Biblica_yoOBYO17/05DEUyoOBYO17.SFM

1642 lines
195 KiB
Plaintext
Raw Permalink Blame History

This file contains ambiguous Unicode characters

This file contains Unicode characters that might be confused with other characters. If you think that this is intentional, you can safely ignore this warning. Use the Escape button to reveal them.

\id DEU - Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible (Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
\rem Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
\h Deuteronomi
\toc1 Ìwé Deuteronomi
\toc2 Deuteronomi
\toc3 De
\mt1 Ìwé Deuteronomi
\c 1
\s1 Àṣẹ láti jáde kúrò ní Horebu
\p
\v 1 Wọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Mose sọ fún gbogbo Israẹli ní aginjù, aginjù ìlà-oòrùn Jordani, ni Arabah, ní òdìkejì Ṣufi, ní àárín Parani àti Tofeli, Labani, Haserotu àti Disahabu.
\v 2 (Ọjọ́ mọ́kànlá ni ó gbà láti rin ìrìnàjò láti Horebu dé Kadeṣi-Barnea, bí a bá gba ọ̀nà òkè Seiri.)
\p
\v 3 Ní ìgbà tí ó pé ogójì ọdún, ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kọ́kànlá, Mose sọ ohun gbogbo tí \nd Olúwa\nd* pàṣẹ nípa àwọn ọmọ Israẹli fún wọn.
\v 4 Èyí ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣẹ́gun Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó jẹ ọba ní Heṣboni, àti Ogu ọba Baṣani ni ó ṣẹ́gun ní Edrei, ẹni tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu.
\p
\v 5 Ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani tí ó wà nínú ilẹ̀ Moabu ni Mose bẹ̀rẹ̀ sísọ àsọyé òfin wọ̀nyí wí pé:
\b
\p
\v 6 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa bá wa sọ̀rọ̀ ní Horebu pé, “Ẹ ti dúró ní orí òkè yìí pẹ́ tó.
\v 7 Ẹ yípadà kí ẹ sì tẹ̀síwájú ní ìrìnàjò yín lọ sí ilẹ̀ òkè àwọn ará Amori, ẹ tọ gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń gbé Arabah lọ ní aginjù, ní àwọn orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀, ní gúúsù àti ní etí Òkun, lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani àti lọ sí Lebanoni, títí fi dé odò ńlá Eufurate.
\v 8 Wò ó, èmi tí fi ilẹ̀ yí fún un yín, ẹ wọ inú rẹ̀ lọ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí \nd Olúwa\nd* ti búra wí pé òun yóò fún àwọn baba yín: fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu, àti fún àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn.”
\s1 Yíyan àwọn olórí
\p
\v 9 \x - \xo 1.9-15: \xt Nu 11.10-25.\x*Mo wí fún un yín nígbà náà pé, “Èmi nìkan kò lè dá ẹrù u yín gbé.
\v 10 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ti sọ yín di púpọ̀ lónìí, ẹ̀yin sì ti pọ̀ bí ìràwọ̀ ní ojú ọ̀run.
\v 11 Kí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run àwọn baba yín sọ yín di púpọ̀ ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún (1,000) sí i, kí ó sì bùkún un yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí.
\v 12 Báwo ni èmi nìkan ṣe lè máa ru àjàgà àti ìṣòro yín àti èdè-àìyedè yín?
\v 13 Ẹ yan àwọn ọlọ́gbọ́n, olóye àti àwọn ẹni àpọ́nlé, láti inú ẹ̀yà yín kọ̀ọ̀kan, èmi yóò sì fi wọ́n ṣe olórí yín.”
\p
\v 14 Ẹ̀yin sì dá mi lóhùn wí pé, “Ohun tí ìwọ ti gbèrò láti ṣe nì dára.”
\p
\v 15 Bẹ́ẹ̀ ni mo yan olórí àwọn ẹ̀yà yín, àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin, ẹni àpọ́nlé, mo sì fi jẹ olórí yín, olórí ẹgbẹẹ̀rún, olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta, àti olórí mẹ́wàá mẹ́wàá gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀yà yín.
\v 16 \x - \xo 1.16-18: \xt El 18.25,26.\x*Mo sì kìlọ̀ fún àwọn onídàájọ́ yín nígbà náà pé, ẹ gbọ́ èdè-àìyedè tí ó wà láàrín àwọn ènìyàn an yín kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ òdodo, bóyá ẹjọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ láàrín Israẹli sí Israẹli ni tàbí láàrín Israẹli kan sí àlejò.
\v 17 Ẹ má sì ṣe ojúsàájú ní ìdájọ́. Ẹ ṣe ìdájọ́ ẹni ńlá àti kékeré bákan náà. Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹnikẹ́ni torí pé ti Ọlọ́run ni ìdájọ́. Ẹjọ́ tí ó bá le jù fún un yín ni kí ẹ mú wá fún mi. Èmi yóò sì gbọ́ ọ.
\v 18 Nígbà náà ni èmi yóò sọ ohun tí ẹ ó ṣe fún un yín.
\s1 A rán àwọn Ayọ́lẹ̀wò jáde
\p
\v 19 Nígbà náà ní a gbéra láti Horebu, bí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún wá, a sì la àwọn ilẹ̀ lókè Amori kọjá lọ dé gbogbo aginjù ńlá tí ó ba ni lẹ́rù nì tí ẹ̀yin ti rí, bẹ́ẹ̀ ni a sì dé Kadeṣi-Barnea.
\v 20 Nígbà náà ni mo sọ fún un yín pé, “Ẹ ti dé ilẹ̀ òkè àwọn ará Amori, èyí tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa fún wa.
\v 21 Ẹ kíyèsi i, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ló ni ilẹ̀ náà. Ẹ lọ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà bí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run àwọn baba yín tí sọ fún un yín. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe fòyà.”
\p
\v 22 \x - \xo 1.22-46: \xt Nu 13.114.45; 32.8-13.\x*Nígbà náà ni gbogbo yín tọ̀ mí wá wí pé, “Jẹ́ kí a yan àwọn ayọ́lẹ̀wò láti yọ́ ilẹ̀ náà wò fún wa, kí wọn sì fún wa ní ìròyìn àwọn ọ̀nà tí a ó gbà àti àwọn ìlú tí a ó bá pàdé.”
\p
\v 23 Èrò náà sì dára lójú mi, torí èyí ni mo ṣe yan àwọn ènìyàn méjìlá nínú yín, ẹnìkan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.
\v 24 Wọ́n sì gòkè lọ sí ilẹ̀ òkè náà, wọ́n sì wá sí àfonífojì Eṣkolu, wọ́n sì yẹ̀ ẹ́ wò.
\v 25 Wọ́n sì mú lára èso ilẹ̀ náà wá fún wa pé, “Ilẹ̀ tí ó dára ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa fún wa.”
\s1 Ìṣọ̀tẹ̀ sí \nd Olúwa\nd*
\p
\v 26 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́ gòkè lọ; ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín.
\v 27 Ẹ kùn nínú àgọ́ ọ yín, ẹ sì wí pé, “\nd Olúwa\nd* kórìíra wa, torí èyí ló fi mú wa jáde láti Ejibiti láti fi wá lé àwọn ará Amori lọ́wọ́ láti pa wá run.
\v 28 Níbo la ó lọ? Àwọn arákùnrin wa ti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa nípa sísọ pé, Àwọn ènìyàn náà lágbára wọ́n sì ga jù wá lọ; àwọn ìlú náà tóbi jọjọ bẹ́ẹ̀ ni odi wọn ga kan ọ̀run. A tilẹ̀ rí àwọn òmíràn (ìran Anaki) níbẹ̀.’ ”
\p
\v 29 Nígbà náà ni mo sọ fún un yín pé, “Ẹ má ṣojo, ẹ kò sì gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn.
\v 30 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, tí ń ṣáájú yín yóò jà fún un yín; bí ó ti ṣe fún un yín ní Ejibiti lójú ẹ̀yin tìkára yín
\v 31 \x - \xo 1.31: \xt Ap 13.18.\x*àti ní aginjù. Níbẹ̀ ni ẹ ti rí i bí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ti gbé yín, bí baba ti í gbé ọmọ rẹ̀, ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ lọ títí ẹ fi padà dé ibí yìí.”
\p
\v 32 Pẹ̀lú gbogbo èyí tí mo wí, ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín,
\v 33 tí ń ṣáájú u yín lọ ní gbogbo ọ̀nà yín, nípa fífi iná ṣe amọ̀nà yín ní òru àti ìkùùkuu ní ọ̀sán, láti fi àwọn ibi tí ẹ lè tẹ̀dó sí hàn yín àti àwọn ọ̀nà tí ẹ ó rìn.
\p
\v 34 Nígbà tí \nd Olúwa\nd* gbọ́ ohun tí ẹ sọ, inú bí i, ó sì búra wí pé,
\v 35 “Kò sí ọ̀kan nínú ìran búburú yìí tí yóò dé ilẹ̀ rere tí mo ti búra láti fún àwọn baba ńlá a yín.
\v 36 Bí kò ṣe Kalebu ọmọ Jefunne. Òun ni yóò wọ̀ ọ́. Èmi yóò sì fún òun àti àwọn ìran rẹ̀ ní ilẹ̀ náà tí ó ti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ̀; torí pé ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀lé \nd Olúwa\nd*.”
\p
\v 37 Torí i tiyín ni \nd Olúwa\nd* fi bínú sí mi wí pé, “Ìwọ náà kì yóò wọ ibẹ̀ bákan náà,
\v 38 ṣùgbọ́n Joṣua ọmọ Nuni tí ń ṣe olùrànlọ́wọ́ rẹ ni yóò wọ ibẹ̀. Mú un, ní ọkàn le torí pé, òun yóò ṣáájú àwọn ọmọ Israẹli láti gba ilẹ̀ náà.
\v 39 Àwọn èwe yín tí ẹ sọ pé wọn yóò kó lẹ́rú. Àwọn ọmọ yín tí ko tí ì mọ rere yàtọ̀ sí búburú ni yóò wọ ilẹ̀ náà.
\v 40 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, ẹ yí padà sí aginjù tí ó wà ní ọ̀nà tí ó lọ sí Òkun Pupa.”
\p
\v 41 Nígbà náà ni ẹ fèsì wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀ sí \nd Olúwa\nd*. A ó sì gòkè lọ láti jà, gẹ́gẹ́ bí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún wa.” Torí náà gbogbo yín ẹ mú ohun ìjà a yín, ẹ rò pé ó rọrùn láti gòkè lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè olókè náà.
\p
\v 42 Ṣùgbọ́n \nd Olúwa\nd* sọ fún mi pé, “Sọ fún wọn, ‘Ẹ má ṣe gòkè lọ láti jà torí pé èmi kì yóò wà pẹ̀lú u yín. Àwọn ọ̀tá a yín yóò sì ṣẹ́gun yín.’ ”
\p
\v 43 Bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fún yín, ẹ̀yin kò sì gbọ́, ẹ̀yin ṣọ̀tẹ̀ sí òfin \nd Olúwa\nd*, pẹ̀lú ìgbéraga yín, ẹ gòkè lọ sí ìlú olókè náà.
\v 44 Àwọn ará Amori tí ń gbé ní àwọn òkè náà, dojúkọ yín bí àgbájọpọ̀ oyin. Wọ́n sì lù yín bolẹ̀ láti Seiri títí dé Horma.
\v 45 Ẹ padà, ẹ sì sọkún níwájú \nd Olúwa\nd*, òun kò sì fetí sí igbe ẹkún yín, Ó sì kọ etí dídi sí i yín.
\v 46 Báyìí ni ẹ sì dúró ní Kadeṣi fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti ṣe.
\c 2
\s1 Ìrìn àrè ní aginjù
\p
\v 1 \x - \xo 2.1-8: \xt Nu 21.4-20.\x*Nígbà náà ni a yípadà, tí a sì mú ọ̀nà wa pọ̀n lọ sí aginjù, a gba ọ̀nà Òkun Pupa, bí \nd Olúwa\nd* ti darí mi. Ìgbà pípẹ́ ni a fi ń rìn kiri yíká agbègbè àwọn ìlú olókè Seiri.
\p
\v 2 Nígbà náà ni \nd Olúwa\nd* sọ fún mi pé,
\v 3 “Ẹ ti rìn yí agbègbè ilẹ̀ olókè yìí pẹ́ tó, nísinsin yìí, ẹ yípadà sí ìhà àríwá.
\v 4 \x - \xo 2.4: \xt Gẹ 36.8.\x*Fún àwọn ènìyàn náà ní àwọn òfin wọ̀nyí: ‘Ẹ ti fẹ́ la ilẹ̀ àwọn arákùnrin yín kọjá, àwọn ọmọ Esau; àwọn ará Edomu tí ń gbé ní Seiri. Ẹ̀rù yín yóò bà wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ ṣọ́ra gidigidi.
\v 5 Ẹ má ṣe wá wọn níjà torí pé èmi kò ní fún un yín ní èyíkéyìí nínú ilẹ̀ wọn. Bí ó ti wù kí ó kéré mọ èmi kò ní fún un yín. Mo ti fi ilẹ̀ òkè Seiri fún Esau gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀.
\v 6 Ẹ san owó oúnjẹ tí ẹ bá jẹ fún wọn àti omi tí ẹ bá mu.’ ”
\p
\v 7 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ti bùkún un yín nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín. Ó ti mójútó ìrìnàjò yín nínú aginjù ńlá yìí. \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín wà pẹ̀lú u yín ní ogójì ọdún wọ̀nyí, dé bi pé ẹ̀yin kò ṣaláìní ohunkóhun.
\p
\v 8 Bẹ́ẹ̀ ni a kọjá ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wa, àwọn ọmọ Esau tí ń gbé ní Seiri. A yà kúrò ní ọ̀nà Arabah èyí tí ó wá láti Elati àti Esioni-Geberi, a sì rìn gba ọ̀nà aginjù Moabu.
\p
\v 9 \nd Olúwa\nd* sì sọ fún mi pé, “Ẹ má ṣe dẹ́rùba àwọn ará Moabu bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe bá wọn jagun torí pé n kò ní fi èyíkéyìí nínú ilẹ̀ wọn fún un yín. Mo ti fi Ari fún àwọn ọmọ Lọti bí i ìní.”
\p
\v 10 (Àwọn Emimu ti gbé ibẹ̀ rí, àwọn ènìyàn tó síngbọnlẹ̀ tó sì pọ̀, wọ́n ga bí àwọn Anaki.
\v 11 Gẹ́gẹ́ bí Anaki àwọn ènìyàn náà pè wọ́n ní ará Refaimu ṣùgbọ́n àwọn ará Moabu pè wọ́n ní Emimu.
\v 12 Àwọn ará Hori gbé ní Seiri, kí àwọn ọmọ Esau tó lé wọn kúrò níwájú wọn. Wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn, wọ́n tẹ̀dó sí ààyè wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israẹli tí ṣe ní ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* yóò fún wọn ní ìní wọn.)
\p
\v 13 \nd Olúwa\nd* sì wí pé, “Ẹ dìde, kí ẹ sì la àfonífojì Seredi kọjá.” Bẹ́ẹ̀ ni a la àfonífojì náà kọjá.
\p
\v 14 \x - \xo 2.14: \xt Nu 14.28-35.\x*Ó gbà wá ní ọdún méjìdínlógójì kí ó tó di wí pé a la àfonífojì Seredi kọjá láti ìgbà tí a ti kúrò ní Kadeṣi-Barnea. Nígbà náà gbogbo ìran àwọn tí ó jẹ́ jagunjagun láàrín àwọn ènìyàn náà ti ṣègbé kúrò láàrín àwọn ènìyàn náà ní àsìkò yìí bí \nd Olúwa\nd* ti búra fún wọn.
\v 15 Ọwọ́ \nd Olúwa\nd* sì wà lòdì sí wọn nítòótọ́, láti run wọn kúrò nínú ibùdó, títí gbogbo wọn fi run tan.
\p
\v 16 Lẹ́yìn tí ẹni tí ó gbẹ̀yìn pátápátá nínú àwọn jagunjagun àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti kú,
\v 17 \nd Olúwa\nd* sọ fún mi pé,
\v 18 “Lónìí ni ẹ̀yin yóò la agbègbè Moabu kọjá ní Ari.
\v 19 Bí ẹ bá dé ọ̀dọ̀ àwọn ará Ammoni, ẹ má ṣe halẹ̀ mọ́ wọn, ẹ kò sì gbọdọ̀ bá wọn jagun, torí pé èmi kì yóò fi àwọn ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ará Ammoni fún un yín ní ìní. Mo ti fi fún àwọn ọmọ Lọti ní ìní.”
\p
\v 20 (A ka ilẹ̀ yìí sí ilẹ̀ àwọn Refaimu, tí wọ́n ti gbé níbẹ̀ rí, ṣùgbọ́n àwọn ará Ammoni ń pè wọ́n ní ará Samsummimu.
\v 21 Wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tó lágbára, wọ́n sì pọ̀, wọ́n sì ga gogoro bí àwọn ará Anaki. \nd Olúwa\nd* run wọn kúrò níwájú àwọn ará Ammoni, tí wọ́n lé wọn jáde tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn.
\v 22 Bákan náà ni \nd Olúwa\nd* ṣe fún àwọn ọmọ Esau, tí wọ́n ń gbé ní Seiri, nígbà tí ó pa àwọn ará Hori run níwájú wọn. Wọ́n lé wọn jáde wọ́n sì ń gbé ní ilẹ̀ wọn títí di òní.
\v 23 Nípa ti àwọn ará Affimu, tí wọ́n ń gbé ní àwọn ìlú kéékèèké dé Gasa, àwọn ará Kaftorimu, tí wọ́n jáde láti Krete wá ni ó pa wọ́n run, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn.)
\s1 Israẹli ṣẹ́gun Sioni ọba Heṣboni
\p
\v 24 “Ẹ gbáradì, kí ẹ sì kọjá odò Arnoni. Kíyèsi, Mo ti fi Sihoni ará Amori, ọba Heṣboni àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Ẹ bá ilẹ̀ náà jagun kí ẹ sì gbà á.
\v 25 Èmi bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ìbẹ̀rù àti ìfòyà yín sára gbogbo orílẹ̀-èdè lábẹ́ ọ̀run láti òní lọ. Wọn yóò gbọ́ ìròyìn in yín, wọn yóò sì wárìrì, wọn yóò sì wà nínú ìdààmú ọkàn torí i tiyín.”
\p
\v 26 Mo rán àwọn ìránṣẹ́ láti aginjù Kedemoti lọ́ sọ́dọ̀ Sihoni ọba Heṣboni pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àlàáfíà wí pé,
\v 27 “Jẹ́ kí a la ilẹ̀ ẹ yín kọjá. Àwa yóò gba ti òpópónà nìkan. A kò ní yà sọ́tùn tàbí sósì.
\v 28 Ẹ ta oúnjẹ tí a ó jẹ àti omi tí a ó mu fún wa ní iye owó wọn. Kìkì kí ẹ sá à jẹ́ kí a rìn kọjá:
\v 29 gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Esau tí ó ń gbé ní Seiri àti àwọn ará Moabu tí ó ń gbé ní Ari, ti gbà wá láààyè títí a fi la Jordani já dé ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa yóò fún wa.”
\v 30 Ṣùgbọ́n Sihoni ọba Heṣboni kò gbà fún wa láti kọjá. Torí pé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ti mú ọkàn rẹ̀ yigbì, àyà rẹ̀ sì kún fún agídí kí ó ba à le fi lé e yín lọ́wọ́, bí ó ti ṣe báyìí.
\p
\v 31 \nd Olúwa\nd* sì bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kíyèsi i, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi Sihoni àti ilẹ̀ rẹ̀ lé e yín lọ́wọ́. Báyìí, ẹ máa ṣẹ́gun rẹ̀, kí ẹ sì gba ilẹ̀ rẹ̀.”
\p
\v 32 Nígbà tí Sihoni àti gbogbo àwọn jagunjagun rẹ̀ jáde wá láti bá wa jagun ní Jahasi,
\v 33 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa fi lé wa lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ ni a ṣẹ́gun rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo ológun rẹ̀.
\v 34 Nígbà náà, gbogbo ìlú wọn ni a kó tí a sì pa wọ́n run pátápátá tọkùnrin, tobìnrin àti gbogbo ọmọ wọn. A kò sì dá ẹnikẹ́ni sí.
\v 35 Ṣùgbọ́n a kó gbogbo ohun ọ̀sìn àti ìkógun àwọn ìlú tí a ṣẹ́gun fún ara wa.
\v 36 Láti Aroeri, létí odò Arnoni àti láti àwọn ìlú tí ó wà lẹ́bàá odò náà títí ó fi dé Gileadi, kò sí ìlú tí ó lágbára jù fún wa, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa fi gbogbo wọn fún wa.
\v 37 Ní ìbámu pẹ̀lú òfin \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa, ẹ kò súnmọ́ ọ̀kan nínú ilẹ̀ àwọn ará Ammoni, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò dé ilẹ̀ tí ó lọ sí Jabbok, tàbí ilẹ̀ tí ó yí àwọn ìlú òkè e nì ká.
\c 3
\s1 Ìṣẹ́gun Ogu ọba Baṣani
\p
\v 1 \x - \xo 3.1-11: \xt Nu 21.33-35.\x*Lẹ́yìn èyí ní a yípadà tí a sì kọrí sí ọ̀nà tí ó lọ sí Baṣani, Ogu ọba Baṣani àti gbogbo jagunjagun rẹ̀ ṣígun wá pàdé wa ní Edrei.
\v 2 \nd Olúwa\nd* sọ fún mi pé, “Má ṣe bẹ̀rù rẹ̀, nítorí tí mó tí fi òun lé ọ lọ́wọ́, àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, àti ilẹ̀ rẹ̀. Kí ìwọ kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe sí Sihoni ọba Amori ẹni tí ó ń jẹ ọba ní Heṣboni.”
\p
\v 3 Bẹ́ẹ̀ ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa fi Ogu ọba Baṣani àti àwọn jagunjagun rẹ̀ lé wa lọ́wọ́. A kọlù wọ́n títí kò fi ku ẹnìkan fún un láàyè.
\v 4 Ní ìgbà náà ní a gba gbogbo àwọn ìlú rẹ̀. Kò sí ọ̀kankan tí a kò gbà nínú àwọn ọgọta ìlú tí wọ́n ní, gbogbo agbègbè Argobu, lábẹ́ ìjọba Ogu ní Baṣani.
\v 5 Gbogbo ìlú wọ̀nyí ní a mọ odi gíga yíká pẹ̀lú àwọn ìlẹ̀kùn àti irin. Ọ̀pọ̀ àwọn ìlú kéékèèké tí a kò mọ odi yíká sì tún wà pẹ̀lú.
\v 6 Gbogbo wọn ni a parun pátápátá gẹ́gẹ́ bí á ti ṣe sí Sihoni ọba Heṣboni, tí a pa gbogbo ìlú wọn run pátápátá: tọkùnrin tobìnrin àti àwọn ọmọ wọn.
\v 7 Ṣùgbọ́n a kó gbogbo ohun ọ̀sìn àti ìkógun àwọn ìlú wọn, fún ara wa.
\p
\v 8 Ní ìgbà náà ni a ti gba ilẹ̀ tí ó wà ní Jordani láti odò Arnoni, títí dé orí òkè Hermoni lọ́wọ́ àwọn ọba Amori méjèèjì wọ̀nyí.
\v 9 (Àwọn ará Sidoni ń pe Hermoni ní Sirioni. Àwọn Amori sì ń pè é ní Seniri).
\v 10 Gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè olórí títẹ́ náà ni a gbà àti gbogbo Gileadi, àti gbogbo Baṣani, títí dé Saleka, àti Edrei, ìlú àwọn ọba Ogu ní ilẹ̀ Baṣani.
\v 11 (Ogu tí í ṣe ọba Baṣani nìkan ni ó ṣẹ́kù nínú àwọn ará Refaimu. Ibùsùn rẹ̀ ni a fi irin ṣe, ó sì gùn ju ẹsẹ̀ bàtà mẹ́tàlá lọ ní gígùn àti ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà ní ìbú. Èyí sì wà ní Rabba ti àwọn Ammoni.)
\s1 Pínpín ilẹ̀ náà
\p
\v 12 \x - \xo 3.12-20: \xt Nu 32.\x*Nínú àwọn ilẹ̀ tí a gbà ní ìgbà náà, mo fún àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, ní ilẹ̀ tí ó wà ní àríwá Aroeri níbi odò Arnoni, pọ̀ mọ́ ìdajì ilẹ̀ òkè Gileadi pẹ̀lú gbogbo ìlú wọn.
\v 13 Gbogbo ìyókù Gileadi àti gbogbo Baṣani, ní ilẹ̀ ọba Ogu ni mo fún ìdajì ẹ̀yà Manase. (Gbogbo agbègbè Argobu ni Baṣani tí a mọ̀ sí ilẹ̀ àwọn ará Refaimu.
\v 14 Jairi ọ̀kan nínú àwọn ìran Manase gba gbogbo agbègbè Argobu títí dé ààlà àwọn ará Geṣuri àti àwọn ará Maakati; a sọ ibẹ̀ ní orúkọ rẹ̀ torí èyí ni Baṣani fi ń jẹ́ Hafoti-Jairi títí di òní.)
\v 15 Mo sì fi Gileadi fún Makiri,
\v 16 ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Reubeni àti ọmọ Gadi ni mo fún ní ilẹ̀ láti Gileadi lọ dé odò Arnoni (àárín odò náà sì jẹ́ ààlà) títí ó fi dé odò Jabbok. Èyí tí i ṣe ààlà àwọn ará Ammoni.
\v 17 Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Arabah pẹ̀lú, àti Jordani gẹ́gẹ́ bí òpin ilẹ̀ rẹ̀, láti Kinnereti lọ títí dé Òkun pẹ̀tẹ́lẹ̀ Arabah, àní Òkun Iyọ̀, ní ìsàlẹ̀ àwọn orísun Pisga ní ìhà ìlà-oòrùn.
\p
\v 18 Mo pàṣẹ fún un yín ní ìgbà náà pé, “\nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ti fi ilẹ̀ yìí fún un yín láti ní i. Ṣùgbọ́n, gbogbo àwọn ọkùnrin yín tí ó lera tí wọ́n sì ti dira ogun, gbọdọ̀ kọjá síwájú àwọn arákùnrin yín: ará Israẹli.
\v 19 Àwọn ẹ̀yà a yín, àwọn ọmọ yín àti àwọn ohun ọ̀sìn in yín (mo mọ̀ pé ẹ ti ní ohun ọ̀sìn púpọ̀) lè dúró ní àwọn ìlú tí mo fi fún un yín,
\v 20 títí di ìgbà tí \nd Olúwa\nd* yóò fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi bí ó ti fún un yín, àti ìgbà tí àwọn náà yóò fi gba ilẹ̀ náà tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ti fún wọn ní ìhà kejì Jordani. Nígbà náà ni ọ̀kọ̀ọ̀kan yín tó lè padà lọ sí ìní rẹ̀ tí mo fún un.”
\s1 A kò gba Mose láààyè láti kọjá Jordani
\p
\v 21 Nígbà náà ni mo pàṣẹ fún Joṣua pé, “Ìwọ tí fi ojú rẹ rí ohun gbogbo tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ tí ṣe sí àwọn ọba méjèèjì wọ̀nyí. Bẹ́ẹ̀ ni \nd Olúwa\nd* yóò ṣe sí àwọn ilẹ̀ ọba tí ẹ̀yin n lọ.
\v 22 Ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín tìkára rẹ̀ ni yóò jà fún un yín.”
\p
\v 23 \x - \xo 3.23-27: \xt Nu 27.12-14; De 32.48-52.\x*Nígbà náà ni mo bẹ \nd Olúwa\nd* wí pé,
\v 24 “\nd Olúwa\nd* Olódùmarè, ìwọ tí bẹ̀rẹ̀ sí fi títóbi rẹ àti ọwọ́ agbára rẹ han ìránṣẹ́ rẹ. Ọlọ́run wo ló tó bẹ́ẹ̀ láyé àti lọ́run tí ó lè ṣe àwọn iṣẹ́ agbára ńlá tí o ti ṣe?
\v 25 Jẹ́ kí n kọjá lọ wo ilẹ̀ rere ti ìkọjá Jordani, ilẹ̀ òkè dídára nì àti Lebanoni.”
\p
\v 26 Ṣùgbọ́n torí i tiyín, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run bínú sí mi kò sì gbọ́ tèmi. \nd Olúwa\nd* sọ wí pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, ìwọ kò gbọdọ̀ sọ ohunkóhun lórí ọ̀rọ̀ yìí sí mi mọ́.
\v 27 Gòkè lọ sí orí òkè Pisga, sì wò yíká ìwọ̀-oòrùn, ìlà-oòrùn, àríwá àti gúúsù. Fi ojú ara rẹ wo ilẹ̀ náà níwọ̀n bí ìwọ kò tí ní kọjá Jordani yìí.
\v 28 Ṣùgbọ́n yan Joṣua, kí o sì gbà á níyànjú, mú un lọ́kàn le, torí pé òun ni yóò síwájú àwọn ènìyàn wọ̀nyí kọjá, yóò sì jẹ́ kí wọn jogún ilẹ̀ náà tí ìwọ yóò rí.”
\v 29 Báyìí ni a dúró ní àfonífojì ní ẹ̀bá Beti-Peori.
\c 4
\s1 Mose pàṣẹ ìgbọ́ràn
\p
\v 1 Gbọ́ Israẹli, gbọ́ òfin àti ìlànà tí èmi yóò kọ́ ọ yín. Ẹ tẹ̀lé wọn kí ẹ ba à lè yè, kí ẹ ba à lè lọ láti gba ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run àwọn baba yín yóò fi fún un yín.
\v 2 \x - \xo 4.2: \xt If 22.18,19.\x*Ẹ má ṣe fi kún àwọn ohun tí mo pàṣẹ fún un yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ yọ kúrò nínú wọn, ṣùgbọ́n ẹ pa òfin \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín tí mo fún un yín mọ́.
\p
\v 3 Ẹ ti fi ojú ara yín rí ohun tí \nd Olúwa\nd* ṣe ní Baali-Peori. \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín run gbogbo àwọn tí ó tẹ̀lé òrìṣà Baali-Peori kúrò ní àárín yín.
\v 4 Ṣùgbọ́n gbogbo ẹ̀yin tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run láìyẹsẹ̀ ni ẹ wà láààyè lónìí.
\p
\v 5 Ẹ kíyèsi i, mo ti kọ́ ọ yín ní àwọn òfin àti àṣẹ bí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run mi ti pàṣẹ fún mi, kí ẹ ba à le tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ náà tí ẹ ń lọ láti ní ní ìní.
\v 6 Ẹ máa kíyèsi wọn dáradára. Èyí ni yóò fi ọgbọ́n àti òye yín han àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn tí wọn yóò gbọ́ nípa àwọn ìlànà wọ̀nyí, tí wọn yóò sì máa wí pé, “Dájúdájú, orílẹ̀-èdè ńlá yìí kún fún ọgbọ́n àti òye.”
