùn
\q2 àti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.
\b
\q1
\v 3 Nígbà tí mo dákẹ́,
\q2 egungun mi di gbígbó dànù
\q2 nípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́.
\q1
\v 4 Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru
\q2 ọwọ́ rẹ̀ wúwo sí mi lára;
\q1 agbára mi gbẹ tán
\q2 gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 5 Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ
\q2 àti pé èmi kò sì fi àìṣòdodo mi pamọ́.
\q1 Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́
\q2 ẹ̀ṣẹ̀ mi fún \nd Olúwa\nd*,”
\q1 ìwọ sì dárí
\q2 ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 6 Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọ
\q2 ní ìgbà tí a lè rí ọ;
\q1 nítòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè,
\q2 wọn kì yóò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀.
\q1
\v 7 Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi;
\q2 ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu;
\q2 ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 8 Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà tí ìwọ yóò rìn
\q2 èmi yóò máa gbà ọ́ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ.
\q1
\v 9 Má ṣe dàbí ẹṣin tàbí ìbáaka,
\q2 tí kò ní òye
\q1 ẹnu ẹni tí a gbọdọ̀ fi ìjánu bọ̀,
\q2 kí wọn má ba à súnmọ́ ọ.
\q1
\v 10 Ọ̀pọ̀ ìkáàánú ní yóò wà fún ènìyàn búburú,
\q2 ṣùgbọ́n ìfẹ́ \nd Olúwa\nd* tí ó dúró ṣinṣin
\q2 ni yóò yí àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú \nd Olúwa\nd* ká.
\b
\q1
\v 11 Ẹ yọ̀ nínú \nd Olúwa\nd*, kí ẹ sì ní inú dídùn, ẹ̀yìn olódodo;
\q2 ẹ sì máa kọrin, gbogbo ẹ̀yìn tí àyà yín dúró ṣinṣin.
\c 33
\cl Saamu 33
\q1
\v 1 Ẹ yọ̀ nínú \nd Olúwa\nd*, ẹ̀yin olódodo;
\q2 ìyìn si yẹ fún ẹni dídúró ṣinṣin.
\q1
\v 2 Ẹ yin \nd Olúwa\nd* pẹ̀lú dùùrù;
\q2 ẹ máa fi ohun èlò olókùn mẹ́wàá kọrin sí i.
\q1
\v 3 Ẹ kọ orin tuntun sí i;
\q2 ẹ máa fi ọgbọọgbọ́n lu ohun èlò orin sí i, pẹ̀lú ariwo.
\b
\q1
\v 4 Nítorí pé ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* dúró ṣinṣin,
\q2 gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ni à ń ṣe nínú òtítọ́.
\q1
\v 5 Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;
\q2 ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1
\v 6 Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* ni a ṣe dá àwọn ọ̀run,
\q2 àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu rẹ̀.
\q1
\v 7 Ó kó àwọn omi òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò;
\q2 ó sì fi ibú ṣe ilé ìṣúra gbogbo.
\q1
\v 8 Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù \nd Olúwa\nd*:
\q2 jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayé kí ó wà nínú ìbẹ̀rù rẹ̀.
\q1
\v 9 Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀;
\q2 ó pàṣẹ ó sì dúró ṣinṣin.
\b
\q1
\v 10 \nd Olúwa\nd* ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀-èdè wá sí asán;
\q2 ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákì í.
\q1
\v 11 Ìgbìmọ̀ \nd Olúwa\nd* dúró títí ayérayé,
\q2 àní ìrò inú rẹ̀ láti ìrandíran ni.
\b
\q1
\v 12 Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè náà, Ọlọ́run ẹni tí \nd Olúwa\nd* jẹ́ tirẹ̀,
\q2 àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní rẹ̀.
\q1
\v 13 \nd Olúwa\nd* wò láti ọ̀run wá;
\q2 Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn.
\q1
\v 14 Níbi tí ó ti jókòó lórí ìtẹ́
\q2 Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé
\q1
\v 15 ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà,
\q2 ó sì kíyèsi ìṣe wọn.
\b
\q1
\v 16 A kò gba ọba kan là nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ogun;
\q2 kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá rẹ̀.
\q1
\v 17 Ohun asán ni ẹṣin fún ìṣẹ́gun;
\q2 bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi agbára ńlá rẹ̀ gbani sílẹ̀.
\q1
\v 18 Wò ó, ojú \nd Olúwa\nd* wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
\q2 àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ́ rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin.
\q1
\v 19 Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikú
\q2 àti láti pa wọ́n mọ́ láààyè lọ́wọ́ ìyàn.
\b
\q1
\v 20 Ọkàn wa dúró de \nd Olúwa\nd*;
\q2 òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti asà wa.
\q1
\v 21 Ọkàn wa yọ̀ nínú rẹ̀,
\q2 nítorí pé, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ rẹ mímọ́.
\q1
\v 22 Kí àánú rẹ, \nd Olúwa\nd*, kí ó wà lára wa,
\q2 àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń ṣe ìrètí nínú rẹ.
\c 34
\cl Saamu 34
\d Tí Dafidi. Nígbà tí ó díbọ́n bí ẹni tí ń ṣe wèrè níwájú Abimeleki, ẹni tí ó lé e lọ, ó sì jáde lọ.
\q1
\v 1 Èmi yóò máa fi ìbùkún fún \nd Olúwa\nd* nígbà gbogbo;
\q2 ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.
\q1
\v 2 Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú \nd Olúwa\nd*;
\q2 jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn.
\q1
\v 3 Gbé \nd Olúwa\nd* ga pẹ̀lú mi;
\q2 kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ lékè.
\b
\q1
\v 4 Èmi wá \nd Olúwa\nd*, ó sì dá mi lóhùn;
\q2 Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.
\q1
\v 5 Wọ́n wò ó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn;
\q2 ojú kò sì tì wọ́n.
\q1
\v 6 Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, \nd Olúwa\nd* sì gbóhùn rẹ̀;
\q2 ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.
\q1
\v 7 Angẹli \nd Olúwa\nd* yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká
\q2 ó sì gbà wọ́n.
\b
\q1
\v 8 Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé \nd Olúwa\nd* dára;
\q2 ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú rẹ̀.
\q1
\v 9 Ẹ bẹ̀rù \nd Olúwa\nd*, ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́,
\q2 nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
\q1
\v 10 Àwọn ọmọ kìnnìún a máa ṣe aláìní ebi a sì máa pa wọ́n;
\q2 ṣùgbọ́n àwọn tí ó wá \nd Olúwa\nd* kì yóò ṣe aláìní ohun tí ó dára.
\q1
\v 11 Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi;
\q2 èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 12 \x - \xo 34.12-16: \xt 1Pt 3.10-12.\x*Ta ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀;
\q2 kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere?
\q1
\v 13 Pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi
\q2 àti ètè rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ.
\q1
\v 14 Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere;
\q2 wá àlàáfíà, kí o sì lépa rẹ̀.
\b
\q1
\v 15 Ojú \nd Olúwa\nd* ń bẹ lára àwọn olódodo;
\q2 etí i rẹ̀ sì ṣí sí ẹkún wọn.
\q1
\v 16 Ojú \nd Olúwa\nd* korò sí àwọn tí ń ṣe búburú;
\q2 láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.
\b
\q1
\v 17 Nígbà tí olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́,
\q2 \nd Olúwa\nd* a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn.
\q1
\v 18 \nd Olúwa\nd* súnmọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn;
\q2 ó sì gba irú àwọn tí í ṣe oníròra ọkàn là.
\b
\q1
\v 19 Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀,
\q2 ṣùgbọ́n \nd Olúwa\nd* gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo rẹ̀.
\q1
\v 20 Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́;
\q2 kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn.
\b
\q1
\v 21 Ibi ni ó mú ikú ìkà wá,
\q2 àti àwọn tí ó kórìíra olódodo ni yóò jẹ̀bi.
\q1
\v 22 \nd Olúwa\nd* ra ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ padà;
\q2 kò sí ọ̀kan nínú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé tí yóò jẹ̀bi.
\c 35
\cl Saamu 35
\d Ti Dafidi.
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd*, gbógun ti àwọn tí ń gbóguntì mí;
\q2 kí o sì kọ ojú ìjà sí àwọn tí ó ń bá mi í jà!
\q1
\v 2 Di asà àti àpáta mú,
\q2 kí o sì dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi!
\q1
\v 3 Fa idà àti ọ̀kọ̀ yọ
\q2 kí o sì dojúkọ àwọn tí ń lé mi.
\q1 Sọ fún ọkàn mi pé,
\q2 “Èmi ni ìgbàlà rẹ.”
\b
\q1
\v 4 Kí wọn kí ó dààmú,
\q2 kí a sì ti àwọn tí ń lépa ọkàn mi lójú;
\q1 kí a sì mú wọn padà,
\q2 kí a sì dààmú àwọn tí ń gbèrò ìpalára mi.
\q1
\v 5 Jẹ́ kí wọn dàbí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́,
\q2 kí angẹli \nd Olúwa\nd* kí ó máa lé wọn kiri.
\q1
\v 6 Jẹ́ kí ọ̀nà wọn kí ó ṣókùnkùn, kí ó sì máa yọ́,
\q2 kí angẹli \nd Olúwa\nd* kí ó máa lépa wọn!
\b
\q1
\v 7 Nítorí pé, ní àìnídìí ni wọ́n dẹ àwọ̀n wọn sílẹ̀ fún mi,
\q2 ní àìnídìí ni wọ́n wa kòtò sílẹ̀ fún ọkàn mi.
\q1
\v 8 Kí ìparun kí ó wá sí orí rẹ̀ ní òjijì.
\q2 Àwọ̀n rẹ̀ tí ó dẹ, kí ó mú òun tìkára rẹ̀;
\q2 kí wọn ṣubú sínú kòtò sí ìparun ara rẹ̀.
\q1
\v 9 Nígbà náà ni ọkàn mi yóò yọ̀ nínú \nd Olúwa\nd*,
\q2 àní, yóò sì máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ̀.
\q1
\v 10 Gbogbo egungun mi yóò wí pé,
\q2 “Ta ni ó dàbí ì ìwọ \nd Olúwa\nd*?
\q1 O gba tálákà lọ́wọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ,
\q2 tálákà àti aláìní lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ṣe ìkógun?”
\b
\q1
\v 11 Àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde;
\q2 wọ́n ń bi mi ní ohun tí èmi kò mọ̀.
\q1
\v 12 Wọ́n fi búburú san ìre fún mi;
\q2 láti sọ ọkàn mi di òfo.
\q1
\v 13 Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni, nígbà tí wọn ń ṣe àìsàn, mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀;
\q2 mo fi àwẹ̀ pọ́n ara mi lójú.
\q1 Mo gba àdúrà pẹ̀lú ìtẹríba ní oókan àyà mi;
\q2
\v 14 èmí ń lọ kiri bí ẹni ń ṣọ̀fọ̀
\q2 bí i ẹni wí pé fún ọ̀rẹ́ tàbí ẹ̀gbọ́n mi ni.
\q1 Èmí tẹríba nínú ìbànújẹ́
\q2 bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ìyà rẹ̀.
\q1
\v 15 Ṣùgbọ́n nínú ìkọ̀sẹ̀ mi wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì kó ara wọn jọ;
\q2 wọ́n kó ara wọn jọ sí mi; àní àwọn tí èmi kò mọ̀.
\q2 Wọ́n fà mí ya wọ́n kò sì dákẹ́.
\q1
\v 16 Bí àwọn àgàbàgebè tí ń ṣe ẹlẹ́yà ní àpèjẹ
\q2 wọ́n pa eyín wọn keke sí mi.
\b
\q1
\v 17 Yóò ti pẹ́ tó \nd Olúwa\nd*, tí ìwọ yóò máa wò wọ́n lọ?
\q2 Yọ mí kúrò nínú ìparun wọn,
\q2 àní ẹ̀mí ì mi kúrò lọ́wọ́ kìnnìún.
\q1
\v 18 Nígbà náà ni èmi yóò ṣọpẹ́ fún Ọ nínú àjọ ńlá;
\q2 èmi yóò máa yìn Ọ́ ní àwùjọ ọ̀pọ̀ ènìyàn.
\q1
\v 19 \x - \xo 35.19: \xt Sm 69.4; Jh 15.25.\x*Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi
\q2 kí ó yọ̀ lórí ì mi;
\q1 bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe àwọn tí ó kórìíra mi
\q2 ní àìnídìí máa ṣẹ́jú sí mi.
\q1
\v 20 Nítorí pé wọn kò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà,
\q2 ṣùgbọ́n wọ́n lóyún ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn
\q2 sí àwọn ènìyàn dídákẹ́ ilẹ̀ náà.
\q1
\v 21 Wọ́n ya ẹnu wọn gbòòrò sí mi; wọ́n wí pé, “Háà! Háà!
\q2 Ojú wa sì ti rí i.”
\b
\q1
\v 22 Ìwọ́ ti rí i \nd Olúwa\nd*; má ṣe dákẹ́!
\q2 Olúwa má ṣe jìnnà sí mi!
\q1
\v 23 Dìde! ru ara rẹ̀ sókè fún ààbò mi,
\q2 àti sí ọ̀ràn mi, Ọlọ́run mi àti Olúwa mi!
\q1
\v 24 Ṣe ìdájọ́ mi, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ,
\q2 kí o má sì ṣe jẹ́ kí wọn kí ó yọ̀ lórí mi!
\q1
\v 25 Má ṣe jẹ́ kí wọn wí nínú ara wọn pé, “Háà! A ti rí ohun tí ọkàn wa ń fẹ́!”
\q2 Má ṣe jẹ́ kí wọn kí ó wí pé, “A ti gbé e mì.”
\b
\q1
\v 26 Kí ojú kí ó tì wọ́n,
\q2 kí wọn kí ó sì dààmú pọ̀,
\q1 àní àwọn tí ń yọ̀ sí ìyọnu mi
\q2 kí a fi ìtìjú àti àbùkù wọ̀ wọ́n ní aṣọ tí ń gbéraga sí mi.
\q1
\v 27 Jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ìdáláre mi
\q2 fò fún ayọ̀ àti ìdùnnú;
\q1 kí wọn máa sọ ọ́ títí lọ, “Pé gbígbéga ni \nd Olúwa\nd*,
\q2 sí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ̀.”
\b
\q1
\v 28 Nígbà náà ni ahọ́n mi yóò máa sọ̀rọ̀ òdodo rẹ,
\q2 àti ìyìn rẹ ní gbogbo ọjọ́.
\c 36
\cl Saamu 36
\d Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 1 \x - \xo 36.1: \xt Ro 3.18.\x*Ìré-òfin-kọjá ènìyàn búburú
\q2 jẹ́ kí n mọ̀ nínú ọkàn mi pé,
\q1 ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí
\q2 níwájú wọn.
\b
\q1
\v 2 Nítorí pé wọ́n pọ́n ara wọn ní ojú ara wọn
\q2 títí tí a kò fi le rí ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti kórìíra.
\q1
\v 3 Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ òhun ẹ̀tàn;
\q2 wọ́n ti fi ọgbọ́n àti ṣíṣe rere sílẹ̀.
\q1
\v 4 Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkà nígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn:
\q2 wọ́n gba ọ̀nà tí kò dára
\q2 wọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀.
\b
\q1
\v 5 Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ, ìwọ \nd Olúwa\nd*, ó ga dé ọ̀run,
\q2 òtítọ́ ọ̀ rẹ ga dé àwọsánmọ̀.
\q1
\v 6 Òdodo rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run,
\q2 àwọn ìdájọ́ rẹ dàbí ibú ńlá;
\q2 ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 7 Báwo ni ìṣeun ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ ti tó! Ọlọ́run!
\q2 Kí gbogbo ọmọ ènìyàn le sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ.
\q1
\v 8 Àsè ilé rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùn gidigidi;
\q2 ìwọ yóò sì mú wọn mu nínú odò inú dídùn rẹ.
\q1
\v 9 Nítorí pé pẹ̀lú rẹ ni orísun ìyè wà:
\q2 nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.
\b
\q1
\v 10 Mú ìṣeun ìfẹ́ ẹ̀ rẹ sí àwọn tí ó mọ̀ ọ́n
\q2 àti ìgbàlà rẹ sí àwọn tí ó ní ìdúró ṣinṣin ọkàn!
\q1
\v 11 Má ṣe jẹ́ kí ẹsẹ̀ agbéraga kí ó wá sí orí mi,
\q2 kí o má sì jẹ́ kí ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú sí mi ní ipò.
\q1
\v 12 Níbẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ gbé ṣubú sí:
\q2 a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, wọn kì yóò le è dìde!
\c 37
\cl Saamu 37
\d Ti Dafidi.
\q1
\v 1 Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú,
\q2 kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;
\q1
\v 2 nítorí pé wọn yóò gbẹ bí i koríko,
\q2 wọn yóò sì rẹ̀ dànù bí ewéko tútù.
\b
\q1
\v 3 Gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd*, kí o sì máa ṣe rere;
\q2 torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀.
\q1
\v 4 Ṣe inú dídùn sí \nd Olúwa\nd*;
\q2 òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀.
\b
\q1
\v 5 Fi ọ̀nà rẹ lé \nd Olúwa\nd* lọ́wọ́;
\q2 gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú, òun yóò sì ṣe é.
\q1
\v 6 Yóò sì mú kí òdodo rẹ̀ jáde bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,
\q2 àti ìdájọ́ rẹ̀ bí ọ̀sán gangan.
\b
\q1
\v 7 Ìwọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú \nd Olúwa\nd*,
\q2 kí o sì fi sùúrù dúró dè é;
\q1 má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn,
\q2 nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ.
\b
\q1
\v 8 Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí, kí o sì kọ ìkáàánú sílẹ̀,
\q2 má ṣe ṣe ìkanra, kí ó má ba à ṣé búburú pẹ̀lú.
\q1
\v 9 Nítorí tí á ó gé àwọn olùṣe búburú kúrò,
\q2 ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de \nd Olúwa\nd* àwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà.
\b
\q1
\v 10 Síbẹ̀ nígbà díẹ̀ sí i, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí mọ̀;
\q2 nítòótọ́ ìwọ yóò fi ara balẹ̀ wo ipò rẹ̀, wọn kì yóò sí níbẹ̀.
\q1
\v 11 Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
\q2 wọn yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.
\b
\q1
\v 12 Ènìyàn búburú di rìkíṣí sí olóòtítọ́,
\q2 wọ́n sì pa eyín wọn keke sí wọn;
\q1
\v 13 ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rìn-ín sí àwọn ènìyàn búburú,
\q2 nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀.
\b
\q1
\v 14 Ènìyàn búburú fa idà yọ,
\q2 wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn,
\q1 láti sọ tálákà àti aláìní kalẹ̀,
\q2 láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin.
\q1
\v 15 Idà wọn yóò wọ àyà wọn lọ,
\q2 àti wí pé ọrun wọn yóò sì ṣẹ́.
\b
\q1
\v 16 Ohun díẹ̀ tí olódodo ní,
\q2 sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ènìyàn búburú;
\q1
\v 17 nítorí pé a óò ṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú,
\q2 ṣùgbọ́n \nd Olúwa\nd* gbé olódodo sókè.
\b
\q1
\v 18 \nd Olúwa\nd* mọ àwọn ọjọ́ àwọn tó dúró ṣinṣin,
\q2 àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé.
\q1
\v 19 Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ibi,
\q2 àti ní ọjọ́ ìyàn, a ó tẹ́ wọn lọ́rùn.
\b
\q1
\v 20 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé.
\q2 Àwọn ọ̀tá \nd Olúwa\nd* yóò dàbí ẹwà oko tútù;
\q2 wọn fò lọ; bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò.
\b
\q1
\v 21 Àwọn ènìyàn búburú yá, wọn kò sì san án padà,
\q2 ṣùgbọ́n àwọn olódodo a máa ṣàánú, a sì máa fi fún ni;
\q1
\v 22 nítorí àwọn tí \nd Olúwa\nd* bá bùkún ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
\q2 àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò.
\b
\q1
\v 23 Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wá láti ọ̀dọ̀ \nd Olúwa\nd* wá,
\q2 o sì ṣe inú dídùn sí ọ̀nà rẹ̀;
\q1
\v 24 bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátápátá,
\q2 nítorí tí \nd Olúwa\nd* di ọwọ́ rẹ̀ mú.
\b
\q1
\v 25 Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmi sì dàgbà;
\q2 síbẹ̀ èmi kò ì tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀,
\q2 tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ.
\q1
\v 26 Aláàánú ni òun nígbà gbogbo a máa yá ni;
\q2 a sì máa bùsi i fún ni.
\b
\q1
\v 27 Lọ kúrò nínú ibi, kí o sì máa ṣe rere;
\q2 nígbà náà ni ìwọ yóò gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé.
\q1
\v 28 Nítorí pé \nd Olúwa\nd* fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́,
\q2 kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀.
\b
\q1 Àwọn olódodo ni a ó pamọ́ títí ayérayé,
\q2 ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburú ni a ó ké kúrò.
\q1
\v 29 Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
\q2 yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé.
\b
\q1
\v 30 Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,
\q2 ahọ́n rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́.
\q1
\v 31 Òfin Ọlọ́run rẹ̀ ń bẹ ní àyà wọn;
\q2 àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ kì yóò yẹ̀.
\b
\q1
\v 32 Ènìyàn búburú ń ṣọ́ olódodo,
\q2 Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á.
\q1
\v 33 \nd Olúwa\nd* kì yóò fi lé e lọ́wọ́ kì yóò sì dá a lẹ́bi,
\q2 nígbà tí a bá ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀.
\b
\q1
\v 34 Dúró de \nd Olúwa\nd*,
\q2 kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́.
\q1 Yóò sì gbé ọ lékè láti jogún ilẹ̀ náà;
\q2 nígbà tí a bá gé àwọn ènìyàn búburú kúrò ìwọ yóò ri.
\b
\q1
\v 35 Èmi ti rí ènìyàn búburú tí ń hu ìwà ìkà,
\q2 ó sì fi ara rẹ̀ gbilẹ̀ bí igi tútù ńlá,
\q1
\v 36 ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan sí i ó kọjá lọ, sì kíyèsi, kò sì sí mọ́;
\q2 bi ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé mo wá a kiri, ṣùgbọ́n a kò le è ri.
\b
\q1
\v 37 Máa kíyèsi ẹni pípé, kí o sì wo ẹni tó dúró ṣinṣin;
\q2 nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà.
\q1
\v 38 Ṣùgbọ́n àwọn olùrékọjá ni a ó parun papọ̀;
\q2 ìran àwọn ènìyàn búburú ni a ó gé kúrò.
\b
\q1
\v 39 Ìgbàlà àwọn onídùúró ṣinṣin wá láti ọ̀dọ̀ \nd Olúwa\nd*;
\q2 òun ni ààbò wọn ní ìgbà ìpọ́njú
\q1
\v 40 \nd Olúwa\nd* yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ yóò sì gbà wọ́n;
\q2 yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ènìyàn búburú, yóò sì gbà wọ́n là,
\q2 nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.
\c 38
\cl Saamu 38
\d Saamu Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd*, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe fi ìyà jẹ mí nínú ìrunú rẹ̀.
\q1
\v 2 Nítorí tí ọfà rẹ kàn mọ́ mi ṣinṣin,
\q2 ọwọ́ rẹ sì kì mí mọ́lẹ̀.
\q1
\v 3 Kò sí ibi yíyè ní ara à mi, nítorí ìbínú rẹ;
\q2 kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi.
\q1
\v 4 Nítorí àìṣedéédéé mi ti borí mi mọ́lẹ̀;
\q2 wọ́n tó ìwọ̀n bi àjàgà tí ó wúwo jù fún mi.
\b
\q1
\v 5 Ọgbẹ́ mi ń rùn ó sì díbàjẹ́
\q2 nítorí òmùgọ̀ mi.
\q1
\v 6 Èmi ń jòwèrè, orí mi tẹ̀ ba gidigidi
\q2 èmi ń ṣọ̀fọ̀ rìn kiri ní gbogbo ọjọ́.
\q1
\v 7 Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná tí ń jóni
\q2 kò sì ṣí ibi yíyè ní ara mi.
\q1
\v 8 Ara mi hù, a sì wó mi jẹ́gẹjẹ̀gẹ;
\q2 mo kérora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi.
\b
\q1
\v 9 \nd Olúwa\nd*, gbogbo ìfẹ́ mi ń bẹ níwájú rẹ;
\q2 ìmí ẹ̀dùn mi kò sá pamọ́ fún ọ.
\q1
\v 10 Àyà mi ń mí hẹlẹ, agbára mi yẹ̀ mí sílẹ̀;
\q2 bí ó ṣe ti ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni, ó ti lọ kúrò lára mi.
\q1
\v 11 Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi dúró lókèèrè réré kúrò níbi ìpọ́njú mi,
\q2 àwọn alábágbé mi, dúró lókèèrè.
\q1
\v 12 Àwọn tí n wá ẹ̀mí mi dẹ okùn sílẹ̀ fún mi;
\q2 àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun,
\q2 wọ́n sì ń gbèrò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́.
\b
\q1
\v 13 Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi, èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀;
\q2 àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀.
\q1
\v 14 Nítòótọ́, mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́rọ̀,
\q2 àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn.
\q1
\v 15 Ṣùgbọ́n sí ọ \nd Olúwa\nd*, ìwọ ni mo dúró dè;
\q2 ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run mi, ẹni tí yóò dáhùn.
\q1
\v 16 Nítorí tí mo gbàdúrà, “Gbóhùn mi, kí wọn má ba à yọ̀ mí;
\q2 nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yọ̀ wọn yóò máa gbé ara wọn ga sí mi.”
\b
\q1
\v 17 Nítorí tí mo ti ṣetán láti ṣubú,
\q2 ìrora mi sì wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo.
\q1
\v 18 Mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi;
\q2 àánú sì ṣe mí fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.
\q1
\v 19 Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí pàtàkì, wọ́n lágbára púpọ̀,
\q2 ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà òdì.
\q1
\v 20 Àwọn tí wọn ń fi ibi san rere fún mi
\q2 àwọn ni ọ̀tá mi
\q2 nítorí pé mò ń tọ ìre lẹ́yìn.
\b
\q1
\v 21 Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, ìwọ \nd Olúwa\nd*!
\q2 Ọlọ́run mi, má ṣe jìnnà sí mi.
\q1
\v 22 Yára láti ràn mí lọ́wọ́,
\q2 \nd Olúwa\nd*, Olùgbàlà mi.
\c 39
\cl Saamu 39
\d Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Saamu Dafidi.
\q1
\v 1 Mo wí pé, “Èmi yóò ṣọ́ ọ̀nà mi
\q2 kí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀;
\q1 èmi yóò fi ìjánu kó ara mi ní ẹnu
\q2 níwọ̀n ìgbà tí ènìyàn búburú bá ń bẹ ní iwájú mi.”
\q1
\v 2 Mo fi ìdákẹ́ ya odi;
\q2 mo tilẹ̀ pa ẹnu mi mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rere;
\q1 ìbànújẹ́ mi sì pọ̀ sí i.
\q2
\v 3 Àyà mi gbóná ní inú mi.
\q1 Nígbà tí mo ń ṣàṣàrò, iná ràn;
\q2 nígbà náà ni mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀:
\b
\q1
\v 4 “\nd Olúwa\nd*, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi,
\q2 àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí
\q2 kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín.
\q1
\v 5 Ìwọ ti ṣe ayé mi
\q2 bí ìbú àtẹ́lẹwọ́,
\q1 ọjọ́ orí mi sì dàbí asán
\q2 ní iwájú rẹ.
\q1 Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú
\q2 ìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 6 “Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji.
\q2 Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán;
\q1 wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ,
\q2 wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ.
\b
\q1
\v 7 “Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí,
\q2 \nd Olúwa\nd*,
\q1 kín ni mo ń dúró dè?
\q2 Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ rẹ.
\q1
\v 8 Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo.
\q2 Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gàn
\q1 àwọn ènìyàn búburú.
\q1
\v 9 Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́;
\q2 èmi kò sì ya ẹnu mi,
\q1 nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é.
\q1
\v 10 Mú pàṣán rẹ kúrò ní ara mi;
\q2 èmí ṣègbé tán nípa lílù ọwọ́ rẹ.
\q1
\v 11 Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀
\q2 fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀,
\q1 ìwọ a mú ẹwà rẹ parun
\q2 bí kòkòrò aṣọ;
\q1 nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo.
\b
\q1
\v 12 “Gbọ́ àdúrà mi, \nd Olúwa\nd*,
\q2 kí o sì fetí sí igbe mi;
\q2 kí o má ṣe di etí rẹ sí ẹkún mi.
\q1 Nítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ rẹ,
\q2 àti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí.
\q1
\v 13 Dá mi sí, kí èmi lè ní agbára,
\q2 kí èmi tó lọ kúrò níhìn-ín yìí,
\q2 àti kí èmi ó tó ṣe aláìsí.”
\c 40
\cl Saamu 40
\d Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.
\q1
\v 1 Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de \nd Olúwa\nd*;
\q2 ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi.
\q1
\v 2 Ó fà mí yọ gòkè
\q2 láti inú ihò ìparun,
\q1 láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀,
\q2 ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta,
\q1 ó sì jẹ́ kí ìgbésẹ̀ mi wà láìfòyà.
\q1
\v 3 Ó fi orin tuntun sí mi lẹ́nu,
\q2 àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa.
\q1 Ọ̀pọ̀ yóò rí i wọn yóò sì bẹ̀rù,
\q2 wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1
\v 4 Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n-ọn-nì
\q2 tí ó fi \nd Olúwa\nd* ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn
\q1 tí wọn kò sì yípadà sí agbéraga,
\q2 tàbí àwọn tí ó yapa
\q1 lọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn.
\q1
\v 5 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run mi,
\q2 ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe.
\q1 Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa;
\q2 ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹ,
\q1 tí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn,
\q2 wọ́n ju ohun tí
\q2 ènìyàn le è kà lọ.
\b
\q1
\v 6 \x - \xo 40.6-8: \xt Hb 10.5-9.\x*Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́,
\q2 ìwọ ti ṣí mi ní etí.
\q1 Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀
\q2 ni ìwọ kò béèrè.
\q1
\v 7 Nígbà náà ni mo wí pé,
\q2 “Èmi nìyí;
\q1 nínú ìwé kíká ni
\q2 a kọ ọ nípa tèmi wí pé.
\q1
\v 8 Mo ní inú dídùn
\q2 láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ rẹ,
\q1 ìwọ Ọlọ́run mi,
\q2 òfin rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”
\b
\q1
\v 9 Èmi ti sọ ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlà
\q2 láàrín àwùjọ ńlá;
\q1 wò ó,
\q2 èmi kò pa ètè mi mọ́,
\q1 gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti mọ̀,
\q2 ìwọ \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 10 Èmi kò fi ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà sin ní àyà mi;
\q2 èmí ti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ àti ìgbàlà rẹ.
\q1 Èmi kò sì pa ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ mọ́
\q2 kúrò láàrín àwọn ìjọ ńlá.
\b
\q1
\v 11 Ìwọ má ṣe, fa àánú rẹ tí ó rọ́nú sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi \nd Olúwa\nd*;
\q2 jẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ
\q2 kí ó máa pa mi mọ́ títí ayérayé.
\q1
\v 12 Nítorí pé àìníye ibi
\q2 ni ó yí mi káàkiri,
\q1 ẹ̀ṣẹ̀ mi sì dì mọ́ mi,
\q2 títí tí èmi kò fi ríran mọ́;
\q1 wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,
\q2 àti wí pé àyà mí ti kùnà.
\b
\q1
\v 13 \x - \xo 40.13-17: \xt Sm 70.1-5.\x*Jẹ́ kí ó wù ọ́,
\q2 ìwọ \nd Olúwa\nd*,
\q1 láti gbà mí là;
\q2 \nd Olúwa\nd*,
\q1 yára láti ràn mí lọ́wọ́.
\b
\q1
\v 14 Gbogbo àwọn wọ̀n-ọn-nì ni kí ojú kí ó tì
\q2 kí wọn kí ó sì dààmú;
\q1 àwọn tí ń wá ọkàn mi láti parun
\q2 jẹ́ kí a lé wọn padà sẹ́yìn kí a sì dójútì wọ́n,
\q2 àwọn tí ń wá ìpalára mi.
\q1
\v 15 Jẹ́ kí àwọn tí ó wí fún mi pé, “Háà! Háà!”
\q2 ó di ẹni à fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nítorí ìtìjú wọn.
\q1
\v 16 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ
\q2 kí ó máa yọ̀
\q1 kí inú wọn sì máa dùn sí ọ;
\q2 kí gbogbo àwọn tí ó sì fẹ́ ìgbàlà rẹ
\q1 kí o máa wí nígbà gbogbo pé,
\q2 “Gbígbéga ni \nd Olúwa\nd*!”
\b
\q1
\v 17 Bí ó ṣe ti èmi ni,
\q2 tálákà àti aláìní ni èmi,
\q1 ṣùgbọ́n Olúwa ń ṣe ìrántí mi.
\q2 Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi
\q1 àti ìgbàlà mi;
\q2 má ṣe jẹ́ kí ó pẹ́,
\q2 ìwọ Ọlọ́run mi.
\c 41
\cl Saamu 41
\d Fún adarí orin. Saamu Dafidi.
\q1
\v 1 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní:
\q2 \nd Olúwa\nd* yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú.
\q1
\v 2 \nd Olúwa\nd* yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́:
\q2 yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀
\q1 kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.
\q1
\v 3 \nd Olúwa\nd* yóò gbà á lórí àkéte àìsàn rẹ̀
\q2 yóò sì mú un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn rẹ̀.
\b
\q1
\v 4 Ní ti èmi, mo wí pé “\nd Olúwa\nd*, ṣàánú fún mi;
\q2 wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.
\q1
\v 5 Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi nínú àrankàn, pé,
\q2 “Nígbà wo ni yóò kú, ti orúkọ rẹ̀ yóò sì run?”
\q1
\v 6 Nígbàkígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí,
\q2 wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara rẹ̀;
\q1 nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kálẹ̀.
\b
\q1
\v 7 Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi;
\q2 èmi ni wọ́n ń gbìmọ̀ ibi sí,
\q1
\v 8 wọ́n wí pé, “Ohun búburú ni ó dì mọ́ ọn ṣinṣin
\q2 àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí,
\q1 kì yóò dìde mọ́.”
\q1
\v 9 \x - \xo 41.9: \xt Jh 13.18.\x*Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé,
\q2 ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi,
\q1 tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.
\b
\q1
\v 10 Ṣùgbọ́n ìwọ \nd Olúwa\nd*, ṣàánú fún mi;
\q2 gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn.
\q1
\v 11 Èmi mọ̀ pé inú rẹ̀ dùn sí mi,
\q2 nítorí ọ̀tá mi kò borí mi.
\q1
\v 12 Bí ó ṣe tèmi ni
\q2 ìwọ dì mímú nínú ìwà òtítọ́ mi
\q1 ìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú rẹ títí láé.
\b
\b
\q1
\v 13 Olùbùkún ni \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run Israẹli,
\q2 láé àti láéláé.
\qc Àmín àti Àmín.
\c 42
\ms ÌWÉ KEJÌ
\mr Saamu 4272
\cl Saamu 42
\d Fún adarí orin. Maskili ti àwọn ọmọ Kora.
\q1
\v 1 Bí àgbọ̀nrín ti ń mí hẹlẹ sí ipa odò omi,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń mí hẹlẹ sí ọ Ọlọ́run.
\q1
\v 2 Òùngbẹ Ọlọ́run ń gbẹ ọkàn mi, fún Ọlọ́run alààyè.
\q2 Nígbà wo ni èmi ó lọ bá Ọlọ́run?
\q1
\v 3 Oúnjẹ mi ni omijé mi
\q2 ní ọ̀sán àti ní òru,
\q2 nígbà tí àwọn ènìyàn ń wí fún mi ní gbogbo ọjọ́ pé,
\q2 “Ọlọ́run rẹ dà?”
\q1
\v 4 Nígbà tí mo bá rántí nǹkan yìí,
\q2 èmi tú ọkàn mi jáde nínú mi:
\q1 èmi ti bá ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn lọ,
\q2 èmi bá wọn lọ sí ilé Ọlọ́run
\q1 pẹ̀lú ohùn ayọ̀ àti ìyìn,
\q2 pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń pa ọjọ́ mímọ́ mọ́.
\b
\q1
\v 5 Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?
\q2 Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?
\q1 Ìwọ ṣe ìrètí ní ti Ọlọ́run,
\q2 nítorí èmi yóò sá à máa yìn ín,
\q2 Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.
\b
\q1
\v 6 Ọlọ́run mi, ọkàn mi ń rẹ̀wẹ̀sì nínú mi:
\q2 nítorí náà, èmi ó rántí rẹ
\q1 láti ilẹ̀ Jordani wá,
\q2 láti Hermoni láti òkè Mibsari.
\q1
\v 7 Ibú omi ń pe ibú omi
\q2 nípa híhó omi ṣíṣàn rẹ̀
\q1 gbogbo rírú omi àti bíbì omi rẹ̀
\q2 bò mí mọ́lẹ̀.
\b
\q1
\v 8 Ní ọ̀sán ní \nd Olúwa\nd* ran ìfẹ́ rẹ̀,
\q2 àti ni àṣálẹ́ ni orin rẹ̀ wà pẹ̀lú mi
\q1 àdúrà sí Ọlọ́run ayé mi.
\b
\q1
\v 9 Èmi wí fún Ọlọ́run àpáta mi,
\q2 “Èéṣe tí ìwọ fi gbàgbé mi?
\q1 Èéṣe tí èmi o fi máa rìn nínú ìbànújẹ́,
\q2 nítorí ìnilára ọ̀tá?”
\q1
\v 10 Bí ẹni pé idà egungun mi ni ẹ̀gàn tí
\q2 àwọn ọ̀tá mi ń gàn mí,
\q1 bí wọn ti ń béèrè ní gbogbo ọjọ́.
\q2 “Níbo ni Ọlọ́run rẹ wà?”
\b
\q1
\v 11 Èéṣe tí ìwọ fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?
\q2 Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?
\q1 Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,
\q2 nítorí èmi yóò sì máa yìn ín, Òun ni
\q2 Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.
\c 43
\cl Saamu 43
\q1
\v 1 Dá mi láre, Ọlọ́run mi,
\q2 kí o sì gba ọ̀rọ̀ mi rò lọ́dọ̀ àwọn aláìláàánú orílẹ̀-èdè:
\q1 yọ mí kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti àwọn ènìyàn búburú.
\q1
\v 2 Ìwọ ni Ọlọ́run ibi agbára mi.
\q2 Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mi sílẹ̀?
\q1 Èéṣe tí èmi yóò máa rìn nínú ìbìnújẹ́,
\q2 nítorí ìnilára lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá?
\q1
\v 3 Rán ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ rẹ jáde,
\q2 jẹ́ kí wọn ó máa dáàbò bò mí;
\q1 jẹ́ kí wọn mú mi wá sí òkè mímọ́ rẹ,
\q2 sí ibi tí ìwọ ń gbé.
\q1
\v 4 Nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọ́run,
\q2 sí Ọlọ́run ayọ̀ mi àti ìdùnnú mi,
\q1 èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú dùùrù,
\q2 ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run mi.
\b
\q1
\v 5 Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mí?
\q2 Èéṣe tí ó fi ń ru sókè nínú mi?
\q1 Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,
\q2 nítorí èmi yóò máa yìn ín, Òun ni
\q2 Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.
\c 44
\cl Saamu 44
\d Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Maskili.
\q1
\v 1 À ti fi etí wa gbọ́, Ọlọ́run;
\q2 àwọn baba wa tí sọ fún wa
\q1 ohun tí ìwọ ṣe ní ọjọ́ wọn,
\q2 ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.
\q1
\v 2 Ìwọ fi ọwọ́ rẹ lé orílẹ̀-èdè jáde,
\q2 Ìwọ sì gbin àwọn baba wa;
\q1 ìwọ run àwọn ènìyàn náà
\q2 Ìwọ sì mú àwọn baba wa gbilẹ̀.
\q1
\v 3 Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọ́n gba ilẹ̀ náà,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò ṣe;
\q1 ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti, apá rẹ;
\q2 àti ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn.
\b
\q1
\v 4 Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi,
\q2 ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jakọbu.
\q1
\v 5 Nípasẹ̀ rẹ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣubú;
\q2 nípasẹ̀ orúkọ rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wa mọ́lẹ̀,
\q1
\v 6 èmi kì yóò gbẹ́kẹ̀lé ọrun mi,
\q2 idà mi kì yóò mú ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wá,
\q1
\v 7 ṣùgbọ́n ìwọ fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wa,
\q2 ìwọ sì ti dójúti àwọn tí ó kórìíra wa.
\q1
\v 8 Nínú Ọlọ́run àwa ń ṣògo ní gbogbo ọjọ́,
\q2 àwa ó sì yin orúkọ rẹ títí láé. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 9 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ ti kọ̀ wá, ìwọ sì ti dójútì wá,
\q2 Ìwọ kò sì bá àwọn ọmọ-ogun wa jáde mọ́.
\q1
\v 10 Ìwọ ti bá wa jà,
\q2 ìwọ sì ti ṣẹ́gun wa níwájú àwọn ọ̀tá wa,
\q1 àwọn ọ̀tá wa ti gba ilẹ̀ wa,
\q2 wọ́n sì fi ipá gba oko wa.
\q1
\v 11 Ìwọ fi wá fún jíjẹ bí ẹran àgùntàn,
\q2 Ìwọ sì ti tú wa ká sí àárín àwọn kèfèrí.
\q1
\v 12 Ìwọ ta àwọn ènìyàn rẹ fún owó kékeré,
\q2 Ìwọ kò sì jẹ èrè kankan lórí iye tí ìwọ tà wọ́n.
\b
\q1
\v 13 Ìwọ sọ wá di ẹni ẹ̀sín ní ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wa,
\q2 ẹlẹ́yà àti ẹni àbùkù sí àwọn tí ó yí wa ká.
\q1
\v 14 Ìwọ ti sọ wá di ẹni ìfisọ̀rọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
\q2 àwọn ènìyàn ń mi orí wọn sí wa.
\q1
\v 15 Ìdójútì mi ń bẹ pẹ̀lú mi ní gbogbo ọjọ́,
\q2 ìtìjú sì bojú mi mọ́lẹ̀,
\q1
\v 16 nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn
\q2 ní ojú àwọn ọ̀tá àti olùgbẹ̀san.
\b
\q1
\v 17 Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ sí wa,
\q2 síbẹ̀ àwa kò gbàgbé rẹ
\q1 bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣèké sí májẹ̀mú rẹ̀.
\q1
\v 18 Ọkàn wa kò padà sẹ́yìn;
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wa kò yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà rẹ̀.
\q1
\v 19 Ṣùgbọ́n wọ́n kọlù wá,
\q2 ìwọ sì sọ wá di ẹran ọdẹ fún àwọn ẹranko búburú,
\q1 tí wọn sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.
\b
\q1
\v 20 Bí àwa bá ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa
\q2 tàbí tí a na ọwọ́ wa sí ọlọ́run àjèjì.
\q1
\v 21 Ǹjẹ́ Ọlọ́run kì yóò rí ìdí rẹ̀,
\q2 níwọ̀n ìgbà tí ó mọ ohun ìkọ̀kọ̀ inú ọkàn?
\q1
\v 22 \x - \xo 44.22: \xt Ro 8.36.\x*Síbẹ̀, nítorí rẹ̀ àwa da àyà kọ ikú, ní ojoojúmọ́
\q2 a ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.
\b
\q1
\v 23 Jí, \nd Olúwa\nd*! Èéṣe tí ìwọ ń sùn?
\q2 Dìde fúnra rẹ̀! Má ṣe kọ̀ wá sílẹ̀ láéláé.
\q1
\v 24 Èéṣe tí ìwọ ń pa ojú rẹ mọ́
\q2 tí ìwọ sì gbàgbé ìpọ́njú àti ìnira wa?
\b
\q1
\v 25 Nítorí a tẹrí ọkàn wa ba sínú eruku;
\q2 ara wa sì dì mọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀.
\q1
\v 26 Dìde kí o sì ràn wá lọ́wọ́;
\q2 rà wá padà nítorí ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.
\c 45
\cl Saamu 45
\d Fún adarí orin. Tí ohun orin “Lílì.” Ti orin àwọn ọmọ Kora. Maskili. Orin ìgbéyàwó.
\q1
\v 1 Ọkàn mi mọ ọ̀rọ̀ rere
\q2 gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń sọ ohun tí mo ti ṣe fún ọba
\q2 ahọ́n mi ni kálámù ayára kọ̀wé.
\b
\q1
\v 2 Ìwọ yanjú ju àwọn ọmọ ènìyàn lọ:
\q2 a da oore-ọ̀fẹ́ sí ọ ní ètè:
\q2 nítorí náà ni Ọlọ́run ṣe bùkún fún ọ láéláé.
\b
\q1
\v 3 Gba idà rẹ mọ́ ìhà rẹ, ìwọ alágbára jùlọ
\q2 wọ ara rẹ ní ògo àti ọláńlá.
\q1
\v 4 Nínú ọláńlá rẹ, máa gẹṣin lọ ní àlàáfíà lórí òtítọ́,
\q2 ìwà tútù àti òtítọ́;
\q2 jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ohun ẹ̀rù.
\q1
\v 5 Jẹ́ kí ọfà mímú rẹ̀ dá ọkàn àwọn ọ̀tá ọba lu
\q2 jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
\q1
\v 6 \x - \xo 45.6-7: \xt Hb 1.8-9.\x*Ọlọ́run láé, àti láéláé ni ìtẹ́ rẹ,
\q2 ọ̀pá aládé ìjọba rẹ, ọ̀pá aládé òtítọ́ ni.
\q1
\v 7 Ìwọ fẹ́ olódodo, ìwọ sì kórìíra ìwà búburú
\q2 nígbà náà Ọlọ́run, Ọlọ́run rẹ ti yàn ọ́ ṣe olórí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ,
\q2 nípa fífi àmì òróró ayọ̀ kùn ọ́.
\q1
\v 8 Gbogbo aṣọ rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjìá àti aloe àti kasia;
\q2 láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe
\q2 orin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú rẹ̀ dùn.
\q1
\v 9 Àwọn ọmọbìnrin àwọn ọba
\q2 wà nínú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀,
\q1 ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúró
\q2 nínú wúrà Ofiri.
\b
\q1
\v 10 Gbọ́ ìwọ ọmọbìnrin, ronú kí o sì dẹtí rẹ sí mi
\q2 gbàgbé àwọn ènìyàn rẹ àti ilé baba rẹ.
\q1
\v 11 Bẹ́ẹ̀ ni ọba yóò fẹ́ ẹwà rẹ gidigidi
\q2 nítorí òun ni olúwa rẹ
\q1 kí ìwọ sì máa tẹríba fún un.
\q1
\v 12 Ọmọbìnrin ọba Tire yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùn
\q2 àwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojúrere rẹ̀.
\q1
\v 13 Gbogbo ògo ni ti ọmọbìnrin ọba ní àárín ilé rẹ̀,
\q2 iṣẹ́ wúrà ọnà abẹ́rẹ́ ní aṣọ rẹ̀.
\q1
\v 14 Nínú aṣọ olówó iyebíye ni a mú un tọ́ ọba wá,
\q2 àwọn wúńdíá ẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ̀lé e, wọ́n sí mú un tọ̀ ọ́ wá.
\q1
\v 15 Wọ́n sì mú un wá pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn
\q2 wọ́n sì wọ ààfin ọba.
\b
\q1
\v 16 Ọmọ rẹ̀ ni yóò gba ipò baba rẹ̀
\q2 ìwọ yóò sì fi wọ́n joyè lórí ilẹ̀ gbogbo.
\b
\q1
\v 17 Èmí yóò máa rántí orúkọ rẹ̀ ní ìran gbogbo,
\q2 nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò yìn ọ́ láé àti láéláé.
\c 46
\cl Saamu 46
\d Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. Orin.
\q1
\v 1 Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa
\q2 ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.
\q1
\v 2 Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí,
\q2 tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.
\q1
\v 3 Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì
\q2 tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 4 Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn,
\q2 ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé.
\q1
\v 5 Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀:
\q2 Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀.
\q1
\v 6 Àwọn orílẹ̀-èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba ṣubú,
\q2 ó gbé ohun rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.
\b
\q1
\v 7 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa,
\q2 Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.
\b
\q1
\v 8 Ẹ wá wo iṣẹ́ \nd Olúwa\nd*
\q2 irú ahoro tí ó ṣe ní ayé.
\q1
\v 9 O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé
\q2 ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì
\q1 ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná.
\q1
\v 10 Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run.
\q1 A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè,
\q2 a ó gbé mi ga ní ayé.
\b
\q1
\v 11 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa;
\q2 Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.
\c 47
\cl Saamu 47
\d Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
\q1
\v 1 Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn
\q2 ẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀.
\b
\q1
\v 2 Báwo ni \nd Olúwa\nd* Ọ̀gá-ògo ti ní ẹ̀rù tó
\q2 ọba ńlá lórí gbogbo ayé.
\q1
\v 3 Ṣe ìkápá àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ wa
\q2 àwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa
\q1
\v 4 Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún wa,
\q2 ọlá Jakọbu, ẹni tí ó fẹ́ wa.
\b
\q1
\v 5 Ọlọ́run tó gòkè lọ tí òun tayọ̀,
\q2 \nd Olúwa\nd* ti òun ti ariwo ìpè.
\q1
\v 6 Ẹ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn.
\q2 Ẹ kọrin ìyìn sí ọba wa, ẹ kọrin ìyìn!
\q1
\v 7 Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayé,
\q2 ẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Saamu!
\b
\q1
\v 8 Ọlọ́run jẹ ọba lórí gbogbo kèfèrí;
\q2 Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ rẹ̀.
\q1
\v 9 Àwọn aládé ayé kó ara wọn jọ
\q2 gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run Abrahamu
\q1 nítorí asà ayé ti Ọlọ́run ni,
\q2 òun ni ó ga jùlọ.
\c 48
\cl Saamu 48
\d Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora.
\q1
\v 1 Ẹni ńlá ní \nd Olúwa\nd*, tí ó sì yẹ láti máa yìn
\q2 ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ rẹ̀.
\b
\q1
\v 2 \x - \xo 48.2: \xt Mt 5.35.\x*Ó dára nínú ipò ìtẹ́ rẹ̀,
\q2 ayọ̀ gbogbo ayé,
\q1 òkè Sioni, ní ìhà àríwá
\q2 ní ìlú ọba ńlá.
\q1
\v 3 Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin rẹ̀;
\q2 ó fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.
\b
\q1
\v 4 Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀,
\q2 wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ.
\q1
\v 5 Wọn rí i, bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́n,
\q2 a yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ.
\q1
\v 6 Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀,
\q2 ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí.
\q1
\v 7 Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Tarṣiṣi,
\q2 wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà-oòrùn.
\b
\q1
\v 8 Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni àwa rí,
\q1 ní inú \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun
\q2 ní ìlú Ọlọ́run wa,
\q2 Ọlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 9 Láàrín tẹmpili rẹ, Ọlọ́run,
\q2 àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ rẹ.
\q1
\v 10 Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ Ọlọ́run,
\q2 ìyìn rẹ̀ dé òpin ayé,
\q2 ọwọ́ ọ̀tún rẹ kún fún òdodo.
\q1
\v 11 Jẹ́ kí òkè Sioni kí ó yọ̀
\q2 kí inú àwọn ọmọbìnrin Juda kí ó dùn
\q2 nítorí ìdájọ́ rẹ.
\b
\q1
\v 12 Rìn Sioni kiri lọ yíká rẹ̀,
\q2 ka ilé ìṣọ́ rẹ̀.
\q1
\v 13 Kíyèsi odi rẹ̀,
\q2 kíyèsi àwọn ààfin rẹ̀
\q1 kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀.
\b
\q1
\v 14 Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayé,
\q2 Òun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.
\c 49
\cl Saamu 49
\d Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
\q1
\v 1 Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn!
\q2 Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin aráyé.
\q1
\v 2 Àti ẹni tí ó ga àti ẹni tí ó kéré
\q2 tálákà àti ọlọ́lá pẹ̀lú!
\q1
\v 3 Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,
\q2 èrò láti ọkàn mi yóò mú òye wá
\q1
\v 4 èmi yóò dẹ etí mi sílẹ̀ sí òwe,
\q2 èmi yóò ṣí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mi sílẹ̀ lójú okùn dùùrù.
\b
\q1
\v 5 Èéṣe ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi dé?
\q2 Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ajinnilẹ́sẹ̀ mi yí mi ká,
\q1
\v 6 àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn,
\q2 tí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ wọn.
\q1
\v 7 Kò sí ọkùnrin tí ó lè ra ẹ̀mí ẹnìkejì rẹ̀
\q2 padà tàbí san owó ìràpadà fún
\q1 Ọlọ́run.
\q1
\v 8 Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ́ iyebíye
\q2 kò sì sí iye owó tó tó fún sísan rẹ̀,
\q1
\v 9 ní ti kí ó máa wà títí ayé
\q2 láìrí isà òkú.
\q1
\v 10 Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kú,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú ṣègbé
\q1 wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.
\q1
\v 11 Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláé,
\q2 ibùgbé wọn láti ìrandíran,
\q1 wọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn.
\b
\q1
\v 12 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́
\q2 ó sì dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.
\b
\q1
\v 13 Èyí ni òtítọ́ àwọn ènìyàn tí ó
\q2 gbàgbọ́ nínú ara wọn,
\q1 àti àwọn tí ń tẹ̀lé wọn,
\q2 tí ó gba ọ̀rọ̀ wọn. \qs Sela.\qs*
\q1
\v 14 Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn ni a tẹ́ wọn sínú isà òkú
\q2 ikú yóò jẹun lórí wọn;
\q1 ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni yóò,
\q2 jẹ ọba lórí wọn ní òwúrọ̀.
\q1 Ẹwà wọn yóò díbàjẹ́,
\q2 isà òkú ni ibùgbé ẹwà wọn.
\q1
\v 15 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ra ọkàn mi padà
\q2 kúrò nínú isà òkú,
\q1 yóò gbé mi lọ sọ́dọ̀ òun fún rara rẹ̀.
\q1
\v 16 Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnìkan bá di ọlọ́rọ̀.
\q2 Nígbà tí ìyìn ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i.
\q1
\v 17 Nítorí kì yóò mú ohun kan lọ nígbà tí ó bá kú,
\q2 ògo rẹ̀ kò ní bá a sọ̀kalẹ̀ sí ipò òkú.
\q1
\v 18 Nígbà tí ó wà láyé, ó súre fún ọkàn ara rẹ̀.
\q2 Àwọn ènìyàn yìn ọ́ nígbà tí ìwọ ṣe rere.
\q1
\v 19 Òun yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ìran àwọn baba rẹ̀
\q2 àwọn tí ki yóò ri ìmọ́lẹ̀ ayé.
\b
\q1
\v 20 Ọkùnrin tí ó ní ọlá tí kò ní òye dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.
\c 50
\cl Saamu 50
\d Saamu ti Asafu.
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run alágbára,
\q2 sọ̀rọ̀ kí o sì pe ayé jọ
\q2 láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀.
\q1
\v 2 Láti Sioni wá, pípé ni ẹwà,
\q2 Ọlọ́run tí ń tan ìmọ́lẹ̀
\q1
\v 3 Ọlọ́run ń bọ̀,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dákẹ́,
\q1 iná yóò máa jó níwájú rẹ̀,
\q2 àti ní àyíká rẹ̀ ni ẹ̀fúùfù líle yóò ti máa jà ká.
\q1
\v 4 Yóò sì pe àwọn ọ̀run láti òkè wá jọ àti ayé,
\q2 kí o le máa ṣe ìdárò àwọn ènìyàn rẹ̀.
\q1
\v 5 “Kó àwọn ènìyàn mímọ́ jọ fún mi
\q2 àwọn tí wọn fi ẹbọ dá májẹ̀mú fún mi.”
\q1
\v 6 Àwọn ọ̀run yóò sì sọ̀rọ̀ òdodo rẹ̀,
\q2 nítorí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni onídàájọ́.
\b
\q1
\v 7 “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi yóò si sọ̀rọ̀, ìwọ Israẹli, èmi yóò jẹ́rìí sí ọ:
\q2 èmi ní Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ.
\q1
\v 8 Èmi kí yóò bá ọ wí
\q2 nítorí àwọn ìrúbọ rẹ,
\q1 tàbí ọrẹ ẹbọ sísun rẹ, èyí tí ó wà níwájú mi
\q2 ní ìgbà gbogbo.
\q1
\v 9 Èmí kò fẹ́ kí ó mú akọ màlúù láti inú ilé tí o kọ́ fún un,
\q2 tàbí kí o mú òbúkọ láti
\q1 inú agbo ẹran rẹ̀
\q1
\v 10 nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmi
\q2 àti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún (1,000) òkè.
\q1
\v 11 Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńlá
\q2 àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà ní orí ilẹ̀ ni tèmi.
\q1
\v 12 Bí ebi tilẹ̀ ń pa mí, èmi kì yóò sọ fún ọ,
\q2 nítorí ayé ni tèmi àti ohun gbogbo
\q1 tí ó wa ní inú rẹ̀.
\q1
\v 13 Ǹjẹ́ èmi yóò ha jẹ ẹran akọ màlúù tàbí
\q2 mú ẹ̀jẹ̀ òbúkọ?
\b
\q1
\v 14 “Rú ẹbọ ọpẹ́ sí Ọlọ́run,
\q2 kí o sì san ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ọ̀gá-ògo.
\q1
\v 15 Kí o sì pè mí ní ọjọ́ ìpọ́njú,
\q2 èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.”
\p
\v 16 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún àwọn, ènìyàn búburú:
\q1 “Kí ní ẹ̀tọ́ tí o ní tí ìwọ fi ń tún àwọn ìlànà mi sọ,
\q2 tàbí tí ìwọ sì ń sọ májẹ̀mú mi ní ẹnu rẹ?
\q1
\v 17 Ìwọ kórìíra àṣẹ mi,
\q2 ìwọ sì ṣá ọ̀rọ̀ mí tì sí apá kan.
\q1
\v 18 Nígbà tí ìwọ rí olè, ìwọ dára pọ̀ mọ́ ọn,
\q2 ìwọ sì da ara rẹ dé àwọn alágbèrè.
\q1
\v 19 Ìwọ lo ẹnu rẹ fún aburú,
\q2 ìwọ sì ń fi ahọ́n rẹ pète ẹ̀tàn.
\q1
\v 20 Ní ìgbà gbogbo ìwọ ń sọ̀rọ̀ sí arákùnrin rẹ,
\q2 ìwọ sì ń ba orúkọ ọmọ ìyá rẹ jẹ́.
\q1
\v 21 Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ ti ṣe, mo sì dákẹ́;
\q2 ìwọ rò pé mo jẹ́ irú kan náà bí ìrẹ,
\q1 ṣùgbọ́n èmi yóò bá ọ wí,
\q2 èmi yóò sì fi ẹ̀sùn kàn ọ́ ní ojú ara rẹ.
\b
\q1
\v 22 “Ǹjẹ́ ìwọ ro èyí wò, ẹ̀yin tí ó gbàgbé Ọlọ́run.
\q2 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ èmi yóò fa yin ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, láìsí ẹni tí yóò gbà yin sílẹ̀.
\q1
\v 23 Ẹni tí ó ba ní ẹbọ ọrẹ-ọpẹ́ bu ọlá fún mi; kí ó sì tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe,
\q2 kí èmi kí ó le fi ìgbàlà Ọlọ́run hàn án.”
\c 51
\cl Saamu 51
\d Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Nígbà ti wòlíì Natani tọ wá, lẹ́yìn tí Dafidi dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè rẹ̀ pẹ̀lú Batṣeba.
\q1
\v 1 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run,
\q2 gẹ́gẹ́ bí ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ̀,
\q1 gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀
\q2 kí o sì pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́.
\q1
\v 2 Wẹ gbogbo àìṣedéédéé mi nù kúrò
\q2 kí o sì wẹ̀ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi!
\b
\q1
\v 3 Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi,
\q2 nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi.
\q1
\v 4 \x - \xo 51.4: \xt Ro 3.4.\x*Sí ọ, ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí
\q2 ni mo sì ṣe búburú níwájú rẹ̀,
\q1 kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀,
\q2 kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọ bá ń ṣe ìdájọ́.
\q1
\v 5 Nítòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi,
\q2 nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi.
\q1
\v 6 Nítòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú;
\q2 ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀kọ̀.
\b
\q1
\v 7 Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé hísópù, èmi yóò sì mọ́;
\q2 fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju yìnyín lọ.
\q1
\v 8 Jẹ́ kí n gbọ́ ayọ̀ àti inú dídùn;
\q2 jẹ́ kí gbogbo egungun tí ìwọ ti run kí ó máa yọ̀.
\q1
\v 9 Pa ojú rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi
\q2 kí o sì pa gbogbo àwọn àìṣedéédéé mi rẹ́.
\b
\q1
\v 10 Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run,
\q2 kí o sì tún ẹ̀mí dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi.
\q1
\v 11 Má ṣe jù mi nù kúrò níwájú rẹ,
\q2 kí o má ṣe gba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ lọ́wọ́ mi.
\q1
\v 12 Mú ayọ̀ ìgbàlà rẹ tọ̀ mí wá,
\q2 kí o sì fún mi ní ẹ̀mí ìfẹ́, tí yóò mú mi dúró.
\b
\q1
\v 13 Nígbà náà ni èmi yóò máa kọ́ àwọn olùrékọjá ní ọ̀nà rẹ,
\q2 àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò sì yí padà sí ọ.
\q1
\v 14 Gbà mí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, Ọlọ́run,
\q2 ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà mi,
\q1 ahọ́n mi yóò sì máa kọrin òdodo rẹ kíkan.
\q1
\v 15 \nd Olúwa\nd*, ṣí mi ní ètè mi gbogbo,
\q2 àti ẹnu mi yóò sì máa kéde ìyìn rẹ.
\q1
\v 16 Nítorí ìwọ kò ní inú dídùn sí ẹbọ, tí èmi kò bá mú wá;
\q2 Ìwọ kò ní inú dídùn sí ọrẹ ẹbọ sísun.
\q1
\v 17 Ẹbọ Ọlọ́run ni ìròbìnújẹ́ ọkàn ìròbìnújẹ́ àti ìrora àyà.
\b
\q1
\v 18 Ṣe rere ní dídùn inú rẹ sí Sioni,
\q2 ṣe rere; tún odi Jerusalẹmu mọ.
\q1
\v 19 Nígbà náà ni inú rẹ yóò dùn sí ẹbọ òdodo,
\q2 pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ọrẹ ẹbọ sísun,
\q2 nígbà náà ni wọn yóò fi akọ màlúù rú ẹbọ lórí pẹpẹ rẹ.
\c 52
\cl Saamu 52
\d Fún adarí orin. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí Doegi ará Edomu tọ Saulu lọ láti sọ fún pé, “Dafidi wà ní ilé Ahimeleki.”
\q1
\v 1 Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe féfé nínú ìwà ìkà, ìwọ alágbára ọkùnrin?
\q2 Èéṣe tí ìwọ fi ń gbéraga nígbà gbogbo,
\q2 ìwọ ẹni ẹ̀gàn níwájú Ọlọ́run?
\q1
\v 2 Ahọ́n rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun;
\q2 ó dàbí abẹ mímú,
\q2 ìwọ ẹni tí ń hùwà ẹ̀tàn.
\q1
\v 3 Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ìre lọ,
\q2 àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ.
\q1
\v 4 Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo,
\q2 ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!
\b
\q1
\v 5 Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé,
\q2 yóò sì dì ọ́ mú,
\q1 yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó rẹ,
\q2 yóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. \qs Sela.\qs*
\q1
\v 6 Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rù
\q2 wọn yóò sì rẹ́rìn-ín rẹ̀, wí pé,
\q1
\v 7 “Èyí ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára rẹ̀,
\q2 bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé,
\q2 ó sì mu ara rẹ̀ le nínú ìwà búburú rẹ̀.”
\b
\q1
\v 8 Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi Olifi
\q2 tí ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run;
\q1 èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnà
\q2 láé àti láéláé.
\q1
\v 9 Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe;
\q2 èmi ní ìrètí nínú orúkọ rẹ,
\q1 nítorí orúkọ rẹ dára.
\q2 Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́.
\c 53
\cl Saamu 53
\d Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí mahalati. Maskili ti Dafidi.
\q1
\v 1 \x - \xo 53.1-3: \xt Ro 3.10-12.\x*\x - \xo 53.1-6: \xt Sm 14.1-7.\x*Aṣiwèrè wí ní ọkàn rẹ̀ pé,
\q2 “Ọlọ́run kò sí.”
\q1 Wọ́n bàjẹ́, gbogbo ọ̀nà wọn sì burú;
\q2 kò sì ṣí ẹnìkan tí ń ṣe rere.
\b
\q1
\v 2 Ọlọ́run bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run
\q2 sórí àwọn ọmọ ènìyàn,
\q1 láti wò bóyá ẹnìkan wà, tí ó ní òye,
\q2 tí ó sì ń wá Ọlọ́run.
\q1
\v 3 Gbogbo ènìyàn tí ó ti yí padà,
\q2 wọ́n ti parapọ̀ di ìbàjẹ́;
\q1 kò sí ẹnìkan tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan.
\b
\q1
\v 4 Ṣé àwọn oníṣẹ́ búburú kò ní ìmọ̀?
\b
\q2 Àwọn ẹni tí ń jẹ ènìyàn mi, bí ẹni jẹun
\q2 tí wọn kò sì pe Ọlọ́run?
\q1
\v 5 Níbẹ̀ ni ìwọ gbé wà ní ìbẹ̀rù ńlá
\q2 níbi tí ẹ̀rù kò gbé sí,
\q1 nítorí Ọlọ́run tí fọ́n egungun àwọn tí ó dó tì ọ́ ká;
\q2 ìwọ tí dójútì wọ́n, nítorí Ọlọ́run ti kẹ́gàn wọn.
\b
\q1
\v 6 Ìgbàlà Israẹli ìbá jáde wá láti Sioni!
\q2 Nígbà tí Ọlọ́run bá mú ohun ìní àwọn ènìyàn rẹ̀ padà,
\q2 jẹ́ kí Jakọbu yọ̀ kí inú Israẹli sì máa dùn!
\c 54
\cl Saamu 54
\d Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí àwọn ará Sifi lọ sọ fún Saulu pé, “Dafidi sá pamọ́ sọ́dọ̀ wa?”
\q1
\v 1 Gbà mí, Ọlọ́run nípa orúkọ rẹ:
\q2 dá mi láre nípa agbára rẹ.
\q1
\v 2 Gbọ́ àdúrà mi, Ọlọ́run;
\q2 fi etí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
\b
\q1
\v 3 Àwọn agbéraga àlejò dìde sí mí.
\q2 Àwọn aninilára sì ń wá mi láti pa,
\q1 àwọn ẹni tí kò ka Ọlọ́run sí ní ojú wọn.
\b
\q1
\v 4 Kíyèsi i Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́ mi;
\q2 Olúwa ní ẹni tí ó mú mi dúró,
\q2 pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ.
\b
\q1
\v 5 Jẹ́ kí ibi padà sẹ́yìn sí àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi;
\q2 pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ.
\b
\q1
\v 6 Èmí yóò rú ẹbọ àtinúwá sí ọ,
\q2 èmi yóò yin orúkọ rẹ, \nd Olúwa\nd*,
\q2 nítorí tí ó dára.
\q1
\v 7 Nítorí tí ó yọ mí kúrò nínú ibi gbogbo
\q2 ojú mi ti wo ìṣẹ́gun lórí ọ̀tá mi.
\c 55
\cl Saamu 55
\d Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi.
\q1
\v 1 Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run,
\q2 má ṣe fi ojú pa ẹ̀bẹ̀ mi rẹ́:
\q2
\v 2 gbọ́ mi kí o sì dá mi lóhùn.
\q1 Èrò mi ń dà mí láàmú, èmi sì ń pariwo.
\q2
\v 3 Sí ohùn àwọn ọ̀tá ni,
\q2 nítorí igbe àwọn ènìyàn búburú;
\q1 nítorí wọ́n mú ìjìyà wá sórí mi,
\q2 wọ́n sì kẹ́gàn mi nínú ìbínú wọn.
\b
\q1
\v 4 Ọkàn mi wà nínú ìrora pẹ̀lú;
\q2 ẹ̀rù ikú kọjú ìjà sí mi.
\q1
\v 5 Ìbẹ̀rù àti ìwárìrì wa sí ara mi;
\q2 ìbẹ̀rù ti bò mí mọ́lẹ̀.
\q1
\v 6 Èmi sọ pé, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà!
\q2 Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi.
\q1
\v 7 Èmi ìbá sálọ, jìnnà réré,
\q2 kí ń sì dúró sí aginjù;
\q1
\v 8 èmi ìbá yára lọ́ si ibùgbé mi ní ibi ààbò,
\q2 jìnnà kúrò nínú ìjì àti ẹ̀fúùfù líle.”
\b
\q1
\v 9 Da àwọn ẹni búburú láàmú, \nd Olúwa\nd*, da ahọ́n wọn rú,
\q2 nítorí èmi rí ìwà agbára àti ìjà ní ìlú náà.
\q1
\v 10 Ọ̀sán àti òru ni wọ́n fi ń rìn gbogbo odi kiri;
\q2 ìwà ìkà àti èébú wà láàrín rẹ̀.
\q1
\v 11 Ìwà búburú ń bẹ ní àárín rẹ̀;
\q2 ẹ̀tàn àti èké kò kúrò ní ìgboro rẹ̀.
\b
\q1
\v 12 Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi,
\q2 èmi yóò fi ara mọ́ ọn;
\q1 tí ọ̀tá bá gbé ara rẹ̀ ga sí mi,
\q2 èmi ìbá sá pamọ́ fún un.
\q1
\v 13 Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi,
\q2 ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó súnmọ́ mi,
\q1
\v 14 pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádùn adùn ìdàpọ̀,
\q2 bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwùjọ ní ilé Ọlọ́run.
\b
\q1
\v 15 Kí ikú kí ó dé bá wọn,
\q2 kí wọn ó lọ láààyè sí isà òkú,
\q1 jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà,
\q2 nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn.
\b
\q1
\v 16 Ṣùgbọ́n èmi pe Ọlọ́run;
\q2 \nd Olúwa\nd* yóò sì gbà mí.
\q1
\v 17 Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sán
\q2 èmi sọkún jáde nínú ìpọ́njú,
\q2 o sì gbọ́ ohùn mi.
\q1
\v 18 Ó rà mí padà láìléwu
\q2 kúrò nínú ogun tí ó dìde sí mi,
\q2 nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó dìde sí mi.
\q1
\v 19 Ọlọ́run yóò gbọ́, yóò sì pọ́n wọn lójú àní,
\q2 ẹni tí ó ti jókòó láti ìgbàanì \qs Sela,\qs*
\q1 nítorí tí wọn kò ní àyípadà,
\q2 tí wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run.
\b
\q1
\v 20 Ọ̀rẹ́ mi yìí ti dalẹ̀ èmi ọ̀rẹ́ rẹ̀;
\q2 ó ti ba májẹ̀mú rẹ̀ jẹ́.
\q1
\v 21 Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kúnná ju òrí-àmọ́,
\q2 ṣùgbọ́n ogun wà ni àyà rẹ̀;
\q1 ọ̀rọ̀ rẹ̀ fẹ́lẹ́ ju òróró lọ,
\q2 ṣùgbọ́n idà fífàyọ ní wọn.
\b
\q1
\v 22 \x - \xo 55.22: \xt 1Pt 5.7.\x*Gbé ẹrù rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ \nd Olúwa\nd*
\q2 yóò sì mú ọ dúró;
\q1 òun kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú.
\q1
\v 23 Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni yóò mu àwọn ọ̀tá mi
\q2 wá sí ihò ìparun;
\q1 àwọn ẹni tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ àti ẹni ẹ̀tàn,
\q2 kì yóò gbé ààbọ̀ ọjọ́ wọn.
\b
\q1 Ṣùgbọ́n fún èmi, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ.
\c 56
\cl Saamu 56
\d Fún adarí orin. Ti ohùn “Àdàbà lórí Óákù òkè réré.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí àwọn ará Filistini ka mọ́ ní Gati.
\q1
\v 1 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run,
\q2 nítorí àwọn ènìyàn ń fi ìgbónára lépa mi;
\q2 ní gbogbo ọjọ́ ni wọn ń kọjú ìjà sí mi, wọn ń ni mi lára.
\q1
\v 2 Àwọn ọ̀tá mi ń lé mi ní gbogbo ọjọ́,
\q2 àwọn ènìyàn ń kọjú ìjà sí mi nínú ìgbéraga wọn.
\b
\q1
\v 3 Nígbà tí ẹ̀rù bà ń bà mí,
\q2 èmi o gbẹ́kẹ̀lé ọ.
\q1
\v 4 Nínú Ọlọ́run èmi yóò máa yìn ọ̀rọ̀ rẹ,
\q2 nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi; ẹ̀rù kì yóò bà mí
\q1 kí ni ẹran-ara lè ṣe sí mi?
\b
\q1
\v 5 Wọn ń yí ọ̀rọ̀ mí ní gbogbo ọjọ́,
\q2 wọn ń gbèrò nígbà gbogbo láti ṣe mí níbi.
\q1
\v 6 Wọn kó ara wọn jọ, wọ́n ba.
\q2 Wọ́n ń ṣọ́ ìgbésẹ̀ mi
\q1 wọn ń làkàkà láti gba ẹ̀mí mi.
\q1
\v 7 San ẹ̀san iṣẹ́ búburú wọ́n fún wọn;
\q2 ní ìbínú rẹ, Ọlọ́run, wọ́ àwọn ènìyàn náà bọ́ sílẹ̀.
\b
\q1
\v 8 Kọ ẹkún mi sílẹ̀;
\q2 kó omijé mi sí ìgò rẹ,
\q1 wọ́n kò ha sí nínú ìkọ̀sílẹ̀ rẹ bí?
\q1
\v 9 Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóò pẹ̀yìndà
\q2 nígbà tí mo bá pè fún ìrànlọ́wọ́
\q2 nípa èyí ni mo mọ̀ pé Ọlọ́run ń bẹ fún mi.
\b
\q1
\v 10 Nínú Ọlọ́run, ẹni tí mo yìn ọ̀rọ̀ rẹ̀
\q2 nínú \nd Olúwa\nd*, ẹni tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,
\q1
\v 11 nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi:
\q2 ẹ̀rù kì yóò bà mí.
\q1 Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?
\b
\q1
\v 12 Mo jẹ́ ẹ̀jẹ́ lábẹ́ rẹ Ọlọ́run:
\q2 èmi o mú ìyìn mi wá fún ọ.
\q1
\v 13 Nítorí ìwọ tí gbà mí lọ́wọ́ ikú
\q2 àti ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú,
\q1 kí èmí lè máa rìn níwájú Ọlọ́run
\q2 ní ìmọ́lẹ̀ àwọn alààyè.
\c 57
\cl Saamu 57
\d Fún adarí orin. Ní ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí ó sá níwájú Saulu lọ sínú ihò òkúta.
\q1
\v 1 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi,
\q2 nítorí nínú rẹ ni ààbò ọkàn mí wà.
\q1 Èmi o fi ààbò mí sí ibi ìyẹ́ apá rẹ
\q2 títí tí ewu yóò fi kọjá lọ.
\b
\q1
\v 2 Mo kígbe sókè sí Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ,
\q2 sí Ọlọ́run tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ fún mi.
\q1
\v 3 Òun yóò ránṣẹ́ láti ọ̀run wá,
\q2 yóò sì gbà mí, bí ẹni tí ń fẹ́ gbé mi mì
\q1 tilẹ̀ ń kẹ́gàn mi.
\q2 Ọlọ́run yóò rán àánú rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ jáde.
\b
\q1
\v 4 Mo wà ní àárín àwọn kìnnìún;
\q2 mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburú,
\q1 àwọn ènìyàn tí eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfà
\q2 ẹni tí ahọ́n rẹ̀ jẹ́ idà mímú.
\b
\q1
\v 5 Kí a yìn ọ́ Ọlọ́run, ju ọ̀run lọ,
\q2 kí ògo rẹ kò ju ti gbogbo ayé lọ.
\b
\q1
\v 6 Wọ́n ti ta àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ mi:
\q2 a tẹ orí ọkàn mi ba nínú ìtìjú,
\q1 wọ́n gbẹ́ kòtò sí ọ̀nà mi:
\q1 ṣùgbọ́n wọ́n ti jì síbẹ̀ fún ara wọn.
\b
\q1
\v 7 \x - \xo 57.7-11: \xt Sm 108.1-5.\x*Ọkàn mi ti múra Ọlọ́run;
\q2 ọkàn mi ti múra, èmi ó kọrin, èmi ó si máa kọrin ìyìn.
\q1
\v 8 Jí, ìwọ ọkàn mi!
\q2 Jí, ohun orin èlò àti dùùrù!
\q2 Èmi tìkára mi, yóò sì jí ní kùtùkùtù.
\b
\q1
\v 9 Èmi ó máa yìn ọ́, \nd Olúwa\nd*, láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
\q2 èmi ó máa kọrin sí ọ láàrín àwọn ènìyàn.
\q1
\v 10 Nítorí títóbi ní ìfẹ́ rẹ, tí ó dé ọ̀run;
\q2 òtítọ́ rẹ tàn dé àwọsánmọ̀.
\b
\q1
\v 11 Gbígbéga ni ọ́, Ọlọ́run, ju àwọn ọ̀run lọ;
\q2 kí ògo rẹ kí ó ju gbogbo ayé lọ.
\c 58
\cl Saamu 58
\d Fún adarí orin. Tí ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu.
\q1
\v 1 Ẹ̀yin ha ń sọ òdodo nítòótọ́
\q2 ẹ̀yin ìjọ ènìyàn?
\q1 Ǹjẹ́ ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ tí ó ṣe títọ́
\q2 ẹ̀yìn ọmọ ènìyàn?
\q1
\v 2 Bẹ́ẹ̀ kọ́, nínú ọkàn yín ẹ̀yìn ń gbèrò àìṣòdodo,
\q2 ọwọ́ yín sì tú ìwà ipá jáde ni ayé.
\b
\q1
\v 3 Ní inú ìyá wọn wá ni ènìyàn búburú tí ṣìnà,
\q2 lójúkan náà tí a ti bí wọn, wọn a máa ṣèké.
\q1
\v 4 Oró wọn dàbí oró ejò,
\q2 wọn dàbí adití ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di ara rẹ̀ ni etí,
\q1
\v 5 tí kò ní gbọ́ ìpè àwọn atunilójú,
\q2 bí ó ti wù kí ó máa fi ọgbọ́n ṣe ìtujú tó.
\b
\q1
\v 6 Ká eyín ẹnu wọn, Ọlọ́run;
\q2 ní ẹnu wọn,
\q1 ká ọ̀gàn àwọn ọmọ kìnnìún, \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 7 Jẹ́ kí wọn parẹ́ bí omi tó ń sàn lọ;
\q2 nígbà tí ó bá fa ọfà rẹ̀, kí ọ̀kọ̀ wọn kí ó ṣẹ́.
\q1
\v 8 Jẹ́ kí wọn rí bí ìgbín tí rẹ̀ dànù tí ó sì ṣègbé
\q2 bí ọmọ tí oṣù rẹ̀ kò pé, kí wọn má ṣe rí oòrùn.
\b
\q1
\v 9 Kí ìkòkò yín kí ó tó mọ ìgbóná ẹ̀gún;
\q2 bóyá ní tútù tàbí ní gbígbẹ, yóò fi ìjì gbá wọn lọ.
\q1
\v 10 Olódodo yóò yọ̀ nígbà a bá ń gbẹ̀san wọn,
\q2 nígbà tí wọn bá wẹ ẹsẹ̀ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn búburú.
\q1
\v 11 Àwọn ènìyàn yóò wí pé,
\q2 “Lóòtítọ́ èrè àwọn ń bẹ fún olódodo;
\q2 lóòtítọ́ òun ni Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ ní ayé.”
\c 59
\cl Saamu 59
\d Fún adarí orin. Tí ohùn orin “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí Saulu rán àwọn olùṣọ́ sí ilé Dafidi kí òun bá le rí i pa.
\q1
\v 1 Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi, Ọlọ́run;
\q2 dáàbò bò mí kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó dìde sí mi.
\q1
\v 2 Gbà mí lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ búburú
\q2 kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ń pòǹgbẹ ẹ̀jẹ̀.
\b
\q1
\v 3 Wò ó, bí wọ́n ṣe ba ní bùba dè mí!
\q2 Àwọn alágbára ń gbìmọ̀ lòdì sí mi
\q1 kì í ṣe nítorí ìrékọjá mi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ mí, \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 4 Èmi kò ṣe àìṣedéédéé kan, síbẹ̀ wọ́n sáré wọ́n ṣetán láti kọlù mí.
\q2 Dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi, kí o sì wo àìlera mi.
\q1
\v 5 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run Alágbára,
\q2 Ọlọ́run Israẹli,
\q1 dìde fún ara rẹ kí o sì bá àwọn orílẹ̀-èdè wí;
\q2 má ṣe ṣàánú fún àwọn olùrékọjá búburú nì. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 6 Wọ́n padà ní àṣálẹ́,
\q2 wọ́n ń gbó bí àwọn ajá,
\q2 wọ́n ń rìn yí ìlú náà káàkiri.
\q1
\v 7 Kíyèsi ohun tí wọ́n tú jáde ní ẹnu:
\q2 wọn ń tú idà jáde láti ètè wọn,
\q2 wọ́n sì wí pé, “Ta ni ó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ wa?”
\q1
\v 8 Ṣùgbọ́n ìwọ, \nd Olúwa\nd*, yóò fi wọ́n rẹ́rìn-ín,
\q2 Ìwọ ó yọ ṣùtì sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.
\b
\q1
\v 9 Ìwọ agbára mi, èmi ó máa kọrin ìyìn sí ọ;
\q2 nítorí ìwọ Ọlọ́run ni ààbò mi,
\q2
\v 10 Ọlọ́run àánú mi ni yóò ṣáájú mi.
\b
\q1 Ọlọ́run yóò sì jẹ́ kí èmi rí ìfẹ́ mi lára àwọn ọ̀tá mi.
\q2 Yóò sì jẹ́ kí n yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi.
\q1
\v 11 Ṣùgbọ́n má ṣe pa wọ́n, Olúwa asà wa,
\q2 kí àwọn ènìyàn mi má ba à gbàgbé.
\q1 Nínú agbára rẹ, jẹ́ kí wọn máa rìn kiri,
\q2 kí o sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.
\q1
\v 12 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnu wọn,
\q2 ní ọ̀rọ̀ ètè wọn,
\q2 kí a mú wọn nínú ìgbéraga wọn.
\q1 Nítorí èébú àti èké tí wọn ń sọ,
\q2
\v 13 pa wọ́n run nínú ìbínú,
\q2 run wọ́n di ìgbà tí wọn kò ní sí mọ́.
\q1 Nígbà náà ni yóò di mí mọ̀ dé òpin ayé
\q2 pé Ọlọ́run jẹ ọba lórí Jakọbu. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 14 Wọ́n padà ní àṣálẹ́,
\q2 wọn ń gbó bí àwọn ajá
\q2 wọ́n ń rin ìlú náà káàkiri.
\q1
\v 15 Wọ́n ń rin kiri fún oúnjẹ
\q2 wọ́n sì ń yán nígbà tí wọn kò yó.
\q1
\v 16 Ṣùgbọ́n èmi ó kọrin agbára rẹ,
\q2 n ó kọrin ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀;
\q1 nítorí ìwọ ni ààbò mi,
\q2 ibi ìsádi mi ní ìgbà ìpọ́njú.
\b
\q1
\v 17 Ìwọ agbára mi, èmi ó kọrin ìyìn sí ọ;
\q2 ìwọ, Ọlọ́run, ààbò mi, Ọlọ́run ìfẹ́ mi.
\c 60
\cl Saamu 60
\d Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì ti Májẹ̀mú.” Miktamu ti Dafidi. Fún ìkọ́ni. Nígbà tí ó bá Aramu-Naharaimu àti Siria-Soba jà, àti nígbà tí Joabu yípadà tí ó sì pa ẹgbẹ̀rún méjìlá àwọn ará Edomu ní àfonífojì Iyọ̀.
\q1
\v 1 Ìwọ ti kọ̀ wá sílẹ̀,
\q2 Ọlọ́run, ìwọ ti tú wa ká,
\q1 ìwọ ti bínú nísinsin yìí, tún ara rẹ yípadà sí wa.
\q1
\v 2 Ìwọ ti mú ilẹ̀ wárìrì, ìwọ ti fọ́ ọ;
\q2 mú fífọ́ rẹ̀ bọ̀ sípò, nítorí tí ó mì.
\q1
\v 3 Ìwọ ti fi ìgbà ewu han àwọn ènìyàn rẹ;
\q2 ìwọ fún wa ní wáìnì tí ó máa ń ta wá gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n.
\q1
\v 4 Àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, ní ìwọ fi ọ̀págun fún
\q2 kí a lè fihàn nítorí òtítọ́. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 5 \x - \xo 60.5-12: \xt Sm 108.6-13.\x*Fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbà wá, kí o sì ràn wá lọ́wọ́,
\q2 kí a lè gba àwọn tí o fẹ́ là.
\q1
\v 6 Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀:
\q2 “Ní ayọ̀, èmi ó pọ Ṣekemu jáde
\q2 èmi ó sì wọ́n àfonífojì Sukkoti.