\v 7 Orílẹ̀-èdè olókìkí wo ni ọlọ́run wọn tún súnmọ́ wọn, bí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa ti súnmọ́ wa nígbàkígbà tí a bá ń ké pè é?
\v 8 Orílẹ̀-èdè wo ló tún le lókìkí láti ní àwọn ìlànà òdodo, àti òfin gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin wọ̀nyí tí mo ń gbé kalẹ̀ fún un yín lónìí.
\p
\v 9 \x - \xo 4.9-14: \xt El 19.120.21.\x*Kìkì i kí ẹ kíyèsára, kí ẹ sì ṣọ́ra a yín gidigidi kí ẹ má ba à gbàgbé àwọn ohun tí ojú yín ti rí, kí wọn má sì ṣe sá kúrò lóókan àyà yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ sì wà láààyè. Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ wọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn wọn.
\v 10 Ẹ rántí ọjọ́ tí ẹ dúró níwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ní Horebu, nígbà tí ó wí fún mi pé, “Kó àwọn ènìyàn wọ̀nyí jọ síwájú mi láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí wọ́n lè kọ́ láti máa bu ọlá náà fún mi ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá gbé lórí ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì le è fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn.”
\v 11 Ẹ̀yin súnmọ́ tòsí, ẹ sì dúró ní ẹsẹ̀ òkè náà, òkè náà sì ń jóná dé agbede-méjì ọrun, pẹ̀lú òkùnkùn, àti àwọsánmọ̀, àti òkùnkùn biribiri.
\v 12 \nd Olúwa\nd* sì bá yín sọ̀rọ̀ láti àárín iná náà wá. Ẹ gbọ́ àwọn ìró ohùn, ṣùgbọ́n ẹ kò rí ẹnikẹ́ni, ohùn nìkan ni ẹ gbọ́.
\v 13 \x - \xo 4.13: \xt El 31.18; 34.28; De 9.10.\x*Ó sọ àwọn májẹ̀mú rẹ̀ fún un yín àní àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó pàṣẹ fún un yín láti máa tẹ̀lé, ó sì kọ wọ́n sórí wàláà òkúta méjì.
\v 14 \x - \xo 4.14: \xt El 21.1.\x*\nd Olúwa\nd* sì pàṣẹ fún mi nígbà náà láti kọ yín ní ìlànà àti ìdájọ, kí ẹ̀yin kí ó lè máa ṣe wọ́n ní ilẹ̀ náà, ní ibi tí ẹ̀yin ń lọ láti gbà á.
\s1 Èèwọ̀ ni ìbọ̀rìṣà jẹ́
\p
\v 15 Ẹ kíyèsára gidigidi, torí pé, ẹ kò rí ìrísí ohunkóhun ní ọjọ́ tí \nd Olúwa\nd* bá yín sọ̀rọ̀ ní Horebu láti àárín iná wá. Torí náà ẹ ṣọ́ra yín gidigidi,
\v 16 kí ẹ ma ba à ba ara yín jẹ́ nípa ṣíṣe ère fún ara yín, àní ère lóríṣìíríṣìí yálà èyí tí ó ní ìrísí ọkùnrin tàbí tí obìnrin,
\v 17 tàbí ti ẹranko orí ilẹ̀, tàbí ti ẹyẹ tí ń fò ní òfúrufú,
\v 18 tàbí ti àwòrán onírúurú ẹ̀dá tí ń fà lórí ilẹ̀, tàbí ti ẹja nínú omi.
\v 19 Bí ẹ bá wòkè tí ẹ rí oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀: àwọn ohun tí a ṣe lọ́jọ̀ sójú ọ̀run, ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ dé bi pé ẹ̀yin yóò foríbalẹ̀ fún wọn, àti láti máa sin ohun tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín dá fún gbogbo orílẹ̀-èdè lábẹ́ ọ̀run.
\v 20 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín sì ti mú ẹ̀yin jáde kúrò nínú iná ìléru ńlá, àní ní Ejibiti, láti lè jẹ́ ènìyàn ìní i rẹ̀, bí ẹ̀yin ti jẹ́ báyìí.
\p
\v 21 Inú \nd Olúwa\nd* ru sí mi nítorí yín, ó sì ti búra pé èmi kì yóò la Jordani kọjá, èmi kì yóò sì wọ ilẹ̀ rere tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run fi fún un yín, ní ìní yín.
\v 22 Èmi yóò kú ní ilẹ̀ yìí, èmi kì yóò la Jordani kọjá, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti fẹ́ rékọjá sí òdìkejì odò láti gba ilẹ̀ rere náà.
\v 23 Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe gbàgbé májẹ̀mú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín tí ó ti bá a yín dá. Ẹ má ṣe ṣe ère ní ìrísí ohunkóhun fún ara yín, èèwọ̀ ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín kà á sí.
\v 24 Torí pé iná ajónirun ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, Ọlọ́run owú ni.
\p
\v 25 Lẹ́yìn ìgbà tí ẹ ti ní àwọn ọmọ àti àwọn ọmọ ọmọ, tí ẹ sì ti gbé ní ilẹ̀ yìí pẹ́, bí ẹ bá wá ba ara yín jẹ́ nípa ṣíṣe irú ère yówù tó jẹ́, tí ẹ sì ṣe búburú lójú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, tí ẹ sì mú un bínú.
\v 26 Mo pe ọ̀run àti ayé láti jẹ́rìí takò yín lónìí, pé kíákíá ni ẹ ó parun ní ilẹ̀ náà tí ẹ ń la Jordani kọjá lọ láti gbà. Ẹ kò ní pẹ́ ní ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò run pátápátá.
\v 27 \nd Olúwa\nd* yóò fọ́n yín ká sí àárín àwọn ènìyàn náà, àwọn díẹ̀ nínú yín ni yóò yè láàrín orílẹ̀-èdè tí \nd Olúwa\nd* yóò fọ́n yín sí.
\v 28 Ẹ ó sì máa sin ọlọ́run tí á fi ọwọ́ ènìyàn ṣe: tí wọ́n fi igi àti òkúta ṣe, èyí tí kò le ríran, gbọ́rọ̀, jẹun tàbí gbọ́ òórùn.
\v 29 Bí ẹ̀yin bá wá \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín láti bẹ̀ ẹ́, ẹ ó ri i, bí ẹ bá wá a, pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo àyà a yín.
\v 30 Bí ẹ bá wà nínú wàhálà, bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ṣẹlẹ̀ sí yín, láìpẹ́ ẹ ó tún padà tọ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín wá, ẹ ó sì gbọ́ tirẹ̀.
\v 31 Nítorí pé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín aláàánú ni, kò ní gbàgbé tàbí pa yín rẹ́ tàbí kó gbàgbé májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín, èyí tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ìbúra.
\s1 \nd Olúwa\nd* ni Ọlọ́run
\p
\v 32 Ẹ béèrè báyìí nípa ti àwọn ọjọ́ ìgbàanì ṣáájú kí a tó bí i yín, láti ìgbà tí Ọlọ́run ti dá ènìyàn sórí ilẹ̀ ayé. Ẹ béèrè láti igun ọ̀run kan sí èkejì. Ǹjẹ́ irú nǹkan olókìkí báyìí: ti ṣẹlẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a ti gbọ́ irú u rẹ̀ rí?
\v 33 Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn mìíràn tí ì gbọ́ ohùn Ọlọ́run rí, tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti inú iná, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti gbọ́ tí ẹ sì yè?
\v 34 Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan ti gbìyànjú àti mú orílẹ̀-èdè kan jáde kúrò nínú òmíràn fúnra rẹ̀ rí, nípa ìdánwò, nípa iṣẹ́ àmì, àti iṣẹ́ ìyanu nípa ogun, tàbí nípa ọwọ́ agbára tàbí nína apá, àti nípa ẹ̀rù ńlá: gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ṣe fún un yín ní Ejibiti ní ojú ẹ̀yin tìkára yín?
\p
\v 35 A fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn yín kí ẹ bá a lè gbà pé \nd Olúwa\nd* ni Ọlọ́run. Kò sì sí ẹlòmíràn lẹ́yìn rẹ̀.
\v 36 Ó jẹ́ kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ láti ọ̀run wá, láti kọ́ ọ yín. Ní ayé, ó fi iná ńlá rẹ̀ hàn yín, ẹ sì gbọ́ ohùn rẹ̀ láti àárín iná wá,
\v 37 torí pé ó fẹ́ràn àwọn baba ńlá yín, ó sì yan àwọn ọmọ wọn ní ipò lẹ́yìn wọn. Nípa ìwà láààyè àti nípa agbára ńlá rẹ̀ ni ó fi mú un yín kúrò ní Ejibiti.
\v 38 Láti lé àwọn orílẹ̀-èdè tí ó tóbi tí ó sì lágbára níwájú yín; láti le è mú un yín wá sí ilẹ̀ wọn kí ẹ lè jogún rẹ̀ bí ó ti rí lónìí.
\p
\v 39 Ẹ gbà kí ẹ sì fi sọ́kàn lónìí pé \nd Olúwa\nd* ni Ọlọ́run lókè ọ̀run lọ́hùn ún àti ní ilẹ̀ ní ìsàlẹ̀ níhìn-ín. Kò sí òmíràn mọ́.
\v 40 Ẹ pa àwọn ìlànà àti àṣẹ rẹ̀ mọ́ tí mo ń fún un yín lónìí; kí ó ba à le è yẹ yín, kí ẹ̀yin sì le è pẹ́ ní ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín fún un yín ní gbogbo ìgbà.
\s1 Àwọn ìlú ààbò
\p
\v 41 \x - \xo 4.41-43: \xt Nu 35.6,9-34; De 19.2-13; Jo 20.7-9.\x*Mose sì ya àwọn ìlú mẹ́ta kan sọ́tọ̀ ní apá ìwọ̀-oòrùn Jordani.
\v 42 Kí apànìyàn kí ó lè máa sá síbẹ̀, tí ó bá ṣi ẹnìkejì rẹ̀ pa, tí kò sì kórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, àti pé bí ó bá sá sí ọ̀kan nínú ìlú wọ̀nyí kí ó lè là.
\v 43 Àwọn ìlú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà nìwọ̀nyí: Beseri ní ijù, ní ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀, tí àwọn ọmọ Reubeni; Ramoti ní Gileadi, ti àwọn ọmọ Gadi àti Golani ní Baṣani, ti àwọn ará Manase.
\s1 Ìfáàrà sí òfin
\p
\v 44 Èyí ni òfin tí Mose gbé kalẹ̀ fún àwọn ará Israẹli.
\v 45 Wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀rí, àti ìlànà àti ìdájọ́ tí Mose fi lélẹ̀ fún ún àwọn ọmọ Israẹli, lẹ́yìn tí wọ́n ti jáde kúrò ní Ejibiti.
\v 46 Tí wọ́n sì wà ní ẹ̀bá àfonífojì Beti-Peori ní ìlà-oòrùn Jordani; ní ilẹ̀ Sihoni, ọba àwọn Amori tí ó jẹ ọba Heṣboni tí Mose àti àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ́gun, bí wọ́n ṣe ń ti Ejibiti bọ̀.
\v 47 Wọ́n gba ilẹ̀ rẹ̀, àti ilẹ̀ Ogu ọba Baṣani àwọn ọba Amori méjèèjì tí ń bẹ ní ìlà-oòrùn Jordani.
\v 48 Ilẹ̀ wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri ní etí odò Arnoni dé orí òkè Sirioni (èyí ni Hermoni).
\v 49 Àti gbogbo aginjù ní ìlà-oòrùn Jordani títí dé Òkun Iyọ̀ ní ìsàlẹ̀ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Pisga.
\c 5
\s1 Àwọn òfin mẹ́wàá
\p
\v 1 Mose sì pe gbogbo Israẹli jọ, ó sì wí pé,
\p Gbọ́ ìwọ Israẹli, gbọ́ ìlànà àti òfin tí mo mú wá sí etí ìgbọ́ ọ yín lónìí. Ẹ kọ wọ́n, kí ẹ sì ri dájú pé ẹ̀ ń ṣe wọ́n.
\v 2 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa bá wa dá májẹ̀mú ní Horebu.
\v 3 Kì í ṣe àwọn baba wa ni \nd Olúwa\nd* bá dá májẹ̀mú yìí bí kò ṣe àwa, àní pẹ̀lú gbogbo àwa tí a wà láààyè níbí lónìí.
\v 4 \nd Olúwa\nd* bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú láàrín iná lórí òkè.
\v 5 (Ní ìgbà yìí, mo wà láàrín ẹ̀yin pẹ̀lú Ọlọ́run láti sọ ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* fún un yín torí pé ẹ̀rù Ọlọ́run ń bà yín, ẹ kò sì lè kọjá lọ sórí òkè.)
\p Ó sì wí pé,
\b
\li4
\v 6 \x - \xo 5.6-21: \xt El 20.2-17.\x*“Èmi ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti, láti oko ẹrú jáde wá.
\b
\li1
\v 7 “Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi.
\li1
\v 8 Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara yín, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ ní òkè ọ̀run, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀.
\v 9 Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n; nítorí Èmi \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run owú ni mí, tí ń bẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wò lára àwọn ọmọ, láti ìran kẹta títí dé ẹ̀kẹrin nínú àwọn tí ó kórìíra mi.
\v 10 Èmi a sì máa fi àánú hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ó fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́.
\li1
\v 11 Ẹ má ṣe ṣi orúkọ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín lò, torí pé ẹnikẹ́ni tí o bá ṣi orúkọ rẹ̀ lò kì yóò lọ láìjẹ̀bi.
\li1
\v 12 \x - \xo 5.12: \xt El 16.23-30; 31.12-14.\x*Rántí ọjọ́ ìsinmi láti yà á sí mímọ́, bí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín.
\v 13 \x - \xo 5.13,14: \xt El 23.12; 31.15; 34.21; 35.2; Le 23.3.\x*Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò fi ṣiṣẹ́, kí ìwọ kí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ.
\v 14 Ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ: nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan: ìwọ, àti ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, àti akọ màlúù rẹ, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, àti ohun ọ̀sìn rẹ kan, àti àlejò tí ń bẹ nínú ibodè rẹ; kí ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin kí ó lè sinmi gẹ́gẹ́ bí ìwọ.
\v 15 Sì rántí pé, ìwọ ti jẹ́ ẹrú ní Ejibiti rí, àti pé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ yọ ọ́ kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú agbára ńlá, àti nína ọwọ́ rẹ̀. Torí èyí ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ ṣe pàṣẹ fún ọ láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́.
\li1
\v 16 \x - \xo 5.16-20: \xt Mt 19.18,19; Mk 10.19; Lk 18.20.\x*\x - \xo 5.16: \xt Mt 15.4; Mk 7.10; Ef 6.3.\x*Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ, bí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún ọ, kí ọjọ́ rẹ kí ó lè pẹ́, àti kí ó lè dára fún ọ ní ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.
\li1
\v 17 \x - \xo 5.17,18: \xt Jk 2.11.\x*\x - \xo 5.17-21: \xt Ro 13.9.\x*Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn.
\li1
\v 18 Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.
\li1
\v 19 Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.
\li1
\v 20 Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ.
\li1
\v 21 \x - \xo 5.21: \xt Ro 7.7.\x*Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí aya ẹnìkéjì rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ẹnìkéji rẹ, oko rẹ̀, àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọ màlúù rẹ̀ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, àti ohun gbogbo tí í ṣe ti ẹnìkéji rẹ.”
\b
\p
\v 22 \x - \xo 5.22-27: \xt El 20.18-21.\x*Wọ̀nyí ni àwọn àṣẹ \nd Olúwa\nd* tí a kéde rẹ̀ sí gbogbo ìpéjọpọ̀ ọ yín, níbẹ̀ ní orí òkè, láàrín iná, ìkùùkuu àti òkùnkùn biribiri, kò sì fi ohunkóhun kún un mọ́. Ó sì kọ wọ́n sínú wàláà méjì, Ó sì fi wọ́n lé mi lọ́wọ́.
\p
\v 23 Nígbà tí ẹ gbóhùn láti inú òkùnkùn wá, nígbà tí iná náà ń yọ iná lala, àwọn aṣáájú ẹ̀yà a yín àti àwọn àgbàgbà yín tọ̀ mí wá.
\v 24 Ẹ sì sọ pé, “\nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa ti fi ògo rẹ̀ hàn wá, àti títóbi rẹ̀ a sì ti gbóhùn rẹ̀ láti àárín iná wá. A ti rí i lónìí pé, ènìyàn sì lè wà láààyè lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá bá a sọ̀rọ̀.
\v 25 Ṣùgbọ́n èéṣe tí àwa yóò fi kú? Iná ńlá yìí yóò jó wa run, bí àwa bá sì tún gbọ́ ohun \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa, àwa ó kú.
\v 26 Ta ni nínú ẹlẹ́ran ara tí ó ti gbọ́ ohun Ọlọ́run alààyè láti inú iná rí, bí àwa ti gbọ́ ọ, tí a sì wà láyé?
\v 27 Súnmọ́ tòsí ibẹ̀ kí o sì gbọ́ gbogbo ohun tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa yóò sọ, nígbà náà sọ ohunkóhun tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa sọ fún ọ fún wa. A ó sì fetísílẹ̀, a ó sì gbọ́rọ̀.”
\p
\v 28 \nd Olúwa\nd* ń gbọ́ nígbà tí ẹ̀yin ń bá mi sọ̀rọ̀, \nd Olúwa\nd* sì sọ fún mi pé, “Mo ti gbọ́ ohun tí àwọn ènìyàn yí sọ fún ọ. Gbogbo ohun tí wọ́n sọ dára,
\v 29 ìbá ti dára tó, bí ọkàn wọn bá lè bẹ̀rù mi, tí ó sì ń pa gbogbo òfin mi mọ́ nígbà gbogbo, kí ó bá à lè dára fún wọn, àti àwọn ọmọ wọn láéláé.
\p
\v 30 “Lọ sọ fún wọn kí wọn padà sínú àgọ́ wọn.
\v 31 Ṣùgbọ́n ìwọ túbọ̀ dúró síbí pẹ̀lú mi, kí n bá à lè fún ọ ní àwọn àṣẹ tí o gbọdọ̀ fi kọ́ wọn láti máa tẹ̀lé ní ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún wọn láti ní.”
\p
\v 32 Torí èyí, ẹ ṣọ́ra láti máa ṣe ohun tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín tí pa ní àṣẹ fún un yín; ẹ má ṣe yà sọ́tùn ún tàbí sósì.
\v 33 Ẹ rìn ní gbogbo ọ̀nà tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín, kí ẹ bá à le yè, kí ó sì dára fún un yín, kí ọjọ́ ọ yín bá à lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin yóò gbà.
\c 6
\s1 Fẹ́ràn \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ
\p
\v 1 Wọ̀nyí ni àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín pàṣẹ fún mi láti kọ́ ọ yín kí ẹ lè kíyèsi i, ní ilẹ̀ náà tí ẹ ó ni lẹ́yìn tí ẹ bá kọjá a Jordani.
\v 2 Kí ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ wọn, lẹ́yìn wọn bá à lè bẹ̀rù \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá wà láyé, nípa pípa àwọn ìlànà àti àṣẹ rẹ̀ tí mo fún un yín mọ́, kí ẹ bá à lè pẹ́ lórí ilẹ̀.
\v 3 Gbọ́ ìwọ Israẹli, kí o sì ṣọ́ra láti gbọ́rọ̀, kí ó bá à lè dára fún ọ, kí o bá à lè gbilẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ní ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti fún oyin, gẹ́gẹ́ bí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run àwọn baba rẹ ti ṣèlérí fún ọ.
\p
\v 4 \x - \xo 6.4,5: \xt Mt 22.37; Mk 12.29,30; Lk 10.27.\x*Gbọ́ ìwọ Israẹli, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa, \nd Olúwa\nd* kan ni.
\v 5 Fẹ́ràn \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ.
\v 6 \x - \xo 6.6-9: \xt De 6.20-25; 11.18-20.\x*Àwọn àṣẹ tí mo fún un yín lónìí gbọdọ̀ máa wà lóókan àyà yín.
\v 7 Ẹ fi kọ́ àwọn ọmọ yín gidigidi. Bí ẹ bá jókòó nínú ilé, ẹ jíròrò nípa wọn, àti nígbà tí ẹ bá ń rìn ní ojú ọ̀nà, bí ẹ bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí ẹ bá dìde.
\v 8 \x - \xo 6.8: \xt El 13.9,16; De 11.18.\x*Ẹ so wọ́n sí ọwọ́ yín fún àmì, ẹ so ó mọ́ iwájú orí yín.
\v 9 Kí ìwọ kí ó kọ wọ́n sára òpó ilé rẹ̀, àti sí ara ìlẹ̀kùn ọ̀nà òde rẹ.
\p
\v 10 Nígbà tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín bá mú yín dé ilẹ̀ náà tí ó ti búra fún àwọn baba yín, fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu láti fi fún un yín, ilẹ̀ tí ó kún fún àwọn ìlú ńlá ńlá tí kì í ṣe ẹ̀yin ló kọ́ ọ,
\v 11 àwọn ilé tí ó kún fún gbogbo ohun mèremère tí kì í ṣe ẹ̀yin ló rà wọ́n, àwọn kànga tí ẹ kò gbẹ́, àti àwọn ọgbà àjàrà àti èso olifi tí kì í ṣe ẹ̀yin ló gbìn wọ́n. Nígbà tí ẹ bá jẹ tí ẹ sì yó,
\v 12 ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe gbàgbé \nd Olúwa\nd*, tí o mú un yín jáde láti Ejibiti wá, kúrò ní oko ẹrú.
\p
\v 13 \x - \xo 6.13: \xt Mt 4.10; Lk 4.8.\x*Bẹ̀rù \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ, Òun nìkan ni kí o sì máa sìn, búra ní orúkọ rẹ̀ nìkan.
\v 14 Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run àwọn tí ó yí i yín ká;
\v 15 torí pé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín tí ó wà láàrín yín, Ọlọ́run owú ni, ìbínú rẹ̀ yóò sì run yín kúrò ní ilẹ̀ náà.
\v 16 \x - \xo 6.16: \xt Mt 4.7; Lk 4.12.\x*Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ dán \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín wò bí ẹ̀yin ti dán wò ní Massa.
\v 17 Ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń pa àwọn òfin \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín mọ́ àti àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà tí ó ti fún un yín.
\v 18 Ẹ ṣe èyí tí ó dára tí ó sì tọ́ lójú \nd Olúwa\nd*, kí ó bá à lè dára fún un yín, kí ẹ̀yin bá à lè lọ láti gba ilẹ̀ dáradára náà tí Ọlọ́run ti fi ìbúra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá a yín.
\v 19 Ẹ̀yin yóò sì ti àwọn ọ̀tá yín jáde níwájú u yín bí \nd Olúwa\nd* ti ṣèlérí.
\p
\v 20 Ní ọjọ́ iwájú, bí ọmọ rẹ bá béèrè pé, “Kí ni ìtumọ̀ àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin wọ̀nyí tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún ọ?”
\v 21 Sọ fún un pé: “Ẹrú Farao ní ilẹ̀ Ejibiti ni wá tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n \nd Olúwa\nd* fi ọwọ́ agbára ńlá yọ wá jáde lóko ẹrú Ejibiti.
\v 22 Lójú wa ni \nd Olúwa\nd* tí ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu: tí ó lágbára tí ó sì ba ni lẹ́rù: lórí Ejibiti àti Farao, àti gbogbo ènìyàn rẹ̀.
\v 23 Ṣùgbọ́n ó mú wa jáde láti ibẹ̀ wá láti mú wa wọ inú àti láti fún wa ní ilẹ̀ tí ó ti fì búra fún àwọn baba ńlá wa.
\v 24 \nd Olúwa\nd* pàṣẹ fún wa láti ṣe ìgbọ́ràn sí gbogbo ìlànà wọ̀nyí, láti bẹ̀rù \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa, kí ó ba à lè máa dára fún wa nígbà gbogbo, kí a sì lè wà láyé, bí a ṣe wà títí di òní.
\v 25 Bí a bá ṣọ́ra láti pa gbogbo òfin wọ̀nyí mọ́ níwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa, bí ó ti pàṣẹ fún wa, èyí ni yóò máa jẹ́ òdodo wa.”
\c 7
\s1 Lílé àwọn orílẹ̀-èdè jáde
\p
\v 1 \x - \xo 7.1: \xt Ap 13.19.\x*Nígbà tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ bá mú ọ dé ilẹ̀ náà, tí ìwọ yóò wọ̀ lọ láti gbà, tí ìwọ yóò sì lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè kúrò níwájú rẹ. Àwọn ará Hiti, Girgaṣi, Amori, Kenaani, Peresi, Hifi àti àwọn ará Jebusi. Àwọn orílẹ̀-èdè méje tí wọ́n lágbára tí wọ́n sì pọ̀jù ọ lọ,
\v 2 \x - \xo 7.2-4: \xt El 23.32,33; 34.12,15,16.\x*nígbà tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ bá sì ti fi wọ́n lé ẹ lọ́wọ́, tí ìwọ sì ti ṣẹ́gun wọn, kí ìwọ kí ó sì pa wọ́n run pátápátá. Má ṣe bá wọn ṣe àdéhùn àlàáfíà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣàánú fún wọn.
\v 3 \x - \xo 7.3: \xt El 34.15,16.\x*Ìwọ kò gbọdọ̀ bá wọn dá àna. Àwọn ọmọbìnrin rẹ kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọkùnrin wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ,
\v 4 torí pé wọ́n yóò yí àwọn ọmọ rẹ padà kúrò lẹ́yìn mi, láti jẹ́ kí wọn máa sin òrìṣà, ìbínú \nd Olúwa\nd* yóò sì wá sórí rẹ, yóò sì run yín kíákíá.
\v 5 \x - \xo 7.5: \xt El 23.24; 34.13; Nu 33.52; De 12.3.\x*Èyí ni kí ẹ ṣe sí wọn, ẹ wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ bi òpó òkúta ibi mímọ́ òrìṣà wọn lulẹ̀, òpó òrìṣà Aṣerah wọn ni kí ẹ gé lulẹ̀ kí ẹ sì sun ère òrìṣà wọn ní iná.
\v 6 \x - \xo 7.6: \xt El 19.5; 22.31; Le 11.44,45; 19.2; 20.7,26; Nu 15.40; De 14.2,21; 26.19; 28.9.\x*Torí pé ènìyàn mímọ́ ni ẹ jẹ́ sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ti yàn yín láàrín gbogbo ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé, láti jẹ́ ènìyàn rẹ̀: ohun ìní iyebíye rẹ̀.
\p
\v 7 \nd Olúwa\nd* kò torí pé ẹ pọ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ju àwọn ènìyàn yòókù lọ yàn yín, ẹ̀yin sá à lẹ kéré jù nínú gbogbo ènìyàn.
\v 8 Ṣùgbọ́n torí \nd Olúwa\nd* fẹ́ràn yín, tí ó sì pa ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín mọ́ ni ó ṣe fi ọwọ́ agbára ńlá mú un yín jáde tí ó sì rà yín padà nínú oko ẹrú, àti láti ọwọ́ agbára Farao ọba Ejibiti.
\v 9 Nítorí náà ẹ mọ̀ dájúdájú pé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, Òun ni Ọlọ́run, Ọlọ́run olóòtítọ́ ni, tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran, àwọn tí ó fẹ́ ẹ tí ó sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
\v 10 Ṣùgbọ́n
\q1 àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ ni yóò san ẹ̀san fún ní gbangba nípa pípa wọ́n run;
\q2 kì yóò sì jáfara láti san ẹ̀san fún àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ ní gbangba.
\m
\v 11 Nítorí náà ẹ kíyèsi láti máa tẹ̀lé àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin tí mo fun un yín lónìí.
\p
\v 12 \x - \xo 7.12-16: \xt De 11.13-17.\x*Bí ẹ bá ń kíyèsi àwọn òfin wọ̀nyí tí ẹ sì ń ṣọ́ra láti ṣe wọ́n, nígbà náà ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín yóò pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún un yín, bí ó ti búra fún àwọn baba ńlá a yín.
\v 13 Yóò fẹ́ràn yín, yóò bùkún un yín yóò sì mú kí ẹ pọ̀ sí i. Yóò bùkún èso inú yín, ọ̀gbìn ilẹ̀ yín, oúnjẹ yín, wáìnì tuntun àti òróró yín, àwọn màlúù, agbo ẹran yín, àti àwọn àgùntàn, ọ̀wọ́ ẹran yín, ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá yín láti fún un yín.
\v 14 A ó bùkún un yín ju gbogbo ènìyàn lọ, kò sí ẹni tí yóò yàgàn nínú ọkùnrin tàbí obìnrin yín, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ọ̀kan nínú àwọn ohun ọ̀sìn in yín tí yóò wà láìlọ́mọ.
\v 15 \nd Olúwa\nd* yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ààrùn gbogbo, kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí ààrùn búburú tí ẹ mọ̀ ní Ejibiti wá sára yín, ṣùgbọ́n yóò fi wọ́n lé ara gbogbo àwọn tí ó kórìíra yín.
\v 16 Gbogbo àwọn ènìyàn tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín fi lé yín lọ́wọ́ ni kí ẹ parun pátápátá. Ẹ má ṣe ṣàánú fún wọn, ẹ má ṣe sin olúwa ọlọ́run wọn torí pé ìdánwò ni èyí jẹ́ fún un yín.
\p
\v 17 Ẹ lè máa rò láàrín ara yín pé, “Àwọn orílẹ̀-èdè yìí lágbára jù wá lọ. Báwo ni a o ṣe lé wọn jáde?”
\v 18 Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, ẹ rántí dáradára ohun tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ṣe sí Farao àti gbogbo Ejibiti.
\v 19 Ẹ sá à fi ojú u yín rí àwọn àdánwò ńlá, àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá, ọwọ́ agbára àti nínà ọwọ́ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín fi mú un yín jáde. \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín yóò ṣe bákan náà sí gbogbo àwọn ènìyàn náà tí ẹ ń bẹ̀rù.
\v 20 Pẹ̀lúpẹ̀lú, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín yóò rán oyin sáàrín wọn títí tí àwọn tí ó sálà tí wọ́n sá pamọ́ fún un yín, yóò fi ṣègbé.
\v 21 Ẹ má gbọ̀n jìnnìjìnnì torí wọn, torí pé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín tí ó wà láàrín yín, Ọlọ́run alágbára ni, àti Ọlọ́run tí ó tóbi lọ́pọ̀lọ́pọ̀.
\v 22 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín yóò lé gbogbo orílẹ̀-èdè wọ̀n-ọn-nì kúrò níwájú u yín díẹ̀díẹ̀. A kò nígbà yín láààyè láti lé wọn dànù lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Kí àwọn ẹranko igbó má ba à gbilẹ̀ sí i láàrín yín.
\v 23 Ṣùgbọ́n \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín yóò fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́, yóò sì máa fà wọ́n sínú dàrúdàpọ̀ títí tí wọn yóò fi run.