\q1
\v 7 Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase;
\q2 Efraimu ni àṣíborí mi,
\q2 Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.
\q1
\v 8 Moabu ní ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,
\q2 lórí Edomu ní mo bọ́ bàtà mi sí;
\q2 lórí Filistia ni mo kígbe ayọ̀.”
\b
\q1
\v 9 Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi nì?
\q2 Ta ni yóò tọ́ mí lọ sí Edomu?
\q1
\v 10 Kì í ha ń ṣe ìwọ, Ọlọ́run, tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀
\q2 tí o kò sì bá ogun wa jáde mọ́?
\q1
\v 11 Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀tá,
\q2 nítorí asán ni ìrànlọ́wọ́ ènìyàn.
\q1
\v 12 Nípa Ọlọ́run ni a óò ní ìṣẹ́gun,
\q2 yóò sì tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.
\c 61
\cl Saamu 61
\d Fún adarí orin. Ohun èlò orin olókùn. Ti Dafidi.
\q1
\v 1 Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run;
\q2 tẹ́tí sí àdúrà mi.
\b
\q1
\v 2 Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́,
\q2 mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀;
\q2 mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.
\q1
\v 3 Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi,
\q2 ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá.
\b
\q1
\v 4 Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé
\q2 kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ.
\q1
\v 5 Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run;
\q2 Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.
\b
\q1
\v 6 Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn,
\q2 ọdún rẹ̀ fún ìrandíran.
\q1
\v 7 Kí ó máa jẹ ọba níwájú Ọlọ́run títí láé;
\q2 pèsè àánú àti òtítọ́ rẹ tí yóò máa ṣe ìtọ́jú rẹ.
\b
\q1
\v 8 Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ títí láé
\q2 kí n san ẹ̀jẹ́ mi ní ojoojúmọ́.
\c 62
\cl Saamu 62
\d Fún adarí orin. Fun Jedutuni. Saamu Dafidi.
\q1
\v 1 Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi;
\q2 ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá.
\q1
\v 2 Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi;
\q2 Òun ni ààbò mi, a kì yóò sí mi ní ipò padà.
\b
\q1
\v 3 Ẹ̀yin ó ti máa kọ́lú ènìyàn kan pẹ́ tó?
\q2 Gbogbo yín ni ó fẹ́ pa á,
\q2 bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀, àti bí ọgbà tí ń wó lọ?
\q1
\v 4 Kìkì èrò wọn ni láti bì ṣubú
\q2 kúrò nínú ọlá rẹ̀;
\q2 inú wọn dùn sí irọ́.
\q1 Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre,
\q2 ṣùgbọ́n wọ́n ń gégùn ún nínú ọkàn wọn. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 5 Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmi wà, ìwọ Ọlọ́run mi.
\q2 Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.
\q1
\v 6 Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi;
\q2 Òun ni ààbò mi, a kì yóò ṣí mi ní ipò.
\q1
\v 7 Ìgbàlà mi àti ògo mi dúró nínú Ọlọ́run;
\q2 Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi.
\q1
\v 8 Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn;
\q2 tú ọkàn rẹ jáde sí i,
\q1 nítorí Ọlọ́run ni ààbò wa.
\b
\q1
\v 9 Nítòótọ́, asán ni àwọn ọmọ ènìyàn,
\q2 èké sì ni àwọn olóyè,
\q1 wọ́n gòkè nínú ìwọ̀n,
\q2 lápapọ̀ wọ́n jẹ́ èémí.
\q1
\v 10 Má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ìnilára,
\q2 tàbí gbéraga nínú olè jíjà,
\q1 nítòótọ́ bí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i,
\q2 má ṣe gbẹ́kẹ̀ rẹ lé wọn.
\b
\q1
\v 11 Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì,
\q2 ni mo gbọ́ èyí pé,
\q1 “Ti Ọlọ́run ni agbára,
\q2
\v 12 \x - \xo 62.12: \xt Jr 17.10; If 2.23; 22.12.\x*pẹ̀lúpẹ̀lú, \nd Olúwa\nd*, tìrẹ ni àánú;
\q2 nítorí tí ìwọ san án fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.”
\c 63
\cl Saamu 63
\d Saamu ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú aginjù Juda.
\q1
\v 1 Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi,
\q2 nígbà gbogbo ni mo ń ṣàfẹ́rí rẹ,
\q1 òǹgbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi,
\q2 ara mi fà sí ọ,
\q1 ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tí ń ṣàárẹ̀
\q2 níbi tí kò sí omi.
\b
\q1
\v 2 Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́,
\q2 mo rí agbára àti ògo rẹ.
\q1
\v 3 Nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ayé lọ,
\q2 ètè mi yóò fògo fún ọ.
\q1
\v 4 Èmi ó yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè,
\q2 èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ rẹ.
\q1
\v 5 A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ;
\q2 pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ́.
\b
\q1
\v 6 Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi;
\q2 èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru.
\q1
\v 7 Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi,
\q2 mo kọrin níbi òjìji ìyẹ́ apá rẹ.
\q1
\v 8 Ọkàn mí fà sí ọ:
\q2 ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbé mi ró.
\b
\q1
\v 9 Àwọn tí ó ń wá ọkàn mí ni a ó parun;
\q2 wọn ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé.
\q1
\v 10 Wọn ó ti ọwọ́ idà ṣubú
\q2 wọn ó sì di jíjẹ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀.
\b
\q1
\v 11 Ṣùgbọ́n ọba yóò yọ̀ nínú Ọlọ́run
\q2 ẹni tí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra yóò ṣògo
\q2 ṣùgbọ́n ẹnu àwọn òpùrọ́ la ó pamọ́.
\c 64
\cl Saamu 64
\d Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
\q1
\v 1 Gbóhùn mi, Ọlọ́run, bí mo ti ń sọ àròyé mi
\q2 pa ọkàn mi mọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀rù àwọn ọ̀tá.
\b
\q1
\v 2 Pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn búburú
\q2 kúrò nínú ọ̀pọ̀ igbe lọ́wọ́ ìrúkèrúdò oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
\q1
\v 3 Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà,
\q2 wọ́n sì fa ọrun wọn le láti tafà wọn, àní ọ̀rọ̀ kíkorò.
\q1
\v 4 Wọ́n tafà ní ìkọ̀kọ̀ sí àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀:
\q2 wọ́n tafà si lójijì, wọn kò sì bẹ̀rù.
\b
\q1
\v 5 Wọ́n, gba ara wọn níyànjú nínú èrò búburú,
\q2 wọ́n sọ̀rọ̀ lórí dídẹkùn sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀
\q2 wọ́n wí pé, “Ta ni yóò rí wa?”
\q1
\v 6 Wọ́n gbìmọ̀ àìṣòdodo, wọ́n wí pé,
\q2 “A wa ti parí èrò tí a gbà tán!”
\q2 Lóòótọ́ àyà àti ọkàn ènìyàn kún fún àrékérekè.
\b
\q1
\v 7 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ta wọ́n ní ọfà;
\q2 wọn ó sì gbọgbẹ́ lójijì.
\q1
\v 8 Ahọ́n wọn yóò sì dojú ìjà kọ wọ́n, yóò sì run wọ́n,
\q2 gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn yóò sì mi orí fún wọn.
\q1
\v 9 Gbogbo ènìyàn yóò máa bẹ̀rù
\q2 wọn ó kéde iṣẹ́ Ọlọ́run
\q2 wọn ó dúró lé ohun tí ó ṣe.
\b
\q1
\v 10 Jẹ́ kí olódodo kí ó yọ̀ nínú \nd Olúwa\nd*
\q2 yóò sì rí ààbò nínú rẹ̀.
\q2 Gbogbo ẹni ìdúró ṣinṣin ní ọkàn yóò máa yìn ín.
\c 65
\cl Saamu 65
\d Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Orin.
\q1
\v 1 Ìyìn ń dúró dè ọ́, Ọlọ́run, ní Sioni;
\q2 sí ọ ni a ó mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.
\q1
\v 2 Ìwọ tí ó ń gbọ́ àdúrà,
\q2 gbogbo ènìyàn yóò sì wá sọ́dọ̀ rẹ.
\q1
\v 3 Ọ̀ràn àìṣedéédéé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni!
\q2 Ìwọ ni yóò wẹ̀ wọ́n nù kúrò.
\q1
\v 4 Ìbùkún ni fún àwọn tí o yàn
\q2 tí o mú wa láti máa gbé àgọ́ rẹ!
\q1 A tẹ́ wá lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere inú ilé rẹ,
\q2 ti tẹmpili mímọ́ rẹ.
\b
\q1
\v 5 Ìwọ dá wa lóhùn pẹ̀lú ohun ìyanu ti òdodo,
\q2 Ọlọ́run olùgbàlà wa,
\q1 ẹni tí ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé gbogbo òpin ayé
\q2 àti àwọn tí ó jìnnà nínú òkun,
\q1
\v 6 ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára rẹ,
\q2 tí odi ara rẹ ní àmùrè agbára,
\q1
\v 7 ẹni tí ó mú rírú omi òkun dákẹ́,
\q2 ríru ariwo omi wọn,
\q2 àti ìdágìrì àwọn ènìyàn.
\q1
\v 8 Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù,
\q2 nítorí àmì rẹ wọ̀n-ọn-nì;
\q2 ìwọ mú ìjáde òwúrọ̀ àti ti àṣálẹ́ yọ̀,
\q2 ìwọ pè fún orin ayọ̀.
\b
\q1
\v 9 Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin;
\q2 ìwọ mú un ọ̀rọ̀ púpọ̀.
\q1 Odò Ọlọ́run kún fún omi
\q2 láti pèsè ọkà fún àwọn ènìyàn,
\q1 nítorí ibẹ̀ ni ìwọ ti yàn án.
\q1
\v 10 Ìwọ fi bomirin sí aporo rẹ̀
\q2 ìwọ tẹ́ ògúlùtu rẹ̀;
\q1 ìwọ fi òjò mú ilẹ̀ rẹ̀ rọ̀,
\q2 o sì bùkún ọ̀gbìn rẹ̀.
\q1
\v 11 Ìwọ fi oore rẹ dé ọdún ní adé,
\q2 ọ̀rá ń kán ní ipa ọ̀nà rẹ.
\q1
\v 12 Pápá tútù ní aginjù ń kan
\q2 àwọn òkè kéékèèké fi ayọ̀ di ara wọn ní àmùrè.
\q1
\v 13 Agbo ẹran ni a fi wọ pápá tútù náà ní aṣọ;
\q2 àfonífojì ni a fi ọkà bò mọ́lẹ̀,
\q2 wọ́n hó fún ayọ̀, wọ́n ń kọrin pẹ̀lú.
\c 66
\cl Saamu 66
\d Fún adarí orin. Orin. Saamu.
\q1
\v 1 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ilẹ̀ gbogbo!
\q2
\v 2 Ẹ kọrin ọlá orúkọ rẹ̀;
\q2 ẹ kọrin ìyìnsí i.
\q1
\v 3 Ẹ wí fún Ọlọ́run pé, “Ìwọ ti ní ẹ̀rù tó nínú iṣẹ́ rẹ!
\q2 Nípa ọ̀pọ̀ agbára rẹ
\q2 ni àwọn ọ̀tá rẹ yóò fi sìn ọ́.
\q1
\v 4 Gbogbo ayé ń wólẹ̀ fún ọ;
\q2 wọn ń kọrin ìyìn sí ọ,
\q2 wọ́n ń kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ.” \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 5 Ẹ wá wo ohun tí Ọlọ́run ṣe,
\q2 iṣẹ́ rẹ̀ ti ní ẹ̀rù tó sí àwọn ọmọ ènìyàn!
\q1
\v 6 Ó yí òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ,
\q2 wọ́n fi ẹsẹ̀ rin inú omi kọjá,
\q2 níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú rẹ̀.
\q1
\v 7 Ó ń jẹ ọba títí láé nípa agbára rẹ̀,
\q2 ojú rẹ̀ ń wo orílẹ̀-èdè
\q2 kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má ṣe gbé ara wọn ga. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 8 Ẹ yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn,
\q2 jẹ́ kí a mú ni gbọ́ ohùn ìyìn rẹ̀;
\q1
\v 9 Ó ti dá ààbò bo ẹ̀mí wa,
\q2 kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa kí ó yẹ̀.
\q1
\v 10 Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, dán wa wò;
\q2 ìwọ dán wa bí a tí ń dán fàdákà wò.
\q1
\v 11 Ìwọ mú wa wá sínú ẹ̀wọ̀n
\q2 o sì di ẹrù lé ẹ̀yìn wa.
\q1
\v 12 Ìwọ mú àwọn ènìyàn gún wá ní orí
\q2 àwa la iná àti omi kọjá
\q2 ṣùgbọ́n ìwọ mú wa dé ibi ọ̀pọ̀.
\b
\q1
\v 13 Èmi ó wá sí tẹmpili rẹ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun,
\q2 kí n sì mú ẹ̀jẹ́ mi ṣẹ sí ọ,
\q1
\v 14 ẹ̀jẹ́ tí ètè mi jẹ́, tí ẹnu mi sì sọ
\q2 nígbà tí mo wà nínú ìṣòro.
\q1
\v 15 Èmi ó rú ẹbọ sísun ọlọ́ràá sí ọ,
\q2 àti ẹbọ ọ̀rá àgbò;
\q2 èmi ó rú akọ màlúù àti ewúrẹ́. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 16 Ẹ wá gbọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run;
\q2 ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí ó ṣe fún mi.
\q1
\v 17 Mo fi ẹnu mi kígbe sókè sí i,
\q2 ìyìn rẹ̀ wà ní ẹnu mi.
\q1
\v 18 Bí èmi bá gba ẹ̀ṣẹ̀ ní àyà mi,
\q2 Olúwa kì yóò gbọ́ ohùn mi;
\q1
\v 19 ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbọ́ nítòótọ́
\q2 ó ti gbọ́ ohùn mi nínú àdúrà.
\q1
\v 20 Ìyìn ni fún Ọlọ́run
\q2 ẹni tí kò kọ àdúrà mi
\q2 tàbí mú ìfẹ́ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi!
\c 67
\cl Saamu 67
\d Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu. Orin.
\q1
\v 1 Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa kí ó sì bùkún fún wa,
\q2 kí ó sì jẹ́ kí ojú rẹ̀ tàn yí wa ká,
\q1
\v 2 kí ọ̀nà rẹ le di mí mọ̀ ní ayé,
\q2 ìgbàlà rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.
\b
\q1
\v 3 Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;
\q2 kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́!
\q1
\v 4 Kí orílẹ̀-èdè kí ó yọ̀, kí ó sì kọrin fún ayọ̀,
\q2 nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyàn,
\q2 ìwọ sì jẹ ọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé.
\q1
\v 5 Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;
\q2 kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 6 Nígbà náà ní ilẹ̀ yóò mú ìkórè rẹ̀ wá, Ọlọ́run,
\q2 Ọlọ́run wa, yóò bùkún fún wa.
\q1
\v 7 Ọlọ́run yóò bùkún fún wa,
\q2 àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù rẹ̀.
\c 68
\cl Saamu 68
\d Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Orin.
\q1
\v 1 Kí Ọlọ́run kí ó dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó fọ́nká;
\q2 kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó sá níwájú rẹ̀.
\q1
\v 2 Bí ìjì ti ń fẹ́ èéfín lọ,
\q2 kí ó fẹ́ wọn lọ;
\q1 bí ìda ti í yọ́ níwájú iná,
\q2 kí olùṣe búburú ṣègbé níwájú Ọlọ́run.
\q1
\v 3 Ṣùgbọ́n kí inú olódodo kí ó dùn
\q2 kí ó sì kún fún ayọ̀ níwájú Ọlọ́run;
\q2 kí inú wọn kí ó dùn, kí ó sì kún fún ayọ̀.
\b
\q1
\v 4 Ẹ kọrin sí Ọlọ́run,
\q2 ẹ kọrin ìyìn sí i,
\q1 ẹ la ọ̀nà fún ẹni tí ń rékọjá ní aginjù.
\q2 \nd Olúwa\nd* ni orúkọ rẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀.
\q1
\v 5 Baba àwọn aláìní baba àti onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ní ibùgbé
\q2 rẹ̀ mímọ́
\q1
\v 6 Ọlọ́run gbé aláìlera
\q2 kalẹ̀ nínú ìdílé,
\q1 ó darí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú orin,
\q2 ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ní ń gbé nínú ilẹ̀ gbígbẹ.
\b
\q1
\v 7 Nígbà tí ìwọ bá jáde lónìí níwájú àwọn ènìyàn rẹ, Ọlọ́run,
\q2 tí ń kọjá lọ láàrín aginjù, \qs Sela.\qs*
\q1
\v 8 Ilẹ̀ mì títí,
\q2 àwọn ọ̀run ń rọ òjò jáde,
\q1 níwájú Ọlọ́run,
\q2 ẹni Sinai,
\q1 níwájú Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli.
\q1
\v 9 Ìwọ fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò, Ọlọ́run;
\q2 ìwọ tu ilẹ̀ ìní rẹ̀ lára nígbà tí ó rẹ̀ ẹ́ tan.
\q1
\v 10 Àwọn ènìyàn rẹ tẹ̀dó síbẹ̀
\q2 nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní rẹ, Ọlọ́run, ìwọ pèsè fún àwọn aláìní.
\b
\q1
\v 11 Olúwa ti pàṣẹ ọ̀rọ̀,
\q2 púpọ̀ ní ogun àwọn ẹni tí ó ń ròyìn rẹ̀.
\q1
\v 12 “Àwọn ọba àti àwọn ológun yára sálọ;
\q2 obìnrin tí ó sì jókòó ni ilé ní ń pín ìkógun náà.
\q1
\v 13 Nígbà tí ẹ̀yin dùbúlẹ̀ láàrín agbo ẹran,
\q2 nígbà náà ni ẹ̀yin ó dàbí ìyẹ́ àdàbà ti a bò ní fàdákà,
\q2 àti ìyẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú wúrà pupa.”
\q1
\v 14 Nígbà tí Olódùmarè fọ́n àwọn ọba ká ní ilẹ̀ náà,
\q2 ó dàbí òjò dídi ní Salmoni.
\b
\q1
\v 15 Òkè Baṣani jẹ́ òkè Ọlọ́run;
\q2 òkè tí ó ní orí púpọ̀ ni òkè Baṣani.
\q1
\v 16 Kí ló dé tí ẹ̀yin fi ń ṣe ìlara,
\q2 ẹ̀yin òkè wúwo, òkè tí Ọlọ́run ti fẹ́ láti jẹ ọba
\q2 níbi tí \nd Olúwa\nd* fúnra rẹ̀ yóò máa gbé títí láé?
\q1
\v 17 Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ni kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́run
\q2 ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún;
\q2 Olúwa ń bẹ láàrín wọn, ní Sinai ni ibi mímọ́ rẹ̀.
\q1
\v 18 Ìwọ ti gòkè sí ibi gíga
\q2 ìwọ ti di ìgbèkùn ní ìgbèkùn lọ;
\q2 ìwọ ti gba ẹ̀bùn fún ènìyàn:
\q1 nítòótọ́, fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ pẹ̀lú,
\q2 kí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run lè máa bá wọn gbé.
\b
\q1
\v 19 Olùbùkún ni \nd Olúwa\nd*,
\q2 Ọlọ́run Olùgbàlà wa,
\q1 ẹni tí ó ń fi ojoojúmọ́ gba ẹrù wa rù. \qs Sela.\qs*
\q1
\v 20 Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run tó ń gbàlà
\q2 àti sí \nd Olúwa\nd* Olódùmarè ni ó ń gbà wá lọ́wọ́ ikú.
\b
\q1
\v 21 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò tẹ orí àwọn ọ̀tá rẹ̀,
\q2 àti agbárí onírun àwọn tó ń tẹ̀síwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn
\q1
\v 22 Olúwa wí pé, “Èmi ó mú wọn wá láti Baṣani;
\q2 èmi ó mú wọn wá láti ibú omi Òkun,
\q1
\v 23 kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó le pọ́n ní inú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá rẹ,
\q2 àti ahọ́n àwọn ajá rẹ ní ìpín tiwọn lára àwọn ọ̀tá rẹ.”
\b
\q1
\v 24 Wọ́n ti rí ìrìn rẹ, Ọlọ́run,
\q2 ìrìn Ọlọ́run mi àti ọba mi ní ibi mímọ́ rẹ̀.
\q1
\v 25 Àwọn akọrin wà ní iwájú, àwọn olórin wà lẹ́yìn;
\q2 àwọn ọmọbìnrin tí ń lu ṣaworo sì wà pẹ̀lú wọn.
\q1
\v 26 Ẹ fi ìyìn fún \nd Olúwa\nd* ní ẹgbẹgbẹ́;
\q2 àní fún \nd Olúwa\nd* ẹ̀yin tí ó ti orísun Israẹli wá.
\q1
\v 27 Níbẹ̀ ní ẹ̀yà kékeré Benjamini wà, tí ó ń darí wọn,
\q2 níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Juda,
\q2 níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Sebuluni àti tí Naftali.
\b
\q1
\v 28 Pàṣẹ agbára rẹ, Ọlọ́run;
\q2 fi agbára rẹ hàn wá, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe ní ìṣáájú.
\q1
\v 29 Nítorí tẹmpili rẹ ni Jerusalẹmu
\q2 àwọn ọba yóò mú ẹ̀bùn wá fún ọ.
\q1
\v 30 Bá àwọn ẹranko búburú wí,
\q2 tí ń gbé láàrín eèsún
\q1 ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọ màlúù
\q2 pẹ̀lú àwọn ọmọ màlúù
\q1 títí olúkúlùkù yóò fi foríbalẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀n fàdákà:
\q2 tú àwọn ènìyàn tí ń ṣe inú dídùn sí ogun ká.
\q1
\v 31 Àwọn ọmọ-aládé yóò wá láti Ejibiti;
\q2 Etiopia yóò na ọwọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run.
\b
\q1
\v 32 Kọrin sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ìjọba ayé,
\q2 kọrin ìyìn sí \nd Olúwa\nd*, \qs Sela.\qs*
\q1
\v 33 Sí ẹni tí ń gun ọ̀run dé ọ̀run àtijọ́ lókè,
\q2 tó ń fọhùn rẹ̀, ohùn ńlá.
\q1
\v 34 Kéde agbára Ọlọ́run,
\q2 ọláńlá rẹ̀ wà lórí Israẹli,
\q2 tí agbára rẹ̀ wà lójú ọ̀run.
\q1
\v 35 Ìwọ ní ẹ̀rù, Ọlọ́run, ní ibi mímọ́ rẹ;
\q2 Ọlọ́run Israẹli fi agbára àti okun fún àwọn ènìyàn rẹ.
\b
\q1 Olùbùkún ní Ọlọ́run!
\c 69
\cl Saamu 69
\d Fún adarí orin. Tí ohùn “Àwọn Lílì.” Ti Dafidi.
\q1
\v 1 Gbà mí, Ọlọ́run,
\q2 nítorí omi ti kún dé ọrùn mi.
\q1
\v 2 Mo ń rì nínú irà jíjìn,
\q2 níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé.
\q1 Mo ti wá sínú omi jíjìn;
\q2 ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀.
\q1
\v 3 Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́;
\q2 ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú,
\q1 nígbà tí èmi dúró de Ọlọ́run mi.
\q1
\v 4 \x - \xo 69.4: \xt Sm 35.19; Jh 15.25.\x*Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí
\q2 wọ́n ju irun orí mi lọ,
\q1 púpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí,
\q2 àwọn tí ń wá láti pa mí run.
\q1 A fi ipá mú mi
\q2 láti san ohun tí èmi kò jí.
\b
\q1
\v 5 Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run;
\q2 ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú rẹ.
\b
\q1
\v 6 Má ṣe dójútì àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ nítorí mi,
\q2 Olúwa, \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun;
\q1 má ṣe jẹ́ kí àwọn tó ń wá ọ dààmú nítorí mi,
\q2 Ọlọ́run Israẹli.
\q1
\v 7 Nítorí rẹ ni mo ń ru ẹ̀gàn,
\q2 ìtìjú sì bo ojú mi.
\q1
\v 8 Mo jẹ́ àjèjì si àwọn arákùnrin mi;
\q2 àlejò sí àwọn arákùnrin ìyá mi;
\q1
\v 9 \x - \xo 69.9: \xt Jh 2.17; Ro 15.3.\x*nítorí ìtara ilé rẹ jẹ mí run,
\q2 àti ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mí.
\q1
\v 10 Nígbà tí mo sọkún
\q2 tí mo sì ń fi àwẹ̀ jẹ ara mi ní ìyà
\q1 èyí náà sì dín ẹ̀gàn mi kù;
\q1
\v 11 nígbà tí mo wọ aṣọ àkísà,
\q2 àwọn ènìyàn ń pa òwe mọ́ mi.
\q1
\v 12 Àwọn tí ó jókòó ní ẹnu ibodè ń bú mi,
\q2 mo sì di orin àwọn ọ̀mùtí.
\b
\q1
\v 13 Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni
\q2 ìwọ ni èmi ń gbàdúrà mi sí \nd Olúwa\nd*,
\q1 ní ìgbà ìtẹ́wọ́gbà
\q2 Ọlọ́run, nínú ìfẹ́ títóbi rẹ,
\q1 dá mi lóhùn pẹ̀lú ìgbàlà rẹ tí ó dájú.
\q1
\v 14 Gbà mí kúrò nínú ẹrẹ̀,
\q2 má ṣe jẹ́ kí n rì;
\q1 gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi,
\q2 kúrò nínú ibú omi.
\q1
\v 15 Má ṣe jẹ́ kí ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀
\q2 bẹ́ẹ̀ ni má ṣe jẹ́ kí ọ̀gbìn gbé mi mì
\q1 kí o má sì ṣe jẹ́ kí ihò pa ẹnu rẹ̀ dé mọ́ mi.
\b
\q1
\v 16 Dá mí lóhùn, \nd Olúwa\nd*, nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ;
\q2 nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ yípadà sí mi.
\q1
\v 17 Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ:
\q2 yára dá mi lóhùn, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú.
\q1
\v 18 Súnmọ́ tòsí kí o sì gbà mí là;
\q2 rà mí padà nítorí àwọn ọ̀tá mi.
\b
\q1
\v 19 Ìwọ ti mọ ẹ̀gàn mi, ìtìjú mi àti àìlọ́lá;
\q2 gbogbo àwọn ọ̀tá mi wà níwájú rẹ.
\q1
\v 20 Ẹ̀gàn ba ọkàn mi jẹ́,
\q2 wọ́n fi mí sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́;
\q2 mo ń wá aláàánú, ṣùgbọ́n kò sí,
\q2 mo ń wá olùtùnú, ṣùgbọ́n n kò rí ẹnìkankan.
\q1
\v 21 Wọ́n fi òróró fún mi pẹ̀lú ohun jíjẹ mi,
\q2 àti ní òùngbẹ mi, wọ́n fi ọtí kíkan fún mi.
\b
\q1
\v 22 Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó di ìkẹ́kùn
\q2 ní iwájú wọn, kí ó sì di okùn dídẹ
\q2 fún àwọn tó wà ní àlàáfíà.
\q1
\v 23 Kí ojú wọn kì í ó ṣókùnkùn, kí wọn má ṣe ríran,
\q2 kí ẹ̀yin wọn di títẹ̀ títí láé.
\q1
\v 24 \x - \xo 69.24: \xt If 16.1.\x*Tú ìbínú rẹ jáde sí wọn;
\q2 kí ìbínú gbígbóná rẹ bò wọ́n mọ́lẹ̀.
\q1
\v 25 \x - \xo 69.25: \xt Ap 1.20.\x*Kí ibùjókòó wọn di ahoro;
\q2 kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé nínú wọn.
\q1
\v 26 Nítorí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí ẹni tí ìwọ ti lù,
\q2 àti ìrora àwọn tí ó ti ṣèṣe.
\q1
\v 27 Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn;
\q2 Má ṣe jẹ́ kí wọn pín nínú ìgbàlà rẹ.
\q1
\v 28 \x - \xo 69.28: \xt If 3.5; 13.8; 17.8; 20.12,15; 21.27.\x*Jẹ́ kí a yọ wọ́n kúrò nínú ìwé ìyè
\q2 kí á má kà wọ́n pẹ̀lú àwọn olódodo.
\b
\q1
\v 29 Ṣùgbọ́n tálákà àti ẹni-ìkáàánú ni èmí,
\q2 Ọlọ́run, jẹ́ kí ìgbàlà rẹ gbé mi lékè.
\b
\q1
\v 30 Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run ga
\q2 èmi yóò fi ọpẹ́ gbé orúkọ rẹ̀ ga.
\q1
\v 31 Eléyìí tẹ́ \nd Olúwa\nd* lọ́rùn ju ọ̀dá màlúù lọ
\q2 ju akọ màlúù pẹ̀lú ìwo rẹ̀ àti bàtà rẹ̀.
\q1
\v 32 Àwọn òtòṣì yóò rí, wọn yóò sì yọ̀:
\q2 ẹ̀yin yóò wá Ọlọ́run, ọkàn yín yóò sì wà láààyè!
\q1
\v 33 \nd Olúwa\nd*, gbọ́ ti aláìní,
\q2 kì ó sì kọ àwọn ìgbèkùn sílẹ̀.
\b
\q1
\v 34 Kí ọ̀run àti ayé yìn ín,
\q2 òkun àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀,
\q1
\v 35 nítorí tí Ọlọ́run yóò gba Sioni là
\q2 yóò sì tún àwọn ìlú Juda wọ̀nyí kọ́.
\q1 Kí wọn ó lè máa gbé ibẹ̀, kí wọn ó lè máa ní ní ilẹ̀ ìní;
\q2
\v 36 àwọn ọmọ ọmọ ọ̀dọ̀ ni yóò máa jogún rẹ̀,
\q2 àwọn tí ó fẹ́ orúkọ rẹ ni yóò máa gbé inú rẹ̀.
\c 70
\cl Saamu 70
\d Fún adarí orin. Ti Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.
\q1
\v 1 \x - \xo 70.1-5: \xt Sm 40.13-17.\x*Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là,
\q2 \nd Olúwa\nd*, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́.
\b
\q1
\v 2 Kí àwọn tí ń wá ọkàn mi
\q2 kí a dójútì wọ́n, kí wọn sì dààmú;
\q1 kí àwọn tó ń wá ìparun mi
\q2 yí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú.
\q1
\v 3 Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrè
\q2 ìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Háà! Háà!”
\q1
\v 4 Ṣùgbọ́n kí àwọn tí ó ń wá ọ ó máa yọ̀
\q2 kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa rẹ,
\q1 kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà rẹ máa wí pé,
\q2 “Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”
\b
\q1
\v 5 Ṣùgbọ́n mo jẹ́ òtòṣì àti aláìní;
\q2 wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run.
\q1 Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùdáǹdè mi;
\q2 \nd Olúwa\nd*, má ṣe dúró pẹ́.
\c 71
\cl Saamu 71
\q1
\v 1 Nínú rẹ, \nd Olúwa\nd*, ni mo ní ààbò;
\q2 má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
\q1
\v 2 Gbà mí kí o sì tú mi sílẹ̀ nínú òdodo rẹ;
\q2 dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbà mí.
\q1
\v 3 Jẹ́ àpáta ààbò mi,
\q2 níbi tí èmi lè máa lọ,
\q1 pa àṣẹ láti gbà mí,
\q2 nítorí ìwọ ni àpáta àti odi agbára mi.
\q1
\v 4 Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú,
\q2 ní ọwọ́ aláìṣòdodo àti ìkà ọkùnrin.
\b
\q1
\v 5 Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, \nd Olúwa\nd* Olódùmarè,
\q2 ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi láti ìgbà èwe.
\q1
\v 6 Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi;
\q2 Ìwọ mú mi jáde láti inú ìyá mi wá
\q1 èmi ó máa yìn ọ́ títí láé.
\q1
\v 7 Mo di àmì fún ọ̀pọ̀ ènìyàn,
\q2 ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.
\q1
\v 8 Ìyìn rẹ̀ kún ẹnu mi,
\q2 ó ń sọ ti ọlá rẹ ní ọjọ́ gbogbo.
\b
\q1
\v 9 Má ṣe ta mí nù ní ọjọ́ ogbó mi,
\q2 má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́.
\q1
\v 10 Nítorí àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀-òdì sí mi,
\q2 àwọn tí wọn dúró láti pa mí gbìmọ̀ pọ̀.
\q1
\v 11 Wọ́n wí pé, “Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;
\q2 lépa rẹ̀ kí ẹ sì mu,
\q2 nítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á.”
\q1
\v 12 Má ṣe jìnnà sí mi, Ọlọ́run;
\q2 wa kánkán, Ọlọ́run mi, láti ràn mí lọ́wọ́.
\q1
\v 13 Jẹ́ kí wọn kí ó dààmú,
\q2 kí a sì run àwọn tí ń ṣe ọ̀tá ọkàn mi
\q1 kí a sì fi ẹ̀gàn àti àbùkù
\q2 bo àwọn tí ń wá ìpalára mi.
\b
\q1
\v 14 Ṣùgbọ́n ní tèmi, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi;
\q2 èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sí i.
\b
\q1
\v 15 Ẹnu mi yóò sọ nípa ti òdodo rẹ,
\q1 ti ìgbàlà rẹ, ni gbogbo ọjọ́,
\q1 lóòtítọ́, èmi kò mọ iye rẹ̀.
\q1
\v 16 Èmi ó wá láti wá kéde agbára,
\q2 \nd Olúwa\nd* Olódùmarè;
\q2 èmi ó kéde òdodo rẹ̀ nìkan.
\q1
\v 17 Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ ti kọ́ mi
\q2 títí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ.
\q1
\v 18 Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo sì hewú,
\q2 má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run mi,
\q1 títí èmi ó fi ipá rẹ han ìran tí ń bọ̀,
\q2 àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn.
\b
\q1
\v 19 Ọlọ́run, òdodo rẹ dé ọ̀run,
\q2 ìwọ tí o ti ṣe ohun ńlá.
\q2 Ta ni ó dàbí rẹ, Ọlọ́run?
\q1
\v 20 Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí ó pọ̀ tí ó sì korò,
\q2 ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí
\q1 ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè
\q2 láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá.
\q1 Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀.
\q1
\v 21 Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ mi
\q2 ìwọ yóò tù mí nínú ní ha gbogbo.
\b
\q1
\v 22 Èmi yóò fi dùùrù mi yìn
\q2 fún òtítọ́ rẹ, Ọlọ́run mi;
\q1 èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrù
\q2 ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli.
\q1
\v 23 Ètè mi yóò kígbe fún ìyìn
\q2 nígbà tí mo bá kọrin ìyìn sí ọ:
\q2 èmi, ẹni tí o rà padà.
\q1
\v 24 Ahọ́n mi yóò sọ ti òdodo rẹ ní gbogbo ọjọ́,
\q2 fún àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára,
\q2 a sì dójúti àwọn tí ń wá ìdààmú mi.
\c 72
\cl Saamu 72
\d Ti Solomoni.
\q1
\v 1 Fi ìdájọ́ fún àwọn ọba, Ọlọ́run,
\q2 ọmọ-aládé ni ìwọ fi òdodo rẹ fún.
\q1
\v 2 Yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú òdodo,
\q2 yóò sì máa fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn tálákà rẹ̀.
\b
\q1
\v 3 Àwọn òkè ńlá yóò máa mú àlàáfíà fún àwọn ènìyàn
\q2 àti òkè kéékèèké nípa òdodo.
\q1
\v 4 Yóò dáàbò bo àwọn tí a pọ́n lójú láàrín àwọn ènìyàn
\q2 yóò gba àwọn ọmọ aláìní;
\q2 yóò sì fa àwọn aninilára ya.
\q1
\v 5 Àwọn òtòṣì àti aláìní
\q2 yóò máa fi ọ̀wọ̀ ńlá fún ọ nígbà gbogbo,
\q1 níwọ̀n ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá bá ń ràn,
\q2 yóò ti pẹ́ tó, láti ìrandíran.
\q1
\v 6 Yóò dàbí òjò tí ó ń rọ̀ sórí pápá ìrẹ́mọ́lẹ̀,
\q2 bí ọwọ́ òjò tó ń rin ilẹ̀.
\q1
\v 7 Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀ ni ọjọ́ rẹ̀
\q2 ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà yóò sì wà;
\q2 títí tí òṣùpá kò fi ní sí mọ́.
\b
\q1
\v 8 Yóò máa jẹ ọba láti òkun dé òkun
\q2 àti láti odò Eufurate títí dé òpin ayé.
\q1
\v 9 Àwọn tí ó wà ní aginjù yóò tẹríba fún un
\q2 àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò máa lá erùpẹ̀ ilẹ̀.
\q1
\v 10 Àwọn ọba Tarṣiṣi àti ti erékùṣù
\q2 wọn yóò mú ọrẹ wá fún un;
\q1 àwọn ọba Ṣeba àti Seba
\q2 wọn ó mú ẹ̀bùn wá fún un.
\q1
\v 11 Gbogbo ọba yóò tẹríba fún un
\q2 àti gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sìn ín.
\b
\q1
\v 12 Nítorí yóò gba àwọn aláìní
\q2 nígbà tí ó bá ń ké,
\q1 tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
\q1
\v 13 Yóò káàánú àwọn aláìlera àti aláìní
\q2 yóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú.
\q1
\v 14 Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipá
\q2 nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣọ̀wọ́n níwájú rẹ̀.
\b
\q1
\v 15 Yóò sì pẹ́ ní ayé!
\q2 A ó sì fún un ní wúrà Ṣeba.
\q1 Àwọn ènìyàn yóò sì máa gbàdúrà fún un nígbà gbogbo
\q2 kí a sì bùkún fún un lójoojúmọ́.
\q1
\v 16 Kí ìkúnwọ́ ọkà wà lórí ilẹ̀;
\q2 ní orí òkè ni kí ó máa dàgbà
\q1 kí èso rẹ̀ kí o gbilẹ̀ bí ti Lebanoni
\q2 yóò máa gbá yìn bí i koríko ilẹ̀.
\q1
\v 17 Kí orúkọ rẹ̀ kí ó wà títí láé;
\q2 orúkọ rẹ̀ yóò máa gbilẹ̀ níwọ̀n bí oòrùn yóò ti pẹ́ tó.
\b
\q1 Wọn ó sì máa bùkún fún ara wọn nípasẹ̀ rẹ.
\q2 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní yóò máa pè mí ní alábùkún fún.
\b
\b
\q1
\v 18 Olùbùkún ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli,
\q2 ẹnìkan ṣoṣo tí ó ń ṣe ohun ìyanu.
\q1
\v 19 Olùbùkún ni orúkọ rẹ̀ tí ó lógo títí láé;
\q2 kí gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.
\qc Àmín àti Àmín.
\b
\b
\q1
\v 20 Èyí ni ìparí àdúrà Dafidi ọmọ Jese.
\c 73
\ms ÌWÉ KẸTA
\mr Saamu 7389
\cl Saamu 73
\d Saamu ti Asafu.
\q1
\v 1 Nítòótọ́ Ọlọ́run dára fún Israẹli,
\q2 fún àwọn ọlọ́kàn funfun.
\b
\q1
\v 2 Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi, ẹsẹ̀ mi ti yẹ̀ tán;
\q2 ìrìn mi fẹ́rẹ̀ yọ̀ tán.
\q1
\v 3 Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣe féfé
\q2 nígbà tí mo bá rí àlàáfíà àwọn ènìyàn búburú.
\b
\q1
\v 4 Wọn kò ṣe wàhálà;
\q2 ara wọn mókun wọn sì lágbára.
\q1
\v 5 Wọn kò ní ìpín nínú àjàgà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn;
\q2 a kò pọ́n wọn lójú nípa ẹlòmíràn.
\q1
\v 6 Ìgbéraga ni ọ̀ṣọ́ ọrùn wọn;
\q2 ìwà ipá bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí aṣọ.
\q1
\v 7 Láti inú ọkàn àrékérekè ni àìṣòdodo ti wá;
\q2 ẹ̀rí ọkàn búburú wọn kò ní òdínwọ̀n.
\q1
\v 8 Wọn ń ṣẹ̀sín, wọn sì ń sọ̀rọ̀-òdì ní ti ìnilára,
\q2 wọ́n ń sọ̀rọ̀ láti ibi gíga.
\q1
\v 9 Wọ́n ń gbé ẹ̀mí wọn lé ọ̀run
\q2 ahọ́n wọn gba ipò ayé.
\q1
\v 10 Nítorí náà àwọn ènìyàn wọn yípadà sí wọn
\q2 wọ́n sì mu omi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
\q1
\v 11 Wọ́n wí pé, “Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe mọ̀?
\q2 Ọ̀gá-ògo ha ní ìmọ̀ bí?”
\b
\q1
\v 12 Bí àwọn ènìyàn búburú ṣe rí nìyí,
\q2 ènìyàn asán, wọ́n ń pọ̀ ní ọrọ̀.
\b
\q1
\v 13 Nítòótọ́ nínú asán ni mo pa ọkàn mi mọ́;
\q2 nínú asán ni mo wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀.
\q1
\v 14 Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu;
\q2 a sì ń jẹ mí ní yà ní gbogbo òwúrọ̀.
\b
\q1
\v 15 Bí mo bá wí pé, “Èmi ó wí báyìí,”
\q2 èmi ó ṣẹ̀ sí ìran àwọn ọmọ rẹ̀.
\q1
\v 16 Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí,
\q2 Ó jẹ́ ìnilára fún mi,
\q1
\v 17 títí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run;
\q2 nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi.
\b
\q1
\v 18 Lóòtítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́
\q2 ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun.
\q1
\v 19 Báwo ní a ti mú wọn lọ sínú ìdahoro yìí
\q2 bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan!
\q1 Ìbẹ̀rù ni a fi ń run wọ́n pátápátá!
\q1
\v 20 Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, \nd Olúwa\nd*,
\q2 ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn.
\b
\q1
\v 21 Nígbà tí inú mi bàjẹ́
\q2 àti ọkàn mi ṣì korò,
\q1
\v 22 mo jẹ́ aṣiwèrè àti aláìlóye;
\q2 mo jẹ́ ẹranko ní iwájú rẹ.
\b
\q1
\v 23 Síbẹ̀ mo wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo;
\q2 ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.
\q1
\v 24 Ìwọ fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi
\q2 ní ìkẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo.
\q1
\v 25 Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ?
\q2 Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn rẹ.
\q1
\v 26 Ara mi àti ọkàn mi le è kùnà
\q2 ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí mi
\q2 àti ìpín mi títí láé.
\b
\q1
\v 27 Àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóò ṣègbé
\q2 ìwọ ti pa gbogbo wọn run;
\q1 tí ń ṣe àgbèrè kiri kúrò lọ́dọ̀ rẹ.
\q1
\v 28 Ṣùgbọ́n ní ti èmi, ó dára láti súnmọ́ Ọlọ́run.
\q2 Èmi ti fi \nd Olúwa\nd* Olódùmarè ṣe ààbò mi;
\q2 kí èmi ó lè máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ.