\v 24 Yóò fi àwọn ọba wọn lé e yín lọ́wọ́, ẹ̀yin ó sì pa orúkọ wọn rẹ́ lábẹ́ ọ̀run. Kò sí ẹni tí yóò lè dojú ìjà kọ yín títí tí ẹ ó fi pa wọ́n run.
\v 25 Dá iná sun àwọn ère òrìṣà wọn, ẹ má ṣe ṣe ojúkòkòrò sí fàdákà tàbí wúrà tí ó wà lára wọn. Ẹ má ṣe mú un fún ara yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò jẹ́ ìdẹ̀kùn fún un yín, torí pé ìríra ni sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín.
\v 26 Ẹ má ṣe mú ohun ìríra wá sí ilé yín, kí ìwọ má ba à di ẹni ìparun bí i rẹ̀. Ẹ kórìíra rẹ̀ kí ẹ sì kà á sí ìríra pátápátá, torí pé a yà á sọ́tọ̀ fún ìparun ni.
\c 8
\s1 Má ṣe gbàgbé \nd Olúwa\nd*
\p
\v 1 Ẹ kíyèsi i láti máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ tí mo fún un yín lónìí, kí ẹ bá à le yè, kí ẹ sì pọ̀ sí i wọ ilẹ̀ náà, kí ẹ sì le gba ilẹ̀ náà, tí \nd Olúwa\nd* fì búra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá a yín.
\v 2 Ẹ rántí bí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ti tọ́ ọ yín ṣọ́nà ní gbogbo ọ̀nà ní aginjù fún ogójì ọdún wọ̀nyí láti tẹ orí yín ba àti láti dán an yín wò kí ó ba à le mọ bí ọkàn yín ti rí, bóyá ẹ ó pa òfin rẹ̀ mọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.
\v 3 \x - \xo 8.3: \xt Mt 4.4; Lk 4.4.\x*Ó rẹ̀ yín sílẹ̀ nípa fífi ebi pa yín, Ó sì fi manna bọ́ ọ yín, èyí tí ẹ kò mọ̀, tí àwọn baba yín kò mọ̀, kí ó ba à lè kọ́ ọ yín pé, ènìyàn kò ti ipa oúnjẹ nìkan wà láààyè, bí kò ṣe ohun gbogbo tí ó jáde láti ẹnu \nd Olúwa\nd* wá.
\v 4 Aṣọ yín kò gbó mọ́ ọn yín lọ́rùn bẹ́ẹ̀ ní ẹsẹ̀ yín kò sì wú, ní ogójì ọdún náà.
\v 5 Ẹ mọ̀ ní ọkàn an yín pé, bí baba ti ń kọ́ ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ń kọ́ ọ yín.
\p
\v 6 Nítorí èyí, ẹ gbọdọ̀ pa òfin \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín mọ́, nípa rínrìn ní ọ̀nà rẹ̀, àti bíbẹ̀rù rẹ̀.
\v 7 Nítorí pé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ń mú un yín bọ̀ wá sí ilẹ̀ rere ilẹ̀ tí ó kún fún odò àti ibú omi, pẹ̀lú àwọn ìsun tí ń sàn jáde láti orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀.
\v 8 Ilẹ̀ tí ó kún fún jéró àti ọkà barle, tí ó sì kún fún àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́, igi pomegiranate, òróró olifi àti oyin.
\v 9 Ilẹ̀ tí oúnjẹ kò ti wọ́n, kò sí ohun tí ẹ̀yin yóò ṣe aláìní, ilẹ̀ tí irin ti pọ̀ bí òkúta, ẹ̀yin sì lè wa idẹ jáde láti inú òkè rẹ̀ wá.
\p
\v 10 Nígbà tí ẹ bá ti jẹ tí ẹ sì yó tán ẹ yin \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín fún pípèsè ilẹ̀ rere fún un yín.
\v 11 \x - \xo 8.11-16: \xt Ho 13.5,6.\x*Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má gbàgbé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, nípa kíkùnà láti pa àṣẹ rẹ̀, àwọn òfin rẹ̀, àti àwọn ìlànà rẹ̀ tí mo ń fún un yín lónìí mọ́.
\v 12 Kí ó má ba à jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun yó tán, tí ẹ bá kọ́ ilé tí ó dára tán, tí ẹ sí ń gbé inú rẹ̀,
\v 13 nígbà tí àwọn agbo màlúù yín àti tí ewúrẹ́ ẹ yín bá pọ̀ sí i tán, tí fàdákà àti wúrà yín sì ń peléke sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní sì ń pọ̀ sí i,
\v 14 nígbà náà ni ọkàn yín yóò gbéga, tí ẹ̀yin yóò sì gbàgbé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá, nínú oko ẹrú.
\v 15 Òun ni ó mú un yín la aginjù ẹlẹ́rù ńlá já, ilẹ̀ tí kò sí omi tí ó sì kún fún òǹgbẹ, pẹ̀lú àwọn ejò olóró ńlá ńlá àti àkéekèe. Ó mú omi jáde fún un yín láti inú àpáta.
\v 16 Ó fún yín ní manna láti jẹ nínú aginjù, ohun tí àwọn baba yín kò mọ̀ rí, kí Òun bá à le tẹ orí yín ba kí ó sì lè dán an yín wò, kí ó bá à lè dára fún un yín.
\v 17 Ẹ lè rò nínú ara yín pé, “Agbára mi àti iṣẹ́ ọwọ́ mi ni ó mú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá fún mi.”
\v 18 Ṣùgbọ́n ẹ rántí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín tí ó fún un yín ní agbára àti lè ní àwọn ọrọ̀ wọ̀nyí, tí ó sì fi mú májẹ̀mú rẹ̀ ṣẹ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá a yín bí ó ti rí lónìí.
\p
\v 19 Bí ẹ bá wá gbàgbé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, tí ẹ sì tẹ̀lé àwọn òrìṣà mìíràn, tí ẹ sì sìn wọ́n, tí ẹ sì foríbalẹ̀ fún wọn, Mo kìlọ̀ fún un yín pé rírun ni ẹ̀yin yóò run.
\v 20 Bí àwọn orílẹ̀-èdè tí \nd Olúwa\nd* parun níwájú u yín, bákan náà ni ẹ ó parun, torí pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín lẹ́nu.
\c 9
\s1 Kì í ṣe nítorí òdodo Israẹli
\p
\v 1 Gbọ́, ìwọ Israẹli. Báyìí, ẹ̀yin ti gbáradì láti la Jordani kọjá, láti lọ gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tóbi, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ, tí wọ́n ní àwọn ìlú ńlá ńlá, tí odi wọn kan ọ̀run.
\v 2 Àwọn ènìyàn náà lágbára wọ́n sì ga àní àwọn ọmọ Anaki ni wọ́n. Ẹ gbọ́ nípa wọn, ẹ sì gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sọ nípa wọn pé, “Ta ni ó le è dojú ìjà kọ àwọn ọmọ Anaki (òmíràn)?”
\v 3 \x - \xo 9.3: \xt Hb 12.29.\x*Ṣùgbọ́n kí ó dá a yín lójú lónìí pé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ni ó ń ṣáájú u yín lọ gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun. Yóò jó wọn run, yóò sì tẹ orí wọn ba níwájú yín. Ẹ̀yin yóò sì lé wọ́n jáde, ẹ̀yin yóò sì run wọ́n kíákíá, bí \nd Olúwa\nd* ti ṣèlérí fún un yín.
\p
\v 4 Lẹ́yìn tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín bá ti lé wọn jáde níwájú u yín, ẹ má ṣe wí fún ara yín pé, “Torí òdodo mi ní \nd Olúwa\nd* ṣe mú mi wá síbí láti gba ilẹ̀ náà.” Rárá, ṣùgbọ́n nítorí ìwà búburú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ni \nd Olúwa\nd* yóò ṣe lé wọn jáde níwájú u yín.
\v 5 Kì í ṣe nítorí òdodo yín, tàbí ìdúró ṣinṣin ni ẹ ó fi wọ ìlú wọn lọ láti gba ilẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n nítorí ìwà búburú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín yóò fi lé wọn jáde kúrò níwájú u yín láti lè mú ohun tí ó búra fún àwọn baba ṣẹ: fún Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu.
\v 6 Ṣùgbọ́n kí ó yé yín pé kì í ṣe nítorí òdodo yín ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín fi ń fún un yín ní ilẹ̀ rere náà, láti ní, nítorí pé ènìyàn ọlọ́rùn líle ni ẹ jẹ́.
\s1 Ère òrìṣà wúrà
\p
\v 7 Ẹ rántí, ẹ má sì ṣe gbàgbé bí ẹ̀yin ti mú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín bínú ní aginjù. Láti ọjọ́ ti ẹ tí kúrò ní Ejibiti ni ẹ̀yin ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí \nd Olúwa\nd* títí tí ẹ̀yin fi dé ìhín yìí.
\v 8 \x - \xo 9.8-21: \xt El 32.7-20.\x*Ní Horebu ẹ̀yin ti mú kí \nd Olúwa\nd* bínú, títí dé bi pé ó fẹ́ run yín.
\v 9 Nígbà tí mo gòkè lọ láti lọ gba wàláà òkúta, wàláà májẹ̀mú ti \nd Olúwa\nd* ti bá a yín dá. Ogójì ọ̀sán àti òru ni mo fi wà lórí òkè náà, èmi kò fẹnu kan oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ni ń kò mu omi.
\v 10 \nd Olúwa\nd* fún mi ní wàláà òkúta méjì tí a fi ìka Ọlọ́run kọ. Lórí wọn ni a kọ àwọn òfin tí Ọlọ́run sọ fún un yín lórí òkè láàrín iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀ sí.
\p
\v 11 Lópin ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí, \nd Olúwa\nd* fún mi ní sílétì òkúta méjì, wàláà òkúta májẹ̀mú náà.
\v 12 Bẹ́ẹ̀ ni \nd Olúwa\nd* sọ fún mi pé, “Sọ̀kalẹ̀ kúrò níhìn-ín kíákíá, torí pé àwọn ènìyàn rẹ tí o mú jáde láti Ejibiti ti hùwà ìbàjẹ́. Wọ́n ti yípadà kúrò, nínú ọ̀nà mi, wọ́n sì ti ṣe ère dídá fún ara wọn.”
\p
\v 13 \nd Olúwa\nd* sì sọ fún mi pé, “Mo ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí pé ènìyàn ọlọ́rùn líle gbá à ni wọ́n.
\v 14 Fi mí sílẹ̀, jẹ́ kí n run wọ́n, kí n sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run. Èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè tí ó lágbára tí ó sì pọ̀jù wọ́n lọ.”
\p
\v 15 Báyìí ni mo yípadà, tí mó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà wá, orí òkè tí o ń yọ iná. Àwọn wàláà májẹ̀mú méjèèjì sì wà lọ́wọ́ mi.
\v 16 Ìgbà tí mo ṣàkíyèsí, mo rí i pé ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín. Ẹ ti ṣe ère òrìṣà ní ìrí ọ̀dọ́ màlúù, fún ara yín. Ẹ ti yípadà kánkán kúrò nínú ọ̀nà tí \nd Olúwa\nd* ti pàṣẹ fún un yín.
\v 17 Bẹ́ẹ̀ ni mó ju wàláà méjèèjì náà mọ́lẹ̀, mo sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ lójú u yín.
\p
\v 18 Lẹ́yìn náà mo tún wólẹ̀ níwájú \nd Olúwa\nd* fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, èmi kò jẹ oúnjẹ kankan bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mu omi, nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ tí dá, tí ẹ sì ń ṣe búburú lójú \nd Olúwa\nd*, tí ẹ sì ń mú u bínú.
\v 19 Mo bẹ̀rù ìbínú àti ìrunú \nd Olúwa\nd*, nítorí pé inú bí i sí i yín dé bi wí pé ó fẹ́ pa yín run. Ṣùgbọ́n \nd Olúwa\nd* tún fetí sí mi lẹ́ẹ̀kan sí i.
\v 20 Inú sì bí \nd Olúwa\nd* sí Aaroni láti pa á run, nígbà náà ni mo tún gbàdúrà fún Aaroni náà.
\v 21 Bẹ́ẹ̀ ni mo sì mú ohun tí ó mú un yín dẹ́ṣẹ̀, àní ère ẹgbọrọ màlúù tí ẹ ti ṣe, mo sì fi iná sun ún, bẹ́ẹ̀ ni mo gún un, mo sì lọ̀ ọ́ lúúlúú bí eruku lẹ́búlẹ́bú, mo sì da ẹ̀lọ̀ rẹ̀ sínú odò tí ń sàn nísàlẹ̀ òkè.
\p
\v 22 Ẹ̀yin tún mú \nd Olúwa\nd* bínú ní Tabera, Massa àti ní Kibirotu-Hattaafa.
\p
\v 23 Nígbà tí \nd Olúwa\nd* ran an yín jáde ní Kadeṣi-Barnea, Ó wí pé, “Ẹ gòkè lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín.” Ṣùgbọ́n ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí òfin \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín. Ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé e, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́ tirẹ̀.
\v 24 Láti ìgbà tí mo ti mọ̀ yín ni ẹ ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí \nd Olúwa\nd*.
\p
\v 25 Mo ti wólẹ̀ níwájú \nd Olúwa\nd* fún ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí nítorí pé \nd Olúwa\nd* sọ pé Òun yóò pa yín run.
\v 26 Mo gbàdúrà sí \nd Olúwa\nd* wí pé, “\nd Olúwa\nd* Olódùmarè, má ṣe run àwọn ènìyàn rẹ, àní ogún rẹ tí o ti rà padà, nípa agbára rẹ tí o sì fi agbára ńlá mú wọn jáde láti Ejibiti wá.
\v 27 Rántí àwọn ìránṣẹ́ rẹ Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu. Fojú fo orí kunkun àwọn ènìyàn yìí, pẹ̀lú ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
\v 28 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti mú wa jáde wá yóò wí pé, Torí pé \nd Olúwa\nd* kò lè mú wọn lọ sí ilẹ̀ náà tí ó ti ṣèlérí fún wọn, àti pé ó ti kórìíra wọn, ni ó fi mú wọn jáde láti pa wọ́n ní aginjù.
\v 29 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn rẹ ni wọ́n, ogún rẹ tí o ti fi ọwọ́ agbára rẹ àti nínà ọwọ́ rẹ mú jáde.”
\c 10
\s1 Wàláà òfin bí i ti ìṣáájú
\p
\v 1 Nígbà náà ni \nd Olúwa\nd* wí fún mi pé, “Gbé wàláà òkúta méjì bí i ti àkọ́kọ́ kí o sì gòkè tọ̀ mí wá. Kí o sì tún fi igi kan àpótí kan.
\v 2 Èmi yóò sì kọ ọ̀rọ̀ tí ó wà lára wàláà àkọ́kọ́ tí ìwọ fọ́, sára wàláà wọ̀nyí. Ìwọ yóò sì fi wọ́n sínú àpótí náà.”
\p
\v 3 Mo sì kan àpótí náà pẹ̀lú igi kasia, mo sì gbẹ́ wàláà òkúta méjì náà jáde bí i ti ìṣáájú. Mo sì gòkè lọ pẹ̀lú wàláà méjèèjì lọ́wọ́ mí.
\v 4 \nd Olúwa\nd* tún ohun tí ó ti kọ tẹ́lẹ̀ kọ sórí wàláà wọ̀nyí. Àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó ti sọ fún un yín lórí òkè, láàrín iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀. \nd Olúwa\nd* sì fi wọ́n fún mi.
\v 5 Mo sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà, mo sì ki àwọn wàláà òkúta náà sínú àpótí tí mo ti kàn, bí \nd Olúwa\nd* ti pàṣẹ fún mi, wọ́n sì wà níbẹ̀ di ìsinsin yìí.
\p
\v 6 (Àwọn ará Israẹli sì gbéra láti kànga àwọn ará Jaakani dé Mosera. Níbí ni Aaroni kú sí, tí a sì sin ín, Eleasari ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ bí i àlùfáà.
\v 7 Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti rìn lọ sí Gudgoda, títí dé Jotbata, ilẹ̀ tí o kún fún odò tí ó ń sàn.
\v 8 Ní ìgbà yìí ni \nd Olúwa\nd* yan àwọn ẹ̀yà Lefi láti máa ru àpótí ẹ̀rí \nd Olúwa\nd*, láti máa dúró níwájú \nd Olúwa\nd* láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti láti fi orúkọ \nd Olúwa\nd* súre bí wọ́n ti ń ṣe títí di òní yìí.
\v 9 Ìdí nìyí tí àwọn ẹ̀yà Lefi kò fi ní ìpín tàbí ogún kan láàrín àwọn arákùnrin wọn. \nd Olúwa\nd* ni ogún wọn gẹ́gẹ́ bí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run ti sọ fún un yín.)
\p
\v 10 Mo tún dúró ní orí òkè náà fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, bí mo ti ṣe ní ìgbà àkọ́kọ́, \nd Olúwa\nd* sì gbọ́ tèmi ní àkókò yìí bákan náà. Kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ láti run yín.
\v 11 \nd Olúwa\nd* sọ fún mi pé, “Lọ darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọ̀nà wọn, kí wọn bá à lè wọ ilẹ̀ náà, kí wọn sì gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn láti fún wọn.”
\s1 Ẹ bẹ̀rù \nd Olúwa\nd*
\p
\v 12 Nísinsin yìí ìwọ Israẹli, kín ni ohun tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe kí ìwọ bẹ̀rù \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ àti láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti fẹ́ràn rẹ̀, láti fi gbogbo ọkàn rẹ sin \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ ọkàn àti àyà rẹ,
\v 13 àti láti máa kíyèsi àṣẹ àti ìlànà \nd Olúwa\nd* tí mo ń fún ọ lónìí, fún ìre ara à rẹ.
\p
\v 14 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ni ó ni ọ̀run àní àwọn ọ̀run tó ga ju ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.
\v 15 Síbẹ̀ \nd Olúwa\nd* sì tún fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún àwọn baba ńlá a yín, Ó sì fẹ́ wọn Ó sì yan ẹ̀yin ọmọ wọn láti borí gbogbo orílẹ̀-èdè títí di òní.
\v 16 Ẹ kọ ọkàn yín ní ilà, kí ẹ má sì ṣe jẹ́ olórí kunkun mọ́ láti òní lọ.
\v 17 \x - \xo 10.17: \xt Ap 10.34; Ga 2.6; If 17.14; 19.16.\x*Torí pé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn olúwa. Ọlọ́run alágbára, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, tí kì í ṣe ojúsàájú kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
\v 18 Ó máa ń gbẹjọ́ aláìní baba àti opó rò, Ó fẹ́ràn àjèjì, Òun fi aṣọ àti oúnjẹ fún wọn.
\v 19 \x - \xo 10.19: \xt El 22.21; 23.9; Le 19.34.\x*Ẹ gbọdọ̀ fẹ́ràn àwọn àjèjì, torí pé ẹ̀yin pẹ̀lú ti jẹ́ àjèjì rí ní Ejibiti.
\v 20 Ẹ bẹ̀rù \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, ẹ sì máa sìn ín. Ẹ dìímú ṣinṣin, kí ẹ sì búra ní orúkọ rẹ̀.
\v 21 Òun ni ìyìn in yín, Òun sì ni Ọlọ́run yín, tí ó ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá àti ohun ẹ̀rù, tí ẹ fojú ara yín rí.
\v 22 \x - \xo 10.22: \xt Ap 7.14.\x*Àádọ́rin péré ni àwọn baba ńlá a yín tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti, ṣùgbọ́n \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ti mú un yín pọ̀ sí i ní iye bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run.
\c 11
\s1 Fẹ́ràn \nd Olúwa\nd* kí o sì gbọ́ tirẹ̀
\p
\v 1 Ẹ fẹ́ràn \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, kí ẹ sì pa ìfẹ́ rẹ̀, ìlànà rẹ̀, òfin rẹ̀ àti àṣẹ rẹ̀ mọ́ ní ìgbà gbogbo.
\v 2 Ẹ rántí lónìí pé, kì í ṣe àwọn ọmọ yín, ni ó rí ìbáwí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín; títóbi rẹ̀, ọwọ́ agbára rẹ̀, nína ọwọ́ rẹ̀;
\v 3 iṣẹ́ àmì rẹ̀ àti ohun tí ó ṣe ní àárín àwọn ará Ejibiti, sí Farao ọba Ejibiti àti gbogbo orílẹ̀-èdè rẹ̀.
\v 4 Ohun tí ó ṣe sí àwọn jagunjagun Ejibiti, sí kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹlẹ́ṣin rẹ̀: bí ó ṣe rì wọ́n sínú Òkun Pupa, bí wọ́n ṣe ń lé e yín tí \nd Olúwa\nd* fi pa wọ́n run pátápátá títí di òní olónìí yìí.
\v 5 Kì í ṣe àwọn ọmọ yín ni ó rí ohun tí ó ṣe fún un yín ní aginjù, títí ẹ fi dé ìhín yìí,
\v 6 \x - \xo 11.6: \xt Nu 16.31,32.\x*ohun tí ó ṣe sí Datani àti Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, ẹ̀yà Reubeni, bí ilẹ̀ ti lanu ní ojú gbogbo ará Israẹli tí ó sì gbé wọn mì pẹ̀lú gbogbo ìdílé wọn, gbogbo àgọ́ ọ wọn àti gbogbo ohun alààyè tí ó jẹ́ tiwọn.
\v 7 Ṣùgbọ́n ojú u yín gan an ni ó rí gbogbo nǹkan ńlá wọ̀nyí tí \nd Olúwa\nd* ti ṣe.
\p
\v 8 Nítorí náà, ẹ kíyèsi gbogbo àṣẹ tí mo ń fún yín lónìí, kí ẹ ba à lè lágbára àti lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí ẹ ó la Jordani kọjá lọ.
\v 9 Kí ẹ ba à lè pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* ti búra fún àwọn baba ńlá a yín, láti fún àwọn àti àwọn ọmọ wọn: ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin.
\v 10 Ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà kò rí bí ilẹ̀ Ejibiti, níbi tí ẹ ti wá, níbi tó jẹ́ wí pé ẹsẹ̀ yín ni ẹ fi ń rìn lọ bomirin irúgbìn tí ẹ gbìn bí oko ẹ̀fọ́.
\v 11 Ṣùgbọ́n ilẹ̀ tí ẹ ó la Jordani kọjá láti gbà, jẹ́ ilẹ̀ olókè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí òjò ń rọ̀ sí latọ̀run.
\v 12 Ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ń mójútó ni, ojú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín sì ń fi ìgbà gbogbo wà lórí rẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún dé òpin ọdún.
\p
\v 13 \x - \xo 11.13-17: \xt Le 26.3-5; De 7.12-16; 28.1-14.\x*Nítorí náà, bí ẹ bá gbọ́rọ̀ sí àṣẹ tí mo fún un yín lónìí tọkàntọkàn: tí ẹ fẹ́ràn \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, tí ẹ sì sìn ín, pẹ̀lú gbogbo àyà yín àti gbogbo ọkàn yín:
\v 14 nígbà náà, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ ẹ yín lákòókò rẹ̀, àti òjò àkọ́rọ̀ àti ti àrọ̀kẹ́yìn, kí ẹ ba à lè kórè oúnjẹ yín wọlé àní wáìnì tuntun àti òróró.
\v 15 Èmi yóò mú kí koríko hù lórí ilẹ̀ yín fún àwọn ohun ọ̀sìn in yín, ẹ ó sì jẹ, ẹ ó sì yó.
\p
\v 16 Ẹ ṣọ́ra, kí a má ba à tàn yín jẹ láti yípadà kí ẹ sì sin ọlọ́run mìíràn àti láti máa foríbalẹ̀ fún wọn.
\v 17 Nígbà náà ni ìbínú \nd Olúwa\nd* yóò sì ru sí i yín, Òun yóò ti ìlẹ̀kùn ọ̀run kí òjò má ba à rọ̀, ilẹ̀ kì yóò sì so èso kankan, ẹ ó sì ṣègbé ní ilẹ̀ rere tí \nd Olúwa\nd* fi fún un yín.
\v 18 Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí sí àyà a yín, àti ọkàn an yín, ẹ so wọ́n bí àmì sórí ọwọ́ yín, kí ẹ sì so wọ́n mọ́ iwájú orí yín.
\v 19 Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín, ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa wọn bí ẹ bá jókòó nínú ilé, àti ní ojú ọ̀nà bí ẹ bá ń rìn lọ, bí ẹ bá sùn àti bí ẹ bá jí.
\v 20 Kí ìwọ kí ó kọ wọ́n sára òpó ilé rẹ̀, àti sí ara ìlẹ̀kùn ọ̀nà òde rẹ.
\v 21 Kí ọjọ́ ọ yín àti ti àwọn ọmọ yín lè pọ̀ ní ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* ti búra láti fi fún àwọn baba ńlá a yín, ní ìwọ̀n ìgbà tí ọ̀run wà lókè tí ayé sì ń bẹ ní ìsàlẹ̀.
\p
\v 22 Bí ẹ bá fi ara balẹ̀ kíyèsi àwọn òfin tí mo ń fún un yín, láti tẹ̀lé, láti fẹ́ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti láti dìímú ṣinṣin:
\v 23 \nd Olúwa\nd* yóò sì lé gbogbo orílẹ̀-èdè wọ̀nyí kúrò níwájú u yín. Ẹ ó sì gba orílẹ̀-èdè tí ó lágbára tí ó sì tóbi jù yín lọ.
\v 24 Gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹsẹ̀ ẹ yín tẹ̀ ni yóò jẹ́ tiyín, ilẹ̀ ẹ yín yóò gbilẹ̀ láti aginjù dé Lebanoni, àti láti odò Eufurate dé Òkun Ńlá.
\v 25 Kò sí ẹni náà tí yóò lè kò yín lójú ìjà, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín yóò fi ẹ̀rù àti ìwárìrì i yín sórí gbogbo ilẹ̀ náà bí ó ti ṣèlérí fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá lọ.
\p
\v 26 Ẹ kíyèsi i, mo fi ìbùkún àti ègún lélẹ̀ níwájú u yín lónìí:
\v 27 ìbùkún ni, bí ẹ bá pa òfin \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, tí mo ń fún un yín lónìí mọ́.
\v 28 Ègún ni, bí ẹ bá ṣàìgbọ́ràn, sí òfin \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, tí ẹ sì yapa kúrò ní ọ̀nà tí mo ti là sílẹ̀ fún yín lónìí, nípa títẹ̀lé ọlọ́run mìíràn, tí ẹ kò tí ì mọ̀.
\v 29 Nígbà tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín bá ti mú un yín dé ilẹ̀ náà tí ẹ ń wọ̀ láti gbà, kí ẹ kéde àwọn ìbùkún náà ní orí òkè Gerisimu, kí ẹ sì kéde àwọn ègún ní orí òkè Ebali.
\v 30 Bí ẹ ti mọ̀ pé àwọn òkè wọ̀nyí wà ní ìkọjá a Jordani ní apá ìwọ̀-oòrùn lójú ọ̀nà lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, ní ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó More, ní ilẹ̀ àwọn ará a Kenaani, tí wọ́n ń gbé ní aginjù, ni agbègbè Gilgali.
\v 31 Ẹ ti ṣetán láti la Jordani kọjá láti lè gba ilẹ̀ náà tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ń fún un yín. Nígbà tí ẹ bá gbà á, tí ẹ bá sì ń gbé ibẹ̀,
\v 32 ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń gbọ́rọ̀ sí gbogbo ìlànà àti òfin tí mo ń gbé kalẹ̀ fún un yín lónìí.
\c 12
\s1 Ibi ìsìn kan ṣoṣo
\p
\v 1 \x - \xo 12.1-28: \xt El 20.24.\x*Wọ̀nyí ni àwọn ìlànà àti òfin tí ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra láti máa tẹ̀lé, ní ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run àwọn baba yín, fi fún un yín láti gbà: ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá fi wà lórí ilẹ̀ náà.
\v 2 Gbogbo ibi gíga àwọn òkè ńlá, àti òkè kéékèèké àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀ níbi tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ ó lé jáde, tí ń sin òrìṣà wọn ní kí ẹ mú kúrò pátápátá.
\v 3 Ẹ wó àwọn pẹpẹ wọn, ẹ bi òpó ìsìn wọn ṣubú, kí ẹ sì sun òpó Aṣerah wọn ní iná. Ẹ gé gbogbo ère òrìṣà wọn lulẹ̀, kí ẹ sì pa orúkọ wọn rẹ́ ní gbogbo ààyè wọn.
\p
\v 4 Ẹ kò gbọdọ̀ sin \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín bí i tiwọn.
\v 5 Ṣùgbọ́n ẹ wá ibi tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín yóò yàn láàrín àwọn ẹ̀yà yín, láti fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀ bí i ibùgbé rẹ̀. Ibẹ̀ ni kí ẹ lọ.
\v 6 Níbẹ̀ ni kí ẹ mú ẹbọ sísun àti ẹbọ yín wá, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àwọn ẹ̀jẹ́ yín, ọrẹ àtinúwá yín, àti àwọn àkọ́bí gbogbo màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín.
\v 7 Níwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín níbẹ̀, kí ẹ̀yin àti ìdílé yín jẹun kí ẹ sì yó, nínú gbogbo ìdáwọ́lé e yín, torí pé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ti bùkún un yín.
\p
\v 8 Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣe gẹ́gẹ́ bí a tí ṣe níhìn-ín lónìí yìí, tí olúkúlùkù ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú ara rẹ̀.
\v 9 Níwọ́n ìgbà tí ẹ ti dé ibi ìsinmi, àti ibi ogún tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín fún un yín.
\v 10 Ṣùgbọ́n ẹ ó la Jordani kọjá, ẹ ó sì máa gbé ní ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín fún un yín bí ìní, yóò sì fún un yín ní ìsinmi, kúrò láàrín àwọn ọ̀tá a yín, tí ó yí i yín ká, kí ẹ ba à lè máa gbé láìléwu.
\v 11 Níbi tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín yóò yàn bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ mú gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún un yín wá: àwọn ọrẹ ẹ yín àti àwọn ẹbọ sísun, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àti gbogbo ohun ìní yín tí ẹ ti yàn, èyí tí ẹ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún \nd Olúwa\nd*.
\v 12 Kí ẹ máa yọ̀ níwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín níbẹ̀, ẹ̀yin, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, ìránṣẹ́bìnrin àti ìránṣẹ́kùnrin yín, àti àwọn Lefi láti ìlú u yín, tí wọn kò ní ìpín tàbí ogún tiwọn.
\v 13 Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe rú ẹbọ sísun yín ní ibikíbi tí ẹ̀yin fẹ́.
\v 14 Ibi tí \nd Olúwa\nd* yóò yàn láàrín àwọn ẹ̀yà a yín nìkan ni kí ẹ ti máa rú ẹbọ sísun yín, kí ẹ sì máa kíyèsi ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún un yín níbẹ̀.