\c 74
\cl Saamu 74
\d Maskili ti Asafu.
\q1
\v 1 Ọlọ́run, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé?
\q2 Èéṣe tí ìbínú rẹ̀ fi dìde sí àwọn àgùntàn pápá rẹ?
\q1
\v 2 Rántí àwọn ènìyàn tí ìwọ ti rà nígbà àtijọ́,
\q2 ẹ̀yà ilẹ̀ ìní rẹ, tí ìwọ ti rà padà.
\q2 Òkè Sioni, níbi tí ìwọ ń gbé.
\q1
\v 3 Yí ẹsẹ̀ rẹ padà sí ìparun ayérayé wọn,
\q2 gbogbo ìparun yìí tí ọ̀tá ti mú wá sí ibi mímọ́.
\b
\q1
\v 4 Àwọn ọ̀tá rẹ ń bú ramúramù
\q2 láàrín ènìyàn rẹ,
\q1 wọ́n ń gbé àsíá wọn sókè fún àmì.
\q1
\v 5 Wọ́n ń rí bí ọkùnrin tí ó gbé àáké rẹ̀ sókè
\q2 láti gé igi igbó dídí.
\q1
\v 6 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, iṣẹ́ ọnà fínfín,
\q2 ni wọ́n fi àáké wó lulẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan náà.
\q1
\v 7 Wọ́n sun ibi mímọ́ rẹ lulẹ̀
\q2 wọ́n ba ibùgbé orúkọ rẹ jẹ́.
\q1
\v 8 Wọ́n wí ní ọkàn wọn. “Àwa ó run wọ́n pátápátá!”
\q2 Wọ́n sun gbogbo ibi ìjọ́sìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà.
\b
\q1
\v 9 A kò fún wa ní àmì iṣẹ́ ìyanu kankan;
\q2 kò sí wòlíì kankan
\q2 ẹnìkankan wa kò mọ ìgbà tí eléyìí yóò dà.
\q1
\v 10 Àwọn ọ̀tá yóò ti kùn sí ọ pẹ́ tó, Ọlọ́run?
\q2 Àwọn ọ̀tá yóò ha ba orúkọ rẹ jẹ́ títí láé?
\q1
\v 11 Èéṣe tí ìwọ fi dá ọwọ́ rẹ dúró, ọwọ́ ọ̀tún rẹ?
\q2 Mú un kúrò nínú ìṣẹ́po aṣọ rẹ kí o sì run wọ́n!
\b
\q1
\v 12 Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run ni ọba mi láti ìgbà pípẹ́;
\q2 Ó mú ìgbàlà wá sórí ilẹ̀ ayé.
\b
\q1
\v 13 Ìwọ ni ó la òkun sílẹ̀ nípa agbára rẹ;
\q2 ìwọ fọ́ orí ẹ̀mí búburú nínú omi.
\q1
\v 14 Ìwọ fọ́ orí Lefitani túútúú, o sì fi ṣe oúnjẹ fun àwọn ẹ̀dá tí ń gbé inú ijù
\q2 tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ sì ni alẹ́ pẹ̀lú;
\q2 ìwọ fi ìdí oòrùn àti òṣùpá lélẹ̀.
\q1
\v 15 Ìwọ ya orísun omi àti ìṣàn omi;
\q2 Ìwọ mú kí odò tó ń sàn gbẹ.
\q1
\v 16 Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú;
\q2 ìwọ yà oòrùn àti òṣùpá.
\q1
\v 17 Ìwọ pààlà etí ayé;
\q2 Ìwọ dá ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù.
\b
\q1
\v 18 Rántí bí àwọn ọ̀tá ń kẹ́gàn rẹ, \nd Olúwa\nd*
\q2 bí àwọn aṣiwèrè ènìyàn ti ń ba orúkọ rẹ jẹ́.
\q1
\v 19 Má ṣe fi ẹ̀mí àdàbà rẹ fún ẹranko igbó búburú;
\q2 má ṣe gbàgbé ẹ̀mí àwọn ènìyàn rẹ tí a ń pọ́n lójú títí láé.
\q1
\v 20 Bojú wo májẹ̀mú rẹ,
\q2 nítorí ibi òkùnkùn ayé kún fún ibùgbé ìkà.
\q1
\v 21 Má ṣe jẹ́ kí àwọn aninilára padà sẹ́yìn nínú ìtìjú
\q2 jẹ́ kí àwọn aláìní àti tálákà yin orúkọ rẹ.
\q1
\v 22 Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara rẹ rò;
\q2 rántí bí àwọn aṣiwèrè ti ń kẹ́gàn rẹ ní gbogbo ọjọ́.
\q1
\v 23 Má ṣe gbàgbé ohùn àwọn ọ̀tá rẹ,
\q2 bíbú àwọn ọ̀tá rẹ, tí ó ń pọ̀ sí i nígbà gbogbo.
\c 75
\cl Saamu 75
\d Fún adarí orin. Tí ohùn, “Má ṣe parun.” Saamu ti Asafu. Orin.
\q1
\v 1 A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run,
\q2 a yìn ọ́, nítorí orúkọ rẹ súnmọ́ tòsí;
\q2 àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu rẹ.
\b
\q1
\v 2 Ìwọ wí pé, “Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀;
\q2 Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo.
\q1
\v 3 Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì,
\q2 Èmi ni mo di òpó rẹ̀ mú ṣinṣin.
\q1
\v 4 Èmí wí fún àwọn agbéraga pé,
\q2 ẹ má ṣe gbéraga mọ́;
\q1 àti sí ènìyàn búburú;
\q2 ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè.
\q1
\v 5 Ẹ má ṣe gbe ìwo yín sókè sí ọ̀run;
\q2 ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọrùn líle.”
\b
\q1
\v 6 Nítorí ìgbéga kò ti ìlà-oòrùn wá
\q2 tàbí ní ìwọ̀-oòrùn,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti gúúsù wá.
\q1
\v 7 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdájọ́;
\q2 Ó ń rẹ ẹnìkan sílẹ̀, ó sì ń gbé ẹlòmíràn ga.
\q1
\v 8 Ní ọwọ́ \nd Olúwa\nd* ni ago kan wà,
\q2 ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú,
\q1 ó fún ọtí àdàlú tí a pò mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde,
\q2 àwọn ènìyàn búburú ayé gbogbo mú u pátápátá.
\b
\q1
\v 9 Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn rẹ títí láé;
\q2 èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jakọbu.
\q1
\v 10 Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú,
\q2 ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.
\c 76
\cl Saamu 76
\d Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Asafu. Orin.
\q1
\v 1 Ní Juda ni a mọ Ọlọ́run;
\q2 orúkọ rẹ̀ sì lágbára ní Israẹli
\q1
\v 2 Àgọ́ rẹ̀ wà ní Salẹmu,
\q2 ibùgbé rẹ̀ ni Sioni.
\q1
\v 3 Níbẹ̀ ni ó ṣẹ́ ọfà,
\q2 asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 4 Ìwọ ni ògo àti ọlá,
\q2 ju òkè ńlá ìkógun wọ̀nyí lọ.
\q1
\v 5 A kó àwọn alágídí ọkàn ní ìkógun
\q2 wọ́n sun oorun ìgbẹ̀yìn wọn;
\q1 kò sí ọ̀kan nínú àwọn akọni
\q2 tó lè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.
\q1
\v 6 Ní ìfibú rẹ, Ọlọ́run Jakọbu,
\q2 àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.
\b
\q1
\v 7 Ìwọ nìkan ni ó yẹ kí a bẹ̀rù.
\q2 Ta ló lé dúró níwájú rẹ, nígbà tí ìwọ bá ń bínú?
\q1
\v 8 Ìwọ ń ṣe ìdájọ́ láti ọ̀run,
\q2 ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ẹ́,
\q1
\v 9 nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run,
\q2 bá dìde láti ṣe ìdájọ́,
\q1 láti gba àwọn ẹni ìnilára ilẹ̀ náà. \qs Sela.\qs*
\q1
\v 10 Lóòótọ́, ìbínú rẹ sí àwọn ènìyàn ń mú ìyìn wá fún ọ,
\q2 ẹni tí ó yọ nínú ìbínú rẹ ní a dá nígbà tí ìwọ bá fi ìbínú ìyókù di ara rẹ ni àmùrè.
\b
\q1
\v 11 Jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ kí o sì mú un ṣẹ;
\q2 kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká
\q2 mú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí ó tọ́ láti bẹ̀rù.
\q1
\v 12 Ó ké ẹ̀mí àwọn aládé kúrò;
\q2 àwọn ọba ayé sì ń bẹ̀rù rẹ̀.
\c 77
\cl Saamu 77
\d Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Ti Asafu. Saamu.
\q1
\v 1 Mó kígbe sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́;
\q2 mo kígbe sí Ọlọ́run láti gbọ́ tèmi.
\q1
\v 2 Nígbà tí mo wà nínú ìpọ́njú,
\q2 mo wá \nd Olúwa\nd*;
\q1 ní òru ni mo na ọwọ́ mi jáde ní àìkáárẹ̀
\q2 ọkàn mí sì kọ̀ láti tù ú nínú.
\b
\q1
\v 3 Èmi rántí rẹ, Ọlọ́run,
\q2 mo sì kẹ́dùn;
\q1 mo ṣe àròyé, ẹ̀mí mi sì rẹ̀wẹ̀sì. \qs Sela.\qs*
\q1
\v 4 Ìwọ kò fẹ́ kí èmi fi ojú ba oorun,
\q2 mo dààmú tó bẹ́ẹ̀ tí ń kò le sọ̀rọ̀.
\q1
\v 5 Mo ronú nípa ọjọ́ ìgbàanì;
\q2 ọdún pípẹ́ sẹ́yìn;
\q1
\v 6 mo rántí orin mi ní òru.
\q2 Èmi ń bá àyà mi sọ̀rọ̀,
\q2 ọkàn mi sì ń ṣe àwárí jọjọ.
\b
\q1
\v 7 “Olúwa yóò ha kọ̀ títí láé?
\q2 Ki yóò ha ṣe ojúrere rẹ̀ mọ́?
\q1
\v 8 Ṣe ìfẹ́ rẹ̀ àti àánú rẹ̀ ti kú lọ láéláé?
\q2 Ìlérí rẹ̀ ha kùnà títí ayé?
\q1
\v 9 Ọlọ́run ha gbàgbé láti máa ṣàánú?
\q2 Ní ìbínú rẹ̀, ó ha sé ojúrere rẹ̀ mọ́?” \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 10 Èmi wí pé, “Èyí ní ẹ̀dùn ọkàn mi,
\q2 pé ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀gá-ògo jùlọ ti yípadà”.
\q1
\v 11 Èmi ó rántí iṣẹ́ \nd Olúwa\nd*:
\q2 bẹ́ẹ̀ ni, èmi ó rántí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ọjọ́ pípẹ́.
\q1
\v 12 Èmi ṣàṣàrò lórí iṣẹ́ rẹ gbogbo,
\q2 pẹ̀lú, ènìyàn sì máa sọ̀rọ̀ gbogbo iṣẹ́ agbára rẹ.
\b
\q1
\v 13 Ọlọ́run, ọ̀nà rẹ jẹ́ mímọ́.
\q2 Ọlọ́run wo ni ó sì tóbi bí Ọlọ́run wa?
\q1
\v 14 Ìwọ ni Ọlọ́run tó ń ṣe ìyanu;
\q2 ìwọ fi agbára rẹ hàn nínú àwọn ènìyàn.
\q1
\v 15 Pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ ni ìwọ ra àwọn ènìyàn padà,
\q2 àwọn ọmọ Jakọbu àti Josẹfu. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 16 Nígbà tí àwọn omi rí Ọlọ́run,
\q2 nígbà tí àwọn omi rí ọ,
\q1 ẹ̀rù bà wọ́n,
\q2 nítòótọ́ ara ibú kò balẹ̀.
\q1
\v 17 Àwọn ojú ọ̀run tú omi sílẹ̀,
\q2 àwọsánmọ̀ fi àrá dáhùn;
\q2 ọfà rẹ̀ ń tàn sẹ́yìn àti síwájú.
\q1
\v 18 Àrá rẹ̀ ni a gbọ́ nínú ìjì,
\q2 ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí gbogbo ayé;
\q2 ayé bẹ̀rù, wọ́n sì wárìrì.
\q1
\v 19 Ipa rẹ̀ gba Òkun, ọ̀nà rẹ̀ ń bẹ nínú Òkun,
\q2 ọ̀nà la omi alágbára kọjá ipa rẹ̀ ń bẹ nínú líla omi alágbára kọjá,
\q2 nítòótọ́ a kò rí ojú ẹsẹ̀ rẹ̀.
\b
\q1
\v 20 Ó tọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran
\q2 nípa ọwọ́ Mose àti Aaroni.
\c 78
\cl Saamu 78
\d Maskili ti Asafu.
\q1
\v 1 Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi;
\q2 tẹ́tí rẹ sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
\q1
\v 2 \x - \xo 78.2: \xt Mt 13.35.\x*Èmi ó la ẹnu mi ní òwe,
\q2 èmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́;
\q1
\v 3 ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,
\q2 ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa.
\q1
\v 4 Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́
\q2 kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ,
\q1 ní fífi ìyìn \nd Olúwa\nd*, àti ipa rẹ̀
\q2 àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn
\q1 fún ìran tí ń bọ̀.
\q1
\v 5 Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jakọbu
\q2 o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Israẹli,
\q1 èyí tí ó pàṣẹ fún àwọn baba ńlá wa
\q2 láti kọ́ àwọn ọmọ wọn,
\q1
\v 6 nítorí náà, àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́n
\q2 bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí
\q2 tí yóò dìde tí wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn.
\q1
\v 7 Nígbà náà ni wọ́n ò fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́run
\q2 wọn kò sì ní gbàgbé iṣẹ́ Ọlọ́run
\q2 ṣùgbọ́n wọn ó pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
\q1
\v 8 Kí wọn kí ó má ṣe dàbí àwọn baba ńlá wọn,
\q2 ìran alágídí àti ọlọ́tẹ̀,
\q2 ìran tí ọkàn wọn kò ṣọ òtítọ́ si olóore,
\q2 àti ẹ̀mí ẹni tí kò bá Ọlọ́run dúró ṣinṣin.
\b
\q1
\v 9 Àwọn ọkùnrin Efraimu, tí ó há mọ́ ọ tí wọ́n mú ọrun,
\q2 wọ́n yípadà ní ọjọ́ ogun
\q1
\v 10 Wọn kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́
\q2 wọn sì kọ̀ láti máa gbé nínú òfin rẹ̀.
\q1
\v 11 Wọ́n gbàgbé ohun tí ó ti ṣe,
\q2 àwọn ìyanu tí ó ti fihàn wọ́n.
\q1
\v 12 Ó ṣe ìyanu níwájú àwọn baba wọn ní ilẹ̀ Ejibiti, ní agbègbè Ṣoani.
\q1
\v 13 Ó pín òkun ní yà, ó sì mú wọn kọjá
\q2 Ó mù kí omi náà dúró bi odi gíga.
\q1
\v 14 Ní ọ̀sán, ó fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ṣe amọ̀nà wọn
\q2 àti ní gbogbo òru pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ iná.
\q1
\v 15 Ó sán àpáta ní aginjù
\q2 ó sì fún wọn ní omi mímu lọ́pọ̀lọ́pọ̀
\q2 bí ẹni pé láti inú ibú wá.
\q1
\v 16 Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta
\q2 omi ṣíṣàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí odò.
\b
\q1
\v 17 Wọ́n sì tún tẹ̀síwájú láti dẹ́ṣẹ̀ sí i
\q2 ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo ní aginjù.
\q1
\v 18 Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wò
\q2 nípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún.
\q1
\v 19 Wọ́n sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, wí pé
\q2 “Ọlọ́run ha lè tẹ́ tábìlì ní aginjù?
\q1
\v 20 Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde,
\q2 odò sì sàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀
\q1 ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ
\q2 ó ha le pèsè ẹran fún àwọn ènìyàn rẹ̀?”
\q1
\v 21 Nígbà tí \nd Olúwa\nd* gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi;
\q1 iná rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jakọbu,
\q1 ìbínú rẹ̀ sì rú sí Israẹli,
\q1
\v 22 nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́,
\q2 wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà rẹ̀.
\q1
\v 23 Síbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀run,
\q2 ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀;
\q1
\v 24 \x - \xo 78.24: \xt Jh 6.31.\x*Ó rọ manna fún àwọn ènìyàn láti jẹ,
\q2 ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run.
\q1
\v 25 Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn angẹli;
\q2 Ó fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó,
\q1
\v 26 Ó mú afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀run wá
\q2 ó mú afẹ́fẹ́ gúúsù wá nípa agbára rẹ̀.
\q1
\v 27 Ó rọ òjò ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀,
\q2 àti ẹyẹ abìyẹ́ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí òkun
\q1
\v 28 Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn,
\q2 yíká àgọ́ wọn.
\q1
\v 29 Wọ́n jẹ, wọ́n sì yó jọjọ
\q2 nítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún.
\q1
\v 30 Ṣùgbọ́n wọn kò kúrò nínú oúnjẹ tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún,
\q2 nígbà tí oúnjẹ wọn sì wà ní ẹnu wọn,
\q1
\v 31 ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọn
\q2 ó pa àwọn tí ó jùlọ nínú wọn,
\q2 ó sì lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli bolẹ̀.
\b
\q1
\v 32 Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ síwájú;
\q2 nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọ́n kò gbàgbọ́.
\q1
\v 33 O fi òpin sí ayé wọn nínú asán
\q2 àti ọdún wọn nínú ìpayà.
\q1
\v 34 Nígbàkígbà tí Ọlọ́run bá pa wọ́n,
\q2 wọn yóò wá a kiri;
\q2 wọn yóò fi ìtara yípadà sí i.
\q1
\v 35 Wọ́n rántí pé Ọlọ́run ní àpáta wọn;
\q2 wí pé Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ ni olùràpadà àpáta wọn.
\q1
\v 36 Ṣùgbọ́n nígbà náà ni wọ́n yóò pọ́n ọn pẹ̀lú ẹnu wọ́n
\q2 wọ́n fi ahọ́n wọ́n purọ́ fún un;
\q1
\v 37 \x - \xo 78.37: \xt Ap 8.21.\x*ọkàn wọn kò sòtítọ́ sí i,
\q2 wọn kò jẹ́ olódodo sí májẹ̀mú rẹ̀.
\q1
\v 38 Síbẹ̀ ó ṣàánú;
\q2 ó dárí àìṣedéédéé wọn jì
\q1 òun kò sì pa wọ́n run
\q2 nígbà púpọ̀ ló ń yí ìbínú rẹ̀ padà
\q1 kò sì ru ìbínú rẹ̀ sókè
\q1
\v 39 Ó rántí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n,
\q2 afẹ́fẹ́ tó ń kọjá tí kò lè padà.
\b
\q1
\v 40 Nígbà gbogbo ní wọn ń ṣọ̀tẹ̀ sí i ní aginjù
\q2 wọn mú un bínú nínú ilẹ̀ tí ó di ahoro!
\q1
\v 41 Síwájú àti síwájú wọ́n dán Ọlọ́run wò;
\q2 wọ́n mú ẹni mímọ́ Israẹli bínú.
\q1
\v 42 Wọ́n kò rántí agbára rẹ̀:
\q2 ní ọjọ́ tí ó rà wọ́n padà lọ́wọ́ àwọn aninilára,
\q1
\v 43 ní ọjọ́ tí ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ hàn ní Ejibiti,
\q2 àti iṣẹ́ àmì rẹ̀ ni ẹkùn Ṣoani
\q1
\v 44 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀;
\q2 wọn kò lè mu láti odò wọn.
\q1
\v 45 Ó rán ọ̀wọ́ eṣinṣin láti pa wọ́n run,
\q2 àti ọ̀pọ̀lọ́ tí ó bá wọn jẹun.
\q1
\v 46 Ó fi ọkà wọn fún láńtata,
\q2 àwọn ìre oko wọn fún eṣú.
\q1
\v 47 Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́
\q2 ó bá èso sikamore wọn jẹ́.
\q1
\v 48 Ó fi ohun ọ̀sìn wọn fún yìnyín,
\q2 agbo ẹran wọn fún mọ̀nàmọ́ná.
\q1
\v 49 Ó mú kíkorò ìbínú rẹ̀ wá sí wọn lára,
\q2 ìrunú àti ìkáàánú, àti ìpọ́njú,
\q2 nípa rírán angẹli apanirun sí wọn.
\q1
\v 50 Ó pèsè ipa fún ìbínú rẹ̀,
\q2 òun kò gbà wọ́n lọ́wọ́ ikú,
\q2 ṣùgbọ́n ó fi ẹ̀mí wọ́n fún àjàkálẹ̀-ààrùn.
\q1
\v 51 Ó kọlu àwọn àkọ́bí ọmọ ọkùnrin Ejibiti,
\q2 olórí agbára wọn nínú àgọ́ Hamu.
\q1
\v 52 Ṣùgbọ́n ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde bí ọ̀wọ́ ẹran;
\q2 ó ṣọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú aginjù.
\q1
\v 53 Ó dáàbò bò wọ́n dáradára, nítorí náà ni ẹ̀rù kò ṣe bà wọ́n
\q2 ṣùgbọ́n òkun padé mọ́ àwọn ọ̀tá wọn.
\q1
\v 54 Bákan náà ni ó mú wọn wá sí etí ilẹ̀ mímọ́ rẹ̀
\q2 òkè tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ti gbà
\q1
\v 55 Ó lé kèfèrí jáde níwájú wọn
\q2 ó sì fi títa okùn pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní;
\q2 ó mú àwọn ẹ̀yà Israẹli jókòó ní ilẹ̀ wọn.
\b
\q1
\v 56 Ṣùgbọ́n wọn dán Ọlọ́run wò
\q2 wọn sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo;
\q2 wọn kò pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
\q1
\v 57 Ṣùgbọ́n wọ́n yípadà,
\q2 wọn jẹ́ aláìṣòdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn
\q1 wọ́n sì pẹ̀yìndà sí apákan bí ọrun ẹ̀tàn.
\q1
\v 58 Wọ́n bí i nínú pẹ̀lú ibi gíga wọn;
\q2 wọn rú owú rẹ̀ sókè nípa òrìṣà wọn.
\q1
\v 59 Nígbà tí Ọlọ́run gbọ́ wọn,
\q2 inú bí i gidigidi;
\q1 ó kọ Israẹli pátápátá.
\q1
\v 60 Ó kọ àgọ́ Ṣilo sílẹ̀,
\q2 àgọ́ tí ó ti gbé kalẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn.
\q1
\v 61 Ó rán àpótí ẹ̀rí, agbára rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn,
\q2 dídán ògo rẹ̀ lọ sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá.
\q1
\v 62 Ó fi àwọn ènìyàn rẹ̀ lé idà lọ́wọ́,
\q2 ó sì bínú sí àwọn ohun ìní rẹ̀.
\q1
\v 63 Iná run àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn,
\q2 àwọn ọmọbìnrin wọn kò sì ní orin ìgbéyàwó:
\q1
\v 64 àfi àlùfáà wọn fún idà,
\q2 àwọn opó wọn kò sì le è sọkún.
\b
\q1
\v 65 Olúwa sì jí gẹ́gẹ́ bí ẹni ojú oorun,
\q2 gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ti i jí kúrò nínú ìraníyè ọtí.
\q1
\v 66 Ó kọlu àwọn ọ̀tá rẹ̀ padà;
\q2 ó fi wọn sínú ìtìjú ayérayé.
\q1
\v 67 Nígbà náà ni ó kọ́ àgọ́ Josẹfu,
\q2 kò sì yan ẹ̀yà Efraimu,
\q1
\v 68 ṣùgbọ́n ó yan ẹ̀yà Juda,
\q2 òkè Sioni, èyí tí ó fẹ́ràn.
\q1
\v 69 Ó kọ́ ibi mímọ́ rẹ̀, ibi gíga,
\q2 gẹ́gẹ́ bí ayé tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.
\q1
\v 70 Ó yan Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀
\q2 ó mú láti inú àwọn agbo ẹran;
\q1
\v 71 Ó mú un jáde nínú ìtọ́jú àgùntàn
\q2 láti jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn rẹ̀ Jakọbu
\q2 àti Israẹli ogún un rẹ̀.
\q1
\v 72 Dafidi sì ṣọ́ wọn pẹ̀lú òtítọ́ inú ọkàn;
\q2 pẹ̀lú ọwọ́ òye ni ó fi darí wọn.
\c 79
\cl Saamu 79
\d Saamu ti Asafu.
\q1
\v 1 Ọlọ́run, àwọn orílẹ̀-èdè ti wá ilẹ̀ ìní rẹ;
\q2 wọ́n ti ba tẹmpili mímọ́ rẹ jẹ́,
\q2 wọn di Jerusalẹmu kù sí òkìtì àlàpà.
\q1
\v 2 Wọn ti fi ara òkú àwọn ìránṣẹ́ rẹ
\q2 fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní oúnjẹ,
\q2 ẹran-ara àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ fún ẹranko ilẹ̀.
\q1
\v 3 Wọ́n tu ẹ̀jẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí omi
\q2 yí Jerusalẹmu ká,
\q2 kò sì ṣí àwọn tí yóò sìn wọ́n.
\q1
\v 4 Àwa di ohun ẹ̀gàn sí àwọn tí ó yí wa ká,
\q2 àbùkù àti ìfiṣe ẹlẹ́yà sí àwọn tí ó yí wa ká.
\b
\q1
\v 5 Nígbà wo, \nd Olúwa\nd*? Ní ìwọ ó máa bínú títí láé?
\q2 Yóò ti pẹ́ tó ti owú rẹ yóò ha jò bí iná?
\q1
\v 6 Tú ìbínú rẹ jáde sí orílẹ̀-èdè
\q2 tí kò ní ìmọ̀ rẹ,
\q1 lórí àwọn ìjọba
\q2 tí kò pe orúkọ rẹ;
\q1
\v 7 nítorí wọ́n ti run Jakọbu
\q2 wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ di ahoro.
\b
\q1
\v 8 Má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa sí wa lọ́rùn
\q2 jẹ́ kí àánú rẹ wá kánkán láti bá wa,
\q2 nítorí tí a rẹ̀ wá sílẹ̀ gidigidi.
\q1
\v 9 Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọ́run Olùgbàlà wa,
\q2 fún ògo orúkọ rẹ;
\q1 gbà wá kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì
\q2 nítorí orúkọ rẹ.
\q1
\v 10 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa wí pé,
\q2 “Níbo ni Ọlọ́run wọn wà?”
\b
\q1 Ní ojú wa, kí a mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
\q2 kí ó sì gbẹ̀san àwọn ẹ̀jẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ tí a tú jáde.
\q1
\v 11 Jẹ́ kí ìmí ẹ̀dùn oǹdè náà wá síwájú rẹ,
\q2 gẹ́gẹ́ bí títóbi agbára rẹ
\q2 ìwọ ṣe ìtọ́jú àwọn ti a dá lẹ́bi ikú.
\q1
\v 12 San án padà sí àyà àwọn aládùúgbò wa nígbà méje
\q2 nípa ẹ̀gàn tí wọn ti gàn ọ́ \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 13 Nígbà náà àwa ènìyàn rẹ,
\q2 àti àgùntàn pápá rẹ,
\q1 yóò fi ọpẹ́ fún ọ títí láé;
\q2 láti ìran dé ìran
\q1 ni àwa ó fi ìyìn rẹ hàn.
\c 80
\cl Saamu 80
\d Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì Ti Májẹ̀mú.” Ti Safu. Saamu.
\q1
\v 1 Gbọ́ tiwa, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn Israẹli;
\q2 ìwọ tí ó darí Josẹfu bí ọ̀wọ́ ẹran.
\q1 Ìwọ tí o jókòó lórí ìtẹ́ láàrín Kérúbù,
\q2 tàn jáde
\v 2 níwájú Efraimu, Benjamini àti Manase.
\q1 Ru agbára rẹ̀ sókè;
\q2 wá fún ìgbàlà wa.
\b
\q1
\v 3 Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run;
\q2 jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,
\q1 kí a bá à lè gbà wá là.
\b
\q1
\v 4 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run alágbára,
\q2 ìbínú rẹ̀ yóò ti pẹ́ tó
\q2 sí àdúrà àwọn ènìyàn rẹ?
\q1
\v 5 Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọn
\q2 ìwọ ti mú wọn wa ẹkún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
\q1
\v 6 Ìwọ sọ wá di ẹlẹ́yà fún àwọn aládùúgbò wa,
\q2 àwọn ọ̀tá wa sì ń yọ̀ wá.
\b
\q1
\v 7 Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run alágbára;
\q2 jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa,
\q2 kí a ba à lè gbà wá là.
\b
\q1
\v 8 Ìwọ mú àjàrà jáde láti Ejibiti;
\q2 ìwọ lé àwọn kèfèrí jáde, o sì gbìn ín.
\q1
\v 9 Ìwọ ṣí ààyè sílẹ̀ fún un,
\q2 ìwọ sì mu ta gbòǹgbò jinlẹ̀
\q1 ó sì kún ilẹ̀ náà.
\q1
\v 10 A bò àwọn òkè mọ́lẹ̀ òkè pẹ̀lú òjìji rẹ̀,
\q2 ẹ̀ka rẹ̀ dàbí kedari Ọlọ́run.
\q1
\v 11 O yọ ẹ̀ka rẹ̀ sínú Òkun,
\q2 ọwọ́ rẹ̀ sí odò ńlá nì.
\b
\q1
\v 12 Èéṣe tí ìwọ fi wó odi rẹ̀
\q2 tí àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá fi ń ṣa èso rẹ̀?
\q1
\v 13 Ìmàdò láti inú igbó ń bá a jẹ́
\q2 àti ẹranko igbó ń jẹ ẹ́ run.
\q1
\v 14 Yípadà sí wa, àwa ń bẹ̀ ọ́, Ọlọ́run alágbára!
\q2 Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì wò ó!
\q1 Kí o sì bẹ àjàrà yìí wò,
\q1
\v 15 gbòǹgbò èyí tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ti gbìn,
\q2 àti ẹ̀ka tí ìwọ ti mú lágbára fún ara rẹ.
\b
\q1
\v 16 A gé àjàrà rẹ lulẹ̀, a ti fi iná sun ún;
\q2 ní ìfibú, àwọn ènìyàn rẹ̀ ń ṣègbé.
\q1
\v 17 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára ọkùnrin tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,
\q2 ọmọ ènìyàn tí ìwọ tí gbé kalẹ̀ fún ara rẹ.
\q1
\v 18 Nígbà náà àwa kí yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ;
\q2 mú wa yè, àwa o sì máa pe orúkọ rẹ.
\b
\q1
\v 19 Tún wa yípadà, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run alágbára;
\q2 kí ojú rẹ̀ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,
\q2 kí á ba à lè gbà wá là.
\c 81
\cl Saamu 81
\d Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti Asafu.
\q1
\v 1 Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa
\q2 ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jakọbu!
\q1
\v 2 Ẹ mú orin mímọ́, kí ẹ sì mú ìlù wá,
\q2 tẹ dùùrù dídùn pẹ̀lú ohun èlò orin mímọ́.
\b
\q1
\v 3 Ẹ fún ìpè ní oṣù tuntun
\q2 àní nígbà tí a yàn;
\q1 ní ọjọ́ àjọ wa tí ó ní ìrònú.
\q1
\v 4 Èyí ni àṣẹ fún Israẹli,
\q2 àti òfin Ọlọ́run Jakọbu.
\q1
\v 5 Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Josẹfu
\q2 nígbà tí ó la ilẹ̀ Ejibiti já.
\b
\q2 Níbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa.
\b
\q1
\v 6 Ó wí pé, “Mo gbé àjàgà kúrò ní èjìká yín,
\q2 a tú ọwọ́ wọn sílẹ̀ kúrò nínú apẹ̀rẹ̀.
\q1
\v 7 Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là,
\q2 mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá,
\q2 mo dán an yín wò ní odò Meriba. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 8 “Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín,
\q2 bí ìwọ bá fetí sí mi, ìwọ Israẹli.
\q1
\v 9 Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrín yín;
\q2 ẹ̀yin kì yóò foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run àjèjì.
\q1
\v 10 Èmi ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ,
\q2 ẹni tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti.
\q2 Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un.
\b
\q1
\v 11 “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi;
\q2 Israẹli kò ní tẹríba fún mi.
\q1
\v 12 Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn
\q2 láti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn.
\b
\q1
\v 13 “Bí àwọn ènìyàn mi yóò bá gbọ́ tèmi
\q2 bí Israẹli yóò bá tẹ̀lé ọ̀nà mi,
\q1
\v 14 ní kánkán ni èmi yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn
\q2 kí n sì yí ọwọ́ mi padà sí ọ̀tá wọn!
\q1
\v 15 Àwọn tí ó kórìíra \nd Olúwa\nd* yóò tẹríba níwájú rẹ̀.
\q2 Ìjìyà wọn yóò sì pẹ́ títí láé.
\q1
\v 16 Ṣùgbọ́n a ó fi ọkà tí ó dára bọ́ ọ yín
\q2 èmi ó tẹ́ ẹ yín lọ́rùn pẹ̀lú oyin inú àpáta.”
\c 82
\cl Saamu 82
\d Saamu ti Asafu.
\q1
\v 1 Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá,
\q2 ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn “ọlọ́run òrìṣà”.
\b
\q1
\v 2 “Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìṣòdodo
\q2 kí ó sì ṣe ojú ìṣáájú sí àwọn ènìyàn búburú?
\q1
\v 3 Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba;
\q2 ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára.
\q1
\v 4 Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní;
\q2 gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú.
\b
\q1
\v 5 “Wọn kò mọ̀ ohun kankan,
\q2 wọn kò lóye ohun kankan.
\q1 Wọn ń rìn kiri nínú òkùnkùn;
\q2 à si mí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé.
\b
\q1
\v 6 \x - \xo 82.6: \xt Jh 10.34.\x*“Mo wí pé, Ẹyin ní “Ọlọ́run òrìṣà”;
\q2 ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ.
\q1
\v 7 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ó kú bí ènìyàn lásán;
\q2 ẹ̀yin ó ṣubú bí ọ̀kan nínú ọmọ-aládé.”
\b
\q1
\v 8 Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ayé,
\q2 nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè ni ìní rẹ.
\c 83
\cl Saamu 83
\d Orin. Saamu ti Asafu.
\q1
\v 1 Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́;
\q2 má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ẹ́.
\q1
\v 2 Wo bí àwọn ọ̀tá rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ,
\q2 bi àwọn ọ̀tá rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè.
\q1
\v 3 Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ;
\q2 wọn sí dìtẹ̀ mọ́ àwọn tí o fẹ́.
\q1
\v 4 Wọn wí pé, “wá, ẹ jẹ́ kí á pa wọ́n run bí orílẹ̀-èdè,
\q2 kí orúkọ Israẹli ma bá a sí ní ìrántí mọ́.”
\b
\q1
\v 5 Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan;
\q2 wọ́n ṣe àdéhùn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ
\q1
\v 6 Àgọ́ Edomu àti ti àwọn ará Iṣmaeli,
\q2 ti Moabu àti ti Hagari
\q1
\v 7 Gebali, Ammoni àti Amaleki,
\q2 Filistia, pẹ̀lú àwọn ènìyàn Tire.
\q1
\v 8 Asiria pẹ̀lú ti darapọ̀ mọ́ wọn
\q2 láti ran àwọn ọmọ Lọti lọ́wọ́. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 9 Ṣe sí wọn bí ìwọ ti ṣe sí Midiani
\q2 bí o ti ṣe sí Sisera àti Jabini ní odò Kiṣoni,
\q1
\v 10 ẹni tí ó ṣègbé ní Endori
\q2 tí wọn sì dàbí ààtàn ní orí ilẹ̀.
\q1
\v 11 Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí Orebu àti Seebu,
\q2 àwọn ọmọ-aládé wọn bí Seba àti Salmunna,
\q1
\v 12 tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbà ní ìní
\q2 àní pápá oko tútù Ọlọ́run.”
\b
\q1
\v 13 Ìwọ Ọlọ́run, ṣe wọ́n bí ààjà,
\q2 bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.
\q1
\v 14 Bí iná ti í jó igbó,
\q2 àti bí ọ̀wọ́-iná ti ń mú òkè ńlá gbiná,
\q1
\v 15 bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ẹ̀fúùfù líle rẹ lépa wọn
\q2 dẹ́rùbà wọn lójú pẹ̀lú ìjì rẹ.
\q1
\v 16 Fi ìtìjú kún ojú wọn,
\q2 kí àwọn ènìyàn bá à lè ṣe àfẹ́rí orúkọ rẹ àti kí o fi ìjì líle rẹ dẹ́rùbà, ìwọ \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1
\v 17 Jẹ́ kí ojú kí ó tì wọ́n, kí wọ́n sì dààmú láéláé
\q2 kí wọ́n ṣègbé sínú ẹ̀gàn
\q1
\v 18 jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ \nd Olúwa\nd*:
\q2 pé ìwọ nìkan ní Ọ̀gá-ògo jùlọ lórí gbogbo ayé.
\c 84
\cl Saamu 84
\d Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
\q1
\v 1 Ibùgbé rẹ̀ ti lẹ́wà tó,
\q2 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun!
\q1
\v 2 Ọkàn mi ń ṣàfẹ́rí nítòótọ́
\q2 ó tilẹ̀ pòǹgbẹ fún àgbàlá \nd Olúwa\nd*
\q1 àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀
\q2 sí Ọlọ́run alààyè.
\q1
\v 3 Nítòótọ́ ológoṣẹ́ ri ilé,
\q2 ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara rẹ̀,
\q2 níbi tí yóò máa pa ọmọ rẹ̀ mọ́ sí:
\q1 ibùgbé ní tòsí pẹpẹ rẹ̀,
\q2 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.
\q1
\v 4 Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé rẹ;
\q2 wọn ó máa yìn ọ́ títí láé.
\b
\q1
\v 5 Ìbùkún ni fún àwọn tí agbára wọn wà nínú rẹ
\q2 àwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.
\q1
\v 6 Àwọn tí ń la àfonífojì omijé lọ
\q2 wọn sọ ọ́ di kànga
\q2 àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó.
\q1
\v 7 Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipá
\q2 títí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Sioni.
\b
\q1
\v 8 Gbọ́ àdúrà mi, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run Alágbára;
\q2 tẹ́tí sí mi, Ọlọ́run Jakọbu.
\q1
\v 9 Wo asà wa, Ọlọ́run;
\q2 fi ojú àánú wò àwọn ẹni àmì òróró rẹ.
\b
\q1
\v 10 Dídára ní ọjọ́ kan ní ààfin rẹ
\q2 ju ẹgbẹ̀rún (1,000) ọjọ́ lọ;
\q1 èmi o kúkú máa ṣe aṣọ́nà nínú ilé Ọlọ́run mi
\q2 jù láti gbé ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú.
\q1
\v 11 Nítorí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run jẹ́ òòrùn àti asà;
\q2 \nd Olúwa\nd* fún ni ní ojúrere àti ọlá;
\q1 kò sí ohun rere kan tí yóò fàsẹ́yìn
\q2 fún àwọn tí ó rìn ní àìlábùkù.
\b
\q1
\v 12 \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun,
\q2 ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
\c 85
\cl Saamu 85
\d Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
\q1
\v 1 Ìwọ fi ojúrere hàn fún ilé rẹ, \nd Olúwa\nd*;
\q2 ìwọ mú ohun ìní Jakọbu bọ̀ sí ipò.
\q1
\v 2 Ìwọ dárí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn rẹ jì
\q2 ìwọ sì bó ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. \qs Sela.\qs*
\q1
\v 3 Ìwọ fi àwọn ìbínú rẹ sápá kan
\q2 ìwọ sì yípadà kúrò nínú ìbínú gbígbóná rẹ.
\b
\q1
\v 4 Yí wa padà, Ọlọ́run ìgbàlà wa,
\q2 kí o sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ wa.
\q1
\v 5 Ìwọ yóò ha máa bínú sí wa títí láé?
\q2 Ìwọ yóò ha mú ìbínú rẹ pẹ́ yí gbogbo ìran ká?
\q1
\v 6 Ìwọ kì yóò ha sọ wá jí padà mọ́,
\q2 pé kí àwọn ènìyàn rẹ lè yọ nínú rẹ?
\q1
\v 7 Fi ìfẹ́ rẹ tí kò le è kùnà hàn wá, \nd Olúwa\nd*,
\q2 kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ.
\b
\q1
\v 8 Èmi ó gbọ́ ohun tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yóò wí;
\q2 ó ṣèlérí àlàáfíà fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àní ẹni mímọ́ rẹ̀,
\q1 ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn padà sí àìmoye.
\q1
\v 9 Nítòótọ́ ìgbàlà rẹ̀ súnmọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
\q2 pé kí ògo rẹ̀ kí ó lè gbé ní ilẹ̀ wa.
\b
\q1
\v 10 Ìfẹ́ àti òtítọ́ parapọ̀;
\q2 òdodo àti àlàáfíà fẹnu ko ara wọn.
\q1
\v 11 Òtítọ́ ń sun jáde láti ilẹ̀ wá
\q2 òdodo sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run.
\q1
\v 12 \nd Olúwa\nd* yóò fi ohun dídára fún ni nítòótọ́,
\q2 ilẹ̀ wa yóò sì mú ìkórè rẹ̀ jáde.
\q1
\v 13 Òdodo síwájú rẹ lọ
\q2 o sì pèsè ọ̀nà fún ìgbésẹ̀ rẹ̀.
\c 86
\cl Saamu 86
\d Àdúrà ti Dafidi.
\q1
\v 1 Gbọ́, \nd Olúwa\nd*, kí o sì dá mi lóhùn,
\q2 nítorí mo jẹ́ tálákà àti aláìní.
\q1
\v 2 Dáàbò bò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ:
\q2 ìwọ ni Ọlọ́run mi,
\q1 gbà ìránṣẹ́ rẹ là
\q2 tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
\q1
\v 3 Ṣàánú fún mi, \nd Olúwa\nd*,
\q2 nítorí èmi ń pè ọ́ ní gbogbo ọjọ́.
\q1
\v 4 Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ rẹ,
\q2 nítorí ìwọ, \nd Olúwa\nd*,
\q2 ni mo gbé ọkàn mí sókè sí.
\b
\q1
\v 5 Ìwọ ń dáríjì, ìwọ sì dára, \nd Olúwa\nd*,
\q2 ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́.
\q1
\v 6 Gbọ́ àdúrà mi, \nd Olúwa\nd*;
\q2 tẹ́tí sí ẹkún mi fún àánú.
\q1
\v 7 Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi èmi yóò pè ọ́,
\q2 nítorí ìwọ yóò dá mi lóhùn.
\b
\q1
\v 8 Nínú àwọn òrìṣà kò sí ẹni tí ó dàbí i rẹ, \nd Olúwa\nd*:
\q2 kò sí àwọn iṣẹ́ tí a lè fiwé tìrẹ.
\q1
\v 9 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ dá
\q2 yóò wá láti wá jọ́sìn níwájú rẹ, Olúwa;
\q2 wọn ó mú ògo wà fún orúkọ rẹ̀.
\q1
\v 10 Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ sì ń ṣe ohun ìyanu;
\q2 ìwọ nìkan ni Ọlọ́run.
\b
\q1
\v 11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, \nd Olúwa\nd*,
\q2 èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ;
\q1 fún mi ní ọkàn tí kì í yapa,
\q2 kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ.
\q1
\v 12 Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;
\q2 èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé.
\q1
\v 13 Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi;
\q2 ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú.
\b
\q1
\v 14 Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run;
\q2 àti ìjọ àwọn alágbára ń wá
\q1 ọkàn mi kiri,
\q2 wọn kò sì fi ọ́ pè.
\q1
\v 15 Ṣùgbọ́n ìwọ, \nd Olúwa\nd*, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere,
\q2 Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́.
\q1
\v 16 Yípadà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi;
\q2 fún àwọn ènìyàn rẹ ní agbára
\q2 kí o sì gba ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin rẹ là.
\q1
\v 17 Fi àmì hàn mí fún rere,
\q2 kí àwọn tí ó kórìíra mi lè ri,
\q1 kí ojú lè tì wọ́n, nítorí ìwọ \nd Olúwa\nd*
\q2 ni ó ti tù mí nínú.
\c 87
\cl Saamu 87
\d Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Orin.
\q1
\v 1 Ó ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkè mímọ́;
\q1
\v 2 \nd Olúwa\nd* fẹ́ràn ẹnu-ọ̀nà Sioni
\q2 ju gbogbo ibùgbé Jakọbu lọ.
\b
\q1
\v 3 Ohun ológo ni a sọ nípa rẹ̀,
\q2 ìlú Ọlọ́run,
\q1
\v 4 “Èmi ó dárúkọ Rahabu àti Babeli
\q2 láàrín àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi:
\q1 Filistia pẹ̀lú, àti Tire, pẹ̀lú Kuṣi,
\q2 yóò sọ pé, Èyí ni a bí ní Sioni.’ ”
\q1
\v 5 Nítòótọ́, ti Sioni ni a ó sọ,
\q2 “Eléyìí àti eléyìí ni a bí nínú rẹ̀,
\q2 àti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo ni yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀.”
\q1
\v 6 \nd Olúwa\nd* yóò kọ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀:
\q2 “Eléyìí ni a bí ní Sioni.”
\b
\q1
\v 7 Àti àwọn olórin àti àwọn tí ń lu
\q2 ohun èlò orin yóò wí pé,
\q2 “Gbogbo orísun mi ń bẹ nínú rẹ.”
\c 88
\cl Saamu 88
\d Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora. Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti mahalati leannoti. Maskili ti Hemani ará Esra.
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run tí ó gbà mí là,
\q2 ní ọ̀sán àti ní òru, mo kígbe sókè sí Ọ.
\q1
\v 2 Jẹ́ kí àdúrà mi kí ó wá sí iwájú rẹ;
\q2 dẹ etí rẹ sí igbe mi.
\b
\q1
\v 3 Nítorí ọkàn mi kún fún ìpọ́njú
\q2 ọkàn mi sì súnmọ́ isà òkú.
\q1
\v 4 A kà mí mọ́ àwọn tí wọ́n lọ sí ọ̀gbun ilẹ̀
\q2 èmi dàbí ọkùnrin tí kò ni agbára.
\q1
\v 5 A yà mí sọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn òkú
\q2 bí ẹni tí a pa tí ó dùbúlẹ̀ ní ipò ikú,
\q1 ẹni tí ìwọ kò rántí mọ́,
\q2 ẹni tí a gé kúrò lára àwọn tí ìwọ ń tọ́jú.
\b
\q1
\v 6 Ìwọ tí ó fi mí sí kòtò jíjìn,
\q2 ní ibi ọ̀gbun tó ṣókùnkùn.
\q1
\v 7 Ìbínú rẹ ṣubú lé mi gidigidi;
\q2 ìwọ ti fi àwọn ìjì rẹ borí mi.
\q1
\v 8 Ìwọ tí gba ọ̀rẹ́ mi tí ó súnmọ́ mi kúrò lọ́wọ́ mi
\q2 ìwọ sì sọ mi di ìríra sí wọn.
\q1 A há mi mọ́, èmi kò sì le è jáde;
\q1
\v 9 ojú mi káàánú nítorí ìpọ́njú.
\b
\q2 Mo kígbe pè ọ́, \nd Olúwa\nd*, ní gbogbo ọjọ́;
\q1 mo na ọwọ́ mi jáde sí ọ.
\q1
\v 10 Ìwọ ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ hàn fún òkú bi?
\q2 Àwọn òkú yóò ha dìde láti yìn ọ́ bí?
\q1
\v 11 A ó ha fi ìṣeun ìfẹ́ rẹ hàn ní ibojì bí,
\q2 tàbí òtítọ́ rẹ ní ipò ìparun?
\q1
\v 12 A ha lè mọ iṣẹ́ ìyanu rẹ ní òkùnkùn bí
\q2 àti òdodo rẹ ní ilẹ̀ ìgbàgbé?
\b
\q1
\v 13 Ṣùgbọ́n mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, \nd Olúwa\nd*;
\q2 ní òwúrọ̀ ni àdúrà mí wá sọ́dọ̀ rẹ.
\q1
\v 14 \nd Olúwa\nd*, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí
\q2 tí ìwọ fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?
\b
\q1
\v 15 Láti ìgbà èwe mi, ìṣẹ́ ń ṣẹ́ mi,
\q2 èmi múra àti kú;
\q1 nígbà tí ẹ̀rù rẹ bá ń bà mí,
\q2 èmi di gbére-gbère.
\q1
\v 16 Ìbínú rẹ ti kọjá lára mi;
\q2 ìbẹ̀rù rẹ ti gé mi kúrò.
\q1
\v 17 Ní gbogbo ọjọ́ ni wọn yí mi ká bí ìkún omi;
\q2 wọ́n mù mí pátápátá.
\q1
\v 18 Ìwọ ti mú ọ̀rẹ́ àti olùfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi;
\q2 òkùnkùn sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi.
\c 89
\cl Saamu 89
\d Maskili ti Etani ará Esra.
\q1
\v 1 Èmi kọrin títóbi ìfẹ́ \nd Olúwa\nd* títí láé;
\q2 pẹ̀lú ẹnu mi ní èmi yóò jẹ́ kí a mọ òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran.
\q1
\v 2 Èmi ó wí pé, ìfẹ́ rẹ dúró títí láé,
\q2 pé ìwọ gbe òtítọ́ rẹ kalẹ̀ ní ọ̀run fúnra rẹ̀.
\q1
\v 3 \x - \xo 89.3-4: \xt Sm 132.11; Ap 2.30.\x*Ìwọ wí pé, “Èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ mi
\q2 mo ti búra fún Dafidi ìránṣẹ́ mi.
\q1
\v 4 Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ múlẹ̀ títí láé
\q2 èmí ó sì máa gbe ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ”
\b
\q1
\v 5 Àwọn ọ̀run yóò máa yin iṣẹ́ ìyanu rẹ, \nd Olúwa\nd*,
\q2 òtítọ́ rẹ ni ìpéjọpọ̀ àwọn ẹni mímọ́.
\q1
\v 6 Ta ni ó wà ní ọ̀run tí a lè fiwé \nd Olúwa\nd*?
\q2 Ta ni nínú àwọn ọmọ alágbára ti a lè fiwé \nd Olúwa\nd*?
\q1
\v 7 Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi;
\q2 ó sì ní ìbùyìn fún ju gbogbo àwọn tí ó yí i ká.
\q1
\v 8 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run alágbára, ta ló dàbí rẹ
\q2 ìwọ jẹ́ alágbára, \nd Olúwa\nd*, òtítọ́ rẹ sì yí ọ ká.
\b
\q1
\v 9 Ìwọ ń darí ríru omi Òkun;
\q2 nígbà tí ó ru àwọn omi sókè, ìwọ mú wọn parọ́rọ́.
\q1
\v 10 Ìwọ ni ó ti ya Rahabu pẹ́rẹpẹ̀rẹ
\q2 bí ẹni tí a pa;
\q1 ìwọ ti fi apá ọwọ́ agbára rẹ
\q2 tú àwọn ọ̀tá rẹ ká.
\q1
\v 11 Tìrẹ ní àwọn ọ̀run, ayé pẹ̀lú jẹ́ tìrẹ:
\q2 ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀:
\q1 ìwọ ti gbé wọn kalẹ̀.
\q1
\v 12 Gúúsù àti àríwá ìwọ ni ó dá wọn;
\q2 Tabori àti Hermoni ń fi ayọ̀ yin orúkọ rẹ.
\q1
\v 13 Ìwọ ní apá agbára;
\q2 agbára ní ọwọ́ rẹ, gíga ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
\b
\q1
\v 14 Òdodo àti òtítọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ:
\q2 ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ àti òtítọ́ ń lọ síwájú rẹ.
\q1
\v 15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ ohùn ayọ̀ nì,
\q2 \nd Olúwa\nd* wọ́n ó máa rìn ní ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ.
\q1
\v 16 Wọn ń ṣògo nínú orúkọ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́,
\q2 wọn ń yin òdodo rẹ.
\q1
\v 17 Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn;
\q2 nípa ojúrere ni ìwo wá ń ṣògo.
\q1
\v 18 Nítorí ti \nd Olúwa\nd* ni asà wa,
\q2 ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.
\b
\q1
\v 19 Nígbà náà ni ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran, sí àwọn olóòtítọ́ rẹ, wí pé,
\q2 “Èmi ti gbé adé kalẹ̀ sórí ẹni tí ó lágbára,
\q2 èmi ti gbé ẹni tí a yàn láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ga.
\q1
\v 20 \x - \xo 89.20: \xt Ap 13.22.\x*Èmi ti rí Dafidi ìránṣẹ́ mi;
\q2 pẹ̀lú òróró mímọ́ mi ni mo fi yàn án.
\q1
\v 21 Ìgbà gbogbo ni ọwọ́ mi yóò máa wà pẹ̀lú rẹ̀
\q2 apá mí yóò sì fi agbára fún un.
\q1
\v 22 Àwọn ọ̀tá kì yóò borí rẹ̀,
\q2 àwọn ènìyàn búburú kì yóò rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀.
\q1
\v 23 Èmi yóò run àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ
\q2 èmi yóò lu àwọn tí ó kórìíra rẹ bolẹ̀.
\q1
\v 24 Òtítọ́ mi àti ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ yóò wà pẹ̀lú rẹ
\q2 àti ní orúkọ mi ni a ó gbé ìwo rẹ ga.
\q1
\v 25 Èmi ó gbé ọwọ́ rẹ lórí òkun,
\q2 àti ọwọ́ ọ̀tún rẹ lórí àwọn odo ńlá.
\q1
\v 26 Òun yóò kígbe sí mi pé, Ìwọ ni baba mi, Ọlọ́run mi, àti àpáta ìgbàlà mi!
\q1
\v 27 \x - \xo 89.27: \xt If 1.5.\x*Èmi yóò ṣe é ni àkọ́bí mi,
\q2 ẹni gíga ju àwọn ọba ayé.
\q1
\v 28 Títí láé ni èmi yóò pa ìfẹ́ dídúró ṣinṣin mọ́ fún un,
\q2 àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ̀ yóò dúró gbọingbọin.
\q1
\v 29 Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ̀ múlẹ̀ títí láé,
\q2 àti ìtẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti wà láé.
\b
\q1
\v 30 “Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀
\q2 tí wọn kò sì rìn gẹ́gẹ́ bí ìlànà mi.
\q1
\v 31 Tí wọn bá ba ìlànà mi jẹ́
\q2 tí wọn kò sì pa àṣẹ mi mọ́,
\q1
\v 32 nígbà náà ni èmi ó fì ọ̀gọ̀ bẹ ìrékọjá wọn wò;
\q2 àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú pàṣán;
\q1
\v 33 ṣùgbọ́n èmi kò ní mú ìfẹ́ mi tí ó dúró ṣinṣin kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò jẹ́ kí òtítọ́ mi kí ó yẹ̀.
\q1
\v 34 Èmi kì yóò sẹ́ májẹ̀mú mi,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu mi jáde padà.
\q1
\v 35 Lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ni èmi ti fi ìwà mímọ́ mi búra;
\q1 èmi kì yóò purọ́ fún Dafidi.
\q1
\v 36 Irú-ọmọ rẹ yóò dúró títí láé,
\q2 àti ìtẹ́ rẹ̀ yóò dúró bí oòrùn níwájú mi.
\q1
\v 37 \x - \xo 89.37: \xt If 1.5; 3.14.\x*A ó fi múlẹ̀ títí láé bí òṣùpá,
\q2 àti bi ẹlẹ́rìí òtítọ́ ni ọ̀run.” \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 38 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ti ṣá tì, ìwọ sì kórìíra;
\q2 ìwọ kún fún ìrunú sí ẹni àmì òróró rẹ.
\q1
\v 39 Ìwọ ti sọ májẹ̀mú ìránṣẹ́ rẹ di òfo;
\q2 ìwọ tàbùkù adé rẹ nínú eruku.
\q1
\v 40 Ìwọ ti wó gbogbo àwọn odi rẹ̀
\q2 ìwọ sọ ibi gíga rẹ̀ di ahoro.
\q1
\v 41 Àwọn tí ń kọjá lọ fi ṣe ìjẹ;
\q2 ó ti di ẹ̀gàn àwọn olùbágbé rẹ̀.
\q1
\v 42 Ìwọ ti gbé ọwọ́ ọ̀tún ọ̀tá rẹ̀ sókè;
\q2 ìwọ mú gbogbo ọ̀tá rẹ̀ yọ̀.
\q1
\v 43 Pẹ̀lú, ìwọ ti yí ojú idà rẹ̀ padà,
\q2 ìwọ kò sì dúró tì í nínú ogun.
\q1
\v 44 Ìwọ ti mú ògo rẹ̀ kùnà,
\q2 ìwọ si wó ìtẹ́ rẹ̀ palẹ̀ sílẹ̀ẹ́lẹ̀.
\q1
\v 45 Ìwọ ti gé ọjọ́ èwe rẹ̀ kúrú;
\q2 ìwọ sì fi ìtìjú bò ó.
\b
\q1
\v 46 Yóò ti pẹ́ tó, \nd Olúwa\nd*?
\q2 Tí ìwọ ó ha fi ara rẹ pamọ́ títí láé?
\q2 Yóò ti pẹ́ to tí ìbínú rẹ yóò máa jó bí iná?
\q1
\v 47 Rántí bí ọjọ́ mi ti kúrú tó
\q2 nítorí asán ha ni ìwọ fi ṣẹ̀dá àwọn ènìyàn!
\q1
\v 48 Ta ni yóò wà láààyè tí kò ní rí ikú rẹ̀?
\q2 Ta ló lè sá kúrò nínú agbára isà òkú?
\q1
\v 49 \nd Olúwa\nd*, níbo ni ìṣeun ìfẹ́ rẹ àtijọ́ wà,
\q2 tí ìwọ ti fi òtítọ́ rẹ búra fún Dafidi?
\q1
\v 50 Rántí, \nd Olúwa\nd*, bí a ti ń gan àwọn ìránṣẹ́ rẹ;
\q2 bí èmi ti gbà ní àyà mi láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn,
\q1
\v 51 ẹ̀gàn tí àwọn ọ̀tá rẹ gàn, \nd Olúwa\nd*,
\q2 tí wọn gan ipasẹ̀ ẹni àmì òróró rẹ.
\b
\b
\q1
\v 52 Olùbùkún ní \nd Olúwa\nd* títí láé.
\qc Àmín àti Àmín.
\c 90
\ms ÌWÉ KẸRIN
\mr Saamu 90106
\cl Saamu 90
\d Àdúrà Mose ènìyàn Ọlọ́run.
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd*, ìwọ ti jẹ́ ibùgbé wa ní gbogbo ìran dé ìran.
\q1
\v 2 Kí a tó bí àwọn òkè ńlá
\q2 àti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé,
\q1 láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run.
\b
\q1
\v 3 Ìwọ yí ènìyàn padà sí erùpẹ̀,
\q2 wí pé, “Padà sí erùpẹ̀, ìwọ ọmọ ènìyàn.”
\q1
\v 4 \x - \xo 90.4: \xt 2Pt 3.8.\x*Nítorí pé ìgbà tí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún bá kọjá lójú rẹ,
\q2 bí àná ni ó rí, bí ìgbà ìṣọ́ kan lóru.
\q1
\v 5 Ìwọ gbá ènìyàn dànù nínú oorun ikú;
\q2 wọ́n dàbí koríko tuntun ní òwúrọ̀.
\q1
\v 6 Lóòtítọ́, ní òwúrọ̀, ó yọ tuntun
\q2 ní àṣálẹ́ ni yóò gbẹ, tí yóò sì rẹ̀ dànù.
\b
\q1
\v 7 A pa wá run nípa ìbínú rẹ
\q2 nípa ìbínú rẹ ara kò rọ̀ wá.
\q1
\v 8 Ìwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ka iwájú rẹ,
\q2 àti ohun ìkọ̀kọ̀ wa nínú ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ.
\q1
\v 9 Gbogbo ọjọ́ wa ń kọjá lọ lábẹ́ ìbínú rẹ;
\q2 àwa ń lo ọjọ́ wa lọ bí àlá tí à ń rọ́.
\q1
\v 10 Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún wá,
\q2 bi ó sì ṣe pé nípa agbára
\q1 tí wọn bá tó ọgọ́rin ọdún,
\q2 agbára nínú làálàá pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni,
\q1 nítorí pé a kò ní pẹ́ gé e kúrò,
\q2 àwa a sì fò lọ.
\q1
\v 11 Ta ni ó mọ agbára ìbínú rẹ?
\q2 Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ.
\q1
\v 12 Kọ́ wa bí a ti ń kaye ọjọ́ wa dáradára,
\q2 kí àwa ba à lè fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n.
\b
\q1
\v 13 Yípadà, \nd Olúwa\nd*! Yóò ti pẹ́ tó?
\q2 Ṣàánú fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ.
\q1
\v 14 Tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀ nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ,
\q2 kí àwa kí ó lè kọrin fún ayọ̀
\q2 kí inú wa sì dùn ní gbogbo ọjọ́.
\q1
\v 15 Mú inú wa dùn bí ọjọ́ tí ìwọ ti pọ́n wa lójú,
\q2 fún ọjọ́ púpọ̀ tí àwa ti rí wàhálà.
\q1
\v 16 Jẹ́ kí a fi iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀,
\q2 ògo rẹ̀ sí àwọn ọmọ wọn.
\b
\q1
\v 17 Jẹ́ kí ẹwà Olúwa Ọlọ́run wa wà lára wa;
\q2 fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ lára wa,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni, kí ó sì fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀.
\c 91
\cl Saamu 91
\q1
\v 1 Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo
\q2 ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè.
\q1
\v 2 Èmi yóò sọ nípa ti \nd Olúwa\nd* pé,
\q2 “Òun ni ààbò àti odi mi,
\q2 Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”.
\b
\q1
\v 3 Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú
\q2 ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ
\q2 àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú.
\q1
\v 4 Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí,
\q2 àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò;
\q2 òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.
\q1
\v 5 Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru,
\q2 tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,
\q1
\v 6 tàbí fún àjàkálẹ̀-ààrùn tí ń rìn kiri ní òkùnkùn,
\q2 tàbí fún ìparun tí ń rìn kiri ní ọ̀sán gangan.
\q1
\v 7 Ẹgbẹ̀rún (1,000) yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,
\q2 ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,
\q2 ṣùgbọ́n kì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.
\q1
\v 8 Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú rẹ
\q2 àti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú.
\b
\q1
\v 9 Nítorí ìwọ fi \nd Olúwa\nd* ṣe ààbò rẹ,
\q2 ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ.
\q1
\v 10 Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́,
\q2 Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ.
\q1
\v 11 \x - \xo 91.11-12: \xt Mt 4.6; Lk 4.10-11.\x*Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn angẹli nípa tìrẹ
\q2 láti pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ;
\q1
\v 12 wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn,
\q2 nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gún òkúta.
\q1
\v 13 \x - \xo 91.13: \xt Lk 10.19.\x*Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀;
\q2 ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò ńlá ni ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.
\b
\q1
\v 14 “Nítorí ti ìfẹ́ rẹ sí mi, èmi yóò gbà ọ́;
\q2 èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi.
\q1
\v 15 Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn;
\q2 èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìpọ́njú,
\q2 èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un.
\q1
\v 16 Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn,
\q2 èmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.”
\c 92
\cl Saamu 92
\d Saamu. Orin. Fún Ọjọ́ Ìsinmi.
\q1
\v 1 Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún \nd Olúwa\nd*
\q2 àti láti máa kọrin sí orúkọ rẹ̀, Ọ̀gá-ògo,
\q1
\v 2 láti kéde ìfẹ́ rẹ̀ ní òwúrọ̀
\q2 àti òtítọ́ rẹ̀ ní alẹ́,
\q1
\v 3 lára ohùn èlò orin olókùn mẹ́wàá
\q2 àti lára ohun èlò orin haapu.
\b
\q1
\v 4 Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùn
\q2 nípa iṣẹ́ rẹ \nd Olúwa\nd*;
\q1 èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
\q1
\v 5 Báwo ni iṣẹ́ rẹ tí tóbi tó, \nd Olúwa\nd*?
\q2 Èrò inú rẹ ìjìnlẹ̀ ni!
\q1
\v 6 Òpè ènìyàn kò mọ̀ ọ́n,
\q2 aṣiwèrè kò sì mọ̀ ọ́n,
\q1
\v 7 nígbà tí àwọn ènìyàn búburú bá rú jáde bí i koríko
\q2 àti gbogbo àwọn olùṣe búburú gbèrú,
\q2 wọn yóò run láéláé.
\b
\q1
\v 8 Ṣùgbọ́n ìwọ \nd Olúwa\nd* ni a ó gbéga títí láé.
\b
\q1
\v 9 Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ,
\q1 \nd Olúwa\nd*,
\q2 nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ yóò ṣègbé;
\q1 gbogbo àwọn olùṣe búburú
\q2 ni a ó fọ́nká.
\q1
\v 10 Ìwọ ti gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó;
\q2 òróró dídára ni a dà sí mi ní orí.
\q1
\v 11 Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi;
\q2 ìparun sí àwọn ènìyàn búburú
\q2 tí ó dìde sí mi.
\b
\q1
\v 12 Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ,
\q2 wọn yóò dàgbà bí i igi kedari Lebanoni,
\q1
\v 13 tí a gbìn sí ilé \nd Olúwa\nd*,
\q2 Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.
\q1
\v 14 Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbó,
\q2 wọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini,
\q1
\v 15 láti fihàn pé, “Ẹni ìdúró ṣinṣin ni \nd Olúwa\nd*;
\q2 òun ni àpáta mi, kò sì ṣí aburú
\q2 kankan nínú rẹ̀.”
\c 93
\cl Saamu 93
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd* ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ;
\q2 ọláńlá ni \nd Olúwa\nd* wọ̀ ní aṣọ
\q2 àti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára.
\q1 Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;
\q2 kò sì le è yí.
\q1
\v 2 Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́;
\q2 ìwọ wà títí ayérayé.
\b
\q1
\v 3 A ti gbé òkun sókè, \nd Olúwa\nd*,
\q2 òkun ti gbé ohùn wọn sókè;
\q2 òkun ti gbé rírú omi wọn sókè.
\q1
\v 4 Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ,
\q2 ó ni ògo ju òkun rírú lọ
\q2 \nd Olúwa\nd* ga ní ògo.
\b
\q1
\v 5 Ẹ̀rí rẹ̀ dúró ṣinṣin;
\q2 ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́
\q2 fún ọjọ́ àìlópin, \nd Olúwa\nd*.
\c 94
\cl Saamu 94
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san,
\q2 Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san.
\q1
\v 2 Gbé ara rẹ sókè, ìwọ onídàájọ́ ayé;
\q2 san ẹ̀san fún agbéraga
\q2 ohun tí ó yẹ wọ́n.
\q1
\v 3 Báwo ní yóò ti pẹ́ tó,
\q2 \nd Olúwa\nd*
\q1 tí àwọn ẹni búburú
\q2 yóò kọ orin ayọ̀?
\b
\q1
\v 4 Wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga jáde;
\q2 gbogbo àwọn olùṣe búburú
\q1 kún fún ìṣògo.
\q1
\v 5 Wọ́n fọ́ àwọn ènìyàn rẹ túútúú, \nd Olúwa\nd*:
\q2 wọ́n pọ́n ilẹ̀ ìní rẹ̀ lójú.
\q1
\v 6 Wọ́n pa àwọn opó àti àlejò,
\q2 wọ́n sì pa àwọn ọmọ aláìní baba.
\q1
\v 7 Wọ́n sọ pé, “\nd Olúwa\nd* kò rí i;
\q2 Ọlọ́run Jakọbu kò sì kíyèsi i.”
\b
\q1
\v 8 Kíyèsi i, ẹ̀yin aláìlóye nínú àwọn ènìyàn;
\q2 ẹ̀yin aṣiwèrè, nígbà wo ni ẹ̀yin yóò lóye?
\q1
\v 9 Ẹni tí ó gbin etí, ó lè ṣe aláìgbọ́ bí?
\q2 Ẹni tí ó dá ojú?
\q1 Ó ha lè ṣe aláìríran bí?
\q1
\v 10 Ẹni tí ń bá orílẹ̀-èdè wí, ṣé kò lè tọ́ ni ṣọ́nà bí?
\q2 Ẹni tí ń kọ́ ènìyàn ha lè ṣàìní ìmọ̀ bí?
\q1
\v 11 \x - \xo 94.11: \xt 1Kọ 3.20.\x*\nd Olúwa\nd* mọ èrò inú ènìyàn;
\q2 ó mọ̀ pé asán ni wọ́n.
\b
\q1
\v 12 Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí
\q2 ìwọ bá wí, \nd Olúwa\nd*,
\q1 ẹni tí ìwọ kọ́ nínú òfin rẹ,
\q1
\v 13 Ìwọ gbà á kúrò nínú ọjọ́ ibi,
\q2 títí a ó fi wa ihò sílẹ̀ fún ẹni búburú.
\q1
\v 14 Nítorí \nd Olúwa\nd* kò ní kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀,
\q1 Òun kò sì ní kọ ilẹ̀ ìní rẹ̀ sílẹ̀.
\q1
\v 15 Ìdájọ́ yóò padà sí òdodo,
\q2 àti gbogbo àwọn ọlọ́kàn
\q2 dídúró ṣinṣin yóò tẹ̀lé e lẹ́yìn.
\b
\q1
\v 16 Ta ni yóò dìde fún mi
\q2 sí àwọn olùṣe búburú?
\q2 Tàbí ta ni yóò dìde sí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún mi?
\q1
\v 17 Bí kò ṣe pé \nd Olúwa\nd* fún mi ní ìrànlọ́wọ́,
\q2 èmi fẹ́rẹ̀ máa gbé ní ilẹ̀ tí ó dákẹ́.
\q1
\v 18 Nígbà tí mo sọ pé, “Ẹsẹ̀ mi ń yọ̀”,
\q2 \nd Olúwa\nd*, ìfẹ́ rẹ̀ ni ó tì mí lẹ́yìn.
\q1
\v 19 Nígbà tí àníyàn ńlá wà nínú mi,
\q2 ìtùnú rẹ̀ mú ayọ̀ sí ọkàn mi.
\b
\q1
\v 20 Ìjọba ìbàjẹ́ ha lè kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú rẹ
\q2 ẹni tí ń fi òfin dì mọ́ ìwà ìkà?
\q1
\v 21 Wọ́n kó ara wọn jọ sí olódodo
\q2 wọ́n sì ń dá àwọn aláìṣẹ̀ lẹ́bi sí ikú.
\q1
\v 22 Ṣùgbọ́n, \nd Olúwa\nd* ti di odi alágbára mi,
\q2 àti Ọlọ́run mi ni àpáta nínú ẹni
\q2 tí mo ti ń gba ààbò.
\q1
\v 23 Òun yóò san ẹ̀san ibi wọn fún wọn
\q2 yóò sì pa wọ́n run nítorí búburú wọn
\q2 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa yóò pa wọ́n run.
\c 95
\cl Saamu 95
\q1
\v 1 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a kọ orin ayọ̀ sí \nd Olúwa\nd*,
\q2 ẹ jẹ́ kí a kígbe sókè sí àpáta ìgbàlà wa.
\q1
\v 2 Ẹ jẹ́ kí a wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
\q2 kí a sì pòkìkí rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò
\q2 orin àti ìyìn.
\b
\q1
\v 3 Nítorí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run títóbi ni,
\q2 ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.
\q1
\v 4 Ní ọwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà,
\q2 ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe.
\q1
\v 5 Tirẹ̀ ni Òkun, nítorí òun ni ó dá a
\q2 àti ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.
\b
\q1
\v 6 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a foríbalẹ̀ kí a sìn ín,
\q2 ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú
\q1 \nd Olúwa\nd* ẹni tí ó dá wa,
\q1
\v 7 \x - \xo 95.7-11: \xt Hb 3.7-11; 4.3-11.\x*nítorí òun ni Ọlọ́run wa,
\q2 àwa sì ni ènìyàn pápá rẹ̀,
\q1 àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ rẹ̀.
\b
\q2 Lónìí tí ìwọ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
\q1
\v 8 “Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Meriba,
\q2 àti bí ẹ ti ṣe ní ọjọ́ náà ní Massa ní aginjù,
\q1
\v 9 nígbà tí àwọn baba yín dán mi wò
\q2 tí wọn wádìí mi,
\q1 tí wọn sì rí iṣẹ́ mi.
\q1
\v 10 Fún ogójì ọdún ni èmi fi bínú sí ìran náà;
\q2 mo wí pé, Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ọkàn wọn ṣáko lọ
\q2 wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.
\q1
\v 11 Nítorí náà ni mo kéde ìbúra nínú ìbínú mi,
\q2 Wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi.’ ”
\c 96
\cl Saamu 96
\q1
\v 1 \x - \xo 96.1-13: \xt 1Ki 16.23-33.\x*Ẹ kọrin tuntun sí \nd Olúwa\nd*,
\q2 ẹ kọrin sí \nd Olúwa\nd* gbogbo ayé.
\q1
\v 2 Ẹ kọrin sí \nd Olúwa\nd*, yin orúkọ rẹ̀
\q2 ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́.
\q1
\v 3 Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
\q2 àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn.
\b
\q1
\v 4 Nítorí títóbi ní \nd Olúwa\nd* ẹni tí ìyìn tọ́ sí;
\q2 òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ.
\q1
\v 5 Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè
\q2 ṣùgbọ́n \nd Olúwa\nd* dá àwọn ọ̀run.
\q1
\v 6 Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀
\q2 agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀.
\b
\q1
\v 7 Ẹ fi fún \nd Olúwa\nd*, ẹ̀yin ìbátan ènìyàn,
\q2 ẹ fi agbára àti ògo fún \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 8 Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí \nd Olúwa\nd* fún un;
\q2 ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀.
\q1
\v 9 Ẹ máa sin \nd Olúwa\nd* nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀;
\q2 ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé.
\q1
\v 10 Sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, “\nd Olúwa\nd* jẹ ọba.”
\q2 A fi ìdí ayé múlẹ̀, tí kò sì lè yí;
\q2 ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn.
\b
\q1
\v 11 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì pariwo
\q2 jẹ́ kí pápá òkun kí ó hó pẹ̀lú ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀.
\q1
\v 12 Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀;
\q1 nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀.
\q2
\v 13 Wọn yóò kọrin níwájú \nd Olúwa\nd*,
\q2 nítorí tí ó ń bọ̀ wá, ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé.
\q1 Yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé
\q2 àti ti àwọn ènìyàn ni yóò fi òtítọ́ rẹ̀ ṣe.
\c 97
\cl Saamu 97
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd* jẹ ọba, jẹ́ kí ayé kí ó yọ̀
\q2 jẹ́ kí inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù kí ó dùn.
\q1
\v 2 Ojú ọ̀run àti òkùnkùn yíká
\q2 òdodo àti ìdájọ́ ni ó ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.
\q1
\v 3 Iná ń jó níwájú rẹ̀. Ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ yíkákiri.
\q1
\v 4 Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn ó sì kárí ayé
\q2 ayé rí i ó sì wárìrì.
\q1
\v 5 Òkè gíga yọ́ gẹ́gẹ́ bí ìda níwájú \nd Olúwa\nd*,
\q2 níwájú Olúwa gbogbo ayé.
\q1
\v 6 Àwọn ọ̀run ròyìn òdodo rẹ̀, gbogbo ènìyàn sì rí ògo rẹ̀.
\b
\q1
\v 7 \x - \xo 97.7: \xt Hb 1.6.\x*Gbogbo àwọn tí ń sin ère fínfín ni ojú yóò tì,
\q2 àwọn tí ń fi ère gbéraga,
\q2 ẹ máa sìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́run!
\b
\q1
\v 8 Sioni gbọ́, inú rẹ̀ sì dùn
\q2 inú àwọn ilé Juda sì dùn,
\q2 nítorí ìdájọ́ rẹ, \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 9 Nítorí pé ìwọ, \nd Olúwa\nd*, ni ó ga ju gbogbo ayé lọ
\q2 ìwọ ni ó ga ju gbogbo òrìṣà lọ.
\q1
\v 10 Jẹ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́
\q2 \nd Olúwa\nd*, kórìíra ibi, ó pa ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́
\q2 ó gbà wọ́n ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú.
\q1
\v 11 Ìmọ́lẹ̀ tàn sórí àwọn olódodo
\q2 àti ayọ̀ nínú àlàyé ọkàn.
\q1
\v 12 Ẹ yọ̀ nínú \nd Olúwa\nd*, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olódodo,
\q2 kí ẹ sì yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.
\c 98
\cl Saamu 98
\q1
\v 1 Ẹ kọrin tuntun sí \nd Olúwa\nd*,
\q2 nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu;
\q1 ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti apá mímọ́ rẹ̀
\q2 o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un
\q1
\v 2 \nd Olúwa\nd* ti sọ ìgbàlà rẹ̀ di mí mọ̀
\q2 o fi òdodo rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè.
\q1
\v 3 Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ fún àwọn ará ilé Israẹli;
\q2 gbogbo òpin ayé ni ó ti rí
\q2 iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa.
\b
\q1
\v 4 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí \nd Olúwa\nd*, gbogbo ayé,
\q2 ẹ bú sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn,
\q1
\v 5 ẹ fi dùùrù kọrin sí \nd Olúwa\nd*, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́,
\q1
\v 6 pẹ̀lú ìpè àti fèrè
\q2 ẹ hó fún ayọ̀ níwájú \nd Olúwa\nd* ọba.
\b
\q1
\v 7 Jẹ́ kí òkun kí ó hó pẹ̀lú gbogbo
\q2 ohun tí ó wà nínú rẹ̀,
\q1 Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
\q1
\v 8 Ẹ jẹ́ kí odo kí ó ṣápẹ́,
\q2 ẹ jẹ́ kí òkè kí ó kọrin pẹ̀lú ayọ̀;
\q1
\v 9 ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú \nd Olúwa\nd*,
\q2 nítorí tí yóò wá ṣèdájọ́ ayé
\q1 bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodo
\q2 àti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú.
\c 99
\cl Saamu 99
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd* jẹ ọba;
\q2 jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì
\q1 Ó jókòó lórí ìtẹ́ kérúbù
\q2 jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì.
\q1
\v 2 \nd Olúwa\nd* tóbi ní Sioni;
\q2 Ó sì ga jù gbogbo orílẹ̀-èdè lọ.
\q1
\v 3 Kí wọ́n sì yin orúkọ rẹ̀ tí ó tóbi
\q2 tí ó ni ẹ̀rù, Mímọ́ ni Òun.
\b
\q1
\v 4 Ọba náà ní agbára, ó sì fẹ́ òdodo,
\q2 ìwọ fi ìdí àìṣègbè múlẹ̀;
\q2 ìwọ ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí ó yẹ nínú Jakọbu.
\q1
\v 5 Gbígbéga ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa
\q2 ẹ foríbalẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀; ó jẹ́ mímọ́.
\b
\q1
\v 6 Mose àti Aaroni wà nínú àwọn àlùfáà rẹ̀
\q2 Samuẹli wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ rẹ̀
\q2 wọ́n ké pe \nd Olúwa\nd*, ó sì dá wọn lóhùn.
\q1
\v 7 Ó sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀,
\q2 wọ́n pa ẹ̀rí rẹ̀ mọ́ àti ìlànà tí ó fún wọn.
\b
\q1
\v 8 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa, ó dá wọn lóhùn;
\q2 ó jẹ́ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì àwọn ọmọ Israẹli
\q2 ìwọ tí ó ń fi ìyà àìṣedéédéé wọn jẹ wọ́n.
\q1
\v 9 Gbígbéga ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa
\q2 kí a sìn ín ní òkè mímọ́ rẹ̀
\q2 nítorí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́.
\c 100
\cl Saamu 100
\d Saamu. Fún ọpẹ́.
\q1
\v 1 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí \nd Olúwa\nd*, gbogbo ayé.
\q1
\v 2 Ẹ fi ayọ̀ sin \nd Olúwa\nd*,
\q2 ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn
\q1
\v 3 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run ni ó dá wa,
\q2 kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé
\q1 tirẹ̀ ni àwa, àwa ní ènìyàn rẹ̀
\q2 àti àgùntàn pápá rẹ̀.
\b
\q1
\v 4 Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
\q2 àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn;
\q2 ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.
\q1
\v 5 Nítorí tí \nd Olúwa\nd* pọ̀ ní oore
\q2 ìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé;
\q2 àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.
\c 101
\cl Saamu 101
\d Ti Dafidi. Saamu.
\q1
\v 1 Èmi yóò kọrin ìfẹ́ àti òdodo;
\q2 sí ọ \nd Olúwa\nd*, èmi yóò máa kọrin ìyìn.
\q1
\v 2 Èmi yóò máa rin ìrìn mi pẹ̀lú ọgbọ́n láìlẹ́ṣẹ̀,
\q2 ìgbà wo ni ìwọ yóò wá sí ọ̀dọ̀ mi?
\b
\q1 Èmi yóò máa rìn ní ilé mi
\q2 pẹ̀lú àyà pípé.
\q1
\v 3 Èmi kì yóò gbé ohun búburú sí iwájú mi:
\q2 iṣẹ́ àwọn tí ó yapa ni èmi kórìíra.
\b
\q2 Wọn kì yóò rọ̀ mọ́ mi.
\q1
\v 4 Agídí ọkàn yóò kúrò lọ́dọ̀ mi;
\q2 èmi kì yóò mọ ènìyàn búburú.
\b
\q1
\v 5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀,
\q2 òun ní èmi yóò gé kúrò
\q1 ẹni tí ó bá gbé ojú rẹ̀ ga tí ó sì ní ìgbéraga àyà,
\q2 òun ní èmi kì yóò faradà fún.
\b
\q1
\v 6 Ojú mi yóò wà lára àwọn olóòtítọ́ lórí ilẹ̀,
\q2 kí wọn kí ó lè máa bá mi gbé;
\q1 ẹni tí ó bá n rin ọ̀nà pípé
\q2 òun ni yóò máa sìn mí.
\b
\q1
\v 7 Ẹni tí ó bá ń ṣe ẹ̀tàn, kì yóò gbé ilé mi,
\q2 kò sí ẹni tí ń ṣèké tí yóò dúró ní iwájú mi.
\b
\q1
\v 8 Ní ojoojúmọ́ ní èmi yóò wá máa pa a lẹ́nu mọ
\q2 gbogbo àwọn ènìyàn búburú ilẹ̀ náà;
\q1 èmi yóò gé àwọn olùṣe búburú
\q2 kúrò ní ìlú \nd Olúwa\nd*.
\c 102
\cl Saamu 102
\d Àdúrà olùpọ́njú tí àárẹ̀ mú, tí ó sí ọkàn rẹ̀ payá níwájú \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 1 Gbọ́ àdúrà mi, \nd Olúwa\nd*,
\q2 jẹ́ kí igbe ẹ̀bẹ̀ mi kí ó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ.
\q1
\v 2 Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi
\q2 ní ọjọ́ tí èmi wà nínú ìpọ́njú.
\q1 Dẹ etí rẹ sí mi;
\q2 nígbà tí mo bá pè, dá mi lóhùn kíákíá.
\b
\q1
\v 3 Nítorí tí ọjọ́ mi run bí èéfín;
\q2 egungun mi sì jóná bí ààrò.
\q1
\v 4 Àyà mi lù, ó sì rọ bí i koríko;
\q2 mo gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi.
\q1
\v 5 Nítorí ohùn ìkérora mi,
\q2 egungun mi lẹ̀ mọ́ ẹran-ara mi.
\q1
\v 6 Èmi dàbí ẹyẹ igún ní ijù:
\q2 èmi dàbí òwìwí ibi ahoro.
\q1
\v 7 Èmi dìde; èmi dàbí ẹyẹ lórí ilé.
\q1
\v 8 Ní ọjọ́ gbogbo, àwọn ọ̀tá ológoṣẹ́ mi ń gàn mí;
\q2 àwọn tí ń ṣe ìkanra sí mi ń fi orúkọ mi bú.
\q1
\v 9 Èmi jẹ eérú gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ mi, èmi sì da ohun mímu mi pọ̀ pẹ̀lú omijé.
\q1
\v 10 Nítorí ìbínú ríru rẹ, nítorí ìwọ ti gbé mi sókè, ìwọ sì gbé mi ṣánlẹ̀.
\q1
\v 11 Ọjọ́ mi dàbí òjìji àṣálẹ́
\q2 èmi sì rọ bí koríko.
\b
\q1
\v 12 Ṣùgbọ́n ìwọ, \nd Olúwa\nd*, ni yóò dúró láéláé;
\q2 ìrántí rẹ láti ìran dé ìran.
\q1
\v 13 Ìwọ ó dìde ìwọ ó sì ṣàánú fún Sioni,
\q2 nítorí ìgbà àti ṣe ojúrere sí i;
\q2 àkókò náà ti dé.
\q1
\v 14 Nítorí tí àwọn òkúta jẹ́ inú dídùn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ;
\q2 wọ́n sì káàánú erùpẹ̀ rẹ.
\q1
\v 15 Àwọn kèfèrí yóò bẹ̀rù orúkọ \nd Olúwa\nd*,
\q2 gbogbo ọba ayé yóò máa bẹ̀rù ògo rẹ.
\q1
\v 16 Torí tí \nd Olúwa\nd* yóò gbé Sioni ró, yóò farahàn nínú ògo rẹ̀.
\q1
\v 17 Yóò dáhùn àdúrà àwọn aláìní;
\q2 kì yóò sì gan ẹ̀bẹ̀ wọn.