\p
\v 15 Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ lọ pa àwọn ẹran yín ní èyíkéyìí nínú àwọn ìlú u yín, kí ẹ sì jẹ ẹran náà tó bí ẹ ti fẹ́, bí ẹ ti ń ṣe sí àgbọ̀nrín àti èsúró, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín tí ó fi fún un yín, àti ẹni mímọ́ àti aláìmọ́ ni ó lè jẹ nínú àwọn ẹran náà.
\v 16 \x - \xo 12.16,23: \xt Le 17.10-14; 19.26.\x*Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ wọn, ẹ dà á sílẹ̀ bí omi.
\v 17 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ìdámẹ́wàá oúnjẹ yín, wáìnì tuntun, òróró, àkọ́bí àwọn màlúù yín, tàbí ti ewúrẹ́ ẹ yín, ohunkóhun tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́, ọrẹ àtinúwá, tàbí ẹ̀bùn pàtàkì ní ìlú ẹ̀yin tìkára yín.
\v 18 Bí kò ṣe kí ẹ jẹ ẹ́ níwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, níbi tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, yóò yàn: ìwọ, àwọn ọmọkùnrin rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti àwọn ọmọ Lefi láti ìlú u yín, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, nínú gbogbo ìdáwọ́lé e yín.
\v 19 Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe gbàgbé àwọn Lefi, ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá ń gbé ní ilẹ̀ ẹ yín.
\p
\v 20 Bí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín bá ti fẹ́ agbègbè e yín bí ó ti ṣe ìlérí, fún un yín, tí ẹ sì wí pé, àwa yóò jẹ ẹran, nítorí tí ọkàn wa fẹ́ jẹran. Ẹ jẹ ẹran náà bí ẹ tí fẹ́.
\v 21 Bí ibi tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín bá yàn fún orúkọ rẹ̀ bá jìnnà sí i yín, kí ẹ pa màlúù tàbí ewúrẹ́ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín tí fún un yín, bí mo ti pàṣẹ fún un yín ní ìlú u yín, ẹ lè jẹ ẹ́ bí ẹ ti fẹ́.
\v 22 Ẹ jẹ wọ́n bí ẹ ó ti jẹ èsúró tàbí àgbọ̀nrín, ẹni tí a kà sí mímọ́ àti aláìmọ́ ni ó lè jẹ ẹ́.
\v 23 Ṣùgbọ́n ẹ rí i dájú pé ẹ kò jẹ ẹ̀jẹ̀ wọn, nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí, ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹ̀mí pọ̀ mọ́ ẹran.
\v 24 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, ẹ dà á sílẹ̀ bí omi.
\v 25 Ẹ má ṣe jẹ ẹ́, kí ó bá à lè dára fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín, tí ń bọ̀ lẹ́yìn in yín. Nígbà yí ní ẹ tó ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà lójú \nd Olúwa\nd*.
\p
\v 26 Ẹ mú àwọn ohun tí ẹ yà sọ́tọ̀ àti àwọn ẹ̀jẹ́ yín, kí ẹ sì lọ sí ibi tí \nd Olúwa\nd* yóò yàn.
\v 27 Ẹ fi ẹbọ sísun yín kalẹ̀ lórí i pẹpẹ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, àti ẹran àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ ọrẹ yín ni ki ẹ dà sí pẹpẹ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, ṣùgbọ́n ẹ lè jẹ ẹran.
\v 28 Ẹ kíyèsára láti máa gbọ́rọ̀ sí gbogbo ìlànà tí mò ń fún un yín, kí o bá à dára fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín nígbà gbogbo, nítorí pé nígbà náà ní ẹ tó ń ṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ̀nà níwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín.
\p
\v 29 \x - \xo 12.29-32: \xt El 23.24; 34.12-14; Nu 33.52.\x*\nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín yóò gé àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ fẹ́ lé kúrò tí ẹ sì fẹ́ gba ilẹ̀ wọn kúrò níwájú u yín. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ bá ti lé wọn jáde tí ẹ sì ń gbé ilẹ̀ wọn.
\v 30 Lẹ́yìn ìgbà tí a bá ti pa wọ́n run níwájú u yín, ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ba à bọ́ sínú àdánwò nípa bíbéèrè nípa àwọn òrìṣà wọn wí pé, “Báwo ni àwọn orílẹ̀-èdè yìí ṣe ń sin àwọn òrìṣà wọn? Àwa náà yóò ṣe bẹ́ẹ̀”.
\v 31 Ẹ kò gbọdọ̀ sin \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín bí àwọn, torí pé, nípa sínsin ọlọ́run wọn, wọ́n ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìríra tí Ọlọ́run kórìíra. Wọ́n ń dáná sun àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn láti fi rú ẹbọ sí ère òrìṣà wọn.
\p
\v 32 \x - \xo 12.32: \xt De 4.2; If 22.18,19.\x*Ẹ rí i pé ẹ̀ ń ṣe gbogbo ohun tí mo ti pàṣẹ fún un yín. Ẹ má ṣe fi kún un, ẹ má sì ṣe yọ kúrò níbẹ̀.
\c 13
\s1 Sí sin àwọn ọlọ́run mìíràn
\p
\v 1 Bí wòlíì tàbí alásọtẹ́lẹ̀ nípa àlá lílá bá farahàn láàrín yín, tí ó sì ń kéde iṣẹ́ àmì tàbí iṣẹ́ ìyanu,
\v 2 bí iṣẹ́ àmì tàbí iṣẹ́ ìyanu tí ó sọ̀rọ̀ rẹ̀ bá ṣẹ tí òun sì wí pé, “ẹ wá ẹ jẹ́ kí a tẹ̀lé ọlọ́run mìíràn” (àwọn ọlọ́run tí ẹ kò mọ̀ rí) “kí ẹ sì jẹ́ kí a máa sìn wọ́n,”
\v 3 ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ wòlíì tàbí àlá náà, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ń dán an yín wò ni, láti mọ̀ bóyá ẹ fẹ́ràn rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àyà yín àti gbogbo ọkàn an yín.
\v 4 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ni kí ẹ tẹ̀lé, Òun ni kí ẹ bu ọlá fún, ẹ pa òfin rẹ̀ mọ́ kí ẹ sì gbọ́ tirẹ̀, ẹ sìn ín, kí ẹ sì dìímú ṣinṣin.
\v 5 Wòlíì náà tàbí alálàá náà ni kí ẹ pa, nítorí pé wàásù ìṣọ̀tẹ̀ sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, tí ó mú yín jáde láti Ejibiti wá, tí ó sì rà yín padà lóko ẹrú. Ó ti gbìyànjú láti fà yín kúrò lójú ọ̀nà tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín láti máa rìn. Ẹ gbọdọ̀ yọ ibi náà kúrò láàrín yín.
\p
\v 6 Bí arákùnrin tìrẹ gan an ọmọ ìyá rẹ tàbí ọmọ rẹ ọkùnrin tàbí obìnrin, aya tí o fẹ́ràn jù, tàbí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ bá tàn ọ́ jẹ níkọ̀kọ̀ wí pé, “Jẹ́ kí a lọ sin ọlọ́run mìíràn” (ọlọ́run tí ìwọ tàbí baba rẹ kò mọ̀,
\v 7 ọlọ́run àwọn tí ó wà láyìíká yín, yálà wọ́n jìnnà tàbí wọ́n wà nítòsí, láti òpin ilẹ̀ kan dé òmíràn),
\v 8 má ṣe fetí sí i, má sì dá sí i, má ṣe dáàbò bò ó.
\v 9 Ṣùgbọ́n pípa ni kí o pa á. Ọwọ́ rẹ ni yóò kọ́kọ́ wà lára rẹ̀ láti pa á, lẹ́yìn náà ọwọ́ gbogbo ènìyàn.
\v 10 Sọ ọ́ ní òkúta pa nítorí pé ó gbìyànjú láti fà ọ́ kúrò lẹ́yìn \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ, tí ó mú ọ jáde ti Ejibiti wá kúrò ní oko ẹrú.
\v 11 Gbogbo Israẹli yóò sì gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n, kò sì sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí yóò dán irú ibi bẹ́ẹ̀ wò mọ́.
\p
\v 12 Bí ẹ̀yin bá gbọ́ tí a sọ nípa èyíkéyìí nínú àwọn ìlú u yín tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín fún un yín láti máa gbé,
\v 13 pé àwọn ènìyàn búburú, ti farahàn láàrín yín, tí ó sì ti mú kí àwọn ènìyàn ìlú wọn ṣìnà lọ, tí wọ́n wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sin ọlọ́run mìíràn.” (àwọn ọlọ́run tí ẹ kò mọ̀.)
\v 14 Kí ẹ wádìí, ẹ béèrè, kí ẹ sì tọpinpin ọ̀rọ̀ náà dájúṣáká, bí ó bá jẹ́ òtítọ́ ni, tí ó sì hàn dájú pé ìwà ìríra yìí ti ṣẹlẹ̀ láàrín yín.
\v 15 Gbogbo àwọn tí ó ń gbé ìlú náà ni kí ẹ fi idà run pátápátá. Ẹ run ún pátápátá, àti ènìyàn àti ẹran ọ̀sìn inú rẹ̀.
\v 16 Ẹ kó gbogbo ìkógun ìlú náà, sí àárín gbogbo ènìyàn, kí ẹ sun ìlú náà àti gbogbo ìkógun rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ. Ó gbọdọ̀ wà ní píparun láéláé, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ tún un kọ.
\v 17 A kò gbọdọ̀ rí ọ̀kan nínú àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ fún ìparun wọ̀n-ọn-nì lọ́wọ́ yín, kí \nd Olúwa\nd* ba à le yípadà kúrò nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀, yóò sì ṣàánú fún un yín, yóò sì bá a yín kẹ́dùn, yóò sì mú kí ẹ pọ̀ sí i, bí ó ti fì búra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá yín.
\v 18 Nítorí pé ẹ̀yin gbọ́rọ̀ sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, tí ẹ̀yin sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́, tí mo ń fún un yín lónìí yìí, tí ẹ̀yin sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ lójú rẹ̀.
\c 14
\s1 Oúnjẹ tí ó mọ́ àti èyí tí kò mọ́
\p
\v 1 \x - \xo 14.1: \xt Le 19.28.\x*Ọmọ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ni ẹ̀yin jẹ́: nítorí náà, ẹ má ṣe ya ara yín ní abẹ. Ẹ má ṣe gé irun iwájú orí yín nítorí òkú.
\v 2 \x - \xo 14.2: \xt Ek 19.5,6; De 26.19; Tt 2.14; 1Pt 2.9; If 1.6; 5.10.\x*Nítorí pé ènìyàn mímọ́ ní ẹ jẹ́ fún \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, Ọlọ́run ti yàn yín láti jẹ́ ìṣúra iyebíye rẹ̀.
\p
\v 3 \x - \xo 14.3-20: \xt Le 11.2-23.\x*Ẹ má ṣe jẹ ohun ìríra kankan.
\v 4 Àwọn wọ̀nyí ni ẹranko tí ẹ lè máa jẹ: màlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́,
\v 5 àgbọ̀nrín, èsúró, etu, àgóró, ẹfọ̀n, ìgalà àti àgùntàn igbó.
\v 6 Ẹ lè jẹ gbogbo ẹranko tí pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ kì í ṣe méjì tí ó sì tún jẹ àpọ̀jẹ.
\v 7 Síbẹ̀síbẹ̀ nínú gbogbo ẹran tí ń jẹ àpọ̀jẹ tí ó sì tún ya pátákò ẹsẹ̀ tí ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ni: ìbákasẹ, ehoro, àti ẹranko tí ó dàbí ehoro tí ń gbé inú àpáta. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jẹ àpọ̀jẹ, ṣùgbọ́n wọn kò la pátákò ẹsẹ̀, a kà wọ́n sí àìmọ́ fún yín.
\v 8 Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́ àìmọ́; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ya pátákò ẹsẹ̀, kì í jẹ àpọ̀jẹ, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran rẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú rẹ̀.
\p
\v 9 Nínú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ẹ lè jẹ èyíkéyìí tí ó ní lẹbẹ àti ìpẹ́.
\v 10 Ṣùgbọ́n èyíkéyìí tí kò bá ní lẹbẹ àti ìpẹ́, ẹ má ṣe jẹ ẹ́, nítorí pé àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín.
\p
\v 11 Ẹ lè jẹ ẹyẹ tí ó bá mọ́.
\v 12 Ṣùgbọ́n ìwọ̀nyí ní ẹ kò gbọdọ̀ jẹ: idì, igún, àkàlà,
\v 13 onírúurú àṣá àti àṣá alátagbà,
\v 14 onírúurú ẹyẹ ìwò,
\v 15 ògòǹgò, òwìwí, pẹ́pẹ́yẹdò àti onírúurú àwòdì,
\v 16 onírúurú òwìwí,
\v 17 òwìwí ọ̀dàn, àkàlà, ìgò,
\v 18 àkọ̀, òòdẹ̀, onírúurú ẹyẹ odò mìíràn, atọ́ka àti àdán.
\p
\v 19 Àti gbogbo kòkòrò tí ń fò tí wọ́n ń kọ́wọ̀ọ́ rìn jẹ́ aláìmọ́ fun un yín, ẹ má ṣe jẹ wọ́n.
\v 20 Ṣùgbọ́n ẹ lè jẹ èyíkéyìí ẹ̀dá abìyẹ́ tí ó bá mọ́.
\p
\v 21 \x - \xo 14.21: \xt Le 11.39,40; 17.15; El 23.19; 34.26.\x*Ẹ má ṣe jẹ ohun tí ó ti kú sílẹ̀. Ẹ lè fún àwọn àjèjì tí ń gbé ní èyíkéyìí nínú ìlú yín. Òun lè jẹ ẹ́ tàbí kí ẹ tà á fún àwọn àjèjì. Ṣùgbọ́n ènìyàn mímọ́ fún \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ni ẹ̀yin jẹ́.
\p Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀.
\s1 Ìdámẹ́wàá
\p
\v 22 \x - \xo 14.22-29: \xt Le 27.30-33; Nu 18.21-32.\x*Ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń fi ìdákan nínú mẹ́wàá nínú ìre oko yín lọ́dọọdún pamọ́ sí apá kan.
\v 23 Ẹ jẹ ìdámẹ́wàá oúnjẹ yín, wáìnì tuntun, òróró, àti àkọ́bí àwọn màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín, níwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, ní ibi tí yóò yàn bí ibùgbé orúkọ rẹ̀. Kí ẹ lè kọ́ bí a ṣé ń bu ọlá fún \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín nígbà gbogbo.
\v 24 Bí ibẹ̀ bá jì tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ sì ti bùkún fún ọ, tí o kò sì le ru àwọn ìdámẹ́wàá rẹ (nítorí pé ibi tí \nd Olúwa\nd* yóò yàn láti fi orúkọ rẹ̀ sí jìnnà jù).
\v 25 Ẹ pààrọ̀ àwọn ìdámẹ́wàá yín sí owó, ẹ mú owó náà lọ sí ibi tí \nd Olúwa\nd* yóò yàn.
\v 26 Fi owó náà ra ohunkóhun tí o bá fẹ́, màlúù, àgùntàn, wáìnì, tàbí ọtí líle, tàbí ohunkóhun tí o bá fẹ́. Kí ìwọ àti ìdílé rẹ sì jẹ ẹ́ níwájú \nd Olúwa\nd* níbẹ̀ kí ẹ sì máa yọ̀.
\v 27 Ẹ má ṣe gbàgbé àwọn Lefi tí ó ń gbé nì ìlú yín, nítorí pé wọn kò ní ìpín kan tàbí ogún kan tí í ṣe tiwọn.
\p
\v 28 Ní òpin ọdún mẹ́ta mẹ́ta, ẹ̀yin yóò mú gbogbo ìdámẹ́wàá ìre oko àwọn ọdún náà, kí ẹ kó wọn jọ ní ìlú yín.
\v 29 Kí àwọn Lefi (tí kò ní ìpín tàbí ogún tiwọn) àti àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé ìlú yín lè wá, kí wọn sì jẹ kí wọn sì yó, kí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ le è bùkún fún ọ, nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
\c 15
\s1 Ọdún ìyọ̀ǹda àti ìdáríjì
\p
\v 1 Ní òpin ọdún méje méje, ẹ̀yin gbọdọ̀ máa yọ̀ǹda àwọn gbèsè.
\v 2 Báyìí ni kí ẹ máa ṣe é. Gbogbo ẹni tí wọ́n jẹ ní gbèsè gbọdọ̀ fojú fo gbèsè tí ó ti yá ará Israẹli ènìyàn rẹ̀. Kò gbọdọ̀ béèrè ohun náà, lọ́dọ̀ ará Israẹli ènìyàn rẹ̀ tàbí lọ́dọ̀ arákùnrin rẹ̀: nítorí pé a ti kéde àkókò \nd Olúwa\nd* láti fojú fo gbèsè.
\v 3 Ẹ lè béèrè ìsanpadà lọ́dọ̀ àjèjì. Ṣùgbọ́n ẹ fa igi lé gbèsè yówù kó jẹ́ tí arákùnrin yín jẹ yín.
\v 4 Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò tọ́ sí nínú yín, nítorí pé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín lọ́pọ̀lọ́pọ̀ nínú ilẹ̀ náà tí ó ń mú un yín lọ láti gbà bí ìní yín.
\v 5 Kìkì bí ẹ bá gbọ́rọ̀ sí àṣẹ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín tí ẹ sì kíyèsára láti máa rìn nínú gbogbo àṣẹ wọ̀nyí, tí èmi ń pa fún un yín lónìí.
\v 6 Nítorí pé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín bí ó ti ṣèlérí, ẹ̀yin yóò sì máa yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ẹ kì yóò sì tọrọ. Ẹ ó ṣàkóso ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n kò sí orílẹ̀-èdè tí yóò lè jẹ ọba lé e yín lórí.
\p
\v 7 \x - \xo 15.7,8: \xt Le 25.35.\x*Bí tálákà kan bá wà láàrín àwọn arákùnrin yín ní èyíkéyìí àwọn ìlú, ilẹ̀ náà tí \nd Olúwa\nd* yín yóò fún un yín. Ẹ má ṣe ṣe àìláàánú, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe háwọ́ sí arákùnrin yín tí ó jẹ́ tálákà.
\v 8 Ṣùgbọ́n ẹ lawọ́ kí ẹ sì fi tọkàntọkàn yá wọn ní ohun tí wọ́n nílò.
\v 9 Ẹ ṣọ́ra kí èrò búburú kan má ṣe sí nínú àyà rẹ wí pé, “Ọdún keje tí í ṣe ọdún ìyọ̀ǹda gbèsè ti súnmọ́,” nípa bẹ́ẹ̀, ojú rẹ a sì burú sí arákùnrin rẹ tálákà, tí ìwọ kò sì fun ní nǹkan, o kò sì fun ní nǹkan kan. Òun a si kígbe pe Olúwa nítorí rẹ, a si di ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ.
\v 10 Fún un tọkàntọkàn, láìsí ìkùnsínú, nítorí èyí, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ yóò bùkún fún ọ nínú iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, àti gbogbo ìdáwọ́lé rẹ.
\v 11 A kò lè fẹ́ tálákà kù ní ilẹ̀ náà ní ìgbà gbogbo, mo pàṣẹ fún un yín láti lawọ́ sí àwọn arákùnrin yín, sí àwọn tálákà àti sí àwọn aláìní, ní ilẹ̀ ẹ yín.
\s1 Ìdásílẹ̀ àwọn ẹrú
\p
\v 12 \x - \xo 15.12-18: \xt El 21.2-11; Le 25.39-46.\x*Bí Heberu ara yín kan, yálà ọkùnrin tàbí obìnrin bá ta ara rẹ̀ fún ọ, tí ó sì sìn ọ́ fún ọdún mẹ́fà. Ní ọdún keje, jẹ́ kí ó di òmìnira.
\v 13 Nígbà tí ó bá dá a sílẹ̀ má ṣe jẹ́ kí ó lọ lọ́wọ́ òfo.
\v 14 Fi tọkàntọkàn fún un láti inú agbo ewúrẹ́ rẹ, ilẹ̀ ìpakà rẹ, àti ibi ìfúntí rẹ. Fún un gẹ́gẹ́ bí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ ti bùkún fún ọ tó.
\v 15 Ẹ rántí pé ẹ ti fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú ní Ejibiti, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín sì rà yín padà, ìdí nìyí tí mo fi pa àṣẹ yìí fún un yín lónìí.
\p
\v 16 Ṣùgbọ́n bí ìránṣẹ́ rẹ bá sọ fún ọ pé, “Èmi kò fẹ́ fi ọ́ sílẹ̀,” nítorí pé ó fẹ́ràn ìwọ àti ìdílé rẹ, tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn,
\v 17 kí ìwọ kí ó mú ìlu kan lu etí rẹ̀ mọ́ ara ìlẹ̀kùn, yóò sì di ẹrú rẹ láéláé. Bẹ́ẹ̀ náà ni kí o ṣe sí ìránṣẹ́ ẹrúbìnrin rẹ.
\p
\v 18 Má ṣe kà á sí ohun ìnira láti dá ẹrú rẹ sílẹ̀, nítorí ìsìnrú rẹ̀ fún ọ, ní ọdún mẹ́fà náà tó ìlọ́po méjì iṣẹ́ alágbàṣe, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ yóò bùkún fún ọ nínú gbogbo ìdáwọ́lé rẹ.
\s1 Àkọ́bí àwọn ẹran ọ̀sìn
\p
\v 19 \x - \xo 15.19-23: \xt El 13.11,12; 22.30; 34.19; Nu 18.17,18.\x*Gbogbo àkọ́bí tí o jẹ́ akọ nínú agbo màlúù rẹ ni kí o yà sọ́tọ̀ fún \nd Olúwa\nd*, àti nínú agbo ewúrẹ́ bákan náà. Ẹ má ṣe fi àkọ́bí màlúù yín ṣiṣẹ́ rárá. Má ṣe rẹ́ irun àkọ́bí àgùntàn rẹ pẹ̀lú.
\v 20 Ní ọdọọdún ni kí ìwọ àti ìdílé rẹ máa jẹ ẹ́ níwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín níbi tí Òun yóò yàn.
\v 21 Bí ẹran ọ̀sìn kan bá ní àbùkù: bóyá ó yarọ, tàbí fọ́jú, tàbí tí ó ní èyíkéyìí àbùkù tó burú. Ẹ kò gbọdọ̀ fi rú ẹbọ sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín.
\v 22 Ẹ jẹ ẹ́ ní ìlú u yín. Àti ẹni tí a kà sí mímọ́ àti aláìmọ́ ni ó lè jẹ ẹ́ bí ìgbà tí a ń jẹ èsúró tàbí àgbọ̀nrín.
\v 23 \x - \xo 15.23: \xt Gẹ 9.4; Le 7.26,27; 17.10-14; 19.26; De 12.16,23.\x*Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, ẹ dà á síta bí omi.
\c 16
\s1 Àjọ ìrékọjá
\p
\v 1 \x - \xo 16.1-17: \xt El 23.14-17; Le 23; Nu 2829.\x*Ẹ kíyèsi oṣù Abibu, kí ẹ sì máa ṣe àjọ̀dún ìrékọjá ti \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, nítorí pé ní oṣù Abibu yìí ni ó mú un yín jáde ní Ejibiti lóru.
\v 2 Ẹ fi ẹran kan rú ẹbọ bí ìrékọjá sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín láti inú ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo màlúù yín ní ibi tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín yóò yàn bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀.
\v 3 Ẹ má ṣe jẹ ẹ́ pẹ̀lú u àkàrà tí a fi ìwúkàrà ṣe, ṣùgbọ́n ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, àkàrà ìpọ́njú, nítorí pé pẹ̀lú ìkánjú ni ẹ kúrò ní Ejibiti: kí ẹ bá à lè rántí ìgbà tí ẹ kúrò ní Ejibiti ní gbogbo ọjọ́ ayé yín.
\v 4 Kí a má sì ṣe rí àkàrà wíwú ní ọ̀dọ̀ rẹ nínú ilẹ̀ rẹ ní ijọ́ méje. Kí ìwọ má ṣe jẹ́ kí nǹkan kan ṣẹ́kù nínú ẹran tí ìwọ ó fi rú ẹbọ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní di àárọ̀ ọjọ́ kejì.
\p
\v 5 Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ìrékọjá náà ní ìlúkílùú kankan, tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín fi fún un yín
\v 6 bí kò ṣe ibi tí yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀, níbẹ̀ ni ki ẹ ti ṣe ìrúbọ ìrékọjá náà ní ìrọ̀lẹ́ nígbà tí oòrùn bá ń wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìrántí ìgbà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.
\v 7 Ẹ sun ún kí ẹ sì jẹ ẹ́ ní ibi tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín yóò yàn. Ní àárọ̀, kí ẹ padà sí àgọ́ ọ yín.
\v 8 Ọjọ́ mẹ́fà ní kí ẹ fi jẹ àkàrà aláìwú, ní ọjọ́ keje, ẹ pe àjọ kan fún \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, kí ẹ má sì ṣe iṣẹ́ kankan.
\s1 Ayẹyẹ àwọn ọ̀sẹ̀
\p
\v 9 Ka ọ̀sẹ̀ méje láti ìgbà tí ẹ bá ti bẹ̀rẹ̀ sí fi dòjé ṣe ìkórè ọkà.
\v 10 Nígbà náà ni kí ẹ ṣe àjọ ọ̀sẹ̀ sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, nípa pípèsè ọrẹ àtinúwá, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín fún un yín.
\v 11 Kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ní ibi tí yóò yàn ní ibùgbé fún orúkọ rẹ̀: ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin, àwọn ẹrú yín ọkùnrin àti àwọn ẹrú yín obìnrin, àwọn Lefi tí ó wà ní ìlú yín, àti àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé àárín yín.
\v 12 Ẹ rántí pé, ẹ ti jẹ́ ẹrú ní Ejibiti rí, nítorí náà ẹ tẹ̀lé àwọn ìlànà wọ̀nyí dáradára.
\s1 Ayẹyẹ àgọ́ ìpàdé
\p
\v 13 Ẹ ṣe ayẹyẹ àgọ́ ìpàdé fún ọjọ́ méje lẹ́yìn ìgbà tí ẹ bá ti kórè oko yín tí ẹ ti pakà tí ẹ sì ti fún ọtí tán.
\v 14 Ẹ máa yọ̀ ní àkókò àjọ̀dún un yín, ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin, àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin yín, àti àwọn Lefi, àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba àti àwọn opó tí ń gbé ní àwọn ìlú u yín.
\v 15 Ọjọ́ méje ni kí ẹ̀yin kí ó fi ṣe ayẹyẹ fún \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ní ibi tí \nd Olúwa\nd* yóò yàn. Nítorí pé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín ní gbogbo ìkórè e yín, àti ní gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín, ayọ̀ ọ yín yóò sì kún.
\p
\v 16 Ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́dún ni kí gbogbo àwọn ọkùnrin rẹ kí ó farahàn níwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ̀, ní ibi tí yóò yàn. Níbi àjọ àkàrà àìwú, níbi àjọ ọ̀sẹ̀, àti àjọ àgọ́ ìpàdé. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá sí iwájú \nd Olúwa\nd* ní ọwọ́ òfo.
\v 17 Kí olúkúlùkù ó mú ọrẹ wá bí agbára rẹ̀ ti tó, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ tí ó fi fún un ọ̀.
\s1 Àwọn adájọ́
\p
\v 18 Ẹ yan àwọn adájọ́ àti àwọn olóyè fún ẹ̀yà a yín kọ̀ọ̀kan, ní gbogbo ìlú tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín yóò fún un yín, wọ́n sì gbọdọ̀ máa fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.
\v 19 \x - \xo 16.19: \xt El 23.6-9; Le 19.15.\x*Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúsàájú ènìyàn. Ìwọ kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń fọ́ ojú ọlọ́gbọ́n, ó sì ń ba ọ̀rọ̀ olódodo jẹ́.
\v 20 Ẹ tẹ̀lé ìdájọ́ òtítọ́ àní ìdájọ́ òtítọ́ nìkan, kí ẹ bá à lè gbé kí ẹ sì gba ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ń fún un yín.
\s1 Sí sin ọlọ́run mìíràn
\p
\v 21 \x - \xo 16.21,22: \xt Le 26.1.\x*Ẹ má ṣe ri ère òrìṣà Aṣerah sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ tí ẹ ti mọ fún \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín.
\v 22 Ẹ kò gbọdọ̀ gbé òkúta òrìṣà gbígbẹ́ kan kalẹ̀ fún ara yín, nítorí èyí ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín kórìíra.
\c 17
\p
\v 1 \x - \xo 17.1: \xt Le 22.17-24.\x*Ẹ má ṣe fi màlúù tàbí àgùntàn tí ó ní àbùkù, tàbí àbàwọ́n rú ẹbọ sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, nítorí ìríra ni èyí yóò jẹ́ fún un.
\p
\v 2 \x - \xo 17.2-7: \xt Ek 22.20.\x*Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tó ń gbé láàrín yín ní èyíkéyìí ìlú wọ̀n-ọn-nì, tí \nd Olúwa\nd* fún un yín bá ń ṣe ibi ní ojú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, ní ríré májẹ̀mú rẹ̀ kọjá,
\v 3 èyí tí ó lòdì sí òfin mi, ó ń sin ọlọ́run mìíràn, ó ń foríbalẹ̀ fún wọn: àní sí oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run,
\v 4 tí èyí sì dé etí ìgbọ́ ọ yín, kí ẹ wádìí ọ̀rọ̀ náà dájúdájú. Bí ó bá jẹ́ òtítọ́ tí ó sì hàn gbangba pé ó ti ṣe ohun ìríra yìí, ní Israẹli.
\v 5 Ẹ mú ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó ti ṣe ibi yìí wá sí ẹnu-ọ̀nà ibodè ìlú u yín, kí ẹ sọ ọ́ ní òkúta pa.
\v 6 \x - \xo 17.6: \xt Nu 35.30; De 19.15; Mt 18.16; 2Kọ 13.1; 1Tm 5.19; Hb 10.28.\x*Lénu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta ni a ó pa ọkùnrin náà tí ó yẹ láti kú, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe pànìyàn nípasẹ̀ ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo.
\v 7 \x - \xo 17.7: \xt De 19.19; 1Kọ 5.13.\x*Àwọn ẹlẹ́rìí ni kí ó kọ́kọ́ gbọ́wọ́ lé e láti pa á. Lẹ́yìn èyí ni kí gbogbo ènìyàn dáwọ́jọ láti pa á. Nípa báyìí, ẹ̀yin yóò sì fọ ohun búburú náà mọ́ kúrò ní àárín yín.
\s1 Àwọn ilé ẹjọ́
\p
\v 8 Bí ẹjọ́ bá wá sí ilé ẹjọ́ èyí tí ó nira jù láti dá, yálà ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni, ọ̀ràn dídá tàbí ìkanni-lábùkù, ẹ mú wọn lọ sí ibi tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín yóò yàn.