\b
\q1
\v 18 Jẹ́ kí a kọ èyí fún ìran tí ń bọ̀,
\q2 àwọn ènìyàn tí a kò tí ì dá yóò yin \nd Olúwa\nd*:
\q1
\v 19 “\nd Olúwa\nd* wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá
\q2 láti ọ̀run wá ni ó bojú wo ayé,
\q1
\v 20 láti gbọ́ ìrora ará túbú,
\q2 láti tú àwọn tí a yàn sí ikú sílẹ̀.”
\q1
\v 21 Kí a lè sọ orúkọ \nd Olúwa\nd* ní Sioni
\q2 àti ìyìn rẹ̀ ní Jerusalẹmu.
\q1
\v 22 Ní ìgbà tí a kó àwọn ènìyàn àti
\q2 ìjọba pọ̀ láti máa sìn \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1
\v 23 Ní ipa ọ̀nà mi, ó rẹ agbára mi sílẹ̀,
\q2 ó gé ọjọ́ mi kúrú.
\q1
\v 24 Èmi sì wí pé:
\q2 “Ọlọ́run mi, má ṣe mú mi kúrò ní agbede-méjì ọjọ́ mi; ọdún rẹ̀ ń lọ láti ìran dé ìran.
\q1
\v 25 \x - \xo 102.25-27: \xt Hb 1.10-12.\x*Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,
\q2 ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
\q1
\v 26 Wọn yóò ṣègbé, wọn yóò parun, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà;
\q2 gbogbo wọn ni yóò gbó bí aṣọ.
\q1 Bí ẹ̀wù ni ìwọ yóò pààrọ̀ wọn
\q2 wọn yóò sì di àpatì.
\q1
\v 27 Ṣùgbọ́n ìwọ wà digbí síbẹ̀,
\q2 ọdún rẹ kò sì ní òpin.
\q1
\v 28 Àwọn ọmọ ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò dúró ní iwájú rẹ pẹ́;
\q2 a ó sì fi ẹsẹ̀ irú-ọmọ wọn sọlẹ̀ ní iwájú rẹ.”
\c 103
\cl Saamu 103
\d Ti Dafidi.
\q1
\v 1 Yin \nd Olúwa\nd*, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́.
\q1
\v 2 Yin \nd Olúwa\nd*, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀,
\q1
\v 3 ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́
\q2 tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn,
\q1
\v 4 ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú
\q2 ẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,
\q1
\v 5 ẹni tí ó fi ohun dídára tẹ́ ọ lọ́rùn
\q2 kí ìgbà èwe rẹ̀ lè di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.
\b
\q1
\v 6 \nd Olúwa\nd* ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún
\q2 gbogbo àwọn tí a ni lára.
\b
\q1
\v 7 Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli;
\q1
\v 8 \x - \xo 103.8: \xt Jk 5.11.\x*\nd Olúwa\nd* ni aláàánú àti olóore,
\q2 ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.
\q1
\v 9 Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo
\q2 bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ mọ́ láéláé,
\q1
\v 10 Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa
\q2 bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa gẹ́gẹ́
\q1 bí àìṣedéédéé wa.
\q1
\v 11 Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
\q1
\v 12 Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.
\b
\q1
\v 13 Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni \nd Olúwa\nd* ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
\q1
\v 14 nítorí tí ó mọ dídá wa,
\q2 ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.
\q1
\v 15 Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ rẹ̀ dàbí koríko,
\q2 ó gbilẹ̀ bí ìtànná ewéko igbó,
\q1
\v 16 afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí rẹ̀,
\q2 kò sì rántí ibùjókòó rẹ̀ mọ́.
\q1
\v 17 \x - \xo 103.17: \xt Lk 1.50.\x*Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́
\q2 \nd Olúwa\nd* ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
\q2 àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ,
\q1
\v 18 sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́
\q2 àti àwọn tí ó rántí òfin rẹ̀ láti ṣe wọ́n.
\b
\q1
\v 19 \nd Olúwa\nd* ti pèsè ìtẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀run,
\q2 ìjọba rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo.
\b
\q1
\v 20 Yin \nd Olúwa\nd*, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,
\q2 tí ó ní ipá,
\q2 tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́, tì ó sì ń se ìfẹ́ rẹ̀.
\q1
\v 21 Yin \nd Olúwa\nd*, ẹ̀yin ogun ọ̀run rẹ̀ gbogbo,
\q2 ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
\q1
\v 22 Yin \nd Olúwa\nd*, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní
\q2 ibi gbogbo ìjọba rẹ̀.
\b
\q1 Yin \nd Olúwa\nd*, ìwọ ọkàn mi.
\c 104
\cl Saamu 104
\q1
\v 1 Yin \nd Olúwa\nd*, ìwọ ọkàn mi.
\b
\q1 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi jọjọ;
\q2 ọlá àti ọláńlá ni ìwọ wọ̀ ní aṣọ.
\b
\q1
\v 2 Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara rẹ gẹ́gẹ́ bí aṣọ;
\q2 ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní,
\q1
\v 3 ìwọ tí ó fi omi ṣe ìtì igi àjà ìyẹ̀wù rẹ.
\q2 Ìwọ tí o ṣe àwọsánmọ̀ ní kẹ̀kẹ́ ogun rẹ
\q2 ìwọ tí ó ń rìn lórí apá ìyẹ́ afẹ́fẹ́.
\q1
\v 4 \x - \xo 104.4: \xt Hb 1.7.\x*Ó fi ẹ̀fúùfù ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ,
\q2 ọ̀wọ́-iná ni àwọn olùránṣẹ́ rẹ.
\b
\q1
\v 5 O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀;
\q2 tí a kò le è mì láéláé.
\q1
\v 6 Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ;
\q2 àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá.
\q1
\v 7 Ṣùgbọ́n nípa ìbáwí rẹ ni àwọn omi lọ,
\q2 nípa ohùn àrá rẹ ni wọ́n sálọ.
\q1
\v 8 wọ́n sàn kọjá lórí àwọn òkè,
\q2 wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀,
\q2 sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn.
\q1
\v 9 Ìwọ gbé òpin tí wọn kò lè kọjá rẹ̀ kálẹ̀;
\q2 láéláé ni wọ́n kò ní lè bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.
\b
\q1
\v 10 Ìwọ mú kí ìsun da omi sí àwọn àfonífojì;
\q2 tí ó ń sàn láàrín àwọn òkè.
\q1
\v 11 Wọ́n fún gbogbo àwọn ẹranko igbó ní omi
\q2 àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ń pa òǹgbẹ wọn.
\q1
\v 12 Àwọn ẹyẹ ojú òfúrufú tẹ́ ìtẹ́ wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi
\q2 wọ́n ń kọrin láàrín àwọn ẹ̀ka.
\q1
\v 13 Ó bu omi rin àwọn òkè láti ìyẹ̀wù rẹ̀ wá;
\q2 a tẹ́ ayé lọ́rùn nípa èso iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
\q1
\v 14 Ó mú kí koríko hù jáde fún àwọn ẹranko láti jẹ
\q2 àti àwọn ewébẹ̀ fún ènìyàn láti lò,
\q2 kí ó lè mú oúnjẹ jáde láti ilẹ̀ wá.
\q1
\v 15 Ọtí wáìnì tí ó ń mú ọkàn ènìyàn yọ̀,
\q2 òróró láti mú ojú rẹ̀ tan,
\q2 àti àkàrà láti ra ọkàn rẹ̀ padà.
\q1
\v 16 Àwọn igi \nd Olúwa\nd* ni a bu omi rin dáradára,
\q2 kedari ti Lebanoni tí ó gbìn.
\q1
\v 17 Níbẹ̀ ní àwọn ẹyẹ ṣe ìtẹ́ wọn
\q2 bí ó ṣe tí àkọ̀ ni, orí igi gíga ni ilé rẹ̀.
\q1
\v 18 Àwọn òkè gíga ni ààbò fún àwọn ewúrẹ́ igbó;
\q2 àti àwọn àlàpà jẹ́ ààbò fún àwọn ehoro.
\b
\q1
\v 19 Òṣùpá jẹ́ àmì fún àkókò
\q2 oòrùn sì mọ ìgbà tí yóò wọ̀.
\q1
\v 20 Ìwọ mú òkùnkùn wá, ó sì di òru,
\q2 nínú èyí tí gbogbo ẹranko igbó ń rìn kiri.
\q1
\v 21 Kìnnìún ń bú ramúramù fún ohun ọdẹ wọn
\q2 wọ́n sì ń wá oúnjẹ wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
\q1
\v 22 Oòrùn ràn, wọ́n sì kó ara wọn jọ,
\q2 wọn padà lọ dùbúlẹ̀ sí ihò wọn.
\q1
\v 23 Ọkùnrin jáde lọ sí iṣẹ́ wọn,
\q2 àti sí làálàá rẹ̀ títí di àṣálẹ́.
\b
\q1
\v 24 Iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó, \nd Olúwa\nd*!
\q2 Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn:
\q2 ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá á rẹ.
\q1
\v 25 Bẹ́ẹ̀ ni Òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì ni ìbú,
\q2 tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè ní ìsàlẹ̀ láìníye
\q2 ohun alààyè tí tóbi àti kékeré.
\q1
\v 26 Níbẹ̀ ni ọkọ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn,
\q2 àti Lefitani, tí ìwọ dá láti ṣe àríyá nínú rẹ̀.
\b
\q1
\v 27 Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́
\q2 láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò rẹ̀.
\q1
\v 28 Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn,
\q2 wọn yóò kó jọ;
\q1 nígbà tí ìwọ bá la ọwọ́ rẹ̀,
\q2 a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere.
\q1
\v 29 Nígbà tí ìwọ bá pa ojú rẹ mọ́
\q2 ara kò rọ̀ wọ́n
\q1 nígbà tí ìwọ bá mú ẹ̀mí wọn lọ,
\q2 wọn ó kú, wọn ó sì padà sí erùpẹ̀.
\q1
\v 30 Nígbà tí ìwọ rán ẹ̀mí rẹ,
\q2 ni a dá wọn,
\q2 ìwọ sì tún ojú ayé ṣe.
\b
\q1
\v 31 Jẹ́ kí ògo \nd Olúwa\nd* wà pẹ́ títí láé;
\q2 kí inú \nd Olúwa\nd* kí ó dùn ní ti iṣẹ́ rẹ̀,
\q1
\v 32 ẹni tí ó wo ayé, tí ó sì wárìrì,
\q2 ẹni tí ó fọwọ́ tọ́ àwọn òkè, tí wọ́n yọ èéfín.
\b
\q1
\v 33 Ní gbogbo ayé mi ní n ó kọrin sí \nd Olúwa\nd*:
\q2 èmi ó kọrin ìyìn sí \nd Olúwa\nd*
\q1 níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè.
\q1
\v 34 Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ mi kí ó tẹ́ ọ lọ́rùn
\q2 bí mo ti ń yọ̀ nínú \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 35 Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́ṣẹ̀ kúrò láyé
\q2 kí ènìyàn búburú má sì sí mọ́.
\b
\q1 Yin \nd Olúwa\nd*, ìwọ ọkàn mi.
\b
\q1 Yin \nd Olúwa\nd*.
\c 105
\cl Saamu 105
\q1
\v 1 \x - \xo 105.1-15: \xt 1Ki 16.8-22.\x*Ẹ fi ọpẹ́ fún \nd Olúwa\nd*, ké pe orúkọ rẹ̀,
\q2 jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.
\q1
\v 2 Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i;
\q2 sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ gbogbo.
\q1
\v 3 Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀,
\q2 jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá \nd Olúwa\nd* kí ó yọ̀.
\q1
\v 4 Wá \nd Olúwa\nd* àti ipá rẹ̀;
\q2 wa ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.
\b
\q1
\v 5 Rántí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe,
\q2 ìyanu rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ,
\q1
\v 6 ẹ̀yin ìran Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀,
\q2 ẹ̀yin ọmọkùnrin Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.
\q1
\v 7 Òun ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa:
\q2 ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ayé.
\b
\q1
\v 8 \x - \xo 105.8-9: \xt Lk 1.72-73.\x*Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé,
\q2 ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran,
\q1
\v 9 májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu,
\q2 ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki.
\q1
\v 10 Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí àṣẹ,
\q2 sí Israẹli, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé:
\q1
\v 11 “Fún ìwọ ni èmi ó fún ní ilẹ̀ Kenaani
\q2 gẹ́gẹ́ bí ìpín tí ìwọ ó jogún.”
\b
\q1
\v 12 Nígbà tí wọn kéré níye,
\q2 wọ́n kéré jọjọ, àti àwọn àjèjì níbẹ̀
\q1
\v 13 wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè,
\q2 láti ìjọba kan sí èkejì.
\q1
\v 14 Kò gba ẹnikẹ́ni láààyè láti pọ́n wọn lójú;
\q2 ó fi ọba bú nítorí tiwọn:
\q1
\v 15 “Má ṣe fọwọ́ kan ẹni àmì òróró mi; má sì ṣe wòlíì mi níbi.”
\b
\q1
\v 16 Ó pe ìyàn sórí ilẹ̀ náà
\q2 ó sì pa gbogbo ìpèsè oúnjẹ wọn run;
\q1
\v 17 Ó sì rán ọkùnrin kan síwájú wọn
\q2 Josẹfu tí a tà gẹ́gẹ́ bí ẹrú.
\q1
\v 18 Wọn fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ bọ ẹsẹ̀ rẹ̀
\q2 a gbé ọrùn rẹ̀ sínú irin,
\q1
\v 19 títí ọ̀rọ̀ tí ó sọtẹ́lẹ̀ fi ṣẹ
\q2 títí ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* fi dá a láre.
\q1
\v 20 Ọba ránṣẹ́ lọ tú u sílẹ̀
\q2 àwọn aláṣẹ ènìyàn tú u sílẹ̀
\q1
\v 21 Ó fi jẹ olúwa lórí ilẹ̀ rẹ̀,
\q2 aláṣẹ lórí ohun gbogbo tí ó ní,
\q1
\v 22 gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa
\q2 ṣe àkóso àwọn ọmọ-aládé
\q2 kí ó sì kọ́ àwọn àgbàgbà rẹ̀ ní ọgbọ́n.
\b
\q1
\v 23 Israẹli wá sí Ejibiti;
\q2 Jakọbu sì ṣe àtìpó ní ilé Hamu.
\q1
\v 24 \nd Olúwa\nd*, sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ bí sí i
\q2 ó sì mú wọn lágbára jù
\q2 àwọn ọ̀tá wọn lọ
\q1
\v 25 Ó yí wọn lọ́kàn padà láti kórìíra àwọn ènìyàn
\q2 láti ṣe àrékérekè sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.
\q1
\v 26 Ó rán Mose ìránṣẹ́ rẹ̀,
\q2 àti Aaroni tí ó ti yàn.
\q1
\v 27 Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín wọn
\q2 ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní Hamu.
\q1
\v 28 Ó rán òkùnkùn, o sì mú ilẹ̀ ṣú
\q2 wọn kò sì sọ̀rọ̀-òdì sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
\q1
\v 29 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,
\q2 ó pa ẹja wọn.
\q1
\v 30 Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀lọ́ jáde wá,
\q2 èyí tí ó lọ sí ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn.
\q1
\v 31 Ó sọ̀rọ̀, onírúurú eṣinṣin sì dìde,
\q2 ó sì hu kantíkantí ní ilẹ̀ wọn
\q1
\v 32 Ó sọ òjò di yìnyín,
\q2 àti ọ̀wọ́-iná ní ilẹ̀ wọn;
\q1
\v 33 Ó lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn
\q2 ó sì dá igi orílẹ̀-èdè wọn.
\q1
\v 34 Ó sọ̀rọ̀, eṣú sì dé,
\q2 àti kòkòrò ní àìníye,
\q1
\v 35 wọn sì jẹ gbogbo ewé ilẹ̀ wọn,
\q2 wọ́n sì jẹ èso ilẹ̀ wọn run.
\q1
\v 36 Nígbà náà, ó kọlu gbogbo àwọn ilẹ̀ wọn,
\q2 ààyò gbogbo ipá wọn.
\q1
\v 37 Ó mú Israẹli jáde
\q2 ti òun ti fàdákà àti wúrà,
\q2 nínú ẹ̀yà rẹ̀ kò sí aláìlera kan.
\q1
\v 38 Inú Ejibiti dùn nígbà tí wọn ń lọ,
\q2 nítorí ẹ̀rù àwọn Israẹli ń bá wọ́n.
\b
\q1
\v 39 Ó ta àwọsánmọ̀ fún ìbòrí,
\q2 àti iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ lálẹ́.
\q1
\v 40 Wọn béèrè, ó sì mú ẹyẹ àparò wá,
\q2 ó sì fi oúnjẹ ọ̀run tẹ́ wọn lọ́rùn.
\q1
\v 41 Ó sì la àpáta, ó sì mú omi jáde;
\q2 gẹ́gẹ́ bí odò tí ń sàn níbi gbígbẹ.
\b
\q1
\v 42 Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ rẹ̀
\q2 àti Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀.
\q1
\v 43 Ó sì fi ayọ̀ mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde
\q2 pẹ̀lú ayọ̀ ní ó yan àyànfẹ́ rẹ̀
\q1
\v 44 Ó fún wọn ní ilẹ̀ ìní náà,
\q2 wọ́n sì jogún iṣẹ́ àwọn ènìyàn náà,
\q1
\v 45 kí wọn kí ó lè máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́
\q2 kí wọn kí ó lè kíyèsi òfin rẹ̀.
\b
\q1 Ẹ fi ìyìn fún \nd Olúwa\nd*.
\c 106
\cl Saamu 106
\q1
\v 1 \x - \xo 106.1: \xt 1Ki 16.34.\x*Yin \nd Olúwa\nd*! Ẹ fi ìyìn fún
\q2 \nd Olúwa\nd*, nítorí tí ó ṣeun.
\b
\q1 Ẹ fi ọpẹ́ fún \nd Olúwa\nd* nítorí tí ó ṣeun,
\q2 nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.
\b
\q1
\v 2 Ta ni ó lè ròyìn iṣẹ́ agbára \nd Olúwa\nd*,
\q2 ta ní lè sọ nípa ìyìn rẹ̀?
\q1
\v 3 Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́?
\q2 Ẹni tí n ṣe ohun tí ó tọ́.
\b
\q1
\v 4 Rántí mi, \nd Olúwa\nd*,
\q2 nígbà tí o bá fi ojúrere rẹ hàn,
\q2 wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n,
\q1
\v 5 kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yàn,
\q2 kí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn,
\q2 ìní rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo.
\b
\q1
\v 6 Àwa ti dẹ́ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe,
\q2 àwa ti ṣe ohun tí kò dá a,
\q2 a sì ti hùwà búburú.
\q1
\v 7 Nígbà tí àwọn baba wa wà ní Ejibiti,
\q2 iṣẹ́ ìyanu rẹ kò yé wọn,
\q1 wọn kò rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ,
\q2 gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí ọ níbi Òkun, àní níbi Òkun Pupa.
\q1
\v 8 Ṣùgbọ́n o gbà wọ́n là nítorí orúkọ rẹ
\q2 láti jẹ́ kí agbára ńlá rẹ di mí mọ̀.
\q1
\v 9 O bá Òkun Pupa wí, ó sì gbẹ;
\q2 o sì mú wọn la ìbú já bí aginjù.
\q1
\v 10 O gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn,
\q2 láti ọwọ́ ọ̀tá ni o ti gbà wọ́n.
\q1
\v 11 Omi ya lu àwọn ọ̀tá wọn;
\q2 bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí ó yè nínú wọn.
\q1
\v 12 Nígbà náà wọn gba ìpinnu rẹ gbọ́
\q2 wọ́n sì kọrin ìyìn rẹ.
\b
\q1
\v 13 Ṣùgbọ́n wọn kò pẹ́ gbàgbé ohun tí o ṣe
\q2 wọn kò sí dúró gba ìmọ̀ràn rẹ.
\q1
\v 14 Nínú aginjù ni wọ́n tí ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́,
\q2 nínú aṣálẹ̀, wọ́n dán Ọlọ́run wò.
\q1
\v 15 Nígbà náà, ó fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún
\q2 ṣùgbọ́n ó rán àìsàn búburú sí wọn.
\b
\q1
\v 16 Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mose
\q2 pẹ̀lú Aaroni, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 17 Ilẹ̀ la ẹnu ó sì gbé Datani mì
\q2 ó bo ẹgbẹ́ Abiramu mọ́lẹ̀.
\q1
\v 18 Ọwọ́ iná yọ ní ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀;
\q2 iná jo àwọn ènìyàn búburú.
\q1
\v 19 Ní Horebu wọ́n ṣe ẹgbọrọ màlúù
\q2 wọ́n sì sin òrìṣà tí a ṣe láti ara irin.
\q1
\v 20 Wọ́n pa ògo wọn dà
\q2 sí àwòrán màlúù, tí ń jẹ koríko.
\q1
\v 21 Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run, ẹni tí ó gbà wọ́n
\q2 ẹni tí ó ti ṣe ohun ńlá ní Ejibiti,
\q1
\v 22 iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu
\q2 àti ohun ẹ̀rù ni ẹ̀bá Òkun Pupa.
\q1
\v 23 Bẹ́ẹ̀ ni, ó sọ wí pé, òun yóò pa wọ́n run
\q2 bí kò bá ṣe ti Mose, tí ó yàn,
\q1 tí ó dúró níwájú ẹ̀yà náà
\q2 tí ó pa ìbínú rẹ̀ mọ́ láti má pa wọ́n run mọ́.
\b
\q1
\v 24 Nígbà náà, wọ́n kẹ́gàn ilẹ̀ dídára náà
\q2 wọn kò gba ìlérí rẹ̀ gbọ́.
\q1
\v 25 Wọ́n ń kùn nínú àgọ́ wọn
\q2 wọn kò sì gbọ́rọ̀ sí \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 26 Bẹ́ẹ̀ ni ó búra fún wọn nípa gbígbé ọwọ́ rẹ̀ sókè
\q2 kí òun lè jẹ́ kí wọn ṣubú nínú aginjù,
\q1
\v 27 láti jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣubú lára orílẹ̀-èdè
\q2 láti fọ́n wọn káàkiri lórí ilẹ̀.
\b
\q1
\v 28 Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali-Peori,
\q2 wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí a rú sí àwọn òkú òrìṣà,
\q1
\v 29 wọ́n mú Ọlọ́run bínú pẹ̀lú ohun búburú tí wọn ń ṣe
\q2 àjàkálẹ̀-ààrùn jáde láàrín wọn.
\q1
\v 30 Ṣùgbọ́n Finehasi dìde láti dá sí i,
\q2 àjàkálẹ̀-ààrùn náà sì dáwọ́ dúró lọ́gán.
\q1
\v 31 A sì ka èyí sí òdodo fún un àti
\q2 fún àwọn ìrandíran tí ń bọ̀
\q1
\v 32 Níbi omi Meriba, wọ́n bí Ọlọ́run nínú,
\q2 ohun búburú wá sí orí Mose nítorí wọn.
\q1
\v 33 Nítorí tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹ̀mí Ọlọ́run.
\q2 Ọ̀rọ̀ àìdára sì ti ẹnu Mose wá.
\b
\q1
\v 34 Wọn kò pa àwọn ènìyàn run
\q2 gẹ́gẹ́ bí \nd Olúwa\nd* ti sọ fún wọn,
\q1
\v 35 Ṣùgbọ́n wọ́n dàpọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,
\q2 wọ́n sì gbà láti ṣe bí àṣà wọn.
\q1
\v 36 Wọ́n sì sin àwọn òrìṣà wọn
\q2 tí ó di ìkẹ́kùn fún wọn.
\q1
\v 37 Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rú ẹbọ
\q2 àti àwọn ọmọbìnrin fún òrìṣà.
\q1
\v 38 Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,
\q2 ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọ.
\q1 Wọ́n fi wọ́n rú ẹbọ sí ère Kenaani,
\q2 ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀.
\q1
\v 39 Wọ́n sì fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́,
\q2 wọ́n sì ṣe àgbèrè lọ pẹ̀lú iṣẹ́ wọn.
\b
\q1
\v 40 Nígbà náà ni \nd Olúwa\nd* bínú sí àwọn ènìyàn rẹ̀
\q2 ó sì kórìíra àwọn ènìyàn ìní rẹ̀
\q1
\v 41 Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́,
\q2 àwọn ọ̀tá wọn sì jẹ ọba lórí wọn.
\q1
\v 42 Àwọn ọ̀tá wọn sì ń pọ́n wọn lójú
\q2 wọn sì mú wọn sìn lábẹ́ àṣẹ wọn.
\q1
\v 43 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun gbà wọ́n,
\q2 síbẹ̀ wọ́n sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí i
\q2 wọ́n sì ṣòfò dànù nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
\q1
\v 44 Ṣùgbọ́n ó kíyèsi wọn nítorí ìṣòro
\q2 nígbà tí ó gbọ́ ẹkún wọn,
\q1
\v 45 ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ nítorí wọn
\q2 Nítorí agbára ìfẹ́ rẹ̀, ó ṣàánú wọn.
\q1
\v 46 Lójú gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn
\q2 ó mú wọn rí àánú.
\b
\q1
\v 47 \x - \xo 106.47-48: \xt 1Ki 16.35-36.\x*Gbà wá, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa,
\q2 kí o sì ṣà wá jọ kúrò láàrín àwọn kèfèrí,
\q1 láti máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ
\q2 láti máa ṣògo nínú ìyìn rẹ.
\b
\b
\q1
\v 48 Olùbùkún ni \nd Olúwa\nd*,
\q2 Ọlọ́run Israẹli, láti ìrandíran.
\b
\q1 Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kí ó wí pé, “Àmín!”
\b
\q1 Ẹ fi ìyìn fún \nd Olúwa\nd*!
\c 107
\ms ÌWÉ KARÙN-ÚN
\mr Saamu 107150
\cl Saamu 107
\q1
\v 1 Ẹ fi ọpẹ́ fún \nd Olúwa\nd*, nítorí tí ó ṣeun;
\q2 nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.
\b
\q1
\v 2 Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà \nd Olúwa\nd* kí ó wí báyìí,
\q2 àwọn ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,
\q1
\v 3 àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì,
\q2 láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn,
\q2 láti àríwá àti Òkun wá.
\b
\q1
\v 4 Wọ́n ń rìn káàkiri ní aginjù ní ibi tí ọ̀nà kò sí,
\q2 wọn kò rí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tí
\q2 wọn ó máa gbé.
\q1
\v 5 Ebi ń pa wọn, òǹgbẹ gbẹ wọ́n,
\q2 ó sì rẹ ọkàn wọn nínú wọn.
\q1
\v 6 Ní ìgbà náà, wọ́n kígbe sókè
\q2 sí \nd Olúwa\nd* nínú ìdààmú wọn,
\q1 ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn
\q1
\v 7 Ó fi ọ̀nà títọ́ hàn wọ́n sí ìlú
\q2 tí wọn lè máa gbé.
\q1
\v 8 Ẹ jẹ́ kí wọn máa yin \nd Olúwa\nd* nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́
\q2 ìyanu rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn,
\q1
\v 9 nítorí tí ó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn lọ́run
\q2 ó sì fi ìre fún ọkàn tí ebi ń pa.
\b
\q1
\v 10 Ọ̀pọ̀ jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú,
\q2 a dè wọ́n ní ìrora àti ní irin,
\q1
\v 11 nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀
\q2 Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá-ògo,
\q1
\v 12 Ó sì fi ìkorò rẹ àyà wọn sílẹ̀;
\q2 wọn ṣubú, kò sì ṣí ẹni tí
\q2 yóò ràn wọ́n lọ́wọ́.
\q1
\v 13 Ní ìgbà náà wọ́n ké pe
\q2 \nd Olúwa\nd* nínú ìdààmú wọn,
\q2 ó sì gbà wọ́n nínú ìṣòro wọn
\q1
\v 14 Ó mú wọn jáde kúrò nínú
\q2 òkùnkùn àti òjìji ikú,
\q2 ó sì fa irin tí wọ́n fi dè wọ́n já.
\q1
\v 15 Ẹ jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún \nd Olúwa\nd*! Nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sí ọmọ ènìyàn.
\q1
\v 16 Nítorí tí ó já ìlẹ̀kùn idẹ wọ̀n-ọn-nì
\q2 ó sì ké irin wọn ní agbede-méjì.
\b
\q1
\v 17 Ọ̀pọ̀ di aṣiwèrè nítorí ìrékọjá wọn
\q2 wọ́n sì pọ́n wọn lójú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
\q1
\v 18 Wọ́n kọ gbogbo oúnjẹ
\q2 wọ́n sì súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú.
\q1
\v 19 Nígbà náà wọ́n kígbe sí \nd Olúwa\nd* nínú ìṣòro wọn,
\q2 ó sì yọ wọ́n nínú ìdààmú wọn.
\q1
\v 20 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀, ara wọn sì dá
\q2 ó sì yọ wọ́n nínú isà òkú.
\q1
\v 21 Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún \nd Olúwa\nd* nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.
\q1
\v 22 Jẹ́ kí wọn rú ẹbọ ọpẹ́
\q2 kí wọn kí ó fi ayọ̀ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ̀.
\b
\q1
\v 23 Àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun nínú ọkọ̀ ojú omi,
\q2 wọ́n jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá.
\q1
\v 24 Wọ́n rí iṣẹ́ \nd Olúwa\nd*,
\q2 àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ nínú ibú.
\q1
\v 25 Nítorí tí ó pàṣẹ, ó sì mú ìjì fẹ́
\q2 tí ó gbé ríru rẹ̀ sókè.
\q1
\v 26 Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọ́n sì
\q2 tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú:
\q2 nítorí ìpọ́njú, ọkàn wọn di omi.
\q1
\v 27 Wọ́n ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn:
\q2 ọgbọ́n wọn sì dé òpin.
\q1
\v 28 Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókè
\q2 sí \nd Olúwa\nd* nínú ìdààmú wọn,
\q2 ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn.
\q1
\v 29 Ó sọ ìjì di ìdákẹ́rọ́rọ́
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ríru omi rẹ̀ dúró jẹ́ẹ́.
\q1
\v 30 Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀,
\q2 ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ.
\q1
\v 31 Jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún
\q2 \nd Olúwa\nd* nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀
\q2 àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.
\q1
\v 32 Jẹ́ kí wọn gbé e ga ní àárín àwọn ènìyàn
\q2 kí wọn kí ó sì yìn ín ní ìjọ àwọn àgbàgbà.
\b
\q1
\v 33 Ó sọ odò di aginjù,
\q2 àti orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ.
\q1
\v 34 Ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀
\q2 nítorí ìwà búburú àwọn tí ó wà nínú rẹ̀.
\q1
\v 35 O sọ aginjù di adágún omi àti
\q2 ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi,
\q1
\v 36 níbẹ̀ ó mú ẹni tí ebi ń pa wà,
\q2 wọ́n sì pilẹ̀ ibi tí wọn ó máa gbé.
\q1
\v 37 Wọn fún irúgbìn, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà
\q2 tí yóò máa so èso tí ó dára;
\q1
\v 38 Ó bùkún wọn, wọ́n sì pọ̀ sí i ní iye
\q2 kò sí jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọn kí ó dínkù.
\b
\q1
\v 39 Nígbà náà, ọjọ́ wọn kúrú,
\q2 ìnira, ìpọ́njú àti ìṣòro wọn sì dínkù,
\q1
\v 40 ẹni tí ó da ẹ̀gàn lu ọmọ-aládé
\q2 ó sì mú wọn rìn níbi tí ọ̀nà kò sí.
\q1
\v 41 Ṣùgbọ́n ó gbé aláìní sókè kúrò nínú ìnira
\q2 ó mú ìdílé wọn pọ̀ bí agbo ẹran.
\q1
\v 42 Àwọn tí ó dúró sì rí i, inú wọn sì dùn
\q2 ṣùgbọ́n gbogbo olùṣe búburú yóò pa ẹnu rẹ̀ mọ́.
\b
\q1
\v 43 Ẹni tí ó bá gbọ́n, jẹ́ kí ó kíyèsi nǹkan wọ̀nyí
\q2 kí ó wo títóbi ìfẹ́ \nd Olúwa\nd*.
\c 108
\cl Saamu 108
\d Orin. Saamu ti Dafidi.
\q1
\v 1 \x - \xo 108.1-5: \xt Sm 57.7-11.\x*Ọlọ́run, ọkàn mi dúró ṣinṣin
\q2 èmi ó máa kọrin, èmi ó máa fi ọkàn mi kọrin.
\q1
\v 2 Jí ohun èlò orin àti haapu!
\q2 Èmi ó jí ní kùtùkùtù,
\q1
\v 3 èmi ó yìn ọ́, \nd Olúwa\nd*, nínú àwọn orílẹ̀-èdè,
\q2 èmi ó kọrin rẹ nínú àwọn ènìyàn.
\q1
\v 4 Nítorí tí o tóbi ní àánú rẹ
\q2 ju àwọn ọ̀run lọ
\q2 àti òdodo rẹ dé àwọsánmọ̀.
\q1
\v 5 Gbé ara rẹ ga, Ọlọ́run, lórí àwọn ọ̀run,
\q2 àti ògo rẹ lórí gbogbo ayé.
\b
\q1
\v 6 \x - \xo 108.6-13: \xt Sm 60.5-12.\x*Kí a sì lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ là;
\q2 fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ìgbàlà,
\q2 kí o sì dá mi lóhùn
\q1
\v 7 Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀ pé,
\q2 “Èmi yóò yọ̀, èmi yóò pín Ṣekemu,
\q2 èmi yóò sì wọn àfonífojì Sukkoti kúrò.
\q1
\v 8 Gileadi ni tèmi, Manase ni tèmi,
\q2 Efraimu ni ìbòrí mi,
\q2 Juda ni olófin mi,
\q1
\v 9 Moabu sì ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,
\q2 lórí Edomu ni èmi ó bọ́ bàtà mi sí,
\q2 lórí òkè Filistia ni èmi yóò hó ìhó ayọ̀.”
\b
\q1
\v 10 Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi?
\q2 Ta ni yóò sìn mí wá sí Edomu?
\q1
\v 11 Ìwọ Ọlọ́run ha kọ́, ìwọ tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀.
\q2 Ọlọ́run ìwọ kì yóò bá àwọn jagunjagun wa jáde mọ́.
\q1
\v 12 Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ nínú ìpọ́njú,
\q2 nítorí ìrànlọ́wọ́ ènìyàn asán ni.
\q1
\v 13 Nípasẹ̀ Ọlọ́run ni àwa ó ṣe akin
\q2 nítorí òun ó tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.
\c 109
\cl Saamu 109
\d Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.
\q1
\v 1 Ọlọ́run, ti èmi ń fi ìyìn fún,
\q2 má ṣe dákẹ́,
\q1
\v 2 nítorí àwọn ènìyàn búburú àti ẹlẹ́tàn
\q2 ti ya ẹnu wọn sí mi
\q2 wọ́n ti fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ sí mi.
\q1
\v 3 Wọ́n fi ọ̀rọ̀ ìríra yí mi káàkiri;
\q2 wọ́n bá mi jà láìnídìí
\q1
\v 4 Nípò ìfẹ́ mi, wọn ń ṣe ọ̀tá mi,
\q2 ṣùgbọ́n èmi ń gba àdúrà.
\q1
\v 5 Wọ́n sì fi ibi san ìre fún mi
\q2 àti ìríra fún ìfẹ́ mi.
\b
\q1
\v 6 Yan àwọn ènìyàn búburú láti dojúkọ
\q2 jẹ́ kí àwọn olùfisùn
\q2 dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
\q1
\v 7 Kí a dá a lẹ́bi nígbà tí a bá ṣe ìdájọ́
\q2 kí àdúrà rẹ̀ kí ó lè di ìkọ̀sílẹ̀.
\q1
\v 8 \x - \xo 109.8: \xt Ap 1.20.\x*Kí ọjọ́ rẹ̀ kí ó kúrú;
\q2 kí ẹlòmíràn kí ó rọ́pò iṣẹ́ rẹ̀.
\q1
\v 9 Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìní baba
\q2 kí aya rẹ̀ sì di opó.
\q1
\v 10 Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe kiri
\q2 kí wọn máa tọrọ oúnjẹ jìnnà sí ibi ahoro wọn.
\q1
\v 11 Jẹ́ kí alọ́nilọ́wọ́gbà kí ó mú ohun gbogbo tí ó ní
\q2 jẹ́ kí àlejò kí o kó èrè iṣẹ́ rẹ̀ lọ.
\q1
\v 12 Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ṣe àánú fún un
\q2 tàbí kí wọn káàánú lórí
\q2 àwọn ọmọ rẹ̀ aláìní baba.
\q1
\v 13 Kí a gé àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ kúrò
\q2 kí orúkọ wọn kí ó parẹ́ ní ìran tí ń bọ̀.
\q1
\v 14 Kí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba rẹ̀ kí
\q2 ó wà ní ìrántí ní ọ̀dọ̀ \nd Olúwa\nd*.
\q2 Má ṣe jẹ́ kí a yọ ẹ̀ṣẹ̀ ìyá wọn kúrò.
\q1
\v 15 Jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí ó wà ní ìrántí níwájú \nd Olúwa\nd*
\q2 kí ó lè gé ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.
\b
\q1
\v 16 Nítorí kò rántí láti ṣàánú,
\q2 ṣùgbọ́n ó ṣe inúnibíni sí ọkùnrin tálákà àti olùpọ́njú,
\q2 kí ó lè pa oníròbìnújẹ́ ọkàn.
\q1
\v 17 Ó fẹ́ràn láti máa mú ègún wá sí orí rẹ̀:
\q2 bi inú rẹ̀ kò ti dùn si ìre, bẹ́ẹ̀ ni kí ó jìnnà sí.
\q1
\v 18 Bí ó ti fi ègún wọ ará rẹ̀ láṣọ bí ẹ̀wù
\q2 bẹ́ẹ̀ ni kí ó wá sí inú rẹ̀ bí omi.
\q1
\v 19 Jẹ́ kí ó rí fún un bí aṣọ tí a dà bò ó ní ara,
\q2 àti fún àmùrè tí ó fi gba ọ̀já nígbà gbogbo.
\q1
\v 20 Èyí ni èrè àwọn ọ̀tá mi láti ọwọ́ \nd Olúwa\nd* wá;
\q2 àti ti àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọkàn mi.
\b
\q1
\v 21 Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ ṣe fún mi \nd Olúwa\nd* Olódùmarè,
\q2 ṣe rere fún mi nítorí orúkọ rẹ.
\q2 Nítorí tí àánú rẹ dára, ìwọ gbà mí.
\q1
\v 22 Nítorí pé tálákà àti aláìní ni mí,
\q2 àyà mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.
\q1
\v 23 Èmi ń kọjá lọ bí òjìji tí àṣálẹ́,
\q2 mo ń gbọ̀n sókè bí eṣú.
\q1
\v 24 Eékún mi di aláìlera nítorí àwẹ̀ gbígbà
\q2 ẹran-ara mi sì gbẹ nítorí àìlera mi.
\q1
\v 25 \x - \xo 109.25: \xt Mt 27.39; Mk 15.29.\x*Mo dàbí ẹ̀gàn fún àwọn olùfisùn mi;
\q2 nígbà tí wọn wò mí, wọ́n gbọn orí wọn.
\b
\q1
\v 26 Ràn mí lọ́wọ́, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run mi;
\q2 gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìṣeun ìfẹ́ rẹ.
\q1
\v 27 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ọwọ́ rẹ ni èyí
\q2 wí pé ìwọ, \nd Olúwa\nd*, ni ó ṣe é.
\q1
\v 28 Wọ́n ó máa gégùn ún, ṣùgbọ́n ìwọ máa súre,
\q2 nígbà tí wọn bá dìde kí ojú kí ó tì wọ́n,
\q2 ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ yóò yọ̀.
\q1
\v 29 Jẹ́ kí a wọ àwọn ọ̀tá mi ní aṣọ ìtìjú
\q2 kí á sì fi ìdàrúdàpọ̀ bọ̀ wọ́n lára bí ẹ̀wù.
\b
\q1
\v 30 Pẹ̀lú ẹnu mi èmi yóò máa yin \nd Olúwa\nd* gidigidi
\q2 ní àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn èmi yóò máa yìn ín.
\q1
\v 31 Nítorí ó dúró ní apá ọ̀tún aláìní
\q2 láti gbà á lọ́wọ́ àwọn tí ń dá ọkàn rẹ̀ lẹ́bi.
\c 110
\cl Saamu 110
\d Ti Dafidi. Saamu.
\q1
\v 1 \x - \xo 110.1: \xt Mt 22.44; 26.64; Mk 12.36; 14.62; 16.19; Lk 20.42-43; 22.69; Ap 2.34; 1Kọ 15.25; Ef 1.20; Kl 3.1; Hb 1.3,13; 10.12-13; 12.2.\x*\nd Olúwa\nd* sọ fún Olúwa mi pé,
\b
\q1 “Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,
\q2 títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
\q2 di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”
\b
\q1
\v 2 \nd Olúwa\nd* yóò na ọ̀pá agbára rẹ̀
\q2 láti Sioni wá, ìwọ jẹ ọba láàrín àwọn ọ̀tá rẹ.
\q1
\v 3 Àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwá
\q2 ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ, nínú ẹwà mímọ́,
\q2 láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà rẹ.
\b
\q1
\v 4 \x - \xo 110.4: \xt Hb 5.6,10; 6.20; 7.11,15,21.\x*\nd Olúwa\nd* ti búra,
\q2 kò sì í yí ọkàn padà pé,
\q1 “Ìwọ ni àlùfáà,
\q2 ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”
\b
\q1
\v 5 \nd Olúwa\nd*, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni
\q2 yóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú rẹ̀.
\q1
\v 6 Yóò ṣe ìdájọ́ láàrín kèfèrí,
\q2 yóò kún ibùgbé wọn pẹ̀lú òkú ara;
\q2 yóò fọ́n àwọn olórí ká sí orí ilẹ̀ ayé tí ó gbòòrò.
\q1
\v 7 Yóò mu nínú odò ṣíṣàn ní ọ̀nà:
\q2 nítorí náà ni yóò ṣe gbé orí sókè.
\c 111
\cl Saamu 111
\q1
\v 1 Ẹ máa yin \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1 Èmi yóò máa yin \nd Olúwa\nd* pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi,
\q2 ní àwùjọ àwọn olóòtítọ́, àti ní ìjọ ènìyàn.
\b
\q1
\v 2 Iṣẹ́ \nd Olúwa\nd* tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀.
\q1
\v 3 Iṣẹ́ rẹ̀ ni ọláńlá àti ògo:
\q2 àti òdodo rẹ̀ dúró láéláé.
\q1
\v 4 Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, láti máa rántí:
\q2 \nd Olúwa\nd* ni olóore-ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú.
\q1
\v 5 Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀:
\q2 òun ń rántí májẹ̀mú rẹ̀.