\v 9 Ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àlùfáà tí í ṣe Lefi, àní sí ọ̀dọ̀ adájọ́ tí ó wà fún ìgbẹ́jọ́ ní ìgbà náà. Ẹ béèrè lọ́wọ́ wọn, wọn yóò sì ṣe ìdájọ́.
\v 10 Kí ìwọ kí ó sì ṣe bí ọ̀rọ̀ ìdájọ́, ti àwọn ará ibi tí \nd Olúwa\nd* yóò yàn náà yóò fihàn ọ, kí ìwọ kí ó sì máa kíyèsí àti máa ṣe gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí wọn kọ́ ọ.
\v 11 Ẹ ṣe bí òfin tí wọ́n kọ́ ọ yín, àti ìpinnu tí wọ́n fún un yín. Ẹ má ṣe yípadà sọ́tùn tàbí sósì, kúrò nínú ohun tí wọ́n sọ fún un yín.
\v 12 Ọkùnrin náà tí ó bá ṣe àìbọ̀wọ̀ fún adájọ́ tàbí àlùfáà tí ó ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, níbẹ̀ ni kí ẹ pa á. Nípa báyìí ẹ̀yin yóò sì fọ ohun búburú náà mọ́ kúrò ní Israẹli.
\v 13 Gbogbo ènìyàn ni yóò sì gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n, wọn kò sì ní ṣe àìgbọ́ràn mọ́.
\s1 Ọba
\p
\v 14 Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín yóò fún un yín, tí ẹ sì ti gba ilẹ̀ náà, tí ẹ sì ń gbé inú rẹ̀, tí ẹ sì wá sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a yan ọba tí yóò jẹ lé wa lórí bí i ti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká.”
\v 15 Ẹ rí i dájú pé ọba tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín yàn fún un yín ní ẹ yàn. Ó gbọdọ̀ jẹ́ láàrín àwọn arákùnrin yín. Ẹ má ṣe fi àjèjì jẹ ọba lórí i yín: àní ẹni tí kì í ṣe arákùnrin ní Israẹli.
\v 16 Síwájú sí i, ọba náà kò gbọdọ̀ kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣin jọ fún ara rẹ̀, tàbí kí ó rán àwọn ènìyàn náà padà sí Ejibiti láti wá àwọn ẹṣin sí i, nítorí pé \nd Olúwa\nd* ti sọ fún un yín pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ tún padà lọ ní ọ̀nà náà mọ́.”
\v 17 Kò gbọdọ̀ kó aya jọ, kí ọkàn rẹ̀ má bá a yapa kúrò. Kò gbọdọ̀ kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara rẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀.
\p
\v 18 Nígbà tí ó bá jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kí ó ṣe àdàkọ àwọn òfin wọ̀nyí sí inú ìwé fún ara rẹ̀, láti inú ti àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi.
\v 19 Èyí yóò sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀, òun ó sì máa kà nínú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, kí ó lè máa kọ́ àti bẹ̀rù \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ̀, láti máa tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí àti àwọn ìlànà rẹ̀ tọkàntọkàn.
\v 20 Kí ó má ba à lérò pé òun sàn ju àwọn arákùnrin rẹ̀ yòókù lọ, kí ó sì ti ipa bẹ́ẹ̀ yípadà kúrò nínú òfin wọ̀nyí sí ọ̀tún tàbí sí òsì. Bẹ́ẹ̀ ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jẹ ọba pẹ́ títí ní Israẹli.
\c 18
\s1 Ọrẹ fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi
\p
\v 1 \x - \xo 18.1-8: \xt Nu 18.20-24.\x*Àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi, àní gbogbo ẹ̀yà Lefi, wọn kì yóò ní ìpín tàbí ogún láàrín Israẹli, wọn yóò máa jẹ nínú ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe sí \nd Olúwa\nd*, nítorí òun ni ogún un tiwọn.
\v 2 Wọn kì yóò ní ìní láàrín àwọn arákùnrin wọn; \nd Olúwa\nd* ni yóò jẹ́ ìní i tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn.
\p
\v 3 Gbogbo èyí ni yóò jẹ́ ìpín àwọn àlùfáà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó fi akọ màlúù tàbí àgùntàn rú ẹbọ; wọn yóò fi èjìká àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ méjèèjì àti gbogbo inú fún àlùfáà.
\v 4 Àkọ́so irúgbìn ọkà rẹ, ti wáìnì àti ti òróró rẹ, àti àkọ́rẹ́ irun àgùntàn rẹ ni ìwọ yóò fi fún wọn.
\v 5 Nítorí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n àti àwọn ọmọ wọn láti inú gbogbo ẹ̀yà láti dúró àti láti ṣe ìránṣẹ́ ní orúkọ \nd Olúwa\nd* títí láé.
\p
\v 6 Tí ọmọ Lefi kan bá sì wá láti ibikíbi nínú àwọn ìlú u yín ní Israẹli, níbi tí ó ń gbé ṣe àtìpó, tí ó sì wá gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀ sí ibi tí \nd Olúwa\nd* yóò yàn.
\v 7 Nígbà náà ni ó lè máa ṣe ìránṣẹ́ ní orúkọ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Lefi arákùnrin rẹ̀ ti ń dúró ṣe iṣẹ́ ìsìn níwájú \nd Olúwa\nd* níbẹ̀.
\v 8 Wọn yóò ní ìpín kan láti jẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti gba owó nípa títa ogún baba rẹ̀.
\s1 Ohun ìríra
\p
\v 9 Nígbà tí o bá wọ ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ, ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ láti tẹ̀lé àwọn ọ̀nà ìríra àwọn orílẹ̀-èdè náà tí ó wà níbẹ̀.
\v 10 \x - \xo 18.10,11: \xt Ek 22.18; Le 19.26,31; 20.6,27.\x*Má ṣe jẹ́ kí a rí ẹnikẹ́ni láàrín yín tí ó fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin la iná já (fi ọmọ rẹ rú ẹbọ) kí ẹnikẹ́ni má ṣe lọ fọ àfọ̀ṣẹ, tàbí ṣẹ́ oṣó, tàbí túmọ̀ àwọn àmì nǹkan tí ń bọ̀, tàbí àjẹ́,
\v 11 tàbí afògèdè, tàbí jẹ́ a bá iwin gbìmọ̀ tàbí oṣó tàbí abókùúsọ̀rọ̀.
\v 12 Ẹnikẹ́ni tó bá ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìríra sí \nd Olúwa\nd*, àti nítorí àwọn ìwà ìríra wọ̀nyí ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ yóò fi lé àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jáde kúrò níwájú rẹ.
\v 13 \x - \xo 18.13: \xt Mt 5.48.\x*O ní láti jẹ́ aláìlẹ́gàn níwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ.
\s1 Wòlíì
\p
\v 14 Àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ yóò gba ilẹ̀ tí wọ́n ń gbé, wọ́n fetí sí tí àwọn tí ó ń ṣe oṣó tàbí ṣe àfọ̀ṣẹ. Ṣùgbọ́n, ní ti ìwọ, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ kò fi ààyè gbà ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
\v 15 \x - \xo 18.15-19: \xt Ap 3.22,23; 7.37.\x*\nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ yóò gbé wòlíì kan dìde gẹ́gẹ́ bí èmi láàrín àwọn arákùnrin rẹ. Tìrẹ ni kí o gbọ́.
\v 16 Nítorí èyí ni ohun tí ìwọ béèrè lọ́wọ́ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ ní Horebu ní ọjọ́ àjọ, nígbà tí ìwọ wí pé, “Kí àwa má ṣe gbọ́ ohùn \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa tàbí rí iná ńlá yìí mọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò kú.”
\p
\v 17 \nd Olúwa\nd* sì wí fún mi pé, “Ohun tí wọ́n sọ dára.
\v 18 Èmi yóò gbé wòlíì kan dìde fún wọn láàrín àwọn arákùnrin wọn bí ìwọ, Èmi yóò fi ọ̀rọ̀ mi sí i ní ẹnu, yóò sì sọ fún wọn gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún un.
\v 19 \x - \xo 18.19: \xt Ap 3.23.\x*Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi tí wòlíì náà yóò sọ ní orúkọ mi, èmi fúnra à mi yóò sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
\v 20 Ṣùgbọ́n bí wòlíì kan bá kùgbù sọ ọ̀rọ̀ kan tí èmi kò paláṣẹ fún un láti sọ ní orúkọ mi tàbí wòlíì tí ó sọ̀rọ̀ ní orúkọ ọlọ́run mìíràn, irú wòlíì bẹ́ẹ̀ ní láti kú.”
\p
\v 21 Ṣùgbọ́n ìwọ lè wí ní ọkàn rẹ pé, “Báwo ni àwa yóò ṣe mọ ọ̀rọ̀ tí \nd Olúwa\nd* kò sọ?”
\v 22 Nígbà tí ohun tí wòlíì bá sọ ní orúkọ \nd Olúwa\nd* kò bá wá sí ìmúṣẹ tàbí jẹ́ òtítọ́, ìyẹn ni ọ̀rọ̀ tí \nd Olúwa\nd* kò sọ, irú wòlíì bẹ́ẹ̀ tí sọ láìwádìí. Kí ẹ má ṣe bẹ̀rù rẹ̀.
\c 19
\s1 Ìlú ààbò
\p
\v 1 \x - \xo 19.1-13: \xt Ek 21.12-14; Nu 35.\x*Nígbà tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ bá ti pa àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò fi ilẹ̀ wọn fún ọ run, àti nígbà tí ìwọ bá ti lé wọn jáde tí o sì dó sí àwọn ilẹ̀ àti ilé wọn gbogbo.
\v 2 Ìwọ yóò ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ fún ara à rẹ láàrín ilẹ̀ rẹ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run fún ọ láti ni.
\v 3 Ṣe àwọn ọ̀nà sí wọn àti kí o pín ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún sí ọ̀nà mẹ́ta nítorí kí apànìyàn lè sá níbẹ̀.
\p
\v 4 Èyí ni òfin nípa apànìyàn, tí ó sì sá síbẹ̀ láti pa ẹ̀mí rẹ̀ mọ́. Ẹni tí ó pa aládùúgbò láìmọ̀ọ́mọ̀ṣeé láìjẹ́ pé ó ti ní àrankàn pẹ̀lú u rẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́.
\v 5 Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan lè lọ sínú igbó pẹ̀lú aládùúgbò rẹ̀ láti gé igi, bí ó sì ti gbé àáké e rẹ̀ láti gé igi náà lulẹ̀, bí àáké náà bá yọ tí ó sì bà aládùúgbò rẹ̀, tí òun sì kú. Ọkùnrin yìí lè sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú yìí láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là.
\v 6 Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ lè máa lépa rẹ̀ nínú ìbínú, kí ó sì lé e bá nítorí pé ọ̀nà jì, kí ó sì pa á bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ sí ikú, nígbà tí ó ṣe é sí aládùúgbò rẹ̀ láìjẹ́ pé ó ti ní àrankàn pẹ̀lú u rẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́.
\v 7 Ìdí nìyìí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ fún ara rẹ.
\p
\v 8 Tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ bá sì fẹ́ agbègbè rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba ńlá a yín, tí ó sì fún ọ ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ti ṣe ìlérí fún wọn,
\v 9 nítorí tí ìwọ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tẹ̀lé gbogbo òfin yìí tí mo pàṣẹ fún ọ lónìí yìí, kí o fẹ́ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ, kí o sì rìn ní ọ̀nà an rẹ̀ ní gbogbo ìgbà náà, kí o ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀.
\v 10 Ṣe èyí kí a má ṣe ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ni ilẹ̀ rẹ, èyí tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ yóò fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún, kí ìwọ kí ó má bá a jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ títa.
\p
\v 11 Ṣùgbọ́n tí ọkùnrin kan bá kórìíra arákùnrin rẹ̀, tí ó sì lúgọ dè é, tí ó mú u tí o lù ú pa, tí ọkùnrin náà sì sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú wọ̀nyí,
\v 12 àwọn àgbàgbà ìlú rẹ yóò sì ránṣẹ́ pè é ìwọ, yóò sì mú un padà láti ìlú náà, wọn yóò sì fi í lé àwọn agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́ kí ó lè kú.
\v 13 Má ṣe ṣàánú fún un. O ní láti fọ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò ni Israẹli, kí ó bá à lè dára fún ọ.
\p
\v 14 Má ṣe pa òkúta ààlà aládùúgbò rẹ dà tí aṣíwájú rẹ fi lélẹ̀ nínú ogún tí ó gbà nínú ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ fi fún ọ láti ni ní ìní.
\s1 Ẹlẹ́rìí
\p
\v 15 \x - \xo 19.15: \xt Nu 35.30; De 17.6; Mt 18.16; 2Kọ 13.1; 1Tm 5.19; Hb 10.28.\x*Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo kò tó láti dájọ́ ọkùnrin kan tí o fi ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ yóò wù kí ó lè ṣẹ̀ lẹ́bi. A ó fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ láti orí ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta.
\p
\v 16 \x - \xo 19.16-20: \xt El 20.16; 23.1; Le 19.16; De 5.20.\x*Tí alárankàn ẹlẹ́rìí èké bá dúró láti fi ẹ̀sùn ẹ̀ṣẹ̀ kan ọkùnrin kan,
\v 17 àwọn méjèèjì tí àríyànjiyàn wà láàrín wọn gbọdọ̀ dúró níwájú \nd Olúwa\nd* níwájú àwọn àlùfáà àti àwọn adájọ́ tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní ìgbà náà.
\v 18 Àwọn adájọ́ gbọdọ̀ ṣe ìwádìí fínní fínní bí ẹ̀rí bá sì jẹ́ irọ́, tí ó fi ẹ̀rí èké sun arákùnrin rẹ̀,
\v 19 \x - \xo 19.19: \xt 1Kọ 5.13.\x*nígbà náà ni kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fẹ́ ṣe sí arákùnrin rẹ̀. O ní láti wẹ búburú kúrò láàrín rẹ.
\v 20 Àwọn ènìyàn tókù yóò gbọ́ nípa èyí, wọn yóò sì bẹ̀rù, kí irú nǹkan búburú bẹ́ẹ̀ máa tún sẹ̀ mọ́ láàrín yín.
\v 21 \x - \xo 19.21: \xt El 21.23-26; Le 24.20; Mt 5.38.\x*Má ṣe fi àánú hàn, ẹ̀mí fún ẹ̀mí, ojú fún ojú, eyín fún eyín, apá fún apá, ẹsẹ̀ fún ẹsẹ̀.
\c 20
\s1 Lílọ sí ogun
\p
\v 1 Nígbà tí o bá lọ sí ogun pẹ̀lú ọ̀tá rẹ, tí o sì rí ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti ológun tí ó jù ọ́ lọ, má ṣe bẹ̀rù u wọn, nítorí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ tí ń mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti, yóò wà pẹ̀lú rẹ.
\v 2 Nígbà tí o bá fẹ́ lọ jagun, àlùfáà yóò wá síwájú, yóò sì bá ọmọ-ogun sọ̀rọ̀,
\v 3 yóò sì wí pé, “Gbọ́, ìwọ Israẹli, lónìí ò ń jáde lọ sójú ogun sí ọ̀tá rẹ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín ṣojo tàbí bẹ̀rù; ẹ má ṣe jáyà tàbí kí ẹ fi ààyè fún ìjayà níwájú u wọn.
\v 4 Nítorí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ní bá yín lọ, láti bá àwọn ọ̀tá yín jà fún yín, láti gbà yín là.”
\p
\v 5 Àwọn olórí ogun yóò sì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó kọ́ ilé tuntun tí kò sì tì ì yà á sọ́tọ̀? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí ó lè kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì gbà á.
\v 6 Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó gbin ọgbà àjàrà kan tí kò sì tí ì bẹ̀rẹ̀ sí ń gbádùn rẹ̀? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí kí ó kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì gbádùn rẹ̀.
\v 7 Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó wá ògo obìnrin kan tí kò ì tí ì fẹ́ ẹ? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí kí ó kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì fẹ́ ẹ.”
\v 8 Nígbà náà ni olórí yóò tún fi kún un pé, “Ǹjẹ́ ọkùnrin kankan ń bẹ̀rù tàbí páyà? Jẹ́ kí ó lọ ilé nítorí kí arákùnrin rẹ̀ má ba à wá tún dáyà fò ó.”
\v 9 Nígbà tí olórí ogun bá ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ sí àwọn ènìyàn, wọn yóò yan olórí ogun lórí i rẹ̀.
\p
\v 10 Nígbà tí ó bá súnmọ́ iwájú láti dojúkọ ìlú kan láti bá a jà, nígbà náà ni kí ó fi àlàáfíà lọ̀ ọ́.
\v 11 Tí wọ́n bá dá ọ lóhùn àlàáfíà, tí wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn, gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ yóò máa jẹ́ olùsìn fún ọ, wọn ó sì máa sìn ọ́.
\v 12 Tí wọ́n bá kọ̀ láti bá ọ ṣe àlàáfíà ṣùgbọ́n tí wọ́n bá gbóguntì ọ́, nígbà náà ni kí ìwọ gbà á.
\v 13 Nígbà tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ bá fi lé ọ lọ́wọ́, kí ẹ̀yin kí ó fi ojú idà pa gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó wà níbẹ̀.
\v 14 Ní ti obìnrin, àwọn ọmọdé, ohun ọ̀sìn àti gbogbo ohun tí ó kù nínú ìlú náà, o lè mú ìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ìkógun fún ara rẹ. O sì lè lo ìkógun tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ fi fún ọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá rẹ.
\v 15 Báyìí ni ìwọ yóò ṣe sí gbogbo ìlú tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn sí ọ tí wọn kò sì tara àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ rẹ.
\p
\v 16 Ṣùgbọ́n, nínú àwọn ìlú ti àwọn orílẹ̀-èdè tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ ń fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún, má ṣe dá ohun ẹlẹ́mìí kankan sí.
\v 17 Pa wọ́n run pátápátá, àwọn ọmọ Hiti, ọmọ Amori, ọmọ Kenaani, ọmọ Peresi, ọmọ Hifi, ọmọ Jebusi gẹ́gẹ́ bí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ ti pa á láṣẹ fún ọ.
\v 18 Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kọ́ ọ láti tẹ̀lé gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe nínú sí sin àwọn ọlọ́run wọn, ìwọ yóò sì ṣẹ̀ sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ.
\p
\v 19 Nígbà tí o bá dó ti ìlú kan láti ọjọ́ pípẹ́, ẹ bá wọn jà láti gbà á, má ṣe pa àwọn igi ibẹ̀ run nípa gbígbé àáké lé wọn, nítorí o lè jẹ èso wọn. Má ṣe gé wọn lulẹ̀. Nítorí igi igbó ha á ṣe ènìyàn bí, tí ìwọ ó máa dó tì rẹ̀.
\v 20 Ṣùgbọ́n ìwọ lè gé àwọn igi tí o mọ̀ pé wọn kì í ṣe igi eléso lulẹ̀ kí o sì lò wọ́n láti kọ́ ìṣọ́ sí ìlú tí ó ń bá ọ jagun, títí tí yóò fi ṣubú.
\c 21
\s1 Ìdáríjì ìpànìyàn láìnítumọ̀
\p
\v 1 Tí a bá rí ọkùnrin tí a pa, ní ìdùbúlẹ̀ ní pápá nínú ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ ń fún ọ láti jogún, tí a kò sì mọ ẹni tí ó pa á,
\v 2 àwọn àgbàgbà yín yóò jáde lọ láti wọn jíjìnnà ibi òkú sí ìlú tí ó wà nítòsí.
\v 3 Nígbà náà ni àwọn àgbàgbà ìlú tí ó wà nítòsí òkú yóò mú ẹgbọrọ abo màlúù tí kò ì ṣiṣẹ́ rí àti tí kò sì fà nínú àjàgà rí,
\v 4 kí àwọn àgbàgbà ìlú náà kí wọn mú ẹgbọrọ abo màlúù náà sọ̀kalẹ̀ wá sí àfonífojì tí ó ní omi ṣíṣàn kan, tí a kò ro, tí a kò sì gbìn, kí wọn kí ó sì ṣẹ́ ọrùn ẹgbọrọ màlúù náà níbẹ̀ ní àfonífojì náà.
\v 5 Àwọn àlùfáà, ọmọ Lefi yóò wá síwájú, nítorí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún un àti láti bùkún ní orúkọ \nd Olúwa\nd* àti láti parí gbogbo ẹjọ́ àríyànjiyàn àti ọ̀rọ̀ ìlú.
\v 6 Nígbà náà ni gbogbo àwọn àgbàgbà ìlú tí ó wà nítòsí yóò wẹ ọwọ́ wọn lórí ẹgbọrọ abo màlúù tí a ti kan ọrùn rẹ̀ ní àfonífojì,
\v 7 wọn yóò sì sọ pé, “Ọwọ́ wa kò ta ẹ̀jẹ̀ yìí sílẹ̀, tàbí kí ojú wa rí i ní títa sílẹ̀.”
\v 8 Dáríjì, \nd Olúwa\nd*, àwọn ènìyàn rẹ ni Israẹli, tí ìwọ ti dá sílẹ̀, àti kí ìwọ má ṣe gba ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ ní àárín àwọn ènìyàn rẹ ní Israẹli. Ṣùgbọ́n kí a dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ yìí jì.
\v 9 Nígbà náà ni ìwọ wẹ̀ kúrò láàrín rẹ ẹ̀bi títa ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí o ti ṣe èyí tí ó tọ́ níwájú \nd Olúwa\nd*.
\s1 Fífẹ́ obìnrin ìgbèkùn
\p
\v 10 Nígbà tí o bá lọ sí ogun sí àwọn ọ̀tá rẹ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ tí o sì mú àwọn ìgbèkùn,
\v 11 tí o sì rí obìnrin tí ó dára lára àwọn ìgbèkùn, tí o sì ní ìfẹ́ sí i, o lè mu u gẹ́gẹ́ bí aya à rẹ.
\v 12 Mú u wá sí ilé e rẹ kí o sì jẹ́ kí ó fá irun orí rẹ̀, gé èékánná an rẹ̀,
\v 13 kí o sì mú aṣọ tí ó wọ̀ nígbà tí ó di ìgbèkùn sí ẹ̀gbẹ́ kan. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ń gbé ilé rẹ tí ó sì ti ṣọ̀fọ̀ baba àti ìyá rẹ̀ fún odidi oṣù kan, nígbà náà ni o lè tọ̀ ọ́ lọ kí o sì ṣe ọkọ rẹ̀ kí ó jẹ́ aya rẹ.
\v 14 Bí inú rẹ̀ kò bá sì dùn sí i, jẹ́ kí ó lọ sí ibikíbi tí ó bá fẹ́. O kò gbọdọ̀ tà á tàbí lò ó bí ẹrú, lẹ́yìn ìgbà tí o ti dójútì í.
\s1 Ẹ̀tọ́ àkọ́bí
\p
\v 15 Bí ọkùnrin kan bá ní ìyàwó méjì, tí ó sì fẹ́ ọ̀kan ṣùgbọ́n tí kò fẹ́ èkejì, tí àwọn méjèèjì sì bí àwọn ọmọkùnrin fún un ṣùgbọ́n tí àkọ́bí jẹ́ ọmọ ìyàwó rẹ̀ tí kò fẹ́ràn.
\v 16 Nígbà tí ó bá ń pín ohun ìní rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, kò gbọdọ̀ fi ẹ̀tọ́ àkọ́bí fún ọmọ ìyàwó tí kò fẹ́ràn.
\v 17 Ó ní láti fi ipò ọmọ ìyàwó rẹ̀ tí kò fẹ́ràn fun un gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí i rẹ̀ nípa fífún un ní ìlọ́po ìpín gbogbo ohun tí ó ní. Ọmọ yẹn ni àmì àkọ́kọ́ agbára baba rẹ̀. Ẹ̀tọ́ àkọ́bí jẹ́ tirẹ̀.
\s1 Ọlọ̀tẹ̀ ọmọ
\p
\v 18 \x - \xo 21.18-21: \xt El 20.12; 21.15,17; Le 20.9; De 5.16; 27.16.\x*Bí ọkùnrin kan bá ní aláìgbọ́ràn tàbí ọlọ̀tẹ̀ ọmọ tí kò gbọ́rọ̀ sí baba àti ìyá rẹ̀ tí kò sì ní í gbà tí wọ́n bá ń bá a wí,
\v 19 baba àti ìyá rẹ̀ yóò gbá a mú, wọn yóò mu wá fún àwọn àgbàgbà ní ẹnu-bodè ìlú u rẹ̀.
\v 20 Wọn yóò sì wí fún àwọn àgbàgbà pé, “Ọmọ wa yìí jẹ́ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀. Kò ní gbọ́rọ̀ sí wa lẹ́nu. Ọ̀jẹun àti ọ̀mùtípara ni.”
\v 21 Nígbà náà ni gbogbo ọkùnrin ìlú rẹ̀ yóò sọ ọ́ ní òkúta pa. Ìwọ yóò sì mú ìwà ibi kúrò láàrín yín, gbogbo Israẹli yóò gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n.
\s1 Onírúurú òfin
\p
\v 22 \x - \xo 21.22: \xt Ap 5.30; 10.39.\x*Bí ọkùnrin kan tí ó jẹ̀bi ẹ̀sùn bá ní láti kú tí ó sì kú, tí a sì gbé òkú rẹ̀ kọ́ sára igi,
\v 23 \x - \xo 21.23: \xt Ga 3.13.\x*o kò gbọdọ̀ fi òkú rẹ̀ sílẹ̀ sára igi ní gbogbo òru. Gbìyànjú láti sin ín ní ọjọ́ náà gan an, nítorí ẹni tí a bá gbé kọ́ sórí igi wà lábẹ́ ègún Ọlọ́run. Ìwọ kò gbọdọ̀ ba ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún jẹ́.
\c 22
\p
\v 1 \x - \xo 22.1-4: \xt El 23.4,5.\x*Bí o bá rí màlúù tàbí àgùntàn arákùnrin rẹ tí ó ń sọnù, má ṣe ṣé àìkíyèsí i rẹ̀ ṣùgbọ́n rí i dájú pé o mú padà wá fún un.
\v 2 Bí ọkùnrin náà kì í bá gbé ní tòsí rẹ tàbí bí o kò bá mọ ẹni náà, mú un lọ ilé pẹ̀lú rẹ kí o sì fi pamọ́ títí yóò fi wá a wá. Nígbà náà ni kí o fi fún un.
\v 3 Ṣe bákan náà tí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ arákùnrin rẹ tàbí aṣọ ìlekè tàbí ohunkóhun rẹ̀ tí ó sọnù. Má ṣe ṣe àìkíyèsí i rẹ̀.
\p
\v 4 Bí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí màlúù arákùnrin rẹ tí o dùbúlẹ̀ sójú ọ̀nà, má ṣe ṣàìfiyèsí i rẹ̀, ràn án lọ́wọ́ láti dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀.
\p
\v 5 Obìnrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọ ọkùnrin, tàbí kí ọkùnrin wọ aṣọ obìnrin, nítorí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó ṣe èyí.
\p
\v 6 Bí ìwọ bá ṣe alábòápàdé ìtẹ́ ẹyẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, bóyá lára igi tàbí lórí ilẹ̀, tí ìyá wọn sì jókòó lórí àwọn ọmọ, tàbí lórí àwọn ẹyin, má ṣe gbé ìyá pẹ̀lú àwọn ọmọ.
\v 7 Ìwọ lè gbé ọmọ, ṣùgbọ́n rí i dájú pé o jọ̀wọ́ ìyá lọ́wọ́ lọ, kí ó ba à lè dára fún ọ àti kí o lè ní ẹ̀mí gígùn.
\p
\v 8 Nígbà tí o bá kọ́ ilé tuntun, mọ odi yí òrùlé rẹ̀ ká nítorí kí o má ba à mú ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ wá sórí ilẹ̀ rẹ bí ẹnikẹ́ni bá ṣubú láti òrùlé.
\p
\v 9 \x - \xo 22.9-11: \xt Le 19.19.\x*Má ṣe gbin oríṣìí èso méjì sínú ọgbà àjàrà rẹ; bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe èso oko tí o gbìn nìkan ṣùgbọ́n èso ọgbà àjàrà pẹ̀lú yóò bàjẹ́.
\p
\v 10 Ìwọ kò gbọdọ̀ fi akọ màlúù àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tulẹ̀ pọ̀.
\p
\v 11 Ìwọ kò gbọdọ̀ wọ aṣọ onírun àgùntàn àti aṣọ funfun papọ̀.
\p
\v 12 \x - \xo 22.12: \xt Nu 15.37-41.\x*Kí o ṣe wajawaja sí etí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin aṣọ ìlekè rẹ.
\s1 Ìrúfin ìgbéyàwó
\p
\v 13 Bí ọkùnrin kan bá mú ìyàwó àti, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti dùbúlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, kórìíra rẹ̀,
\v 14 tí ó ṣì sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sì i, tí o sì fún un ní orúkọ búburú, wí pé, “Mo fẹ́ obìnrin yìí, ṣùgbọ́n nígbà tí mo súnmọ́ ọn. Èmi kò rí àmì ìbálé rẹ̀.”
\v 15 Nígbà náà ni baba ọmọbìnrin náà àti ìyá rẹ̀ yóò mú ẹ̀rí pé, ó ti wà ní ìbálé tẹ́lẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbàgbà ìlú ní ẹnu-bodè.
\v 16 Baba obìnrin náà yóò wí fún àwọn àgbàgbà pé, “Mo fi ọmọbìnrin mi fún ọkùnrin yìí láti fẹ́ níyàwó, ṣùgbọ́n ó kórìíra rẹ̀.
\v 17 Ní ìsinsin yìí ó ti sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí i ó sì wí pé, Èmi kò rí ọmọbìnrin rẹ kí ó wà ní wúńdíá. Ṣùgbọ́n níhìn-ín yìí ni ẹ̀rí ìbálé ọmọbìnrin mi.” Nígbà náà ni àwọn òbí rẹ̀ yóò fi aṣọ hàn níwájú àwọn àgbàgbà ìlú,
\v 18 àwọn àgbàgbà yóò sì mú ọkùnrin náà, wọn yóò sì jẹ ní yà.
\v 19 Wọn yóò sì gba ìtánràn ọgọ́rùn-ún ṣékélì owó fàdákà fún baba ọmọbìnrin náà, nítorí ọkùnrin yìí ti fi orúkọ búburú fún wúńdíá Israẹli. Yóò sì máa ṣe ìyàwó rẹ̀; kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní gbogbo ayé e rẹ̀.
\p
\v 20 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀sùn náà bá jẹ́ òtítọ́ tí a kò sí rí ẹ̀rí ìbálé obìnrin náà,
\v 21 \x - \xo 22.21: \xt 1Kọ 5.13.\x*wọn yóò mú wá sí ẹnu-ọ̀nà ilé baba rẹ̀ níbẹ̀ sì ni àwọn ọkùnrin ìlú rẹ̀ yóò ti sọ ọ́ ní òkúta pa. Ó ti ṣe ohun ìtìjú ní Israẹli nípa ṣíṣe àgbèrè nígbà tí ó wà nílé baba rẹ̀. Ẹ ní láti pa ohun búburú kúrò láàrín yín.