\b
\q1
\v 6 Ó ti fihan àwọn ènìyàn rẹ̀ agbára iṣẹ́ rẹ̀
\q2 láti fún wọn ní ilẹ̀ ìlérí ní ìní.
\q1
\v 7 Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;
\q2 gbogbo òfin rẹ̀ sì dájú.
\q1
\v 8 Wọ́n dúró láé àti láé,
\q2 ní òtítọ́ àti òdodo ni a ṣe wọ́n.
\q1
\v 9 Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn rẹ̀:
\q2 ó pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ títí láé,
\q2 mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ̀.
\b
\q1
\v 10 Ìbẹ̀rù \nd Olúwa\nd* ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n:
\q2 òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀,
\q2 ìyìn rẹ̀ dúró láé.
\c 112
\cl Saamu 112
\q1
\v 1 Ẹ fi ìyìn fún \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run,
\q2 tí ó ní inú dídùn ńlá sí àwọn òfin rẹ̀.
\b
\q1
\v 2 Irú-ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé:
\q2 ìran àwọn olóòtítọ́ ni a ó bùkún fún.
\q1
\v 3 Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé rẹ̀;
\q2 òdodo rẹ̀ sì dúró láé.
\q1
\v 4 Fún olóòótọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yóò tàn fún ní òkùnkùn:
\q2 olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti òdodo.
\q1
\v 5 Ènìyàn rere fi ojúrere hàn,
\q2 a sì wínni;
\q2 ìmòye ni yóò máa fi la ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀.
\b
\q1
\v 6 Dájúdájú a kì yóò le yí ní ipò padà láéláé:
\q2 olódodo ni a ó máa ṣe ìrántí rẹ láéláé.
\q1
\v 7 Òun kì yóò béèrè ìyìn búburú:
\q2 ọkàn rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 8 Ó ti mú ọkàn rẹ̀ gbilẹ̀, ẹ̀rù kí yóò bà á,
\q2 títí yóò fi rí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.
\q1
\v 9 \x - \xo 112.9: \xt 2Kọ 9.9.\x*Ó ti pín ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú,
\q2 nítorí òdodo rẹ̀ dúró láé;
\q2 ìwo rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá.
\b
\q1
\v 10 Ènìyàn búburú yóò ri, inú wọn yóò sì bàjẹ́,
\q2 yóò sì pa eyín keke, yó sì yọ dànù:
\q2 èròǹgbà ọkàn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.
\c 113
\cl Saamu 113
\q1
\v 1 Ẹ máa yin \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1 Yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ \nd Olúwa\nd*,
\q1 ẹ yin orúkọ \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 2 Fi ìbùkún fún orúkọ \nd Olúwa\nd* láti
\q2 ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
\q1
\v 3 Láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀
\q2 orúkọ \nd Olúwa\nd* ni kí a máa yìn.
\b
\q1
\v 4 \nd Olúwa\nd* ga lórí gbogbo orílẹ̀-èdè,
\q2 àti ògo rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run.
\q1
\v 5 Ta ló dàbí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa,
\q2 tí ó gbé ní ibi gíga.
\q1
\v 6 Tí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti wò
\q2 òun tí ó ń bẹ lọ́run, àti nínú ayé!
\b
\q1
\v 7 Ó gbé òtòṣì dìde láti inú erùpẹ̀,
\q2 àti pé ó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá.
\q1
\v 8 Kí ó le mú un jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé
\q2 àní pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àwọn ènìyàn rẹ̀.
\q1
\v 9 Ó mú àgàn obìnrin gbé inú ilé,
\q2 àti láti jẹ́ aláyọ̀ ìyá fún àwọn ọmọ rẹ̀.
\b
\q1 Ẹ yin \nd Olúwa\nd*.
\c 114
\cl Saamu 114
\q1
\v 1 Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti,
\q2 ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè
\q1
\v 2 Juda wà ní ibi mímọ́,
\q2 Israẹli wà ní ìjọba.
\b
\q1
\v 3 \x - \xo 114.3: \xt El 14.21; Jo 3.16.\x*Òkun sì rí i, ó sì wárìrì:
\q2 Jordani sì padà sẹ́yìn.
\q1
\v 4 Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti
\q2 òkè kéékèèké bí ọ̀dọ́-àgùntàn.
\b
\q1
\v 5 Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì?
\q2 Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?
\q1
\v 6 Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò,
\q2 àti ẹ̀yin òkè kéékèèké bí ọ̀dọ́-àgùntàn?
\b
\q1
\v 7 Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú \nd Olúwa\nd*;
\q2 ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu
\q1
\v 8 tí ó sọ àpáta di adágún omi,
\q2 àti òkúta-ìbọn di orísun omi.
\c 115
\cl Saamu 115
\q1
\v 1 Kì í ṣe fún wa, \nd Olúwa\nd* kì í ṣe fún wa,
\q2 ṣùgbọ́n fún orúkọ rẹ ni a fi ògo fún,
\q2 fún àánú àti òtítọ́ rẹ.
\b
\q1
\v 2 Torí kí ni àwọn kèfèrí yóò ṣe sọ pé,
\q2 níbo ni Ọlọ́run wa wà.
\q1
\v 3 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run:
\q2 tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú.
\q1
\v 4 \x - \xo 115.4-8: \xt Sm 135.15-18.\x*Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà,
\q2 iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni.
\q1
\v 5 Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀,
\q2 wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.
\q1
\v 6 Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀:
\q2 wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbóòórùn.
\q1
\v 7 Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó,
\q2 wọ́n ní ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rìn;
\q2 bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀ nínú òfin wọn.
\q1
\v 8 Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn;
\q2 gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.
\b
\q1
\v 9 Ìwọ Israẹli gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd*:
\q2 òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn
\q1
\v 10 Ẹ̀ yin ilé Aaroni, gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd*:
\q2 òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn.
\q1
\v 11 Ẹ̀ yin tí ó bẹ̀rù \nd Olúwa\nd*, gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd*:
\q2 òun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn.
\b
\q1
\v 12 \nd Olúwa\nd* tí ń ṣe ìrántí wa; yóò bùkún ilé Israẹli;
\q2 yóò bùkún ilé Aaroni.
\q1
\v 13 \x - \xo 115.13: \xt If 11.18; 19.5.\x*Ìbùkún ni fún àwọn tí ó bẹ̀rù \nd Olúwa\nd*,
\q2 àti kékeré àti ńlá.
\b
\q1
\v 14 \nd Olúwa\nd* yóò mú ọ pọ̀ sí i síwájú àti síwájú,
\q2 ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀.
\q1
\v 15 Ẹ fi ìbùkún fún \nd Olúwa\nd*
\q2 ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.
\b
\q1
\v 16 Ọ̀run àní ọ̀run ni ti \nd Olúwa\nd*:
\q2 ṣùgbọ́n ayé ló fi fún ọmọ ènìyàn.
\q1
\v 17 Òkú kò lè yìn \nd Olúwa\nd*,
\q2 tàbí ẹni tí ó ti lọ sí ìsàlẹ̀ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́.
\q1
\v 18 Ṣùgbọ́n àwa ó fi ìbùkún fún \nd Olúwa\nd*
\q2 láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
\b
\q1 Ẹ yin \nd Olúwa\nd*.
\c 116
\cl Saamu 116
\q1
\v 1 Èmi fẹ́ràn \nd Olúwa\nd*, nítorí ó gbọ́ ohùn mi;
\q2 ó gbọ́ ẹkún mi fún àánú.
\q1
\v 2 Nítorí ó yí etí rẹ̀ padà sí mi,
\q2 èmi yóò máa pè é ni wọ́n ìgbà tí mo wà láààyè.
\b
\q1
\v 3 Okùn ikú yí mi ká,
\q2 ìrora isà òkú wá sórí mi;
\q2 ìyọnu àti ìbànújẹ́ borí mi.
\q1
\v 4 Nígbà náà ni mo ké pe orúkọ \nd Olúwa\nd*:
\q2 “\nd Olúwa\nd*, èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi!”
\b
\q1
\v 5 \nd Olúwa\nd* ní oore-ọ̀fẹ́, ó sì ní òdodo;
\q2 Ọlọ́run wa kún fún àánú.
\q1
\v 6 \nd Olúwa\nd* pa àwọn ọlọ́kàn fífúyẹ́ mọ́
\q2 nígbà tí mo wà nínú àìní ńlá, ó gbà mí.
\b
\q1
\v 7 Padà, ìwọ ọkàn mi, sí ibi ìsinmi rẹ,
\q2 nítorí \nd Olúwa\nd* ṣe dáradára sí ọ.
\b
\q1
\v 8 Nítorí ìwọ, \nd Olúwa\nd*, ti gba ọkàn mi
\q2 kúrò lọ́wọ́ ikú,
\q1 ojú mi kúrò lọ́wọ́ omijé,
\q2 àti ẹsẹ̀ mi kúrò lọ́wọ́ ìṣubú,
\q1
\v 9 nítorí èmi yóò máa rìn níwájú \nd Olúwa\nd*
\q2 ní ilẹ̀ alààyè.
\b
\q1
\v 10 \x - \xo 116.10: \xt 2Kọ 4.13.\x*Èmi gbàgbọ́; nítorí náà mo wí pé,
\q2 “èmi rí ìpọ́njú púpọ̀”.
\q1
\v 11 Àti nínú ìdààmú mi mo wí pé,
\q2 “Èké ni gbogbo ènìyàn”.
\b
\q1
\v 12 Kí ni èmi yóò san fún \nd Olúwa\nd*
\q2 nítorí gbogbo rere rẹ̀ sí mi?
\b
\q1
\v 13 Èmi yóò gbé ago ìgbàlà sókè
\q2 èmi yóò sì máa ké pe orúkọ \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 14 Èmi yóò mú ìlérí mi ṣẹ sí \nd Olúwa\nd*
\q2 ní ojú àwọn ènìyàn rẹ̀.
\b
\q1
\v 15 Iyebíye ní ojú \nd Olúwa\nd*
\q2 àti ikú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.
\q1
\v 16 \nd Olúwa\nd*, nítòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́;
\q2 èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ;
\q2 ó ti tú mi sílẹ̀ nínú ìdè mi.
\b
\q1
\v 17 Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ
\q2 èmi yóò sì ké pe orúkọ \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 18 Èmi yóò mú ìlérí mi sẹ sí \nd Olúwa\nd*
\q2 ní ojú gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀,
\q1
\v 19 nínú àgbàlá ilé \nd Olúwa\nd*
\q2 ní àárín rẹ̀, ìwọ Jerusalẹmu.
\b
\q1 Ẹ yin \nd Olúwa\nd*.
\c 117
\cl Saamu 117
\q1
\v 1 \x - \xo 117.1: \xt Ro 15.11.\x*Ẹ yin \nd Olúwa\nd*, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè;
\q2 ẹ pòkìkí rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn.
\q1
\v 2 Nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó ní sí wa,
\q2 àti òtítọ́ \nd Olúwa\nd* dúró láéláé.
\b
\q1 Ẹ yin \nd Olúwa\nd*!
\c 118
\cl Saamu 118
\q1
\v 1 \x - \xo 118.1: \xt 1Ki 16.34; 2Ki 5.13; 7.3; Es 3.11; Sm 100.5; 106.1; 107.1; 136.1; Jr 33.11.\x*Ẹ fi ọpẹ́ fún \nd Olúwa\nd*, nítorí tí ó dára;
\q2 àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\b
\q1
\v 2 Jẹ́ kí Israẹli wí pé:
\q2 “Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.
\q1
\v 3 Jẹ́ kí ilé Aaroni wí pé:
\q2 “Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.
\q1
\v 4 Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù \nd Olúwa\nd* wí pé:
\q2 “Àánú rẹ̀ dúró láéláé.”
\b
\q1
\v 5 Nínú ìrora mi, mo sọkún sí \nd Olúwa\nd*,
\q2 ó sì dá mi lóhùn nípa pé ó tú mi sílẹ̀.
\q1
\v 6 \x - \xo 118.6: \xt Hb 13.6.\x*\nd Olúwa\nd* ń bẹ fún èmi; èmi kì yóò bẹ̀rù.
\q2 Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?
\q1
\v 7 \nd Olúwa\nd* ń bẹ fún mi; òun ni olùrànlọ́wọ́ mi.
\q2 Nítorí náà ni èmi ó ṣe rí ìṣẹ́gun mi lórí àwọn tí ó kórìíra mi.
\b
\q1
\v 8 Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd*
\q2 ju àti gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn lọ.
\q1
\v 9 Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd*
\q2 ju à ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọmọ-aládé lọ.
\q1
\v 10 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yí mi káàkiri,
\q2 ṣùgbọ́n ní orúkọ \nd Olúwa\nd* èmi gé wọn kúrò.
\q1
\v 11 Wọ́n yí mi káàkiri ní gbogbo ẹ̀gbẹ́,
\q2 ṣùgbọ́n ní orúkọ \nd Olúwa\nd* èmi gé wọn dànù.
\q1
\v 12 Wọ́n gbá yìn ìn yí mi ká bí oyin,
\q2 ṣùgbọ́n wọ́n kú kíákíá bí iná ẹ̀gún;
\q2 ní orúkọ \nd Olúwa\nd* èmi ké wọn dànù.
\q1
\v 13 Ìwọ tì mí gidigidi kí n lè ṣubú,
\q2 ṣùgbọ́n \nd Olúwa\nd* ràn mí lọ́wọ́.
\q1
\v 14 \nd Olúwa\nd* ni agbára àti orin mi;
\q2 ó sì di ìgbàlà mi.
\b
\q1
\v 15 Ohùn ayọ̀ àti ìgbàlà ń bẹ nínú àgọ́ àwọn olódodo:
\q2 “Ọwọ́ ọ̀tún \nd Olúwa\nd* ń ṣe ohun agbára!
\q1
\v 16 Ọwọ́ ọ̀tún \nd Olúwa\nd* ní a gbéga;
\q2 ọwọ́ ọ̀tún \nd Olúwa\nd* ń ṣe ohun agbára!”
\q1
\v 17 Èmi kì yóò kú, ṣùgbọ́n èmi yóò yè,
\q2 èmi yóò pòkìkí ohun tí \nd Olúwa\nd* ṣe.
\q1
\v 18 \nd Olúwa\nd* bá mi wí gidigidi,
\q2 ṣùgbọ́n òun kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.
\q1
\v 19 Ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà òdodo fún mi:
\q2 èmi yóò bá ibẹ̀ wọlé, èmi yóò sì fi ọpẹ́ fún \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 20 Èyí ni ìlẹ̀kùn \nd Olúwa\nd*
\q2 ibẹ̀ ni àwọn olódodo yóò bá wọlé.
\q1
\v 21 Èmi yóò fi ọpẹ́ fún ọ, nítorí ó dá mi lóhùn;
\q2 ìwọ sì di ìgbàlà mi.
\b
\q1
\v 22 \x - \xo 118.22-23: \xt Mt 21.42; Mk 12.10-11; Lk 20.17; Ap 4.11; 1Pt 2.7.\x*Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
\q2 ni ó di pàtàkì igun ilé;
\q1
\v 23 \nd Olúwa\nd* ti ṣe èyí,
\q2 ó ṣe ìyanu ní ojú wa.
\q1
\v 24 Èyí ni ọjọ́ tí \nd Olúwa\nd* dá:
\q2 ẹ jẹ́ kí ayọ̀ kí inú wa sì máa dùn nínú rẹ̀.
\b
\q1
\v 25 \x - \xo 118.25-26: \xt Mt 21.9; 23.39; Mk 11.9-10; Lk 13.35; 19.38; Jh 12.13.\x*\nd Olúwa\nd*, gbà wá;
\q2 \nd Olúwa\nd*, fún wa ní àlàáfíà.
\b
\q1
\v 26 Ìbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ \nd Olúwa\nd*.
\q2 Àwa ti fi ìbùkún fún ọ láti ilé \nd Olúwa\nd* wá.
\q1
\v 27 \nd Olúwa\nd* ni Ọlọ́run,
\q2 ó ti mú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn sí wa lára
\q2 pẹ̀lú ẹ̀ka igi ní ọwọ́, ó dára pọ̀ mọ́
\q1 ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń wọ́ nínú ayọ̀
\q2 ẹ fi okùn di ẹbọ náà mọ́ ìwo pẹpẹ.
\b
\q1
\v 28 Ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ;
\q2 ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò gbé ọ ga.
\b
\q1
\v 29 Ẹ fi ọpẹ́ fún \nd Olúwa\nd*, nítorí tí ó ṣeun;
\q2 nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\c 119
\cl Saamu 119
\q1
\v 1 Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́ṣẹ̀,
\q2 ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 2 Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́
\q2 tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.
\q1
\v 3 Wọn kò ṣe ohun tí kò dára;
\q2 wọ́n rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
\q1
\v 4 Ìwọ ti la ìlànà rẹ̀ sílẹ̀
\q2 kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi.
\q1
\v 5 Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣin
\q2 láti máa pa òfin rẹ̀ mọ́!
\q1
\v 6 Nígbà náà, ojú kò ní tì mí
\q2 nígbà tí mo bá ń kíyèsi àṣẹ rẹ̀ gbogbo.
\q1
\v 7 Èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú ọkàn ìdúró ṣinṣin
\q2 bí èmi bá ti kọ́ òfin òdodo rẹ̀.
\q1
\v 8 Èmi yóò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀,
\q2 má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ pátápátá.
\b
\q1
\v 9 Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ yóò ti ṣe pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́?
\q1 Láti máa gbé ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ rẹ.
\q1
\v 10 Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi
\q2 má ṣe jẹ́ kí èmi yapa kúrò nínú àṣẹ rẹ.
\q1
\v 11 Èmi ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́ ní ọkàn mi
\q2 kí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ.
\q1
\v 12 Ìyìn ni fún \nd Olúwa\nd*;
\q2 kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
\q1
\v 13 Pẹ̀lú ètè mi èmi tún ṣírò
\q2 gbogbo òfin tí ó wá láti ẹnu rẹ.
\q1
\v 14 Èmi ń yọ̀ ní ọ̀nà ẹ̀rí rẹ,
\q2 bí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọláńlá.
\q1
\v 15 Èmi ń ṣe àṣàrò nínú ìlànà rẹ
\q2 èmi sì kíyèsi ọ̀nà rẹ.
\q1
\v 16 Inú mi dùn sí àṣẹ rẹ;
\q2 èmi kì yóò gbàgbé ọ̀nà rẹ.
\b
\q1
\v 17 Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ, èmi yóò sì wà láààyè;
\q2 èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ.
\q1
\v 18 La ojú mi kí èmi lè ríran rí
\q2 ohun ìyanu tí ó wà nínú òfin rẹ.
\q1
\v 19 Àlejò ní èmi jẹ́ láyé,
\q2 má ṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fún mi.
\q1
\v 20 Ọkàn mi pòruurù pẹ̀lú ìfojúsọ́nà
\q2 nítorí òfin rẹ nígbà gbogbo.
\q1
\v 21 Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn ún
\q2 tí ó ṣìnà kúrò nínú àṣẹ rẹ.
\q1
\v 22 Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi,
\q2 nítorí èmi pa òfin rẹ mọ́.
\q1
\v 23 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọpọ̀,
\q2 wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi,
\q2 ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ rẹ.
\q1
\v 24 Òfin rẹ ni dídùn inú mi;
\q2 àwọn ní olùbádámọ̀ràn mi.
\b
\q1
\v 25 Ọkàn mí lẹ̀ mọ́ erùpẹ̀;
\q2 ìwọ sọ mí di ààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
\q1
\v 26 Èmi tún ọ̀nà mi ṣírò ìwọ sì dá mi lóhùn;
\q2 kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
\q1
\v 27 Jẹ́ kí n mọ ẹ̀kọ́ ìlànà rẹ:
\q2 nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu rẹ.
\q1
\v 28 Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́;
\q2 fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
\q1
\v 29 Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tàn
\q2 fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ nípa òfin rẹ.
\q1
\v 30 Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́
\q2 èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin rẹ.
\q1
\v 31 Èmi yára di òfin rẹ mú. \nd Olúwa\nd*
\q2 má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
\q1
\v 32 Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ,
\q2 nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀.
\b
\q1
\v 33 Kọ́ mi, \nd Olúwa\nd*, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ;
\q2 nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin.
\q1
\v 34 Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
\q2 èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi.
\q1
\v 35 Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí,
\q2 nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn.
\q1
\v 36 Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹ
\q2 kí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́.
\q1
\v 37 Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán:
\q2 pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
\q1
\v 38 Mú ìlérí rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,
\q2 nítorí òfin rẹ dára.
\q1
\v 39 Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù
\q2 nítorí tí ìdájọ́ rẹ dára.
\q1
\v 40 Kíyèsi i, ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ rẹ!
\q2 Pa ayé mi mọ́ nínú òdodo rẹ.
\b
\q1
\v 41 Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, \nd Olúwa\nd*,
\q2 ìgbàlà rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
\q1
\v 42 Nígbà náà ni èmi yóò dá
\q2 ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn,
\q2 nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
\q1
\v 43 Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi
\q2 nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ rẹ.
\q1
\v 44 Èmi yóò máa gbọ́rọ̀ sí òfin rẹ nígbà gbogbo
\q2 láé àti láéláé.
\q1
\v 45 Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira,
\q2 nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ rẹ jáde.
\q1
\v 46 Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba
\q2 ojú kì yóò sì tì mí,
\q1
\v 47 nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ rẹ
\q2 nítorí èmi ní ìfẹ́ wọn.
\q1
\v 48 Èmi gbé ọwọ́ mi sókè nítorí àṣẹ rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn,
\q2 èmi sì ń ṣe àṣàrò òfin rẹ̀.
\b
\q1
\v 49 Rántí ọ̀rọ̀ rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,
\q2 nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí.
\q1
\v 50 Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí:
\q2 ìpinnu rẹ pa ayé mi mọ́.
\q1
\v 51 Àwọn agbéraga fi mí ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró,
\q2 ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin rẹ.
\q1
\v 52 Èmi rántí àwọn òfin rẹ ìgbàanì, \nd Olúwa\nd*,
\q2 èmi sì rí ìtùnú nínú wọn.
\q1
\v 53 Ìbínú dì mímú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburú,
\q2 tí wọ́n ti kọ òfin rẹ sílẹ̀.
\q1
\v 54 Òfin rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin mi
\q2 níbikíbi tí èmi ń gbé.
\q1
\v 55 Ní òru èmi rántí orúkọ rẹ, \nd Olúwa\nd*,
\q2 èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
\q1
\v 56 nítorí tí mo
\q2 gba ẹ̀kọ́ rẹ gbọ́.
\b
\q1
\v 57 Ìwọ ni ìpín mi, \nd Olúwa\nd*:
\q2 èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ rẹ.
\q1
\v 58 Èmi ti wá ojú rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:
\q2 fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
\q1
\v 59 Èmi ti kíyèsi ọ̀nà mi
\q2 èmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin rẹ.
\q1
\v 60 Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́ra
\q2 láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
\q1
\v 61 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn,
\q2 èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
\q1
\v 62 Ní àárín ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọ
\q2 nítorí òfin òdodo rẹ.
\q1
\v 63 Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,
\q2 sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ rẹ.
\q1
\v 64 Ayé kún fún ìfẹ́ rẹ, \nd Olúwa\nd*,
\q2 kọ́ mi ní òfin rẹ.
\b
\q1
\v 65 Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ
\q2 gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 66 Kọ́ mi ní ìmọ̀ àti ìdájọ́ rere,
\q2 nítorí mo gbàgbọ́ nínú àṣẹ rẹ.
\q1
\v 67 Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti ṣìnà,
\q2 ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí èmi gbọ́rọ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ.
\q1
\v 68 Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni;
\q2 kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
\q1
\v 69 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti gbìmọ̀ èké sí mí,
\q2 èmi pa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.
\q1
\v 70 Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú,
\q2 ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin rẹ.
\q1
\v 71 Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú
\q2 nítorí kí èmi lè kọ́ òfin rẹ.
\q1
\v 72 Òfin tí ó jáde láti ẹnu rẹ ju iyebíye sí mi lọ
\q2 ó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ.
\b
\q1
\v 73 Ọwọ́ rẹ ni ó dá mi tí ó sì mọ mí;
\q2 fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ rẹ.
\q1
\v 74 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ máa yọ̀ nígbà tí wọ́n bá rí mi,
\q2 nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
\q1
\v 75 Èmi mọ, \nd Olúwa\nd*, nítorí òfin rẹ òdodo ni,
\q2 àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú.
\q1
\v 76 Kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi,
\q2 gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ.
\q1
\v 77 Jẹ́ kí àánú rẹ kí ó tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè yè,
\q2 nítorí òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi.
\q1
\v 78 Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraga
\q2 nítorí wọn pa mí lára láìnídìí
\q2 ṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
\q1
\v 79 Kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yí padà sí mi,
\q2 àwọn tí ó ní òye òfin rẹ.
\q1
\v 80 Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin rẹ,
\q2 kí ojú kí ó má ṣe tì mí.
\b
\q1
\v 81 Ọkàn mi ń fojú ṣọ́nà nítorí ìgbàlà rẹ,
\q2 ṣùgbọ́n èmi ti fi ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
\q1
\v 82 Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wíwo ìpinnu rẹ;
\q2 èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?”
\q1
\v 83 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí awọ-wáìnì lójú èéfín,
\q2 èmi kò gbàgbé ìlànà rẹ.
\q1
\v 84 Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó?
\q2 Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọn
\q2 tí ń ṣe inúnibíni sí mi wí?
\q1
\v 85 Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi,
\q2 tí ó lòdì sí òfin rẹ.
\q1
\v 86 Gbogbo àṣẹ rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé;
\q2 ràn mí lọ́wọ́, nítorí ènìyàn ń ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí.
\q1
\v 87 Wọ́n fẹ́rẹ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé,
\q2 ṣùgbọ́n èmi kò kọ ẹ̀kọ́ rẹ.
\q1
\v 88 Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ,
\q2 èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu rẹ̀ gbọ́.
\b
\q1
\v 89 Ọ̀rọ̀ rẹ, \nd Olúwa\nd*, títí láé ni;
\q2 ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run.
\q1
\v 90 Òtítọ́ rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran;
\q2 ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin.
\q1
\v 91 Òfin rẹ dúró di òní
\q2 nítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́.
\q1
\v 92 Bí òfin rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi,
\q2 èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi.
\q1
\v 93 Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ láé,
\q2 nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́.
\q1
\v 94 Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹ
\q2 èmi ti wá ẹ̀kọ́ rẹ.
\q1
\v 95 Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run,
\q2 ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsi ẹ̀rí rẹ.
\q1
\v 96 Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin;
\q2 ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ aláìlópin ni.
\b
\q1
\v 97 Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó!
\q2 Èmi ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀
\q1 ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá.
\q1
\v 98 Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,
\q2 nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé.
\q1
\v 99 Èmi ní iyè inú ju gbogbo olùkọ́ mi lọ,
\q2 nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin rẹ.
\q1
\v 100 Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ,
\q2 nítorí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.
\q1
\v 101 Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibi
\q2 nítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ rẹ.
\q1
\v 102 Èmi kò yà kúrò nínú òfin rẹ,
\q2 nítorí ìwọ fúnra rẹ̀ ni ó kọ́ mi.
\q1
\v 103 Báwo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó,
\q2 ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi!
\q1
\v 104 Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ rẹ;
\q2 nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́.
\b
\q1
\v 105 Ọ̀rọ̀ rẹ ni fìtílà sí ẹsẹ̀ mi
\q2 àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi.
\q1
\v 106 Èmi ti ṣe ìbúra èmi sì ti tẹnumọ́ ọn
\q2 wí pé èmi yóò máa tẹ̀lé òfin òdodo rẹ.
\q1
\v 107 A pọ́n mi lójú gidigidi;
\q2 \nd Olúwa\nd*, sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ
\q1
\v 108 \nd Olúwa\nd*, gba ìyìn àtinúwá ẹnu mi,
\q2 kí o sì kọ́ mi ní òfin rẹ̀.
\q1
\v 109 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé mi wà ni ọwọ́ mi nígbà gbogbo,
\q2 èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
\q1
\v 110 Àwọn ẹni búburú ti dẹ okùn sílẹ̀ fún mi,
\q2 ṣùgbọ́n èmi kò ṣìnà kúrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
\q1
\v 111 Òfin rẹ ni ogún mi láéláé;
\q2 àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi.
\q1
\v 112 Ọkàn mi ti lé pípa òfin rẹ mọ́
\q2 láé dé òpin.
\b
\q1
\v 113 Èmi kórìíra àwọn ọlọ́kàn méjì,
\q2 ṣùgbọ́n èmi fẹ́ òfin rẹ.
\q1
\v 114 Ìwọ ni ààbò mi àti asà mi;
\q2 èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
\q1
\v 115 Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin olùṣe búburú,
\q2 kí èmi lè pa àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́!
\q1
\v 116 Gbé mi sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ,
\q2 kí èmi kí ó lè yè
\q2 Má sì jẹ́ kí ojú ìrètí mi kí ó tì mí.
\q1
\v 117 Gbé mi sókè, èmí yóò sì wa láìléwu;
\q2 nígbà gbogbo ni èmi yóò máa júbà òfin rẹ.
\q1
\v 118 Ìwọ kọ gbogbo àwọn tí ó ṣìnà kúrò nínú òfin rẹ,
\q2 nítorí ẹ̀tàn wọn asán ni.
\q1
\v 119 Gbogbo àwọn ẹni búburú ní ayé ni ìwọ yọ kúrò bí i ìdàrọ́;
\q2 nítorí náà, èmi fẹ́ òfin rẹ̀.
\q1
\v 120 Ara mi wárìrì ní ìbẹ̀rù nítorí rẹ̀:
\q2 èmi dúró ní ìbẹ̀rù òfin rẹ.
\b
\q1
\v 121 Èmi ti ṣe ohun tí i ṣe òdodo àti ẹ̀tọ́:
\q2 má ṣe fi mí sílẹ̀ fún àwọn tó ń ni mí lára.
\q1
\v 122 Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ dájú:
\q2 má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára.
\q1
\v 123 Ojú mi kùnà, fún wíwo ìgbàlà rẹ,
\q2 fún wíwo ìpinnu òdodo rẹ.
\q1
\v 124 Ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí dídúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ
\q2 kí o sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
\q1
\v 125 Èmi ni ìránṣẹ́ rẹ; ẹ fún mi ní òye
\q2 kí èmi lè ní òye òfin rẹ
\q1
\v 126 Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, \nd Olúwa\nd*;
\q2 nítorí òfin rẹ ti fọ́.
\q1
\v 127 Nítorí èmi fẹ́ràn àṣẹ rẹ
\q2 ju wúrà, àní ju wúrà dídára lọ,
\q1
\v 128 nítorí èmi kíyèsi gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ rẹ̀,
\q2 èmi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà búburú.
\b
\q1
\v 129 Òfin rẹ̀ ìyanu ni:
\q2 nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́.
\q1
\v 130 Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá;
\q2 ó fi òye fún àwọn òpè.
\q1
\v 131 Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ,
\q2 nítorí èmi fojú ṣọ́nà sí àṣẹ rẹ.
\q1
\v 132 Yí padà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi,
\q2 bí ìwọ ṣe máa ń ṣe nígbà gbogbo sí àwọn
\q2 tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ.
\q1
\v 133 Fi ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ,
\q2 má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi.
\q1
\v 134 Rà mí padà lọ́wọ́ aninilára ènìyàn,
\q2 kí èmi lè gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.
\q1
\v 135 Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ rẹ lára
\q2 kí ó sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
\q1
\v 136 Omijé sàn jáde ní ojú mi,
\q2 nítorí wọn kò gba pé òfin rẹ̀ jẹ́ òtítọ́.
\b
\q1
\v 137 Olódodo ni ìwọ \nd Olúwa\nd*
\q2 ìdájọ́ rẹ sì dúró ṣinṣin.
\q1
\v 138 Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo:
\q2 wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé.
\q1
\v 139 Ìtara mi ti pa mí run,
\q2 nítorí àwọn ọ̀tá mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ rẹ dá.
\q1
\v 140 Wọ́n ti dán ìpinnu rẹ wò pátápátá
\q2 ìránṣẹ́ rẹ sì fẹ́ràn wọ́n.
\q1
\v 141 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gàn
\q2 èmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ.
\q1
\v 142 Òdodo rẹ wà títí láé
\q2 òtítọ́ ni òfin rẹ̀.
\q1
\v 143 Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi,
\q2 ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ ni inú dídùn mi.
\q1
\v 144 Òfin rẹ jẹ́ òtítọ́ láé;
\q2 fún mi ní òye kí èmi lè yè.
\b
\q1
\v 145 Èmi kígbe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:
\q2 dá mi lóhùn \nd Olúwa\nd*,
\q2 èmi yóò sì gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
\q1
\v 146 Èmi kígbe pè ọ́; gbà mí
\q2 èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́.
\q1
\v 147 Èmi dìde ṣáájú àfẹ̀mọ́júmọ́ èmi ké fún ìrànlọ́wọ́;
\q2 èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
\q1
\v 148 Ojú mi ṣáájú ìṣọ́ òru,
\q2 nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ.
\q1
\v 149 Gbọ́ ohùn mi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ:
\q2 pa ayé mi mọ́, \nd Olúwa\nd*, gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
\q1
\v 150 Àwọn tí ń gbìmọ̀ ìlànà búburú wà ní tòsí,
\q2 ṣùgbọ́n wọ́n jìnnà sí òfin rẹ.
\q1
\v 151 Síbẹ̀ ìwọ wà ní tòsí, \nd Olúwa\nd*,
\q2 àti gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òtítọ́.
\q1
\v 152 Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin rẹ
\q2 tí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé.
\b
\q1
\v 153 Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí,
\q2 nítorí èmi kò gbàgbé òfin rẹ.
\q1
\v 154 Gba ẹjọ́ mi rò kí o sì rà mí padà;
\q2 pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
\q1
\v 155 Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburú
\q2 nítorí wọn kò wá àṣẹ rẹ.
\q1
\v 156 Ìyọ́nú rẹ̀ tóbi, \nd Olúwa\nd*;
\q2 pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
\q1
\v 157 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀tá tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi,
\q2 ṣùgbọ́n èmi kò tí ì yípadà kúrò nínú òfin rẹ.
\q1
\v 158 Èmi wo àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́
\q2 nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́.
\q1
\v 159 Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ rẹ;
\q2 pa ayé mi mọ́, \nd Olúwa\nd*, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ.
\q1
\v 160 Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ;
\q2 gbogbo òfin òdodo rẹ láéláé ni.
\b
\q1
\v 161 Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí,
\q2 ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ rẹ.
\q1
\v 162 Èmi yọ̀ nínú ìpinnu rẹ
\q2 bí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀.
\q1
\v 163 Èmi kórìíra mo sì kọ èké ṣíṣe
\q2 ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin rẹ.
\q1
\v 164 Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́
\q2 nítorí òfin òdodo rẹ.
\q1
\v 165 Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin rẹ,
\q2 kò sì ṣí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.
\q1
\v 166 Èmi yóò dúró de ìgbàlà rẹ, \nd Olúwa\nd*,
\q2 èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ.
\q1
\v 167 Èmi gba òfin rẹ gbọ́,
\q2 nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀púpọ̀.
\q1
\v 168 Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ rẹ àti òfin rẹ,
\q2 nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi.
\b
\q1
\v 169 Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú rẹ, \nd Olúwa\nd*;
\q2 fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
\q1
\v 170 Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú rẹ;
\q2 gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
\q1
\v 171 Ètè mi yóò sọ ìyìn jáde,
\q2 nítorí ìwọ kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
\q1
\v 172 Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ rẹ,
\q2 nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo.
\q1
\v 173 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣetán láti ràn mí lọ́wọ́,
\q2 nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ rẹ.
\q1
\v 174 Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà rẹ, \nd Olúwa\nd*,
\q2 àti òfin rẹ jẹ́ dídùn inú mi.
\q1
\v 175 Jẹ́ kí èmi wà láààyè ki èmi lè yìn ọ́,
\q2 kí o sì jẹ́ kí òfin rẹ mú mi dúró.
\q1
\v 176 Èmí ti ṣìnà bí àgùntàn tí ó sọnù.
\q2 Wá ìránṣẹ́ rẹ,
\q2 nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ rẹ.
\c 120
\cl Saamu 120
\d Orin fún ìgòkè.
\q1
\v 1 Èmi ké pe \nd Olúwa\nd* nínú ìpọ́njú mi,
\q2 ó sì dá mi lóhùn.
\q1
\v 2 Gbà mí, \nd Olúwa\nd*, kúrò lọ́wọ́ ètè èké
\q2 àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn.
\b
\q1
\v 3 Kí ni kí a fi fún ọ?
\q2 Àti kí ni kí a túnṣe fún ọ,
\q2 ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn?
\q1
\v 4 Òun yóò bá ọ wí pẹ̀lú ọfà mímú ológun,
\q2 pẹ̀lú ẹ̀yín iná igi ìgbálẹ̀.
\b
\q1
\v 5 Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Meṣeki,
\q2 nítorí èmi gbé nínú àgọ́ ìlú Kedari!
\q1
\v 6 Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbé
\q2 láàrín àwọn tí ó kórìíra àlàáfíà.
\q1
\v 7 Ènìyàn àlàáfíà ni mí;
\q2 ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni dúró fun wọn.
\c 121
\cl Saamu 121
\d Orin fún ìgòkè.
\q1
\v 1 Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì—
\q2 níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá?
\q1
\v 2 Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ \nd Olúwa\nd* wá,
\q2 ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.
\b
\q1
\v 3 Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀;
\q2 ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.
\q1
\v 4 Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́,
\q2 kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.
\b
\q1
\v 5 \nd Olúwa\nd* ni olùpamọ́ rẹ;
\q2 \nd Olúwa\nd* ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
\q1
\v 6 Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán
\q2 tàbí òṣùpá ní ìgbà òru.
\b
\q1
\v 7 \nd Olúwa\nd* yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo
\q2 yóò pa ọkàn rẹ mọ́
\q1
\v 8 \nd Olúwa\nd* yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́
\q2 láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.
\c 122
\cl Saamu 122
\d Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.
\q1
\v 1 Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé,
\q2 “Ẹ jẹ́ kí á lọ sílé \nd Olúwa\nd*.”
\q1
\v 2 Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè rẹ,
\q2 ìwọ Jerusalẹmu.
\b
\q1
\v 3 Jerusalẹmu, ìwọ tí a kọ́ bí ìlú
\q2 tí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan.
\q1
\v 4 Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ,
\q2 àwọn ẹ̀yà \nd Olúwa\nd*,
\q1 ẹ̀rí fún Israẹli,
\q2 láti máa dúpẹ́ fún orúkọ \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 5 Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀,
\q2 àwọn ìtẹ́ ilé Dafidi.
\b
\q1
\v 6 Gbàdúrà fún àlàáfíà Jerusalẹmu;
\q2 àwọn tí ó fẹ́ ọ yóò ṣe rere.
\q1
\v 7 Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi rẹ̀,
\q2 àti ìre nínú ààfin rẹ̀.
\q1
\v 8 Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mi
\q2 èmi yóò wí nísinsin yìí pé,
\q2 kí àlàáfíà kí ó wà nínú rẹ̀.
\q1
\v 9 Nítorí ilé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa,
\q2 èmi yóò máa wá ìre rẹ̀.
\c 123
\cl Saamu 123
\d Orin fún ìgòkè.
\q1
\v 1 Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí,
\q2 ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run.
\q1
\v 2 Kíyèsi, bí ojú àwọn
\q2 ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn,
\q2 àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀
\q1 bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa,
\q2 títí yóò fi ṣàánú fún wa.
\b
\q1
\v 3 \nd Olúwa\nd*, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa;
\q2 nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀.
\q1
\v 4 Ọkàn wa kún púpọ̀
\q2 fún ẹ̀gàn àwọn onírera,
\q2 àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.
\c 124
\cl Saamu 124
\d Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.
\q1
\v 1 “Ìbá má ṣe pé \nd Olúwa\nd* tí ó ti wà fún wa,”
\q2 kí ni Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí;
\q1
\v 2 ìbá má ṣe pé \nd Olúwa\nd* tó wà ní tiwa,
\q2 nígbà tí àwọn ènìyàn gbógun sí wa,
\q1
\v 3 nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè
\q2 nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa,
\q1
\v 4 nígbà náà ni omi
\q2 wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀,
\q1
\v 5 nígbà náà ni agbéraga
\q1 omi ìbá borí ọkàn wa.
\b
\q1
\v 6 Olùbùkún ni \nd Olúwa\nd*, tí kò fi wá fún wọ́n
\q2 bí ohun ọdẹ fún eyín wọn.
\q1
\v 7 Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ;
\q2 okùn já àwa sì yọ.
\q1
\v 8 Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ \nd Olúwa\nd*,
\q2 tí ó dá ọ̀run òun ayé.
\c 125
\cl Saamu 125
\d Orin fún ìgòkè.
\q1
\v 1 Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd* yóò dàbí òkè Sioni,
\q2 tí a kò lè ṣí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé.
\q1
\v 2 Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni \nd Olúwa\nd* yí ènìyàn ká
\q2 láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
\b
\q1
\v 3 Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburú
\q2 kì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo;
\q1 kí àwọn olódodo kí ó máa ba à
\q2 fi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀.
\b
\q1
\v 4 \nd Olúwa\nd* ṣe rere fún àwọn ẹni rere,
\q2 àti fún àwọn tí àyà wọn dúró ṣinṣin.
\q1
\v 5 Bí ó ṣe ti irú àwọn tí wọn yà sí ipa ọ̀nà wíwọ́ wọn;
\q2 \nd Olúwa\nd* yóò jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
\b
\q1 Ṣùgbọ́n àlàáfíà yóò wà lórí Israẹli.
\c 126
\cl Saamu 126
\d Orin fún ìgòkè.
\q1
\v 1 Nígbà tí \nd Olúwa\nd* mú ìkólọ Sioni padà,
\q2 àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá.
\q1
\v 2 Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,
\q2 àti ahọ́n wa kọ orin;
\q1 nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé,
\q2 \nd Olúwa\nd* ṣe ohun ńlá fún wọn.
\q1
\v 3 \nd Olúwa\nd* ṣe ohun ńlá fún wa;
\q2 nítorí náà àwa ń yọ̀.
\b
\q1
\v 4 \nd Olúwa\nd* mú ìkólọ wa padà,
\q2 bí ìṣàn omi ní gúúsù.
\q1
\v 5 Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn
\q2 yóò fi ayọ̀ ka.
\q1
\v 6 Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ,
\q2 tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́,
\q1 lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá,
\q2 yóò sì ru ìtí rẹ̀.
\c 127
\cl Saamu 127
\d Orin fún ìgòkè. Ti Solomoni.
\q1
\v 1 Bí kò ṣe pé \nd Olúwa\nd* bá kọ́ ilé náà
\q2 àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán ni;
\q2 bí kò ṣe pé \nd Olúwa\nd* bá pa ìlú mọ́, olùṣọ́ jí lásán.
\q1
\v 2 Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtù
\q2 láti pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ làálàá;
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ìre fún olùfẹ́ rẹ̀ lójú ọ̀run.