\p
\v 22 Bí o bá rí ọkùnrin kan tí ó bá ìyàwó ọkùnrin mìíràn lòpọ̀, àwọn méjèèjì ní láti kú. Ẹ ní láti pa ohun búburú kúrò láàrín Israẹli.
\p
\v 23 Bí ó bá ṣẹlẹ̀ wí pé ọkùnrin kan pàdé wúńdíá tí a ti fi fún ni láti fẹ́ láàrín ìlú tí ó sì lòpọ̀ pẹ̀lú u rẹ̀,
\v 24 \x - \xo 22.24: \xt 1Kọ 5.13.\x*ìwọ yóò mú àwọn méjèèjì lọ sí ẹnu ibodè ìlú náà kí o sì sọ wọ́n ní òkúta pa nítorí ọmọbìnrin náà wà ní ìlú kò sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́, àti ọkùnrin náà nítorí ó ba ìyàwó ọkùnrin mìíràn jẹ́. O ní láti wẹ búburú kúrò láàrín rẹ.
\p
\v 25 Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìgbẹ́ ní ó ti ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan ti pàdé ọmọbìnrin tí a ti fẹ́ ṣọ́nà tí o sì fi tagbára tagbára bá a ṣe, ọkùnrin náà nìkan tí ó ṣe èyí ni yóò kú.
\v 26 Má ṣe fi ohunkóhun ṣe ọmọbìnrin náà; kò ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tọ́ sí ikú. Ẹjọ́ yìí rí bí i ti ẹnìkan tí a gbámú tí ó pa aládùúgbò rẹ̀.
\v 27 Nítorí ọkùnrin náà rí ọmọbìnrin náà ní ìta ibodè, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọbìnrin àfẹ́sọ́nà kígbe, kò sí ẹnìkankan níbẹ̀ láti gbà á kalẹ̀.
\p
\v 28 \x - \xo 22.28,29: \xt El 22.16,17.\x*Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin pàdé wúńdíá tí kò ì tí ì ní àfẹ́sọ́nà tí ó sì fi tipátipá bá a ṣe tí a gbá wọn mú.
\v 29 Ó ní láti san àádọ́ta fàdákà fún baba obìnrin náà, nítorí tí ó ti bà á jẹ́. Kò lè kọ̀ ọ́ sílẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ó sì wà láààyè.
\p
\v 30 \x - \xo 22.30: \xt Le 18.8; 20.11; De 27.20.\x*Ọkùnrin kò gbọdọ̀ fẹ́ ìyàwó baba rẹ̀; kò gbọdọ̀ sọ ìtẹ́ baba rẹ̀ di àìlọ́wọ̀.
\c 23
\s1 Yíyọ orúkọ ènìyàn kúrò nínú orúkọ àwọn ènìyàn \nd Olúwa\nd*
\p
\v 1 Kí ẹnikẹ́ni tí a fọ́ ní kóró ẹpọ̀n nípa rírùn tàbí gígé má ṣe wọ inú ìjọ \nd Olúwa\nd* wá.
\p
\v 2 Kí ọmọ àlè má ṣe wọ ìpéjọ \nd Olúwa\nd*, pàápàá títí dé ìran kẹwàá.
\p
\v 3 \x - \xo 23.3-5: \xt Ne 13.1,2.\x*Kí ọmọ Ammoni tàbí ọmọ Moabu, kì yóò wọ ìjọ \nd Olúwa\nd*, àní títí dé ìran kẹwàá, ènìyàn wọn kan kì yóò wọ inú ìjọ ènìyàn \nd Olúwa\nd* láéláé.
\v 4 \x - \xo 23.4: \xt Nu 22.1-6.\x*Nítorí wọn kò fi àkàrà àti omi pàdé e yín lójú ọ̀nà nígbà tí ò ń bọ̀ láti Ejibiti àti nítorí wọ́n gba ẹ̀yà iṣẹ́ láti fi ọ́ gégùn ún Balaamu ọmọ Beori ará a Petori ti Aramu-Naharaimu.
\v 5 \x - \xo 23.5: \xt Nu 23.724.9.\x*Síbẹ̀síbẹ̀, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ kò ní fetí sí Balaamu ṣùgbọ́n ó yí ègún sí ìbùkún fún ọ, nítorí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ fẹ́ràn rẹ.
\v 6 Ìwọ kò gbọdọ̀ wá àlàáfíà, tàbí ire wọn níwọ̀n ìgbà tí o sì wà láààyè.
\p
\v 7 Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra ará Edomu kan nítorí arákùnrin rẹ ni. Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra ará Ejibiti, nítorí o gbé gẹ́gẹ́ bí àjèjì ní ilẹ̀ rẹ̀.
\v 8 Ìran kẹta àwọn ọmọ tí a bí fún wọn lè wọ ìpéjọ \nd Olúwa\nd*.
\s1 Ìwà àìmọ́ nínú àgọ́
\p
\v 9 Nígbà tí o bá dó ti àwọn ọ̀tá rẹ, pa gbogbo ohun àìmọ́ kúrò.
\v 10 Bí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin rẹ bá jẹ́ aláìmọ́ nítorí ìtújáde tí ó ní, o ní láti jáde kúrò nínú àgọ́, kí o má ṣe wọ inú àgọ́.
\v 11 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́ o ní láti wẹ ara rẹ, àti ní àṣálẹ́ kí o padà sínú àgọ́.
\p
\v 12 Sàmì sí ibìkan lóde àgọ́, níbi tí o lè máa lọ láti dẹ ara rẹ lára.
\v 13 Kí ìwọ kí ó sì mú ìwalẹ̀ kan pẹ̀lú ohun ìjà rẹ; yóò sì ṣe, nígbà tí ìwọ yóò bá gbọnṣẹ̀ lẹ́yìn ibùdó, kí ìwọ kí ó mú ìwalẹ̀, kí ìwọ kí ó sì yípadà, kí o sì bo ohun tí ó jáde láara rẹ.
\v 14 Nítorí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ ń rìn láàrín àgọ́ láti dáàbò bò ọ́ àti láti fi àwọn ọ̀tá à rẹ lé ọ lọ́wọ́. Àgọ́ rẹ ní láti jẹ́ mímọ́, nítorí kí ó má ba à rí ohun àìtọ́ láàrín yín kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ yín.
\s1 Onírúurú òfin
\p
\v 15 Bí ẹrú kan bá ti gba ààbò lọ́dọ̀ rẹ, má ṣe fi lé ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.
\v 16 Jẹ́ kí ó máa gbé láàrín rẹ níbikíbi tí ó bá fẹ́ àti èyíkéyìí ìlú tí ó bá mú. Má ṣe ni í lára.
\p
\v 17 Kí ọkùnrin tàbí obìnrin Israẹli má ṣe padà di alágbèrè ojúbọ òrìṣà.
\v 18 Ìwọ kò gbọdọ̀ mú owó iṣẹ́ panṣágà obìnrin tàbí ọkùnrin wá sí ilé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ láti fi san ẹ̀jẹ́ kankan; nítorí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ kórìíra àwọn méjèèjì.
\p
\v 19 \x - \xo 23.19: \xt El 22.26; Le 25.35-37.\x*Ìwọ kò gbọdọ̀ ka èlé sí arákùnrin rẹ lọ́rùn, bóyá lórí owó tàbí oúnjẹ tàbí ohunkóhun mìíràn tí ó lè mú èlé wá.
\v 20 Ìwọ lè ka èlé sí àlejò lọ́rùn, ṣùgbọ́n kì í ṣe arákùnrin ọmọ Israẹli, nítorí kí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ lè bùkún ọ nínú ohun gbogbo tí o bá dáwọ́lé ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.
\p
\v 21 \x - \xo 23.21-23: \xt Nu 30.2-16.\x*Bí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ, má ṣe lọ́ra láti san án, nítorí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ yóò béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ, o sì máa jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀.
\v 22 Ṣùgbọ́n tí o bá fàsẹ́yìn láti jẹ́ ẹ̀jẹ́, o kò ní jẹ̀bi.
\v 23 Rí i dájú pé o ṣe ohunkóhun tí o bá ti ètè rẹ jáde, nítorí pé ìwọ fi tinútinú rẹ jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú ẹnu ara rẹ.
\p
\v 24 Bí ìwọ bá wọ inú ọgbà àjàrà aládùúgbò rẹ, o lè jẹ gbogbo èso àjàrà tí o bá fẹ́, ṣùgbọ́n má ṣe fi nǹkan kan sínú agbọ̀n rẹ.
\v 25 Bí ìwọ bá wọ inú oko ọkà aládùúgbò rẹ, o lè fi ọwọ́ rẹ ya síírí rẹ̀, ṣùgbọ́n o kò gbọdọ̀ ki dòjé bọ ọkà tí ó dúró.
\c 24
\p
\v 1 \x - \xo 24.1: \xt Mt 5.31; 19.7; Mk 10.4.\x*Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ obìnrin kan, tí ó sì gbe ní ìyàwó, yóò sì ṣe, bí obìnrin náà kò bá rí ojúrere ní ojú ọkùnrin náà, nítorí ó rí ohun àìtọ́ kan lára rẹ̀, ǹjẹ́ kí ó kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún obìnrin náà, kí ó sì fi lé e lọ́wọ́, kí ó sì ran jáde kúrò nínú ilé rẹ̀,
\v 2 tí ó bá di ìyàwó ọkùnrin mìíràn lẹ́yìn ìgbà tí ó kúrò nílé rẹ,
\v 3 àti tí ọkọ rẹ̀ kejì kò bá fẹ́ràn rẹ̀ tí ó sì kọ ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ sí i, kí ó fi fún un kí ó sì lé e kúrò nílé e rẹ̀, tàbí tí ọkọ rẹ̀ kejì bá kú,
\v 4 nígbà náà ni ọkọ, tí ó ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kò gbọdọ̀ fẹ́ ẹ mọ́ lẹ́yìn tí ó ti di àìmọ́. Nítorí èyí ni ìríra níwájú \nd Olúwa\nd*. Má ṣe mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sórí ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ bí ogún.
\p
\v 5 Bí ọkùnrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, o kò gbọdọ̀ ran lọ sí ogun tàbí kí ó ní iṣẹ́ kan láti ṣe. Ó ní láti ní òmìnira fún ọdún kan kí ó dúró sílé kí ó sì mú inú dídùn bá ìyàwó rẹ̀ tí ó fẹ́.
\p
\v 6 \x - \xo 24.6,10-13: \xt El 22.26,27.\x*Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gba ìyá ọlọ tàbí ọmọ ọlọ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdúró fún gbèsè, nítorí pé ẹ̀mí ènìyàn ni ó gbà ní pàṣípàrọ̀ n nì.
\p
\v 7 \x - \xo 24.7: \xt Ek 21.16; 1Kọ 5.13.\x*Bí a bá mú ọkùnrin kan tí ó jí ọ̀kan nínú arákùnrin rẹ̀ ní Israẹli gbé àti tí ó jí ọ̀kan nínú ẹrú tàbí kí ó tà á, ẹni tí ó jí ènìyàn gbé ní láti kú. Ẹ ní láti wẹ búburú kúrò láàrín yín.
\p
\v 8 \x - \xo 24.8,9: \xt Le 1314.\x*Ní ti ààrùn ẹ̀tẹ̀ kíyèsára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi ti pàṣẹ fún ọ. O ní láti máa fi ìṣọ́ra tẹ̀lé ohun tí mo ti pàṣẹ fún wọn.
\v 9 Rántí ohun tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ ṣe sí Miriamu lójú ọ̀nà lẹ́yìn ìgbà tí o jáde kúrò ní Ejibiti.
\p
\v 10 Nígbà tí o bá wín arákùnrin rẹ ní ohunkóhun, má ṣe lọ sí ilé rẹ̀ láti gba ohun tí ó bá mú wá bí ẹ̀rí.
\v 11 Dúró síta gbangba kí o sì jẹ́ kí ọkùnrin tí o wín mú ògo rẹ jáde wá fún ọ.
\v 12 Bí ọkùnrin náà bá jẹ́ tálákà má ṣe lọ sùn ti ìwọ ti ògo rẹ.
\v 13 Dá aṣọ ìlekè rẹ padà ní àṣálẹ́ kí ó bá à le sùn lórí i rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, ó sì máa jásí ìwà òdodo níwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ.
\p
\v 14 \x - \xo 24.14,15: \xt Le 19.13; Jk 5.4.\x*Má ṣe ni alágbàṣe kan lára tí ó jẹ́ tálákà àti aláìní, bóyá ó jẹ́ arákùnrin Israẹli tàbí àlejò tí ó ń gbé ní ọ̀kan nínú àwọn ìlú rẹ.
\v 15 San owó iṣẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà kí ó tó di àṣálẹ́, nítorí ó jẹ́ tálákà, ó sì gbẹ́kẹ̀lé e bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ ó lè ké pe \nd Olúwa\nd* sí ọ, o sì máa gba ìdálẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀.
\p
\v 16 Baba kò gbọdọ̀ kú fún àwọn ọmọ wọn tàbí kí àwọn ọmọ kú fún baba wọ́n; olúkúlùkù ní láti kú fún ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkára rẹ̀.
\p
\v 17 \x - \xo 24.17,18: \xt Ek 22.21-24; 23.9; Le 19.33,34.\x*Má ṣe yí ìdájọ́ po fún àlejò tàbí aláìní baba, tàbí gba aṣọ ìlekè opó bí ẹ̀rí.
\v 18 Rántí pé o jẹ́ ẹrú ní Ejibiti tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ sì gbà ọ́ níbẹ̀. Ìdí nìyí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ṣe èyí.
\p
\v 19 \x - \xo 24.19-22: \xt Le 19.9,10; 23.22.\x*Nígbà tí o bá ń kórè oko rẹ tí o sì fojú fo ìtí kan, má ṣe padà lọ mú u. Fi í kalẹ̀ fún àwọn àlejò, aláìní baba àti opó, kí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ lè bùkún fún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ.
\v 20 Nígbà tí o bá ń gun igi olifi lára àwọn igi i rẹ, má ṣe padà lọ sí ẹ̀ka náà ní ìgbà kejì. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó.
\v 21 Nígbà tí ìwọ bá kórè èso àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ, má ṣe lọ sí ọgbà náà mọ́. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó.
\v 22 Rántí pé ìwọ ti jẹ́ àlejò ní Ejibiti. Ìdí nìyí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ṣe èyí.
\c 25
\p
\v 1 Nígbà tí àwọn ènìyàn méjì bá ń jà, kí wọn kó ẹjọ́ lọ sí ilé ìdájọ́, kí àwọn onídàájọ́ dá ẹjọ́ náà, kí wọn dá àre fún aláre àti ẹ̀bi fún ẹlẹ́bi.
\v 2 Bí ó bá tọ́ láti na ẹlẹ́bi, kí onídàájọ́ dá a dọ̀bálẹ̀ kí a sì nà án ní ojú u rẹ̀ ní iye pàṣán tí ó tọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀.
\v 3 Ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ fún un ju ogójì pàṣán lọ. Bí ó bá nà án ju bẹ́ẹ̀ lọ, arákùnrin rẹ̀ yóò di ẹni ìrẹ̀sílẹ̀ ní ojú rẹ̀.
\p
\v 4 \x - \xo 25.4: \xt 1Kọ 9.9; 1Tm 5.18.\x*Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu.
\p
\v 5 \x - \xo 25.5,6: \xt Mt 22.24; Mk 12.19; Lk 20.28.\x*Bí àwọn arákùnrin bá ń gbé pọ̀, tí ọ̀kan nínú wọn bá sì kú, tí kò sí ní ọmọkùnrin, kí aya òkú má ṣe ní àlejò ará òde ní ọkọ rẹ̀. Arákùnrin ọkọ rẹ̀ ni kí ó wọlé tọ̀ ọ́, kí ó fi ṣe aya, kí ó sì ṣe iṣẹ́ arákùnrin ọkọ fún un.
\v 6 Ọmọkùnrin tí ó bá kọ́ bí ni yóò máa jẹ́ orúkọ arákùnrin rẹ̀ tí ó kú náà, kí orúkọ rẹ̀ má ba á parẹ́ ní Israẹli.
\p
\v 7 Ṣùgbọ́n bí ọkùnrin náà kò bá fẹ́ fi aya arákùnrin rẹ̀ ṣe aya rẹ̀, obìnrin náà yóò lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbàgbà ní ẹnu-bodè ìlú láti sọ pé, “Arákùnrin ọkọ ọ̀ mi kọ̀ láti gbé orúkọ arákùnrin rẹ̀ ró ní Israẹli. Kò ní ṣe ojúṣe rẹ̀ bí arákùnrin ọkọ mi sí mi.”
\v 8 Nígbà náà ni àwọn àgbàgbà ìlú rẹ̀ yóò pè é, wọn yóò sì bá sọ̀rọ̀. Bí ó bá sì kọ̀ jálẹ̀ tí ó bá sọ pé, “Èmi kò fẹ́ láti fẹ́ ẹ,”
\v 9 opó arákùnrin rẹ̀ yìí yóò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ojú àwọn àgbàgbà ìlú rẹ̀, yóò yọ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ kan, yóò sì tu itọ́ sí ọkùnrin náà lójú, yóò sì wí pé, “Èyí ni ohun tí a ṣe sí ọkùnrin tí kò jẹ́ kí ìdílé arákùnrin rẹ̀ wà títí ayé.”
\v 10 A ó sì mọ ìdílé arákùnrin yìí ní Israẹli gẹ́gẹ́ bí “Ìdílé tí a yọ bàtà rẹ̀.”
\p
\v 11 Bí ọkùnrin méjì bá ń jà, tí ìyàwó ọ̀kan nínú wọn bá sì wá láti gbèjà ọkọ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin tí ń lù ú, tí ó sì nawọ́ di nǹkan ọkùnrin abẹ́ ẹ rẹ̀ mú.
\v 12 Ìwọ yóò gé ọwọ́ rẹ̀ náà kúrò. Má ṣe ṣàánú fún un.
\p
\v 13 \x - \xo 25.13-16: \xt Le 19.35,36.\x*Má ṣe ní oríṣìí ìtẹ̀wọ̀n méjì tó yàtọ̀ sí ara wọn nínú àpò rẹ, ọ̀kan wúwo àti ọ̀kan fífúyẹ́.
\v 14 Má ṣe ní oríṣìí ìwọ̀n méjì tí ó yàtọ̀ sí ara wọn ní ilé è rẹ: ọ̀kan fífẹ̀, ọ̀kan kékeré.
\v 15 O gbọdọ̀ ní ìtẹ̀wọ̀n àti òsùwọ̀n pípé àti ti òtítọ́ nítorí náà kí ìwọ kí ó lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ fún ọ.
\v 16 Nítorí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nǹkan wọ̀nyí, àní ẹnikẹ́ni tí ń ṣe àìṣòdodo.
\p
\v 17 \x - \xo 25.17-19: \xt Ek 17.14; 1Sa 15.\x*Rántí ohun tí àwọn ará Amaleki ṣe sí i yín ní ọ̀nà nígbà tí ẹ̀ ń jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá.
\v 18 Nígbà tí àárẹ̀ mú un yín tí agara sì dá a yín, wọ́n pàdé e yín ní ọ̀nà àjò o yín, wọ́n gé àwọn tí ó rẹ̀yìn kúrò, wọn kò ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
\v 19 Nígbà tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín bá fún un yín ní ìsinmi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá yín tí ó yí i yín ká ní ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run ń fi fún yín láti ni ní ìní, ẹ̀yin yóò sì pa ìrántí Amaleki rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run. Má ṣe gbàgbé.
\c 26
\s1 Àkọ́so àti ìdámẹ́wàá
\p
\v 1 \x - \xo 26.1-11: \xt El 22.29; 23.19; 34.26; Nu 18.12,13.\x*Nígbà tí ìwọ bá wọ ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní tí ìwọ sì ti jogún, tí ìwọ sì ti ń gbé níbẹ̀,
\v 2 mú díẹ̀ nínú ohun tí o pèsè láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀ náà tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ, kó wọn sínú agbọ̀n. Nígbà náà kí o lọ sí ibi tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibi tí orúkọ rẹ̀ yóò máa gbé.
\v 3 Kí o sì sọ fun àlùfáà tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní àsìkò náà, pé, “Mo sọ ọ́ di mí mọ̀ fún \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ pé mo ti wá sí ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* búra fún àwọn baba wa.”
\v 4 Àlùfáà yóò gbé agbọ̀n náà kúrò ní ọwọ́ rẹ, yóò sì gbé e kalẹ̀ níwájú pẹpẹ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ.
\v 5 Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní iwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ pé, “Baba mi jẹ́ alárìnkiri ará Aramu, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Ejibiti pẹ̀lú ènìyàn díẹ̀, ó sì ń gbé níbẹ̀, ó sì wá di orílẹ̀-èdè olókìkí, alágbára, tí ó kún fún ọ̀pọ̀ ènìyàn.
\v 6 Ṣùgbọ́n àwọn ará Ejibiti ṣe àìdára sí wa, wọ́n jẹ wá ní yà, wọ́n fún wa ní iṣẹ́ líle ṣe.
\v 7 Nígbà náà ni a kégbe pe \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run àwọn baba wa, \nd Olúwa\nd* sì gbọ́ ohùn wa, ó sì rí ìrora, làálàá àti ìnira wa.
\v 8 Nígbà náà ni \nd Olúwa\nd* mú wa jáde wá láti Ejibiti pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà, pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá àti iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu.
\v 9 Ó mú wa wá síbí, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin;
\v 10 àti pé ní báyìí, mo mú àkọ́so ilẹ̀ tí ìwọ \nd Olúwa\nd* ti fún mi wá.” Ìwọ yóò gbé agbọ̀n náà síwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ, kí o sì wólẹ̀ níwájú u rẹ̀.
\v 11 Ìwọ àti àwọn ọmọ Lefi àti àjèjì láàrín yín yóò máa yọ̀ nínú gbogbo oore tí \nd Olúwa\nd* ti fi fún ọ àti fún àwọn ará ilé rẹ.
\p
\v 12 Nígbà tí ìwọ bá ṣetán láti ya ìdámẹ́wàá gbogbo ohun tí o ti mú jáde ní ọdún kẹta sọ́tọ̀ sí apá kan. Ọdún ìdámẹ́wàá, ìwọ yóò fi fún ọmọ Lefi, àjèjì, aláìní baba àti opó, kí wọn kí ó lè jẹ ní àwọn ìlú rẹ, kí wọn sì yó.
\v 13 Nígbà náà ní kí o wí fún \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ pé, “Èmi ti mú ohun mímọ́ kúrò nínú ilé mi, èmi sì ti fi fún àwọn Lefi, àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba àti àwọn opó, gẹ́gẹ́ bí ohun gbogbo tí ìwọ ti pàṣẹ. Èmi kò yípadà kúrò nínú àṣẹ rẹ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gbàgbé ọ̀kankan nínú wọn.
\v 14 Èmi kò jẹ lára ohun mímọ́ ní ìgbà tí mo ń ṣọ̀fọ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mu nínú wọn ní ìgbà tí mo wà ní àìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi nínú wọn fún òkú. Èmi ti ṣe ìgbọ́ràn sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run mi, èmi sì ti ṣe gbogbo ohun tí ó pàṣẹ fún mi.
\v 15 Wo ilẹ̀ láti ọ̀run wá, ibùgbé mímọ́ rẹ, kí o sì bùkún fún àwọn ènìyàn Israẹli, àti fún ilẹ̀ náà tí ìwọ ti fi fún wa, bí ìwọ ti búra fún àwọn baba ńlá wa, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti fún oyin.”
\s1 Tẹ̀lé àṣẹ \nd Olúwa\nd*
\p
\v 16 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ pàṣẹ fún ọ ní òní láti máa tẹ̀lé àwọn ìlànà àti òfin, kí o sì máa ṣe wọ́n pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo àyà rẹ.
\v 17 Ìwọ jẹ́wọ́ \nd Olúwa\nd* ní òní pé \nd Olúwa\nd* ni Ọlọ́run rẹ, àti pé ìwọ yóò máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, àti pé ìwọ yóò máa pa ìlànà rẹ̀, àṣẹ rẹ̀ àti òfin rẹ̀ mọ́, àti pé ìwọ yóò máa ṣe ìgbọ́ràn sí i.
\v 18 Ní òní ni \nd Olúwa\nd* jẹ́wọ́ rẹ pé ìwọ ni ènìyàn òun, ilé ìṣúra rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí, àti pé ìwọ yóò máa pa gbogbo àṣẹ rẹ̀ mọ́.
\v 19 Òun sì jẹ́wọ́ pé, òun yóò gbé ọ sókè ju gbogbo orílẹ̀-èdè tí òun ti dá lọ, ní ìyìn, ní òkìkí àti ní ọlá; kí ìwọ kí ó le jẹ́ ènìyàn mímọ́ sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí.
\c 27
\s1 Pẹpẹ ní orí òkè Ebali
\p
\v 1 Mose àti àwọn àgbàgbà Israẹli pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Pa gbogbo àṣẹ tí mo fún ọ lónìí mọ́.
\v 2 Nígbà tí o bá ti kọjá a Jordani sí inú ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, gbé kalẹ̀ lára àwọn òkúta ńlá àti aṣọ ìlekè rẹ pẹ̀lú ẹfun.
\v 3 Kí ìwọ kí ó kọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí sára wọn nígbà tí ìwọ bá ti ń rékọjá láti wọ ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, gẹ́gẹ́ bí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run àwọn baba yín ti ṣèlérí fún ọ.
\v 4 Àti nígbà tí o bá ti kọjá a Jordani, kí o gbé òkúta yìí kalẹ̀ sórí i Ebali, bí mo ti pa à láṣẹ fún ọ lónìí, kí o sì wọ̀ wọ́n pẹ̀lú ẹfun.
\v 5 Kọ́ pẹpẹ síbẹ̀ fún \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ, pẹpẹ òkúta. Má ṣe lo ohun èlò irin lórí wọn.
\v 6 Kí ìwọ kí ó mọ pẹpẹ pẹ̀lú òkúta àìgbẹ́ fún \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ, kí ìwọ kí ó sì máa rú ẹbọ sísun ni orí rẹ̀ fún \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ.
\v 7 Rú ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀ kí o jẹ wọ́n, kí o sì yọ̀ níwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ.
\v 8 Kí o sì kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí ketekete sórí òkúta tí ó ti gbé kalẹ̀.”
\s1 Ègún ní orí òkè Ebali
\p
\v 9 Nígbà náà ni Mose àti àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi, sọ fún Israẹli pé, “Ẹ dákẹ́ ẹ̀yin Israẹli, kí ẹ sì fetísílẹ̀! O ti wá di ènìyàn \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ báyìí.
\v 10 Gbọ́rọ̀ sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ kí o sì tẹ̀lé àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mo ń fi fún ọ lónìí.”
\p
\v 11 Ní ọjọ́ kan náà Mose pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé.
\p
\v 12 Nígbà tí ìwọ bá ti kọjá a Jordani, àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Gerisimu láti súre fún àwọn ènìyàn: Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Josẹfu àti Benjamini.
\v 13 Àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Ebali láti gé ègún: Reubeni, Gadi, àti Aṣeri, àti Sebuluni, Dani, àti Naftali.
\p
\v 14 Àwọn ẹ̀yà Lefi yóò ké sí gbogbo ènìyàn Israẹli ní ohùn òkè:
\b
\p
\v 15 \x - \xo 27.15: \xt Ek 20.4,23; 34.17; Le 19.4; 26.1; De 4.16,23,25; 5.8; 7.25.\x*“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó fín ère tàbí gbẹ́ òrìṣà ohun tí ó jẹ́ ìríra níwájú \nd Olúwa\nd*, iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nà tí ó gbé kalẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.”
\pr Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
\p
\v 16 \x - \xo 27.16: \xt Ek 20.12; 21.15,17; Le 20.9; De 5.16; 21.18-21.\x*“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dójútì baba tàbí ìyá rẹ̀.”
\pr Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
\p
\v 17 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí òkúta ààlà aládùúgbò o rẹ̀.”
\pr Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
\p
\v 18 \x - \xo 27.18: \xt Le 19.14.\x*“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣi afọ́jú lọ́nà ní ojú ọ̀nà.”
\pr Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
\p
\v 19 \x - \xo 27.19: \xt Ek 22.21-24; 23.9; Le 19.33,34; De 24.17,18.\x*“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí ìdájọ́ po fún àlejò, aláìní baba tàbí opó.”
\pr Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
\p
\v 20 \x - \xo 27.20: \xt Le 18.8; 20.11; De 22.30.\x*“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó baba rẹ̀, nítorí ó ti dójúti ibùsùn baba rẹ̀.”
\pr Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
\p
\v 21 \x - \xo 27.21: \xt Ek 22.19; Le 18.23; 20.15.\x*“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹranko.”
\pr Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
\p
\v 22 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú arábìnrin rẹ̀, ọmọbìnrin baba rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀.”
\pr Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
\p
\v 23 \x - \xo 27.23: \xt Le 18.17; 20.14.\x*“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyá ìyàwó o rẹ̀.”
\pr Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
\p
\v 24 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó pa aládùúgbò rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.”
\pr Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
\p
\v 25 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa ènìyàn láìjẹ̀bi.”
\pr Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
\p
\v 26 \x - \xo 27.26: \xt Ga 3.10.\x*“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí kò gbé ọ̀rọ̀ òfin yìí ró nípa ṣíṣe wọ́n.”
\pr Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
\c 28
\s1 Ìbùkún fún ìgbọ́ràn
\p
\v 1 \x - \xo 28.1-14: \xt Le 26.3-45.\x*Bí ìwọ bá gbọ́rọ̀ sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ ní kíkún kí o sì kíyèsára láti tẹ̀lé gbogbo ohun tí ó pàṣẹ tí mo fi fún ọ lónìí, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ yóò gbé ọ lékè ju gbogbo orílẹ̀-èdè ayé lọ.
\v 2 Gbogbo ìbùkún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ bí o bá gbọ́rọ̀ sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ.
\pm
\v 3 Ìbùkún ni fún ọ ni ìlú, ìbùkún ni fún ọ ní oko.
\pm
\v 4 Ìbùkún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, àti irú ohun ọ̀sìn rẹ àti ìbísí i màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.
\pm
\v 5 Ìbùkún ni fún agbọ̀n rẹ àti fún ọpọ́n ipò ìyẹ̀fun rẹ.
\pm
\v 6 Ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá wọlé, ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.
\p
\v 7 \nd Olúwa\nd* yóò gbà fún ọ pé gbogbo ọ̀tá tí ó dìde sí ọ yóò bì ṣubú níwájú rẹ. Wọn yóò tọ̀ ọ́ wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n wọn yóò sá fún ọ ní ọ̀nà méje.
\p
\v 8 \nd Olúwa\nd* yóò rán ìbùkún sí ọ àti sí ohun gbogbo tí o bá dáwọ́ rẹ lé. \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ yóò bùkún un fún ọ nínú ilẹ̀ tí ó ń fi fún ọ.
\p
\v 9 \nd Olúwa\nd* yóò fi ọ́ múlẹ̀ bí ènìyàn mímọ́, bí ó ti ṣe ìlérí fún ọ lórí ìbúra, bí o bá pa àṣẹ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ mọ́ tí o sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
\v 10 Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé yóò rí i pé a pè ọ́ ní orúkọ \nd Olúwa\nd*, wọn yóò sì bẹ̀rù rẹ.
\v 11 \nd Olúwa\nd* yóò fi àlàáfíà fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, fún ọmọ inú rẹ, irú ohun ọ̀sìn rẹ àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá rẹ láti fún ọ.
\p
\v 12 \nd Olúwa\nd* yóò ṣí ọ̀run sílẹ̀, ìṣúra rere rẹ̀ fún ọ, láti rọ òjò sórí ilẹ̀ rẹ ní àsìkò rẹ àti láti bùkún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ. Ìwọ yóò yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ṣùgbọ́n ìwọ kò ní í yá lọ́wọ́ ẹnìkankan.
\v 13 \nd Olúwa\nd* yóò fi ọ́ ṣe orí, ìwọ kì yóò sì jẹ́ ìrù. Bí o bá fi etí sílẹ̀ sí àṣẹ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ tí mo fi fún ọ kí o sì máa rọra tẹ̀lé wọn, ìwọ yóò máa wà lókè, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò wà ní ìsàlẹ̀ láé.
\v 14 Má ṣe yà sọ́tùn tàbí sósì kúrò, nínú èyíkéyìí àwọn àṣẹ tí mo fi fún ọ ní òní yìí, kí o má ṣe tẹ̀lé àwọn ọlọ́run mìíràn láti máa sìn wọ́n.
\s1 Ègún fún àìgbọ́ràn
\p
\v 15 Ṣùgbọ́n bí o kò bá gbọ́ ti \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ kí o sì rọra máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí, gbogbo ègún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ.
\pm
\v 16 Ègún ni fún ọ ní ìlú, ègún ni fún ọ ní oko.
\pm
\v 17 Ègún ni fún agbọ̀n rẹ àti ọpọ́n ìpo-fúláwà rẹ.
\pm
\v 18 Ègún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, ìbísí màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.
\pm
\v 19 Ègún ni fún ọ nígbà tí o bá wọlé ègún sì ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.
\p
\v 20 \nd Olúwa\nd* yóò rán ègún sórí rẹ, rúdurùdu àti ìfibú nínú gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ rẹ lé, títí ìwọ yóò fi parun àti wá sí ìparun lójijì nítorí búburú tí o ti ṣe ní kíkọ̀ mi sílẹ̀.
\v 21 \nd Olúwa\nd* yóò fi àjàkálẹ̀-ààrùn bá ọ jà títí tí yóò fi pa ọ́ run kúrò ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.
\v 22 \nd Olúwa\nd* yóò kọlù ọ́ pẹ̀lú ààrùn ìgbẹ́, pẹ̀lú ibà àti àìsàn wíwú, pẹ̀lú ìjóni ńlá àti idà, pẹ̀lú ìrẹ̀dànù àti ìmúwòdù tí yóò yọ ọ́ lẹ́nu títí ìwọ yóò fi parun.
\v 23 Ojú ọ̀run tí ó wà lórí rẹ yóò jẹ́ idẹ, ilẹ̀ tí ń bẹ níṣàlẹ̀ rẹ yóò sì jẹ́ irin.
\v 24 \nd Olúwa\nd* yóò yí òjò ilẹ̀ rẹ sí eruku àti ẹ̀tù; láti ọ̀run ni yóò ti máa sọ̀kalẹ̀ sí ọ, títí tí ìwọ yóò fi run.
\p
\v 25 \nd Olúwa\nd* yóò fi ọ́ gégùn ún láti ṣubú níwájú àwọn ọ̀tá rẹ. Ìwọ yóò tọ̀ wọ́n wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n ìwọ yóò sá fún wọn ní ọ̀nà méje, ìwọ yóò sì padà di ohun ìbẹ̀rù fún gbogbo ìjọba lórí ayé.
\v 26 Òkú rẹ yóò jẹ́ oúnjẹ fún gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko ayé, àti pé kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóò lé wọn kúrò.
\v 27 \nd Olúwa\nd* yóò bá ọ jà pẹ̀lú oówo, Ejibiti àti pẹ̀lú kókó, ojú egbò kíkẹ̀ àti ìhúnra.
\v 28 \nd Olúwa\nd* yóò bá ọ jà pẹ̀lú ìsínwín, ojú fífọ́ àti rúdurùdu àyà.
\v 29 Ní ọ̀sán gangan ìwọ yóò fi ọwọ́ tálẹ̀ kiri bí ọkùnrin afọ́jú nínú òkùnkùn ìwọ kì yóò ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí o bá ń ṣe, ojoojúmọ́ ni wọn yóò máa ni ọ́ lára àti jà ọ́ ní olè, tí kò sì ní í sí ẹnìkan láti gbà ọ́.
\p
\v 30 Ìwọ yóò gba ògo láti fẹ́ obìnrin kan ṣùgbọ́n ẹlòmíràn yóò gbà á yóò sì tẹ́ ẹ́ ní ògo. Ìwọ yóò kọ́ ilé, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò gbé ibẹ̀. Ìwọ yóò gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n ìwọ kò tilẹ̀ ní gbádùn èso rẹ.
\v 31 Màlúù rẹ yóò di pípa níwájú rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò jẹ nǹkan kan nínú rẹ̀. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ yóò sì di mímú pẹ̀lú agbára kúrò lọ́dọ̀ rẹ, a kì yóò sì da padà. Àgùntàn rẹ yóò di mímú fún àwọn ọ̀tá rẹ, ẹnìkankan kò sì ní gbà á.
\v 32 Àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ yóò di mímú fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ìwọ yóò sì fi ojú rẹ ṣọ́nà dúró dè wọ́n láti ọjọ́ dé ọjọ́, ìwọ yóò sì jẹ́ aláìlágbára láti gbé ọwọ́.
\v 33 Èso ilẹ̀ rẹ àti gbogbo iṣẹ́ làálàá rẹ ni orílẹ̀-èdè mìíràn tí ìwọ kò mọ̀ yóò sì jẹ, ìwọ yóò jẹ́ kìkì ẹni ìnilára àti ẹni ìtẹ̀mọ́lẹ̀.
\v 34 Ìran tí ojú rẹ yóò rí, yóò sọ ọ́ di òmùgọ̀.
\v 35 \nd Olúwa\nd* yóò lu eékún àti ẹsẹ̀ rẹ pẹ̀lú oówo dídùn tí kò le san tán láti àtẹ̀lé méjèèjì rẹ lọ sí òkè orí rẹ.
\p
\v 36 \nd Olúwa\nd* yóò lé ọ àti ọba tí ó yàn lórí rẹ lọ sí orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀ tàbí ti àwọn baba rẹ kò mọ̀. Ibẹ̀ ni ìwọ̀ yóò sì sin ọlọ́run mìíràn, ọlọ́run igi àti òkúta.
\v 37 Ìwọ yóò di ẹni ìyanu, àti ẹni òwe, àti ẹni ìfisọ̀rọ̀ sọ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè tí \nd Olúwa\nd* yóò darí rẹ sí.
\p
\v 38 Ìwọ yóò gbin irúgbìn púpọ̀ ṣùgbọ́n ìwọ yóò kórè kékeré, nítorí eṣú yóò jẹ ẹ́ run.
\v 39 Ìwọ yóò gbin ọgbà àjàrà púpọ̀ ìwọ yóò sì ro wọ́n ṣùgbọ́n kò ní mú wáìnì náà tàbí kó àwọn èso jọ, nítorí kòkòrò yóò jẹ wọ́n run.
\v 40 Ìwọ yóò ní igi olifi jákèjádò ilẹ̀ rẹ ṣùgbọ́n ìwọ kò ní lo òróró náà, nítorí olifi náà yóò rẹ̀ dànù.
\v 41 Ìwọ yóò ní àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ṣùgbọ́n ìwọ kò nípa wọ́n mọ́, nítorí wọn yóò lọ sí ìgbèkùn.
\v 42 Ọ̀wọ́ eṣú yóò gba gbogbo àwọn igi rẹ àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ.
\p
\v 43 Àjèjì tí ń gbé láàrín rẹ yóò gbé sókè gíga jù ọ́ lọ, ṣùgbọ́n ìwọ yóò máa di ìrẹ̀sílẹ̀.
\v 44 Yóò yà ọ́, ṣùgbọ́n o kì yóò yà á, òun ni yóò jẹ́ orí, ìwọ yóò jẹ́ ìrù.
\p
\v 45 Gbogbo ègún yìí yóò wá sórí rẹ, wọn yóò lé ọ wọn yóò sì bá ọ títí tí ìwọ yóò fi parun, nítorí ìwọ kò gbọ́rọ̀ sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ, ìwọ kò sì kíyèsi àṣẹ àti òfin tí ó fi fún ọ.
\v 46 Wọn yóò jẹ́ àmì àti ìyanu fún ọ àti fún irú-ọmọ rẹ títí láé.
\v 47 Nítorí ìwọ kò sin \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ ní ayọ̀ àti inú dídùn ní àkókò àlàáfíà.
\v 48 Nítorí náà nínú ebi àti òǹgbẹ, nínú ìhòhò àti àìní búburú, ìwọ yóò sin àwọn ọ̀tá à rẹ tí \nd Olúwa\nd* rán sí ọ. Yóò sì fi àjàgà irin bọ̀ ọ́ ní ọrùn, títí yóò fi run ọ́.
\p
\v 49 \x - \xo 28.49: \xt 1Kọ 14.21.\x*\nd Olúwa\nd* yóò mú àwọn orílẹ̀-èdè wá sí ọ láti ọ̀nà jíjìn, bí òpin ayé, bí idì ti ń bẹ́ láti orí òkè sílẹ̀, orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò gbọ́ èdè wọn.
\v 50 Orílẹ̀-èdè tí ó rorò tí kò ní ojúrere fún àgbà tàbí àánú fún ọmọdé.
\v 51 Wọn yóò jẹ ohun ọ̀sìn rẹ run àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ títí tí ìwọ yóò fi parun. Wọn kì yóò fi hóró irúgbìn kan fún ọ, wáìnì tuntun tàbí òróró, tàbí agbo ẹran màlúù rẹ kankan tàbí ọ̀wọ́ ẹran àgùntàn rẹ títí ìwọ yóò fi run.
\v 52 Wọn yóò gbógun ti gbogbo ìlú rẹ títí tí odi ìdáàbòbò gíga yẹn tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé yóò fi wó lulẹ̀. Wọn yóò gbógun ti gbogbo ìlú rẹ jákèjádò ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ ń fún ọ.
\p
\v 53 Ìwọ ó sì jẹ èso ọmọ inú rẹ̀, ẹran-ara àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ti àwọn ọmọ rẹ obìnrin tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run ti fi fún ọ; nínú ìdótì náà àti nínú ìhámọ́ náà tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò há ọ mọ́.
\v 54 Ọkùnrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù nínú yín, tí ó sì ṣe ẹlẹgẹ́, ojú rẹ̀ yóò korò sí arákùnrin rẹ̀ àti sí aya oókan àyà rẹ̀, àti sí ìyókù ọmọ rẹ̀ tí òun jẹ kù.
\v 55 Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fún ẹnikẹ́ni nínú ẹran-ara àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó ń jẹ, nítorí kò sí ohun kan tí ó kù sílẹ̀ fún un nínú ìdótì náà àti ìhámọ́, tí àwọn ọ̀tá yóò fi há ọ mọ́ ní ibodè rẹ gbogbo.
\v 56 Obìnrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù nínú yín, tí ó sì ṣe ẹlẹgẹ́, tí kò jẹ́ dáṣà láti fi àtẹ́lẹsẹ̀ ẹ rẹ̀ kan ilẹ̀ nítorí ìkẹ́ra àti ìwà ẹlẹgẹ́, ojú u rẹ̀ yóò korò sí ọkọ oókan àyà rẹ̀, àti sí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ rẹ̀ obìnrin,
\v 57 àti sí ọmọ rẹ̀ tí ó ti agbede-méjì ẹsẹ̀ rẹ̀ jáde, àti sí àwọn ọmọ rẹ̀ tí yóò bí. Nítorí òun ó jẹ wọ́n ní ìkọ̀kọ̀, nítorí àìní ohunkóhun nínú ìdótì àti ìhámọ́ náà, tí àwọn ọ̀tá yóò fi há ọ mọ́ ní ibodè rẹ.
\p
\v 58 Bí ìwọ kò bá rọra tẹ̀lé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí, tí a kọ sínú ìwé yìí, tí ìwọ kò sì bu ọlá fún ògo yìí àti orúkọ dáradára: orúkọ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ,
\v 59 \nd Olúwa\nd* yóò sọ ìyọnu rẹ di ìyanu, àti ìyọnu irú-ọmọ ọ̀ rẹ, àní àwọn ìyọnu ńlá èyí tí yóò pẹ́, àti ààrùn búburú èyí tí yóò pẹ́.
\v 60 \nd Olúwa\nd* yóò mú gbogbo ààrùn Ejibiti tí ó mú ẹ̀rù bà ọ́ wá padà bá ọ, wọn yóò sì lẹ̀ mọ́ ọ.
\v 61 \nd Olúwa\nd* yóò tún mú onírúurú àìsàn àti ìpọ́njú tí a kò kọ sínú ìwé òfin yìí wá sórí rẹ, títí ìwọ yóò fi run.
\v 62 Ìwọ tí ó dàbí àìmoye bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò ṣẹ́ku kékeré níye, nítorí tí o kò ṣe ìgbọ́ràn sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ.
\v 63 Gẹ́gẹ́ bí ó ti dùn mọ́ \nd Olúwa\nd* nínú láti mú ọ ṣe rere àti láti pọ̀ si ní iye, bẹ́ẹ̀ ni yóò dùn mọ́ ọ nínú láti bì ọ́ ṣubú kí ó sì pa ọ́ run. Ìwọ yóò di fífà tu kúrò lórí ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.
\p
\v 64 Nígbà náà ni \nd Olúwa\nd* yóò fọ́n ọ ká láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè, láti òpin kan ní ayé sí òmíràn. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò ti sin ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run igi àti ti òkúta. Èyí tí ìwọ àti àwọn baba rẹ kò mọ̀.
\v 65 Ìwọ kì yóò sinmi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè náà, kò sí ibi ìsinmi fún àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ. Níbẹ̀ ni \nd Olúwa\nd* yóò ti fún ọ ní ọkàn ìnàngà, àárẹ̀ ojú, àti àìnírètí àyà.
\v 66 Ìwọ yóò gbé ní ìdádúró ṣinṣin, kún fún ìbẹ̀rùbojo lọ́sàn án àti lóru, bẹ́ẹ̀ kọ́ láé ni ìwọ yóò rí i ní àrídájú wíwà láyé rẹ.
\v 67 Ìwọ yóò wí ní òwúrọ̀ pé, “Bí ó tilẹ̀ lè jẹ́ pé ìrọ̀lẹ́ nìkan ni!” Nítorí ẹ̀rù tí yóò gba ọkàn rẹ àti ìran tí ojú rẹ yóò máa rí.
\v 68 \nd Olúwa\nd* yóò rán ọ padà nínú ọkọ̀ sí Ejibiti sí ìrìnàjò tí mo ní ìwọ kì yóò lọ mọ́. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò tún fi ara rẹ fún àwọn ọ̀tá à rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò rà ọ́.
\c 29
\s1 Ìsọdi tuntun májẹ̀mú
\p
\v 1 Èyí ni àwọn ìpinnu májẹ̀mú tí \nd Olúwa\nd* pàṣẹ fún Mose láti ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli ní Moabu, ní àfikún májẹ̀mú tí ó ti ṣe pẹ̀lú u wọn ní Horebu.
\p
\v 2 Mose pàṣẹ fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ó sì wí fún wọn wí pé,
\b
\p ojú rẹ ti rí gbogbo ohun tí \nd Olúwa\nd* ti ṣe ní Ejibiti sí Farao àti, sí gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀ àti sí ilẹ̀ ẹ rẹ̀.
\v 3 Pẹ̀lú ojú ara rẹ ni ìwọ rí àwọn ìdánwò ńlá náà, àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá.
\v 4 \x - \xo 29.4: \xt Ro 11.8.\x*Ṣùgbọ́n títí di àsìkò yìí \nd Olúwa\nd* kò fi ọkàn ìmòye tàbí ojú tí ó ń rí tàbí etí tí ó n gbọ́ fún ọ.
\v 5 Nígbà ogójì ọdún tí mò ń tọ́ yín ṣọ́nà ní aginjù, aṣọ ọ̀ rẹ kò gbó tàbí bàtà ẹsẹ̀ rẹ.
\v 6 O kò jẹ oúnjẹ tàbí mu wáìnì kankan tàbí rú ohun mímu mìíràn. Mo ṣe èyí kí o lè mọ̀ pé Èmi ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ.
\p
\v 7 Nígbà tí o dé ibí yìí, Sihoni ọba Heṣboni àti Ogu ọba Baṣani jáde wá láti bá ọ jà, ṣùgbọ́n a ṣẹ́gun wọn.
\v 8 A gba ilẹ̀ wọn a sì fi fún àwọn ọmọ Reubeni, àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase bí ogún.
\p
\v 9 Nítorí náà, ẹ pa májẹ̀mú yìí mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n, kí ẹ̀yin kí ó lè máa rí ire nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe.
\v 10 Gbogbo yín ń dúró lónìí yìí níwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ: àwọn olórí yín, àwọn ẹ̀yà yín, àwọn àgbàgbà yín àti àwọn ìjòyè yín, àní gbogbo àwọn ọkùnrin mìíràn ní Israẹli,
\v 11 pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ọ̀ rẹ àti ìyàwó ò rẹ àti àwọn àjèjì tí wọ́n ń gbé ní àgọ́ ọ̀ rẹ, tí ó ké pópòpó igi rẹ, tí ó sì gbé omi rẹ.
\v 12 O dúró níhìn-ín yìí kí o lè wọ inú májẹ̀mú pẹ̀lú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ, májẹ̀mú tí \nd Olúwa\nd* ń ṣe pẹ̀lú rẹ lónìí yìí àti tí òun dè pẹ̀lú ìbúra,
\v 13 láti jẹ́wọ́ rẹ lónìí yìí bí ènìyàn an rẹ̀, pé kí ó lè jẹ́ Ọlọ́run rẹ bí ó ti ṣèlérí àti bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba à rẹ Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu.
\v 14 Èmi ń ṣe májẹ̀mú yìí, pẹ̀lú ìbúra rẹ̀, kì í ṣe fún ìwọ nìkan
\v 15 tí ó dúró níbí pẹ̀lú wa lónìí níwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa ṣùgbọ́n àti fún gbogbo àwọn tí kò sí níbí lónìí.
\p
\v 16 Ìwọ fúnra à rẹ mọ bí a ṣe gbé ní Ejibiti àti bí a ṣe kọjá láàrín àwọn orílẹ̀-èdè nílẹ̀ ibí yìí.
\v 17 Ìwọ rí láàrín wọn ìríra wọn, àwọn ère àti àwọn òrìṣà igi àti ti òkúta, ti fàdákà àti ti wúrà.
\v 18 \x - \xo 29.18: \xt Ap 8.23; Hb 12.15.\x*Rí i dájú pé kò sí ọkùnrin tàbí obìnrin, ìdílé tàbí ẹ̀yà láàrín yín lónìí tí ọkàn an rẹ̀ yóò yí kúrò lọ́dọ̀ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa láti lọ àti láti sin àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè náà; rí i dájú pé kò sí gbòǹgbò tí ó ń mú irú èso kíkan bẹ́ẹ̀ jáde láàrín yín.
\p
\v 19 Nígbà tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá gbọ́ ìbúra yìí, kí ó gbàdúrà ìbùkún sórí ara rẹ̀ nígbà náà ni kí ó ronú, “Èmi yóò wà ní àlàáfíà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fi àáké kọ́rí nípa lílọ nínú ọ̀nà ti ara à mi.” Èyí yóò mú àjálù wá sórí ilẹ̀ tútù àti sórí ilẹ̀ gbígbẹ bákan náà
\v 20 \nd Olúwa\nd* kì yóò ní ìfẹ́ sí àti dáríjì í; ìbínú àti ìtara rẹ̀ yóò jó ọkùnrin náà. Gbogbo àwọn ègún tí a kọ sínú ìwé yìí yóò wá sórí i rẹ̀, \nd Olúwa\nd* yóò sì yọ orúkọ rẹ̀ kúrò lábẹ́ ọ̀run.
\v 21 \nd Olúwa\nd* yóò sì yọ òun nìkan kúrò nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli fún àjálù, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ègún májẹ̀mú tí a kọ sí inú ìwé òfin yìí.
\p
\v 22 Àwọn ọmọ rẹ tí ó tẹ̀lé ìran rẹ lẹ́yìn àti àwọn àjèjì tí ó wá láti ilẹ̀ jíjìn yóò rí wàhálà tí ó wá sórí ilẹ̀ àti àwọn ààrùn pẹ̀lú tí \nd Olúwa\nd* mú bá ọ.
\v 23 Gbogbo ilẹ̀ náà yóò di imí-oòrùn, àti iyọ̀, àti ìjóná tí a kò lè fi ọkàn sí, tàbí tí kò lè so èso tàbí tí koríko kò lè hù nínú u rẹ̀, yóò dàbí ìbìṣubú Sodomu àti Gomorra, Adma àti Seboimu, tí \nd Olúwa\nd* bì ṣubú nínú ìbínú rẹ̀, àti ìkáàánú rẹ̀.
\v 24 Gbogbo orílẹ̀-èdè yóò béèrè pé, “Kí ló dé tí \nd Olúwa\nd* fi ṣe èyí sí ilẹ̀ yìí? Kí ni a lè mọ ooru ìbínú ńlá yìí sí?”
\p
\v 25 Ìdáhùn yóò sì jẹ́ báyìí: “Nítorí tí ènìyàn yìí kọ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run baba wọn sílẹ̀, májẹ̀mú tí ó ti bá wọn dá nígbà tí ó mú wọn jáde wá láti Ejibiti.
\v 26 Wọ́n lọ wọ́n sì sin ọlọ́run mìíràn, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún wọn, ọlọ́run tí wọn kò mọ̀, ọlọ́run tí kò fi fún wọn.
\v 27 Nígbà náà ni ìbínú \nd Olúwa\nd* ru sí ilẹ̀ wọn, dé bi pé ó mú gbogbo ègún tí a kọ sínú ìwé yìí wá sórí i rẹ̀.
\v 28 Ní ìbínú àti ní ìkáàánú, àti ní ìrunú ńlá, \nd Olúwa\nd* sì fà wọ́n tu kúrò ní ilẹ̀ wọn, ó sì lé wọn lọ sí ilẹ̀ mìíràn, bí ó ti rí ní òní yìí.”
\p
\v 29 Ohun ìkọ̀kọ̀ jẹ́ ti \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa, ṣùgbọ́n ohun tí a fihàn jẹ́ ti wa àti ti àwọn ọmọ wa títí láé, kí a lè tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí.
\c 30
\s1 Àlàáfíà lẹ́yìn ìyípadà sí Ọlọ́run
\p
\v 1 Nígbà tí gbogbo ìbùkún àti ègún wọ̀nyí tí mo ti gbé kalẹ̀ síwájú u yín bá wá sórí i yín àti tí o bá mú wọn sí àyà rẹ níbikíbi tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ bá tú ọ ká sí láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
\v 2 àti nígbà tí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ bá yípadà sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ tí o sì gbọ́rọ̀ sí pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún un yín lónìí.
\v 3 Nígbà náà ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ yóò mú ohun ìní rẹ bọ̀ sípò yóò sì ṣàánú fún ọ, yóò sì tún ṣà yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè níbi tí ó ti fọ́n yín ká sí.
\v 4 \x - \xo 30.4: \xt Mt 24.31; Mk 13.27.\x*Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé ẹni rẹ kan sí ilẹ̀ tí ó jìnnà jù lábẹ́ ọ̀run, láti ibẹ̀ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ yóò ṣà yín jọ yóò sì tún mú u yín padà.
\v 5 Yóò mú ọ wá sí ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn baba yín, ìwọ yóò sì mú ìní níbẹ̀. \nd Olúwa\nd* yóò mú ọ wà ní àlàáfíà kíkún, yóò mú ọ pọ̀ sí i ju àwọn baba yín lọ.
\v 6 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ yóò kọ ọkàn rẹ ní ilà àti ọkàn àwọn ọmọ yín, nítorí kí o lè fẹ́ ẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, àti ayé rẹ.
\v 7 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ yóò mú gbogbo ègún yín wá sórí àwọn ọ̀tá à rẹ tí wọ́n kórìíra àti tí wọ́n ṣe inúnibíni rẹ.
\v 8 Ìwọ yóò tún gbọ́rọ̀ sí \nd Olúwa\nd* àti tẹ̀lé gbogbo àṣẹ rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí.
\v 9 Nígbà náà ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ yóò mú ọ ṣe rere nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ, àti nínú gbogbo ọmọ inú rẹ, agbo ẹran ọ̀sìn rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ. \nd Olúwa\nd* yóò tún mú inú dídùn sínú rẹ yóò sì mú ọ ṣe déédé, gẹ́gẹ́ bí ó ti fi inú dídùn sínú àwọn baba rẹ.
\v 10 Bí o bá gbọ́ ti \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ tí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́ àti àṣẹ tí a kọ sínú ìwé òfin yìí kí o sì yípadà sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.
\s1 Ìfifún ìyè tàbí ikú
\p
\v 11 Nítorí àṣẹ yìí tí mo pa fún ọ lónìí, kò ṣòro jù fún ọ, bẹ́ẹ̀ ni kò kọjá agbára rẹ.
\v 12 \x - \xo 30.12,13: \xt Ro 10.6,7.\x*Kò sí ní ọ̀run, tí ìwọ kò bá fi wí pé, “Ta ni yóò gòkè lọ sí ọ̀run fún wa, tí yóò sì mú wa fún wa, kí àwa lè gbọ́, kí a sì le ṣe é?”
\v 13 Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní ìhà kejì Òkun, tí ìwọ ìbá fi wí pé, “Ta ni yóò rékọjá òkun lọ fún wa, tí yóò sì mú un wá fún wa, kí àwa lè gbọ́ ọ, kí a si le ṣe é?”
\v 14 \x - \xo 30.14: \xt Ro 10.8.\x*Kì í ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ náà súnmọ́ tòsí rẹ, ó wà ní ẹnu rẹ àti ní ọkàn rẹ kí ìwọ lè máa ṣe é.
\p
\v 15 Wò ó mo gbé kalẹ̀ síwájú u yín lónìí, ìyè àti àlàáfíà, ikú àti ìparun.
\v 16 Ní èyí tí mo pàṣẹ fún ọ ní òní láti máa fẹ́ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ, láti máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀ àti láti máa pa àṣẹ rẹ̀, àti ìlànà rẹ̀, àti ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, kí ìwọ kí ó lè yè, kí ó sì máa bí sí i, kí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run lè bù si fún ọ ní ilẹ̀ náà, ní ibi tí ìwọ ń lọ láti gbà á.
\p
\v 17 Ṣùgbọ́n tí ọkàn an yín bá yí padà tí ìwọ kò sì ṣe ìgbọ́ràn, àti bí o bá fà, lọ láti foríbalẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn àti sìn wọ́n,
\v 18 èmi ń sọ fún un yín lónìí yìí pé ìwọ yóò parun láìsí àní àní. O kò ní í gbé pẹ́ ní ilẹ̀ tí ìwọ ń kọjá Jordani láti gbà àti láti ní.
\p
\v 19 Èmi pe ọ̀run àti ilẹ̀ láti jẹ́rìí tì yín ní òní pé, èmi fi ìyè àti ikú, ìbùkún àti ègún síwájú rẹ: nítorí náà yan ìyè, kí ìwọ kí ó lè yè, ìwọ àti irú-ọmọ rẹ,
\v 20 kí ìwọ kí ó le máa fẹ́ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ, fetísílẹ̀ sí ohùn un rẹ̀, kí o sì dúró ṣinṣin nínú rẹ̀. Nítorí \nd Olúwa\nd* ni ìyè rẹ, yóò sì fún ọ ní ọdún púpọ̀ ní ilẹ̀ tí ó ti búra láti fi fún àwọn baba rẹ Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu.
\c 31
\s1 Joṣua rọ́pò Mose
\p
\v 1 Nígbà náà ni Mose jáde tí ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí gbogbo Israẹli pé,
\v 2 “Mo jẹ́ ọmọ ọgọ́fà ọdún báyìí àti pé èmi kò ni lè darí i yín mọ́. \nd Olúwa\nd* ti sọ fún mi pé, Ìwọ kò ní kọjá Jordani.
\v 3 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ fúnra rẹ̀ ni yóò rékọjá fún ọ. Yóò pa àwọn orílẹ̀-èdè yìí run níwájú rẹ, ìwọ yóò sì mú ìní ilẹ̀ wọn, Joṣua náà yóò rékọjá fún ọ, bí \nd Olúwa\nd* ti sọ.
\v 4 \nd Olúwa\nd* yóò sì ṣe fún wọn ohun tí ó ti ṣe sí Sihoni àti sí Ogu ọba Amori, tí ó parun pẹ̀lú ilẹ̀ ẹ wọn.
\v 5 \nd Olúwa\nd* yóò fi wọ́n fún ọ, kí o sì ṣe sí wọn gbogbo èyí tí mo ti pàṣẹ fún ọ.
\v 6 \x - \xo 31.6,8: \xt Hb 13.5.\x*Jẹ́ alágbára kí o sì ní ìgboyà. Má ṣe bẹ̀rù tàbí jáyà nítorí i wọn, nítorí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ ń lọ pẹ̀lú rẹ, Òun kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”
\p
\v 7 Nígbà náà ni Mose pe Joṣua ó sì wí fún un níwájú gbogbo Israẹli pé, “Jẹ́ alágbára àti onígboyà, nítorí o ní láti lọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí ilẹ̀ tí \nd Olúwa\nd* búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fún wọn, kí o sì pín ilẹ̀ náà láàrín wọn bí ogún wọn.
\v 8 \nd Olúwa\nd* fúnra rẹ̀ ń lọ níwájú rẹ yóò sì wà pẹ̀lú rẹ; kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Má ṣe bẹ̀rù má sì ṣe fòyà.”
\s1 Kíka òfin
\p
\v 9 Nígbà náà ni Mose kọ òfin yìí kalẹ̀ ó sì fi fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi, tí ń gbé àpótí ẹ̀rí \nd Olúwa\nd*, àti fún gbogbo àwọn àgbàgbà ní Israẹli.
\v 10 Nígbà náà ni Mose pàṣẹ fún wọn, “Ní òpin ọdún méje méje, ní àkókò ọdún ìdásílẹ̀, nígbà àjọ àwọn àgọ́.