\b
\q1
\v 3 Kíyèsi i, àwọn ọmọ ni ìní \nd Olúwa\nd*:
\q2 ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀.
\q1
\v 4 Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe.
\q1
\v 5 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí apó rẹ̀ kún fún wọn;
\q2 ojú kì yóò tì wọ́n,
\q2 ṣùgbọ́n wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá ní ẹnu-ọ̀nà.
\c 128
\cl Saamu 128
\d Orin fún ìgòkè.
\q1
\v 1 Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù \nd Olúwa\nd*:
\q2 tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
\q1
\v 2 Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ
\q2 ìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ.
\q1
\v 3 Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rere
\q2 eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ;
\q2 àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká.
\q1
\v 4 Kíyèsi i pé, bẹ́ẹ̀ ni a ó bùsi i fún ọkùnrin náà,
\q2 tí ó bẹ̀rù \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1
\v 5 Kí \nd Olúwa\nd* kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá,
\q2 kí ìwọ kí ó sì máa rí ìre
\q1 Jerusalẹmu ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo.
\q2
\v 6 Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì máa rí àti ọmọdọ́mọ rẹ.
\q1 Láti àlàáfíà lára Israẹli.
\c 129
\cl Saamu 129
\d Orin fún ìgòkè.
\q1
\v 1 “Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú
\q2 láti ìgbà èwe mi wá,”
\q2 jẹ́ kí Israẹli kí ó wí nísinsin yìí;
\q1
\v 2 “Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú
\q2 láti ìgbà èwe mi wá;
\q2 síbẹ̀ wọn kò tí ì borí mi.
\q1
\v 3 Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi:
\q2 wọ́n sì la aporo wọn gígùn.
\q1
\v 4 Olódodo ni \nd Olúwa\nd*:
\q2 ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.”
\b
\q1
\v 5 Kí gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni kí ó dààmú,
\q2 kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà.
\q1
\v 6 Kí wọn kí ó dàbí koríko orí ilẹ̀
\q2 tí ó gbẹ dànù kí ó tó dàgbàsókè,
\q1
\v 7 èyí tí olóko pípa kó kún ọwọ́ rẹ̀:
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń di ìtí, kó kún apá rẹ̀.
\q1
\v 8 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kò wí pé,
\q2 ìbùkún \nd Olúwa\nd* kí ó pẹ̀lú yín:
\q2 àwa ń súre fún yin ní orúkọ \nd Olúwa\nd*.
\c 130
\cl Saamu 130
\d Orin fún ìgòkè.
\q1
\v 1 Láti inú ibú wá ni
\q2 èmi ń ké pè é ọ́ \nd Olúwa\nd*
\q1
\v 2 \nd Olúwa\nd*, gbóhùn mi,
\q2 jẹ́ kí etí rẹ kí o tẹ́ sílẹ̀ sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
\b
\q1
\v 3 \x - \xo 130.3: \xt Sm 143.2; Ro 3.20; Ga 2.16.\x*\nd Olúwa\nd*, ìbá ṣe pé kí ìwọ máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀,
\q2 \nd Olúwa\nd*, tá ni ìbá dúró.
\q1
\v 4 Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ,
\q2 kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.
\b
\q1
\v 5 Èmi dúró de \nd Olúwa\nd*, ọkàn mi dúró,
\q2 àti nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí.
\q1
\v 6 Ọkàn mi dúró de \nd Olúwa\nd*,
\q2 ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ,
\q2 àní ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.
\b
\q1
\v 7 Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti \nd Olúwa\nd*:
\q2 nítorí pé lọ́dọ̀ \nd Olúwa\nd* ni àánú wà,
\q2 àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáǹdè wà.
\q1
\v 8 Òun ó sì dá Israẹli ní ìdè
\q2 kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbogbo.
\c 131
\cl Saamu 131
\d Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd* àyà mi kò gbéga,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè:
\q1 bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi ọwọ́ mi lé ọ̀ràn ńlá,
\q2 tàbí lé ohun tí ó ga jù mí lọ.
\q1
\v 2 Nítòótọ́ èmi mú ọkàn mi sinmi,
\q2 mo sì mú un dákẹ́ jẹ́ẹ́,
\q1 bí ọmọ tí a ti ọwọ́ ìyá rẹ̀ gbà ní ẹnu ọmú:
\q2 ọkàn mi rí gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí a já ní ẹnu ọmú.
\b
\q1
\v 3 Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti \nd Olúwa\nd*
\q2 láti ìsinsin yìí lọ àti láéláé.
\c 132
\cl Saamu 132
\d Orin fún ìgòkè.
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd*, rántí Dafidi
\q2 nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.
\b
\q1
\v 2 Ẹni tí ó ti búra fún \nd Olúwa\nd*,
\q2 tí ó sì ṣe ìlérí fún alágbára Jakọbu pé.
\q1
\v 3 Nítòótọ́, èmi kì yóò wọ inú àgọ́ ilé mi lọ,
\q2 bẹ́ẹ̀ èmi kì yóò gun orí àkéte mi.
\q1
\v 4 Èmi kì yóò fi oorun fún ojú mi,
\q2 tàbí òògbé fún ìpéǹpéjú mi,
\q1
\v 5 títí èmi ó fi rí ibi fún \nd Olúwa\nd*,
\q2 ibùjókòó fún alágbára Jakọbu.
\b
\q1
\v 6 Kíyèsi i, àwa gbúròó rẹ̀ ni Efrata:
\q2 àwa rí i nínú oko ẹgàn náà.
\q1
\v 7 Àwa ó lọ sínú àgọ́ rẹ̀:
\q2 àwa ó máa sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀
\q1
\v 8 \nd Olúwa\nd*, dìde sí ibi ìsinmi rẹ:
\q2 ìwọ, àti àpótí agbára rẹ.
\q1
\v 9 Kí a fi òdodo wọ àwọn àlùfáà rẹ:
\q2 kí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ kí ó máa hó fún ayọ̀.
\b
\q1
\v 10 Nítorí tí Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀,
\q2 má ṣe yí ojú ẹni òróró rẹ padà.
\b
\q1
\v 11 \x - \xo 132.11: \xt Sm 89.3-4; Ap 2.30.\x*\nd Olúwa\nd* ti búra nítòótọ́ fún Dafidi,
\q2 Òun kì yóò yípadà kúrò nínú rẹ̀,
\q2 nínú irú-ọmọ inú rẹ ni èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ rẹ.
\q1
\v 12 Bí àwọn ọmọ rẹ̀ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́
\q2 àti ẹ̀rí mi tí èmi yóò kọ́ wọn,
\q2 àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ láéláé.
\b
\q1
\v 13 Nítorí tí \nd Olúwa\nd* ti yan Sioni:
\q2 ó ti fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀.
\q1
\v 14 Èyí ni ibi ìsinmi mi láéláé:
\q2 níhìn-ín ni èmi yóò máa gbé:
\q2 nítorí tí mo fẹ́ ẹ.
\q1
\v 15 Èmi yóò bùkún oúnjẹ rẹ̀ púpọ̀púpọ̀:
\q2 èmi yóò fi oúnjẹ tẹ́ àwọn tálákà rẹ̀ lọ́rùn.
\q1
\v 16 Èmi yóò sì fi ìgbàlà wọ àwọn àlùfáà rẹ̀:
\q2 àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ yóò máa hó fún ayọ̀.
\b
\q1
\v 17 Níbẹ̀ ni èmi yóò gbé mú ìwo Dafidi yọ̀,
\q2 èmi ti ṣe ìlànà fìtílà kan fún ẹni òróró mi.
\q1
\v 18 Àwọn ọ̀tá rẹ̀ ni èmi yóò fi ìtìjú wọ̀:
\q2 ṣùgbọ́n lára òun tìkára rẹ̀ ni adé yóò máa gbilẹ̀.
\c 133
\cl Saamu 133
\d Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.
\q1
\v 1 Kíyèsi, ó ti dára ó sì ti dùn tó fún
\q2 àwọn ará láti máa jùmọ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀.
\b
\q1
\v 2 Ó dàbí òróró ìkunra iyebíye ní orí,
\q2 tí ó sàn dé irùngbọ̀n, àní irùngbọ̀n Aaroni:
\q2 tí ó sì sàn sí etí aṣọ sórí rẹ̀.
\q1
\v 3 Bí ìrì Hermoni
\q2 tí o sàn sórí òkè Sioni.
\q1 Nítorí níbẹ̀ ní \nd Olúwa\nd* gbé pàṣẹ ìbùkún,
\q2 àní ìyè láéláé.
\c 134
\cl Saamu 134
\d Orin ìgòkè.
\q1
\v 1 Ẹ kíyèsi i, ẹ fi ìbùkún fún \nd Olúwa\nd*,
\q2 gbogbo ẹ̀yin ìránṣẹ́ \nd Olúwa\nd*,
\q2 tí ó dúró ní ilé \nd Olúwa\nd* ní òru.
\q1
\v 2 Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè sí ibi mímọ́,
\q2 kí ẹ sì fi ìbùkún fún \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1
\v 3 \nd Olúwa\nd* tí ó dá ọ̀run òun ayé,
\q2 kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá.
\c 135
\cl Saamu 135
\q1
\v 1 Ẹ yin \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1 Ẹ yin orúkọ \nd Olúwa\nd*;
\q2 ẹ yìn ín, ẹ̀yin ìránṣẹ́ \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 2 Ẹ̀yin tí ń dúró ní ilé \nd Olúwa\nd*,
\q2 nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run wa.
\b
\q1
\v 3 Ẹ yin \nd Olúwa\nd*: nítorí tí \nd Olúwa\nd* ṣeun;
\q2 ẹ kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ̀; nítorí tí ó dùn.
\q1
\v 4 Nítorí tí \nd Olúwa\nd* ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀;
\q2 àní Israẹli fún ìṣúra ààyò rẹ̀.
\b
\q1
\v 5 Nítorí tí èmi mọ̀ pé \nd Olúwa\nd* tóbi,
\q2 àti pé Olúwa jù gbogbo òrìṣà lọ.
\q1
\v 6 \nd Olúwa\nd* ṣe ohunkóhun tí ó wù ú,
\q2 ní ọ̀run àti ní ayé,
\q2 ní Òkun àti ní ọ̀gbun gbogbo.
\q1
\v 7 Ó mú ìkùùkuu gòkè láti òpin ilẹ̀ wá:
\q2 ó dá mọ̀nàmọ́ná fún òjò:
\q2 ó ń mú afẹ́fẹ́ ti inú ilẹ̀ ìṣúra rẹ̀ wá.
\b
\q1
\v 8 Ẹni tí ó kọlu àwọn àkọ́bí Ejibiti,
\q2 àti ti ènìyàn àti ti ẹranko.
\q1
\v 9 Ẹni tí ó rán iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu sí àárín rẹ̀, ìwọ Ejibiti,
\q2 sí ara Farao àti sí ara àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.
\q1
\v 10 Ẹni tí ó kọlu àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀,
\q2 tí ó sì pa àwọn alágbára ọba.
\q1
\v 11 Sihoni, ọba àwọn ará Amori, àti Ogu,
\q2 ọba Baṣani, àti gbogbo ìjọba Kenaani:
\q1
\v 12 Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní,
\q2 ìní fún Israẹli, ènìyàn rẹ̀.
\b
\q1
\v 13 \nd Olúwa\nd* orúkọ rẹ dúró láéláé;
\q2 ìrántí rẹ \nd Olúwa\nd*, láti ìrandíran.
\q1
\v 14 \x - \xo 135.14: \xt Hb 10.30.\x*Nítorí tí \nd Olúwa\nd* yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀,
\q2 yóò sì ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀.
\b
\q1
\v 15 Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà,
\q2 iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni.
\q1
\v 16 Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀;
\q2 wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.
\q1
\v 17 Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀;
\q1 bẹ́ẹ̀ ni kò si èémí kan ní ẹnu wọn.
\q1
\v 18 Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn:
\q2 gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.
\b
\q1
\v 19 Ẹ̀yin ara ilé Israẹli, ẹ fi ìbùkún fún \nd Olúwa\nd*,
\q2 ẹ̀yin ará ilé Aaroni, fi ìbùkún fún \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 20 Ẹ̀yin ará ilé Lefi, fi ìbùkún fún \nd Olúwa\nd*;
\q2 ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù \nd Olúwa\nd*, fi ìbùkún fún \nd Olúwa\nd*.
\q1
\v 21 Olùbùkún ni \nd Olúwa\nd*, láti Sioni wá,
\q2 tí ń gbé Jerusalẹmu.
\b
\q1 Ẹ fi ìyìn fún \nd Olúwa\nd*.
\c 136
\cl Saamu 136
\q1
\v 1 Ẹ fi ọpẹ́ fún \nd Olúwa\nd* nítorí tí ó ṣeun;
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\q1
\v 2 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run:
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\q1
\v 3 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa,
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\b
\q1
\v 4 Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá;
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\q1
\v 5 Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run;
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\q1
\v 6 \x - \xo 136.6: \xt Gẹ 1.2.\x*Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi;
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\q1
\v 7 \x - \xo 136.7-9: \xt Gẹ 1.16.\x*Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá;
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\q1
\v 8 Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán;
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\q1
\v 9 Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru;
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\b
\q1
\v 10 \x - \xo 136.10: \xt Ek 12.29.\x*Fún ẹni tí ó kọlu Ejibiti lára àwọn àkọ́bí wọn;
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\q1
\v 11 \x - \xo 136.11: \xt Ek 12.51.\x*Ó sì mú Israẹli jáde kúrò láàrín wọn;
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\q1
\v 12 Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà;
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\b
\q1
\v 13 \x - \xo 136.13-15: \xt Ek 14.21-29.\x*Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà;
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\q1
\v 14 Ó sì mú Israẹli kọjá láàrín rẹ̀
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\q1
\v 15 Ṣùgbọ́n ó bi Farao àti ogun rẹ̀ ṣubú nínú Òkun pupa;
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\b
\q1
\v 16 Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn rẹ̀ la aginjù já
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\b
\q1
\v 17 Fún ẹni tí ó kọlu àwọn ọba ńlá;
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\q1
\v 18 Ó sì pa àwọn ọba olókìkí
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\q1
\v 19 Sihoni, ọba àwọn ará Amori
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\q1
\v 20 Àti Ogu, ọba Baṣani;
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\q1
\v 21 Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní,
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\q1
\v 22 Ìní fún Israẹli, ìránṣẹ́ rẹ̀,
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\b
\q1
\v 23 Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa;
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\q1
\v 24 Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa;
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\q1
\v 25 Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbo
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\b
\q1
\v 26 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run;
\qr nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
\c 137
\cl Saamu 137
\q1
\v 1 Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòó
\q2 àwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni.
\q1
\v 2 Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílò,
\q2 tí ó wà láàrín rẹ̀.
\q1
\v 3 Nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn
\q2 tí ó kó wa ní ìgbèkùn béèrè orin lọ́wọ́ wa,
\q1 àti àwọn tí ó ni wá lára béèrè ìdárayá;
\q2 wọn wí pé, “Ẹ kọ orin Sioni kan fún wa!”
\b
\q1
\v 4 Àwa ó ti ṣe kọ orin
\q2 \nd Olúwa\nd* ní ilẹ̀ àjèjì
\q1
\v 5 Jerusalẹmu, bí èmi bá gbàgbé rẹ
\q2 jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò rẹ̀.
\q1
\v 6 Bí èmi kò bá rántí rẹ,
\q2 jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi;
\q1 bí èmi kò bá fi Jerusalẹmu ṣáájú
\q2 olórí ayọ̀ mi gbogbo.
\b
\q1
\v 7 \nd Olúwa\nd* rántí ọjọ́ Jerusalẹmu,
\q2 lára àwọn ọmọ Edomu,
\q1 àwọn ẹni tí ń wí pé,
\q2 “Wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!”
\q1
\v 8 Ìwọ, ọmọbìnrin Babeli, ẹni tí a ó parun;
\q2 ìbùkún ni fún ẹni tí ó san án fún ọ
\q2 bí ìwọ ti rò sí wa.
\q1
\v 9 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó mú ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ
\q2 tí ó sì fi wọ́n ṣán òkúta.
\c 138
\cl Saamu 138
\d Ti Dafidi.
\q1
\v 1 Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo;
\q2 níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ.
\q1
\v 2 Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀
\q2 èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ
\q1 nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ;
\q2 nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ.
\q1
\v 3 Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn,
\q2 ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.
\b
\q1
\v 4 Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́,
\q2 \nd Olúwa\nd*, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ.
\q1
\v 5 Nítòótọ́, wọn ó máa kọrin ní ipa ọ̀nà \nd Olúwa\nd*;
\q2 nítorí pé ńlá ni ògo \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1
\v 6 Bí \nd Olúwa\nd* tilẹ̀ ga, síbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀;
\q2 ṣùgbọ́n agbéraga ni ó mọ̀ ní òkèrè réré.
\q1
\v 7 Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè;
\q2 ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi,
\q2 ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí.
\q1
\v 8 \nd Olúwa\nd* yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé;
\q2 \nd Olúwa\nd*, àánú rẹ dúró láéláé;
\q2 má ṣe kọ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ sílẹ̀.
\c 139
\cl Saamu 139
\d Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd*, ìwọ tí wádìí mi,
\q2 ìwọ sì ti mọ̀ mí.
\q1
\v 2 Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi,
\q2 ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré.
\q1
\v 3 Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi,
\q2 gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ.
\q1
\v 4 Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi,
\q2 kíyèsi i, \nd Olúwa\nd*, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.
\q1
\v 5 Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú,
\q2 ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi.
\q1
\v 6 Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù;
\q2 ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n.
\b
\q1
\v 7 Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ni ọwọ́ ẹ̀mí rẹ?
\q2 Tàbí níbo ni èmi yóò sáré kúrò níwájú rẹ?
\q1
\v 8 Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀;
\q2 bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú,
\q2 kíyèsi i, ìwọ wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
\q1
\v 9 Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀,
\q2 kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin Òkun,
\q1
\v 10 àní, níbẹ̀ náà ni ọwọ́ rẹ̀ yóò fà mí
\q2 ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mímú.
\q1
\v 11 Bí mo bá wí pé, “Ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀;
\q2 kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.”
\q1
\v 12 Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọ́dọ̀ rẹ;
\q2 ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán;
\q2 àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ní fún ọ.
\b
\q1
\v 13 Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi;
\q2 ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.
\q1
\v 14 Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi;
\q2 ìyanu ní iṣẹ́ rẹ;
\q2 èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú.
\q1
\v 15 Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
\q2 nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀.
\q2 Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,
\q1
\v 16 ojú rẹ ti rí ohun ara mi
\q2 nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé,
\q2 àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí,
\q1 ní ọjọ́ tí a dá wọn,
\q2 nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.
\q1
\v 17 Ọlọ́run, èrò inú rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi,
\q2 iye wọn ti pọ̀ tó!
\q1
\v 18 Èmi ìbá kà wọ́n,
\q2 wọ́n ju iyanrìn lọ ní iye:
\q1 nígbà tí mo bá jí,
\q2 èmi yóò wà lọ́dọ̀ rẹ síbẹ̀.
\b
\q1
\v 19 Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa àwọn ènìyàn búburú nítòótọ́;
\q2 nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹlẹ́jẹ̀.
\q1
\v 20 Ẹni tí ń fi inú búburú sọ̀rọ̀ sí ọ,
\q2 àwọn ọ̀tá rẹ ń pe orúkọ rẹ ní asán!
\q1
\v 21 \nd Olúwa\nd*, ǹjẹ́ èmi kò kórìíra àwọn tó kórìíra rẹ?
\q2 Ǹjẹ́ inú mi kò a sì bàjẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ?
\q1
\v 22 Èmi kórìíra wọn ní àkótán;
\q2 èmi kà wọ́n sí ọ̀tá mi.
\q1
\v 23 Ọlọ́run, wádìí mi, kí o sì mọ ọkàn mí;
\q2 dán mi wò, kí o sì mọ ìrò inú mi.
\q1
\v 24 Kí ó sì wò ó bí ipa ọ̀nà búburú
\q2 kan bá wà nínú mi kí ó sì
\q2 fi ẹsẹ̀ mi lé ọ̀nà àìnípẹ̀kun.
\c 140
\cl Saamu 140
\d Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd*, gbà mi lọ́wọ́ ọkùnrin búburú u nì,
\q2 yọ mí lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì,
\q1
\v 2 ẹni tí ń ro ìwà búburú ní inú wọn;
\q2 nígbà gbogbo ni wọ́n ń rú ìjà sókè sí mi.
\q1
\v 3 Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò,
\q2 oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ ní abẹ́ ètè wọn.
\b
\q1
\v 4 \nd Olúwa\nd*, pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú;
\q2 yọ mí kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì
\q2 ẹni tí ó ti pinnu rẹ̀ láti bi ìrìn mi ṣubú.
\q1
\v 5 Àwọn agbéraga ti dẹkùn sílẹ̀ fún mi àti okùn:
\q2 wọ́n ti na àwọ̀n lẹ́bàá ọ̀nà;
\q2 wọ́n ti kẹ́kùn sílẹ̀ fún mi.
\b
\q1
\v 6 Èmi wí fún \nd Olúwa\nd* pé ìwọ ni Ọlọ́run mi;
\q2 \nd Olúwa\nd*, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
\q1
\v 7 \nd Olúwa\nd* Olódùmarè, agbára ìgbàlà mi,
\q2 ìwọ ni ó bo orí mi mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ ìjà.
\q1
\v 8 \nd Olúwa\nd*, máa ṣe fi ìfẹ́ ènìyàn búburú fún un;
\q2 má ṣe kún ọgbọ́n búburú rẹ̀ lọ́wọ́;
\q2 kí wọn kí ó máa ba à gbé ara wọn ga. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 9 Bí ó ṣe ti orí àwọn tí ó yí mi káàkiri ni,
\q2 jẹ́ kí ète ìka ara wọn kí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀.
\q1
\v 10 A ó da ẹ̀yin iná sí wọn lára,
\q2 Òun yóò wọ́ wọn lọ sínú iná,
\q1 sínú ọ̀gbun omi jíjìn,
\q2 kí wọn kí ó má ba à le dìde mọ́.
\q1
\v 11 Má ṣe jẹ́ kí aláhọ́n búburú fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ní ayé;
\q2 ibi ni yóò máa dọdẹ ọkùnrin ìkà nì láti bì í ṣubú.
\b
\q1
\v 12 Èmi mọ̀ pé, \nd Olúwa\nd* yóò mú ọ̀nà olùpọ́njú dúró,
\q2 yóò sì ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tálákà.
\q1
\v 13 Nítòótọ́ àwọn olódodo yóò
\q2 máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ;
\q2 àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yóò máa gbé iwájú rẹ.
\c 141
\cl Saamu 141
\d Saamu ti Dafidi.
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd*, èmi ké pè ọ́; yára wá sí ọ̀dọ̀ mi.
\q2 Gbọ́ ohùn mi, nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́.
\q1
\v 2 Jẹ́ kí àdúrà mi ó wá sí iwájú rẹ bí ẹbọ tùràrí
\q2 àti ìgbé ọwọ́ mi si òkè rí bí ẹbọ àṣálẹ́.
\b
\q1
\v 3 Fi ẹ̀ṣọ́ ṣọ́ ẹnu mi, \nd Olúwa\nd*:
\q2 kí o sì máa pa ìlẹ̀kùn ètè mi mọ́.
\q1
\v 4 Má ṣe jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ohun tí ń ṣe ibi,
\q2 láti máa bá àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ búburú
\q2 má sì ṣe jẹ́ kí èmi jẹ àdídùn wọn.
\b
\q1
\v 5 Jẹ́ kí olódodo lù mí, ìṣeun ni ó jẹ́:
\q2 jẹ́ kí ó bá mi wí, ó jẹ́ òróró ní orí mi.
\q2 Tí kì yóò fọ́ mi ní orí.
\b
\q1 Síbẹ̀ àdúrà mi wá láìsí ìṣe àwọn olùṣe búburú.
\q2
\v 6 A ó ju àwọn alákòóso sílẹ̀ láti bẹ̀bẹ̀ òkúta,
\q2 àwọn ẹni búburú yóò kọ pé àwọn ọ̀rọ̀ mi dùn.
\q1
\v 7 Wọn yóò wí pé, “Bí ẹni tí ó la aporo sórí ilẹ̀,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni egungun wa tànkálẹ̀ ní ẹnu isà òkú.”
\b
\q1
\v 8 Ṣùgbọ́n ojú mi ń bẹ lára rẹ, \nd Olúwa\nd* Olódùmarè;
\q2 nínú rẹ̀ ni èmi ti rí ààbò, má ṣe fà mi fún ikú.
\q1
\v 9 Pa mí mọ́ kúrò nínú okùn tí wọn ti dẹ sílẹ̀ fún mi,
\q2 kúrò nínú ìkẹ́kùn àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
\q1
\v 10 Jẹ́ kí àwọn ẹni búburú ṣubú sínú àwọ̀n ara wọn,
\q2 nígbà tí èmi bá kọjá lọ láìléwu.
\c 142
\cl Saamu 142
\d Maskili ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú ihò òkúta. Àdúrà.
\q1
\v 1 Èmi kígbe sókè sí \nd Olúwa\nd*;
\q2 èmi gbé ohùn mi sókè sí \nd Olúwa\nd* fún àánú.
\q1
\v 2 Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú rẹ̀,
\q2 bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú rẹ̀.
\b
\q1
\v 3 Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi,
\q2 ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi.
\q1 Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìn
\q2 ènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀.
\q1
\v 4 Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì rì i
\q2 kò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn mi
\q1 èmi kò ní ààbò;
\q2 kò sí ẹni tí ó náání ọkàn mi.
\b
\q1
\v 5 Èmi kígbe sí ọ, \nd Olúwa\nd*:
\q2 èmi wí pé, “Ìwọ ni ààbò mi,
\q2 ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè.”
\b
\q1
\v 6 Fi etí sí igbe mi,
\q2 nítorí tí èmi wà nínú àìnírètí
\q1 gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi,
\q2 nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ.
\q1
\v 7 Mú ọkàn mi jáde kúrò nínú túbú,
\q2 kí èmi lè máa yin orúkọ rẹ.
\q1 Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò yí mi káàkiri
\q2 nítorí ìwọ yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ba mi ṣe.
\c 143
\cl Saamu 143
\d Saamu ti Dafidi.
\q1
\v 1 \nd Olúwa\nd* gbọ́ àdúrà mi,
\q2 fetísí igbe mi fún àánú;
\q2 nínú òtítọ́ àti òdodo rẹ, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi.
\q1
\v 2 \x - \xo 143.2: \xt Sm 130.3; Ro 3.20; Ga 2.16.\x*Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìdájọ́,
\q2 nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè
\q2 tí ó ṣe òdodo níwájú rẹ.
\q1
\v 3 Ọ̀tá ń lépa mi,
\q2 ó fún mi pamọ́ ilẹ̀;
\q1 ó mú mi gbé nínú òkùnkùn
\q2 bí àwọn tí ó ti kú ti pẹ́.
\q1
\v 4 Nítorí náà ẹ̀mí mi ṣe rẹ̀wẹ̀sì nínú mi;
\q2 ọkàn mi nínú mi ṣì pòruurù.
\q1
\v 5 Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́;
\q2 èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ
\q2 mo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ rẹ ti ṣe.
\q1
\v 6 Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ:
\q2 òǹgbẹ rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀. \qs Sela.\qs*
\b
\q1
\v 7 Dá mi lóhùn kánkán, \nd Olúwa\nd*;
\q2 ó rẹ ẹ̀mí mi tán.
\q1 Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lára mi
\q2 kí èmi má ba à dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò.
\q1
\v 8 Mú mi gbọ́ ìṣeun ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀:
\q2 nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé.
\q1 Fi ọ̀nà tí èmi i bá rìn hàn mí,
\q2 nítorí èmi gbé ọkàn mi sókè sí ọ.
\q1
\v 9 Gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, \nd Olúwa\nd*,
\q2 nítorí èmi fi ara mi pamọ́ sínú rẹ.
\q1
\v 10 Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ rẹ,
\q2 nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi
\q1 jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ dídára
\q2 darí mi sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.
\b
\q1
\v 11 Nítorí orúkọ rẹ, \nd Olúwa\nd*, sọ mi di ààyè;
\q2 nínú òdodo rẹ, mú ọkàn mi jáde nínú wàhálà.
\q1
\v 12 Nínú ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà, ké àwọn ọ̀tá mi kúrò,
\q2 run gbogbo àwọn tí ń ni ọkàn mi lára,
\q2 nítorí pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ.
\c 144
\cl Saamu 144
\d Ti Dafidi.
\q1
\v 1 Ìyìn sí \nd Olúwa\nd* àpáta mi,
\q2 ẹni tí ó kọ́ ọwọ́ mi fún ogun,
\q2 àti ìka mi fún ìjà.
\q1
\v 2 Òun ni Ọlọ́run ìfẹ́ mi àti odi alágbára mi,
\q2 ibi gíga mi àti olùgbàlà mi, asà mi,
\q1 ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé,
\q2 ẹni tí ó tẹrí àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi.
\b
\q1
\v 3 \nd Olúwa\nd*, kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún un,
\q2 tàbí ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa rẹ̀?
\q1
\v 4 Ènìyàn rí bí èmi;
\q2 ọjọ́ rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ.
\b
\q1
\v 5 Tẹ ọ̀run rẹ ba, \nd Olúwa\nd*, kí o sì sọ̀kalẹ̀;
\q2 tọ́ àwọn òkè ńlá wọn yóò sí rú èéfín.
\q1
\v 6 Rán mọ̀nàmọ́ná kí ó sì fọ́n àwọn ọ̀tá ká;
\q2 ta ọfà rẹ kí ó sì dà wọ́n rú.
\q1
\v 7 Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti ibi gíga;
\q2 gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu
\q1 kúrò nínú omi ńlá:
\q2 kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì.
\q1
\v 8 Ẹnu ẹni tí ó kún fún èké
\q2 ẹni tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jẹ́ ìrẹ́jẹ.
\b
\q1
\v 9 Èmi yóò kọ orin tuntun sí ọ
\q2 Ọlọ́run; lára ohun èlò orin
\q1 olókùn mẹ́wàá èmi yóò
\q2 kọ orin sí ọ.
\q1
\v 10 Òun ni ó fi ìgbàlà fún àwọn ọba,
\q2 ẹni tí ó gba Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ idà ìpanilára.
\b
\q1 Lọ́wọ́ pípanirun.
\v 11 Gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu
\q2 kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì
\q1 tí ẹnu wọn kún fún èké,
\q2 tí ọwọ́ ọ̀tún wọn jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké.
\b
\q1
\v 12 Kí àwọn ọmọkùnrin wa
\q2 kí ó dàbí igi gbígbìn tí ó dàgbà ni ìgbà èwe wọn,
\q1 àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilé
\q2 tí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin.
\q1
\v 13 Àká wa yóò kún
\q2 pẹ̀lú gbogbo onírúurú oúnjẹ
\q1 àgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún,
\q2 ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa:
\q1
\v 14 àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwo
\q2 kí ó má sí ìkọlù,
\q1 kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn,
\q2 kí ó má sí i igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa.
\q1
\v 15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà tí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀,
\q2 ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà,
\q2 tí ẹni tí Ọlọ́run \nd Olúwa\nd* ń ṣe.
\c 145
\cl Saamu 145
\d Saamu ìyìn. Ti Dafidi.
\q1
\v 1 Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi;
\q2 èmi yóò yin orúkọ rẹ̀ láé àti láéláé.
\q1
\v 2 Ní ojoojúmọ́ èmi yóò yìn ọ́
\q2 èmi yóò sì pòkìkí orúkọ rẹ láé àti láéláé.
\b
\q1
\v 3 Títóbi ni \nd Olúwa\nd*. Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀:
\q2 kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi rẹ̀.
\q1
\v 4 Ìran kan yóò máa yin iṣẹ́ rẹ dé ìran mìíràn;
\q2 wọn yóò máa sọ iṣẹ́ agbára rẹ.
\q1
\v 5 Wọn yóò máa sọ ìyìn ọláńlá rẹ tí ó lógo,
\q2 èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú iṣẹ́ ìyanu rẹ.
\q1
\v 6 Wọn yóò sọ iṣẹ́ agbára rẹ tí ó ní ẹ̀rù
\q2 èmi yóò kéde iṣẹ́ ńlá rẹ̀.
\q1
\v 7 Wọn yóò ṣe ìrántí ọ̀pọ̀lọpọ̀
\q2 ìwà rere rẹ àti orin ayọ̀ òdodo rẹ.
\b
\q1
\v 8 Olóore-ọ̀fẹ́ ni \nd Olúwa\nd* àti aláàánú
\q2 ó lọ́ra láti bínú ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀.
\b
\q1
\v 9 \nd Olúwa\nd* dára sí ẹni gbogbo;
\q2 ó ní àánú lórí ohun gbogbo tí ó dá.
\q1
\v 10 Gbogbo ohun tí ìwọ ti dá ni
\q2 yóò máa yìn ọ́ \nd Olúwa\nd*;
\q2 àwọn ẹni mímọ́ yóò máa pòkìkí rẹ.
\q1
\v 11 Wọn yóò sọ ògo ìjọba rẹ
\q2 wọn yóò sì sọ̀rọ̀ agbára rẹ,
\q1
\v 12 kí gbogbo ènìyàn le mọ iṣẹ́ agbára rẹ̀
\q2 àti ọláńlá ìjọba rẹ tí ó lógo.
\q1
\v 13 Ìjọba rẹ ìjọba ayérayé ni,
\q2 àti ìjọba rẹ wà ní gbogbo ìrandíran.
\q1
\v 14 \nd Olúwa\nd* mú gbogbo àwọn tí ó ṣubú ró
\q2 ó sì gbé gbogbo àwọn tí ó tẹríba dìde.
\q1
\v 15 Ojú gbogbo ènìyàn ń wò ọ́,
\q2 ó sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó yẹ.
\q1
\v 16 Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ
\q2 ìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.
\b
\q1
\v 17 \nd Olúwa\nd* jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀
\q2 àti ìfẹ́ rẹ̀ sí gbogbo ohun tí o dá.
\q1
\v 18 \nd Olúwa\nd* wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é,
\q2 sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.
\q1
\v 19 Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ṣẹ;
\q2 ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n.
\q1
\v 20 \nd Olúwa\nd* dá gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́ sẹ sí
\q2 ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹni
\q2 búburú ní yóò parun.
\b
\q1
\v 21 Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ìyìn \nd Olúwa\nd*.
\q2 Jẹ́ kí gbogbo ẹ̀dá yín orúkọ rẹ̀ mímọ́ láé àti láéláé.
\c 146
\cl Saamu 146
\q1
\v 1 Ẹ fi ìyìn fún \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1 Fi ìyìn fún \nd Olúwa\nd*, ìwọ ọkàn mi.
\b
\q1
\v 2 Èmi yóò yin \nd Olúwa\nd* ní gbogbo ayé mi,
\q2 èmi yóò kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láààyè.
\q1
\v 3 Ẹ má ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ọmọ-aládé,
\q2 àní, ọmọ ènìyàn,
\q2 lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.
\q1
\v 4 Ẹ̀mí rẹ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀,
\q2 ní ọjọ́ náà gan, èrò wọn yóò di òfo.
\q1
\v 5 Ìbùkún ni fún ẹni tí
\q2 Ọlọ́run Jakọbu ń ṣe ìrànlọ́wọ́ rẹ̀
\q2 tí ìrètí rẹ̀ wà nínú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ̀.
\b
\q1
\v 6 Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ayé,
\q2 òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn,
\q2 ẹni tí ó pa òtítọ́ mọ́ títí ayé.
\q1
\v 7 Ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ni lára,
\q2 tí ó fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa,
\q1 \nd Olúwa\nd*, tú àwọn oǹdè sílẹ̀,
\q2
\v 8 \nd Olúwa\nd* mú àwọn afọ́jú ríran,
\q1 \nd Olúwa\nd*, gbé àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ ga,
\q2 \nd Olúwa\nd* fẹ́ràn àwọn olódodo.
\q1
\v 9 \nd Olúwa\nd* ń dá ààbò bo àwọn àlejò
\q2 ó sì ń dá àwọn aláìní baba àti opó sí
\q2 ṣùgbọ́n ó ba ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú jẹ́.
\b
\q1
\v 10 \nd Olúwa\nd* jẹ ọba títí láé;
\q2 Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni, àti fún gbogbo ìran.
\b
\q1 Ẹ fi ìyìn fún \nd Olúwa\nd*.
\c 147
\cl Saamu 147
\q1
\v 1 Ẹ fi ìyìn fún \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1 Nítorí ohun rere ni láti máa kọrin ìyìn sí Ọlọ́run wa,
\q2 ó yẹ láti kọrin ìyìn sí i!
\b
\q1
\v 2 \nd Olúwa\nd* kọ́ Jerusalẹmu;
\q2 Ó kó àwọn Israẹli tí a lé sọnù jọ.
\q1
\v 3 Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sàn
\q2 ó sì di ọgbẹ́ wọ́n.
\q1
\v 4 Ó ka iye àwọn ìràwọ̀
\q2 ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ.
\q1
\v 5 Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára
\q2 òye rẹ̀ kò sì ní òpin.
\q1
\v 6 \nd Olúwa\nd* wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀
\q2 bẹ́ẹ̀ ni ó rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀.
\b
\q1
\v 7 Fi ọpẹ́ kọrin sí \nd Olúwa\nd*
\q2 fi ohun èlò orin olókùn yin Ọlọ́run.
\b
\q1
\v 8 Ó fi ìkùùkuu bo àwọ̀ sánmọ̀
\q2 ó rọ òjò sí orílẹ̀ ayé
\q2 ó mú kí koríko hù lórí àwọn òkè
\q1
\v 9 Ó pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹranko
\q2 àti fún àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò ní ìgbà tí wọ́n bá ń ké.
\b
\q1
\v 10 Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹṣin,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni Òun kò ní ayọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin
\q1
\v 11 \nd Olúwa\nd* ni ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
\q2 sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú rẹ̀.
\b
\q1
\v 12 Yin \nd Olúwa\nd*, ìwọ Jerusalẹmu;
\q2 yin Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni.
\b
\q1
\v 13 Nítorí tí ó ti mú ọ̀pá ìdábùú ibodè rẹ̀ lágbára,
\q2 Òun sì ti bùkún fún àwọn ọmọ rẹ̀ nínú rẹ
\q1
\v 14 Òun jẹ́ kí àlàáfíà wà ní àwọn ẹnu ibodè rẹ̀,
\q2 òun sì fi jéró dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn.
\b
\q1
\v 15 Òun sì rán àṣẹ rẹ̀ sí ayé
\q2 ọ̀rọ̀ rẹ̀ sáré tete.
\q1
\v 16 Ó fi yìnyín fún ni bi irun àgùntàn
\q2 ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú
\q1
\v 17 Ó rọ òjò yìnyín rẹ̀ bí òkúta wẹ́wẹ́
\q2 ta ni ó lè dúró níwájú òtútù rẹ̀
\q1
\v 18 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde ó sì mú wọn yọ̀
\q2 ó mú kí afẹ́fẹ́ rẹ̀ fẹ́
\q2 ó sì mú odò rẹ̀ sàn.
\b
\q1
\v 19 Ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di mí mọ̀ fún Jakọbu
\q2 àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ fún Israẹli.
\q1
\v 20 Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀-èdè kan rí, bí ó ṣe ti ìdájọ́ rẹ̀
\q2 wọn ko mọ òfin rẹ̀.
\b
\q1 Ẹ fi ìyìn fún \nd Olúwa\nd*.
\c 148
\cl Saamu 148
\q1
\v 1 Ẹ fi ìyìn fún \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1 Ẹ fi ìyìn fún \nd Olúwa\nd* láti ọ̀run wá,
\q2 ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.
\q1
\v 2 Ẹ fi ìyìn fún un,
\q2 gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀,
\q1 ẹ fi ìyìn fún un,
\q2 gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀.
\q1
\v 3 Ẹ fi ìyìn fún un,
\q2 oòrùn àti òṣùpá.
\q1 Ẹ fi ìyìn fún un,
\q2 gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.
\q1
\v 4 Ẹ fi ìyìn fún un,
\q2 ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga
\q2 àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.
\b
\q1
\v 5 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ \nd Olúwa\nd*
\q2 nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn
\q1
\v 6 Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé
\q2 ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.
\b
\q1
\v 7 Ẹ yin \nd Olúwa\nd* láti ilẹ̀ ayé wá
\q2 ẹ̀yin ẹ̀dá inú òkun títóbi
\q2 àti ẹ̀yin ibú òkun,
\q1
\v 8 mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín
\q2 ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu,
\q2 ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,
\q1
\v 9 òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèké,
\q2 igi eléso àti gbogbo igi kedari,
\q1
\v 10 àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn
\q2 gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́,
\q1
\v 11 àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo
\q2 àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé,
\q1
\v 12 ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin
\q2 àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.
\b
\q1
\v 13 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ \nd Olúwa\nd*
\q2 nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá
\q2 ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run
\q1
\v 14 Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀,
\q2 ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli,
\q2 àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.
\b
\q1 Ẹ fi ìyìn fún \nd Olúwa\nd*.
\c 149
\cl Saamu 149
\q1
\v 1 Ẹ fi ìyìn fún \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1 Ẹ kọrin tuntun sí \nd Olúwa\nd*.
\q2 Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́.
\b
\q1
\v 2 Jẹ́ kí Israẹli kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá a
\q2 jẹ́ kí àwọn ọmọ Sioni kí ó ní
\q2 ayọ̀ nínú ọba wọn.
\q1
\v 3 Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ rẹ̀
\q2 jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.
\q1
\v 4 Nítorí \nd Olúwa\nd* ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn rẹ̀
\q2 ó fi ìgbàlà dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé.
\q1
\v 5 Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mímọ́ kí ó yọ̀ nínú ọlá rẹ̀
\q2 kí wọn kí ó máa kọrin fún ayọ̀ ní orí ibùsùn wọn.
\b
\q1
\v 6 Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọn
\q2 àti idà olójú méjì ní ọwọ́ wọn.
\q1
\v 7 Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè,
\q2 àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn,
\q1
\v 8 láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọn
\q2 àti láti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀
\q1 irin de àwọn ọlọ́lá wọn.
\q1
\v 9 Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ sí wọn
\q2 èyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀.
\b
\q1 Ẹ fi ìyìn fún \nd Olúwa\nd*.
\c 150
\cl Saamu 150
\q1
\v 1 Ẹ fi ìyìn fún \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1 Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ rẹ̀,
\q2 ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run rẹ̀.
\q1
\v 2 Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára rẹ̀.
\q2 Ẹ yìn ín fún títóbi rẹ̀ tí ó tayọ̀.
\q1
\v 3 Ẹ fi ohùn ìpè yìn ín.
\q2 Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín.
\q1
\v 4 Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín
\q2 fi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín,
\q1
\v 5 Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè,
\q2 ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro.
\b
\q1
\v 6 Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin \nd Olúwa\nd*.
\b
\q1 Ẹ fi ìyìn fún \nd Olúwa\nd*.