\v 11 Nígbà tí gbogbo Israẹli bá wá láti fi ara hàn níwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa ní ibi tí yóò yàn, ìwọ yóò ka òfin yìí níwájú wọn sí etí ìgbọ́ wọn.
\v 12 Pe àwọn ènìyàn jọ àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn àjèjì tí ń gbé àwọn ìlú u yín kí wọn lè fetí sí i kí wọn sì lè kọ́ láti bẹ̀rù \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ kí wọn sì rọra tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí.
\v 13 Àwọn ọmọ wọn tí wọn kò mọ òfin yìí, gbọdọ̀ gbọ́ kí wọn sì kọ́ láti bẹ̀rù \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ níwọ̀n ìgbà tí o tí ń gbé ní ilẹ̀ tí ò ń kọjá la Jordani lọ láti ni.”
\s1 Ìsọtẹ́lẹ̀ Israẹli ọlọ̀tẹ̀
\p
\v 14 \nd Olúwa\nd* sọ fún Mose pé, “Ọjọ́ ikú rẹ ti súnmọ́ etílé báyìí. Pe Joṣua kí ẹ sì fi ara yín hàn nínú àgọ́ àjọ, níbi tí èmi yóò ti fi àṣẹ fún un.” Nígbà náà ni Mose àti Joṣua wá, wọ́n sì fi ara wọn hàn níbi àgọ́ àjọ.
\p
\v 15 Nígbà náà ni \nd Olúwa\nd* farahàn níbi àgọ́ ní ọ̀wọ́ àwọsánmọ̀, àwọsánmọ̀ náà sì dúró sókè ẹnu-ọ̀nà àgọ́.
\v 16 \nd Olúwa\nd* sì sọ fún Mose pé, “Ìwọ ń lọ sinmi pẹ̀lú àwọn baba à rẹ, àwọn wọ̀nyí yóò sì ṣe àgbèrè ara wọn sí ọlọ́run àjèjì ilẹ̀ tí wọn ń wọ̀ lọ láìpẹ́. Wọn yóò kọ̀ mí sílẹ̀ wọn yóò sì da májẹ̀mú tí mo bá wọn dá.
\v 17 Ní ọjọ́ náà ni èmi yóò bínú sí wọn èmi yóò sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀; èmi yóò pa ojú mi mọ́ kúrò fún wọn, wọn yóò sì parun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àjálù àti ìṣòro yóò wá sórí wọn, àti ní ọjọ́ náà ni wọn yóò béèrè pé, Ǹjẹ́ ìpọ́njú wọ̀nyí kò wá sórí i wa nítorí Ọlọ́run wa kò sí pẹ̀lú u wa?
\v 18 Èmi yóò sì pa ojú mi mọ́ dájúdájú ní ọjọ́ náà nítorí i gbogbo ìwà búburú wọn ní yíyípadà sí ọlọ́run mìíràn.
\p
\v 19 “Ní báyìí kọ ọ́ kalẹ̀ fúnra à rẹ orin yìí kí o sì kọ ọ́ sí Israẹli kí o sì jẹ́ kí wọn kọ ọ́ kí ó lè jẹ́ ẹ̀rí ì mi sí wọn.
\v 20 Nígbà tí mo ti mú wọn wá sí ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti fún oyin, ilẹ̀ tí mo ti ṣe ìlérí ní ìbúra fún àwọn baba ńlá wọn, àti nígbà tí wọ́n bá jẹ, tí ó sì tẹ́ wọn lọ́rùn, tí wọ́n sì gbilẹ̀, wọn yóò yí padà sí ọlọ́run mìíràn wọn yóò sì sìn wọ́n, wọn yóò kọ̀ mí sílẹ̀, wọn yóò sì da májẹ̀mú mi.
\v 21 Àti nígbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú àti ìṣòro bá wá sórí i wọn, orin yìí yóò jẹ́ ẹ̀rí sí wọn, nítorí kò ní di ìgbàgbé fún àwọn ọmọ wọn. Mo mọ̀ ohun tí wọ́n ní inú dídùn sí láti ṣe, pàápàá kí èmi tó mú wọn wá sí ilẹ̀ tí mo ṣe ìlérí fún wọn lórí ìbúra.”
\v 22 Nígbà náà ni Mose kọ orin yìí kalẹ̀ ní ọjọ́ náà ó sì kọ ọ́ sí Israẹli.
\p
\v 23 \nd Olúwa\nd* sì fún Joṣua ọmọ Nuni ní àṣẹ yìí: “Jẹ́ alágbára àti onígboyà, nítorí ìwọ yóò mú Israẹli wá sí ilẹ̀ tí mo ṣèlérí fún wọn lórí ìbúra, èmi fúnra à mi yóò sì wà pẹ̀lú rẹ.”
\p
\v 24 Lẹ́yìn ìgbà tí Mose ti parí i kíkọ ọ̀rọ̀ òfin yìí sínú ìwé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin,
\v 25 ó sì fi àṣẹ yìí fún àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ń gbé àpótí ẹ̀rí \nd Olúwa\nd*:
\v 26 “Gba ìwé òfin yìí kí o sì fi sí ẹ̀gbẹ́ àpótí ẹ̀rí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ. Níbẹ̀ ni yóò wà bí ẹ̀rí sí ọ.
\v 27 Nítorí mo mọ irú ọlọ̀tẹ̀ àti ọlọ́rùn líle tí ẹ jẹ́. Bí o bá ṣe ọlọ̀tẹ̀ sí \nd Olúwa\nd* nígbà tí mo pàpà wà láyé pẹ̀lú yín, báwo ní ẹ ó ti ṣe ọlọ̀tẹ̀ tó nígbà tí mo bá kú tán!
\v 28 Ẹ péjọpọ̀ síwájú mi gbogbo àgbà ẹ̀yà yín àti àwọn aláṣẹ yín, kí èmi lè sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí etí ìgbọ́ ọ́ wọn.
\v 29 Nítorí tí mo mọ̀ pé lẹ́yìn ikú mi, ó dájú pé ìwọ yóò padà di ìbàjẹ́ pátápátá, ẹ ó sì yípadà kúrò ní ọ̀nà tí mo ti pàṣẹ fún un yín. Ní ọjọ́ tó ń bọ̀, ìpọ́njú yóò sọ̀kalẹ̀ sórí i yín nítorí ẹ̀yin yóò ṣe búburú níwájú \nd Olúwa\nd* ẹ ó sì mú u bínú nípa ohun tí ọwọ́ yín ti ṣe.”
\s1 Orin Mose
\p
\v 30 Mose sì ka ọ̀rọ̀ inú orin yìí láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin sí etí ìgbọ́ ọ gbogbo ìjọ Israẹli:
\c 32
\q1
\v 1 Fetísílẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run, èmi yóò sọ̀rọ̀;
\q2 ẹ gbọ́, ìwọ ayé, ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
\q1
\v 2 Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ ọ̀ mi máa rọ̀ bí òjò,
\q2 kí àwọn ọ̀rọ̀ mi máa sọ̀kalẹ̀ bí ìrì,
\q1 bí òjò wíníwíní sára ewéko tuntun,
\q2 bí ọ̀wààrà òjò sára ohun ọ̀gbìn.
\b
\q1
\v 3 Èmi yóò kókìkí orúkọ \nd Olúwa\nd*.
\q2 Ẹyin títóbi Ọlọ́run wa!
\q1
\v 4 Òun ni àpáta, iṣẹ́ ẹ rẹ̀ jẹ́ pípé,
\q2 gbogbo ọ̀nà an rẹ̀ jẹ́ òdodo.
\q1 Ọlọ́run olóòtítọ́ tí kò ṣe àṣìṣe kan,
\q2 Ó dúró ṣinṣin, òdodo àti òtítọ́ ni òun.
\b
\q1
\v 5 \x - \xo 32.5: \xt Fp 2.15.\x*Wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìbàjẹ́ sọ́dọ̀ ọ rẹ̀;
\q2 fún ìtìjú u wọn, wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀ mọ́,
\q2 ṣùgbọ́n ìran tí ó yí sí apá kan tí ó sì dorí kodò.
\q1
\v 6 Ṣé báyìí ni ẹ̀yin yóò ṣe san an fún \nd Olúwa\nd*,
\q2 ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìgbọ́n ènìyàn?
\q1 Ǹjẹ́ òun kọ́ ni baba yín, Ẹlẹ́dàá yín,
\q2 tí ó dá a yín tí ó sì mọ yín?
\b
\q1
\v 7 Rántí ìgbà láéláé;
\q2 wádìí àwọn ìran tí ó ti kọjá.
\q1 Béèrè lọ́wọ́ baba à rẹ yóò sì sọ fún ọ,
\q2 àwọn àgbàgbà rẹ, wọn yóò sì ṣàlàyé fún ọ.
\q1
\v 8 Nígbà tí Ọ̀gá-ògo fi ogún àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn,
\q2 nígbà tí ó pín onírúurú ènìyàn,
\q1 ó sì gbé ààlà kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn
\q2 gẹ́gẹ́ bí iye ọmọkùnrin Israẹli.
\q1
\v 9 Nítorí ìpín \nd Olúwa\nd* ni àwọn ènìyàn an rẹ̀,
\q2 Jakọbu ni ìpín ìní i rẹ̀.
\b
\q1
\v 10 Ní aginjù ni ó ti rí i,
\q2 ní aginjù níbi tí ẹranko kò sí.
\q1 Ó yíká, ó sì tọ́jú rẹ̀,
\q2 ó pa á mọ́ bí ẹyin ojú u rẹ̀.
\q1
\v 11 Bí idì ti í ru ìtẹ́ rẹ̀ ti ó sì ń
\q2 rábàbà sórí ọmọ rẹ̀,
\q1 tí ó na ìyẹ́ apá rẹ̀ láti gbé wọn ki ó sì
\q2 gbé wọn sórí ìyẹ́ apá rẹ̀.
\q1
\v 12 \nd Olúwa\nd* ṣamọ̀nà;
\q2 kò sì sí ọlọ́run àjèjì pẹ̀lú rẹ̀.
\b
\q1
\v 13 Ó mú gun ibi gíga ayé
\q2 ó sì fi èso oko bọ́ ọ.
\q1 Ó sì jẹ́ kí ó mú oyin láti inú àpáta wá,
\q2 àti òróró láti inú akọ òkúta wá.
\q1
\v 14 Pẹ̀lú u wàràǹkàṣì àti wàrà àgùntàn
\q2 àti ti àgbò ẹran
\q1 àti pẹ̀lú ọ̀rá ọ̀dọ́-àgùntàn àti ewúrẹ́,
\q2 pẹ̀lú àgbò irú u ti Baṣani
\q1 tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ èso àjàrà, àní àti wáìnì.
\b
\q1
\v 15 Jeṣuruni sanra tán ó sì tàpá;
\q2 ìwọ sanra tán, ìwọ ki tan, ọ̀rá sì bò ọ́ tán.
\q1 O kọ Ọlọ́run tí ó dá ọ
\q2 o sì kọ àpáta ìgbàlà rẹ.
\q1
\v 16 Wọ́n sì fi òrìṣà mú un jowú,
\q2 ohun ìríra ni wọ́n fi mú un bínú.
\q1
\v 17 Wọ́n rú ẹbọ sí iwin búburú, tí kì í ṣe Ọlọ́run,
\q2 ọlọ́run tí wọn kò mọ̀ rí,
\q2 ọlọ́run tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ farahàn láìpẹ́,
\q2 ọlọ́run tí àwọn baba yín kò bẹ̀rù.
\q1
\v 18 Ìwọ kò rántí àpáta, tí ó bí ọ;
\q2 o sì gbàgbé Ọlọ́run tí ó dá ọ.
\b
\q1
\v 19 \nd Olúwa\nd* sì rí èyí ó sì kọ̀ wọ́n,
\q2 nítorí tí ó ti bínú nítorí ìwà ìmúnibínú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ.
\q1
\v 20 Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú mi mọ́ kúrò lára wọn,
\q2 èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí;
\q1 nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí,
\q2 àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú wọn.
\q1
\v 21 \x - \xo 32.21: \xt Ro 10.19; 11.11; 1Kọ 10.22.\x*Wọ́n fi mí jowú nípa ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run,
\q2 wọ́n sì fi ohun asán an wọn mú mi bínú.
\q1 Èmi yóò mú wọn kún fún ìlara láti ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ènìyàn;
\q2 èmi yóò sì mú wọn bínú láti ọ̀dọ̀ aṣiwèrè orílẹ̀-èdè.
\q1
\v 22 Nítorí pé iná kan ràn nínú ìbínú mi,
\q2 yóò sì jó dé ipò ikú ní ìsàlẹ̀.
\q1 Yóò sì run ayé àti ìkórè e rẹ̀
\q2 yóò sì tiná bọ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá.
\b
\q1
\v 23 “Èmi yóò kó àwọn ohun búburú lé wọn lórí
\q2 èmi ó sì na ọfà mi tán sí wọn lára.
\q1
\v 24 Èmi yóò mú wọn gbẹ,
\q2 ooru gbígbóná àti ìparun kíkorò ni a ó fi run wọ́n.
\q1 Pẹ̀lú oró ohun tí ń rákò nínú erùpẹ̀.
\q1
\v 25 Idà ní òde, àti ẹ̀rù nínú ìyẹ̀wù,
\q2 ni yóò run ọmọkùnrin àti wúńdíá.
\q1 Ọmọ ẹnu ọmú àti arúgbó eléwú irun pẹ̀lú.
\q1
\v 26 Mo ní èmi yóò tú wọn ká
\q2 èmi yóò sì mú ìrántí i wọn dà kúrò nínú àwọn ènìyàn,
\q1
\v 27 nítorí bí mo ti bẹ̀rù ìbínú ọ̀tá,
\q2 kí àwọn ọ̀tá a wọn kí ó má
\q1 ba à wí pé, Ọwọ́ wa lékè ni;
\q2 kì í sì í ṣe \nd Olúwa\nd* ni ó ṣe gbogbo èyí.’ ”
\b
\q1
\v 28 Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí kò ní ìmọ̀,
\q2 bẹ́ẹ̀ ni kò sí òye nínú wọn.
\q1
\v 29 Bí ó ṣe pé wọ́n gbọ́n, kí òye yìí sì yé wọn
\q2 kí wọn ro bí ìgbẹ̀yìn wọn yóò ti rí!
\q1
\v 30 Báwo ni ẹnìkan ṣe lè lé ẹgbẹ̀rún (1,000),
\q2 tàbí tí ẹni méjì sì lè lé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) sá,
\q1 bí kò ṣe pé àpáta wọn ti tà wọ́n,
\q2 bí kò ṣe pé \nd Olúwa\nd* wọn ti fi wọ́n tọrẹ?
\q1
\v 31 Nítorí pé àpáta wọn kò dàbí àpáta wa,
\q2 àní àwọn ọ̀tá wa tìkára wọn ń ṣe onídàájọ́.
\q1
\v 32 Igi àjàrà a wọn wá láti igi àjàrà Sodomu
\q2 àti ti ìgbẹ́ ẹ Gomorra.
\q1 Èso àjàrà wọn kún fún oró,
\q2 ìdì wọn korò.
\q1
\v 33 Ọtí wáìnì wọn ìwọ ti dragoni ni,
\q2 àti oró mímú ti ejò paramọ́lẹ̀.
\b
\q1
\v 34 “Èmi kò to èyí jọ ní ìpamọ́
\q2 èmi kò sì fi èdìdì dì í ní ìṣúra mi?
\q1
\v 35 Ti èmi ni láti gbẹ̀san. Èmi yóò san án fún wọn
\q2 ní àkókò tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn yóò yọ;
\q1 ọjọ́ ìdààmú wọn súnmọ́ etílé
\q2 ohun tí ó sì ń bọ̀ wá bá wọn yára bọ̀.”
\b
\q1
\v 36 \nd Olúwa\nd* yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn an rẹ̀
\q2 yóò sì ṣàánú fún àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀
\q1 nígbà tí ó bá rí i pé agbára wọn lọ tán
\q2 tí kò sì sí ẹnìkan tí ó kù, ẹrú tàbí ọmọ.
\q1
\v 37 Yóò wí pé, “Òrìṣà wọn dà báyìí,
\q2 àpáta tí wọ́n fi ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé e wọn,
\q1
\v 38 ọlọ́run tí ó jẹ ọ̀rá ẹran ẹbọ wọn
\q2 tí ó ti mu ọtí i wáìnì ẹbọ ohun mímu wọn?
\q1 Jẹ́ kí wọn dìde láti gbà wọ́n!
\q2 Jẹ́ kí wọn ṣe ààbò fún un yín!
\b
\q1
\v 39 “Wò ó báyìí pé, Èmi fúnra à mi, Èmi ni!
\q2 Kò sí ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi.
\q1 Mo sọ di kíkú mo sì tún sọ di ààyè.
\q2 Mo ti ṣá lọ́gbẹ́ Èmi yóò sì mu jiná,
\q2 kò sí ẹni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ ọ̀ mi.
\q1
\v 40 Mo gbé ọwọ́ mi sókè ọ̀run mo sì wí pé,
\q2 Èmi ti wà láààyè títí láé,
\q1
\v 41 nígbà tí mo bá pọ́n idà dídán mi
\q2 àti tí mo bá sì fi ọwọ́ mi lé ìdájọ́,
\q1 Èmi yóò san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá mi
\q2 Èmi ó sì san fún àwọn tí ó kórìíra à mi.
\q1
\v 42 Èmi yóò mú ọfà mu ẹ̀jẹ̀,
\q2 nígbà tí idà mi bá jẹ ẹran:
\q1 ẹ̀jẹ̀ ẹni pípa àti ẹni ìgbèkùn,
\q2 láti orí àwọn aṣáájú ọ̀tá.”
\b
\q1
\v 43 \x - \xo 32.43: \xt Ro 15.10; Hb 1.6 (Septuagint); If 6.10; 19.2.\x*Ẹ yọ̀ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀
\q2 nítorí òun yóò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀;
\q1 yóò sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá a rẹ̀
\q2 yóò sì ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àti ènìyàn rẹ̀.
\p
\v 44 Mose sì wá ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí ní etí àwọn ènìyàn náà, òun, àti Hosea ọmọ Nuni.
\v 45 Nígbà tí Mose parí i kíka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí Israẹli.
\v 46 Ó sọ fún un pé, “Ẹ gbé ọkàn an yín lé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ láàrín yín lónìí, kí ẹ̀yin lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín láti gbọ́rọ̀ àti láti ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí.
\v 47 Wọn kì í ṣe ọ̀rọ̀ asán fún ọ, ìyè e yín ni wọ́n. Nípa wọn ni ẹ̀yin yóò gbé pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ń gòkè e Jordani lọ láti gbà.”
\s1 Ikú Mose lórí òkè Nebo
\p
\v 48 Ní ọjọ́ kan náà, \nd Olúwa\nd* sọ fún Mose pé,
\v 49 “Gòkè lọ sí Abarimu sí òkè Nebo ní Moabu, tí ó kọjú sí Jeriko, kí o sì wo ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ tí mo ń fi fún àwọn ọmọ Israẹli, bí ìní i wọn.
\v 50 Ní orí òkè tí ìwọ ń gùn lọ ìwọ yóò kùú níbẹ̀, kí a sì sin ọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin in rẹ Aaroni ti kú ní orí òkè Hori tí a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn an rẹ̀.
\v 51 Ìdí ni pé ẹ̀yin méjèèjì ṣẹ̀ sí mi láàrín àwọn ọmọ Israẹli ní ibi omi Meriba Kadeṣi ní aginjù Sini àti nítorí ẹ̀yin kò yà mí sí mímọ́ láàrín àwọn ọmọ Israẹli.
\v 52 Nítorí náà, ìwọ yóò rí ilẹ̀ náà ní ọ̀kánkán, o kì yóò wọ inú rẹ̀ ilẹ̀ ti mo ti fi fún àwọn ọmọ Israẹli.”
\c 33
\s1 Mose bùkún fún àwọn ẹ̀yà
\p
\v 1 Èyí ni ìbùkún tí Mose ènìyàn Ọlọ́run bùkún fún àwọn ọmọ Israẹli kí ó tó kú.
\v 2 Ó sì wí pé,
\q1 “\nd Olúwa\nd* ti Sinai wá,
\q2 ó sì yọ sí wọn láti Seiri wá
\q2 ó sì tàn án jáde láti òkè Parani wá.
\q1 Ó ti ọ̀dọ̀ ẹgbẹgbàarùn-ún àwọn mímọ́ wá
\q2 láti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni òfin kan a mú bí iná ti jáde fún wọn wá.
\q1
\v 3 Nítòótọ́, ó fẹ́ràn àwọn ènìyàn an rẹ̀,
\q2 gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ wà ní ọwọ́ rẹ̀.
\q1 Ní ẹsẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti foríbalẹ̀,
\q2 àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti ń gba ọ̀rọ̀,
\q1
\v 4 òfin tí Mose fi fún wa,
\q2 ìní ti ìjọ ènìyàn Jakọbu.
\q1
\v 5 Òun ni ọba lórí Jeṣuruni
\q2 ní ìgbà tí olórí àwọn ènìyàn péjọpọ̀,
\q2 pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Israẹli.
\b
\q1
\v 6 “Jẹ́ kí Reubeni yè kí ó má ṣe kú,
\q2 tàbí kí ènìyàn rẹ mọ níwọ̀n.”
\p
\v 7 Èyí ni ohun tí ó sọ nípa Juda:
\q1 “\nd Olúwa\nd* gbọ́ ohùn Juda
\q2 kí o sì mú tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ wá.
\q1 Kí ọwọ́ rẹ̀ kí ó tó fún un,
\q2 kí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀!”
\p
\v 8 Ní ti Lefi ó wí pé,
\q1 “Jẹ́ kí Tumimu àti Urimu rẹ kí ó wà
\q2 pẹ̀lú ẹni mímọ́ rẹ.
\q1 Ẹni tí ó dánwò ní Massa,
\q2 ìwọ bá jà ní omi Meriba.
\q1
\v 9 Ó wí fún baba àti ìyá rẹ pé,
\q2 Èmi kò buyì fún wọn.
\q1 Kò mọ àwọn arákùnrin rẹ̀,
\q2 tàbí mọ àwọn ọmọ rẹ̀,
\q1 ṣùgbọ́n ó dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀,
\q2 ó sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́.
\q1
\v 10 Ó kọ́ Jakọbu ní ìdájọ́ rẹ̀
\q2 àti Israẹli ní òfin rẹ̀.
\q1 Ó mú tùràrí wá síwájú rẹ̀
\q2 àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹbọ sísun sórí i pẹpẹ rẹ̀.
\q1
\v 11 Bùsi ohun ìní rẹ̀, \nd Olúwa\nd*,
\q2 kí o sì tẹ́wọ́gbà iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
\q1 Lu ẹgbẹ́ àwọn tí ó dìde sí i;
\q2 àwọn tí ó kórìíra rẹ̀,
\q2 kí wọn kí ó má ṣe dìde mọ́.”
\p
\v 12 Ní ti Benjamini ó wí pé,
\q1 “Jẹ́ kí olùfẹ́ \nd Olúwa\nd* máa gbé ní àlàáfíà lọ́dọ̀ rẹ̀,
\q2 òun a máa bò ó ní gbogbo ọjọ́,
\q2 ẹni tí \nd Olúwa\nd* fẹ́ràn yóò máa sinmi láàrín èjìká rẹ̀.”
\p
\v 13 Ní ti Josẹfu ó wí pé,
\q1 “Kí \nd Olúwa\nd* bùkún ilẹ̀ rẹ,
\q2 fún ohun iyebíye láti ọ̀run pẹ̀lú ìrì
\q2 àti ibú tí ó ń bẹ níṣàlẹ̀;
\q1
\v 14 àti fún èso iyebíye tí ọ̀run mú wá
\q2 àti ti ohun iyebíye tí ń dàgbà ní oṣooṣù;
\q1
\v 15 pẹ̀lú ohun pàtàkì òkè ńlá ìgbàanì
\q2 àti fún ohun iyebíye ìgbà ayérayé;
\q1
\v 16 Pẹ̀lú ohun iyebíye ayé àti ẹ̀kún un rẹ̀
\q2 àti fún ìfẹ́ ẹni tí ó ń gbé inú igbó.
\q1 Jẹ́ kí gbogbo èyí sinmi lé orí Josẹfu,
\q2 lórí àtàrí ẹni tí ó yàtọ̀ láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀.
\q1
\v 17 Ní ọláńlá ó dàbí àkọ́bí akọ màlúù;
\q2 ìwo rẹ̀, ìwo àgbáǹréré ni.
\q1 Pẹ̀lú wọn ni yóò fi ti àwọn orílẹ̀-èdè,
\q2 pàápàá títí dé òpin ayé.
\q1 Àwọn sì ni ẹgbẹẹgbàárùn mẹ́wàá Efraimu,
\q2 àwọn sì ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún Manase.”
\p
\v 18 Ní ti Sebuluni ó wí pé,
\q1 “Yọ̀ Sebuluni, ní ti ìjáde lọ rẹ,
\q2 àti ìwọ Isakari, nínú àgọ́ rẹ.
\q1
\v 19 Wọn yóò pe àwọn ènìyàn sórí òkè
\q2 àti níbẹ̀ wọn yóò rú ẹbọ òdodo,
\q1 wọn yóò mu nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òkun,
\q2 nínú ìṣúra tí ó pamọ́ nínú iyanrìn.”
\p
\v 20 Ní ti Gadi ó wí pé,
\q1 “Ìbùkún ni ẹni tí ó mú Gadi gbilẹ̀!
\q2 Gadi ń gbé níbẹ̀ bí kìnnìún,
\q2 ó sì fa apá ya, àní àtàrí.
\q1
\v 21 Ó sì yan ilẹ̀ tí ó dára jù fún ara rẹ̀;
\q2 ìpín olórí ni a sì fi fún un.
\q1 Nígbà tí ó rí tí gbogbo àwọn ènìyàn péjọ,
\q2 ó mú òdodo \nd Olúwa\nd* ṣẹ,
\q2 àti ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli.”
\p
\v 22 Ní ti Dani ó wí pé,
\q1 “Ọmọ kìnnìún ni Dani,
\q2 tí ń fò láti Baṣani wá.”
\p
\v 23 Ní ti Naftali ó wí pé,
\q1 “Ìwọ Naftali, kún fún ojúrere Ọlọ́run
\q2 àti ìbùkún \nd Olúwa\nd*;
\q2 yóò jogún ìhà ìwọ̀-oòrùn àti gúúsù.”
\p
\v 24 Ní ti Aṣeri ó wí pé,
\q1 “Ìbùkún ọmọ ni ti Aṣeri;
\q2 jẹ́ kí ó rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀
\q2 kí ó sì ri ẹsẹ̀ rẹ̀ sínú òróró.
\q1
\v 25 Bàtà rẹ̀ yóò jẹ́ irin àti idẹ,
\q2 agbára rẹ̀ yóò sì rí bí ọjọ́ rẹ̀.
\b
\q1
\v 26 “Kò sí ẹlòmíràn bí Ọlọ́run Jeṣuruni,
\q2 ẹni tí ń gun ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́ rẹ
\q2 àti ní ojú ọ̀run nínú ọláńlá rẹ̀.
\q1
\v 27 Ọlọ́run ayérayé ni ibi ìsádi rẹ,
\q2 àti ní ìsàlẹ̀ ni apá ayérayé wà.
\q1 Yóò lé àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ,
\q2 ó sì wí pé, ‘Ẹ máa parun!
\q1
\v 28 Israẹli nìkan yóò jókòó ní àlàáfíà,
\q2 orísun Jakọbu nìkan
\q1 ní ilẹ̀ ọkà àti ti ọtí wáìnì,
\q2 níbi tí ọ̀run ti ń sẹ ìrì sílẹ̀.
\q1
\v 29 Ìbùkún ni fún ọ, Israẹli,
\q2 ta ni ó dàbí rẹ,
\q2 ẹni tí a gbàlà láti ọ̀dọ̀ \nd Olúwa\nd*?
\q1 Òun ni asà àti ìrànwọ́ rẹ̀
\q2 àti idà ọláńlá rẹ̀.
\q1 Àwọn ọ̀tá rẹ yóò tẹríba fún ọ,
\q2 ìwọ yóò sì tẹ ibi gíga wọn mọ́lẹ̀.”
\c 34
\s1 Ikú Mose
\p
\v 1 Nígbà náà ni Mose gun òkè Nebo láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu sí orí Pisga tí ó dojúkọ Jeriko. Níbẹ̀ ni \nd Olúwa\nd* ti fi gbogbo ilẹ̀ hàn án láti Gileadi dé Dani,
\v 2 gbogbo Naftali, ilẹ̀ Efraimu àti Manase, gbogbo ilẹ̀ Juda títí dé Òkun Ńlá,
\v 3 gúúsù àti gbogbo àfonífojì Jeriko, ìlú ọlọ́pẹ dé Soari.
\v 4 Nígbà náà ní \nd Olúwa\nd* sọ fún un pé, “Èyí ni ilẹ̀ tí mo ṣèlérí lórí ìbúra fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu nígbà tí mo wí pé, Èmi yóò fi fún irú-ọmọ rẹ. Mo ti jẹ́ kí o rí i pẹ̀lú ojú rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò dé bẹ̀.”
\p
\v 5 Bẹ́ẹ̀ ni Mose ìránṣẹ́ \nd Olúwa\nd* kú ní ilẹ̀ Moabu, bí \nd Olúwa\nd* ti wí.
\v 6 Ó sì sin ín nínú àfonífojì ní ilẹ̀ Moabu, ní òdìkejì Beti-Peori, ṣùgbọ́n títí di òní yìí, kò sí ẹnìkan tí ó mọ ibi tí ibojì i rẹ̀ wà.
\v 7 Mose jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún nígbà tí ó kú, síbẹ̀ ojú rẹ̀ kò ṣe bàìbàì bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ kò dínkù.
\v 8 Àwọn ọmọ Israẹli sọkún un Mose ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ọgbọ̀n ọjọ́ títí di ìgbà tí ọjọ́ ẹkún àti ọ̀fọ̀ Mose parí.
\p
\v 9 Joṣua ọmọ Nuni kún fún ẹ̀mí ọgbọ́n nítorí Mose ti gbọ́wọ́ ọ rẹ̀ lé e lórí. Àwọn ọmọ Israẹli sì fetí sí i wọ́n sì ṣe ohun tí \nd Olúwa\nd* ti pàṣẹ fún Mose.
\p
\v 10 \x - \xo 34.10: \xt Nu 12.6-8.\x*Láti ìgbà náà kò sì sí wòlíì tí ó dìde ní Israẹli bí i Mose, ẹni tí \nd Olúwa\nd* mọ̀ lójúkojú,
\v 11 tí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tí \nd Olúwa\nd* rán an láti lọ ṣe ní Ejibiti sí Farao àti sí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ àti sí gbogbo ilẹ̀ náà.
\v 12 Nítorí kò sí ẹni tí ó tí ì fi gbogbo ọ̀rọ̀ agbára hàn, tàbí ṣe gbogbo ẹ̀rù ńlá tí Mose fihàn ní ojú gbogbo Israẹli.